Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 29

Àwọn Ìlànà fún Ìyàsọ́tọ̀ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 “Ohun tí o óo ṣe láti ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi nìyí: mú ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan, ati àgbò meji tí kò ní àbùkù,

2 mú burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ati àkàrà dídùn tí kò ní ìwúkàrà tí a fi òróró pò, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró sí lórí. Ìyẹ̀fun kíkúnná ni kí o fi ṣe wọ́n.

3 Kó àwọn burẹdi ati àkàrà náà sinu agbọ̀n kan, gbé wọn wá pẹlu akọ mààlúù ati àgbò mejeeji náà.

4 “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

5 Lẹ́yìn náà, kó àwọn aṣọ náà, wọ Aaroni lẹ́wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu, ati efodu náà, ati ìgbàyà. Lẹ́yìn náà, fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dì í ní àmùrè.

6 Fi fìlà náà dé e lórí, kí o sì gbé adé mímọ́ lé orí fìlà náà.

7 Gbé òróró ìyàsọ́tọ̀, kí o dà á lé e lórí láti yà á sọ́tọ̀.

8 “Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá, kí o sì wọ̀ wọ́n lẹ́wù,

9 dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi.

10 “Lẹ́yìn náà, mú akọ mààlúù náà wá siwaju àgọ́ àjọ, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé akọ mààlúù náà lórí.

11 Lẹ́yìn náà, pa akọ mààlúù náà níwájú OLUWA lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ.

12 Gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, kí o fi ìka rẹ tọ́ ọ sí ara ìwo pẹpẹ, kí o sì da ìyókù rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.

13 Fá gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati ẹ̀dọ̀ akọ mààlúù náà; mú kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n; kí o sun wọ́n lórí pẹpẹ náà.

14 Ṣugbọn lẹ́yìn ibùdó ni kí o ti fi iná sun ẹran ara rẹ̀, ati awọ rẹ̀, ati nǹkan inú rẹ̀, nítorí pé, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.

15 “Lẹ́yìn náà, mú ọ̀kan ninu àwọn àgbò mejeeji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí.

16 Lẹ́yìn náà, pa àgbò náà, sì gba ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o dà á sí ara pẹpẹ yíká.

17 Gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀. Dà wọ́n mọ́ àwọn tí o gé wẹ́wẹ́ ati orí rẹ̀,

18 kí o sì sun gbogbo wọn lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun olóòórùn dídùn ni sí OLUWA, àní ẹbọ tí a fi iná sun.

19 “Lẹ́yìn náà, mú àgbò keji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí.

20 Pa àgbò náà, kí o sì gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kí o tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn pẹlu. Lẹ́yìn náà, da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ara pẹpẹ yíká.

21 Mú lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lára pẹpẹ, sì mú ninu òróró tí wọ́n máa ń ta sí ni lórí, kí o wọ́n ọn sí Aaroni lórí ati sí ara ẹ̀wù rẹ̀, ati sí orí àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí ara ẹ̀wù wọn. Òun ati ẹ̀wù rẹ̀ yóo di mímọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹ̀wù wọn yóo sì di mímọ́ pẹlu.

22 “Mú ọ̀rá àgbò náà ati ìrù rẹ̀ tòun tọ̀rá rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun ati èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀; ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n ati itan rẹ̀ ọ̀tún, nítorí àgbò ìyàsímímọ́ ni.

23 Mú burẹdi kan, àkàrà dídùn kan pẹlu òróró, ati burẹdi pẹlẹbẹ láti inú agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí ó wà níwájú OLUWA.

24 Kó gbogbo wọn lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú OLUWA.

25 Lẹ́yìn náà, gba gbogbo àkàrà náà lọ́wọ́ wọn, kí o fi iná sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹlu ẹbọ sísun olóòórùn dídùn níwájú OLUWA, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA ni.

26 “Mú igẹ̀ àgbò tí a fi ya Aaroni sí mímọ́, kí o sì fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, èyí ni yóo jẹ́ ìpín tìrẹ.

27 “O óo ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́ ati itan tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa lára àgbò ìyàsímímọ́, nítorí pé, ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni.

28 Yóo máa jẹ́ ìpín ìran wọn títí lae, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa fún àwọn alufaa lára ẹbọ alaafia wọn; ẹbọ wọn sí OLUWA ni.

29 “Ẹ̀wù mímọ́ Aaroni yóo di ti arọmọdọmọ rẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn aṣọ mímọ́ náà ni wọn yóo máa wọ̀; wọn yóo máa wọ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá fi àmì òróró yàn wọ́n, tí wọ́n sì yà wọ́n sí mímọ́.

30 Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó bá di alufaa dípò rẹ̀ yóo wọ àwọn aṣọ wọnyi fún ọjọ́ meje, nígbà tí ó bá wá sí ibi àgọ́ àjọ.

31 “Mú àgbò ìyàsímímọ́ náà, kí o sì bọ ẹran ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan.

32 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo sì jẹ ẹran àgbò náà, ati burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.

33 Wọn yóo jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ètùtù láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, eniyan tí kì í bá ṣe alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni wọ́n.

34 Bí ẹran ìyàsímímọ́ ati burẹdi náà bá kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, fi iná sun ìyókù, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ nítorí pé mímọ́ ni.

35 “Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe sí Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni kí o fi yà wọ́n sí mímọ́.

36 Lojoojumọ ni kí o máa fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètùtù. O sì níláti máa rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún pẹpẹ náà nígbà tí o bá ń ṣe ètùtù fún un, ta òróró sí i láti yà á sí mímọ́.

37 Ọjọ́ meje ni o níláti fi ṣe ètùtù fún pẹpẹ, kí o sì yà á sí mímọ́, nígbà náà ni pẹpẹ náà yóo di mímọ́, ohunkohun tí ó bá sì kan pẹpẹ náà yóo di mímọ́ pẹlu.

Ẹbọ Ojoojumọ

38 “Ohun tí o óo máa fi rú ẹbọ lórí pẹpẹ lojoojumọ ni: ọ̀dọ́ aguntan meji, tí ó jẹ́ ọlọ́dún kan.

39 Fi ọ̀dọ́ aguntan kan rúbọ ní òwúrọ̀, sì fi ekeji rúbọ ní àṣáálẹ́.

40 Ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a pò pọ̀ mọ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ojúlówó epo olifi, ni kí o fi rúbọ pẹlu àgbò kinni, pẹlu idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ìtasílẹ̀.

41 Àṣaálẹ́ ni kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ọtí waini fún ìtasílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti òwúrọ̀. Ẹbọ olóòórùn dídùn ni, àní ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.

42 Atọmọdọmọ yín yóo máa rúbọ sísun náà nígbà gbogbo lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ, níwájú OLUWA, níbi tí n óo ti máa bá yín pàdé, tí n óo sì ti máa bá yín sọ̀rọ̀.

43 Ibẹ̀ ni n óo ti máa bá àwọn eniyan Israẹli pàdé, ògo mi yóo sì máa ya ibẹ̀ sí mímọ́.

44 N óo ya àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà sí mímọ́, ati Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, kí wọ́n lè máa sìn mí gẹ́gẹ́ bí alufaa.

45 N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.

46 Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí n lè máa gbé ààrin wọn. Èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 30

Pẹpẹ fún Sísun Turari

1 “Fi igi akasia tẹ́ pẹpẹ kan, tí wọn yóo máa sun turari lórí rẹ̀.

2 Kí gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, fífẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ kan. Ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí bákan náà, yóo sì ga ní igbọnwọ meji, àṣepọ̀ mọ́ ìwo rẹ̀ ni kí o ṣe é.

3 Fi ojúlówó wúrà bo òkè, ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, ati ìwo rẹ̀ pẹlu. Fi wúrà ṣe ìgbátí yí gbogbo etí rẹ̀ po.

4 Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà meji fún pẹpẹ náà, jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àwọn òrùka náà ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé pẹpẹ náà.

5 Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

6 Gbé e sílẹ̀ lóde aṣọ títa tí ó wà lẹ́bàá àpótí ẹ̀rí, lọ́gangan iwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lókè àpótí ẹ̀rí náà, níbi tí n óo ti máa ba yín pàdé.

7 Kí Aaroni máa sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀, ní àràárọ̀, nígbà tí ó bá ń tọ́jú àwọn fìtílà.

8 Nígbà tí ó bá ń gbé àwọn fìtílà náà sí ààyè wọn ní àṣáálẹ́, yóo máa sun turari náà pẹlu, títí lae ni yóo máa sun turari náà níwájú OLUWA ní ìrandíran yín.

9 Ẹ kò gbọdọ̀ sun turari tí ó jẹ́ aláìmọ́ lórí pẹpẹ náà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sun ẹbọ sísun lórí rẹ̀; tabi ẹbọ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù lórí rẹ̀.

10 Aaroni yóo máa ṣe ètùtù lórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo máa fi ṣe ètùtù náà lórí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní ìrandíran yín. Pẹpẹ náà yóo jẹ́ ohun èlò tí ó mọ́ jùlọ fún OLUWA.”

Owó Orí fún Àgọ́ Wíwà OLUWA

11 OLUWA sọ fún Mose pé,

12 “Nígbà tí o bá ka iye àwọn eniyan Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ mú ohun ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ wá fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn, nígbà tí o bá kà wọ́n.

13 Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.

14 Ẹnikẹ́ni tí a bá kà ní àkókò ìkànìyàn náà, tí ó bá tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó gbọdọ̀ san owó náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA.

15 Bí eniyan ti wù kí ó ní owó tó, kò gbọdọ̀ san ju ìdajì ṣekeli kan lọ; bí ó sì ti wù kí eniyan tòṣì tó, kò gbọdọ̀ san dín ní ìdajì ṣekeli kan, nígbà tí ẹ bá ń san ọrẹ OLUWA fún ìràpadà ẹ̀mí yín.

16 Gba owó ètùtù lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli, kí o sì máa lò ó fún iṣẹ́ ilé ìsìn àgọ́ àjọ, kí ó lè máa mú àwọn ọmọ Israẹli wá sí ìrántí níwájú OLUWA, kí ó sì lè jẹ́ ètùtù fún yín.”

Agbada Idẹ

17 OLUWA tún wí fún Mose pé,

18 “Fi idẹ ṣe agbada omi kan, kí ìdí rẹ̀ náà jẹ́ idẹ, gbé e sí ààrin àgọ́ àjọ ati pẹpẹ, kí o sì bu omi sinu rẹ̀.

19 Omi yìí ni Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo fi máa fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn.

20 Nígbà tí wọ́n bá ń wọ àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, láti rú ẹbọ sísun sí OLUWA; omi yìí ni wọ́n gbọdọ̀ fi fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n má baà kú.

21 Dandan ni kí wọ́n fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má baà kú. Èyí yóo di ìlànà fún wọn títí lae: fún òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ ní gbogbo ìran wọn.”

Òróró Ìyàsímímọ́

22 Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé,

23 “Mú ojúlówó àwọn nǹkan olóòórùn dídùn wọnyi kí o kó wọn jọ: ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli òjíá olómi, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli sinamoni, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli igi olóòórùn dídùn kan tí ó dàbí èèsún,

24 ati ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli kasia, ìwọ̀n ṣekeli ilé OLUWA ni kí wọ́n lò láti wọ̀n wọ́n. Lẹ́yìn náà, mú ìwọ̀n hini ojúlówó òróró olifi kan.

25 Pa gbogbo nǹkan wọnyi pọ̀, kí o fi ṣe òróró mímọ́ fún ìyàsímímọ́. Ṣe é bí àwọn ìpara olóòórùn dídùn, yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ fún OLUWA.

26 Ta òróró yìí sí ara àgọ́ àjọ, ati sí ara àpótí ẹ̀rí,

27 ati sí ara tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò orí rẹ̀, ati sí ara ọ̀pá fìtílà ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara pẹpẹ turari,

28 ati sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara agbada omi, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

29 Fi yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ patapata; ohunkohun tí ó bá kàn wọ́n yóo sì di mímọ́.

30 Ta òróró yìí sí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lórí, kí o fi yà wọ́n sí mímọ́; kí wọ́n lè máa ṣe alufaa fún mi.

31 Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Òróró yìí ni yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ ní ìrandíran yín,

32 ẹ kò gbọdọ̀ dà á sí ara àwọn eniyan lásán, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe òróró mìíràn tí ó dàbí rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

33 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀, tabi ẹnikẹ́ni tí ó bá dà á sórí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe alufaa, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.’ ”

Turari náà

34 OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà.

35 Lọ̀ wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí wọn ń ṣe turari, kí o fi iyọ̀ sí i; yóo sì jẹ́ mímọ́.

36 Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín.

37 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe irú turari náà fún ara yín, ṣugbọn ẹ mú un gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.

38 Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe irú rẹ̀, láti máa lò ó gẹ́gẹ́ bíi turari, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.”

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 31

Àwọn Òṣìṣẹ́ fún Àgọ́ OLUWA

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Wò ó, mo ti pe Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda.

3 Mo sì ti fi ẹ̀mí Ọlọrun kún inú rẹ̀, mo ti fún un ní òye ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà,

4 láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà,

5 láti dá oríṣìíríṣìí àrà sí ara òkúta ati láti tò ó, láti gbẹ́ igi ati láti fi oríṣìíríṣìí ohun èlò ṣe iṣẹ́ ọnà.

6 Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.

7 Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí àgọ́ àjọ, ati àpótí ẹ̀rí ati ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò àgọ́,

8 ati tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, pẹpẹ turari,

9 pẹpẹ ẹbọ sísun ati gbogbo ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀ ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀;

10 ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn,

11 ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.”

Ọjọ́ Ìsinmi

12 OLUWA rán Mose, ó ní,

13 “Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, nítorí pé òun ni àmì tí ó wà láàrin èmi pẹlu yín ní ìrandíran yín; kí ẹ lè mọ̀ pé, èmi OLUWA yà yín sọ́tọ̀ fún ara mi.

14 Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.

15 Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, èyí tí ó jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ ìsinmi, pípa ni kí wọ́n pa á.

16 Nítorí náà, àwọn eniyan Israẹli yóo máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, wọn yóo máa ranti rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì majẹmu ní ìrandíran wọn.

17 Ọjọ́ náà jẹ́ àmì ayérayé tí ó wà láàrin èmi ati àwọn eniyan Israẹli, pé ọjọ́ mẹfa ni èmi Ọlọrun fi dá ọ̀run ati ayé, ati pé ní ọjọ́ keje, mo dáwọ́ iṣẹ́ ṣíṣe dúró, mo sì sinmi.’ ”

18 Nígbà tí Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀ tán lórí òkè Sinai, ó fún un ní wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó fi ìka ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára àwọn wàláà náà.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 32

Ère Mààlúù Wúrà

1 Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i pé Mose ń pẹ́ jù lórí òkè, wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n tọ Aaroni lọ; wọ́n sọ fún un pé, “Ṣe oriṣa kan fún wa, tí yóo máa ṣáájú wa lọ; nítorí pé, a kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.”

2 Aaroni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gba gbogbo yẹtí wúrà etí àwọn aya yín jọ, ati ti àwọn ọmọkunrin yín, ati ti àwọn ọmọbinrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá.”

3 Gbogbo àwọn eniyan náà bá bọ́ yẹtí wúrà etí wọn jọ, wọ́n kó wọn tọ Aaroni lọ.

4 Aaroni gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, ó lo irinṣẹ́ àwọn alágbẹ̀dẹ, ó fi wúrà náà da ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan.

Àwọn eniyan náà bá dáhùn pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ọlọrun yín tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.”

5 Nígbà tí Aaroni rí i bẹ́ẹ̀, ó tẹ́ pẹpẹ kan siwaju ère náà, ó sì kéde pé, “Ọ̀la yóo jẹ́ ọjọ́ àjọ fún OLUWA.”

6 Wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ alaafia wá, wọ́n bá jókòó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn lòpọ̀.

7 OLUWA wí fún Mose pé, “Tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá ti ba ara wọn jẹ́.

8 Wọ́n ti yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn, wọ́n ti yá ère mààlúù kan, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí bọ ọ́, wọ́n sì ti ń rúbọ sí i. Wọ́n ń wí pé, ‘ọlọ́run yín nìyí Israẹli, ẹni tí ó mú yín gòkè wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ ”

9 OLUWA bá wí fún Mose pé, “Mo ti rí àwọn eniyan wọnyi, wò ó, alágídí ni wọ́n.

10 Dá mi dá wọn, inú ń bí mi sí wọn gidigidi, píparẹ́ ni n óo sì pa wọ́n rẹ́, ṣugbọn n óo sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.”

11 Ṣugbọn Mose bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí inú fi bí ọ tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ, àwọn tí o fi agbára ati tipátipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti?

12 Kí ló dé tí o óo fi jẹ́ kí àwọn ará Ijipti wí pé, o mọ̀ọ́nmọ̀ fẹ́ ṣe wọ́n níbi ni o fi kó wọn jáde láti pa wọ́n lórí òkè yìí, ati láti pa wọ́n rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Jọ̀wọ́, má bínú mọ, yí ọkàn rẹ pada, má sì ṣe ibi tí o ti pinnu láti ṣe sí àwọn eniyan rẹ.

13 Wo ti Abrahamu, ati Isaaki, ati Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn tí o ti fi ara rẹ búra fún pé o ó sọ arọmọdọmọ wọn di pupọ gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run; o ní gbogbo ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí ni o óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn; ati pé àwọn ni wọn yóo sì jogún rẹ̀ títí lae.”

14 Ọlọrun bá yí ọkàn rẹ̀ pada, kò sì ṣe ibi tí ó gbèrò láti ṣe sí àwọn eniyan náà mọ́.

15 Mose bá yipada, ó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, tòun ti wàláà òkúta ẹ̀rí mejeeji lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn wàláà òkúta tí Ọlọrun ti kọ nǹkan sí lójú mejeeji.

16 Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn wàláà òkúta náà, Ọlọrun tìkararẹ̀ ni ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára wọn.

17 Bí Joṣua ti gbọ́ ariwo àwọn eniyan náà tí wọn ń ké, ó wí fún Mose pé, “Ariwo ogun wà ninu àgọ́.”

18 Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “Èyí kì í ṣe ìhó ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe igbe ẹni tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, ìró orin ni èyí tí mò ń gbọ́ yìí.”

19 Bí ó ti súnmọ́ tòsí àgọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí ère ọmọ mààlúù, ó sì rí àwọn eniyan tí wọn ń jó. Inú bí Mose gidigidi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ju àwọn wàláà òkúta náà mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ òkè náà.

20 Ó mú ère ọmọ mààlúù náà, tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sun ún níná, ó lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, ó kù ú sójú omi, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Israẹli mu.

21 Mose bi Aaroni pé, “Kí ni àwọn eniyan wọnyi fi ṣe ọ́, tí o fi mú ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá yìí wá sórí wọn?”

22 Aaroni bá dáhùn, ó ní, “Má bínú, oluwa mi, ṣebí ìwọ náà mọ àwọn eniyan wọnyi pé eeyankeeyan ni wọ́n,

23 àwọn ni wọ́n wá bá mi tí wọ́n ní, ‘Ṣe oriṣa fún wa tí yóo máa ṣáájú wa lọ, nítorí pé a kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Mose, tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.’

24 Ni mo bá wí fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Wọ́n kó wọn fún mi, ni mo bá dà wọ́n sinu iná, òun ni mo sì fi yá ère mààlúù yìí.”

25 Nígbà tí Mose rí i pé Aaroni ti dá rúdurùdu sílẹ̀, láàrin àwọn eniyan náà, ati pé apá kò ká wọn mọ́, ọ̀rọ̀ náà sì sọ wọ́n di ẹni ìtìjú níwájú àwọn ọ̀tá wọn,

26 Mose bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ní, “Ẹ̀yin wo ni ẹ̀ ń ṣe ti OLUWA, ẹ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ọmọ Lefi bá kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

27 Mose wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ti wí, ó ní, ‘Gbogbo ẹ̀yin ọkunrin, ẹ sán idà yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín kí ẹ sì máa lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, jákèjádò ibùdó, kí olukuluku máa pa arakunrin rẹ̀ ati ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ati aládùúgbò rẹ̀.’ ”

28 Àwọn ọmọ Lefi sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, àwọn tí wọ́n kú láàrin àwọn eniyan náà tó ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin.

29 Mose bá wí fún wọn pé, “Lónìí ni ẹ yan ara yín fún iṣẹ́ OLUWA, olukuluku yín sì ti fi ẹ̀mí ọmọ rẹ̀, ati ti arakunrin rẹ̀ yan ara rẹ̀, kí ó lè tú ibukun rẹ̀ sí orí yín lónìí yìí.”

30 Ní ọjọ́ keji, Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, n óo tún gòkè tọ OLUWA lọ, bóyá n óo lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

31 Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn;

32 ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.”

33 OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi ni n óo pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé mi.

34 Pada lọ nisinsinyii, kí o sì kó àwọn eniyan náà lọ sí ibi tí mo sọ fún ọ. Ranti pé angẹli mi yóo máa ṣáájú yín lọ, ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo jẹ àwọn eniyan náà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

35 Nítorí náà, nígbà tó yá, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn burúkú kan sáàrin àwọn eniyan náà, nítorí pé wọ́n mú kí Aaroni fi wúrà yá ère mààlúù fún wọn.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 33

OLUWA Pàṣẹ Pé Kí Àwọn Eniyan Israẹli Kúrò ní Òkè Sinai

1 OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn.

2 N óo rán angẹli mi ṣáájú yín, n óo sì lé àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hamori, àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi jáde.

3 Ẹ lọ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá náà, tí ó kún fún wàrà ati oyin; n kò ní sí ní ààrin yín nígbà tí ẹ bá ń lọ, nítorí orí kunkun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo pa yín run lójú ọ̀nà.”

4 Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ ìròyìn burúkú náà, ọkàn wọn bàjẹ́, kò sì sí ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ sí ara rárá.

5 Nítorí náà, OLUWA rán Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé olóríkunkun ni wọ́n, ati pé bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sí ààrin wọn ní ìṣẹ́jú kan, òun yóo pa wọ́n run; nítorí náà, kí wọ́n kó gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, kí òun lè mọ ohun tí òun yóo fi wọ́n ṣe.

6 Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli bọ́ gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, ní òkè Horebu.

Àgọ́ Wíwà OLUWA

7 Mose a máa pa àgọ́ àjọ sí òkèèrè, lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli, ó sì sọ ọ́ ní àgọ́ àjọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní ohunkohun láti bèèrè lọ́dọ̀ OLUWA yóo lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà, tí ó wà lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.

8 Nígbàkúùgbà tí Mose bá ń lọ sí ibi àgọ́ àjọ, olukuluku á dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, wọn a sì máa wò ó títí yóo fi wọ inú àgọ́ àjọ lọ.

9 Bí Mose bá ti wọ inú àgọ́ àjọ náà lọ, ìkùukùu náà á sọ̀kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpó, a sì dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ náà. OLUWA yóo sì bá Mose sọ̀rọ̀.

10 Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan bá sì rí ìkùukùu tí ó dàbí òpó yìí, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, gbogbo àwọn eniyan á dìde, olukuluku wọn á sì sin OLUWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.

11 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú, bí eniyan ṣe ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí Mose bá pada sí ibùdó, Joṣua, iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, tí òun jẹ́ ọdọmọkunrin, kìí kúrò ninu àgọ́ àjọ.

OLUWA Ṣèlérí láti Wà Pẹlu Àwọn Eniyan Rẹ̀

12 Mose bá wí fún OLUWA pé, “Ṣebí ìwọ OLUWA ni o sọ pé kí n kó àwọn eniyan wọnyi wá, ṣugbọn o kò tíì fi ẹni tí o óo rán ṣìkejì mi hàn mí. Sibẹsibẹ, o wí pé, o mọ̀ mí o sì mọ orúkọ mi, ati pé mo ti rí ojurere rẹ.

13 Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, bí inú rẹ bá dùn sí mi, fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kí n lè mọ̀ ọ́, kí ǹ sì lè bá ojurere rẹ pàdé. Sì ranti pé àwọn eniyan rẹ ni àwọn eniyan wọnyi.”

14 OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Ojú mi yóo máa bá ọ lọ, n óo sì fún ọ ní ìsinmi.”

15 Mose wí fún OLUWA pé, “Bí o kò bá ní bá wa lọ, má wulẹ̀ kó wa kúrò níhìn-ín.

16 Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.”

17 OLUWA dá Mose lóhùn pé, “N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.”

18 Mose dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.”

19 OLUWA sì dá Mose lóhùn pé, “N óo mú kí ẹwà mi kọjá níwájú rẹ; n óo sì pe orúkọ mímọ́ mi lójú rẹ, èmi ni OLUWA, èmi a máa yọ́nú sí àwọn tí ó bá wù mí, èmi a sì máa ṣàánú fún àwọn tí mo bá fẹ́.”

20 OLUWA ní, “O kò lè rí ojú mi nítorí pé eniyan kò lè rí ojú mi kí ó wà láàyè.”

21 OLUWA tún dáhùn pé, “Ibìkan wà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, wá dúró lórí òkúta kan níbẹ̀.

22 Nígbà tí ògo mi bá ń kọjá lọ, n óo pa ọ́ mọ́ ninu ihò òkúta yìí, n óo sì fi ọwọ́ mi bò ọ́ lójú nígbà tí mo bá ń rékọjá.

23 Lẹ́yìn náà, n óo ká ọwọ́ mi kúrò, o óo sì rí àkẹ̀yìnsí mi, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí ojú mi.”

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 34

Àwọn Wàláà Òkúta Keji

1 Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Gbẹ́ wàláà òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, n óo sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ sára wàláà ti àkọ́kọ́ tí ó fọ́ sára wọn.

2 Múra ní àárọ̀ ọ̀la, kí o gun òkè Sinai wá, kí o wá farahàn mí lórí òkè náà.

3 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá ọ wá, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ sí níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, àwọn mààlúù, tabi àwọn aguntan kò gbọdọ̀ jẹ káàkiri níbikíbi lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà.”

4 Mose bá gbẹ́ wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gun òkè Sinai lọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un; ó kó àwọn wàláà òkúta mejeeji náà lọ́wọ́.

5 OLUWA tún sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu ó dúró níbẹ̀ pẹlu rẹ̀, ó sì pe orúkọ mímọ́ ara rẹ̀.

6 OLUWA kọjá níwájú rẹ̀, ó sì kéde orúkọ ara rẹ̀ báyìí pé, “OLUWA Ọlọrun aláàánú ati olóore, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ ní àánú ati òtítọ́.

7 Ẹni tí ó máa ń ṣàánú fún ẹgbẹẹgbẹrun, tí ó máa ń dárí àìṣedéédé ji eniyan, ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀, ati ìrékọjá jì, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ láìjìyà, a sì máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.”

8 Mose yára tẹ orí ba, ó dojú bolẹ̀, ó sì sin OLUWA.

9 Ó ní, “Bí inú rẹ bá dùn sí mi nítòótọ́, OLUWA, jọ̀wọ́, máa wà láàrin wa, nígbà tí a bá ń lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóríkunkun ni àwọn eniyan náà; dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé wa jì wá, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí eniyan rẹ.”

Ọlọrun tún Majẹmu Ṣe

10 OLUWA wí fún Mose pé, “Mo dá majẹmu kan, n óo ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú àwọn eniyan náà, irú èyí tí ẹnikẹ́ni kò rí rí ní gbogbo ayé tabi láàrin orílẹ̀-èdè kankan. Gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń gbé ààrin wọn yóo sì rí iṣẹ́ OLUWA, nítorí ohun tí n óo ṣe fún wọn yóo bani lẹ́rù jọjọ.

11 “Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ.

12 Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ rí i pé ẹ kò bá àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá majẹmu kankan, kí wọn má baà dàbí tàkúté tí a dẹ sí ààrin yín.

13 Ṣugbọn, ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ gbogbo àwọn ère wọn, kí ẹ sì gé gbogbo igbó oriṣa wọn lulẹ̀.

14 “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, nítorí èmi OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ owú, Ọlọrun tíí máa jowú ni mí.

15 Ẹ kò gbọdọ̀ bá ẹnikẹ́ni dá majẹmu ninu gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà, kí ẹ má baà bá wọn dá majẹmu tán, kí ó wá di pé, nígbà tí wọn bá ń rúbọ sí oriṣa wọn, tí wọn sì ń ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn, wọn óo máa pè yín, pé kí ẹ máa lọ bá wọn jẹ ninu ẹbọ wọn.

16 Kó má baà wá di pé ẹ̀ ń fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín, kí àwọn ọmọbinrin yín má baà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa, kí wọ́n sì mú kí àwọn ọmọkunrin yín náà máa ṣe ìṣekúṣe nídìí oriṣa wọn.

17 “Ẹ kò gbọdọ̀ yá ère fún ara yín.

18 “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ àìwúkàrà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ fún ọjọ́ meje ní àkókò àjọ náà, ninu oṣù Abibu, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún yín, nítorí pé ninu oṣù Abibu ni ẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti.

19 “Tèmi ni gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ àkọ́bí, gbogbo àkọ́bí ẹran: kì báà jẹ́ ti mààlúù, tabi ti aguntan.

20 Ṣugbọn ọ̀dọ́ aguntan ni kí ẹ máa fi ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí ó bá jẹ́ akọ pada, tí ẹ kò bá fẹ́ rà á pada, ẹ gbọdọ̀ lọ́ ọ lọ́rùn pa. Gbogbo àkọ́bí yín lọkunrin, ni ẹ gbọdọ̀ rà pada.

“Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá siwaju mi ní ọwọ́ òfo láti sìn mí.

21 “Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣe iṣẹ́ yín, ní ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ sinmi; kì báà ṣe àkókò oko ríro, tabi àkókò ìkórè, dandan ni kí ẹ sinmi.

22 “Ẹ gbọdọ̀ máa ṣe àjọ̀dún ọ̀sẹ̀ ìkórè àkọ́so alikama ọkà yín, ati àjọ̀dún ìkójọ nígbà tí ẹ bá ń kórè nǹkan oko sinu abà ní òpin ọdún.

23 “Ẹẹmẹta lọdọọdun, ni gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun Israẹli, kí wọ́n wá sìn mí.

24 Nítorí pé n óo lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún yín, n óo sì fẹ ààlà yín sẹ́yìn. Kò sì ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo fẹ́ gba ilẹ̀ yín nígbà tí ẹ bá lọ sin OLUWA Ọlọrun yín, lẹẹmẹtẹẹta lọdọọdun.

25 “Ẹ kò gbọdọ̀ fi ẹran rúbọ sí mi pẹlu ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni ohunkohun tí ẹ bá sì fi rú ẹbọ àjọ̀dún ìrékọjá kò gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji.

26 “Ẹ gbọdọ̀ mú àkọ́so oko yín wá sí ilé OLUWA Ọlọrun yín.

“Ẹ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi ọmú ìyá rẹ̀.”

27 OLUWA wí fún Mose pé, “Kọ ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀, nítorí pé òun ni majẹmu mi dúró lé lórí pẹlu ìwọ ati Israẹli.”

28 Mose sì wà pẹlu OLUWA fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ó sì kọ ọ̀rọ̀ majẹmu náà, tíí ṣe òfin mẹ́wàá, sára àwọn wàláà òkúta náà.

Mose Sọ̀kalẹ̀ láti Orí Òkè Sinai

29 Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ pada ti orí òkè Sinai dé, pẹlu wàláà ẹ̀rí meji lọ́wọ́ rẹ̀, Mose kò mọ̀ pé ojú òun ń dán, ó sì ń kọ mànàmànà, nítorí pé ó bá Ọlọrun sọ̀rọ̀.

30 Nígbà tí Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, wọ́n ṣe akiyesi pé ojú rẹ̀ ń kọ mànàmànà, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn.

31 Ṣugbọn Mose pè wọ́n, Aaroni ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.

32 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun bá a sọ lórí òkè Sinai lófin fún wọn.

33 Lẹ́yìn tí Mose bá wọn sọ̀rọ̀ tán ó fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀.

34 Ṣugbọn nígbà tí Mose bá wọlé lọ, láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, a máa mú aṣọ ìbòjú náà kúrò ní ojú títí yóo fi jáde, nígbà tí ó bá sì jáde, yóo sọ ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli.

35 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe akiyesi ojú Mose, pé ó ń kọ mànàmànà; Mose a sì máa fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí yóo fi di ìgbà tí yóo tún wọ ilé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 35

Àwọn ìlànà fún Ọjọ́ Ìsinmi

1 Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí:

2 Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á.

3 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”

Àwọn Ẹ̀bùn fún Kíkọ́ Àgọ́ Mímọ́

4 Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní,

5 ‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ,

6 aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́;

7 awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia,

8 òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn,

9 òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’

Àwọn Ohun Èlò fún Kíkọ́ Àgọ́ Mímọ́ OLUWA

10 “Kí gbogbo ọkunrin tí ó bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ ninu yín jáde wá láti ṣe àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ wọnyi:

11 àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn.

12 Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀.

13 Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀.

14 Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn.

15 Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

16 Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

17 Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.

18 Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn;

19 àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.”

Àwọn Eniyan Mú Ọrẹ Wá

20 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose.

21 Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa.

22 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA.

23 Gbogbo àwọn tí wọ́n ní aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò, tabi aṣọ pupa, tabi aṣọ funfun, tabi irun ewúrẹ́, tabi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, tabi awọ ewúrẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn wá.

24 Gbogbo àwọn tí wọ́n lè fi fadaka ati idẹ tọrẹ fún OLUWA ni wọ́n mú wọn wá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí wọ́n ní igi akasia, tí ó wúlò náà mú wọn wá pẹlu.

25 Gbogbo àwọn obinrin tí wọ́n mọ òwú ran ni wọ́n ran òwú tí wọ́n sì kó o wá: àwọn òwú aláwọ̀ aró, elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati funfun tí wọ́n fi ń hun aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.

26 Gbogbo àwọn obinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún, tí wọ́n sì mọ irun ewúrẹ́ ran, ni wọ́n ran án wá.

27 Àwọn àgbààgbà mú òkúta onikisi wá ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà,

28 ati oríṣìíríṣìí èròjà ati òróró ìtànná, ati ti ìyàsímímọ́, ati fún turari olóòórùn dídùn.

29 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọkunrin ati lobinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún ni wọ́n mú ọrẹ àtinúwá wá fún OLUWA, láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.

Àwọn Oníṣẹ́ Ọnà fún Àgọ́ Mímọ́ OLUWA

30 Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “OLUWA fúnra rẹ̀ ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda.

31 Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sinu rẹ̀, ó sì ti fún un ní ọgbọ́n, òye, ati ìmọ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà,

32 láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà;

33 láti gé oríṣìíríṣìí òkúta iyebíye ati láti tò wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni igi gbígbẹ́ ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà ṣíṣe.

34 Ọlọrun sì ti mí ìmísí rẹ̀ sí i ninu láti kọ́ ẹlòmíràn, àtòun ati Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani.

35 Ọlọrun ti fún wọn ní ìmọ̀ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí àwọn oníṣọ̀nà máa ń ṣe, ati ti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati ti àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ, ìbáà jẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò tabi aṣọ pupa tabi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tabi oríṣìí aṣọ mìíràn, gbogbo iṣẹ́ ọnà ni wọn yóo máa ṣe; kò sì sí iṣẹ́ ọnà tí wọn kò lè ṣe.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 36

1 “Kí Besaleli, ati Oholiabu ati olukuluku àwọn tí OLUWA fún ní ìmọ̀ ati òye, láti ṣe èyíkéyìí ninu iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ kíkọ́ ilé mímọ́ náà, ṣe é bí OLUWA ti pa á láṣẹ gan-an.”

Àwọn Eniyan Mú Ọpọlọpọ Ẹ̀bùn Wá

2 Mose bá pe Besaleli ati Oholiabu, ati olukuluku àwọn tí OLUWA ti fún ní ìmọ̀ ati òye ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ náà láti wá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.

3 Àwọn òṣìṣẹ́ náà gba gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ àgọ́ mímọ́ náà lọ́wọ́ Mose. Àwọn eniyan ṣá tún ń mú ọrẹ àtinúwá yìí tọ Mose lọ ní àràárọ̀.

4 Wọ́n mú ọrẹ wá tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ náà tọ Mose lọ;

5 wọ́n sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn eniyan náà mú wá ti pọ̀ ju ohun tí a nílò láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wa.”

6 Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́;

7 nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà.

Kíkọ́ Àgọ́ Mímọ́ Wíwà OLUWA

8 Àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ jù lára àwọn òṣìṣẹ́ náà kọ́ ibi mímọ́ náà pẹlu aṣọ títa mẹ́wàá. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ati aṣọ ẹlẹ́pa ati elése àlùkò ati aṣọ pupa fòò ni wọ́n fi ṣe àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ya àwòrán kerubu sára rẹ̀; wọn fi dárà sí i.

9 Gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, gbogbo wọn rí bákan náà.

10 Ó rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, ó sì rán marun-un yòókù pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

11 Ó mú aṣọ aláwọ̀ aró, wọ́n fi rán ojóbó sára aṣọ títa tí ó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ kinni, wọ́n sì tún rán ojóbó sára aṣọ títa tó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ keji bákan náà.

12 Aadọta ojóbó ni wọ́n rán mọ́ àránpọ̀ aṣọ títa kinni, aadọta ojóbó náà ni wọ́n sì rán mọ́ etí àránpọ̀ aṣọ títa keji, àwọn ojóbó náà dojú kọ ara wọn.

13 Wọ́n ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, wọ́n fi àwọn ìkọ́ náà kọ́ àránpọ̀ aṣọ títa náà mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni àgọ́ náà ṣe di odidi kan.

14 Wọ́n tún mú aṣọ títa mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, wọ́n rán an pọ̀, wọ́n fi ṣe ìbòrí sí àgọ́ náà.

15 Gígùn aṣọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin; bákan náà ni òòró ati ìbú àwọn aṣọ mọkọọkanla.

16 Wọ́n rán marun-un pọ̀ ninu àwọn aṣọ títa náà, lẹ́yìn náà ó rán mẹfa yòókù pọ̀.

17 Wọ́n ṣe aadọta ojóbó sára èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ kinni, ati èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ keji.

18 Wọ́n sì ṣe aadọta ìkọ́ idẹ láti fi mú aṣọ àgọ́ náà papọ̀ kí ó lè di ẹyọ kan ṣoṣo.

19 Wọ́n fi awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní pupa ati awọ ewúrẹ́ ṣe ìbòrí àgọ́ náà.

20 Lẹ́yìn náà, wọ́n fi igi akasia ṣe àkànpọ̀ igi tí ó dúró lóòró fún àgọ́ náà.

21 Gígùn àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

22 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àkànpọ̀ igi náà ní ìkọ́ meji meji láti fi mú wọn pọ̀ mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe gbogbo àwọn àkànpọ̀ igi àgọ́ náà.

23 Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún apá gúsù àgọ́ náà,

24 wọ́n sì ṣe ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka tí wọ́n fi sí abẹ́ ogún àkànpọ̀ igi náà, ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìkọ́ rẹ̀ mejeeji.

25 Wọ́n ṣe ogún àkànpọ̀ igi fún ẹ̀gbẹ́ àríwá àgọ́ mímọ́ náà,

26 pẹlu ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka; ìtẹ́lẹ̀ meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

27 Wọ́n ṣe àkànpọ̀ igi mẹfa fún ẹ̀yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.

28 Wọ́n sì ṣe àkànpọ̀ igi meji fún igun àgọ́ náà tí ó wà ní apá ẹ̀yìn.

29 Àwọn àkànpọ̀ igi náà wà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn wọ́n so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi òrùka kinni, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn àkànpọ̀ igi kinni ati ekeji fún igun mejeeji àgọ́ náà.

30 Àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní igun kinni-keji jẹ́ mẹjọ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrindinlogun, ìtẹ́lẹ̀ meji meji wà lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

31 Wọ́n fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú mẹẹdogun, marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ gúsù,

32 marun-un fún àwọn ti ẹ̀gbẹ́ àríwá, marun-un fún àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn, lápá ìwọ̀ oòrùn àgọ́ náà.

33 Wọ́n fi ọ̀pá ìdábùú kan la àwọn àkànpọ̀ igi náà láàrin, ọ̀pá náà kan igun kinni-keji àgọ́ náà.

34 Wọ́n yọ́ wúrà bo gbogbo àkànpọ̀ igi náà, wọ́n fi wúrà ṣe ìkọ́ fún àwọn àkànpọ̀ igi náà, wọ́n sì yọ́ wúrà bo àwọn ọ̀pá ìdábùú náà pẹlu.

35 Aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe aṣọ àgọ́ náà, wọ́n sì ya àwòrán Kerubu sí i lára.

36 Wọ́n fi igi akasia ṣe òpó mẹrin, wọ́n sì yọ́ wúrà bò ó. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, wọ́n sì fi fadaka ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹrin fún àwọn òpó náà.

37 Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà sí i lára.

38 Òpó marun-un ni wọ́n ṣe fún àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ṣe ìkọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n yọ́ wúrà bo àwọn òpó náà, ati àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi gbé àwọn aṣọ títa náà kọ́, ṣugbọn idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn maraarun.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 37

Kíkan Àpótí Ẹ̀rí

1 Besaleli fi igi akasia àpótí ẹ̀rí náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀, ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀.

2 Ó yọ́ wúrà bò ó ninu ati lóde, ó sì tún fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀.

3 Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà, òrùka meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji.

4 Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

5 Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà láti máa fi gbé e.

6 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

7 Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà,

8 Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji.

9 Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú.

Tabili Àkàrà Ìrúbọ sí Ọlọrun

10 Ó fi igi akasia kan tabili kan; gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

11 Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀.

12 Ìgbátí tí ó ṣe náà fẹ̀ ní àtẹ́lẹwọ́ kan ati ààbọ̀.

13 Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin tabili náà lábẹ́ ìgbátí rẹ̀,

14 àwọn òrùka yìí ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà.

15 Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá tí wọ́n fi máa ń gbé tabili náà, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

16 Wúrà ni ó fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí yóo máa wà lórí tabili náà: àwọn àwo pẹrẹsẹ ati àwọn àwo kòtò fún turari, abọ́, ati ife tí wọn yóo máa fi ta nǹkan sílẹ̀ fún ètùtù.

Ṣíṣe Ọ̀pá Fìtílà

17 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá ìgbámú rẹ̀, àṣepọ̀ ni ó ṣe é, pẹlu àwọn fìtílà rẹ̀, ati àwọn kinní kan bí òdòdó tí ó fi dárà sí i lára.

18 Ẹ̀ka mẹfa ni ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà; mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji.

19 Ó ṣe àwọn kinní kan bí òdòdó alimọndi mẹta mẹta sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà.

20 Ife mẹrin ni ó ṣe sórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí òdòdó alimọndi pẹlu ìrudi ati ìtànná rẹ̀.

21 Ìrudi kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó so mọ́ ara ọ̀pá fìtílà náà lọ́nà mẹtẹẹta.

22 Àṣepọ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà ati ẹ̀ka ara rẹ̀ ati ìrudi abẹ́ wọn; ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe wọ́n.

23 Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà.

24 Odidi talẹnti wúrà marundinlaadọrin ni ó lò lórí ọ̀pá fìtílà yìí ati àwọn ohun èlò tí wọ́n jẹ mọ́ ti ọ̀pá fìtílà.

Ṣíṣe Pẹpẹ fún Sísun Turari

25 Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ turari kan, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ rẹ̀ rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é pẹlu ìwo rẹ̀ mẹrẹẹrin.

26 Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ati òkè ati ẹ̀gbẹ́ ati abẹ́ rẹ̀, ati ìwo rẹ̀ pẹlu, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀.

27 Ó da òrùka wúrà meji meji, ó jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí pẹpẹ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni-keji, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà.

28 Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá rẹ̀, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

Ṣíṣe Òróró Ìyàsímímọ́ ati Turari

29 Ó ṣe òróró ìyàsímímọ́ ati turari olóòórùn dídùn bí àwọn tí wọn ń ṣe turari ṣe máa ń ṣe é.

Categories
ẸKISODU

ẸKISODU 38

Ṣíṣe Pẹpẹ fún Ẹbọ Sísun

1 Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ pẹpẹ náà rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta.

2 Ó ṣe ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin pẹpẹ náà, àṣepọ̀ mọ́ pẹpẹ ni ó ṣe àwọn ìwo náà, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.

3 Ó fi idẹ ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ náà: àwọn bíi ìkòkò, ọ̀kọ̀, agbada, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń mú ẹran ati àwo ìfọnná; idẹ ni ó fi ṣe gbogbo wọn.

4 Ó fi idẹ ṣe ayanran ààrò kan fún pẹpẹ náà, ó ṣe é mọ́ abẹ́ ìgbátí rẹ̀, ayanran náà sì bò ó dé agbede meji sí ìsàlẹ̀.

5 Ó da òrùka mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan ayanran idẹ náà, àwọn òrùka wọnyi ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà.

6 Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.

7 Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà láti máa fi gbé e; pákó ni ó fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ní ihò ninu.

Ṣíṣe Agbada Idẹ

8 Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

Àgbàlá Àgọ́ Wíwà OLUWA

9 Ó ṣe àgbàlá kan, aṣọ funfun, onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni ó fi ṣe aṣọ títa ìhà gúsù àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ.

10 Ogún ni àwọn òpó aṣọ títa, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn náà sì jẹ́ ogún. Idẹ ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni ó fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

11 Gígùn apá àríwá àgọ́ náà jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ pẹlu, ogún ni àwọn òpó rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn sì jẹ́ ogún pẹlu. Idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

12 Gígùn aṣọ títa fún apá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ aadọta igbọnwọ, òpó rẹ̀ jẹ́ mẹ́wàá, àwọn àtẹ̀bọ̀ rẹ̀ náà jẹ́ mẹ́wàá; fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

13 Aṣọ títa ti iwájú àgọ́ náà, ní apá ìlà oòrùn gùn ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ.

14 Aṣọ títa fún apá kan ẹnu ọ̀nà jẹ́ igbọnwọ mẹẹdogun, ó ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta.

15 Bákan náà ni aṣọ títa ẹ̀gbẹ́ kinni keji ẹnu ọ̀nà náà rí, wọ́n gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹẹdogun mẹẹdogun, wọ́n ní òpó mẹta mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta mẹta.

16 Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi ṣe gbogbo aṣọ títa tí ó wà ninu àgbàlá náà.

17 Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó rẹ̀; ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn, fadaka ni wọ́n yọ́ bo àwọn ìbòrí wọn, fadaka ni wọ́n sì fi bo gbogbo àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.

18 Wọ́n fi abẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró, ati aṣọ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ó gùn ní ogún igbọnwọ, ó sì ga ní igbọnwọ marun-un gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣọ títa ti àgbàlá náà.

19 Òpó mẹrin ni aṣọ títa tí ẹnu ọ̀nà yìí ní, pẹlu ìtẹ́lẹ̀ idẹ mẹrin. Fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, fadaka ni wọ́n sì fi bo àwọn ìbòrí òpó náà.

20 Idẹ ni wọ́n fi ṣe gbogbo àwọn èèkàn àgọ́ náà, ati ti gbogbo àgbàlá rẹ̀.

Oríṣìíríṣìí Irin tí Wọ́n Lò fún Àgọ́ Ẹ̀rí Wíwà OLUWA

21 Ìṣirò ohun tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ ẹ̀rí wíwà OLUWA nìyí: Mose ni ó pàṣẹ pé kí ọmọ Lefi ṣe ìṣirò àwọn ohun tí wọ́n lò lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni, alufaa.

22 Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún Mose.

23 Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, wà pẹlu rẹ̀. Oholiabu yìí mọ iṣẹ́ ọnà gan-an. Bákan náà, ó lè lo aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà.

24 Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n.

25 Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ.

26 Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550).

27 Ọgọrun-un talẹnti fadaka yìí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó ilé OLUWA ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn aṣọ títa. Ọgọrun-un talẹnti ni wọ́n lò láti ṣe ọgọrun-un ìtẹ́lẹ̀, talẹnti kọ̀ọ̀kan fún ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

28 Ninu ẹẹdẹgbẹsan ó lé marundinlọgọrin (1,775) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni ó ti ṣe àwọn ìkọ́ fún àwọn òpó náà, ara rẹ̀ ni ó yọ́ lé àwọn ìbòrí wọn, tí ó sì tún fi ṣe àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.

29 Àwọn idẹ tí wọ́n dájọ jẹ́ aadọrin ìwọ̀n talẹnti ati ẹgbaa ó lé irinwo (2,400) ìwọ̀n ṣekeli.

30 Idẹ yìí ni ó lò láti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn ìlẹ̀kùn àgọ́ àjọ, ati pẹpẹ onídẹ, ati àwọn idẹ inú rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò ibi pẹpẹ náà.

31 Lára rẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó àgọ́ náà yípo ati àwọn èèkàn àgọ́ ati àwọn èèkàn àgbàlá inú rẹ̀.