Categories
JOBU

JOBU 37

1 “Nígbà tí mo gbọ́, ọkàn mi wárìrì,

ó sì fò sókè ní ipò rẹ̀.

2 Gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ń dún bí ààrá,

ati ariwo tí ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.

3 Ó rán mànàmáná rẹ̀ sí wọn jákèjádò ojú ọ̀run,

títí dé òpin ilẹ̀ ayé.

4 Lẹ́yìn náà, a gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,

ó sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá rẹ̀,

bí ìgbà tí ààrá bá sán,

sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúró

bí àwọn eniyan ti ń gbóhùn rẹ̀.

5 Ohùn Ọlọrun dún bí ààrá tìyanu-tìyanu,

a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

6 Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀,

bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli,

ati ọ̀wààrà òjò.

7 Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò,

kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.

8 Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ,

wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́.

9 Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀,

òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.

10 Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá,

gbogbo omi inú odò sì dì.

11 Ó fi omi kún inú ìkùukùu,

ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.

12 Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀,

láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.

13 Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀,

bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀,

tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

14 “Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu,

dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.

15 Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ,

tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?

16 Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀,

iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;

17 ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́

nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?

18 Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ,

kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán?

19 Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ,

a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀,

nítorí àìmọ̀kan wa.

20 Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni?

Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì?

21 “Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run

nígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma,

nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.

22 Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ,

ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.

23 Àwámárìídìí ni Olodumare–

agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀.

24 Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀,

kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.”

Categories
JOBU

JOBU 38

OLUWA dá Jobu Lóhùn

1 Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle.

2 Ó bi í pé,

“Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn,

tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀?

3 Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin,

mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn.

4 Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?

Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi.

5 Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀–

ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn!

Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀?

6 Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé,

àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀;

7 tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin,

tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀?

8 Ta ló tìlẹ̀kùn mọ́ òkun,

nígbà tí ó ń ru jáde,

9 tí mo fi awọsanma ṣe ẹ̀wù rẹ̀,

tí òkùnkùn biribiri sì jẹ́ ọ̀já ìgbànú rẹ̀,

10 tí mo sì pa ààlà fún un,

tí mo sé ìlẹ̀kùn mọ́ ọn,

11 tí mo wí pé, ‘Dúró níhìn-ín, o kò gbọdọ̀ kọjá ibẹ̀,

ibí ni ìgbì líle rẹ ti gbọdọ̀ dáwọ́ dúró?’

12 Jobu, láti ọjọ́ tí o ti dé ayé,

ǹjẹ́ o ti pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mọ́ rí,

tabi pé kí àfẹ̀mọ́jú mọ́ àkókò rẹ̀,

13 kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn sí gbogbo ayé,

kí ó sì lè gbọn àwọn ẹni ibi dànù,

kúrò ní ibi ìsápamọ́sí wọn?

14 A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀,

ati bí aṣọ tí a pa láró.

15 A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi,

a sì ká wọn lápá kò.

16 “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí,

tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí?

17 Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí,

tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí?

18 Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó?

Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi.

19 “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀,

ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn,

20 tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀,

tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀?

21 Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà,

o sá ti dàgbà!

22 “Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí,

tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí,

23 àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu,

fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà?

24 Ṣé o mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn wá,

tabi ibi tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sórí ayé?

25 “Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò,

ati fún ààrá,

26 láti rọ òjò sí orí ilẹ̀ níbi tí kò sí eniyan,

ati ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ẹnikẹ́ni?

27 Láti tẹ́ aṣálẹ̀ lọ́rùn,

ati láti mú kí ilẹ̀ hu koríko?

28 Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì?

29 Ìyá wo ló bí yìnyín,

inú ta ni òjò dídì sì ti jáde?

30 Ó sọ omi odò di líle bí òkúta,

ojú ibú sì dì bíi yìnyín.

31 “Ṣé o lè fokùn so ìràwọ̀ Pileiadesi,

tabi kí o tú okùn ìràwọ̀ Orioni?

32 Ṣé o lè darí àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀, ní àkókò wọn,

tabi kí o ṣe atọ́nà ìràwọ̀ Beari ati àwọn ọmọ rẹ̀?

33 Ṣé o mọ àwọn òfin tí ó de ojú ọ̀run?

Tabi o lè fìdí wọn múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

34 “Ǹjẹ́ o lè pàṣẹ fún ìkùukùu pé,

kí ó rọ òjò lé ọ lórí?

35 Ṣé o lè pe mànàmáná pé kí ó wá kí o rán an níṣẹ́

kí ó wá bá ọ kí ó wí pé, ‘Èmi nìyí?’

36 Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùu

ati ìmọ̀ sinu ìrì?

37 Ta ló lè fi ọgbọ́n ká ìkùukùu,

tabi tí ó lè tú omi inú ìkùukùu dà sílẹ̀,

38 nígbà tí ilẹ̀ bá gbẹ,

tóbẹ́ẹ̀ tí ó dì, tí ó sì le koko?

39 “Ṣé o lè wá oúnjẹ fún kinniun,

tabi kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kinniun lọ́rùn,

40 nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ ninu ihò wọn,

tabi tí wọ́n ba ní ibùba wọn?

41 Ta ní ń wá oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò,

nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá kígbe sí Ọlọrun,

tí wọ́n sì ń káàkiri tí wọn ń wá oúnjẹ?

Categories
JOBU

JOBU 39

1 “Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?

Ṣé o ti ká àgbọ̀nrín mọ́ ibi tí ó ti ń bímọ rí?

2 Ǹjẹ́ o lè ka iye oṣù tí wọ́n fi ń lóyún?

Tabi o mọ ìgbà tí wọ́n bímọ?

3 Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀,

tí wọ́n sì bímọ?

4 Àwọn ọmọ wọn á di alágbára,

wọn á dàgbà ninu pápá,

wọn á sì lọ, láìpadà wá sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn mọ́.

5 “Ta ló fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ lómìnira

tí ó sì tú ìdè rẹ̀?

6 Mo fi inú pápá ṣe ilé rẹ̀,

ilẹ̀ oníyọ̀ sì di ibùgbé rẹ̀.

7 Ó ń pẹ̀gàn ìdàrúdàpọ̀ inú ìlú ńlá,

kò gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣiṣẹ́.

8 Ó ń rìn káàkiri àwọn òkè bí ibùjẹ rẹ̀,

ó sì ń wá ewéko tútù kiri.

9 “Ṣé ẹfọ̀n ṣetán láti sìn ọ́?

Ṣé yóo wá sùn ní ibùjẹ ẹran rẹ lálẹ́?

10 Ṣé o lè so àjàgà mọ́ ọn lọ́rùn ní poro oko,

tabi kí ó máa kọ ebè tẹ̀lé ọ?

11 Ṣé o lè gbẹ́kẹ̀lé e nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀,

tabi kí o fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ fún un láti ṣe?

12 Ṣé o ní igbagbọ pé yóo pada,

ati pé yóo ru ọkà rẹ̀ wá sí ibi ìpakà rẹ?

13 “Ògòǹgò lu ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ninu ọláńlá rẹ̀,

ṣugbọn kò lè fò bí ẹyẹ àkọ̀?

14 Ó yé ẹyin rẹ̀ sórí ilẹ̀,

kí ooru ilẹ̀ lè mú wọn,

15 ó gbàgbé pé ẹnìkan le tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ kí wọn sì fọ́,

ati pé ẹranko ìgbẹ́ lè fọ́ wọn.

16 Ògòǹgò kò náání àwọn ọmọ rẹ̀,

ó ń ṣe sí wọn bí ẹni pé kì í ṣe òun ló bí wọn,

kò bìkítà bí wahala rẹ̀ tilẹ̀ já sí asán;

17 nítorí pé Ọlọrun kò fún un ní ọgbọ́n ati òye.

18 Ṣugbọn nígbà tí ó bá ṣetán ati sáré,

a máa fi ẹṣin ati ẹni tí ó gùn ún ṣe yẹ̀yẹ́.

19 “Ṣé ìwọ ni o fún ẹṣin lágbára,

tí o sì fi agbára ṣe gọ̀gọ̀ sí i lọ́rùn?

20 Ṣé ìwọ lò ń mú kí ó máa ta pọ́nún bí eṣú,

tí kíké rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù?

21 Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì,

ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀,

ó sì jáde lọ sí ojú ogun.

22 Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì,

bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà.

23 Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀

tí ń kọ mànà, ati apata.

24 Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára,

nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀.

25 Nígbà tí fèrè dún, ó kọ, ‘Hàáà!’

Ó ń gbóòórùn ogun lókèèrè,

ó ń gbọ́ igbe ọ̀gágun tí ń pàṣẹ.

26 “Ṣé ìwọ lo kọ́ àwòdì bí a ti í fò,

tí ó fi na ìyẹ́ rẹ̀ sí ìhà gúsù?

27 Ṣé ìwọ ni o pàṣẹ fún idì láti fò lọ sókè,

tabi láti tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sórí òkè gíga?

28 Ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí òkè gíga-gíga,

ninu pàlàpálá àpáta.

29 Níbẹ̀ ni ó ti ń ṣọ́ ohun tí yóo pa,

ojú rẹ̀ a sì rí i láti òkèèrè réré.

30 Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa mu ẹ̀jẹ̀,

ibi tí òkú bá sì wà ni idì máa ń wà.”

Categories
JOBU

JOBU 40

1 OLUWA tún sọ fún Jobu pé,

2 “Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́?

Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.”

3 Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní:

4 “OLUWA, kí ni mo jámọ́,

tí n óo fi dá ọ lóhùn?

Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.

5 Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,

n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”

6 Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní,

7 “Múra gírí bí ọkunrin,

mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn.

8 Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni?

O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre?

9 Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun,

àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?

10 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́,

kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ.

11 Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga,

kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12 Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ,

rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13 Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀,

dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.

14 Nígbà náà ni n óo gbà pé,

agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun.

15 “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,

tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,

koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!

16 Wò ó bí ó ti lágbára tó!

Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.

17 Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,

gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.

18 Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ,

ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin.

19 “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá,

sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á.

20 Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ,

níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré.

21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi,

lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀.

22 Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó,

igi tí ó wà létí odò yí i ká.

23 Kò náání ìgbì omi,

kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀.

24 Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un?

Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀?

Categories
JOBU

JOBU 41

1 “Ṣé o lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani jáde,

tabi kí o fi okùn di ahọ́n rẹ̀?

2 Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀,

tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n?

3 Ṣé yóo bẹ̀ ọ́,

tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?

4 Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu,

pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae?

5 Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ,

tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ?

6 Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀?

Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn?

7 Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀,

tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀?

8 Lọ fọwọ́ kàn án;

kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà;

o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae!

9 “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,

nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.

10 Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?

Ta ló tó kò ó lójú?

11 Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?

Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.

12 “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,

tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.

13 Ta ló tó bó awọ rẹ̀,

tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀?

14 Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀?

Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù.

15 Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata,

a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì.

16 Àwọn ìpẹ́ náà lẹ̀ mọ́ ara wọn tímọ́tímọ́,

tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè fẹ́ kọjá láàrin wọn.

17 Wọ́n so pọ̀,

wọ́n lẹ̀ mọ́ ara wọn tóbẹ́ẹ̀,

tí ohunkohun kò lè ṣí wọn.

18 Bí ó bá sín, ìmọ́lẹ̀ á tàn jáde ní imú rẹ̀,

ojú rẹ̀ ń tàn bíi ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kutukutu.

19 Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde,

bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá.

20 Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀,

bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó.

21 Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná,

ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀.

22 Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀,

ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.

23 Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn,

wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí.

24 Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,

ó le ju ọlọ lọ.

25 Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára,

wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí.

26 Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,

bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.

27 Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀,

idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà.

28 Bí wọn ta á lọ́fà, kò ní torí rẹ̀ sá,

àwọn òkúta kànnàkànnà dàbí àgékù koríko lójú rẹ̀.

29 Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀,

a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín.

30 Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú,

wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́.

31 Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò,

ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara.

32 Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀,

eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni.

33 Kò sí ohun tí a lè fi wé láyé,

ẹ̀dá tí ẹ̀rù kì í bà.

34 Ó fojú tẹmbẹlu gbogbo ohun gíga,

ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọmọ agbéraga.”

Categories
JOBU

JOBU 42

1 Jobu bá dá OLUWA lóhùn ó ní:

2 “Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo,

kò sì sí ohun tí ó lè da ìpinnu rẹ rú.

3 Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye?

Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi,

ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi,

n kò sì mọ̀ wọ́n.

4 O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀,

nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,

kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi.

5 Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀,

ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ;

6 nítorí náà, ojú ara mi tì mí,

fún ohun tí mo ti sọ,

mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.”

Ìparí

7 Lẹ́yìn ìgbà tí OLUWA ti bá Jobu sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Elifasi ará Temani pé, “Inú ń bí mi sí ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji. Nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi, bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.

8 Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”

9 Nítorí náà, Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha, ati Sofari ará Naama lọ ṣe ohun tí OLUWA sọ fún wọn, OLUWA sì gbọ́ adura Jobu.

10 Lẹ́yìn ìgbà tí Jobu gbadura fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta tán, OLUWA dá ọrọ̀ Jobu pada, ó sì jẹ́ kí ó ní ìlọ́po meji àwọn ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.

11 Àwọn arakunrin ati arabinrin Jobu ati àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pada wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n jẹ àsè ní ilé rẹ̀, wọ́n káàánú rẹ̀, wọ́n sì tù ú ninu, nítorí ohun burúkú tí OLUWA ti mú wá sórí rẹ̀, olukuluku wọn fún un ní owó ati òrùka wúrà kọ̀ọ̀kan.

12 OLUWA bukun ìgbẹ̀yìn Jobu ju ti iṣaaju rẹ̀ lọ, ó ní ẹgbaaje (14,000) aguntan, ẹgbaata (6,000) ràkúnmí, ẹgbẹrun (1,000) àjàgà mààlúù ati ẹgbẹrun (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

13 Ó tún bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.

14 Ó pe àkọ́bí obinrin ni Jemima, ekeji ni Kesaya, ẹkẹta ni Kereni Hapuki.

15 Kò sì sí ọmọbinrin tí ó lẹ́wà bí àwọn ọmọbinrin Jobu ní gbogbo ayé. Baba wọn sì fún wọn ní ogún láàrin àwọn arakunrin wọn.

16 Lẹ́yìn náà Jobu tún gbé ogoje (140) ọdún sí i láyé, ó rí àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹrin.

17 Ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́ kí ó tó kú.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé tí à ń pè ní

Orin Dafidi

ni ìwé orin ati ìwé adura ninu Bibeli. Ọpọlọpọ ọdún ni àwọn tí ó kọ orin inú ìwé náà fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe àkójọpọ̀ wọn, wọ́n sì ń lò ó fún ìjọ́sìn. Nígbà tí ó yá, wọ́n fi àwọn orin náà kún Ìwé Mímọ́ wọn.

Oríṣìíríṣìí ni àwọn orin ẹ̀sìn wọnyi: orin ìyìn ati orin ìsìn, orin adura ati ìrànlọ́wọ́, orin ààbò ati ìgbàlà; orin ẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, orin ọpẹ́ fún ibukun Ọlọrun, ati ti ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun pé kí ó jẹ àwọn ọ̀tá ẹni níyà. Àwọn adura yìí wà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tabi orílẹ̀-èdè. Àwọn mìíràn jẹ́ ti ẹ̀dùn ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn yòókù sì jẹ́ ti àìní ati èrò ọkàn gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.

Jesu lò lára àwọn ọ̀rọ̀ inú

Ìwé Orin Dafidi

, àwọn tí wọ́n kọ ìwé Majẹmu Titun náà sì ṣe àmúlò rẹ̀. Láti ìgbà tí ìjọ Kristi ti bẹ̀rẹ̀ ni ìwé náà sì ti di ìwé ìṣúra fún ìjọ́sìn.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀nà marun-un ni a pín aadọjọ Orin Dafidi náà sí:

Orin Dafidi 1–41

Orin Dafidi 42–72

Orin Dafidi 73–89

Orin Dafidi 90–106

Orin Dafidi 107–150

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 1

Ayọ̀ Tòótọ́

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà

tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú,

tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn,

tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.

2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,

a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.

3 Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò

tí ń so ní àkókò tí ó yẹ,

tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.

Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.

4 Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,

ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.

5 Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6 Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo,

ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 2

Àyànfẹ́ Ọlọrun

1 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù

tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?

2 Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,

àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,

wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.

3 Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já

kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.”

4 Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;

OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.

5 Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,

yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,

6 Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ,

ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.”

7 N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;

Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,

lónìí ni mo bí ọ.

8 Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè,

gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ.

9 Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn,

o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”

10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n;

ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.

11 Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA,

ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì.

12 Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú,

kí ó má baà pa yín run lójijì;

nítorí a máa yára bínú.

Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 3

Adura ìrànlọ́wọ́ lówùúrọ̀

1 OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!

Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!

2 Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,

Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀!

3 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,

ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà.

4 Mo ké pe OLUWA,

ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.

5 Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,

nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.

6 Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká

kò le bà mí lẹ́rù.

7 Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi!

Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀,

tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú.

8 OLUWA níí gbani,

kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀.