Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 13

Ìbí Samsoni

1 Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Wọ́n sin àwọn ará Filistia fún ogoji ọdún.

2 Ọkunrin kan wà, ará Sora, láti inú ẹ̀yà Dani, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Manoa; àgàn ni iyawo rẹ̀, kò bímọ.

3 Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, angẹli OLUWA fi ara han iyawo Manoa yìí, ó wí fún un pé, “Lóòótọ́, àgàn ni ọ́, ṣugbọn o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan.

4 Nítorí náà, ṣọ́ra, o kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́.

5 Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”

6 Obinrin náà bá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Eniyan Ọlọrun kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ jọ ìrísí angẹli Ọlọrun. Ó bani lẹ́rù gidigidi. N kò bèèrè ibi tí ó ti wá, kò sì sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi.

7 Ṣugbọn ó wí fún mi pé, n óo lóyún, n óo sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní n kò gbọdọ̀ mu ọtí waini, tabi ọtí líle. N kò sì gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́; nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni ọmọ náà yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí yóo fi jáde láyé.”

8 Manoa bá gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí iranṣẹ rẹ tí o rán sí wa tún pada wá, kí ó wá kọ́ wa bí a óo ṣe máa tọ́jú ọmọkunrin tí a óo bí.”

9 Ọlọrun gbọ́ adura Manoa, angẹli Ọlọrun náà tún pada tọ obinrin yìí wá níbi tí ó jókòó sí ninu oko; ṣugbọn Manoa, ọkọ rẹ̀, kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀.

10 Obinrin náà bá sáré lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ mi níjọ́sí tún ti fara hàn mí.”

11 Manoa bá gbéra, ó bá tẹ̀lé iyawo rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó bi í pé, “Ṣé ìwọ ni o bá obinrin yìí sọ̀rọ̀?”

Ọkunrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

12 Manoa tún bèèrè pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, báwo ni ìgbé ayé ọmọ náà yóo rí? Irú kí ni yóo sì máa ṣe?”

13 Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí mo sọ fún obinrin yìí ni kí o kíyèsí.

14 Kò gbọdọ̀ fẹnu kan ohunkohun tí ó bá jáde láti inú èso àjàrà, kò gbọdọ̀ mu waini tabi ọtí líle tabi kí ó jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un ni kí ó ṣe.”

15 Manoa dá angẹli OLUWA náà lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́, dúró díẹ̀ kí á se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.”

16 Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Bí o bá dá mi dúró, n kò ní jẹ ninu oúnjẹ rẹ, ṣugbọn tí o bá fẹ́ tọ́jú ohun tí o fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, OLUWA ni kí o rú u sí.” Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLUWA ni.

17 Manoa bá bèèrè lọ́wọ́ angẹli OLUWA náà, ó ní, “Kí ni orúkọ rẹ kí á lè dá ọ lọ́lá nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ.”

18 Angẹli OLUWA náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bèèrè orúkọ mi nígbà tí ó jẹ́ pé ìyanu ni?”

19 Manoa bá mú ọmọ ewúrẹ́ náà, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ó fi wọ́n rúbọ lórí òkúta kan sí OLUWA tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu.

20 Nígbà tí ọwọ́ iná ẹbọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láti orí pẹpẹ, angẹli OLUWA náà bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ ninu ọwọ́ iná orí pẹpẹ náà, bí Manoa ati iyawo rẹ̀ ti ń wò ó. Wọ́n bá dojú wọn bolẹ̀.

21 Angẹli OLUWA náà kò tún fara han Manoa ati iyawo rẹ̀ mọ́. Manoa wá mọ̀ nígbà náà pé, angẹli OLUWA ni.

22 Manoa bá sọ fún iyawo rẹ̀ pé, “Dájúdájú, a óo kú, nítorí pé a ti rí Ọlọrun.”

23 Ṣugbọn iyawo rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ṣe pé OLUWA fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ tí a rú sí i lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi nǹkan wọnyi hàn wá, tabi kí ó sọ wọ́n fún wa.”

24 Nígbà tí ó yá, obinrin náà bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Samsoni. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, OLUWA sì bukun un.

25 Ẹ̀mí OLUWA sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní Mahanedani, tí ó wà láàrin Sora ati Eṣitaolu.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 14

Samsoni ati Ọmọbinrin Kan, Ará Timna

1 Samsoni lọ sí Timna, ó rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia níbẹ̀.

2 Ó pada wálé wá sọ fún baba ati ìyá rẹ̀, ó ní, “Mo rí ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin ará Filistia ní Timna, ó wù mí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fẹ́ ẹ fún mi.”

3 Baba ati ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Ṣé kò sí obinrin mọ́ ninu gbogbo àwọn ìbátan rẹ tabi láàrin gbogbo àwọn eniyan wa ni o fi níláti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ará Filistia aláìkọlà ni?”

Samsoni bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Ẹ ṣá fẹ́ ẹ fún mi nítorí ó wù mí pupọ.”

4 Ṣugbọn baba ati ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ní ọwọ́ OLUWA ninu, nítorí pé OLUWA ti ń wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Filistia nítorí pé, àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àkókò yìí.

5 Samsoni bá baba ati ìyá rẹ̀ lọ sí Timna ní ọjọ́ kan. Bí ó ti dé ibi ọgbà àjàrà àwọn ará Timna kan báyìí, ni ọ̀dọ́ kinniun kan bá bú mọ́ ọn.

6 Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì fún un ní agbára ńlá, ó bá fa kinniun náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ìgbà tí eniyan ya ọmọ ewúrẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú ohunkohun lọ́wọ́. Ṣugbọn kò sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún baba tabi ìyá rẹ̀.

7 Lẹ́yìn náà, ó lọ bá ọmọbinrin náà sọ̀rọ̀. Ọmọbinrin náà wù ú gidigidi.

8 Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni ó pada lọ láti lọ mú iyawo rẹ̀. Bí ó ti ń lọ, ó yà wo òkú kinniun tí ó pa, ó bá ọ̀wọ́ oyin ati afárá oyin lára rẹ̀.

9 Ó bá yọ́ ninu afárá oyin náà sí ọwọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lá a bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó bá baba ati ìyá rẹ̀, ó fún wọn lá ninu rẹ̀; ṣugbọn kò sọ fún wọn pé ara òkú kinniun ni òun ti rẹ́ afárá oyin náà.

10 Baba rẹ̀ bá lọ sí ọ̀dọ̀ obinrin náà. Samsoni se àsè ńlá kan níbẹ̀, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọdọmọkunrin máa ń ṣe nígbà náà.

11 Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n mú ọgbọ̀n ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá láti wà pẹlu rẹ̀.

12 Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá.

13 Ṣugbọn bí ẹ kò bá lè túmọ̀ àlọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóo fún mi ní ẹ̀wù funfun kọ̀ọ̀kan ati aṣọ àríyá kọ̀ọ̀kan.”

Wọ́n bá dáhùn pé, “Pa àlọ́ rẹ kí á gbọ́.”

14 Ó bá pa àlọ́ náà fún wọn, ó ní,

“Láti inú ọ̀jẹun ni nǹkan jíjẹ tií wá,

láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn tií wá.”

Wọn kò sì lè túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.

15 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n wá bẹ iyawo Samsoni pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún wa, láì ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sun ìwọ ati ilé baba rẹ níná. Àbí pípè tí o pè wá wá sí ibí yìí, o fẹ́ sọ wá di aláìní ni?”

16 Iyawo Samsoni bá bẹ̀rẹ̀ sì sọkún níwájú rẹ̀, ó ní, “O kò fẹ́ràn mi rárá, irọ́ ni ò ń pa fún mi. O kórìíra mi; nítorí pé o pa àlọ́ fún àwọn ará ìlú mi, o kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”

Samsoni bá dá a lóhùn pé, “Ohun tí n kò sọ fún baba tabi ìyá mi, n óo ti ṣe wá sọ fún ọ?”

17 Ni iyawo rẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún títí gbogbo ọjọ́ mejeeje tí wọ́n fi se àsè náà. Ṣugbọn nígbà tí ó di ọjọ́ keje, Samsoni sọ fún un, nítorí pé ó fún un lọ́rùn gidigidi. Obinrin náà bá lọ sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ará ìlú rẹ̀.

18 Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, kí ó tó di pé oòrùn wọ̀, àwọn ará ìlú rẹ̀ náà wá sọ ìtumọ̀ àlọ́ Samsoni wí pé,

“Kí ló dùn ju oyin lọ;

kí ló lágbára ju kinniun lọ?”

Ó ní,

“Bí kò bá jẹ́ pé mààlúù mi ni ẹ fi tulẹ̀,

ẹ kì bá tí lè túmọ̀ àlọ́ mi.”

19 Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé e tagbára tagbára, ó lọ sí Aṣikeloni, ó sì pa ọgbọ̀n ninu àwọn ọkunrin ìlú náà, ó kó ìkógun wọn, ó sì fún àwọn tí wọ́n túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ ní aṣọ àríyá wọn; ó bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀ pẹlu ibinu.

20 Wọ́n bá fi iyawo rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àkókò igbeyawo.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 15

1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè ọkà, Samsoni mú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó lọ bẹ iyawo rẹ̀ wò. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ní, “Mo fẹ́ wọlé lọ bá iyawo mi ninu yàrá.”

Ṣugbọn baba iyawo rẹ̀ kò jẹ́ kí ó wọlé lọ bá a.

2 Baba iyawo rẹ̀ wí fún un pé, “Mo rò pé lóòótọ́ ni o kórìíra iyawo rẹ, nítorí náà, mo ti fi fún ẹni tí ó jẹ́ ọrẹ rẹ tímọ́tímọ́, ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ. Ṣé ìwọ náà rí i pé àbúrò rẹ̀ lẹ́wà jù ú lọ, jọ̀wọ́ fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.”

3 Samsoni dáhùn pé, “Bí mo bá ṣe àwọn ará Filistia ní ibi ní àkókò yìí, n kò ní jẹ̀bi wọn.”

4 Samsoni bá lọ, ó mú ọọdunrun (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàyè, ó wá ìtùfù, ó sì so àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ní ìrù pọ̀ ní meji meji, ó fi ìtùfù sí ààrin ìrù wọn.

5 Ó ṣáná sí àwọn ìtùfù náà, ó sì tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀ ninu oko ọkà àwọn ará Filistia. Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí bá tan iná ran gbogbo ìtí ọkà ati àwọn ọkà tí ó wà ní òòró ati gbogbo ọgbà olifi wọn; gbogbo wọn sì jóná ráúráú.

6 Àwọn ará Filistia bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ta ni ó dán irú èyí wò?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni, ọkọ ọmọ ará Timna ni; nítorí pé àna rẹ̀ fi iyawo rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àwọn ará Filistia bá lọ dáná sun iyawo náà ati baba rẹ̀.

7 Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé bí ẹ óo ti ṣe nìyí n óo gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà, n óo fi yín sílẹ̀.”

8 Samsoni pa ọpọlọpọ ninu wọn. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ ń gbé inú ihò àpáta kan tí ó wà ní Etamu.

Samsoni Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia

9 Àwọn ará Filistia bá kógun wá sí Juda, wọ́n sì kọlu ìlú Lehi.

10 Àwọn ọkunrin Juda bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi gbógun tì wá?”

Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ni a wá mú; ohun tí ó ṣe sí wa ni àwa náà fẹ́ ṣe sí i.”

11 Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?”

Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.”

12 Wọ́n dá a lóhùn pé, “A wá láti dì ọ́ tọwọ́ tẹsẹ̀ kí á sì gbé ọ lọ fún àwọn ará Filistia ni.”

Samsoni dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin tìkara yín kò ní pa mí.”

13 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà.

14 Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

15 Ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹrun ninu àwọn ará Filistia.

16 Samsoni bá dáhùn pé,

“Páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa wọ́n jọ bí òkítì,

Egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa ẹgbẹrun eniyan.”

17 Lẹ́yìn tí ó wí báyìí tán, ó ju egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Ramati Lehi.

18 Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?”

19 Ọlọrun bá la ibi ọ̀gbun kan tí ó wà ní Lehi, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú ọ̀gbun náà. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán, ojú rẹ̀ wálẹ̀, nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Enhakore. Enhakore yìí sì wà ní Lehi títí di òní olónìí.

20 Samsoni ṣe aṣiwaju ní Israẹli ní àkókò àwọn Filistini fún ogún ọdún.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 16

Samsoni ní Ìlú Gasa

1 Ní ọjọ́ kan, Samsoni lọ sí ìlú Gasa, ó rí obinrin aṣẹ́wó kan níbẹ̀, ó bá wọlé tọ̀ ọ́ lọ.

2 Àwọn kan bá lọ sọ fún àwọn ará Gasa pé Samsoni wà níbẹ̀. Wọ́n yí ilé náà po, wọ́n sì ba dè é níbi ẹnu ọ̀nà bodè ìlú ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ní, “Ẹ jẹ́ kí á dúró títí di ìdájí kí á tó pa á.”

3 Ṣugbọn Samsoni sùn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ní òru náà, ó gbéra, ó gbá ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà mú ati àwọn òpó rẹ̀ mejeeji, ó sì fà á tu pẹlu irin ìdábùú rẹ̀, ó gbé wọn lé èjìká, ó sì rù wọ́n lọ sí orí òkè kan tí ó wà ní iwájú Heburoni.

Samsoni ati Delila

4 Lẹ́yìn èyí, Samsoni rí obinrin kan tí ó wù ú ní àfonífojì Soreki, ó sì fẹ́ ẹ. Delila ni orúkọ obinrin náà.

5 Àwọn ọba Filistia wá sọ́dọ̀ obinrin yìí, wọ́n ní, “Tan ọkọ rẹ, kí o sì mọ àṣírí agbára rẹ̀, ati ọ̀nà tí a fi lè kápá rẹ̀; kí á lè dì í lókùn kí á sì ṣẹgun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóo sì fún ọ ní ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka.”

6 Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.”

7 Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

8 Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni.

9 Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀.

10 Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.”

11 Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

12 Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni.

13 Delila tún wí fún Samsoni pé, “Sibẹsibẹ o ṣì tún ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o tún ń purọ́ fún mi. Sọ fún mi bí eniyan ṣe lè gbé ọ dè.”

Ó dá a lóhùn pé, “Bí o bá di ìdì irun meje tí ó wà lórí mi, mọ́ igi òfì, tí o sì dì í papọ̀, yóo rẹ̀ mi, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

14 Nítorí náà, nígbà tí ó sùn, Delila mú ìdì irun mejeeje tí ó wà lórí rẹ̀, ó lọ́ ọ mọ́ igi òfì, ó sì fi èèkàn kàn án mọ́lẹ̀, ó bá pè é, ó ní, “Samsoni! Àwọn Filistini dé.” Ṣugbọn nígbà tí ó jí láti ojú oorun rẹ̀, ó fa èèkàn ati igi òfì náà tu.

15 Delila tún sọ fún un pé, “Báwo ni o ṣe lè wí pé o nífẹ̀ẹ́ mí, nígbà tí ọkàn rẹ kò sí lọ́dọ̀ mi. O ti fi mí ṣe ẹlẹ́yà nígbà mẹta, o kò sì sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi.”

16 Nígbà tí Delila bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu lemọ́lemọ́, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ lojoojumọ, ọ̀rọ̀ náà sú Samsoni patapata.

17 Ó bá tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún Delila, ó ní, “Ẹnìkan kò fi abẹ kàn mí lórí rí, nítorí pé Nasiri Ọlọrun ni mí láti inú ìyá mi wá. Bí wọ́n bá fá irun mi, agbára mi yóo fi mí sílẹ̀, yóo rẹ̀ mí n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

18 Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́.

19 Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀.

20 Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀.

21 Àwọn Filistini bá kì í mọ́lẹ̀, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n mú un wá sí ìlú Gasa, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ dè é. Wọ́n ní kí ó máa lọ àgbàdo ninu ilé ẹ̀wọ̀n.

22 Ṣugbọn irun orí rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.

Ikú Samsoni

23 Ní ọjọ́ kan, àwọn ọba Filistini kó ara wọn jọ láti rú ẹbọ ńlá kan sí Dagoni, oriṣa wọn, ati láti ṣe àríyá pé oriṣa wọn ni ó fi Samsoni ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.

24 Nígbà tí àwọn eniyan rí i, wọ́n yin oriṣa wọn; wọ́n ní, “Oriṣa wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́, ẹni tí ó sọ ilẹ̀ wa di ahoro tí ó sì pa ọpọlọpọ ninu wa.”

25 Nígbà tí inú wọn dùn, wọ́n ní, “Ẹ pe Samsoni náà wá, kí ó wá dá wa lára yá.” Wọ́n pe Samsoni jáde láti inú ilé ẹ̀wọ̀n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá wọn lára yá. Wọ́n mú un lọ sí ààrin òpó mejeeji pé kí ó dúró níbẹ̀.

26 Samsoni bá bẹ ọdọmọkunrin tí ó mú un lọ́wọ́, ó ní, “Jẹ́ kí n fi ọwọ́ kan àwọn òpó tí gbogbo ilé yìí gbé ara lé kí n lè fara tì wọ́n.”

27 Ilé náà kún fún ọpọlọpọ eniyan, lọkunrin ati lobinrin; gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini ni wọ́n wà níbẹ̀. Lórí òrùlé nìkan, àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tó ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, lọkunrin ati lobinrin tí wọn ń wo Samsoni níbi tí ó ti ń dá wọn lára yá.

28 Samsoni bá ké pe OLUWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, ranti mi, kí o sì fún mi lágbára lẹ́ẹ̀kan péré sí i, jọ̀wọ́ Ọlọrun mi, kí n lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini fún ọ̀kan ninu ojú mi mejeeji.”

29 Samsoni bá gbá àwọn òpó mejeeji tí ó wà láàrin, tí ilé náà gbára lé mú, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé ọ̀kan, ó gbé ọwọ́ òsì lé ekeji, ó sì fi gbogbo agbára rẹ̀ tì wọ́n.

30 Ó wí pé, “Jẹ́ kí èmi náà kú pẹlu àwọn ará Filistia.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu gbogbo agbára rẹ̀. Ilé náà sì wó lu gbogbo àwọn ọba Filistini ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Nítorí náà, iye eniyan tí ó pa nígbà tí òun náà yóo fi kú, ju àwọn tí ó pa nígbà tí ó wà láàyè lọ.

31 Àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ bá wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n lọ sin ín sáàrin Sora ati Eṣitaolu ninu ibojì Manoa, baba rẹ̀. Ogún ọdún ni ó fi ṣe aṣiwaju ní Israẹli.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 17

Ère Mika

1 Ọkunrin kan wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika.

2 Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Wọ́n gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka mọ́ ọ lọ́wọ́ nígbà kan, mo sì gbọ́ tí ò ń gbé ẹni tí ó gbé owó náà ṣépè, ọwọ́ mi ni owó náà wà, èmi ni mo gbé e.”

Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “OLUWA yóo bukun ọ, ọmọ mi.”

3 Mika gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka náà pada fún ìyá rẹ̀.

Ìyá rẹ̀ bá dáhùn pé, “Mo ya fadaka náà sí mímọ́ fún OLUWA, kí ọmọ mi yá ère fínfín kan kí ó sì yọ́ fadaka náà lé e lórí. Nítorí náà, n óo dá a pada fún ọ.”

4 Nígbà tí Mika kó owó náà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba owó fadaka ninu rẹ̀, ó kó o fún alágbẹ̀dẹ fadaka láti yọ́ ọ sórí ère náà, wọ́n sì gbé ère náà sí ilé Mika.

5 Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀.

6 Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe.

7 Ọdọmọkunrin kan wà ní Juda, ará Bẹtilẹhẹmu, tí ó jẹ́ ọmọ Lefi láti inú ìdílé Juda, ó ń gbé ibẹ̀.

8 Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu.

9 Mika bá bi í pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”

Ó dá a lóhùn pé, “Ọmọ Lefi, láti Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda ni mí, ibi tí n óo máa gbé ni mò ń wá kiri.”

10 Mika bá sọ fún un pè, “Máa gbé ọ̀dọ̀ mi, kí o sì jẹ́ baba ati alufaa fún mi, n óo máa san owó fadaka mẹ́wàá fún ọ lọ́dún. N óo máa dáṣọ fún ọ, n óo sì máa bọ́ ọ.”

11 Ọdọmọkunrin ọmọ Lefi náà gbà, láti máa gbé ọ̀dọ̀ Mika. Mika sì mú un gẹ́gẹ́ bí ọmọ.

12 Mika fi ọdọmọkunrin náà jẹ alufaa, ó sì ń gbé ilé Mika.

13 Mika bá dáhùn pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo bukun mi, nítorí pé, ọmọ Lefi gan-an ni mo gbà gẹ́gẹ́ bí alufaa.”

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 18

Mika ati Ẹ̀yà Dani

1 Ní àkókò kan, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli, ati pé, ní àkókò náà, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tí wọn yóo gbà, tí wọn yóo sì máa gbé, nítorí pé, títí di àkókò yìí wọn kò tíì fún wọn ní ilẹ̀ kankan láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli.

2 Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Dani rán akikanju marun-un láàrin àwọn eniyan wọn, láti ìlú Sora ati Eṣitaolu, kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n wí fún àwọn amí náà pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì yẹ ilẹ̀ náà wò.” Wọ́n bá gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè ti Efuraimu. Nígbà tí wọ́n dé ilé Mika, wọ́n wọ̀ sibẹ.

3 Nígbà tí wọ́n wà ní ilé Mika, wọ́n ṣàkíyèsí bí ọdọmọkunrin tí ó wà ní ilé Mika ṣe ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì mọ̀ pé ọmọ Lefi ni. Wọ́n bá bi í pé, “Ta ló mú ọ wá síhìn-ín? Kí ni ò ń ṣe níhìn-ín? Kí sì ni iṣẹ́ rẹ?”

4 Ó dá wọn lóhùn pé, “Mika ti bá mi ṣètò, ó ti gbà mí gẹ́gẹ́ bí alufaa rẹ̀.”

5 Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, bá wa wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun, kí á lè mọ̀ bóyá ìrìn àjò tí à ń lọ yìí yóo yọrí sí rere.”

6 Alufaa náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní alaafia, Ọlọrun fọwọ́ sí ìrìn àjò tí ẹ̀ ń lọ.”

7 Àwọn ọkunrin marun-un náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n wá sí Laiṣi, wọ́n sì rí àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀ bí wọ́n ti ń gbé ní àìléwu gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Sidoni tií máa ṣe. Wọ́n ń gbé pọ̀ ní alaafia, kò sí ìjà láàrin wọn, wọ́n ní ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ní ọrọ̀. Wọ́n rí i bí wọ́n ti jìnnà sí ibi tí àwọn ará Sidoni wà tó, ati pé wọn kò bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀ ní gbogbo àyíká wọn.

8 Nígbà tí àwọn ọkunrin marun-un náà pada dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan wọn ní Sora ati Eṣitaolu, àwọn eniyan wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ọ̀hún ti rí?”

9 Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun tì wọ́n nítorí pé a ti rí ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tí ó lọ́ràá ni. Ẹ má jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ẹ má jáfara, ẹ wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì gbà á.

10 Nígbà tí ẹ bá lọ, ẹ óo dé ibìkan tí àwọn eniyan ń gbé láìbẹ̀rù, ilẹ̀ náà tẹ́jú. Dájúdájú Ọlọrun ti fi lé yín lọ́wọ́, kò sí ohun tí eniyan ń fẹ́ ní ayé yìí tí kò sí níbẹ̀.”

11 Ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu ẹ̀yà Dani tí wọ́n dira ogun gbéra láti Sora ati Eṣitaolu.

12 Wọ́n lọ pàgọ́ sí Kiriati Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Mahanedani títí di òní olónìí; ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Kiriati Jearimu.

13 Wọ́n lọ láti ibẹ̀ sí agbègbè olókè ti Efuraimu, wọ́n dé ilé Mika.

14 Nígbà náà ni àwọn ọkunrin marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ Laiṣi sọ fún àwọn arakunrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ̀wù efodu kan wà ninu àwọn ilé wọnyi ati àwọn ère kéékèèké, ati ère tí wọ́n gbẹ́ tí wọ́n sì yọ́ fadaka bò lórí, nítorí náà, kí ni ẹ rò pé ó yẹ kí á ṣe?”

15 Wọ́n bá yà sibẹ, wọ́n sì lọ sí ilé ọdọmọkunrin ọmọ Lefi, tí ó wà ní ilé Mika, wọ́n bèèrè alaafia rẹ̀.

16 Àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ará Dani tí wọ́n dira ogun dúró ní ẹnu ibodè.

17 Àwọn marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà bá wọlé, wọ́n gbé ère dídà, wọn mú ẹ̀wù efodu, wọ́n sì kó àwọn ère kéékèèké ati ère fínfín. Ọdọmọkunrin alufaa yìí sì wà ní ẹnu ibodè pẹlu àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin láti inú ẹ̀yà Dani tí wọ́n ti dira ogun.

18 Nígbà tí àwọn marun-un náà lọ sí ilé Mika tí wọ́n sì kó àwọn ère rẹ̀ ati àwọn nǹkan oriṣa rẹ̀, alufaa náà bi wọ́n léèrè pé, “Irú kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí?”

19 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́, pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì tẹ̀lé wa, kí o jẹ́ baba ati alufaa fún wa. Èwo ni ìwọ náà rò pé ó dára jù; kí o jẹ́ alufaa fún ilé ẹnìkan ni tabi fún odidi ẹ̀yà kan ati ìdílé kan ní Israẹli?”

20 Inú alufaa náà bá dùn, ó gbé ẹ̀wù efodu, ó kó àwọn ère kékeré náà ati ère dídà náà, ó ń bá àwọn eniyan náà lọ.

21 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n ń lọ. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati àwọn ẹrù wọn ń lọ níwájú wọn.

22 Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn jìnnà sí ilé Mika, Mika pe gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá.

23 Wọ́n kígbe pè wọ́n, àwọn ará Dani bá yipada, wọn bi Mika pé, “Kí ní ń dà ọ́ láàmú tí o fi ń bọ̀ pẹlu ọpọlọpọ eniyan báyìí?”

24 Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ kó àwọn oriṣa mi, tí mo dà, ẹ mú alufaa mi lọ; kí ni ó kù mí kù. Ẹ tún wá ń bi mí pé, Kí ló ń ṣe mí?”

25 Àwọn ará Dani dá a lóhùn, wọ́n ní, “Má jẹ́ kí àwọn eniyan gbọ́ ohùn rẹ láàrin wa, kí àwọn tí inú ń bí má baà pa ìwọ ati gbogbo ìdílé rẹ.”

26 Àwọn ará Dani bá ń bá tiwọn lọ, nígbà tí Mika rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ, ó pada sílé rẹ̀.

27 Lẹ́yìn tí àwọn ará Dani ti kó oriṣa Mika, tí wọ́n sì ti gba alufaa rẹ̀, wọ́n lọ sí Laiṣi, wọ́n gbógun ti àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n jókòó sí jẹ́jẹ́ láì bẹ̀rù; wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì dáná sun ìlú wọn.

28 Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọ́n jìnnà sí ìlú Sidoni, wọn kò sì bá ẹnikẹ́ni ní àyíká wọn da nǹkankan pọ̀. Àfonífojì Betirehobu ni ìlú Laiṣi yìí wà. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

29 Wọ́n yí orúkọ ìlú náà pada kúrò ní Laiṣi tí ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n sọ ọ́ ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Israẹli.

30 Àwọn ará Dani gbé ère dídà náà kalẹ̀ fún ara wọn. Jonatani ọmọ Geriṣomu, ọmọ Mose ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ alufaa fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí wọ́n kó gbogbo agbègbè wọn ní ìgbèkùn.

31 Ère tí Mika yá ni wọ́n gbé kalẹ̀, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọrun fi wà ní Ṣilo.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 19

Ọmọ Lefi Kan ati Obinrin Rẹ̀

1 Ní àkókò tí kò sí ọba ní Israẹli, ọmọ Lefi kan ń gbé apá ibìkan tí ó jìnnà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Ọmọ Lefi yìí ní obinrin kan tí ó jẹ́ ará Bẹtilẹhẹmu ni ilẹ̀ Juda.

2 Èdè-àìyedè kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn mejeeji, obinrin yìí bá kúrò lọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu, ó sì ń gbé ibẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹrin.

3 Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ dìde, ó lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó pada. Ọkunrin yìí mú iranṣẹ kan ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi meji lọ́wọ́. Nígbà tí ó dé ilé baba obinrin rẹ̀ yìí, tí baba iyawo rẹ̀ rí i, ó lọ pàdé rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.

4 Baba obinrin náà rọ̀ ọ́ títí ó fi wà pẹlu wọn fún ọjọ́ mẹta; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì wà níbẹ̀.

5 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu wọ́n fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ pé kí ó jẹ oúnjẹ díẹ̀ kí ó tó máa lọ, kí ó lè lágbára.

6 Àwọn ọkunrin mejeeji bá jókòó, wọ́n jẹ, wọ́n mu, lẹ́yìn náà ni baba ọmọbinrin yìí tún dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ kúkú dúró ní alẹ́ yìí kí o máa gbádùn ara rẹ.”

7 Nígbà tí ọkunrin náà gbéra, tí ó fẹ́ máa lọ, baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ títí tí ó tún fi dúró.

8 Nígbà tí ó di ọjọ́ karun-un, ọkunrin náà gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu láti máa lọ, baba ọmọbinrin náà tún rọ̀ ọ́ pé kí ó fọkàn balẹ̀, kí ó di ìrọ̀lẹ́ kí ó tó máa lọ. Àwọn mejeeji bá jọ jẹun.

9 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́ ọkunrin náà ati obinrin rẹ̀ ati iranṣẹ rẹ̀ gbéra, wọ́n fẹ́ máa lọ; baba ọmọbinrin náà tún wí fún un pé, “Ṣé ìwọ náà rí i pè ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, jọ̀wọ́ dúró kí ó di ọ̀la. Ilẹ̀ ló ti ṣú yìí, dúró níhìn-ín kí o sì gbádùn ara rẹ, bí ó bá di ọ̀la kí ẹ bọ́ sọ́nà ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ẹ sì máa lọ sílé.”

10 Ṣugbọn ọkunrin náà kọ̀, ó ní òun kò ní di ọjọ́ keji. Ó bá gbéra, ó ń lọ, títí tí wọ́n fi dé ibìkan tí ó dojú kọ Jebusi (tí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu); àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀, obinrin rẹ̀ sì wà pẹlu rẹ̀.

11 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, iranṣẹ rẹ̀ sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á dúró ní ìlú àwọn ará Jebusi yìí kí á sì sùn níbẹ̀ lónìí.”

12 Ó dá a lóhùn, ó ní, “A kò ní wọ̀ ní ìlú àjèjì, lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, a óo kọjá lọ sí Gibea.”

13 Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí á sì sùn ní Gibea tabi ní Rama.”

14 Wọ́n bá tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ, oòrùn ti wọ̀ kí wọ́n tó dé Gibea, ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Bẹnjamini.

15 Wọ́n yà sibẹ, láti sùn di ọjọ́ keji. Wọ́n lọ jókòó ní ààrin ìgboro ìlú náà, nítorí pé, ẹnikẹ́ni kò gbà wọ́n sílé pé kí wọ́n sùn di ọjọ́ keji.

16 Nígbà tí ó yá, ọkunrin arúgbó kan ń ti oko bọ̀ ní alẹ́; ará agbègbè olókè Efuraimu ni, ṣugbọn Gibea ni ó ń gbé. Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ń gbé ìlú náà.

17 Bí ó ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn àlejò náà ní ìta gbangba láàrin ìgboro ìlú náà; ó sì bi wọ́n léèrè pé, “Níbo ni ẹ̀ ń lọ, níbo ni ẹ sì ti ń bọ̀?”

18 Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Láti Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni a ti ń bọ̀, a sì ń lọ sí ìgbèríko kan ní òpin agbègbè olókè Efuraimu níbi tí mo ti wá. Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni mo lọ, mo wá ń pada lọ sílé, nígbà tí a ti dé ìhín, kò sí ẹni tí ó gbà wá sílé.

19 Koríko tí a mú lọ́wọ́ tó fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa, oúnjẹ ati waini tí a sì mú lọ́wọ́ tó fún èmi ati iranṣẹbinrin rẹ ati ọdọmọkunrin tí ó wà pẹlu wa, ìyà ohunkohun kò jẹ wá.”

20 Baba arúgbó náà bá dáhùn pé, “Ṣé alaafia ni ẹ dé? Ẹ kálọ, n óo pèsè ohun gbogbo tí ẹ nílò fun yín, ẹ ṣá má sun ìta gbangba níhìn-ín.”

21 Baba náà bá mú wọn lọ sí ilé rẹ̀, ó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní koríko. Wọ́n ṣan ẹsẹ̀ wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.

22 Bí wọ́n ti ń gbádùn ara wọn lọ́wọ́ ni àwọn ọkunrin lásánlàsàn kan aláìníláárí, ará ìlú náà, bá yí gbogbo ilé náà po, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lu ìlẹ̀kùn. Wọ́n sọ fún baba arúgbó tí ó ni ilé náà pé, “Mú ọkunrin tí ó wọ̀ sinu ilé rẹ jáde, kí á lè bá a lòpọ̀.”

23 Baba arúgbó tí ó ni ilé yìí bá jáde sí wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ wọ́n, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú báyìí, ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí wá wọ̀ sinu ilé mi ni, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí sí i.

24 Mo ní ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ wundia, ọkunrin náà sì ní obinrin kan, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde sí yín nisinsinyii, kí ẹ sì ṣe wọ́n bí ẹ bá ti fẹ́, kí ẹ tẹ́ ìfẹ́ yín lọ́rùn lára wọn, ṣugbọn ẹ má ṣe hu irú ìwà burúkú yìí sí ọkunrin náà.”

25 Ṣugbọn àwọn ọkunrin náà kọ̀, wọn kò dá a lóhùn. Ó bá ki obinrin ọkunrin náà mọ́lẹ̀, ó tì í sí wọn lóde. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a lòpọ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, wọ́n fi sílẹ̀ pé kí ó máa lọ.

26 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, obinrin yìí bá lọ wó lulẹ̀ sì ẹnu ọ̀nà baba arúgbó náà níbi tí ọkunrin tí ó mú un wá wà, ó wà níbẹ̀ títí tí ilẹ̀ fi mọ́ kedere.

27 Ọkunrin yìí bá dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ó ṣílẹ̀kùn ilé náà tí ó sì jáde pé kí òun máa lọ, òkú obinrin rẹ̀ ni ó rí, tí ó nà sílẹ̀ gbalaja lẹ́nu ọ̀nà, lẹ́bàá ìlẹ̀kùn, pẹlu ọwọ́ tí ó nà tí ó fẹ́ ṣílẹ̀kùn.

28 Ó pè é pé kí ó dìde kí àwọn máa lọ. Ṣugbọn obinrin yìí kò dá a lóhùn. Ó bá gbé òkú rẹ̀ nílẹ̀, ó gbé e sẹ́yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sílé rẹ̀.

29 Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ, ó gé òkú obinrin yìí sí ọ̀nà mejila, ó sì fi wọ́n ranṣẹ sí gbogbo agbègbè Israẹli.

30 Gbogbo àwọn tí wọ́n rí i sì ń wí pé, “A kò rí irú èyí rí láti ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti títí di àkókò yìí, ọ̀rọ̀ náà tó àpérò, ẹ gbìmọ̀ ohun tí a ó ṣe, kí ẹ sì sọ̀rọ̀.”

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 20

Israẹli Múra Ogun

1 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa.

2 Gbogbo àwọn olórí láàrin àwọn eniyan náà jákèjádò ilẹ̀ Israẹli kó ara wọn jọ pẹlu ìjọ eniyan Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn, tí wọ́n sì ń lo idà, tí wọ́n kó ara wọn jọ níbẹ̀ tàwọn ti idà lọ́wọ́ wọn jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ (400,000).

3 Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti kó ara wọn jọ ní Misipa.

Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ ọmọ Lefi náà pé, “Sọ fún wa, báwo ni nǹkan burúkú yìí ti ṣe ṣẹlẹ̀?”

4 Ọmọ Lefi, ọkọ obinrin tí wọ́n pa, bá dáhùn pé, “Èmi ati obinrin mi ni a yà sí Gibea ní ilẹ̀ àwọn ará Bẹnjamini pé kí á sùn níbẹ̀.

5 Àwọn ọkunrin Gibea bá dìde lóru, wọ́n yí ilé tí mo wà po, wọ́n fẹ́ pa mí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá obinrin mi lòpọ̀ títí tí ó fi kú.

6 Mo bá gbé òkú rẹ̀, mo gé e lékìrí lékìrí, mo bá fi ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ Israẹli jákèjádò, nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti ṣe nǹkan burúkú ati ohun ìríra ní Israẹli.

7 Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gba ọ̀rọ̀ yí yẹ̀wò, kí ẹ sì mú ìmọ̀ràn yín wá lórí rẹ̀ nisinsinyii.”

8 Gbogbo àwọn eniyan náà bá fi ohùn ṣọ̀kan pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní pada sí àgọ́ rẹ̀ tabi ilé rẹ̀.

9 Ohun tí a óo ṣe nìyí, gègé ni a óo ṣẹ́ láti mọ àwọn tí yóo gbógun ti Gibea.

10 Ìdámẹ́wàá àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli yóo máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun, àwọn yòókù yóo lọ jẹ àwọn ará Gibea níyà fún ìwà burúkú tí wọ́n hù ní Israẹli yìí.”

11 Gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n gbógun ti ìlú náà.

12 Àwọn ọmọ Israẹli rán oníṣẹ́ jákèjádò ilẹ̀ Bẹnjamini, wọ́n ní, “Irú ìwà ìkà wo ni ẹ hù yìí?

13 Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí.

14 Àwọn ọmọ Bẹnjamini bá kó ara wọn jọ láti gbogbo ìlú ńláńlá, wọ́n wá sí Gibea láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

15 Àwọn ọmọ ogun tí àwọn ará Bẹnjamini kó jọ ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaata (26,000) àwọn ọkunrin tí wọn ń lo idà; láì ka àwọn tí wọn ń gbé Gibea tí àwọn náà kó ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin jọ.

16 Ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin tí wọn ń lo ọwọ́ òsì wà láàrin àwọn ọmọ ogun wọnyi. Wọ́n mọ kànnàkànnà ta, tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé wọ́n lè ta á mọ́ fọ́nrán òwú láì tàsé.

17 Láì ka àwọn tí àwọn ará Bẹnjamini náà kó jọ, àwọn ọmọ Israẹli kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) jagunjagun tí wọn ń lo idà jọ.

Israẹli Bá Ẹ̀yà Bẹnjamini Jagun

18 Àwọn ọmọ Israẹli gbéra lọ sí Bẹtẹli, wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun; ẹ̀yà tí yóo kọ́kọ́ gbógun ti ẹ̀yà Bẹnjamini.

OLUWA dá wọn lóhùn pé ẹ̀yà Juda ni yóo kọ́kọ́ gbógun tì wọ́n.

19 Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ pàgọ́ sí òdìkejì Gibea,

20 wọ́n bá gbógun ti àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fi ìlú Gibea ṣe ojú ogun wọn.

21 Àwọn ará Bẹnjamini bá jáde sí wọn láti ìlú Gibea, wọ́n sì pa ọ̀kẹ́ kan (20,000) ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ọjọ́ náà.

22 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn.

23 Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?”

OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.

24 Àwọn ọmọ Israẹli bá tún lọ gbógun ti àwọn ọmọ ogun Bẹnjamini ní ọjọ́ keji.

25 Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà.

26 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá lọ sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó wọ́n sọkún níbẹ̀ níwájú OLUWA, wọ́n gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú OLUWA.

27 Àwọn ọmọ Israẹli tún wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí pé àpótí majẹmu Ọlọrun wà ní Bẹtẹli ní àkókò náà.

28 Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?”

OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”

29 Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea.

30 Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju.

31 Àwọn ará Bẹnjamini jáde sí wọn, àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí fi ọgbọ́n tàn wọ́n kúrò ní ìlú; àwọn ará Bẹnjamini tún bẹ̀rẹ̀ sí pa ninu àwọn ọmọ Israẹli bíi ti iṣaaju. Wọ́n pa wọ́n ní ojú òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹtẹli ati Gibea ati ninu pápá. Àwọn tí wọ́n pa ninu wọ́n tó ọgbọ̀n eniyan.

32 Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.”

Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.”

33 Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba.

34 Ni ẹgbaarun (10,000) àṣàyàn àwọn jagunjagun ninu àwọn ọmọ Israẹli bá gbógun ti ìlú Gibea. Ogun náà gbóná gidigidi ṣugbọn àwọn ará Bẹnjamini kò mọ̀ pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí wọn.

35 OLUWA bá ṣẹgun àwọn ará Bẹnjamini fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbẹẹdọgbọn ó lé ọgọrun-un (25,100) eniyan ninu àwọn ará Bẹnjamini lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pa jẹ́ jagunjagun tí wọn ń lo idà.

Ìṣẹ́gun Israẹli

36 Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini.

37 Àwọn tí wọ́n ba ní ibùba yára jáde, wọ́n gbógun ti Gibea, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run.

38 Àmì tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn tí wọ́n ba ní ibùba ti jọ ṣe fún ara wọn ni pé, nígbà tí wọ́n bá rí i tí èéfín ńlá yọ sókè ní Gibea,

39 kí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ń sá lọ yipada, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ará Bẹnjamini ti pa bí ọgbọ̀n jagunjagun ninu àwọn Israẹli, wọ́n sì ti ń wí ninu ará wọn pé, “Dájúdájú a ti ṣẹgun wọn bíi ti àkọ́kọ́.”

40 Ṣugbọn nígbà tí èéfín tí àwọn ọmọ ogun Israẹli fi ṣe àmì bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láàrin ìlú, àwọn ará Bẹnjamini wo ẹ̀yìn, wọ́n rí i pé èéfín ti sọ, ó sì ti gba ìlú kan.

41 Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí wọn, ìdààmú sì bá àwọn ọmọ Bẹnjamini nítorí wọ́n rí i pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí.

42 Nítorí náà, wọ́n pada lẹ́yìn àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí ìhà aṣálẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ bà wọ́n, nítorí pé ààrin àwọn jagunjagun tí wọ́n yipada sí wọn, ati àwọn tí wọn ń jáde bọ̀ láti inú ìlú ni wọ́n bọ́ sí.

43 Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láì dáwọ́ dúró bí wọn ti ń lé wọn lọ. Wọ́n pa wọ́n láti Nohahi títí dé iwájú ìlà oòrùn Gibea.

44 Ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) ninu àwọn akikanju ará Bẹnjamini ni àwọn ọmọ Israẹli pa.

45 Wọ́n bá yipada, wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ tí ó lọ sí ibi àpáta Rimoni, àwọn ọmọ Israẹli sì tún pa ẹẹdẹgbaata (5,000) ninu wọn ní ojú ọ̀nà. Wọ́n ń lé wọn lọ tete títí dé Gidomu, wọ́n sì tún pa ẹgbaa (2,000) eniyan ninu wọn.

46 Gbogbo àwọn tí wọ́n kú ninu àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹẹdẹgbaata (25,000); gbogbo wọ́n jẹ́ akikanju jagunjagun tí ń lo idà.

47 Ṣugbọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu wọn sá lọ sí apá aṣálẹ̀, síbi àpáta Rimoni, wọ́n sì ń gbé inú àpáta Rimoni náà fún oṣù mẹrin.

48 Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí àwọn ará Bẹnjamini, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá fojú kàn, ati eniyan ati ẹranko. Gbogbo ìlú wọn tí wọ́n rí ni wọ́n sì sun níná.

Categories
ÀWỌN ADÁJỌ́

ÀWỌN ADÁJỌ́ 21

Àwọn Ẹ̀yà Bẹnjamini Fẹ́ Iyawo

1 Àwọn ọmọ Israẹli ti búra nígbà tí wọ́n wà ní Misipa pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní fi ọmọ rẹ̀ fún ará Bẹnjamini.”

2 Àwọn eniyan bá wá sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó níwájú Ọlọrun títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì sọkún gidigidi.

3 Wọ́n wí pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, tí ó fi jẹ́ pé lónìí ẹ̀yà Israẹli dín kan?”

4 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n tẹ́ pẹpẹ kan, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níbẹ̀.

5 Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè pé, “Èwo ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli ni kò wá sí ibi àjọ níwájú OLUWA?” Nítorí pé wọ́n ti ṣe ìbúra tí ó lágbára nípa ẹni tí kò bá wá siwaju OLUWA ní Misipa, wọ́n ní, “Pípa ni a óo pa á.”

6 Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí káàánú àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini arakunrin wọn, wọ́n ní, “Ẹ̀yà Israẹli dín kan lónìí.

7 Báwo ni a óo ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù; nítorí pé a ti fi OLUWA búra pé a kò ní fi àwọn ọmọbinrin wa fún wọn?”

8 Wọ́n bá bèèrè pé, “Ẹ̀yà wo ninu Israẹli ni kò wá siwaju OLUWA ní Misipa?” Wọ́n rí i pé ẹnikẹ́ni kò wá ninu àwọn ará Jabeṣi Gileadi sí àjọ náà.

9 Nítorí pé nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ, ẹnikẹ́ni láti inú àwọn tí ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi kò sí níbẹ̀.

10 Ìjọ eniyan náà bá rán ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn jagunjagun wọn tí wọ́n gbójú jùlọ, wọ́n sì fún wọn láṣẹ pé, “Ẹ lọ fi idà pa gbogbo àwọn tí ń gbé Jabeṣi Gileadi ati obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn.

11 Ohun tí ẹ ó ṣe nìyí: gbogbo ọkunrin wọn ati gbogbo obinrin tí ó bá ti mọ ọkunrin, pípa ni kí ẹ pa wọ́n.”

12 Wọ́n rí irinwo (400) ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin lára àwọn tí wọn ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì kó wọn wá sí àgọ́ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani.

13 Ni ìjọ eniyan bá ranṣẹ sí àwọn ará Bẹnjamini tí wọ́n wà níbi àpáta Rimoni, pé ìjà ti parí, alaafia sì ti dé.

14 Nígbà náà ni àwọn ará Bẹnjamini tó pada wá, àwọn ọmọ Israẹli sì fún wọn ní àwọn obinrin tí wọ́n mú láàyè ninu àwọn obinrin Jabeṣi Gileadi, ṣugbọn àwọn obinrin náà kò kárí wọn.

15 Àánú àwọn ọmọ Bẹnjamini bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé OLUWA ti dín ọ̀kan kù ninu ẹ̀yà Israẹli.

16 Àwọn àgbààgbà ìjọ eniyan náà bá bèèrè pé, “Níbo ni a óo ti rí aya fún àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, níwọ̀n ìgbà tí a ti pa àwọn obinrin ẹ̀yà Bẹnjamini run.”

17 Wọ́n bá dáhùn pé, “Àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn ara Bẹnjamini gbọdọ̀ ní ogún tiwọn, kí odidi ẹ̀yà kan má baà parun patapata ní Israẹli.

18 Ṣugbọn sibẹsibẹ, a kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọ wa fún wọn.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti búra pé, “Ẹni ègún ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọmọ fún ará Bẹnjamini.”

19 Wọ́n bá pinnu pé, “Ọdọọdún ni a máa ń ṣe àjọ̀dún OLUWA ní Ṣilo, tí ó wà ní apá àríwá Bẹtẹli, ní apá ìlà oòrùn òpópó ọ̀nà tí ó lọ láti Bẹtẹli sí Ṣekemu, ní apá gúsù Lebona.”

20 Wọ́n bá fún àwọn ọkunrin Bẹnjamini láṣẹ pé, “Ẹ lọ ba ní ibùba ninu ọgbà àjàrà,

21 kí ẹ máa ṣọ́ àwọn ọmọbinrin Ṣilo bí wọ́n bá wá jó; ẹ jáde láti inú ọgbà àjàrà, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ki iyawo kọ̀ọ̀kan mọ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọbinrin Ṣilo, kí ẹ sì gbé wọn sá lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini.

22 Nígbà tí àwọn baba wọn, tabi àwọn arakunrin wọn bá wá fi ẹjọ́ sùn wá, a óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún wọn nítorí pé àwọn obinrin tí a rí fún wọn ninu ogún kò kárí; kì í kúkú ṣe pé ẹ fi àwọn ọmọbinrin wọnyi fún wọn ni, tí ègún yóo fi ṣẹ le yín lórí.’ ”

23 Àwọn ará Bẹnjamini bá ṣe bí wọ́n ti sọ fún wọn. Olukuluku wọn gbé obinrin kọ̀ọ̀kan sá lọ ninu àwọn tí wọ́n wá jó, gbogbo wọn sì pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n tún ìlú wọn kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

24 Àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò níbẹ̀, gbogbo wọ́n sì pada sí ilẹ̀ wọn, olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀, sí ààrin ẹbí rẹ̀.

25 Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.

Categories
RUTU

RUTU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ní àkókò jàgídíjàgan, tí àwọn nǹkan tí a kà ninu

Ìwé Àwọn Adájọ́

ṣẹlẹ̀, ni àwọn nǹkan tí a kà ninu

Ìwé Rutu

náà ṣẹlẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀, obinrin gidi, ará ilẹ̀ Moabu ni Rutu; ó fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé ilẹ̀ Moabu nígbà náà. Nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú, Rutu fi ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn rẹ̀ hàn, ó sì dúró gbọningbọnin ti ìyá ọkọ rẹ̀, tí òun jẹ́ ará ilẹ̀ Israẹli, kò sì yẹsẹ̀ ninu sísin Ọlọrun Israẹli. Níkẹyìn, ó fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ẹbí ọkọ rẹ̀, nípasẹ̀ ọkọ rẹ̀ yìí, ọmọ ọmọ rẹ̀ bí Dafidi, tí ó wá di ọba tí ó ṣe pataki jùlọ ninu àwọn ọba Israẹli.

Àwọn ìtàn inú

Ìwé Àwọn Adájọ́

jẹ́ àkójọpọ̀ ìjìyà tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn kò tẹ̀lé ọ̀nà Ọlọrun; ṣugbọn ìtàn Rutu fihàn bí àjèjì tí ó tẹ̀lé ọ̀nà Ọlọrun Israẹli ṣe rí ọpọlọpọ ibukun gbà, tí ó sì di ọ̀kan ninu àwọn eniyan Ọlọrun.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Naomi pada sí Bẹtilẹhẹmu pẹlu Rutu 1:1-22

Rutu pàdé Boasi 2:1–3:18

Boasi fẹ́ Rutu 4:1-22