Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 18

Babiloni tú

1 Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀.

2 Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri.

3 Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.”

4 Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé,

“Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,

kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀.

5 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run,

Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀.

6 Ṣe fún un bí òun náà ti ṣe fún eniyan.

Gbẹ̀san lára rẹ̀ ní ìlọ́po meji ìwà rẹ̀.

Ife tí ó fi ń bu ọtí fún eniyan ni

kí o fi bu ọtí tí ó le ní ìlọ́po meji fún òun alára.

7 Bí ó ti ṣe ń jẹ ọlá,

tí ó ń jẹ ayé tẹ́lẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kí o fún un ní ìrora ati ìbànújẹ́.

Ó ń sọ ní ọkàn rẹ̀ pé,

‘Ọba orí ìtẹ́ ni mí,

èmi kì í ṣe opó,

ojú mi kò ní rí ìbànújẹ́.’

8 Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a,

ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn.

Iná yóo tún jó o ní àjórun,

nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.”

9 Àwọn ọba ayé ati àwọn tí wọ́n ti bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n ti ń bá a jayé yóo sunkún, wọn óo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí nígbà tí wọ́n bá rí èéfín iná tí ń jó o.

10 Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé,

“Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá,

Babiloni ìlú alágbára!

Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.”

11 Àwọn oníṣòwò ayé yóo sunkún, wọn yóo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí, nítorí wọn kò rí ẹni ra ọjà wọn mọ́; àwọn nǹkan bíi:

12 Wúrà, fadaka, òkúta iyebíye, oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀, aṣọ funfun ati àlàárì, ati sányán ati aṣọ pupa; oríṣìíríṣìí pákó, ati àwọn ohun èèlò tí a fi eyín erin, igi iyebíye, idẹ, irin, ati òkúta ṣe;

13 oríṣìíríṣìí òróró ìkunra, turari ati òjíá, ọtí, òróró olifi, ọkà, ati àgbàdo, ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun, ẹrú, àní ẹ̀mí eniyan.

14 Wọ́n ní, “Èso tí o fẹ́ràn kò sí mọ́, gbogbo ìgbé-ayé fàájì ati ti ìdẹ̀ra ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, o kò tún ní rí irú rẹ̀ mọ́.”

15 Àwọn oníṣòwò wọnyi, tí wọ́n ti di olówó ninu rẹ̀ yóo dúró ní òkèèrè nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀, wọn óo máa sunkún, wọn óo máa ṣọ̀fọ̀.

16 Wọn óo máa wí pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà! Ìlú tí ó wọ aṣọ funfun, ati aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa. Ìlú tí wúrà pọ̀ níbẹ̀ ati òkúta iyebíye ati ìlẹ̀kẹ̀!

17 Ní wakati kan péré ni gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ run!”

Nígbà náà ni gbogbo ọ̀gá àwọn awakọ̀ ojú omi, ati gbogbo àwọn tí ó ń wọ ọkọ̀ ati àwọn atukọ̀ ati àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ojú omi òkun lọ dúró ní òkèèrè.

18 Wọ́n ń kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí èéfín iná tí ń jó ìlú náà. Wọ́n wá ń sọ pé, “Ìlú wo ni ó dàbí ìlú ńlá yìí?”

19 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sórí ara wọn, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Wọ́n ní, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà, níbi tí gbogbo àwọn tí wọn ní ọkọ̀ lójú òkun ti di ọlọ́rọ̀ nípa ọrọ̀ rẹ̀, nítorí ní wakati kan ó ti di ahoro!

20 Ọ̀run, yọ̀ lórí rẹ̀! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin eniyan Ọlọrun, ẹ̀yin aposteli, ati ẹ̀yin wolii, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìdájọ́ fún un bí òun náà ti ṣe fún yín!”

21 Ọ̀kan ninu àwọn angẹli alágbára bá gbé òkúta tí ó tóbi bí ọlọ ògì, ó jù ú sinu òkun, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni a óo fi tagbára-tagbára sọ Babiloni ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀ tí a kò ní rí i mọ́.

22 A kò tún ní gbọ́ ohùn fèrè ati ti àwọn olórin tabi ti ohùn ìlù ati ti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ninu rẹ mọ́. A kò ní tún rí àwọn oníṣọ̀nà fún iṣẹ́ ọnà kan ninu rẹ mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ ninu rẹ mọ́.

23 Iná àtùpà kan kò ní tàn ninu rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́. Nígbà kan rí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn gbajúmọ̀ ninu ayé. O fi ìwà àjẹ́ tan gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ.”

24 Ninu rẹ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wolii ati ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun, ati gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n pa lórí ilẹ̀ ayé.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 19

1 Lẹ́yìn èyí mo gbọ́ ohùn kan bí igbe ọ̀pọ̀ eniyan ní ọ̀run, tí ń sọ pé, “Haleluya! Ìgbàlà ati ògo ati agbára ni ti Ọlọrun wa.

2 Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.”

3 Wọ́n tún wí lẹẹkeji pé, “Haleluya! Èéfín rẹ̀ ń gòkè lae ati laelae.”

4 Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun tí ó jókòó lórí ìtẹ́. Wọ́n ní, “Amin! Haleluya!”

Àsè Igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan

5 Ẹnìkan fọhùn láti orí ìtẹ́ náà, ó ní, “Ẹ yin Ọlọrun wa, gbogbo ẹ̀yin ìran rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin mẹ̀kúnnù ati ẹ̀yin eniyan pataki.”

6 Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba.

7 Ẹ jẹ́ kí á yọ̀, kí inú wa dùn, ẹ jẹ́ kí á fi ògo fún un, nítorí ó tó àkókò igbeyawo Ọ̀dọ́ Aguntan náà. Iyawo rẹ̀ sì ti ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ dè é.

8 A fún un ní aṣọ funfun tí ń dán, tí ó sì mọ́. Aṣọ funfun náà ni iṣẹ́ òdodo àwọn eniyan Ọlọrun.”

9 Ó sọ fún mi pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀: àwọn tí a pè sí àsè igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan náà ṣe oríire.” Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ọ̀rọ̀ wọnyi.”

10 Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.”

Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii.

Ẹnìkan tí Ó Gun Ẹṣin Funfun

11 Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun.

12 Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára.

13 Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

14 Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́.

15 Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare.

16 A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”

17 Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun,

18 kí ẹ lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba ati ti àwọn ọ̀gágun, ati ti àwọn alágbára, ati ẹran ẹṣin ati ti àwọn tí wọ́n gùn wọ́n, ati ẹran-ara àwọn òmìnira ati ti ẹrú, ti àwọn mẹ̀kúnnù ati ti àwọn ọlọ́lá.”

19 Mo wá rí ẹranko náà ati àwọn ọba ilé ayé ati àwọn ọmọ-ogun wọn. Wọ́n péjọ láti bá ẹni tí ó gun ẹṣin funfun náà ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jagun.

20 A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá.

21 Wọ́n fi idà tí ó wà lẹ́nu ẹni tí ó gun ẹṣin funfun pa àwọn yòókù. Gbogbo àwọn ẹyẹ bá ń jẹ ẹran-ara wọn ní àjẹrankùn.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 20

Ìjọba Ẹgbẹrun Ọdún

1 Mo wá rí angẹli kan tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó mú kọ́kọ́rọ́ kànga tí ó jìn pupọ náà lọ́wọ́ ati ẹ̀wọ̀n gígùn.

2 Ó bá ki Ẹranko Ewèlè náà mọ́lẹ̀, ejò àtijọ́ náà tíí ṣe Èṣù tabi Satani, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é fún ẹgbẹrun ọdún.

3 Ó bá jù ú sinu kànga tí ó jìn pupọ náà, ó pa ìdérí rẹ̀ dé mọ́ ọn lórí. Ó bá fi èdìdì dì í kí ó má baà tan àwọn eniyan jẹ mọ́ títí ẹgbẹrun ọdún yóo fi parí. Lẹ́yìn náà, a óo dá a sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

4 Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.

5 Àwọn òkú yòókù kò jí dìde títí òpin ẹgbẹrun ọdún. Èyí ni ajinde kinni.

6 Àwọn eniyan Ọlọrun tí ó bá ní ìpín ninu ajinde kinni ṣe oríire. Ikú keji kò ní ní àṣẹ lórí wọn. Wọn óo jẹ́ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn óo sì jọba pẹlu rẹ̀ fún ẹgbẹrun ọdún.

A Ṣẹgun Satani

7 Nígbà tí ẹgbẹrun ọdún bá parí a óo tú Satani sílẹ̀ ninu ẹ̀wọ̀n tí ó ti wà.

8 Yóo wá tún jáde lọ láti máa tan àwọn eniyan jẹ ní igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Yóo kó gbogbo eniyan Gogu ati Magogu jọ láti jagun, wọn óo pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.

9 Wọ́n gba gbogbo ìbú ilẹ̀ ayé, wọ́n wá yí àwọn eniyan Ọlọrun ká ati ìlú tí Ọlọrun fẹ́ràn. Ni iná bá sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, ó bá jó wọn run patapata.

10 A bá ju Èṣù tí ó ń tàn wọ́n jẹ sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá, níbi tí ẹranko náà ati wolii èké náà wà, tí wọn yóo máa joró tọ̀sán-tòru lae ati laelae.

Ìdájọ́ Ìkẹyìn

11 Mo wá rí ìtẹ́ funfun ńlá kan ati ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ayé ati ọ̀run sálọ fún un, a kò rí ààyè fún wọn mọ́.

12 Mo rí òkú àwọn ọlọ́lá ati ti àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ wà ní ṣíṣí. Ìwé mìíràn tún wà ní ṣíṣí, tí orúkọ àwọn alààyè wà ninu rẹ̀. A wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ àwọn òkú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn tí ó wà ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀.

13 Gbogbo àwọn tí wọ́n kú sinu òkun tún jáde sókè. Gbogbo òkú tí ó wà níkàáwọ́ ikú ati àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú ni wọ́n tún jáde. A wá ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

14 Ni a bá ju ikú ati ipò òkú sinu adágún iná. Adágún iná yìí ni ikú keji.

15 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí orúkọ rẹ̀ ninu ìwé ìyè, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 21

Ọ̀run Titun ati Ayé Titun

1 Mo rí ọ̀run titun ati ayé titun, ayé ti àkọ́kọ́ ti kọjá lọ. Òkun kò sì sí mọ́.

2 Lẹ́yìn náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerusalẹmu titun, tí ó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sọ̀kalẹ̀ láti òkè wá. A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bí ìgbà tí a bá ṣe iyawo lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.

3 Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn;

4 yóo nu gbogbo omijé nù ní ojú wọn. Kò ní sí ikú mọ́, tabi ọ̀fọ̀ tabi ẹkún tabi ìrora. Nítorí àwọn ohun ti àtijọ́ ti kọjá lọ.”

5 Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà sọ pé, “Mò ń sọ ohun gbogbo di titun.” Ó ní, “Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí òdodo ọ̀rọ̀ ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí.”

6 Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.

7 Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni yóo jogún nǹkan wọnyi. N óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ̀, òun náà yóo sì máa jẹ́ ọmọ mi.

8 Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.”

Jerusalẹmu Titun

9 Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí ó mú àwo meje lọ́wọ́, tí ìparun ìkẹyìn meje wà ninu wọn, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní “Wá, n óo fi iyawo Ọ̀dọ́ Aguntan hàn ọ́.”

10 Ó bá gbé mi ninu ẹ̀mí lọ sí orí òkè ńlá kan tí ó ga, ó fi Jerusalẹmu ìlú mímọ́ náà hàn mí, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

11 Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara.

12 Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà.

13 Ìlẹ̀kùn mẹta wà ní ìhà ìlà oòrùn, mẹta wà ní ìhà àríwá, mẹta wà ni ìhà gúsù, mẹta wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.

14 Odi ìlú náà ní ìpìlẹ̀ mejila. Orúkọ mejila ti àwọn aposteli mejila ti Ọ̀dọ́ Aguntan wà lára wọn.

15 Ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá ìwọnlẹ̀ wúrà lọ́wọ́ láti fi wọn ìlú náà ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, ati odi rẹ̀.

16 Igun mẹrẹẹrin ìlú náà dọ́gba, bákan náà ni gígùn rẹ̀ ati ìbú rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọnlẹ̀ náà wọn ìlú náà. Bákan náà ni gígùn rẹ̀, ati ìbú rẹ̀, ati gíga rẹ̀. Ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹjọ (1500) ibùsọ̀.

17 Ó wá wọn odi rẹ̀, ó ga tó igba ẹsẹ̀ ó lé ogún (220) gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n eniyan tí angẹli náà ń lò.

18 Òkúta iyebíye ni wọ́n fi mọ odi náà. Wúrà ni gbogbo ìlú náà tí ó mọ́ gaara bíi dígí.

19 Òkúta iyebíye oríṣìíríṣìí ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ odi ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ kinni, òkúta iyebíye oríṣìí kan, ekeji oríṣìí mìíràn, ẹkẹta oríṣìí mìíràn, ẹkẹrin, bẹ́ẹ̀;

20 ẹkarun-un, bẹ́ẹ̀; ẹkẹfa, bẹ́ẹ̀, ekeje bẹ́ẹ̀, ẹkẹjọ, bẹ́ẹ̀, ẹkẹsan-an, bẹ́ẹ̀, ẹkẹwaa, bẹ́ẹ̀, ikọkanla bẹ́ẹ̀, ekejila náà, bẹ́ẹ̀.

21 Òkúta tí ó dàbí ìlẹ̀kẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn mejeejila ìlú náà; ẹyọ òkúta kọ̀ọ̀kan ni wọ́n fi gbẹ́ ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan. Wúrà ni wọ́n yọ́ sí títì ìlú náà. Ó mọ́ gaara bíi dígí.

22 N kò rí Tẹmpili ninu ìlú náà. Nítorí Oluwa Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ni Tẹmpili ibẹ̀.

23 Ìlú náà kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn tabi ti òṣùpá, nítorí pé ògo Ọlọrun ni ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí i; Ọ̀dọ́ Aguntan ni àtùpà ibẹ̀.

24 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa rìn ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ilé-ayé yóo mú ọlá wọn wá sinu rẹ̀.

25 Wọn kò ní ti àwọn ìlẹ̀kùn ìlú náà ní gbogbo ọ̀sán; òru kò sì ní sí níbẹ̀.

26 Wọn yóo mú ẹwà ati ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sí inú rẹ̀.

27 Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀.

Categories
ÌFIHÀN

ÌFIHÀN 22

1 Ó wá fi odò omi ìyè hàn mí, tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Ó ń ti ibi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ṣàn wá.

2 Ó gba ààrin títì ìlú náà. Igi ìyè kan wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ òsì odò náà. Igi ìyè yìí ń so èso mejila, ọ̀kan ní oṣooṣù. Ewé igi náà wà fún ìwòsàn àwọn orílẹ̀-èdè.

3 Kò ní sí ègún mọ́.

Ìtẹ́ Ọlọrun ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan yóo wà níbẹ̀. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa sìn ín.

4 Wọn óo rí i lojukooju, orúkọ rẹ̀ yóo sì wà níwájú wọn.

5 Kò ní sí òru mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní nílò ìmọ́lẹ̀ àtùpà tabi ìmọ́lẹ̀ oòrùn, nítorí Oluwa Ọlọrun wọn ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún wọn. Wọn yóo sì máa jọba lae ati laelae.

Dídé Kristi

6 Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Oluwa Ọlọrun tí ó mí sinu àwọn wolii rẹ̀ ni ó rán angẹli rẹ̀ pé kí ó fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn iranṣẹ rẹ̀.”

7 “Mò ń bọ̀ kíákíá. Ẹni tí ó bá pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́ ṣe oríire.”

8 Èmi Johanu ni mo gbọ́ nǹkan wọnyi, tí mo sì rí wọn. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí wọn, mo dojúbolẹ̀ níwájú angẹli tí ó fi wọ́n hàn mí.

9 Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi náà ati ti àwọn wolii, arakunrin rẹ, ati ti àwọn tí wọ́n ti pa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí mọ́. Ọlọrun ni kí o júbà.”

10 Ó tún sọ fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí nítorí àkókò tí wọn yóo ṣẹ súnmọ́ tòsí. Ẹni tí ó bá ń hùwà burúkú, kí ó máa hùwà burúkú rẹ̀ bọ̀.

11 Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.”

12 “Mò ń bọ̀ ní kíá. Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi, tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.

13 Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.”

14 Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà.

15 Lóde ni àwọn ajá yóo wà ati àwọn oṣó ati àwọn àgbèrè, ati àwọn apànìyàn ati àwọn abọ̀rìṣà ati àwọn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe èké.

16 “Èmi Jesu ni mo rán angẹli mi láti jíṣẹ́ gbogbo nǹkan wọnyi fún ẹ̀yin ìjọ. Èmi gan-an ni gbòǹgbò ati ọmọ Dafidi. Èmi ni ìràwọ̀ òwúrọ̀.”

17 Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!”

Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.”

Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.

18 Mò ń kìlọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá fi nǹkankan kún un, Ọlọrun yóo fi kún àwọn ìyà rẹ̀ tí a ti kọ sinu ìwé yìí.

19 Bí ẹnikẹ́ni bá mú nǹkankan kúrò ninu ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí, Ọlọrun yóo mú ìpín rẹ̀ kúrò lára igi ìyè ati kúrò ninu ìlú mímọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé yìí.

20 Ẹni tí ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, tètè máa bọ̀. Amin! Máa bọ̀, Oluwa Jesu.”

21 Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu gbogbo yín.