Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 20

Ọ̀tẹ̀ Ṣeba

1 Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní,

“Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi,

a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese.

Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.”

2 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lẹ́yìn Dafidi, wọ́n tẹ̀lé Ṣeba. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda tẹ̀lé Dafidi, ọba wọn, pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, láti odò Jọdani títí dé Jerusalẹmu.

3 Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú.

4 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Amasa pé, “Pe gbogbo àwọn ọkunrin Juda jọ, kí o sì kó wọn wá sọ́dọ̀ mi láàrin ọjọ́ mẹta; kí ìwọ náà sì wá.”

5 Amasa bá lọ kó àwọn eniyan Juda jọ, ṣugbọn kò dé títí àkókò tí ọba dá fún un fi kọjá.

6 Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.”

7 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Joabu, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun yòókù, tí wọ́n kù ní Jerusalẹmu bá tẹ̀lé Abiṣai láti lépa Ṣeba.

8 Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá kan, tí ó wà ní Gibeoni, Amasa lọ pàdé wọn. Ẹ̀wù ọmọ ogun ni Joabu wọ̀; ó sán ìgbànú kan, idà rẹ̀ sì wà ninu àkọ̀ lára ìgbànú tí ó ti sán mọ́ ìbàdí. Bí Joabu ti rìn siwaju bẹ́ẹ̀ ni idà yìí bọ́ sílẹ̀.

9 Ó bá bèèrè lọ́wọ́ Amasa pé, “Ṣé alaafia ni, arakunrin mi?” Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá Amasa ní irùngbọ̀n mú, bí ẹni pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

10 Amasa kò fura rárá pé idà wà ní ọwọ́ Joabu. Joabu bá gún un ní idà níkùn, gbogbo ìfun rẹ̀ tú jáde. Amasa kú lẹsẹkẹsẹ, láì jẹ́ pé Joabu tún gún un ní idà lẹẹkeji.

Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ bá ń lépa Ṣeba lọ.

11 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Joabu dúró ti òkú Amasa, ó sì ń kígbe pé, “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ti Joabu ati ti Dafidi tẹ̀lé Joabu.”

12 Òkú Amasa, tí ẹ̀jẹ̀ ti bò, wà ní ojú ọ̀nà gbangba, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọjá, tí ó bá rí i ń dúró. Nígbà tí ọkunrin tí ó dúró ti òkú náà rí i pé gbogbo eniyan ní ń dúró, ó wọ́ òkú náà kúrò lójú ọ̀nà, sinu igbó, ó sì fi aṣọ bò ó.

13 Nígbà tí ó wọ́ ọ kúrò lójú ọ̀nà tán, gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí sá tẹ̀lé Joabu, wọ́n ń lépa Ṣeba lọ.

14 Ṣeba la ilẹ̀ gbogbo ẹ̀yà Israẹli já, ó lọ sí ìlú Abeli ti Beti Maaka. Gbogbo àwọn ará Bikiri bá péjọ, wọ́n sì tẹ̀lé e wọnú ìlú náà.

15 Àwọn ọmọ ogun Joabu bá lọ dó ti ìlú náà, wọ́n fi erùpẹ̀ mọ òkítì gíga sára odi rẹ̀ lóde, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ odi náà lábẹ́, wọ́n fẹ́ wó o lulẹ̀.

16 Obinrin ọlọ́gbọ́n kan wà ninu ìlú náà, tí ó kígbe láti orí odi, ó ní, “Ẹ tẹ́tí, ẹ gbọ́! Ẹ sọ fún Joabu kí ó wá gbọ́! Mo ní ọ̀rọ̀ kan tí mo fẹ́ bá a sọ.”

17 Joabu bá lọ sibẹ. Obinrin náà bèèrè pé, “Ṣé ìwọ ni Joabu?”

Joabu dáhùn pé, “Èmi ni.”

Obinrin náà ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èmi, iranṣẹbinrin rẹ fẹ́ sọ.”

Joabu dá a lóhùn pé, “Mò ń gbọ́.”

18 Obinrin yìí ní, “Nígbà àtijọ́, wọn a máa wí pé, ‘Bí ọ̀rọ̀ kan bá ta kókó, ìlú Abeli ni wọ́n ti í rí ìtumọ̀ rẹ̀.’ Lóòótọ́ sì ni, ibẹ̀ gan-an ni wọ́n tií rí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀.

19 Abeli jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó fẹ́ alaafia, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ jùlọ ní Israẹli. Ṣé o wá fẹ́ pa ìlú tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli run ni? Kí ló dé tí o fi fẹ́ pa nǹkan OLUWA run?”

20 Joabu dáhùn pé, “Rárá o! Kò sí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe ìlú yìí ni mo fẹ́ parun.

21 Ọkunrin kan, tí ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti agbègbè olókè ti Efuraimu, ni ó ń dìtẹ̀ mọ́ Dafidi ọba. Bí o bá ti fa òun nìkan ṣoṣo kalẹ̀, n óo kúrò ní ìlú yín.”

Obinrin yìí bá dáhùn pé, “A óo ju orí rẹ̀ sílẹ̀ sí ọ, láti orí odi.”

22 Obinrin yìí bá tọ gbogbo àwọn ará ìlú lọ, ó sì fi ọgbọ́n bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n bá gé orí Ṣeba, wọ́n jù ú sí Joabu láti orí odi. Joabu bá fọn fèrè ogun, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fi ìlú náà sílẹ̀, wọ́n pada sí ilé. Joabu bá pada lọ sọ́dọ̀ ọba, ní Jerusalẹmu.

Àwọn Adarí Àwọn Òṣìṣẹ́ ní Ààfin Dafidi

23 Joabu ni balogun àwọn ọmọ ogun ní Israẹli. Bẹnaya ọmọ Jehoiada sì ní olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba.

24 Adoramu ni olórí àwọn tí wọ́n ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́. Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ ní ààfin ọba.

25 Ṣefa ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Sadoku ati Abiatari ni alufaa.

26 Ira, ará ìlú Jairi náà jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn alufaa Dafidi.

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 21

Wọ́n Pa Àwọn Ọmọ Ọmọ Saulu

1 Ní àkókò ìjọba Dafidi, ìyàn ńlá kan mú, fún odidi ọdún mẹta. Dafidi bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu ati ìdílé rẹ̀ jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.”

2 Àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli. Ara àwọn ará Amori tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti ṣèlérí pé àwọn kò ní pa wọ́n, sibẹsibẹ Saulu gbìyànjú láti pa wọ́n run, nítorí ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli ati Juda.

3 Dafidi bá pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín? Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ṣe àtúnṣe ibi tí wọ́n ṣe si yín, kí ẹ baà lè súre fún àwọn eniyan OLUWA?”

4 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Aáwọ̀ tí ó wà láàrin àwa ati Saulu ati ìdílé rẹ̀, kì í ṣe ohun tí a lè fi wúrà ati fadaka parí, a kò sì fẹ́ pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.”

Dafidi bá tún bèèrè pé, “Kí ni ẹ wá fẹ́ kí n ṣe fun yín?”

5 Wọ́n dáhùn pé, “Saulu fẹ́ pa wá run, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wa wà láàyè níbikíbi, ní ilẹ̀ Israẹli.

6 Nítorí náà, fún wa ní meje ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, kí á lè so wọ́n kọ́ níwájú OLUWA ní Gibea, ní orí òkè OLUWA.”

Dafidi dáhùn pé, “N óo kó wọn lé yín lọ́wọ́.”

7 Ṣugbọn nítorí majẹmu tí ó wà láàrin Dafidi ati Jonatani, Dafidi kò fi ọwọ́ kan Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu.

8 Ṣugbọn ó mú Arimoni ati Mẹfiboṣẹti àwọn ọmọkunrin mejeeji tí Risipa, ọmọ Aya, bí fún Saulu; ó sì tún mú àwọn ọmọ marun-un tí Merabu, ọmọbinrin Saulu, bí fún Adirieli ọmọ Basilai ará Mehola.

9 Dafidi kó wọn lé àwọn ará Gibeoni lọ́wọ́, àwọn ará Gibeoni sì so wọ́n kọ́ sórí igi, lórí òkè níwájú OLUWA, àwọn mejeeje sì kú papọ̀. Àkókò tí wọ́n kú yìí jẹ́ àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali nígbà tí àkókò ìrúwé fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀.

10 Risipa, ọmọbinrin Aya, fi aṣọ ọ̀fọ̀ pa àtíbàbà fún ara rẹ̀ lórí òkúta, níbi tí òkú àwọn tí wọ́n pa wà. Ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí di àkókò tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ní ojúmọmọ, kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ jẹ wọ́n ní ọ̀sán, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú fọwọ́ kàn wọ́n lóru.

11 Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí Risipa, ọmọ Aya, obinrin Saulu ṣe,

12 ó lọ kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀, tí ó wà lọ́dọ̀ àwọn ará Jabeṣi-Gileadi. (Àwọn ará Jabeṣi ti jí àwọn egungun náà kó kúrò ní ìta gbangba, ní ààrin ìlú ní Beti Ṣani, níbi tí àwọn ará Filistia so wọ́n kọ́ sí, ní ọjọ́ tí wọ́n pa wọ́n ní òkè Giliboa.)

13 Láti ibẹ̀ ni ó ti kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì kó egungun àwọn mejeeje tí wọ́n so kọ́ pẹlu.

14 Wọ́n sin egungun Saulu, ati ti Jonatani, sinu ibojì Kiṣi, baba rẹ̀, ní Sela ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini. Gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni wọ́n ṣe. Lẹ́yìn náà, ni Ọlọrun gbọ́ adura tí wọ́n ń gbà fún ilẹ̀ náà.

Wọ́n Bá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun

15 Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì lọ bá àwọn ará Filistia jagun. Bí wọ́n ti ń jà, àárẹ̀ mú Dafidi.

16 Òmìrán kan tí ń jẹ́ Iṣibibenobu, gbèrò láti pa Dafidi. Ọ̀kọ̀ Iṣibibenobu yìí wọ̀n tó ọọdunrun ṣekeli idẹ, ó sì so idà tuntun mọ́ ẹ̀gbẹ́.

17 Ṣugbọn Abiṣai, ọmọ Seruaya, sáré wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, ó kọlu òmìrán náà, ó sì pa á. Láti ìgbà náà ni àwọn ọmọ ogun Dafidi ti búra fún un pé, “A kò ní jẹ́ kí o bá wa lọ sí ojú ogun mọ́ kí á má baà pàdánù rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìrètí Israẹli.”

18 Lẹ́yìn èyí, ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, ní Gobu, ninu ogun yìí ni Sibekai ará Huṣa ti pa Safu, ọ̀kan ninu àwọn ìran òmìrán.

19 Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia kan náà, ní Gobu. Ninu ogun yìí ni Elihanani ọmọ Jaareoregimu, ará Bẹtilẹhẹmu, ti pa Goliati, ará Giti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ nípọn tó igi òfì tí àwọn obinrin fi máa ń hun aṣọ.

20 Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Òmìrán kan wà níbẹ̀ tí ó fẹ́ràn ogun jíjà pupọ, ìka mẹfa mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan, ati ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan; ìka ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹrinlelogun.

21 Jonatani, ọmọ Ṣimei, arakunrin Dafidi pa á, nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́.

22 Láti ìran àwọn òmìrán ìlú Gati ni àwọn mẹrẹẹrin ti wá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n.

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 22

Orin Ìṣẹ́gun Tí Dafidi Kọ

1 Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé:

2 “OLUWA ni àpáta mi,

ààbò mi, ati olùgbàlà mi;

3 Ọlọrun mi, àpáta mi,

ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí.

Àpáta mi ati ìgbàlà mi,

ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi,

olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá.

4 Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,

Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

5 “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi;

ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi;

6 isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí,

ewu ikú sì dojú kọ mí.

7 Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA

mo ké pe Ọlọrun mi,

ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀;

ó sì tẹ́tí sí igbe mi.

8 “Ayé mì, ó sì wárìrì;

ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì,

ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun.

9 Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,

iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀;

ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde.

10 Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀;

ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

11 Ó gun orí Kerubu, ó fò,

afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò.

12 Ó fi òkùnkùn bo ara,

ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn,

tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí.

13 Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde,

láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀.

14 “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá,

ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo.

15 Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká.

Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá.

16 Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀,

nígbà tí OLUWA bá wọn wí,

tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn.

17 “OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú,

ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn.

18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára;

ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi;

nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

19 Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí,

ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí.

20 Ó ràn mí lọ́wọ́,

ó kó mi yọ ninu ewu,

ó sì gbà mí là,

nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.

21 “OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi,

ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi.

22 Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́,

n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.

23 Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀,

n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀.

24 N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀,

mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá.

25 Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,

ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀.

26 “OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ;

ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi.

27 Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́,

ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú.

28 Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀,

o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

29 “OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi,

ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.

30 Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi,

mo sì lè fo odi kọjá.

31 Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀,

òtítọ́ ni ìlérí OLUWA,

ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀.

32 Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA?

Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa?

33 Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára,

ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi.

34 Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín,

ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè.

35 Ó kọ́ mi ní ogun jíjà,

tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ.

36 “O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ,

ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá.

37 Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí,

bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀.

38 Mo lépa àwọn ọ̀tá mi,

mo sì ṣẹgun wọn

n kò pada lẹ́yìn wọn títí tí mo fi pa wọ́n run.

39 Mo pa wọ́n run, mo bì wọ́n lulẹ̀;

wọn kò sì lè dìde mọ́;

wọ́n ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.

40 Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun,

o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi.

41 O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi,

mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run.

42 Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri,

ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n;

wọ́n pe OLUWA,

ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

43 Mo fọ́ wọn túútúú, wọ́n sì dàbí erùpẹ̀ ilẹ̀;

mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì dàbí ẹrọ̀fọ̀ lójú títì.

44 “Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi,

o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè;

àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí.

45 Àwọn àjèjì ń wólẹ̀ níwájú mi,

ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti gbúròó mi, ni wọ́n ń mú àṣẹ mi ṣẹ.

46 Ẹ̀rù ba àwọn àjèjì,

wọ́n gbọ̀n jìnnìjìnnì jáde ní ibi ààbò wọn.

47 “OLUWA wà láàyè,

ìyìn ni fún àpáta ààbò mi.

Ẹ gbé Ọlọrun mi ga,

ẹni tíí ṣe àpáta ìgbàlà mi.

48 Ọlọrun ti jẹ́ kí n gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,

ó ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba lábẹ́ mi;

49 ó sì fà mí yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

“OLUWA, ìwọ ni o gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá mi lọ,

o sì dáàbò bò mí, lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.

50 Nítorí náà, n óo máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

n óo máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.

51 Ọlọrun fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,

ó sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ han ẹni tí ó fi àmì òróró yàn,

àní Dafidi ati arọmọdọmọ rẹ̀ laelae!”

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 23

Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Dafidi

1 Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi nìyí; àní, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Dafidi, ọmọ Jese, tí a gbé ga ní Israẹli, ẹni àmì òróró Ọlọrun Jakọbu, olórin dídùn ní Israẹli:

2 “Ẹ̀mí OLUWA ń gba ẹnu mi sọ̀rọ̀,

ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní ẹnu mi.

3 Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀,

Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé,

‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba,

tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun,

4 a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,

bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu,

ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu;

ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’

5 “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun,

nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo,

majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀.

Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi.

Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi.

6 Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrun

dàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù,

kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú.

7 Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀,

láti fi wọ́n jóná patapata.”

Àwọn Akọni Ọmọ Ogun Dafidi

8 Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo.

9 Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn.

10 Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa.

11 Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia,

12 ṣugbọn Ṣama dúró gbọningbọnin ní ojú ogun. Ó jà kíkankíkan, ó sì pa àwọn ará Filistia. OLUWA sì ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà.

13 Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu.

14 Dafidi wà ní orí òkè kan tí wọ́n mọ odi yípo, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan ti gba Bẹtilẹhẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀.

15 Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.”

16 Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA.

17 Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe.

18 Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn.

19 Òun ni ó jẹ́ olókìkí jùlọ ninu “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni,” ó sì di aṣiwaju wọn, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” àkọ́kọ́.

20 Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ.

21 Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á.

22 Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”.

23 Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.

24 Àwọn mìíràn tí wọ́n tún jẹ́ ara “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni” náà nìwọ̀nyí: Asaheli arakunrin Joabu, ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu.

25 Ṣama ati Elika, àwọn mejeeji jẹ́ ará Harodu;

26 Helesi, ará Paliti, Ira, ọmọ Ikeṣi, ará Tekoa;

27 Abieseri, ará Anatoti, ati Mebunai, ará Huṣa;

28 Salimoni, ará Ahohi, ati Maharai, ará Netofa;

29 Helebu, ọmọ Baana, tí òun náà jẹ́ ará Netofa, ati Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini;

30 Bẹnaya ará Piratoni ati Hidai ará ẹ̀bá àwọn odò Gaaṣi;

31 Abialiboni ará Araba, ati Asimafeti ará Bahurimu;

32 Eliaba, ará Ṣaaliboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, ati Jonatani;

33 Ṣama, ará Harari, Ahiamu, ọmọ Ṣarari, ará Harari;

34 Elifeleti, ọmọ Ahasibai, ará Maaka, Eliamu, ọmọ Ahitofẹli, ará Gilo;

35 Hesiro, ará Kamẹli, Paarai, ará Abiti;

36 Igali, ọmọ Natani, ará Soba, Bani, ará Gadi;

37 Seleki, ará Amoni, Naharai, ará Beeroti, tí ó máa ń ru ihamọra Joabu, ọmọ Seruaya.

38 Ira ati Garebu, àwọn mejeeji jẹ́ ará Itiri;

39 ati Uraya, ará Hiti.

Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ọmọ ogun náà jẹ́ mẹtadinlogoji.

Categories
SAMUẸLI KEJI

SAMUẸLI KEJI 24

Dafidi Ka Àwọn Eniyan Israẹli

1 Inú tún bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ti Dafidi láti kó ìyọnu bá wọn. OLUWA wí fún un pé, lọ ka àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda.

2 Dafidi bá pàṣẹ fún Joabu, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó ní, “Ẹ lọ sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí ẹ sì ka gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀, kí n lè mọ iye wọn.”

3 Ṣugbọn Joabu bi ọba léèrè pé, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ jù báyìí lọ, ní ìlọ́po ọ̀nà ọgọrun-un (100), nígbà tí oluwa mi ṣì wà láàyè; ṣugbọn, kí ló dé tí kabiyesi fi fẹ́ ka àwọn eniyan wọnyi?”

4 Ṣugbọn àṣẹ tí ọba pa ni ó borí. Ni Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bá jáde kúrò níwájú ọba, wọ́n bá lọ ka àwọn ọmọ Israẹli.

5 Wọ́n ré odò Jọdani kọjá, wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù Aroeri, ìlú tí ó wà ní ààrin àfonífojì, ní agbègbè Gadi. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti lọ sí ìhà àríwá, títí dé Jaseri.

6 Wọ́n lọ sí Gileadi, ati sí Kadeṣi ní ilẹ̀ àwọn ará Hiti. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Dani. Láti Dani, wọ́n lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé Sidoni.

7 Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda.

8 Oṣù mẹsan-an ati ogúnjọ́ ni ó gbà wọ́n láti lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Israẹli, lẹ́yìn náà, wọ́n pada sí Jerusalẹmu.

9 Joabu sọ iye àwọn eniyan tí ó kà fún ọba: Ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) ni àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun jà ní ilẹ̀ Israẹli, àwọn ti ilẹ̀ Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000).

10 Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ka àwọn eniyan náà tán, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú. Ó bá wí fún OLUWA pé, “Ohun tí mo ṣe yìí burú gan-an, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni. Jọ̀wọ́, dáríjì èmi iranṣẹ rẹ, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni mo hù.”

11 Nígbà tí Dafidi jí ní òwúrọ̀, OLUWA rán wolii Gadi, aríran rẹ̀ sí i pé,

12 “Lọ sọ fún Dafidi pé mo fi nǹkan mẹta siwaju rẹ̀; kí ó yan ọ̀kan tí ó fẹ́ kí n ṣe sí òun ninu mẹtẹẹta.”

13 Gadi bá lọ sọ ohun tí OLUWA wí fún Dafidi. Ó bèèrè pé, “Èwo ni o fẹ́ yàn ninu mẹtẹẹta yìí, ekinni, kí ìyàn mú ní ilẹ̀ rẹ fún ọdún mẹta; ekeji, kí o máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ fún oṣù mẹta; ẹkẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn jà fún ọjọ́ mẹta ní gbogbo ilẹ̀ rẹ? Rò ó dáradára, kí o sì sọ èyí tí o fẹ́, kí n lọ sọ fún OLUWA.”

14 Dafidi dá Gadi lóhùn pé, “Ìdààmú ńlá ni ó dé bá mi yìí, ṣugbọn ó yá mi lára kí OLUWA jẹ wá níyà ju pé kí ó fi mí lé eniyan lọ́wọ́ lọ; nítorí pé, aláàánú ni OLUWA.”

15 Nítorí náà, OLUWA fi àjàkálẹ̀ àrùn bá Israẹli jà. Ó bẹ̀rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àkókò tí ó yàn jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Láti Dani títí dé Beeriṣeba, gbogbo àwọn tí ó kú jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000).

16 Nígbà tí angẹli OLUWA náà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti máa pa Jerusalẹmu run, OLUWA yí ọkàn pada nípa jíjẹ tí ó ń jẹ àwọn eniyan náà níyà. Ó bá wí fún angẹli náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Níbi ìpakà Arauna ará Jebusi kan ni angẹli náà wà nígbà náà.

17 Nígbà tí Dafidi rí angẹli tí ó ń pa àwọn eniyan náà, ó wí fún OLUWA pé, “Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo ṣe burúkú. Kí ni àwọn eniyan wọnyi ṣe? Èmi ati ìdílé baba mi ni ó yẹ kí ó jẹ níyà.”

18 Ní ọjọ́ náà gan-an, Gadi tọ Dafidi lọ, ó sì wí fún un pé, “Lọ sí ibi ìpakà Arauna kí o sì tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀.”

19 Dafidi pa àṣẹ OLUWA mọ́, ó sì lọ sí ibi ìpakà Arauna, gẹ́gẹ́ bí Gadi ti sọ fún un.

20 Nígbà tí Arauna wo ìsàlẹ̀, ó rí ọba ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó lọ pàdé rẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀.

21 Ó bi í pé, “Ṣé kò sí, tí oluwa mi, ọba, fi wá sọ́dọ̀ èmi, iranṣẹ rẹ̀?”

Dafidi dá a lóhùn pé, “Ilẹ̀ ìpakà rẹ ni mo fẹ́ rà, mo fẹ́ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.”

22 Arauna dá a lóhùn pé, “Máa mú un, kí o sì mú ohunkohun tí o bá fẹ́ fi rúbọ sí OLUWA. Akọ mààlúù nìwọ̀nyí, tí o lè fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Àwọn àjàgà wọn nìwọ̀nyí, ati àwọn igi ìpakà tí o lè lò fún igi ìdáná.”

23 Arauna kó gbogbo rẹ̀ fún ọba, ó ní, “Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gba ẹbọ náà.”

24 Ṣugbọn ọba dá a lóhùn pé, “Rárá o, n óo san owó rẹ̀ fún ọ, nítorí pé ohunkohun tí kò bá ní ná mi lówó, n kò ní fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun mi.” Dafidi bá ra ibi ìpakà ati àwọn akọ mààlúù náà, ní aadọta ṣekeli owó fadaka.

25 Ó kọ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. OLUWA gbọ́ adura rẹ̀ lórí ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ Israẹli.