Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 10

OLUWA Ṣèlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

1 Ẹ bèèrè òjò lọ́wọ́ OLUWA ní àkókò rẹ̀, àní lọ́wọ́ OLUWA tí ó dá ìṣúdẹ̀dẹ̀ òjò; Òun ló ń fún eniyan ní ọ̀wààrà òjò, tí àwọn ohun ọ̀gbìn fi ń tutù yọ̀yọ̀.

2 Ìsọkúsọ ni àwọn ère ń sọ, àwọn aríran ń ríran èké; àwọn tí ń lá àlá ń rọ́ àlá irọ́, wọ́n sì ń tu àwọn eniyan ninu lórí òfo. Nítorí náà ni àwọn eniyan fi ń rìn káàkiri bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.

3 OLUWA ní, “Inú mi ru sí àwọn olùṣọ́-aguntan, n óo sì fìyà jẹ àwọn alákòóso. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ń tọ́jú agbo mi, àní àwọn eniyan Juda, wọn yóo sì dàbí ẹṣin alágbára lójú ogun.

4 Ninu wọn ni a óo ti rí òkúta igun ilé, tí a lè pè ní olórí, aṣaaju, ati aláṣẹ, láti ṣe àkóso àwọn eniyan mi.

5 Gbogbo wọn óo jẹ́ akikanju lójú ogun, wọn óo tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro; wọn óo jagun, nítorí OLUWA wà pẹlu wọn, wọn óo sì dá àyà já àwọn tí wọn ń gun ẹṣin.

6 “N óo sọ ilé Juda di alágbára,

n óo sì gba ilé Josẹfu là.

N óo mú wọn pada,

nítorí àánú wọn ń ṣe mí,

wọn yóo dàbí ẹni pé n kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ rí;

nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn,

n óo sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ wọn.

7 Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára,

inú wọn yóo sì dùn

bí inú ẹni tí ó mu ọtí waini.

Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i,

inú wọn yóo dùn,

ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA.

8 “N óo ṣẹ́wọ́ sí wọn,

n óo sì kó wọn jọ sinu ilé.

Mo ti rà wọ́n pada,

nítorí náà wọn yóo tún pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn ká

sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,

sibẹsibẹ, wọn yóo ranti mi lọ́nà jíjìn tí wọ́n wà.

Àwọn ati àwọn ọmọ wọn yóo wà láàyè,

wọn yóo sì pada wá sí ilẹ̀ wọn.

10 N óo kó wọn pada sí ilẹ̀ wọn láti ilẹ̀ Ijipti wá,

n óo kó wọn jọ láti ilẹ̀ Asiria;

n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Lẹbanoni,

wọn óo kún ilẹ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ààyè mọ́.

11 Wọn óo la òkun Ijipti kọjá,

ìgbì rẹ̀ yóo sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.

Odò Naili yóo gbẹ kanlẹ̀,

a óo rẹ ìgbéraga ilẹ̀ Asiria sílẹ̀,

agbára óo sì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.

12 N óo sọ wọ́n di alágbára ninu èmi OLUWA,

wọn yóo sì máa ṣògo ninu orúkọ mi.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 11

Ìṣubú Àwọn Aninilára

1 Ṣílẹ̀kùn rẹ, ìwọ ilẹ̀ Lẹbanoni

kí iná lè jó àwọn igi kedari rẹ!

2 Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi Sipirẹsi,

nítorí igi kedari ti ṣubú,

àwọn igi ológo ti parun.

Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi oaku ní Baṣani,

nítorí pé, a ti gé àwọn igi igbó dídí Baṣani lulẹ̀!

3 Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran,

nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́.

Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù,

nítorí igbó tí wọn ń gbé

lẹ́bàá odò Jọdani ti parun!

Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Meji

4 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ọlọrun mi sọ; ó ní, “Fi ara rẹ sí ipò olùṣọ́-aguntan tí ó da àwọn ẹran rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n.

5 Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.”

6 OLUWA ní, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n kò ní ṣàánú àwọn eniyan ilẹ̀ yìí mọ́. Fúnra mi ni n óo fi wọ́n lé àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba wọn lọ́wọ́. Wọn óo run ilẹ̀ náà, n kò sì ní gba ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ wọn.”

7 Mo ti di darandaran agbo ẹran tí à ń dà lọ fún àwọn alápatà. Mo mú ọ̀pá meji, mo sọ ọ̀kan ní “Oore-ọ̀fẹ́,” mo sì sọ ekeji ní “Ìṣọ̀kan.”

8 Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan.

9 Mo wá sọ fún àwọn agbo ẹran náà pé, “N kò ní ṣe olùṣọ́ yín mọ́. Èyí tí yóo bá kú ninu yín kí ó kú, èyí tí yóo bá ṣègbé, kí ó ṣègbé, kí àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù sì máa pa ara wọn jẹ.”

10 Mo bá mú ọ̀pá mi tí ń jẹ́ “Oore-ọ̀fẹ́,” mo dá a, mo fi fi òpin sí majẹmu tí mo bá àwọn orílẹ̀-èdè dá.

11 Nítorí náà, majẹmu mi ti dópin lọ́jọ́ náà. Àwọn tí wọn ń ṣòwò aguntan, tí wọn ń wò mí, mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ṣe ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.

12 Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́ mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ máa mú un lọ.” Wọ́n bá wọn ọgbọ̀n owó fadaka fún mi gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ mi.

13 Nígbà náà ni OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ pa owó náà mọ́ sílé ìṣúra.” Nítorí náà, mo da ọgbọ̀n owó fadaka tí wọ́n san fún mi, sinu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA.

14 Nígbà náà ni mo dá ọ̀pá mi keji tí ń jẹ́ “Ìṣọ̀kan,” mo fi fi òpin sí àjọṣe tí ó wà láàrin Juda ati Israẹli.

15 OLUWA tún sọ fún mi pé “Tún fi ara rẹ sí ipò darandaran tí kò wúlò fún nǹkankan.

16 Wò ó! N óo gbé darandaran kan dìde tí kò ní bìkítà fún àwọn ẹran tí wọ́n ń ṣègbé, kò ní tọpa àwọn tí wọn ń ṣáko lọ, tabi kí ó wo àwọn tí ń ṣàìsàn sàn, tabi kí ó fún àwọn tí ara wọn le ní oúnjẹ. Dípò kí ó tọ́jú wọn, pípa ni yóo máa pa àwọn tí ó sanra jẹ, tí yóo sì máa fa pátákò wọn ya.

17 Olùṣọ́-aguntan mi tí kò bá níláárí gbé! Tí ó ń fi agbo ẹran sílẹ̀. Idà ni yóo ṣá a ní apá, yóo sì bá a ní ojú ọ̀tún, apá rẹ̀ óo rọ patapata, ojú ọ̀tún rẹ̀ óo sì fọ́ patapata.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 12

Ìlérí ìdáǹdè fún Jerusalẹmu

1 Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé,

2 “N óo ṣe ìlú Jerusalẹmu bí ife ọtí àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Wọn óo dojú kọ ilẹ̀ Juda, wọn óo sì dóti ìlú Jerusalẹmu.

3 Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, n óo mú kí ilẹ̀ Jerusalẹmu le kankan bí òkúta tí ó wúwo, orílẹ̀-èdè tí ó bá dábàá pé òun óo ṣí i nídìí, yóo farapa yánnayànna. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo sì parapọ̀ láti bá a jà.

4 Ní ọjọ́ náà, n óo dẹ́rùba àwọn ẹṣin, n óo sì fi wèrè kọlu àwọn tí wọn ń gùn wọ́n. Ṣugbọn n óo máa ṣọ́ àwọn ará Juda, n óo sì fọ́ ojú ẹṣin àwọn ọ̀tá wọn.

5 Àwọn ará Juda yóo wá máa sọ láàrin ara wọn pé, ‘OLUWA, àwọn ọmọ ogun ti sọ àwọn ará Jerusalẹmu di alágbára.’

6 “Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ́ kí àwọn ará Juda dàbí ìkòkò iná tí ń jó ninu igbó, àní, bí iná tí ń jó láàrin oko ọkà, wọn yóo jó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri, ṣugbọn Jerusalẹmu yóo wà láàyè rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

7 “OLUWA yóo kọ́kọ́ fún àwọn ogun Juda ní ìṣẹ́gun, kí ògo ilé Dafidi ati ògo àwọn ará Jerusalẹmu má baà ju ti Juda lọ.

8 Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo dáàbò bo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ẹni tí ó ṣe aláìlera jùlọ ninu wọn yóo lágbára bíi Dafidi. Ìdílé Dafidi yóo dàbí Ọlọrun, yóo máa darí wọn bí angẹli OLUWA.

9 Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá gbógun ti ìlú Jerusalẹmu.

10 “N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí.

11 Ní àkókò náà, ọ̀fọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu yóo pọ̀ bí ọ̀fọ̀ tí wọ́n ṣe fún Hadadi Rimoni ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido.

12 Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ náà yóo ṣọ̀fọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi yóo dá ọ̀fọ̀ tirẹ̀ ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Natani náà yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.

13 Ìdílé Lefi yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Ṣimei pàápàá yóo ṣọ̀fọ̀ tirẹ̀ lọ́tọ̀, àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà lọ́tọ̀;

14 gbogbo àwọn ìdílé yòókù ni wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn iyawo wọn náà yóo sì ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 13

1 OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.

2 “N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́.

3 Bí ẹnikẹ́ni bá pe ara rẹ̀ ní wolii, baba ati ìyá rẹ̀ tí ó bí i yóo wí fún un pé yóo kú, nítorí ó ń purọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, baba ati ìyá rẹ̀ yóo gún un pa.

4 Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ.

5 Ṣugbọn yóo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wolii, àgbẹ̀ ni mí; oko ni mò ń ro láti ìgbà èwe mi.’

6 Bí ẹnikẹ́ni bá bi í pé, ‘Àwọn ọgbẹ́ wo wá ni ti ẹ̀yìn rẹ?’ Yóo dáhùn pé, ‘Ọgbẹ́ tí mo gbà nílé àwọn ọ̀rẹ́ mi ni.’ ”

Àṣẹ pé kí Wọ́n Pa Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Ọlọrun

7 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké.

8 Jákèjádò ilẹ̀ náà, ìdá meji ninu mẹta àwọn eniyan náà ni wọn yóo kú, a óo sì dá ìdá kan yòókù sí.

9 N óo da ìdá kan yòókù yìí sinu iná, n óo fọ̀ wọ́n mọ́, bí a tíí fi iná fọ fadaka. N óo sì dán wọn wò, bí a tíí dán wúrà wò. Wọn yóo pe orúkọ mi, n óo sì dá wọn lóhùn. N óo wí pé, ‘Eniyan mi ni wọ́n’; àwọn náà yóo sì jẹ́wọ́ pé, ‘OLUWA ni Ọlọrun wa.’ ”

Categories
SAKARAYA

SAKARAYA 14

Jerusalẹmu ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè

1 Wò ó! Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀ tí wọn yóo pín àwọn ìkógun tí wọ́n kó ní ilẹ̀ Jerusalẹmu lójú yín.

2 Nítorí n óo kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Wọn yóo ṣẹgun rẹ̀, wọn yóo kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rù lọ, wọn yóo sì fi tipátipá bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀. Ìdajì àwọn ará ìlú náà yóo lọ sóko ẹrú, ṣugbọn ìdajì yòókù ninu wọn yóo wà láàrin ìlú.

3 OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun.

4 Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù.

5 Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀.

6 Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́,

7 kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.

8 Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn.

9 OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n.

10 A óo sọ gbogbo ilẹ̀ náà di pẹ̀tẹ́lẹ̀, láti Geba ní ìhà àríwá, títí dé Rimoni ní ìhà gúsù. Ṣugbọn Jerusalẹmu yóo yọ kedere láàrin àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, láti ẹnubodè Bẹnjamini, lọ dé ẹnubodè àtijọ́ ati dé ẹnubodè Igun, láti ilé-ìṣọ́ Hananeli dé ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí fún ọba.

11 Àwọn eniyan yóo máa gbé inú ìlú Jerusalẹmu, kò ní sí ègún mọ́, ìlú Jerusalẹmu yóo sì wà ní alaafia.

12 Àjàkálẹ̀ àrùn tí OLUWA yóo fi bá àwọn tí wọ́n bá gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu jà nìyí: Ẹran ara wọn yóo rà nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, ojú wọn yóo rà ninu ihò rẹ̀, ahọ́n wọn yóo sì rà lẹ́nu wọn.

13 Tó bá di ìgbà náà, OLUWA yóo mú ìbẹ̀rùbojo bá wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo fi máa pa ara wọn;

14 Àwọn ará Juda pàápàá yóo máa bá àwọn ará Jerusalẹmu jà. A óo kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká jọ: ati fadaka, ati wúrà, ati ọpọlọpọ aṣọ.

15 Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú náà yóo kọlu àwọn ẹṣin, ìbakasíẹ, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá wà ní ibùdó ogun wọn.

16 Àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu yóo máa wá lọdọọdun láti sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Jerusalẹmu ati láti ṣe Àjọ̀dún Àgọ́.

17 Bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò lọ sí ìlú Jerusalẹmu lọ sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, òjò kò ní rọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀.

18 Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí.

19 Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́.

20 Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ.

21 Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà.