Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 80

Fi Ojurere Wò Wá

1 Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli,

Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran.

Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́

2 níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase.

Sọ agbára rẹ jí,

kí o sì wá gbà wá là.

3 Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun;

fi ojurere wò wá,

kí á le gbà wá là.

4 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,

yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí adura

àwọn eniyan rẹ?

5 O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,

o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó.

6 O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;

àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn.

7 Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;

fi ojurere wò wá,

kí á lè là.

8 O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;

o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín.

9 O ro ilẹ̀ fún un;

ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀.

10 Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,

ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá;

11 àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun,

àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá.

12 Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀,

tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ

sì fi ń ká èso rẹ̀?

13 Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun,

gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́.

14 Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!

Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó;

kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí,

15 ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,

àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú.

16 Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀;

fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé!

17 Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú,

àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára.

18 Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ;

dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́!

19 Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!

Fi ojurere wò wá, kí á lè là!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 81

Orin fún Àkókò Àsè

1 Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa;

ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu.

2 Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire.

3 Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati ní

ọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè.

4 Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli,

ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu.

5 Ó pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Josẹfu,

nígbà tí ó kọlu ilẹ̀ Ijipti.

Mo gbọ́ ohùn kan tí n kò gbọ́ rí: tí ó wí pé,

6 “Mo ti sọ àjàgà náà kalẹ̀ lọ́rùn rẹ;

mo ti gba agbọ̀n ẹrù kúrò lọ́wọ́ rẹ.

7 Ninu ìnira, o ké pè mí, mo sì gbà ọ́;

mo dá ọ lóhùn ninu ìjì ààrá, níbi tí mo fara pamọ́ sí;

mo sì dán ọ wò ninu omi odò Meriba.

8 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá

ń kìlọ̀ fun yín,

àní kí ẹ fetí sílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

9 Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín;

ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan.

10 Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín,

tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

Ẹ ya ẹnu yín dáradára, n óo sì bọ yín ní àbọ́yó.

11 “Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,

Israẹli kò sì gba tèmi.

12 Nítorí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ sinu agídí ọkàn wọn,

kí wọn máa ṣe ohun tó wù wọ́n.

13 Àwọn eniyan mi ìbá jẹ́ gbọ́ tèmi,

àní Israẹli ìbá jẹ́ máa rìn ní ọ̀nà mi!

14 Kíákíá ni èmi ìbá kọjú ìjà sí àwọn ọ̀tá wọn,

tí ǹ bá sì ṣẹgun wọn.

15 Àwọn tí ó kórìíra OLUWA yóo fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba fún un,

ìyà óo sì jẹ wọ́n títí lae.

16 Ṣugbọn èmi ó máa fi ọkà tí ó dára jùlọ bọ yín,

n óo sì fi oyin inú àpáta tẹ yín lọ́rùn.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 82

Ọlọrun, Ọba Àwọn Ọba

1 Ọlọrun ti jókòó ní ààyè rẹ̀ ninu ìgbìmọ̀ ọ̀run;

ó sì ń ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run:

2 “Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́,

tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú?

3 Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba;

ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka.

4 Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀,

ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.”

5 Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye,

wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn,

títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì.

6 Mo ní, “oriṣa ni yín,

gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo.

7 Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan,

ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.”

8 Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé,

nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 83

Adura Ìṣẹ́gun

1 Ọlọrun, má dákẹ́;

má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́!

2 Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ;

àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ.

3 Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ;

wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́.

4 Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run;

kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!”

5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò;

wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.

6 Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli,

àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri,

7 àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki,

àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire.

8 Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn;

àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti.

9 Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani,

bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni,

10 àwọn tí o parun ní Endori,

tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀.

11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu;

ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna,

12 àwọn tí ó wí pé,

“Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrun

kí á sọ ọ́ di tiwa.”

13 Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé,

àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù.

14 Bí iná tíí jó igbó,

àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀,

15 bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn,

kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n.

16 Da ìtìjú bò wọ́n,

kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA.

17 Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae,

kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú.

18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan,

tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA,

ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 84

Ṣíṣàárò Ilé Ọlọrun

1 Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,

2 ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí,

àárò rẹ̀ ń sọ mí;

tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀

sí Ọlọrun alààyè.

3 Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé,

àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́

níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ,

àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun,

ọba mi, ati Ọlọrun mi.

4 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ,

wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae!

5 Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó fi ọ́ ṣe agbára wọn,

tí ìrìn àjò sí Sioni jẹ wọ́n lógún.

6 Bí wọ́n ti ń la àfonífojì Baka lọ,

wọ́n ń sọ ọ́ di orísun omi;

àkọ́rọ̀ òjò sì mú kí adágún omi kún ibẹ̀.

7 Wọn ó máa ní agbára kún agbára,

títí wọn ó fi farahàn níwájú Ọlọrun ní Sioni.

8 OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, gbọ́ adura mi;

tẹ́tí sílẹ̀, Ọlọrun Jakọbu!

9 Bojú wo àpáta wa, Ọlọrun,

fi ojú àánú wo ẹni àmì òróró rẹ.

10 Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ,

ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ.

Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun mi

ju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú.

11 Nítorí OLUWA Ọlọrun ni oòrùn ati ààbò wa,

òun níí ṣeni lóore, tíí dáni lọ́lá,

nítorí OLUWA kò ní rowọ́ láti fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ mọ́

ní ohun tí ó dára.

12 OLUWA àwọn ọmọ ogun,

ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 85

Adura Ire Orílẹ̀-Èdè

1 OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ;

o dá ire Jakọbu pada.

2 O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n;

o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

3 O mú ìrúnú rẹ kúrò;

o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró.

4 Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa;

dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró.

5 Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni?

Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni?

6 Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni,

kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ?

7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA;

kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

8 Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí,

nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀,

àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀,

ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀.

9 Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;

kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé;

òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn.

11 Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀;

òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run.

12 Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára;

ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ.

13 Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀,

yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 86

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi,

nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí.

2 Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí;

gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là;

ìwọ ni Ọlọrun mi.

3 Ṣàánú mi, OLUWA,

nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru.

4 Mú inú iranṣẹ rẹ dùn,

nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.

5 Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA,

o máa ń dárí jini;

ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

6 Fetí sí adura mi, OLUWA,

gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi.

7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́,

nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi.

8 OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa;

kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ.

9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá,

OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ:

wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo.

10 Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;

ìwọ nìkan ni Ọlọrun.

11 OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,

kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;

kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.

12 Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;

n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.

13 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;

o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú.

14 Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;

ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;

wọn kò sì bìkítà fún ọ.

15 Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;

o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.

16 Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;

fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;

kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là.

17 Fi àmì ojurere rẹ hàn mí,

kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i,

kí ojú sì tì wọ́n;

nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́,

tí o sì tù mí ninu.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 87

Ìyìn Sioni

1 Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà.

2 OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlú

yòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu.

3 Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ,

ìwọ ìlú Ọlọrun.

4 Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi,

n óo dárúkọ Ijiptiati Babiloni,

Filistia ati Tire, ati Etiopia.

Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.”

5 A óo wí nípa Sioni pé,

“Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,”

nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

6 OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọn

nígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,

“Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.”

7 Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé,

“Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 88

Adura nígbà ìpọ́njú

1 OLUWA, Ọlọrun, Olùgbàlà mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀sán;

mo ké níwájú rẹ ní òru.

2 Jẹ́ kí adura mi dé ọ̀dọ̀ rẹ;

tẹ́tí sí igbe mi.

3 Nítorí pé ọkàn mi kún fún ìyọnu;

mo sì súnmọ́ isà òkú.

4 Mo dàbí àwọn tí ó ń wọ ibojì lọ;

mo dà bí ẹni tí kò lágbára mọ.

5 N kò yàtọ̀ sí ẹni tí a pa tì sí apá kan láàrin àwọn òkú,

mo dàbí ẹni tí a pa, tí ó sùn ninu ibojì,

bí àwọn tí ìwọ kò ranti mọ́,

nítorí pé wọ́n ti kúrò lábẹ́ ìtọ́jú rẹ.

6 O ti fi mí sinu isà òkú tí ó jìn pupọ,

ninu òkùnkùn, àní ninu ọ̀gbun.

7 Ọwọ́ ibinu rẹ wúwo lára mi,

ìgbì ìrúnú rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.

8 O ti mú kí àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi fi mí sílẹ̀;

mo sì ti di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn:

mo wà ninu àhámọ́, n kò sì lè jáde;

9 ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìbànújẹ́.

Lojoojumọ ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA;

tí mò ń tẹ́wọ́ adura sí ọ.

10 Ṣé òkú ni o óo ṣe iṣẹ́ ìyanu hàn?

Ṣé àwọn òkú lè dìde kí wọ́n máa yìn ọ́?

11 Ṣé a lè sọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ninu ibojì?

Àbí ẹnìkan lè sọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ ninu ìparun?

12 Ṣé a lè rí iṣẹ́ ìyanu rẹ ninu òkùnkùn ikú?

Àbí ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ wà ní ilẹ̀ àwọn tí a ti gbàgbé?

13 Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́;

ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ.

14 OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù?

Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà,

tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú,

mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù;

agara sì ti dá mi.

16 Ìrúnú rẹ bò mí mọ́lẹ̀;

ẹ̀rù rẹ sì bà mí dójú ikú.

17 Wọ́n yí mi ká tọ̀sán-tòru bí ìṣàn omi ńlá;

wọ́n ká mi mọ́ patapata.

18 O ti mú kí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi ati àwọn alábàárìn mi kọ̀ mí sílẹ̀;

òkùnkùn nìkan ni ó yí mi ká níbi gbogbo.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 89

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi

1 OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae;

n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.

2 Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae;

o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run.

3 O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹlu

ẹni tí mo yàn,

mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé,

4 ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae,

n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

5 Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;

kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ.

6 Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?

Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?

7 Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,

o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?

8 OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?

OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.

9 Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;

nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.

10 Ìwọ ni o wó Rahabumọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;

o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.

11 Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;

ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.

12 Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,

òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀

yin orúkọ rẹ.

13 Alágbára ni ọ́;

agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;

o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.

14 Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;

ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ.

15 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,

àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,

16 àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,

tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ.

17 Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;

nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun.

18 Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa;

ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.

Ìlérí Ọlọrun fun Dafidi

19 Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé,

“Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí,

mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan.

20 Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi;

mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án;

21 kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae,

kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun.

22 Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba.

23 N óo run ọ̀tá rẹ̀ níwájú rẹ̀;

n óo sì bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ kanlẹ̀.

24 Òtítọ́ mi ati ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ yóo wà pẹlu rẹ̀;

orúkọ mi ni yóo sì máa fi ṣẹgun.

25 N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun;

agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate

26 Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,

Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’

27 N óo fi ṣe àkọ́bí,

àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.

28 N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae;

majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin.

29 Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae;

ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa bẹ níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.

30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀,

tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi,

31 bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi,

tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́;

32 n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn.

33 Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi.

34 N kò ni yẹ majẹmu mi,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada.

35 “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra:

n kò ní purọ́ fún Dafidi.

36 Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae,

ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ.

37 A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae,

yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.”

Ìdárò Ìṣubú Ọba

38 Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ;

o ti ta á nù,

o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

39 O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì,

o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀.

40 O ti wó gbogbo odi rẹ̀;

o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro.

41 Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù;

ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.

42 O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́;

o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́.

43 Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́,

o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun.

44 O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀;

o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀.

45 O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú;

o sì ti da ìtìjú bò ó.

Adura ìdáǹdè

46 Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi?

Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná?

47 OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ,

ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan!

48 Ta ló wà láyé tí kò ní kú?

Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú?

49 OLUWA, níbo ni ìfẹ́ rẹ ìgbàanì tí kì í yẹ̀ wà,

tí o búra fún Dafidi pẹlu òtítọ́ rẹ?

50 OLUWA, ranti bí èmi, iranṣẹ rẹ, ti di ẹni yẹ̀yẹ́;

ati bí mo ti ń farada ẹ̀gàn àwọn eniyan,

51 OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́,

wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀.

52 Ẹni ìyìn ni OLUWA títí lae!

Amin! Amin!