Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 70

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Ọlọrun, dákun, gbà mí,

yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

2 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mi

kí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn;

jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,

kí wọn sì tẹ́.

3 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bo

àwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi;

kí wọn sì gba èrè ìtìjú.

4 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ,

kí inú wọn sì máa dùn,

kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé,

“Ọlọrun tóbi!”

5 Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí,

yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun!

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi,

má pẹ́ OLÚWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 71

Adura Àgbàlagbà kan

1 OLUWA, ìwọ ni mo sá di;

má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae!

2 Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;

tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!

3 Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,

jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,

nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.

4 Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,

àwọn alaiṣootọ ati ìkà.

5 Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,

OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi.

6 Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;

ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.

Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.

7 Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,

ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8 Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,

ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru.

9 Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;

má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.

10 Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,

àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,

11 wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;

ẹ lé e, ẹ mú un;

nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”

12 Ọlọrun, má jìnnà sí mi;

yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!

13 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;

kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14 Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,

n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́.

15 N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,

n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,

nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn.

16 N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,

n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan.

17 Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,

títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,

18 Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,

Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,

títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,

àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.

19 Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,

ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,

Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ?

20 O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,

ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;

óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú.

21 O óo fi kún ọlá mi,

o óo sì tún tù mí ninu.

22 Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́,

nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi;

n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́,

ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.

23 N óo máa kígbe fún ayọ̀,

nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ;

ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀.

24 Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru,

nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,

a sì ti dójú tì wọ́n.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 72

Adura Ọba

1 Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́;

kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ.

2 Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ,

kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́;

3 kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia,

kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké.

4 Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ;

kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀;

kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú.

5 Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran,

níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ.

6 Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti gé

àní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀.

7 Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀;

kí alaafia ó gbilẹ̀ títí

tí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́.

8 Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun,

ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé.

9 Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un;

àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀.

10 Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogbo

yóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un;

àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá.

11 Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un;

gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín.

12 Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀;

a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,

ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

13 A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka,

a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀.

14 A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá,

ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.

15 Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn,

a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ,

a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo;

a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru.

16 Ọkà yóo pọ̀ lóko,

yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè;

èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni,

eniyan yóo pọ̀ ní ìlú,

bíi koríko ninu pápá.

17 Orúkọ ọba óo wà títí lae,

òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn;

àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn,

gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire.

18 Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli,

ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe.

19 Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí,

kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan!

Amin! Amin.

20 Níbi tí adura Dafidi ọmọ Jese parí sí nìyí.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 73

Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun

1 Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli,

ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.

2 Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú,

ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé.

3 Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga

nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

4 Wọn kì í jẹ ìrora kankan,

ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀.

5 Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;

ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn.

6 Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,

wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ.

7 Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;

èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀.

8 Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;

wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.

9 Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;

wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.

10 Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,

wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.

11 Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?

Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”

12 Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;

ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.

13 Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,

tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.

14 Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;

láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.

15 Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”

n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.

16 Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,

mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.

17 Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,

ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.

18 Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,

ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.

19 Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,

tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.

20 Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.

OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.

21 Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,

tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,

22 mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,

mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.

23 Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;

o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24 Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;

lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.

25 Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?

Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.

26 Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,

ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,

ati ìpín mi títí lae.

27 Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,

o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run.

28 Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;

mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,

kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 74

Ranti Wa, OLUWA

1 Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ta wá nù títí ayé?

Kí ló dé tí inú rẹ fi ń ru sí àwa aguntan pápá rẹ?

2 Ranti ìjọ eniyan rẹ tí o ti rà ní ìgbà àtijọ́,

àwọn ẹ̀yà tí o rà pada láti fi ṣe ogún tìrẹ;

ranti òkè Sioni níbi tí o ti ń gbé rí.

3 Rìn káàkiri kí o wo bí gbogbo ilẹ̀ ti di ahoro,

wo bí ọ̀tá ti ba gbogbo nǹkan jẹ́ ninu ibi mímọ́ rẹ.

4 Àwọn ọ̀tá rẹ bú ramúramù ninu ilé ìsìn rẹ;

wọ́n ta àsíá wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣẹ́gun.

5 Wọ́n dàbí ẹni tí ó gbé àáké sókè,

tí ó fi gé igi ìṣẹ́pẹ́.

6 Gbogbo pákó tí a fi dárà sí ara ògiri

ni wọ́n fi àáké ati òòlù fọ́.

7 Wọ́n jó ibi mímọ́ rẹ kanlẹ̀;

wọ́n sì ba ilé tí a ti ń pe orúkọ rẹ jẹ́.

8 Wọ́n pinnu lọ́kàn wọn pé, “A óo bá wọn kanlẹ̀ patapata.”

Wọ́n dáná sun gbogbo ilé ìsìn Ọlọrun tí ó wà ní ilẹ̀ náà.

9 A kò rí àsíá wa mọ́,

kò sí wolii mọ́;

kò sì sí ẹnìkan ninu wa tí ó mọ bí ìṣòro wa yóo ti pẹ́ tó.

10 Yóo ti pẹ́ tó, Ọlọrun, tí ọ̀tá yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀?

Ṣé títí ayé ni ọ̀tá yóo máa gan orúkọ rẹ ni?

11 Kí ló dé tí o ò ṣe nǹkankan?

Kí ló dé tí o káwọ́ gbera?

12 Ọlọrun, ìwọ ṣá ni ọba wa láti ìbẹ̀rẹ̀ wá;

ìwọ ni o máa ń gbà wá là láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè.

13 Ìwọ ni o fi agbára rẹ pín òkun níyà;

o fọ́ orí àwọn ẹranko ńlá inú omi.

14 Ìwọ ni o fọ́ orí Lefiatani túútúú;

o sì fi òkú rẹ̀ ṣe ìjẹ fún àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀.

15 Ìwọ ni o fọ́ àpáta tí omi tú jáde, tí odò sì ń ṣàn,

ìwọ ni o sọ odò tí ń ṣàn di ilẹ̀ gbígbẹ.

16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ náà sì ni òru,

ìwọ ni o gbé òṣùpá ati oòrùn ró.

17 Ìwọ ni o pa gbogbo ààlà ilẹ̀ ayé;

ìwọ ni o dá ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

18 OLUWA, ranti pé àwọn ọ̀tá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́;

àwọn òmùgọ̀ eniyan sì ń fi orúkọ rẹ ṣe ẹlẹ́yà.

19 Má fi ẹ̀mí àwa àdàbà rẹ lé àwọn ẹranko lọ́wọ́;

má sì gbàgbé àwa eniyan rẹ tí ìyà ń jẹ títí lae.

20 Ranti majẹmu rẹ;

nítorí pé gbogbo kọ̀rọ̀ ilẹ̀ wa kún fún ìwà ipá.

21 Má jẹ́ kí ojú ti àwọn tí à ń pọ́n lójú;

jẹ́ kí àwọn tí ìyà ń jẹ ati àwọn aláìní máa yin orúkọ rẹ.

22 Dìde Ọlọrun, gbèjà ara rẹ;

ranti bí àwọn òmùgọ̀ eniyan tí ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.

23 Má gbàgbé ariwo àwọn ọ̀tá rẹ;

àní, igbe àwọn tí ó gbógun tì ọ́, tí wọn ń ké láìdá ẹnu dúró.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 75

Ọlọrun Onídàájọ́

1 A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́.

À ń kéde orúkọ rẹ,

a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

2 OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,

n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú.

3 Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,

ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;

èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú.

4 Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;

èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’

5 Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,

ẹ má sì gbéraga.”

6 Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,

tabi láti ìwọ̀ oòrùn,

bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá.

7 Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:

á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga.

8 Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA,

Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀,

ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú,

yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀;

gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún,

wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.

9 Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae,

n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu.

10 Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò;

ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 76

Ọlọrun Ajàṣẹ́gun

1 Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun,

orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli.

2 Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu,

ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni.

3 Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò,

ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun.

4 Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀,

ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ.

5 A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju,

wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí;

àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà.

6 Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu,

ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin,

gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira.

7 Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́!

Ta ló tó dúró níwájú rẹ

tí ibinu rẹ bá dé?

8 Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́,

ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́;

9 nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀,

láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀.

10 Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ;

àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹ

yóo ṣe àjọ̀dún rẹ.

11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ,

kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá

fún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù.

12 Ẹni tí ń gba ẹ̀mí àwọn ìjòyè,

tí ó ń ṣe ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 77

Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú

1 Mo ké pe Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́,

mo kígbe pe Ọlọrun kí ó lè gbọ́ tèmi.

2 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA;

ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀,

ṣugbọn n kò rí ìtùnú.

3 Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;

mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.

4 OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òru

mo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀.

5 Mo ranti ìgbà àtijọ́,

mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

6 Mo ronú jinlẹ̀ lóru,

mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò.

7 Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;

àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́?

8 Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;

àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata?

9 Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;

àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé?

10 Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni pé

Ọ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”

11 N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,

àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì.

12 N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;

n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

13 Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;

oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa?

14 Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;

o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan.

15 O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là;

àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu.

16 Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun,

àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́,

ẹ̀rù bà á;

ibú omi sì wárìrì.

17 Ìkùukùu da omi òjò sílẹ̀,

ojú ọ̀run sán ààrá;

mànàmáná ń kọ yẹ̀rì káàkiri.

18 Ààrá ń sán kíkankíkan ní ojú ọ̀run,

mànàmáná ń kọ yànràn, gbogbo ayé sì mọ́lẹ̀;

ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì.

19 Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun,

ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já;

sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.

20 O kó àwọn eniyan rẹ jáde bí agbo ẹran,

o fi Mose ati Aaroni ṣe olórí wọn.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 78

Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ dẹtí sí ẹ̀kọ́ mi;

ẹ tẹ́tí si ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

2 N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe;

n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ,

3 ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,

ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa.

4 A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn;

a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn–

iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀,

ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe.

5 Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu;

ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.

Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa,

pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn.

6 Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n,

àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,

kí àwọn náà ní ìgbà tiwọn

lè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.

7 Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,

kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,

kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́,

8 kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn,

ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀,

àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin,

tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare.

9 Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà,

ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà.

10 Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́,

wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́.

11 Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,

ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n.

12 Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu,

ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani.

13 Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀;

ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá.

14 Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán,

ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru.

15 Ó la àpáta ni aṣálẹ̀,

ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú.

16 Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta;

ó sì mú kí ó ṣàn bí odò.

17 Sibẹsibẹ wọn ò dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá;

wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo ninu aṣálẹ̀.

18 Wọ́n dán Ọlọrun wò ninu ọkàn wọn,

wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóo tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn.

19 Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní,

“Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀?

20 Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde,

tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.

Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu,

àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?”

21 Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́,

inú bí i;

iná mọ́ ìdílé Jakọbu,

inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli;

22 nítorí pé wọn kò gba Ọlọrun gbọ́;

wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé agbára ìgbàlà rẹ̀.

23 Sibẹ ó pàṣẹ fún ìkùukùu lókè,

ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀.

24 Ó rọ òjò mana sílẹ̀

fún wọn láti jẹ,

ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run.

25 Ọmọ eniyan jẹ lára oúnjẹ àwọn angẹli;

Ọlọrun fún wọn ní oúnjẹ àjẹtẹ́rùn.

26 Ó mú kí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn fẹ́ ní ojú ọ̀run,

ó sì fi agbára rẹ̀ darí afẹ́fẹ́ ìhà gúsù;

27 ó sì rọ̀jò ẹran sílẹ̀ fún wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀;

àní, ẹyẹ abìyẹ́ bíi yanrìn etí òkun.

28 Ó mú kí wọn bọ́ sílẹ̀ láàrin ibùdó;

yíká gbogbo àgọ́ wọn,

29 Àwọn eniyan náà jẹ, wọ́n sì yó;

nítorí pé Ọlọrun fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.

30 Ṣugbọn kí wọn tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn,

àní, nígbà tí wọn ṣì ń jẹun lọ́wọ́.

31 Ọlọrun bínú sí wọn;

ó pa àwọn tí ó lágbára jùlọ ninu wọn,

ó sì lu àṣàyàn àwọn ọdọmọkunrin Israẹli pa.

32 Sibẹsibẹ wọ́n tún dẹ́ṣẹ̀;

pẹlu gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọn kò gbàgbọ́.

33 Nítorí náà ó mú kí ọjọ́ ayé wọn pòórá bí afẹ́fẹ́;

wọ́n sì lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìjayà.

34 Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a;

wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn.

35 Wọn á ranti pé Ọlọrun ni àpáta ààbò wọn,

ati pé Ọ̀gá Ògo ni olùràpadà wọn.

36 Ṣugbọn wọn kàn ń fi ẹnu wọn pọ́n ọn ni;

irọ́ ni wọ́n sì ń pa fún un.

37 Ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀;

wọn kò sì pa majẹmu rẹ̀ mọ́.

38 Sibẹ, nítorí pé aláàánú ni, ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,

kò sì pa wọ́n run;

ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,

tí kò sì fi gbogbo ara bínú sí wọn.

39 Ó ranti pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,

afẹ́fẹ́ lásán tí ń fẹ́ kọjá lọ, tí kò sì ní pada mọ́.

40 Ìgbà mélòó ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ninu ijù,

tí wọ́n sì bà á lọ́kàn jẹ́ ninu aṣálẹ̀!

41 Wọ́n dán an wò léraléra,

wọ́n sì mú Ẹni Mímọ́ Israẹli bínú.

42 Wọn kò ranti agbára rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ranti ọjọ́ tí ó rà wọ́n pada lọ́wọ́ ọ̀tá;

43 nígbà tí ó ṣe iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti,

tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní oko Soani.

44 Ó sọ omi odò wọn di ẹ̀jẹ̀,

tí wọn kò fi lè mu omi wọn.

45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin sí wọn tí ó jẹ wọ́n,

ati ọ̀pọ̀lọ́ tí ó pa wọ́n run.

46 Ó mú kí kòkòrò jẹ èso ilẹ̀ wọn;

eṣú sì jẹ ohun ọ̀gbìn wọn.

47 Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́;

ó sì fi òjò dídì run igi Sikamore wọn.

48 Ó fi yìnyín pa mààlúù wọn;

ó sì sán ààrá pa agbo aguntan wọn.

49 Ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ lé wọn lórí:

ìrúnú, ìkannú, ati ìpọ́njú,

wọ́n dàbí ikọ̀ ìparun.

50 Ó fi àyè gba ibinu rẹ̀;

kò dá ẹ̀mí wọn sí,

ó sì fi àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n.

51 O kọlu gbogbo àkọ́bí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,

àní, gbogbo àrẹ̀mọ ninu àgọ́ àwọn ọmọ Hamu.

52 Lẹ́yìn náà, ó kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde bí agbo ẹran

ó sì dà wọ́n láàrin aṣálẹ̀ bí agbo aguntan.

53 Ó dà wọ́n lọ láìléwu, ẹ̀rù kò bà wọ́n;

òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀.

54 Ó kó wọn wá sí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀,

sí orí òkè tí ó ti fi agbára rẹ̀ gbà.

55 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde kí wọn ó tó dé ibẹ̀;

ó pín ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn bí ohun ìní;

ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli jókòó ninu àgọ́ wọn.

56 Sibẹ, wọ́n dán Ọ̀gá Ògo wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i;

wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.

57 Wọ́n yipada, wọ́n sì hu ìwà ọ̀dàlẹ̀

bíi ti àwọn baba ńlá wọn;

wọn kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, wọ́n dàbí ọfà tí ó tẹ̀.

58 Wọ́n fi ojúbọ àwọn oriṣa wọn bí i ninu;

wọ́n sì fi ère wọn mú un jowú.

59 Nígbà tí Ọlọrun gbọ́, inú bí i gidigidi;

ó sì kọ Israẹli sílẹ̀ patapata.

60 Ó kọ ibùgbé rẹ̀ ní Ṣilo sílẹ̀,

àní, àgọ́ rẹ̀ láàrin ọmọ eniyan.

61 Ó jẹ́ kí á gbé àmì agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn;

ó sì fi ògo rẹ̀ lé ọ̀tá lọ́wọ́.

62 Ó jẹ́ kí á fi idà pa àwọn eniyan rẹ̀;

ó sì bínú gidigidi sí àwọn eniyan ìní rẹ̀.

63 Iná run àwọn ọdọmọkunrin wọn;

àwọn ọdọmọbinrin wọn kò sì rójú kọrin igbeyawo.

64 Àwọn alufaa kú ikú ogun;

àwọn opó wọn kò sì rójú sọkún.

65 Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun,

bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe.

66 Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn;

ó dójú tì wọ́n títí ayé.

67 Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀;

kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu;

68 ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda,

ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn.

69 Níbẹ̀ ni ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ tí ó ga bí ọ̀run sí,

ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí ayé títí lae.

70 Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀;

ó sì mú un láti inú agbo ẹran.

71 Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntan

tí ó lọ́mọ lẹ́yìn,

kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀,

àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀.

72 Ó tọ́jú wọn pẹlu òdodo,

ó sì tọ́ wọn pẹlu ìmọ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 79

Adura Ìdáǹdè Orílẹ̀-Èdè

1 Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ;

wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́;

wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro.

2 Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹ

fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ;

wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹ

fún àwọn ẹranko ìgbẹ́.

3 Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu;

kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin.

4 A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;

àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́;

wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín.

5 Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?

Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni?

Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná?

6 Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́,

ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́.

7 Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run;

wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro.

8 Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa;

yára, kí o ṣàánú wa,

nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata.

9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa,

nítorí iyì orúkọ rẹ;

gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,

nítorí orúkọ rẹ.

10 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé,

“Níbo ni Ọlọrun wọn wà?”

Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a pa

lára àwọn orílẹ̀-èdè!

11 Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ;

gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ,

dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí.

12 OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́,

san án fún wọn ní ìlọ́po meje,

13 Nígbà náà, àwa eniyan rẹ,

àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ,

yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae;

a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.