Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 40

Orin ìyìn

1 Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA,

ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi.

2 Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun,

láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀;

ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta,

ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀.

3 Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,

àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa.

Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,

wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

4 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà,

tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA,

tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn,

àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa.

5 OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa,

o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá.

Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ;

bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe,

kí n máa ròyìn wọn,

wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ.

6 O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,

ṣugbọn o là mí ní etí;

o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

7 Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;

a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:

8 mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;

mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”

9 Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.

Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,

gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀.

10 Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.

Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;

n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

ninu àwùjọ ńlá.

11 Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,

sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.

Adura Ìrànlọ́wọ́

12 Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,

ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,

tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.

Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,

ọkàn mi ti dàrú.

13 OLUWA, dákun gbà mi;

yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

14 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́

gba ẹ̀mí mi,

kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata,

jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,

kí wọ́n sì tẹ́.

15 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n,

kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú,

àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi.

16 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀,

kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ;

kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ

máa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!”

17 Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí;

ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi,

má pẹ́, Ọlọrun mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 41

Adura Ẹni tí ń Ṣàìsàn

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní:

OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú.

2 OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí.

Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà;

OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

3 Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn,

OLUWA yóo fún un lókun;

ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn.

4 Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn;

mo ti ṣẹ̀ ọ́.”

5 Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,

“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?”

6 Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò,

ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìí

ni yóo máa sọ;

bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà.

Nígbà tí ó bá jáde,

yóo máa rò mí kiri.

7 Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi

jọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi;

ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi.

8 Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀;

kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.”

9 Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé,

tí ó ń jẹun nílé mi,

ó ti kẹ̀yìn sí mí.

10 Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi;

gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un.

11 Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi,

nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi.

12 O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi,

o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae.

13 Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli,

lae ati laelae.

Amin! Amin!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 42

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 Bí ọkàn àgbọ̀nrín tií máa fà sí odò tí omi rẹ̀ tutù,

bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń fà sí ọ, Ọlọrun.

2 Òùngbẹ Ọlọrun ń gbẹ ọkàn mi,

àní, òùngbẹ Ọlọrun alààyè.

Nígbà wo ni n óo lọ, tí n óo tún bá Ọlọrun pàdé?

3 Omijé ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ tọ̀sán-tòru,

nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,

“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

4 Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti,

bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde:

bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn,

tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́

lọ sí ilé Ọlọrun;

pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́,

láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.

5 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?

Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?

Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín,

olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

6 Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,

nítorí náà mo ranti rẹ

láti òkè Herimoni,

ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani,

7 ìbànújẹ́ ń já lura wọn,

ìdààmú sì ń dà gììrì,

wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun.

8 Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn,

ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi,

àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi.

9 Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé,

“Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi?

Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri

nítorí ìnilára ọ̀tá?”

10 Bí ọgbẹ́ aṣekúpani

ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá mi rí lára mi,

nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé,

“Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?”

11 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì?

Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?

Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,

olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 43

Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú

1 Dá mi láre, Ọlọrun, kí o sì gbèjà mi,

lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ̀ Ọ́;

gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn ati alaiṣootọ.

2 Nítorí ìwọ ni Ọlọrun tí mo sá di.

Kí ló dé tí o fi ta mí nù?

Kí ló dé tí mo fi ń ṣọ̀fọ̀ kiri

nítorí ìnilára ọ̀tá?

3 Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati òtítọ́ rẹ jáde,

jẹ́ kí wọ́n máa tọ́ mi sọ́nà;

jẹ́ kí wọ́n mú mi wá sí orí òkè mímọ́ rẹ,

ati ibùgbé rẹ.

4 Nígbà náà ni n óo lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọrun,

àní, sọ́dọ̀ Ọlọrun, ayọ̀ ńlá mi.

Èmi óo sì yìn ọ́ pẹlu hapu,

Ọlọrun, Ọlọrun mi.

5 Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì?

Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi?

Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín,

olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 44

Adura Ààbò

1 Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́,

àwọn baba wa sì ti sọ fún wa,

nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,

àní, ní ayé àtijọ́:

2 Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn,

tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀;

o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà,

o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa.

3 Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,

kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun;

agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ati ojurere rẹ;

nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.

4 Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi;

ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun.

5 Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn,

orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀.

6 Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé;

idà mi kò sì le gbà mí.

7 Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,

o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa.

8 Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo;

a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae.

9 Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,

o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

10 O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;

àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.

11 O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,

o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.

12 O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,

o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn.

13 O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;

a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká.

14 O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.

15 Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,

ìtìjú sì ti bò mí.

16 Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,

lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san.

17 Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ.

18 Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ,

19 sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,

o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,

tabi tí a bá bọ oriṣa,

21 ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?

Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.

22 Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru,

tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà.

23 Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn?

Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae.

24 Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́?

Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa?

25 Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀;

àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́.

26 Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́!

Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 45

Orin Igbeyawo Ọmọ Ọba

1 Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn,

mò ń kọ orin mi fún ọba

ahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́.

2 Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin;

ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ,

nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé.

3 Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára,

ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ.

4 Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ,

máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́,

kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá.

5 Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn,

àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ.

6 Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae.

Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni.

7 O fẹ́ràn òdodo, o sì kórìíra ìwà ìkà

nítorí náà ni Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmì òróró yàn ọ́.

Àmì òróró ayọ̀ ni ó fi gbé ọ ga

ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ.

8 Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari,

láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́

ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá.

9 Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ,

ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára.

10 Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀,

gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ;

11 ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba;

òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un.

12 Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ,

àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ.

13 Yóo máa wá ojurere rẹ,

pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀.

Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀,

14 ó wọ aṣọ aláràbarà, a mú un lọ sọ́dọ̀ ọba,

pẹlu àwọn wundia ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ń sìn ín lọ.

15 Pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn ni a fi ń mú wọn lọ,

bí wọ́n ṣe ń wọ ààfin ọba.

16 Àwọn ọmọkunrin rẹ ni yóo rọ́pò àwọn baba rẹ;

o óo fi wọ́n jọba káàkiri gbogbo ayé.

17 N óo mú kí á máa ki oríkì rẹ láti ìran dé ìran;

nítorí náà àwọn eniyan yóo máa yìn ọ́ lae ati laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 46

Ọlọrun Wà pẹlu Wa

1 Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa,

olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú.

2 Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí,

bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun;

3 bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru,

tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtì

nítorí agbára ríru rẹ̀.

4 Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn,

ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo.

5 Ọlọrun wà láàrin rẹ̀,

kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò;

Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu.

6 Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru,

àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n;

OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́.

7 OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa;

Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.

8 Ẹ wá wo iṣẹ́ OLUWA,

irú iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe láyé.

9 Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé,

ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀,

ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun.

10 “Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun.

A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

a gbé mi ga ní ayé.”

11 OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa,

Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 47

Ọba Àwọn Ọba

1 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;

ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun.

2 Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo,

Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.

3 Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa,

ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa.

4 Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa,

èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn.

5 A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀,

a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè.

6 Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn;

Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn!

7 Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé;

Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn!

8 Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;

Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.

9 Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ

pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu.

Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé;

òun ni ọlọ́lá jùlọ!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 48

OLUWA Tóbi

1 OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ

ní ìlú Ọlọrun wa.

2 Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà,

ni ayọ̀ gbogbo ayé.

Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré,

ìlú ọba ńlá.

3 Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi.

4 Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ;

wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í.

5 Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n,

ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá;

6 ìwárìrì mú wọn níbẹ̀;

ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí.

7 Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi.

8 Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí,

ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun,

ní ìlú Ọlọrun wa:

Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

9 Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,

à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

10 Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,

bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,

iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.

11 Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,

kí gbogbo Juda sì máa yọ̀

nítorí ìdájọ́ rẹ.

12 Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká;

ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀;

13 ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀;

ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ,

kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀

14 pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa,

lae ati laelae.

Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 49

Ìwà Òmùgọ̀ ni Igbẹkẹle Ọrọ̀

1 Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè!

Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé,

2 ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá,

àtolówó ati talaka!

3 Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;

àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye.

4 N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;

n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀.

5 Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,

nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,

6 àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,

tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ?

7 Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada,

tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun;

8 nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ.

Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀,

9 tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae,

kí ó má fojú ba ikú.

10 Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n,

òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run;

wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.

11 Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae,

ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé,

wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn.

12 Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé,

bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú.

13 Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí,

òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn.

14 Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn,

ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn;

ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà.

Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́,

Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀,

ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn.

15 Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikú

nítorí pé yóo gbà mí.

16 Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó,

tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i.

17 Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú,

kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ;

dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì.

18 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè,

ó rò pé Ọlọrun bukun òun,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyan

nígbà tí nǹkan bá ń dára fún un,

19 yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú,

kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́.

20 Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé;

bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku.