Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 20

Adura Ìṣẹ́gun

1 OLUWA óo dá ọ lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú,

orúkọ Ọlọrun Jakọbu óo dáàbò bò ọ́.

2 Yóo rán olùrànlọ́wọ́ sí ọ láti ilé mímọ́ rẹ̀ wá,

yóo sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.

3 Yóo ranti gbogbo ẹbọ ọrẹ rẹ,

yóo sì gba ẹbọ sísun rẹ.

4 Yóo fún ọ ní ohun tí o fẹ́ ninu ọkàn rẹ,

yóo sì mú gbogbo èrò rẹ ṣẹ.

5 Ìhó ayọ̀ ni a óo hó nígbà tí o bá ṣẹgun,

ní orúkọ Ọlọrun wa ni a óo sì fi ọ̀págun wa sọlẹ̀;

OLUWA yóo dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ.

6 Mo wá mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo ran ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ́wọ́;

OLUWA yóo dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá

yóo sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fún un ní ìṣẹ́gun ńlá.

7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun,

àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin,

ṣugbọn ní tiwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa.

8 Àwọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú,

ṣugbọn àwa óo dìde, a óo sì dúró ṣinṣin.

9 Fún ọba ní ìṣẹ́gun, OLUWA;

kí o sì dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń ké pè ọ́.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 21

Orin Ìṣẹ́gun

1 Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA;

inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́!

2 O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́,

o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú.

3 O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀;

o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí.

4 Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un,

àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé.

5 Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́;

o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀.

6 Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae;

o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀.

7 Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA;

a kò ní ṣí i ní ipò pada,

nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀.

8 Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;

ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ.

9 O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn.

OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀;

iná yóo sì jó wọn ní àjórun.

10 O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé,

o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan.

11 Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ,

tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é.

12 Nítorí pé o óo lé wọn sá;

nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn.

13 A gbé ọ ga, nítorí agbára rẹ, OLUWA!

A óo máa kọrin, a óo sì máa yin agbára rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 22

Igbe Ìrora ati Orin Ìyìn

1 Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀,

tí o fi jìnnà sí mi, tí o kò gbọ́ igbe mi,

kí o sì ràn mí lọ́wọ́?

2 Ọlọrun mi, mo kígbe pè ọ́ lọ́sàn-án,

ṣugbọn o ò dáhùn;

mo kígbe lóru, n ò sì dákẹ́.

3 Sibẹ Ẹni Mímọ́ ni ọ́,

o gúnwà, Israẹli sì ń yìn ọ́.

4 Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀lé;

wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ, o sì gbà wọ́n.

5 Wọ́n kígbe pè ọ́, o sì gbà wọ́n;

ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, ojú kò sì tì wọ́n.

6 Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan;

ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

7 Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;

wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi;

wọ́n sì ń mi orí pé,

8 “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́;

kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là,

ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!”

9 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi;

ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú.

10 Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́;

ìwọ ni Ọlọrun mi

láti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi.

11 Má jìnnà sí mi,

nítorí pé ìyọnu wà nítòsí,

kò sì sí ẹni tí yóo ràn mí lọ́wọ́.

12 Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù,

wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára.

13 Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun,

bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù.

14 Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi,

gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé;

ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́.

15 Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì,

ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu;

o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú.

16 Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá;

àwọn aṣebi dòòyì ká mi;

wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya.

17 Mo lè ka gbogbo egungun mi

wọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí.

18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,

wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.

19 Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi!

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́!

20 Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà,

gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá!

21 Já mi gbà kúrò lẹ́nu kinniun nnì

gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwo ẹhànnà mààlúù!

22 N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi;

láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́:

23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ máa yìn ín!

Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ fi ògo fún un,

ẹ dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ níwájú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

24 Nítorí pé kò fi ojú pa ìjìyà àwọn tí à ń jẹ níyà rẹ́;

kò sì ṣá wọn tì,

bẹ́ẹ̀ ni kò fi ojú pamọ́ fún wọn,

ṣugbọn ó gbọ́ nígbà tí wọ́n ké pè é.

25 Ìwọ ni n óo máa yìn láàrin àwùjọ àwọn eniyan;

n óo san ẹ̀jẹ́ mi láàrin àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA.

26 Àwọn tí ojú ń pọ́n yóo jẹ àjẹyó;

àwọn tí ń wá OLUWA yóo yìn ín!

Kí ẹ̀mí wọn ó gùn!

27 Gbogbo ayé ni yóo ranti OLUWA

wọn yóo sì pada sọ́dọ̀ rẹ̀;

gbogbo ẹ̀yà àwọn orílẹ̀-èdè

ni yóo sì júbà níwájú rẹ̀.

28 Nítorí OLUWA ló ni ìjọba,

òun ní ń jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

29 Gbogbo àwọn agbéraga láyé ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀;

gbogbo ẹni tí yóo fi ilẹ̀ bora bí aṣọ

ni yóo wólẹ̀ níwájú rẹ̀,

àní, gbogbo àwọn tí kò lè dá sọ ara wọn di alààyè.

30 Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín;

àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀.

31 Wọn óo máa kéde ìgbàlà rẹ̀ fún àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,

pé, “OLUWA ló ṣe é.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 23

OLUWA ni Olùṣọ́ Mi

1 OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi,

n kò ní ṣe àìní ohunkohun.

2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù,

ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́;

3 ó sọ agbára mi dọ̀tun.

Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodo

nítorí orúkọ rẹ̀.

4 Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú,

n kò ní bẹ̀rù ibi kankan;

nítorí tí o wà pẹlu mi;

ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.

5 O gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú mi,

níṣojú àwọn ọ̀tá mi;

o da òróró sí mi lórí;

o sì bu ife mi kún ní àkúnwọ́sílẹ̀.

6 Dájúdájú, ire ati àánú yóo máa tẹ̀lé mi kiri,

ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;

èmi óo sì máa gbé inú ilé OLUWA laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 24

Ọba Atóbijù

1 OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà

ninu rẹ̀,

òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí

ń gbé inú rẹ̀;

2 nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun,

ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi.

3 Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ?

Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀?

4 Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun,

tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn,

tí kò sì búra èké.

5 Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA,

tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀.

6 Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA,

àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu.

7 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,

ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,

kí Ọba ògo lè wọlé.

8 Ta ni Ọba ògo yìí?

OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára,

OLUWA tí ó lágbára lógun.

9 Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,

ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,

kí Ọba ògo lè wọlé.

10 Ta ni Ọba ògo yìí?

OLUWA àwọn ọmọ ogun,

òun ni Ọba ògo náà.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 25

Adura fún ìtọ́sọ́nà ati Ààbò

1 OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí.

2 Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé,

má jẹ́ kí ojú ó tì mí;

má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí.

3 OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ;

àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì.

4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA,

kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ.

5 Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi,

nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi;

ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo.

6 OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́.

7 Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi,

tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi;

ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

ati nítorí oore rẹ.

8 Olóore ati olódodo ni OLÚWA,

nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

9 A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́,

a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀.

10 Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́,

fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́.

11 Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí,

nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ.

12 Ẹni tí ó bá bẹ̀rù OLUWA

ni OLUWA yóo kọ́ ní ọ̀nà tí yóo yàn.

13 Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀,

àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà.

14 Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́,

a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n.

15 OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo,

nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n.

16 Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi;

nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi.

17 Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò;

kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi.

18 Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi,

kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.

19 Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní,

ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi.

20 Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí;

má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí,

nítorí ìwọ ni mo sá di.

21 Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́,

nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.

22 Ọlọrun, ra Israẹli pada,

kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 26

Adura Ẹni Rere

1 Dá mi láre, OLUWA,

nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn,

mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì.

2 Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò;

yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi.

3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́,

mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn.

4 N kò jókòó ti àwọn èké,

n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn;

5 mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi,

n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀.

6 Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA,

mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.

7 Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè,

mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ.

8 OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé,

ati ibi tí ògo rẹ wà.

9 Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,

má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn,

10 àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún iṣẹ́ ibi,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

11 Ṣugbọn ní tèmi, èmi ń rìn ninu ìwà pípé;

rà mí pada, kí o sì ṣàánú mi.

12 Mo dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;

láwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan ni n óo máa yin OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 27

Adura Ìyìn

1 OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi;

ta ni n óo bẹ̀rù?

OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi,

ẹ̀rù ta ni yóo bà mí?

2 Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi,

tí wọ́n fẹ́ pa mí,

àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi,

wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú.

3 Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí

àyà mi kò ní já.

Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi,

sibẹ, ọkàn mi kò ní mì.

4 Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA,

òun ni n óo sì máa lépa:

Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA

ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,

kí n lè máa wo ẹwà OLUWA,

kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀.

5 Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé,

yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀,

lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí;

yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta.

6 Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun

lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká;

n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀,

n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.

7 Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́;

ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn.

8 Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.”

Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA,

9 má fi ojú pamọ́ fún mi!”

Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò,

ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́,

má ta mí nù, má sì ṣá mi tì,

Ọlọrun ìgbàlà mi.

10 Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀,

OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí.

11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA,

kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ,

nítorí àwọn ọ̀tá mi.

12 Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́;

nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi,

ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà.

13 Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbà

ní ilẹ̀ alààyè.

14 Dúró de OLUWA,

ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí,

àní, dúró de OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 28

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,

ìwọ ni ààbò mi, má di etí sí mi.

Nítorí bí o bá dákẹ́ sí mi

n óo dàbí àwọn òkú, tí wọ́n ti lọ sinu kòtò.

2 Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi,

bí mo ti ń kígbe sí ọ pé kí o ràn mí lọ́wọ́;

tí mo gbé ọwọ́ mi sókè

sí ìhà ilé mímọ́ rẹ.

3 Má ṣe kó mi lọ pẹlu àwọn eniyan burúkú,

pẹlu àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,

àwọn tí ń bá àwọn aládùúgbò wọn

sọ ọ̀rọ̀ alaafia,

ṣugbọn tí ètekéte ń bẹ ninu ọkàn wọn.

4 San án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,

àní gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ burúkú wọn;

san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn,

fún wọn ní èrè tí ó tọ́ sí wọn.

5 Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí,

wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,

OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀,

kò sì ní gbé wọn dìde mọ́.

6 Ẹni ìyìn ni OLUWA!

Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7 OLUWA ni agbára ati asà mi,

òun ni mo gbẹ́kẹ̀lé;

ó ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀;

mo sì fi orin ìyìn dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

8 OLUWA ni agbára àwọn eniyan rẹ̀;

òun ni ààbò ìgbàlà fún ẹni àmì òróró rẹ̀.

9 Gba àwọn eniyan rẹ là, OLUWA,

kí o sì bukun ilẹ̀ ìní rẹ.

Jẹ́ olùṣọ́-aguntan wọn,

kí o sì máa tọ́jú wọn títí lae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 29

Agbára OLUWA ninu ìjì

1 Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA,

ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ.

2 Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀,

ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀.

3 À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun,

Ọlọrun ológo ń sán ààrá,

Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi.

4 Ohùn OLUWA lágbára,

ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá.

5 Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari,

OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni.

6 Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù,

ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó.

7 Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá.

8 Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀;

OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi.

9 Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí,

a máa wọ́ ewé lára igi oko;

gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀.

10 OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi;

OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae.

11 OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára;

OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia.