Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 10

Adura Olùpọ́njú

1 Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA,

tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

2 Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní;

jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ.

3 Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀,

Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA.

4 Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀,

kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀.

5 Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un.

Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ;

ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.

6 Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú,

ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro.

7 Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀;

ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

8 Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé,

níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀;

ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa.

9 Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba;

ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀;

ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ.

10 Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba,

ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú.

11 Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé,

OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.”

12 Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i;

má sì gbàgbé àwọn tí a nilára.

13 Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun,

tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?”

14 Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan,

nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà,

kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san;

nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé,

ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba.

15 Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá,

tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀,

má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin.

16 OLUWA ni ọba lae ati laelae.

Àwọn orílẹ̀-èdè yóo pòórá lórí ilẹ̀ rẹ.

17 OLUWA, o óo gbọ́ igbe àwọn tí a nilára;

o óo mú wọn lọ́kàn le,

o óo sì dẹ etí sílẹ̀ sí igbe wọn

18 kí o lè ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn aláìníbaba

ati àwọn ẹni tí à ń pọ́n lójú,

kí ọmọ eniyan, erùpẹ̀ lásánlàsàn, má lè dẹ́rù bani mọ́.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 11

OLUWA ni Igbẹkẹle Àwọn Olódodo

1 OLUWA ni mo sá di;

ẹ ṣe lè wí fún mi pé,

“Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ;

2 ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà;

wọ́n fa ọrun;

wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà.

3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́,

kí ni olódodo lè ṣe?”

4 OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀,

ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run;

OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan,

ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò.

5 OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò,

ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá.

6 Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú;

ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn.

7 Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo;

àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 12

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́;

àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan.

2 Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀;

ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ.

3 Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu,

4 àwọn tí ń wí pé,

“Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun,

àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?”

5 OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀,

ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú,

n óo dìde nisinsinyii,

n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.”

6 Ìlérí tó dájú ni ìlérí OLUWA,

ó dàbí fadaka tí a yọ́ ninu iná ìléru amọ̀,

tí a dà ninu iná nígbà meje.

7 Dáàbò bò wá, OLUWA, pa wá mọ́ laelae

kúrò lọ́wọ́ irú àwọn eniyan báwọ̀nyí.

8 Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri,

níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 13

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?

Ṣé o óo wá gbàgbé mi laelae ni?

Títí di ìgbà wo ni o óo fi ojú pamọ́ fún mi?

2 Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́

tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà?

Títí di ìgbà wo ni àwọn ọ̀tá mi yóo máa yọ̀ mí?

3 Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi.

Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú.

4 Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.”

Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú.

5 Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;

n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí.

6 N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA,

nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 14

Èrè Òmùgọ̀

1 Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò sí.”

Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn,

kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.

2 OLUWA bojú wo ilẹ̀, láti ọ̀run wá,

ó wo àwọn ọmọ eniyan,

láti mọ̀ bí àwọn kan bá wà tí wọ́n gbọ́n,

tí wọn ń wá Ọlọrun.

3 Gbogbo wọn ti ṣìnà,

gbogbo wọn pátá ni wọ́n sì ti bàjẹ́;

kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,

kò sí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.

4 Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?

Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,

àwọn tí kì í ké pe OLUWA.

5 Níbẹ̀ ni a óo ti dẹ́rù bà wọ́n gidigidi,

nítorí Ọlọrun ń bẹ pẹlu àwọn olódodo.

6 Ẹ̀yin ń fẹ́ da ètò aláìní rú,

ṣugbọn OLUWA ni ààbò rẹ̀.

7 Ìbá ti dára tó kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!

Nígbà tí OLUWA bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,

Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 15

Ìwà tí Ọlọrun Fẹ́

1 OLUWA, ta ni ó lè máa gbé inú àgọ́ rẹ?

Ta ni ó lè máa gbé orí òkè mímọ́ rẹ?

2 Ẹni tí ń rìn déédéé, tí ń ṣe òdodo;

tí sì ń fi tọkàntọkàn sọ òtítọ́.

3 Ẹni tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn,

tí kò ṣe ibi sí ẹnìkejì rẹ̀,

tí kò sì sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa aládùúgbò rẹ̀.

4 Ẹni tí kò ka ẹni ẹ̀kọ̀ sí,

ṣugbọn a máa bu ọlá fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA;

bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, kì í yẹ̀ ẹ́;

bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti wù kí ó nira tó.

5 Kì í yáni lówó kí ó gba èlé,

kìí sìí gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ aláìṣẹ̀.

Ẹni tí ó bá ṣe nǹkan wọnyi,

ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní yẹ̀ laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 16

Mo Sá di OLUWA

1 Pa mí mọ́ Ọlọrun, nítorí ìwọ ni mo sá di.

2 Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi;

ìwọ nìkan ni orísun ire mi.”

3 Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí,

wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn.

4 “Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀:

Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ,

bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.”

5 OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn;

ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀.

6 Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ;

ogún rere ni ogún ti mo jẹ.

7 Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye;

ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru.

8 Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo,

nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀.

9 Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn;

ara sì rọ̀ mí.

10 Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú,

bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́.

11 O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí;

ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ,

ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 17

Adura fún Ìdáláre

1 Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi;

fi ìtara gbọ́ igbe mi.

Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi.

2 Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá;

kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́.

3 Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru.

Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan;

n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀.

4 Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan,

mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá.

5 Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà;

ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀.

6 Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn,

dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu,

fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ

kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n.

8 Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú,

dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ;

9 lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí,

àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

10 Ojú àánú wọn ti fọ́,

ọ̀rọ̀ ìgbéraga sì ń ti ẹnu wọn jáde.

11 Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí;

wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú.

12 Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ,

àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba.

13 Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀;

fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.

14 OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi;

àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí,

fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́;

jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó;

sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ.

15 Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi,

ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 18

Orin Ìṣẹ́gun

1 Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi.

2 OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi;

Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà.

Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi.

3 Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,

ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

4 Ikú wé mọ́ mi bí okùn,

ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi.

5 Isà òkú yí mi ká,

tàkúté ikú sì dojú kọ mí.

6 Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA,

Ọlọrun mi ni mo ké pè.

Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀,

ó sì tẹ́tí sí igbe mi.

7 Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,

ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì;

wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú.

8 Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀,

iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀;

ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.

9 Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá,

ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

10 Ó gun orí Kerubu, ó sì fò,

ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.

11 Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ,

ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi

ni ó fi ṣe ìbòrí.

12 Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ,

ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde,

láti inú ìkùukùu.

13 OLUWA sán ààrá láti ọ̀run,

Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde.

14 Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká,

ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká.

15 Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete,

ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA,

ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ.

16 Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú,

ó fà mí jáde láti inú ibú omi.

17 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára,

ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi;

nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.

18 Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi,

ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi.

19 Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè,

ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi.

20 OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,

bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè.

21 Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́,

n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.

22 Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé,

n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀.

23 Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀,

mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀.

24 Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;

ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀.

25 Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́,

ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé;

26 mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́,

ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ.

27 Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là,

ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.

28 Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn,

OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.

29 Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun,

àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú.

30 Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé,

pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA;

òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í.

31 Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA?

Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa?

32 Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí,

tí ó sì mú ọ̀nà mi pé.

33 Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín,

ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí.

34 Ó kọ́ mi ní ogun jíjà

tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ.

35 O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ,

ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró,

ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá.

36 O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi,

n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́.

37 Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n,

n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run.

38 Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde,

wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi.

39 O gbé agbára ogun wọ̀ mí;

o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.

40 O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi,

mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.

41 Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!”

Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n,

wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

42 Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ,

mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù.

43 O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan,

o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè;

àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí.

44 Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu;

àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi.

45 Àyà pá àwọn àlejò,

wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí.

46 OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi!

Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi!

47 Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi,

tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi;

48 Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;

tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ;

ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi.

49 Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA,

èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.

50 Ó fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,

ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ han ẹni àmì òróró rẹ̀,

àní Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 19

Ògo Ọlọrun ninu àwọn ohun tí Ó dá

1 Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun,

òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

2 Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà

òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn.

3 Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀;

bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn;

4 sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já,

ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé.

Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run,

5 tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀,

ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje.

6 Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá,

a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji;

kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀.

Òfin OLUWA

7 Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí;

àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8 Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀,

àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú.

9 Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae,

ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn.

10 Wọ́n wuni ju wúrà lọ,

àní ju ojúlówó wúrà lọ;

wọ́n sì dùn ju oyin,

àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ.

11 Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀,

èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́.

12 Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀?

Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi.

13 Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá;

má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi.

Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́,

n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi

jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,

OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.