Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 140

Adura Ààbò

1 OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi;

dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá;

2 àwọn tí ó ń pète ibi lọ́kàn wọn,

tí wọ́n sì ń dá ogun sílẹ̀ nígbàkúùgbà,

3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn, ó mú bí ahọ́n ejò;

oró paramọ́lẹ̀ sì ń bẹ ninu eyín wọn.

4 OLUWA, ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú;

dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,

tí ó ń gbìmọ̀ láti ré mi lẹ́pa.

5 Àwọn agbéraga ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,

wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;

wọ́n sì dẹ okùn sílẹ̀ fún mi lẹ́bàá ọ̀nà.

6 Mo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”

OLUWA, tẹ́tí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7 OLUWA, OLUWA mi, alágbára tíí gbani là,

ìwọ ni o dáàbò bò mí ní ọjọ́ ogun.

8 OLUWA, má jẹ́ kí ọwọ́ àwọn eniyan burúkú tẹ ohun tí wọn ń wá;

má jẹ́ kí èrò ọkàn wọn ṣẹ.

9 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ibi ẹnu àwọn tí ó yí mi ká

dà lé wọn lórí.

10 Jẹ́ kí ẹ̀yinná dà lé wọn lórí;

jẹ́ kí wọn já sí kòtò, kí wọn má lè yọ.

11 Má jẹ́ kí abanijẹ́ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ilẹ̀ náà;

jẹ́ kí oníwà ipá ko àgbákò kíákíá.

12 Mo mọ̀ pé OLUWA yóo gba ọ̀ràn olùpọ́njú rò,

yóo sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.

13 Dájúdájú, àwọn olódodo yóo máa fi ọpẹ́ fún ọ;

àwọn olóòótọ́ yóo sì máa gbé níwájú rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 141

Adura Ààbò

1 OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn,

tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.

2 Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,

sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́.

3 OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,

sì ṣe aṣọ́nà ètè mi.

4 Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.

Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,

má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn.

5 N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí,

n ò kọ̀ kí ó nà mí;

kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí.

Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí,

nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn.

6 Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n,

wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA.

7 Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀,

ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì.

8 Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun.

Ìwọ ni asà mi,

má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò.

9 Pa mí mọ́ ninu ewu tàkúté,

ati ti okùn tí àwọn aṣebi dẹ sílẹ̀ dè mí.

10 Jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú ṣubú sinu àwọ̀n ara wọn,

kí èmi sì lọ láìfarapa.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 142

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 Mo ké pe OLUWA,

mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i.

2 Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀,

mo sọ ìṣòro mi fún un.

3 Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì,

ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà.

Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi

ní ọ̀nà tí mò ń rìn.

4 Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká,

mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi;

kò sí ààbò fún mi,

ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi.

5 Mo ké pè ọ́, OLUWA,

mo ní, “Ìwọ ni ààbò mi,

ìwọ ni ìpín mi lórí ilẹ̀ alààyè.”

6 Gbọ́ igbe mi;

nítorí wọ́n ti rẹ̀ mí sílẹ̀ patapata.

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi,

nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

7 Yọ mí kúrò ninu ìhámọ́,

kí n lè yin orúkọ rẹ lógo.

Àwọn olódodo yóo yí mi ká,

nítorí ọpọlọpọ oore tí o óo ṣe fún mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 143

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, gbọ́ adura mi;

fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi!

Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.

2 Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́,

nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ.

3 Ọ̀tá ti lé mi bá,

ó ti lù mí bolẹ̀;

ó jù mí sinu òkùnkùn,

bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.

4 Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì;

ọkàn mi sì pòrúúruù.

5 Mo ranti ìgbà àtijọ́,

mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe,

mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

6 Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́;

bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ,

bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.

7 OLUWA, yára dá mi lóhùn!

Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin!

Má fara pamọ́ fún mi,

kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú.

8 Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀,

nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.

Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn,

nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí.

9 OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;

ìwọ ni mo sá di.

10 Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,

nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi.

Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́.

11 Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí;

ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú.

12 Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi,

kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run,

nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 144

Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1 Ìyìn ni fún OLUWA, àpáta mi,

ẹni tí ó kọ́ mi ní ìjà jíjà,

tí ó kọ́ mi ní iṣẹ́ ogun.

2 Òun ni àpáta mi, ààbò mi, odi mi, olùdáǹdè mi,

asà mi, ẹni tí mo sá di.

Òun ni ó tẹrí àwọn eniyan ba lábẹ́ rẹ̀.

3 OLUWA, kí ni eniyan jẹ́, tí o fi ń náání rẹ̀?

Kí sì ni ọmọ eniyan tí o fi ń ranti rẹ̀?

4 Eniyan dàbí èémí,

ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí òjìji tí ń kọjá lọ.

5 OLUWA, fa ojú ọ̀run wá sílẹ̀, kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,

fọwọ́ kan àwọn òkè ńlá, kí wọ́n máa rú èéfín.

6 Jẹ́ kí mànàmáná kọ, kí o sì tú wọn ká,

ta ọfà rẹ, kí o tú wọn ká.

7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti òkè,

kí o yọ mí ninu ibú omi;

kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

8 tí ẹnu wọn kún fún irọ́,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

9 Ọlọrun, n óo kọ orin titun sí ọ,

n óo fi hapu olókùn mẹ́wàá kọrin sí ọ.

10 Ìwọ ni ò ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,

tí o sì gba Dafidi, iranṣẹ rẹ, là.

11 Gbà mí lọ́wọ́ idà ìkà,

gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

tí ẹnu wọ́n kún fún irọ́,

tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún èké.

12 Ní ìgbà èwe àwọn ọdọmọkunrin wa,

jẹ́ kí wọ́n dàbí igi tí a gbìn tí ó dàgbà,

kí àwọn ọdọmọbinrin wa dàbí òpó igun ilé,

tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí bíi ti ààfin ọba.

13 Kí àká wa kún fún oniruuru oúnjẹ,

kí àwọn aguntan wa bí ẹgbẹẹgbẹrun,

àní, ẹgbẹẹgbaarun ninu pápá oko wa.

14 Kí àwọn mààlúù wa lóyún,

kí wọ́n má rọ́nú, kí wọ́n má bí òkúmọ;

kí ó má sí ariwo àjálù ní ìgboro wa.

15 Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí ó ní irú ibukun yìí;

ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 145

Orin Ìyìn

1 Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi,

n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.

2 Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́,

tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae.

3 OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ;

àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀.

4 Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ,

tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ.

5 Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ,

ati iṣẹ́ ìyanu rẹ.

6 Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu,

èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ.

7 Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó,

wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ.

8 Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni;

kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.

9 OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan,

àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá.

10 OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,

àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́.

11 Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ,

wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ,

12 láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ,

ati ẹwà ògo ìjọba rẹ.

13 Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,

yóo sì máa wà láti ìran dé ìran.

Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀,

olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.

14 OLUWA gbé gbogbo àwọn tí ń ṣubú lọ dìde,

ó sì gbé gbogbo àwọn tí a tẹrí wọn ba nàró.

15 Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́,

o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò.

16 Ìwọ la ọwọ́ rẹ,

o sì tẹ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè lọ́rùn.

17 Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀,

aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.

18 OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é,

àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn.

19 Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn;

ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n.

20 OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí,

ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run.

21 Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA;

kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 146

Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.

2 N óo máa yin OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo wà láyé;

n óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè.

3 Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè;

eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.

4 Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀,

ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé.

5 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó fi Ọlọrun Jakọbu ṣe olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,

tí ó gbójú lé OLUWA, Ọlọrun rẹ̀.

6 Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé,

òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;

Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae,

7 ẹni tíí máa ń dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn tí a ni lára;

tí ń fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ,

OLUWA tíí tú àwọn tí ó wà ninu ìdè sílẹ̀.

8 A máa la ojú àwọn afọ́jú,

a máa gbé àwọn tí a tẹrí wọn ba dúró;

ó fẹ́ràn àwọn olódodo.

9 OLUWA ni olùṣọ́ àwọn àlejò,

òun ni alátìlẹ́yìn àwọn opó ati aláìníbaba,

ṣugbọn a máa da ète àwọn eniyan burúkú rú.

10 OLUWA yóo jọba títí lae,

Sioni, Ọlọrun rẹ yóo jọba láti ìran dé ìran.

Ẹ yin OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 147

Ọlọrun Alágbára

1 Ẹ yin OLUWA!

Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa;

nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́.

2 OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu;

òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ.

3 Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu,

ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn.

4 Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀,

òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ.

5 OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọ

òye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n.

6 OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró,

òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

7 Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA,

ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa.

8 Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run,

ó pèsè òjò fún ilẹ̀,

ó mú koríko hù lórí òkè.

9 Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ,

tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké.

10 Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí,

kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà.

11 Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

12 Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!

Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!

13 Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,

ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.

14 Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ,

ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.

15 Ó pàṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,

àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀ kíá.

16 Ó da òjò dídì bo ilẹ̀ bí ẹ̀gbọ̀n òwú,

ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.

17 Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,

ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?

18 Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,

ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.

19 Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,

ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.

20 Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,

wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 148

Kí gbogbo ẹ̀dá Yin OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,

ẹ yìn ín lókè ọ̀run.

2 Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀;

ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.

3 Ẹ yìn ín, oòrùn ati òṣùpá;

ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tí ń tàn.

4 Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ;

yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run.

5 Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,

nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn.

6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae;

ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá.

7 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,

ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi;

8 iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,

ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.

9 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,

ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari;

10 ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ ati ẹran ọ̀sìn,

ẹ̀yin ẹ̀dá tí ń fàyà fà ati ẹyẹ tí ń fò.

11 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè,

ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;

12 ẹ̀yin ọdọmọkunrin ati ọlọ́mọge,

ẹ̀yin ọmọde ati ẹ̀yin àgbààgbà.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA,

nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù;

ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ.

14 Ó ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára,

ó sì fún àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ ní ìyìn;

ó fún àwọn eniyan Israẹli, tí ó wà lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 149

Orin Ìyìn sí OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,

ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́.

2 Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀,

kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba.

3 Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀,

kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i.

4 Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,

a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

5 Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá;

kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn.

6 Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun;

kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn,

7 láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà;

8 láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn,

ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn;

9 láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀.

Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí.

Ẹ yin OLUWA!