Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 130

Adura Ẹlẹ́ṣẹ̀

1 Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA!

2 OLUWA, gbóhùn mi,

dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

3 Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀,

ta ló lè yege?

4 Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà,

kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.

5 Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e,

mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀.

6 Mò ń retí rẹ, OLUWA,

ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ,

àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.

7 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA!

Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà,

ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà.

8 Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 131

Àṣírí ìfọ̀kànbalẹ̀

1 OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga,

bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè.

N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá,

n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ.

2 Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́,

bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀.

Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́.

3 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA,

láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 132

Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi

1 OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà.

2 Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA,

tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu,

3 tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi;

4 n kò ní sùn,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé,

5 títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA,

àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.”

6 A gbúròó rẹ̀ ní Efurata,

a rí i ní oko Jearimu.

7 “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀;

ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.”

8 Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ,

tìwọ ti àpótí agbára rẹ.

9 Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo,

kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀.

10 Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ,

má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ.

11 OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi,

èyí tí kò ní yipada; ó ní,

“Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ

ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.

12 Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́,

tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn,

àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.”

13 Nítorí OLUWA ti yan Sioni;

ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀:

14 Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae,

níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí.

15 N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ;

n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.

16 N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀,

àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀.

17 Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára;

mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn.

18 N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ,

ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 133

Ìrẹ́pọ̀ Àwọn ará

1 Ó dára, ó sì dùn pupọ,

bí àwọn ará bá ń gbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀.

2 Ó dàbí òróró iyebíye tí a dà síni lórí,

tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n;

bí ó ti ṣàn dé irùngbọ̀n Aaroni,

àní, títí dé ọrùn ẹ̀wù rẹ̀.

3 Ó dàbí ìrì òkè Herimoni,

tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni.

Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun,

àní, ìyè ainipẹkun.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 134

Ẹ yin OLUWA

1 Ẹ wá, ẹ yin OLUWA,

gbogbo ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,

gbogbo ẹ̀yin tí ń sìn ín ninu ilé rẹ̀ lóru.

2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè, kí ẹ gbadura ninu ilé mímọ́ rẹ̀,

kí ẹ sì yin OLUWA.

3 Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé

bukun yín láti Sioni wá.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 135

Orin Ìyìn

1 Ẹ yin OLUWA.

Ẹ yin orúkọ OLUWA;

ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,

2 ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA,

tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa.

3 Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun;

ẹ kọrin ìyìn sí i,

nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni.

4 Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀,

ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.

5 Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi,

ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ.

6 Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣe

lọ́run ati láyé,

ninu òkun ati ninu ibú.

7 Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé,

ó fi mànàmáná fún òjò,

ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.

8 Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,

ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn.

9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti,

ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀.

10 Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run;

ó pa àwọn ọba alágbára:

11 Sihoni ọba àwọn Amori,

Ogu ọba Baṣani,

ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani.

12 Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀;

ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn.

13 OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae,

òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé.

14 OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre,

yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀.

15 Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn,

iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.

16 Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,

wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran.

17 Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn,

bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn.

18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn,

ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn.

19 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA,

ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA!

20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA,

ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín!

21 Ẹ yin OLUWA ní Sioni,

ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 136

Orin Ọpẹ́

1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

3 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

4 Òun nìkan ṣoṣo ní ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

5 Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

6 ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

7 ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

8 Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

9 Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

10 Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

11 ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

12 Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

13 Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

14 ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

15 ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogun

rẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

16 Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

17 ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

18 ó sì pa àwọn ọba olókìkí,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

19 Sihoni ọba àwọn Amori,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

20 ati Ogu ọba Baṣani,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

21 Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

22 ó fún àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ̀,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

23 Òun ni ó ranti wa ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ wa,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;

24 ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

25 Ẹni tí ó pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá alààyè,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

26 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ọ̀run,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 137

Àwọn Ọmọ Israẹli Kọrin Arò ní Ìgbèkùn

1 Lẹ́bàá odò Babiloni ni a jókòó, tí a sọkún,

nígbà tí a ranti Sioni.

2 Lára igi wilo níbẹ̀ ni a fi hapu wa kọ́ sí,

3 nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn

ti ní kí á kọrin fún àwọn.

Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní,

“Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.”

4 Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì?

5 Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,

kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.

6 Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,

bí n kò bá ranti rẹ,

bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.

7 OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣe

nígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,

tí wọn ń pariwo pé,

“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”

8 Babiloni! Ìwọ apanirun!

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ,

fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa!

9 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ,

tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 138

Adura Ọpẹ́

1 N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA,

lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ.

2 Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ,

n óo sì máa yin orúkọ rẹ,

nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ,

nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ.

3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn,

o sì fún mi ní agbára kún agbára.

4 OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,

nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

5 Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,

nítorí pé ògo OLUWA tóbi.

6 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,

ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,

ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè.

7 Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú,

sibẹ, o dá mi sí;

o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi,

o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí.

8 OLUWA yóo mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí mi,

OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

Má kọ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sílẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 139

Ọlọrun Olùmọ̀ràn Ọkàn

1 OLUWA, o ti yẹ̀ mí wò, o sì mọ̀ mí.

2 O mọ ìgbà tí mo jókòó, ati ìgbà tí mo dìde;

o mọ èrò ọkàn mi láti òkèèrè réré.

3 O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò;

gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀.

4 Kódà kí n tó sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,

OLUWA, o ti mọ gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ sọ patapata.

5 O pa mí mọ́, níwájú ati lẹ́yìn;

o gbé ọwọ́ ààbò rẹ lé mi.

6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ́ ohun ìyanu fún mi,

ó ga jù, ojú mi kò tó o.

7 Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀?

Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi?

8 Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀!

Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀.

9 Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá,

kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí,

10 níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi,

tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú.

11 Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀,

kí ọ̀sán di òru fún mi,

12 òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ;

òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;

lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn.

13 Nítorí ìwọ ni o dá inú mi,

ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi.

14 Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́;

ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!

O mọ̀ mí dájú.

15 Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀,

tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí,

kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ.

16 Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi,

o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi

sinu ìwé rẹ,

kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.

17 Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi!

Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye.

18 Bí mo bá ní kí n kà wọ́n,

wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ;

nígbà tí mo bá sì jí,

ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà.

19 Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú,

kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi.

20 Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ nípa rẹ,

àwọn ọ̀tá rẹ ń ba orúkọ rẹ jẹ́.

21 OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ;

mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ?

22 Mo kórìíra wọn dé òpin;

ọ̀tá ni mo kà wọ́n kún.

23 Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi;

yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi.

24 Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀,

kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé.