Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 120

Adura Ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA ni mo ké pè, nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,

ó sì dá mi lóhùn.

2 OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké,

ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn.

3 Kí ni a óo fi san án fun yín?

Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn?

4 Ọfà mímú ni a óo ta yín,

a óo sì dáná sun yín.

5 Mo gbé! Nítorí pé mo dàbí àlejò tó wọ̀ ní Meṣeki,

tí ń gbé ààrin àwọn àgọ́ Kedari.

6 Ó pẹ́ jù tí mo tí ń bá àwọn tí ó kórìíra alaafia gbé.

7 Alaafia ni èmi fẹ́,

ṣugbọn nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ìjà ṣá ni tiwọn.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 121

OLUWA Aláàbò Wa

1 Mo gbójú sókè wo àwọn òkè,

níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá?

2 Ìrànlọ́wọ́ mi ń ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá,

ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.

3 Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀,

ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé.

4 Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́

kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn.

5 OLUWA ni olùpamọ́ rẹ.

OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ.

6 Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án,

bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru.

7 OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi,

yóo pa ọ́ mọ́.

8 OLUWA yóo pa àlọ ati ààbọ̀ rẹ mọ́,

láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 122

Ìyìn Jerusalẹmu

1 Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,

“Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé OLUWA.”

2 A ti tẹsẹ̀ bọ inú ìgboro rẹ, Jerusalẹmu.

3 Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́,

tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan.

4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà,

àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ,

láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA

gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli.

5 Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí,

àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi.

6 Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu!

“Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ!

7 Kí alaafia ó wà ninu rẹ,

kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.”

8 Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi,

n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.”

9 Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa,

èmi óo máa wá ire rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 123

Adura Àánú

1 Ìwọ ni mo gbé ojú sókè sí,

ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run.

2 Wò ó, bí iranṣẹkunrin ti máa ń wo ojú oluwa rẹ̀,

tí iranṣẹbinrin sì máa ń wo ojú oluwa rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni à ń wo ojú OLUWA, Ọlọrun wa,

títí tí yóo fi ṣàánú wa.

3 Ṣàánú wa, OLUWA, ṣàánú wa,

ẹ̀gàn yìí ti pọ̀ jù!

4 Ẹ̀gàn àwọn onírera ti pọ̀ jù fún wa;

yẹ̀yẹ́ àwọn onigbeeraga sì ti sú wa.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 124

Ọlọrun Aláàbò Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa,

ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,

2 “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa

nígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá,

3 wọn ìbá gbé wa mì láàyè,

nígbà tí inú bí wọn sí wa;

4 àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ,

ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀;

5 ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.”

6 Ọpẹ́ ni fún OLUWA,

tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn.

7 A ti yọ, bí ẹyẹ tí ó yọ ninu okùn apẹyẹ:

okùn ti já; àwa sì ti yọ.

8 Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìrànlọ́wọ́ wa ti wá,

ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 125

Ìfọ̀kànbalẹ̀ Àwọn Eniyan OLUWA

1 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni,

tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae.

2 Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká,

láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.

3 Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹ

lórí ilẹ̀ àwọn olódodo,

kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi.

4 OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere,

ati fún àwọn olódodo.

5 Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹ

àwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́.

Alaafia fún Israẹli!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 126

Ẹkún Di Ayọ̀

1 Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada,

ó dàbí àlá lójú wa.

2 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀,

nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé,

“OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!”

3 Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.

4 Dá ire wa pada, OLUWA,

bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu.

5 Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú,

jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.

6 Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún,

yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 127

Abániṣé ni OLUWA

1 Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé,

asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ.

Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú,

asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de.

2 Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu,

kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn.

Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ;

nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.

3 Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ;

òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.

4 Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni.

5 Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn.

Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 128

Ìbẹ̀rù OLUWA lérè

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA,

tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.

2 O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ.

3 Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ;

bí ọmọ tií yí igi olifi ká,

ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká.

4 Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

5 Kí OLUWA bukun ọ láti Sioni!

Kí o máa rí ire Jerusalẹmu

ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

6 Kí o máa rí arọmọdọmọ rẹ.

Kí alaafia máa wà ní Israẹli.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 129

Kí ojú ti ọ̀tá

1 Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.

Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,

2 “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,

sibẹ, wọn kò borí mi.”

3 Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,

gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.

4 Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,

ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú.

5 Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni,

a óo lé wọn pada sẹ́yìn.

6 Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,

tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ.

7 Kò lè kún ọwọ́ ẹni tí ń pa koríko;

kò sì lè kún ọwọ́ ẹni tí ń di koríko ní ìtí.

8 Àwọn èrò ọ̀nà kò sì ní kí ẹni tí ń gé e pé:

“OLUWA óo fèrè síṣẹ́ o!

Ẹ kúuṣẹ́, OLUWA óo fèrè sí i.”