Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 110

OLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀

1 OLUWA wí fún oluwa mi, ọba, pé,

“Jókòó sí apá ọ̀tún mi,

títí tí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ

di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

2 OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni.

O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ.

3 Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀,

lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́.

Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀.

4 OLUWA ti búra, kò sì ní yí ọkàn rẹ̀ pada, pé,

“Alufaa ni ọ́ títí lae,

nípasẹ̀ Mẹlikisẹdẹki.”

5 OLUWA wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

yóo rún àwọn ọba wómúwómú ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.

6 Yóo ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,

ọpọlọpọ òkú ni yóo sì sùn ninu wọn;

yóo sì run àwọn ìjòyè káàkiri ilẹ̀ ayé.

7 Ọba yóo mu omi ninu odò ẹ̀bá ọ̀nà,

nítorí náà yóo sì gbé orí rẹ̀ sókè bí aṣẹ́gun.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 111

Yin OLUWA

1 Ẹ yin OLUWA!

N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn,

láàrin àwọn olódodo,

ati ní àwùjọ àwọn eniyan.

2 Iṣẹ́ OLUWA tóbi,

àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri.

3 Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo,

òdodo rẹ̀ sì wà títí lae.

4 OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,

olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀.

5 A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀,

a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae.

6 Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀,

nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà,

gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú.

8 Wọ́n wà títí lae ati laelae,

ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin.

9 Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀,

ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae,

mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀.

10 Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,

gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé.

Títí lae ni ìyìn rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 112

Ayọ̀ Ẹni Rere

1 Ẹ yin OLUWA!

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA,

tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀.

2 Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé,

a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin.

3 Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀,

Òdodo rẹ̀ wà títí lae.

4 Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn,

olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo.

5 Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan,

tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà.

6 A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae,

títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀.

7 Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù,

ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

8 Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á,

níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

9 Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka,

òdodo rẹ̀ wà títí lae,

yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá.

10 Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i.

Yóo pa eyín keke, yóo pòórá,

ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 113

Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀

1 Ẹ yin OLUWA!

Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA.

Ẹ yin orúkọ OLUWA.

2 Kí á yin orúkọ OLUWA,

láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae.

3 Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,

kí á máa yin orúkọ OLUWA.

4 OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ,

ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ.

5 Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa,

tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run,

6 ẹni tí ó bojú wo ilẹ̀

láti wo ọ̀run ati ayé?

7 Ó gbé talaka dìde láti inú erùpẹ̀,

ó sì gbé aláìní sókè láti orí eérú,

8 láti mú wọn jókòó láàrin àwọn ìjòyè,

àní, àwọn ìjòyè àwọn eniyan rẹ̀.

9 Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ,

ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn.

Ẹ máa yin OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 114

Orin Ìrékọjá

1 Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti,

tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì,

2 Juda di ilé mímọ́ rẹ̀,

Israẹli sì di ìjọba rẹ̀.

3 Òkun rí i, ó sá,

Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn.

4 Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò,

àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan.

5 Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun?

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani?

6 Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò?

Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan?

7 Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀,

wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu.

8 Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi,

tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 115

Ọlọrun Òdodo

1 Ògo kì í ṣe fún wa, OLUWA, Kì í ṣe fún wa,

orúkọ rẹ nìkan ṣoṣo ni kí á yìn lógo,

nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí òtítọ́ rẹ.

2 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi bèèrè pé,

níbo ni Ọlọrun wa wà?

3 Ọlọrun wa wà ní ọ̀run,

ó ń ṣe ohun tí ó wù ú.

4 Fadaka ati wúrà ni ère tiwọn,

iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.

5 Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,

wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran.

6 Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn,

wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn.

7 Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó,

wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin.

8 Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn,

bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn.

9 Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,

òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

10 Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,

òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

11 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ gbẹ́kẹ̀lé e,

òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

12 OLUWA ranti wa, yóo bukun wa,

yóo bukun ilé Israẹli,

yóo bukun ìdílé Aaroni.

13 Yóo bukun àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

ati àwọn ọlọ́lá ati àwọn mẹ̀kúnnù.

14 OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ máa bí sí i,

àtẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín.

15 Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín!

16 OLUWA ló ni ọ̀run,

ṣugbọn ó fi ayé fún àwọn eniyan.

17 Àwọn òkú kò lè yin OLUWA,

àní àwọn tí wọ́n ti dákẹ́ ninu ibojì.

18 Ṣugbọn àwa yóo máa yin OLUWA,

láti ìsinsìnyìí lọ, ati títí laelae.

Ẹ máa yin OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 116

Orin Ọpẹ́

1 Mo fẹ́ràn OLUWA nítorí pé ó gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ mi.

2 Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi,

nítorí náà, n óo máa ké pè é

níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.

3 Tàkúté ikú yí mi ká;

ìrora isà òkú dé bá mi;

ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀.

4 Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA,

mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!”

5 Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA,

aláàánú ni Ọlọrun wa.

6 OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́;

nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí.

7 Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá,

nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ.

8 Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú,

o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé,

o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú.

9 Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè.

10 Igbagbọ mi kò yẹ̀, nígbà tí mo tilẹ̀ wí pé,

“Ìpọ́njú dé bá mi gidigidi.”

11 Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé,

“Èké ni gbogbo eniyan.”

12 Kí ni n óo san fún OLUWA,

nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí mi?

13 N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA,

n óo sì pe orúkọ rẹ̀.

14 N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA,

lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.

15 Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA.

16 OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́,

iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ.

O ti tú ìdè mi.

17 N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ,

n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA.

18 N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA

lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀,

19 ninu àgbàlá ilé OLUWA,

láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu.

Ẹ máa yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 117

Yíyin OLUWA

1 Ẹ máa yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè!

Ẹ yìn ín gbogbo ẹ̀yin eniyan,

2 Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tóbi sí wa,

òtítọ́ rẹ̀ sì wà títí laelae.

Ẹ máa yin OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 118

Adura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé,

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”

3 Kí àwọn ará ilé Aaroni wí pé,

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”

4 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé,

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”

5 Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA,

ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀.

6 Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí.

Kí ni eniyan lè fi mí ṣe?

7 OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́,

nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mi

pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun.

8 Ó sàn láti sá di OLUWA,

ju ati gbẹ́kẹ̀lé eniyan lọ.

9 Ó sàn láti sá di OLUWA,

ju ati gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè.

10 Gbogbo orílẹ̀-èdè dòòyì ká mi,

ṣugbọn ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!

11 Wọ́n yí mi ká, àní, wọ́n dòòyì ká mi,

ṣugbọn ni orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!

12 Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin,

ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́;

ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run.

13 Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú,

ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́.

14 OLUWA ni agbára ati orin mi,

ó ti di olùgbàlà mi.

15 Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun,

ninu àgọ́ àwọn olódodo.

“Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá.

16 A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga,

ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!”

17 N ò ní kú, yíyè ni n óo yè,

n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe.

18 OLUWA jẹ mí níyà pupọ,

ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19 Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi,

kí n lè gba ibẹ̀ wọlé,

kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA.

20 Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA;

àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé.

21 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi,

o sì ti di olùgbàlà mi.

22 Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,

ni ó di pataki igun ilé.

23 OLUWA ló ṣe èyí;

ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.

24 Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá,

ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn.

25 OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,

OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege.

26 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,

láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA.

27 OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.

Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,

títí dé ibi ìwo pẹpẹ.

28 Ìwọ ni Ọlọrun mi,

n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ.

Ìwọ ni Ọlọrun mi,

n óo máa gbé ọ ga.

29 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 119

Òfin OLUWA

1 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n,

àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

2 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́,

tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

3 Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀,

ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

4 O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́,

5 Ìbá ti dára tó

tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!

6 Òun ni ojú kò fi ní tì mí,

nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.

7 N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,

bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ.

8 N óo máa pa òfin rẹ mọ́,

má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

9 Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?

Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.

10 Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,

má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.

11 Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,

kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.

12 Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,

kọ́ mi ní ìlànà rẹ!

13 Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.

14 Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,

bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

15 N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,

n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.

16 N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,

n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

Ayọ̀ ninu Òfin OLUWA

17 Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,

kí n lè wà láàyè,

kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.

18 Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu

tí ó wà ninu òfin rẹ.

19 Àlejò ni mí láyé,

má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi.

20 Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo.

21 O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,

tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́.

22 Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi,

nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́.

23 Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi,

sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.

24 Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi,

àwọn ni olùdámọ̀ràn mi.

Ìpinnu láti Pa Òfin OLUWA mọ́

25 Mo di ẹni ilẹ̀,

sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

26 Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn;

kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

27 La òfin rẹ yé mi,

n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ.

28 Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́,

mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

29 Mú ìwà èké jìnnà sí mi,

kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ.

30 Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́,

mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ.

31 Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA,

má jẹ́ kí ojú ó tì mí.

32 N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́,

nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i.

Adura fún Òye

33 OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,

n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34 Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,

kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.

35 Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,

nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.

36 Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,

kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.

37 Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,

sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.

38 Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,

àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.

39 Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,

nítorí pé ìlànà rẹ dára.

40 Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,

sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!

Gbígbẹ́kẹ̀lé ninu Òfin OLUWA

41 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,

kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

42 Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,

nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.

43 Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,

nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.

44 N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae.

45 N óo máa rìn fàlàlà,

nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ.

46 N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,

ojú kò sì ní tì mí.

47 Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,

nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.

48 Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,

n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.

Igbẹkẹle ninu Òfin OLUWA

49 Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,

èyí tí ó fún mi ní ìrètí.

50 Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:

ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.

51 Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,

ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.

52 Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,

OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.

53 Inú mi á máa ru,

nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,

tí wọn ń rú òfin rẹ.

54 Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,

lákòókò ìrìn àjò mi láyé.

55 Mo ranti orúkọ rẹ lóru;

OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:

56 Èyí ni ìṣe mi:

Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.

Ìfọkànsí Òfin OLUWA

57 OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;

mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.

58 Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,

ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

59 Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,

mo yipada sí ìlànà rẹ;

60 mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.

61 Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,

n kò ní gbàgbé òfin rẹ.

62 Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,

nítorí ìlànà òdodo rẹ.

63 Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,

àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́.

64 OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;

kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

Iyebíye ni Òfin OLUWA

65 OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,

gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

66 Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,

nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.

67 Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;

ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.

68 OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;

kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

69 Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,

ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.

70 Ọkàn wọn ti yigbì,

ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.

71 Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,

ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.

72 Òfin rẹ níye lórí fún mi,

ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.

Òdodo ni Òfin OLUWA

73 Ìwọ ni o mọ mí, ìwọ ni o dá mi,

fún mi ní òye kí n lè kọ́ òfin rẹ.

74 Inú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yóo máa dùn

nígbà tí wọ́n bá rí mi,

nítorí pé mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

75 OLUWA, mo mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ tọ̀nà,

ati pé lórí ẹ̀tọ́ ni o pọ́n mi lójú.

76 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,

gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ.

77 Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,

nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi.

78 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,

nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;

ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.

79 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,

kí wọ́n lè mọ òfin rẹ.

80 Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,

kí ojú má baà tì mí.

Adura Ìdáǹdè

81 Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;

ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

82 Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,

níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.

Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”

83 Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,

sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

84 Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?

Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi?

85 Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,

àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.

86 Gbogbo òfin rẹ ló dájú;

ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi.

87 Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,

ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.

88 Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ.

Igbagbọ ninu Òfin OLUWA

89 OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run.

90 Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran;

o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró.

91 Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní,

nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.

92 Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi,

ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú.

93 Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ,

nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé.

94 Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;

nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.

95 Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,

wọ́n fẹ́ pa mí run,

ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.

96 Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,

àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.

Ìfẹ́ sí Òfin OLUWA

97 Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!

Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.

98 Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,

nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.

99 Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,

nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.

100 Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,

nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

101 N kò rin ọ̀nà ibi kankan,

kí n lè pa òfin rẹ mọ́.

102 N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,

nítorí pé o ti kọ́ mi.

103 Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,

ó dùn ju oyin lọ.

104 Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,

nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.

Ìmọ́lẹ̀ láti Inú Òfin OLUWA

105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni àtùpà fún ẹsẹ̀ mi,

òun ni ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà mi.

106 Mo ti búra, n óo sì mú un ṣẹ,

pé n óo máa pa òfin òdodo rẹ mọ́.

107 Ojú ń pọ́n mi lọpọlọpọ,

sọ mí di alààyè, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

108 Gba ẹbọ ìyìn àtọkànwá mi, OLUWA,

kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

109 Ayé mi wà ninu ewu nígbà gbogbo,

ṣugbọn n kò gbàgbé òfin rẹ.

110 Àwọn eniyan burúkú ti dẹ okùn sílẹ̀ dè mí,

ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.

111 Ìlànà rẹ ni ogún mi títí lae,

nítorí pé òun ni ayọ̀ mi.

112 Mo ti pinnu láti máa tẹ̀lé ìlànà rẹ nígbà gbogbo,

àní, títí dé òpin.

Ààbò ninu Òfin OLUWA

113 Mo kórìíra àwọn oníyèméjì,

ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.

114 Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi ati asà mi,

mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,

kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́.

116 Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè,

má sì dójú ìrètí mi tì mí.

117 Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu,

kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo.

118 O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,

nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn.

119 O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,

nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ.

120 Mo wárìrì nítorí pé mo bẹ̀rù rẹ,

mo sì bẹ̀rù ìdájọ́ rẹ.

Pípa Òfin OLUWA mọ́

121 Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́ tí ó sì yẹ,

má fi mí sílẹ̀ fún àwọn tí wọn ń ni mí lára.

122 Ṣe ìlérí ìrànlọ́wọ́ fún ire èmi iranṣẹ rẹ,

má sì jẹ́ kí àwọn onigbeeraga ni mí lára.

123 Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,

níbi tí mo tí ń retí ìgbàlà rẹ,

ati ìmúṣẹ ìlérí òdodo rẹ.

124 Ṣe sí èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

125 Iranṣẹ rẹ ni mí,

fún mi lóye, kí n lè mọ ìlànà rẹ.

126 OLUWA, ó tó àkókò fún ọ láti ṣe nǹkankan,

nítorí àwọn eniyan ń rú òfin rẹ.

127 Nítorí náà ni èmi ṣe fẹ́ràn òfin rẹ

ju wúrà lọ; àní, ju ojúlówó wúrà.

128 Nítorí náà, èmi ń tẹ̀lé gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ,

mo sì kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.

Ìfẹ́ láti Pa Òfin OLUWA Mọ́

129 Òfin rẹ dára,

nítorí náà ni mo ṣe ń pa wọ́n mọ́.

130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ a máa fúnni ní ìmọ́lẹ̀,

a sì máa fi òye fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.

131 Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ,

nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ.

132 Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóore

bí o ti máa ń ṣe

sí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ.

133 Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ,

má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi.

134 Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan,

kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

135 Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;

kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

136 Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,

nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.

Títọ́ Òfin OLUWA

137 Olódodo ni ọ́, OLUWA,

ìdájọ́ rẹ sì tọ́.

138 Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,

òtítọ́ patapata ni.

139 Mò ń tara gidigidi,

nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

140 A ti yẹ ọ̀rọ̀ rẹ wò fínnífínní, ó dúró ṣinṣin,

mo sì fẹ́ràn rẹ̀.

141 Bí mo tilẹ̀ kéré, tí ayé sì kẹ́gàn mi,

sibẹ n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

142 Òdodo rẹ wà títí lae,

òtítọ́ sì ni òfin rẹ.

143 Ìyọnu ati ìpayà dé bá mi,

ṣugbọn mo láyọ̀ ninu òfin rẹ.

144 Òdodo ni ìlànà rẹ títí lae,

fún mi ní òye kí n lè wà láàyè.

Adura Ìdáǹdè

145 Tọkàntọkàn ni mo fi ń ké pè ọ́,

OLUWA, dá mi lóhùn;

n óo sì máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

146 Mo ké pè ọ́; gbà mí,

n óo sì máa mú àṣẹ rẹ ṣẹ.

147 Mo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́;

mò ń retí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ.

148 N kò fi ojú ba oorun ní gbogbo òru,

kí n lè máa ṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ.

149 Gbóhùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

OLÚWA, dá mi sí nítorí òtítọ́ rẹ.

150 Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi súnmọ́ tòsí;

wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.

151 Ṣugbọn ìwọ wà nítòsí, OLUWA,

òtítọ́ sì ni gbogbo òfin rẹ.

152 Ó pẹ́ tí mo ti kọ́ ninu ìlànà rẹ,

pé o ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́

153 Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí,

nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ.

154 Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí,

sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú,

nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ.

156 Àánú rẹ pọ̀, OLUWA,

sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ.

157 Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀,

ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ.

158 Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra,

nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́.

159 Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó!

Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ,

gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae.

Fífi Ara Ẹni fún Òfin OLUWA

161 Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí,

ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn.

162 Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ,

bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun.

163 Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́,

ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ.

164 Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́

nítorí òfin òdodo rẹ.

165 Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ,

kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.

166 Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA,

mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́.

167 Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́,

mo fẹ́ràn wọn gidigidi.

168 Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ;

gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí.

Adura Ìrànlọ́wọ́

169 Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA,

fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ,

kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

171 Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ,

pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

172 N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ,

nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà.

173 Múra láti ràn mí lọ́wọ́,

nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ.

174 Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA;

òfin rẹ sì ni inú dídùn mi.

175 Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́,

sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́.

176 Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù;

wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí,

nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.