Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 100

Orin Ìyìn

1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé.

2 Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.

Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀.

3 Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,

òun ló dá wa, òun ló ni wá;

àwa ni eniyan rẹ̀,

àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.

4 Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́,

kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn.

Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,

kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.

5 Nítorí OLUWA ṣeun;

ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae,

òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 101

Ìlérí Ọba

1 N óo kọrin ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo,

OLUWA, ìwọ ni n óo máa kọrin ìyìn sí.

2 N óo múra láti hu ìwà pípé pẹlu ọgbọ́n;

nígbà wo ni o óo wá sọ́dọ̀ mi?

N óo máa fi tọkàntọkàn rin ìrìn pípé ninu ilé mi.

3 N kò ní gba nǹkan burúkú láyè níwájú mi.

Mo kórìíra ìṣe àwọn tí wọ́n tàpá sí Ọlọrun.

N kò sì ní bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkankan.

4 Èròkérò yóo jìnnà sí ọkàn mi,

n kò sì ní ṣe ohun ibi kankan,

5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ níbi,

n óo pa á run,

n kò sì ní gba alágbèéré ati onigbeeraga láàyè.

6 N óo máa fi ojurere wo àwọn olóòótọ́ ní ilẹ̀ náà,

kí wọ́n lè máa bá mi gbé;

ẹni tí ó bá sì ń hu ìwà pípé ni yóo máa sìn mí.

7 Ẹlẹ́tàn kankan kò ní gbé inú ilé mi;

bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kankan kò ní dúró níwájú mi.

8 Ojoojumọ ni n óo máa pa àwọn eniyan burúkú run ní ilẹ̀ náà,

n óo lé gbogbo àwọn aṣebi kúrò ninu ìlú OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 102

Adura Olùpọ́njú

1 Gbọ́ adura mi, OLUWA;

kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ.

2 Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro!

Dẹtí sí adura mi;

kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́.

3 Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín,

eegun mi gbóná bí iná ààrò.

4 Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko,

tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun.

5 Nítorí igbe ìrora mi,

mo rù kan eegun.

6 Mo dàbí igúnnugún inú aṣálẹ̀,

àní, bí òwìwí inú ahoro.

7 Mo dùbúlẹ̀ láìlè sùn,

mo dàbí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.

8 Àwọn ọ̀tá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru,

àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi ń fi orúkọ mi ṣépè.

9 Mò ń jẹ eérú bí oúnjẹ,

mo sì ń mu omijé mọ́ omi

10 nítorí ìrúnú ati ibinu rẹ;

o gbé mi sókè,

o sì jù mí nù.

11 Ọjọ́ ayé mi ń lọ bí òjìji àṣáálẹ́,

mo sì ń rọ bíi koríko.

12 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ OLUWA gúnwà títí lae,

ọlá rẹ sì wà láti ìran dé ìran.

13 Ìwọ óo dìde, o óo sì ṣàánú Sioni,

nítorí ó tó àkókò láti fi ojú àánú wò ó.

Àkókò tí o dá tó.

14 Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,

àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀.

15 Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,

gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.

16 Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,

yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀.

17 Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní,

kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn.

18 Kí ẹ kọ èyí sílẹ̀ fún ìran tí ń bọ̀,

kí àwọn ọmọ tí a kò tíì bí lè máa yin OLUWA,

19 pé OLUWA bojú wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀,

láti ọ̀run ni ó ti bojú wo ayé;

20 láti gbọ́ ìkérora àwọn ìgbèkùn,

ati láti dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sílẹ̀.

21 Kí á lè pòkìkí orúkọ OLUWA ní Sioni,

kí á sì máa yìn ín lógo ní Jerusalẹmu,

22 nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn,

láti sin OLUWA.

23 Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́,

ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú.

24 Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,

ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.”

25 Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run.

26 Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae;

gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ,

o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ;

wọn yóo sì di ohun ìpatì.

27 Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà,

ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin.

28 Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé;

bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 103

Ìfẹ́ Ọlọrun

1 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,

fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

2 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,

má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,

3 ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,

tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn;

4 ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn,

tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé.

5 Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn,

tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.

6 OLUWA a máa dáni láre

a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo

àwọn tí a ni lára.

7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose,

ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli.

8 Aláàánú ati olóore ni OLUWA,

kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.

9 Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí,

bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé.

10 Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa,

bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa.

11 Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó

sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12 Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn,

bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.

13 Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn

tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.

14 Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa;

ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.

15 Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko,

eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó;

16 ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀,

á rẹ̀ dànù,

ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́.

17 Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀,

sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,

òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn.

18 Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́,

tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.

19 OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run,

ó sì jọba lórí ohun gbogbo.

20 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀,

ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀,

tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

21 Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,

ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

22 Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,

níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀.

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 104

Yíyin Ẹlẹ́dàá

1 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,

OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ,

ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù.

2 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ,

ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ.

3 Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi,

tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ,

tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́.

4 Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ,

tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ.

5 Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀,

tí kò sì le yẹ̀ laelae.

6 O fi ibú omi bò ó bí aṣọ,

omi sì borí àwọn òkè ńlá.

7 Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá,

nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn.

8 Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkè

lọ sí inú àfonífojì,

sí ibi tí o yàn fún wọn.

9 O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá,

kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.

10 Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì;

omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè.

11 Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu,

ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ.

12 Lẹ́bàá orísun wọnyi

ni àwọn ẹyẹ ń gbé,

wọ́n sì ń kọrin lórí igi.

13 Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá.

Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

14 Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ,

ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan,

kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀;

15 ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn,

ati epo tí ń mú ojú eniyan dán,

ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun.

16 Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn,

àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn.

17 Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́

wọn sí,

àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi.

18 Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó,

abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro.

19 O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò,

oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀.

20 O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,

gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sì

ń jẹ kiri.

21 Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ,

wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ.

22 Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ;

wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn.

23 Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀,

á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́.

24 OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!

Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn.

Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.

25 Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀,

ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá,

nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá.

26 Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ,

ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun.

27 Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò,

fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò.

28 Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ,

nígbà tí o bá la ọwọ́,

wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó.

29 Bí o bá fojú pamọ́,

ẹ̀rù á bà wọ́n,

bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú,

wọn á sì pada di erùpẹ̀.

30 Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde,

wọ́n di ẹ̀dá alààyè,

o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun.

31 Kí ògo OLUWA máa wà títí lae,

kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀.

32 Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì,

tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín.

33 N óo kọrin ìyìn sí OLUWA

níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.

N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi,

níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ.

34 Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninu

nítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA.

35 Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé,

kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́.

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi!

Yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 105

Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀,

ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè.

2 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i,

ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀.

3 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn,

kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀.

4 Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀,

ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo.

5 Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe,

ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.

6 Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,

ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

7 OLUWA ni Ọlọrun wa,

ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé.

8 Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀,

ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,

9 majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,

ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki,

10 tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin,

àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé,

11 ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún,

yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”

12 Nígbà tí wọ́n kéré ní iye,

tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà,

13 tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,

láti ìjọba kan dé òmíràn,

14 kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,

ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.

15 Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì

òróró mi,

ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.”

16 Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà:

ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu.

17 Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn,

Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú.

18 Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀,

wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin,

19 títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ,

tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

20 Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀,

aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀.

21 Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀,

ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀;

22 láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀,

kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀.

23 Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti,

Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu.

24 OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i,

ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ.

25 Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada,

tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀,

tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.

26 Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀,

ati Aaroni, ẹni tí ó yàn.

27 Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀náà,

wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu,

28 Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú,

ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,

ó sì mú kí ẹja wọn kú.

30 Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn,

títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31 Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé,

iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.

32 Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí,

mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn.

33 Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,

ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn.

34 Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé,

ati àwọn tata tí kò lóǹkà;

35 wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn,

ati gbogbo èso ilẹ̀ náà.

36 Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn,

àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn.

37 Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde,

tàwọn ti fadaka ati wúrà,

kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera.

38 Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde,

nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n.

39 OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n,

ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru.

40 Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò,

ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run.

41 Ó la àpáta, omi tú jáde,

ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.

42 Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀,

ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀.

43 Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde,

ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin.

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà.

45 Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ,

kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́.

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 106

Oore OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 Ẹ yin OLUWA!

Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun

nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2 Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán?

Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn?

3 Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́,

àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo.

4 Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń

ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ.

Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là.

5 Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ

kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ,

kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ.

6 A ti ṣẹ̀, àtàwa, àtàwọn baba wa,

a ti ṣe àìdára, a sì ti hùwà burúkú.

7 Nígbà tí àwọn baba ńlá wa wà ní Ijipti,

wọn kò náání iṣẹ́ ìyanu rẹ,

wọn kò sì ranti bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti pọ̀ tó.

Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo lẹ́bàá òkun pupa.

8 Sibẹsibẹ, ó gbà wọ́n là, nítorí orúkọ rẹ̀;

kí ó lè fi títóbi agbára rẹ̀ hàn.

9 Ó bá òkun pupa wí, òkun pupa gbẹ,

ó sì mú wọn la ibú já bí ẹni rìn ninu aṣálẹ̀.

10 Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn,

ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

11 Omi bo àwọn ọ̀tá wọn,

ẹyọ ẹnìkan kò sì là.

12 Nígbà náà ni wọ́n tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́,

wọ́n sì kọrin yìn ín.

13 Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,

wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀.

14 Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀,

wọ́n sì dán Ọlọrun wò.

15 Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè,

ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n.

16 Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó,

ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.

17 Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,

ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀.

18 Iná sọ láàrin wọn,

ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.

19 Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,

wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà.

20 Wọ́n gbé ògo Ọlọrun

fún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.

21 Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,

tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,

22 ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu,

ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa.

23 Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run,

bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀,

tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀,

láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.

24 Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,

wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA.

25 Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,

wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.

26 Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọn

pé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀,

27 ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiri

àwọn orílẹ̀-èdè.

28 Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,

wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.

29 Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú,

àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.

30 Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,

àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.

31 A sì kà á kún òdodo fún un,

láti ìrandíran títí lae.

32 Wọ́n mú OLUWA bínú lẹ́bàá omi Meriba,

wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mose,

33 nítorí wọ́n mú Mose bínú,

ọ̀rọ̀ tí kò yẹ sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.

34 Wọn kò pa àwọn eniyan ilẹ̀ náà run,

gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn,

35 ṣugbọn wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè náà,

wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.

36 Wọ́n bọ àwọn oriṣa wọn,

èyí sì fa ìpalára fún wọn.

37 Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn bọ oriṣa.

38 Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

àní, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkunrin,

ati ti àwọn ọmọbinrin wọn,

tí wọ́n fi bọ àwọn oriṣa ilẹ̀ Kenaani;

wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́.

39 Nítorí náà, wọ́n fi ìṣe wọn sọ ara wọn di aláìmọ́,

wọ́n sì sọ ara wọn di alágbèrè.

40 Nígbà náà ni inú bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,

ó sì kórìíra àwọn ẹni ìní rẹ̀.

41 Ó fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́,

títí tí àwọn tí ó kórìíra wọn fi jọba lé wọn lórí.

42 Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára,

wọ́n sì fi agbára mú wọn sìn.

43 Ọpọlọpọ ìgbà ni ó gbà wọ́n sílẹ̀,

ṣugbọn wọ́n ti pinnu láti máa tàpá sí i,

OLUWA sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

44 Sibẹsibẹ, ninu ìnira wọn, ó ṣàánú wọn,

nígbà tí ó gbọ́ igbe wọn.

45 Nítorí tiwọn, ó ranti majẹmu tí ó dá,

ó sì yí ìpinnu rẹ̀ pada nítorí ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

46 Ó jẹ́ kí àánú wọn ṣe gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn.

47 Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa,

kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,

kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.

48 Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,

lae ati laelae.

Kí gbogbo eniyan máa wí pé, “Amin!”

Ẹ yin OLUWA!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 107

Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀

1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,

nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2 Kí àwọn tí OLUWA ti rà pada kí ó wí bẹ́ẹ̀,

àní, àwọn tí ó yọ kúrò ninu ìpọ́njú,

3 tí ó kó wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì,

láti ìhà ìlà oòrùn ati láti ìhà ìwọ̀ oòrùn,

láti ìhà àríwá ati láti ìhà gúsù.

4 Àwọn kan ń káàkiri ninu aṣálẹ̀,

wọn kò sì rí ọ̀nà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

5 Ebi pa wọ́n, òùngbẹ gbẹ wọ́n,

ó sì rẹ̀ wọ́n wá láti inú.

6 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,

ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn.

7 Ó kó wọn gba ọ̀nà tààrà jáde,

lọ sí ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

8 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan.

9 Nítorí pé ó fi omi tẹ́ àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ lọ́rùn,

ó sì fi oúnjẹ dáradára bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó.

10 Àwọn kan jókòó ninu òkùnkùn pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,

wọ́n wà ninu ìgbèkùn ati ìpọ́njú, a sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,

11 nítorí pé wọ́n tàpá sí òfin Ọlọrun,

wọ́n sì pẹ̀gàn ìmọ̀ràn ọ̀gá ògo.

12 Làálàá mú kí agara dá ọkàn wọn,

wọ́n ṣubú lulẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́.

13 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,

ó sì gbà wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

14 Ó yọ wọ́n kúrò ninu òkùnkùn ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,

ó sì já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn.

15 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

16 Nítorí pé ó fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ,

ó sì gé ọ̀pá ìdábùú irin ní àgéjá.

17 Àwọn kan ninu wọn di òmùgọ̀

nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

ojú sì pọ́n wọn nítorí àìdára wọn.

18 Oúnjẹ rùn sí wọn,

wọ́n sì súnmọ́ bèbè ikú.

19 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,

ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

20 Ó sọ̀rọ̀, ó sì mú wọn lára dá,

ó tún kó wọn yọ ninu ìparun.

21 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

àní, nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

22 Kí wọn máa rú ẹbọ ọpẹ́,

kí wọn sì máa fi orin ayọ̀ ròyìn iṣẹ́ rẹ̀.

23 Àwọn kan wọ ọkọ̀ ojú omi,

wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,

24 wọ́n rí ìṣe OLUWA,

àní iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ninu ibú.

25 Ó pàṣẹ, ìjì líle sì bẹ̀rẹ̀ sí jà,

tóbẹ́ẹ̀ tí ìgbì omi fi ru sókè.

26 Àwọn ọkọ̀ ojú omi fò sókè roro,

wọ́n sì tún já wá sílẹ̀ dòò, sinu ibú,

jìnnìjìnnì bò wọ́n ninu ewu tí wọ́n wà.

27 Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí,

gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu.

28 Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,

ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

29 Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró,

ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀.

30 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀,

ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn.

31 Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.

32 Kí wọn gbé e ga láàrin ìjọ eniyan,

kí wọn sì yìn ín ní àwùjọ àwọn àgbà.

33 Ó sọ odò di aṣálẹ̀,

ó sọ orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ,

34 ó sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀ oníyọ̀,

nítorí ìwà burúkú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

35 Ó sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,

ó sì sọ ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi.

36 Ó jẹ́ kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,

wọ́n sì tẹ ìlú dó, láti máa gbé.

37 Wọ́n dáko, wọ́n gbin àjàrà,

wọ́n sì kórè lọpọlọpọ.

38 Ó bukun wọn, ó mú kí wọn bí sí i lọpọlọpọ,

kò sì jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọ́n dínkù.

39 Nígbà tí wọ́n dínkù, tí a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,

nípa ìnira, ìpọ́njú, ati ìṣòro,

40 ó da ẹ̀gàn lu àwọn ìjòyè,

ó sì mú kí wọn máa rìn kiri ní aṣálẹ̀,

níbi tí kò sí ọ̀nà.

41 Ṣugbọn ó yọ aláìní kúrò ninu ìpọ́njú,

ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran.

42 Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,

a sì pa àwọn eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

43 Kí ẹni tí ó gbọ́n kíyèsí nǹkan wọnyi;

kí ó sì fi òye gbé ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 108

Adura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá

1 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun

ọkàn mi dúró ṣinṣin.

N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́.

Jí, ìwọ ọkàn mi!

2 Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu!

Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu,

3 OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan,

n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

4 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ,

òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

5 Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun,

kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé.

6 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,

fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn.

7 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,

ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,

n óo sì pín àfonífojì Sukotu.

8 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase.

Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,

Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

9 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,

lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé,

n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.”

10 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?

Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?

11 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?

Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́.

12 Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,

nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.

13 Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin;

nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 109

Ìráhùn Ẹni tí Ó Wà ninu Ìṣòro

1 Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn.

2 Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati ti

àwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́,

wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi.

3 Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi,

wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí.

4 Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí,

sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn.

5 Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi,

ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.

6 Yan eniyan burúkú tì í,

jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́.

7 Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀,

jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi;

kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn.

8 Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú,

kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà.

9 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba,

kí aya rẹ̀ di opó.

10 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká,

kí wọn máa ṣagbe kiri;

kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé.

11 Kí ẹni tí ó jẹ lówó gba gbogbo ohun ìní rẹ̀,

kí ẹni ẹlẹ́ni sì kó èrè iṣẹ́ rẹ̀.

12 Kí ó má bá aláàánú pàdé,

kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba.

13 Kí ìran rẹ̀ run,

kí orúkọ rẹ̀ parẹ́ lórí àwọn ọmọ rẹ̀.

14 Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀,

kí ó má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ rẹ́.

15 Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbà gbogbo,

kí á má sì ranti ìran wọn mọ́ láyé.

16 Nítorí pé kò ronú láti ṣàánú,

ṣugbọn ó ṣe inúnibíni talaka ati aláìní,

ati sí oníròbìnújẹ́ títí a fi pa wọ́n.

17 Ó fẹ́ràn láti máa ṣépè;

nítorí náà kí èpè rẹ̀ dà lé e lórí;

inú rẹ̀ kò dùn sí ìre,

nítorí náà kí ìre jìnnà sí i.

18 Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù,

kí èpè mù ún bí omi,

kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn.

19 Kí èpè di aṣọ ìbora fún un,

ati ọ̀já ìgbànú.

20 Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi,

àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi!

21 Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà mi

nítorí orúkọ rẹ, gbà mí!

Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀.

22 Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí,

ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ.

23 Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́,

a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú.

24 Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà,

mo rù kan egungun.

25 Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi,

wọ́n ń wò mí ní àwòmirí.

26 Ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, Ọlọrun mi,

gbà mí, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni èyí,

kí wọn mọ̀ pé, ìwọ OLUWA ni o ṣe é.

28 Kí wọn máa ṣépè, ṣugbọn kí ìwọ máa súre.

Kí ojú ti àwọn alátakò mi,

kí inú èmi, iranṣẹ rẹ, sì máa dùn.

29 Kí ìtìjú bo àwọn ọ̀tá mi bi aṣọ,

àní, kí wọn gbé ìtìjú wọ̀ bí ẹ̀wù.

30 N óo máa fi ẹnu mi yin OLUWA gidigidi,

àní, n óo máa yìn ín ní àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan.

31 Nítorí pé ó dúró ti aláìní

láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ó dájọ́ ikú fún un.