Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 90

Ibi tí Agbára Ẹ̀dá Mọ

1 OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran.

2 Kí o tó dá àwọn òkè,

ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,

láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.

3 O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,

o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.”

4 Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,

tabi bí ìṣọ́ kan ní òru.

5 Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,

bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀;

6 ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré;

ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ.

7 Ibinu rẹ pa wá run;

ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀.

8 O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ;

àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.

9 Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ;

ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀.

10 Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa;

pẹlu ipá a lè tó ọgọrin;

sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu;

kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ.

11 Ta ló mọ agbára ibinu rẹ?

Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí?

12 Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa,

kí á lè kọ́gbọ́n.

13 Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa?

Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ.

14 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,

kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn

ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

15 Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí o

ti fi pọ́n wa lójú,

ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi.

16 Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ,

kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa,

fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀,

jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 91

Ọlọrun Aláàbò wa

1 Ẹni tí ń gbé abẹ́ ààbò Ọ̀gá Ògo,

tí ó wà lábẹ́ òjìji Olodumare,

2 yóo wí fún OLUWA pé,

“Ìwọ ni ààbò ati odi mi,

Ọlọrun mi, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé.”

3 Nítorí yóo yọ ọ́ ninu okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ

ati ninu àjàkálẹ̀ àrùn apanirun.

4 Yóo da ìyẹ́ rẹ̀ bò ọ́,

lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni o óo ti rí ààbò;

òtítọ́ rẹ̀ ni yóo jẹ́ asà ati apata rẹ.

5 O ò ní bẹ̀rù ìdágìrì òru,

tabi ọfà tí ń fò kiri ní ọ̀sán,

6 tabi àjàkálẹ̀ àrùn tí ń jà kiri ninu òkùnkùn,

tabi ìparun tí ń ṣeni lófò ní ọ̀sán gangan.

7 Ẹgbẹrun lè ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,

tabi ẹgbaarun ni apá ọ̀tún rẹ;

ṣugbọn kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

8 Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn,

tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú.

9 Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ,

o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ,

10 ibi kankan kò ní dé bá ọ,

bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ.

11 Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ,

pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.

12 Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè,

kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.

13 O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀;

ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi,

n óo gbà á là;

n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi.

15 Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn;

n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro,

n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá.

16 N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,

n óo sì gbà á là.”

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 92

Orin Ìyìn

1 Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA;

kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo;

2 ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀,

kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́,

3 pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá,

ati hapu.

4 Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ;

OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

5 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA!

Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ!

6 Òpè eniyan kò lè mọ̀,

kò sì le yé òmùgọ̀:

7 pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko,

tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀,

ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn.

8 Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA.

9 Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun;

gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká.

10 Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n;

o ti da òróró dáradára sí mi lórí.

11 Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi,

mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí.

12 Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,

wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni.

13 Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,

tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa.

14 Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn,

wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo;

15 láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA;

òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 93

Ọlọrun Ọba

1 OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù;

OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀,

ó sì di agbára ni àmùrè.

Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;

kò sì ní yẹ̀ laelae.

2 A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae;

láti ayérayé ni o ti wà.

3 Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA,

ibú omi gbé ohùn wọn sókè,

ó sì ń sán bí ààrá.

4 OLUWA lágbára lókè!

Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ,

ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ.

5 Àwọn òfin rẹ kìí yipada,

ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 94

Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé

1 OLUWA, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san,

ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, fi agbára rẹ hàn!

2 Dìde, ìwọ onídàájọ́ ayé;

san ẹ̀san èrè iṣẹ́ àwọn agbéraga fún wọn!

3 OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?

Àní, yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú yóo máa ṣe jàgínní?

4 Wọ́n ń fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ jàbùjàbù,

gbogbo àwọn aṣebi ní ń fọ́nnu.

5 Wọ́n ń rún àwọn eniyan rẹ mọ́lẹ̀, OLUWA,

wọ́n ń pọ́n àwọn eniyan rẹ lójú.

6 Wọ́n ń pa àwọn opó ati àwọn àlejò,

wọ́n sì ń pa àwọn aláìníbaba;

7 wọ́n ń sọ pé, “OLUWA kò rí wa;

Ọlọrun Jakọbu kò ṣàkíyèsí wa.”

8 Ẹ jẹ́ kí ó ye yín,

ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan!

Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n?

9 Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn?

Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran?

10 Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà,

ni kò ní jẹ yín níyà?

Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀?

11 OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan,

ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni.

12 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA,

tí o sì kọ́ ní òfin rẹ,

13 kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro,

títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú.

14 Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;

kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì;

15 nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo,

àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

16 Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú?

Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi?

17 Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́,

ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú.

18 Nígbà tí mo rò pé, “Ẹsẹ̀ mi ti yọ̀,”

OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni ó gbé mi ró.

19 Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ,

ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le.

20 Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ,

àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?

21 Wọ́n para pọ̀ láti gba ẹ̀mí olódodo;

wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún aláìṣẹ̀.

22 Ṣugbọn OLUWA ti di ibi ìsádi mi,

Ọlọrun mi sì ti di àpáta ààbò mi.

23 Yóo san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn,

yóo pa wọ́n run nítorí ìwà ìkà wọn.

OLUWA Ọlọrun wa yóo pa wọ́n run.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 95

Orin Ìyìn

1 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA;

ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa!

2 Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;

ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i.

3 Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,

ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.

4 Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;

gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.

5 Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;

ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba,

ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa!

7 Nítorí òun ni Ọlọrun wa,

àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri,

àwa ni agbo aguntan rẹ̀.

Ọlọrun Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ sọ̀rọ̀

Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,

8 ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba,

ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀

9 nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò,

tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí

ohun tí mo ti ṣe rí.

10 Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi,

tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa,

wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.”

11 Nítorí náà ni mo fi fi ibinu búra pé,

wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 96

Ọlọrun Ọba Àwọn Ọba

1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA;

gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA.

2 Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀;

ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.

3 Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;

ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan.

4 Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ;

ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ.

5 Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn,

ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run.

6 Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀;

agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀.

7 Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé;

ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀.

8 Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀,

ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀.

9 Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́;

gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀.

10 Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba!

A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae;

OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.”

11 Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀;

kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.

12 Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀.

Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin,

13 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀;

ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;

yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 97

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀;

jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn.

2 Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká;

òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3 Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀,

ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì.

4 Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé,

ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì.

5 Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA,

àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.

6 Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀;

gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀.

7 Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa,

àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn;

gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀.

8 Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn.

Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀,

nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA.

9 Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,

o ju gbogbo ayé lọ,

a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.

10 Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;

OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,

a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.

11 Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,

ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.

12 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo,

kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 98

Ọlọrun, Ọba gbogbo Ayé

1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,

nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu;

agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun.

2 OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀,

ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè.

3 Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀

sí àwọn ọmọ Israẹli;

gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa.

4 Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA;

ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.

5 Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,

àní, hapu ati ohùn orin dídùn.

6 Ẹ fun fèrè ati ìwo

kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba.

7 Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,

kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

8 Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́;

kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀

9 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;

yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 99

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì;

ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì.

2 OLUWA tóbi ní Sioni,

ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

3 Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù,

mímọ́ ni OLUWA!

4 Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo,

o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀;

o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu.

5 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,

ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;

mímọ́ ni OLUWA!

6 Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀;

Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀;

wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn.

7 Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu;

wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́;

wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn.

8 OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn;

Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn;

ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn.

9 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,

kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀;

nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.