Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé tí à ń pè ní

Orin Dafidi

ni ìwé orin ati ìwé adura ninu Bibeli. Ọpọlọpọ ọdún ni àwọn tí ó kọ orin inú ìwé náà fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe àkójọpọ̀ wọn, wọ́n sì ń lò ó fún ìjọ́sìn. Nígbà tí ó yá, wọ́n fi àwọn orin náà kún Ìwé Mímọ́ wọn.

Oríṣìíríṣìí ni àwọn orin ẹ̀sìn wọnyi: orin ìyìn ati orin ìsìn, orin adura ati ìrànlọ́wọ́, orin ààbò ati ìgbàlà; orin ẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, orin ọpẹ́ fún ibukun Ọlọrun, ati ti ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun pé kí ó jẹ àwọn ọ̀tá ẹni níyà. Àwọn adura yìí wà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tabi orílẹ̀-èdè. Àwọn mìíràn jẹ́ ti ẹ̀dùn ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn yòókù sì jẹ́ ti àìní ati èrò ọkàn gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.

Jesu lò lára àwọn ọ̀rọ̀ inú

Ìwé Orin Dafidi

, àwọn tí wọ́n kọ ìwé Majẹmu Titun náà sì ṣe àmúlò rẹ̀. Láti ìgbà tí ìjọ Kristi ti bẹ̀rẹ̀ ni ìwé náà sì ti di ìwé ìṣúra fún ìjọ́sìn.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀nà marun-un ni a pín aadọjọ Orin Dafidi náà sí:

Orin Dafidi 1–41

Orin Dafidi 42–72

Orin Dafidi 73–89

Orin Dafidi 90–106

Orin Dafidi 107–150

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 1

Ayọ̀ Tòótọ́

1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà

tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú,

tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn,

tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.

2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,

a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.

3 Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò

tí ń so ní àkókò tí ó yẹ,

tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.

Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.

4 Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,

ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.

5 Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo.

6 Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo,

ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 2

Àyànfẹ́ Ọlọrun

1 Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfù

tí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?

2 Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,

àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,

wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.

3 Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá já

kí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.”

4 Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;

OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.

5 Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,

yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,

6 Yóo wí pé, “Mo ti fi ọba mi jẹ,

ní Sioni, lórí òkè mímọ́ mi.”

7 N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba;

Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi,

lónìí ni mo bí ọ.

8 Bèèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fún ọ ní àwọn orílẹ̀-èdè,

gbogbo ayé yóo sì di tìrẹ.

9 Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn,

o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”

10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n;

ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.

11 Ẹ fi ìbẹ̀rù sin OLUWA,

ẹ yọ̀ pẹlu ìwárìrì.

12 Ẹ júbà ọmọ náà, kí ó má baà bínú,

kí ó má baà pa yín run lójijì;

nítorí a máa yára bínú.

Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo àwọn tí ó wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 3

Adura ìrànlọ́wọ́ lówùúrọ̀

1 OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!

Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!

2 Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,

Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀!

3 Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,

ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà.

4 Mo ké pe OLUWA,

ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.

5 Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,

nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.

6 Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká

kò le bà mí lẹ́rù.

7 Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi!

Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀,

tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú.

8 OLUWA níí gbani,

kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 4

Igbẹkẹle OLUWA

1 Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,

Ọlọrun mi olùdániláre.

Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,

ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi.

2 Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀,

tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri?

3 Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀,

OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

4 Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀;

ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín,

kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.

5 Ẹ rú ẹbọ òdodo,

kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

6 Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?”

OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára.

7 Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn mi

ju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè.

8 N óo dùbúlẹ̀, n óo sì sùn ní alaafia,

nítorí ìwọ OLUWA nìkan ni o mú mi wà láìléwu.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 5

Adura Ààbò

1 Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA;

kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi.

2 Fetí sí igbe mi,

Ọba mi ati Ọlọrun mi,

nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.

3 OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀,

ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ;

èmi óo sì máa ṣọ́nà.

4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú;

àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé.

5 Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ;

o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi.

6 O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run;

OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn.

7 Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

èmi óo wọ inú ilé rẹ;

n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ.

8 OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi;

jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi.

9 Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn;

ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn.

Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;

ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn.

10 Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n;

jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú.

Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn,

nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11 Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn,

kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae.

Dáàbò bò wọ́n,

kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ.

12 Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo;

ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 6

Adura nígbà ìyọnu

1 OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;

má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà.

2 Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,

OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun.

3 Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,

yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?

4 OLUWA, pada wá gbà mí,

gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

5 Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.

Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú?

6 Ìkérora dá mi lágara:

ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;

tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù.

7 Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,

agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá.

8 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi,

nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi.

9 OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi,

OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi.

10 Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi;

ìdààmú ńlá yóo bá wọn,

wọn óo sá pada,

ojú yóo sì tì wọ́n lójijì.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 7

Ọlọrun Onídàájọ́ Òdodo

1 OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di;

gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.

2 Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun,

kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀.

3 OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí,

bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi,

4 bí mo bá fi ibi san án fún olóore,

tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí,

5 jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá,

kí ó tẹ̀ mí pa,

kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

6 OLUWA, fi ibinu dìde!

Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn;

jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀.

7 Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká,

kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá.

8 OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé;

dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi.

9 Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan,

fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú,

kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀.

10 Ọlọrun ni aláàbò mi,

òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là.

11 Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,

a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.

12 Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀;

ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e.

13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀,

ó sì ti tọ́jú ọfà iná.

14 Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké.

15 Ó gbẹ́ kòtò,

ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́.

16 Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀,

àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí.

17 N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀,

n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo.

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 8

Ògo OLUWA ati Ipò Eniyan

1 OLUWA, Oluwa wa,

orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!

Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run.

2 Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ,

wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀,

nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ,

kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.

3 Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀–

4 Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?

Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?

5 O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,

o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé.

6 O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:

7 àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó;

8 àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun,

ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun.

9 OLUWA, Oluwa wa,

orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!

Categories
ORIN DAFIDI

ORIN DAFIDI 9

Ọpẹ́ fún Ọlọrun nítorí Ìdájọ́ Òdodo Rẹ̀

1 OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ;

n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ.

2 N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ;

n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

3 Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà,

wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ.

4 Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre;

ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo.

5 O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,

o pa àwọn eniyan burúkú run,

o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae.

6 O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro,

o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé.

7 Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae,

ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀.

8 Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,

yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.

9 OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,

òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.

10 Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;

nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.

11 Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!

Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!

12 Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti,

kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13 OLUWA, ṣàánú fún mi!

Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú.

Gbà mí kúrò létí bèbè ikú,

14 kí n lè kọrin ìyìn rẹ,

kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni.

15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́,

wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀.

16 OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́,

àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn.

17 Àwọn eniyan burúkú,

àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú.

18 Nítorí pé OLUWA kò ní fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn aláìní,

bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn talaka kò ní já sí òfo títí lae.

19 Dìde, OLUWA, má jẹ́ kí eniyan ó borí,

jẹ́ kí á ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ.

20 OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n,

jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn.