Categories
NỌMBA

NỌMBA 30

Ìlànà nípa Ẹ̀jẹ́ Jíjẹ́

1 Mose sọ fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ:

2 Bí ọmọkunrin kan bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, kò gbọdọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí ó ti wí ni ó gbọdọ̀ ṣe.

3 Bí ọdọmọbinrin kan, tí ń gbé ilé baba rẹ̀ bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun,

4 ó gbọdọ̀ ṣe bí ó ti wí, àfi bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe.

5 Bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe, nígbà tí ó gbọ́ ọ, ọdọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà, OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé baba rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

6 Bí ọmọbinrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, bóyá ó ti ọkàn rẹ̀ wá tabi kò ti ọkàn rẹ̀ wá, tí ó sì lọ ilé ọkọ lẹ́yìn ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́,

7 ó níláti ṣe gbogbo ohun tí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́ ọ.

8 Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, ọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

9 Obinrin tí ó bá jẹ́ opó ati obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ wọn. Wọ́n sì gbọdọ̀ yẹra fún ohun gbogbo tí wọn bá ṣe ìlérí láti yẹra fún.

10 Bí obinrin tí ó ní ọkọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tabi tí ó bá ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun,

11 ó gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ rẹ̀, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí i nígbà tí ó gbọ́.

12 Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, obinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

13 Ọkọ rẹ̀ ní àṣẹ láti gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tabi kí ó kọ̀ fún un láti san án.

14 Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ kò bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́, ó níláti san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀ kò lòdì sí i.

15 Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà lẹ́yìn èyí, ọkọ náà ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ obinrin náà nítorí pé kò jẹ́ kí ó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀.

16 Bẹ́ẹ̀ ni ìlànà tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose láàrin ọkọ ati aya ati láàrin baba ati ọmọ rẹ̀ obinrin, tí ń gbé ninu ilé rẹ̀.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 31

Wọ́n Dojú Ogun Mímọ́ kọ Midiani

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Fìyà jẹ àwọn ará Midiani fún ohun tí wọ́n ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn náà, o óo kú.”

3 Mose bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ múra ogun kí á lè gbógun ti àwọn ará Midiani, kí á sì fìyà jẹ wọ́n fún ohun tí wọ́n ṣe sí OLUWA.

4 Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan yóo mú ẹgbẹrun eniyan wá fún ogun náà.”

5 Nítorí náà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Israẹli, ẹgbaafa (12,000) ọkunrin ni wọ́n dájọ láti lọ sójú ogun, ẹgbẹẹgbẹrun láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

6 Mose sì rán wọn lọ sójú ogun lábẹ́ àṣẹ Finehasi ọmọ Eleasari alufaa, pẹlu àwọn ohun èlò mímọ́ ati fèrè fún ìdágìrì lọ́wọ́ rẹ̀.

7 Wọ́n gbógun ti àwọn ará Midiani gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n sì pa gbogbo àwọn ọkunrin wọn.

8 Wọ́n pa àwọn ọba Midiani maraarun pẹlu. Orúkọ wọn ni: Efi, Rekemu, Suri, Huri ati Reba. Wọ́n pa Balaamu ọmọ Beori pẹlu.

9 Àwọn ọmọ Israẹli kó àwọn obinrin ati àwọn ọmọ Midiani lẹ́rú. Wọ́n kó gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo agbo ẹran wọn ati gbogbo ohun ìní wọn.

10 Wọ́n fi iná sun gbogbo ìlú wọn ati àwọn abúlé wọn,

11 wọ́n kó gbogbo ìkógun: eniyan ati ẹranko.

12 Wọ́n kó wọn wá sọ́dọ̀ Mose ati Eleasari ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ní òdìkejì odò Jọdani, lẹ́bàá Jẹriko.

Àwọn Ọmọ Ogun Pada Wálé

13 Mose, Eleasari ati àwọn olórí jáde lọ pàdé àwọn ọmọ ogun náà lẹ́yìn ibùdó.

14 Mose bínú sí àwọn olórí ogun náà ati sí olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati olórí ọgọọgọrun-un.

15 Ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ dá àwọn obinrin wọnyi sí?

16 Ṣé ẹ ranti pé àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu tí wọ́n sì mú àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA ní Peori, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni àjàkálẹ̀ àrùn ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli?

17 Nítorí náà ẹ pa gbogbo àwọn ọdọmọkunrin wọn, ati àwọn obinrin tí wọn ti mọ ọkunrin.

18 Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọdọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin sí, kí ẹ fi wọ́n ṣe aya fún ara yín.

19 Ǹjẹ́ nisinsinyii gbogbo àwọn tí ó bá ti paniyan tabi tí ó ti fọwọ́ kan òkú láàrin yín yóo dúró lẹ́yìn ibùdó fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, àwọn ati obinrin tí wọ́n mú lójú ogun yóo ṣe ìwẹ̀nùmọ́.

20 Ẹ sì níláti fọ gbogbo aṣọ yín, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí a fi awọ ṣe, tabi irun ewúrẹ́, tabi igi.”

21 Eleasari bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ìlànà tí OLUWA ti fi lélẹ̀ láti ẹnu Mose.

22 Gbogbo wúrà, fadaka, idẹ, irin ati tánńganran ati òjé,

23 àní, gbogbo ohun tí kò bá ti lè jóná ni a óo mú la iná kọjá, kí á lè sọ wọ́n di mímọ́; a óo sì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ fọ àwọn ohun èlò tí wọn bá lè jóná.

24 Ní ọjọ́ keje, ẹ níláti fọ aṣọ yín, kí ẹ sì di mímọ́, lẹ́yìn náà, ẹ óo pada wá sí ibùdó.”

Pípín Ìkógun

25 OLUWA sọ fún Mose pé,

26 “Ìwọ, Eleasari ati àwọn olórí, ẹ ka gbogbo ìkógun tí ẹ kó, ati eniyan ati ẹranko.

27 Pín gbogbo ìkógun náà sí meji, kí apákan jẹ́ ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, kí apá keji sì jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli yòókù.

28 Yọ apákan sílẹ̀ fún OLUWA lára ti àwọn tí wọ́n lọ sójú ogun, ninu ẹẹdẹgbẹta tí o bá kà ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn, ọ̀kan jẹ́ ti OLUWA.

29 Yọ ọ́ lára ìkógun wọn kí o sì kó wọn fún Eleasari alufaa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA.

30 Lára ìdajì tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, mú ẹyọ kan ninu araadọta ninu eniyan ati mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ẹran ọ̀sìn; kí o sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA.”

31 Mose ati Eleasari sì ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn.

32 Ìkógun tí ó kù ninu àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó bọ̀ láti ojú ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹrinlelọgbọn ó dín ẹgbẹẹdọgbọn (675,000) aguntan.

33 Ẹgbaa mẹrindinlogoji (72,000) mààlúù.

34 Ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbẹrun (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

35 Àwọn ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000).

36 Ìdajì rẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ ogun jẹ́ ẹgbaa mejidinlaadọsan-an ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (337,500) aguntan.

37 Ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹẹdọgbọn (675).

38 Mààlúù jẹ́ ẹgbaa mejidinlogun (36,000), ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ mejilelaadọrin.

39 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹgbaa mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (30,500), ìpín ti OLUWA ninu rẹ̀ jẹ́ mọkanlelọgọta.

40 Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaajọ (16,000), ìpín ti OLUWA jẹ́ mejilelọgbọn.

41 Mose kó ìpín ti OLUWA fún Eleasari alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

42 Ìdajì yòókù, tí ó jẹ́ ìpín àwọn ọmọ Israẹli tí kò lọ sójú ogun,

43 jẹ́ ẹgbaa mejidinlaadọsan-an ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (337,500) aguntan.

44 Ẹgbaa mejidinlogun (36,000) mààlúù.

45 Ẹgbaa mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (30,500) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

46 Àwọn eniyan sì jẹ́ ẹgbaa mẹjọ (16,000).

47 Ninu wọn, Mose mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu araadọta ninu àwọn eniyan ati ẹranko, ó sì kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ OLUWA, bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

48 Lẹ́yìn náà ni àwọn olórí ogun àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un tọ Mose wá, wọ́n wí pé,

49 “A ti ka àwọn ọmọ ogun tí ó wà lábẹ́ wa, kò sí ẹni tí ó kú sójú ogun.

50 Nítorí náà a mú ọrẹ ẹbọ: ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, ẹ̀wọ̀n, ẹ̀gbà ọwọ́, òrùka, yẹtí, ati ìlẹ̀kẹ̀ wá fún OLUWA lára ìkógun wa, láti fi ṣe ẹbọ ètùtù fún wa níwájú OLUWA.”

51 Mose ati Eleasari gba àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mìíràn náà lọ́wọ́ wọn.

52 Ìwọ̀n gbogbo ọrẹ ẹbọ tí àwọn olórí ogun náà mú wá jẹ́ ẹgbaajọ ó lé ẹẹdẹgbẹrin ó lé aadọta (16,750) ṣekeli.

53 Àwọn ọmọ ogun tí wọn kì í ṣe olórí ogun ti kó ìkógun tiwọn.

54 Mose ati Eleasari kó wúrà náà lọ sinu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú OLUWA.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 32

Àwọn Ẹ̀yà Ìlà Oòrùn Jọdani

1 Nígbà tí àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn pupọ, rí ilẹ̀ Jaseri ati ilẹ̀ Gileadi pé ibẹ̀ dára fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn,

2 wọ́n wá siwaju Mose, ati Eleasari ati àwọn olórí àwọn eniyan, wọ́n ní,

3 “Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni,

4 tí OLUWA ti ran àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́ láti gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára fún ẹran ọ̀sìn, àwa iranṣẹ yín sì ní ẹran ọ̀sìn pupọ.

5 Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.”

6 Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ jókòó níhìn-ín kí àwọn arakunrin yín máa lọ jagun ni?

7 Kí ló dé tí ẹ fi mú ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n má baà rékọjá lọ sinu ilẹ̀ tí OLUWA fi fún wọn?

8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi Banea láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà.

9 Wọ́n lọ títí dé àfonífojì Eṣikolu, wọ́n wo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n pada dé, wọ́n mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì, kí wọn má lè lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi fún wọn.

10 Nítorí náà ni ibinu Ọlọrun ṣe ru sí wọn nígbà náà. Ó sì búra pé,

11 ‘Ọ̀kan ninu àwọn tí ó ti ilẹ̀ Ijipti wá, láti ẹni ogún ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣèlérí fún Abrahamu, fún Isaaki ati fún Jakọbu, nítorí pé wọn kò fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.’

12 Àfi Kalebu ọmọ Jefune, ọmọ Kenisi ati Joṣua ọmọ Nuni, nítorí pé wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.

13 Ibinu OLUWA ru sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì mú wọn rìn kiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún títí gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe burúkú níwájú OLUWA fi kú tán.

14 Nisinsinyii, ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín láti mú kí inú bí OLUWA gidigidi sí Israẹli.

15 Bí ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pada lẹ́yìn OLUWA, yóo kọ àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. A jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ fa ìparun wọn.”

16 Wọ́n dá Mose lóhùn pé, “A óo kọ́ ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa níhìn-ín ati ìlú olódi fún àwọn ọmọ wa.

17 Ṣugbọn àwa tìkarawa yóo di ihamọra ogun wa, a óo sì ṣáájú ogun fún àwọn yòókù títí wọn yóo fi gba ilẹ̀ ìní tiwọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ wa yóo máa gbé ninu ìlú olódi níhìn-ín kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà má baà yọ wọ́n lẹ́nu.

18 A kò ní pada sí ilẹ̀ wa títí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ní ilẹ̀ ìní tirẹ̀.

19 A kò ní bá wọn pín ninu ilẹ̀ òdìkejì odò Jọdani nítorí pé a ti ní ilẹ̀ ìní tiwa ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani níhìn-ín.”

20 Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí nǹkan tí ẹ sọ yìí bá ti ọkàn yín wá, tí ẹ bá di ihamọra ogun yín níwájú OLUWA,

21 tí àwọn ọmọ ogun yín sì ṣetán láti ré odò Jọdani kọjá ní àṣẹ OLUWA láti gbógun ti àwọn ọ̀tá wa títí OLUWA yóo fi pa wọ́n run,

22 tí yóo sì gba ilẹ̀ náà, lẹ́yìn náà, ẹ lè pada nítorí pé ẹ ti ṣe ẹ̀tọ́ yín sí OLUWA ati sí àwọn arakunrin yín. Ilẹ̀ yìí yóo sì máa jẹ́ ìní yín pẹlu àṣẹ OLUWA.

23 Ṣugbọn bí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ jẹ́ kí ó da yín lójú pé ẹ kò ní lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín.

24 Ẹ lọ kọ́ àwọn ìlú fún àwọn ọmọ yín ati ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ ṣèlérí.”

25 Àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi sì dá Mose lóhùn, wọ́n ní,

26 “Àwọn ọmọ wa, àwọn aya wa, àwọn mààlúù wa ati aguntan wa yóo wà ní àwọn ìlú Gileadi,

27 ṣugbọn a ti ṣetán láti lọ sí ojú ogun nípa àṣẹ OLUWA. A óo ré odò Jọdani kọjá láti jagun gẹ́gẹ́ bí o ti sọ.”

28 Mose bá pàṣẹ fún Eleasari alufaa, ati fún Joṣua ọmọ Nuni ati fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli nípa wọn, ó ní,

29 “Bí àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi bá bá yín ré odò Jọdani kọjá láti jagun níwájú OLUWA, bí wọ́n bá sì ràn yín lọ́wọ́ láti gba ilẹ̀ náà, ẹ óo fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

30 Ṣugbọn bí wọn kò bá bá yín ré odò Jọdani kọjá, tí wọn kò sì lọ sí ojú ogun pẹlu yín, wọn óo gba ìpín ilẹ̀ ìní tiwọn ní Kenaani bíi àwọn ọmọ Israẹli yòókù.”

31 Àwọn ọmọ Gadi ati àwọn ọmọ Reubẹni dáhùn, wọ́n ní, “A óo ṣe ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ.

32 Nípa àṣẹ rẹ̀ ni a óo ré odò Jọdani kọjá, a óo lọ jagun ní ilẹ̀ Kenaani, kí ilẹ̀ ìhà ìlà oòrùn Jọdani lè jẹ́ tiwa.”

33 Mose bá fi ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori, ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani ati àwọn ilẹ̀ ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká fún àwọn ọmọ Gadi, àwọn ọmọ Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu.

34 Àwọn ọmọ Gadi sì tún àwọn ìlú olódi wọnyi kọ́: Diboni, Atarotu ati Aroeri,

35 ati Atirotu Ṣofani, Jaseri, Jogibeha,

36 ati Beti Nimra, Beti Harani, àwọn ìlú olódi ati ilé fún àwọn aguntan.

37 Àwọn ọmọ Reubẹni tún àwọn ìlú wọnyi kọ́: Heṣiboni, Eleale, Kiriataimu,

38 Nebo, Baali Meoni (wọ́n yí orúkọ ìlú yìí pada) ati Sibima. Wọ́n sì fún àwọn ìlú tí wọn tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.

39 Àwọn ọmọ Makiri tíí ṣe ẹ̀yà Manase gbógun ti àwọn ará Amori tí ó wà ní Gileadi, wọ́n lé wọn jáde, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.

40 Nítorí náà Mose fi ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Makiri láti inú ẹ̀yà Manase, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

41 Jairi ọmọ Manase gbógun ti àwọn ìlú kan, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ wọn ní Hafoti Jairi.

42 Noba gbógun ti Kenati ati àwọn ìletò rẹ̀, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Noba tíí ṣe orúkọ ara rẹ̀.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 33

Ìrìn Àjò láti Ijipti sí Moabu

1 Ibi tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí ninu ìrìn àjò wọn láti ìgbà tí wọn ti kúrò ní Ijipti lábẹ́ àṣẹ Mose ati Aaroni nìwọ̀nyí:

2 (Orúkọ gbogbo ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ni Mose ń kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.)

3 Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi ní Ijipti ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ní ọjọ́ keji Àjọ̀dún Ìrékọjá pẹlu ọwọ́ agbára OLUWA, níṣojú àwọn ará Ijipti,

4 tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ.

5 Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Sukotu.

6 Wọ́n kúrò ní Sukotu, wọ́n lọ pàgọ́ sí Etamu tí ó wà létí aṣálẹ̀.

7 Láti ibẹ̀ wọ́n pada sẹ́yìn lọ sí Pi Hahirotu tí ó wà níwájú Baali Sefoni, wọ́n pàgọ́ siwaju Migidoli.

8 Wọ́n kúrò níwájú Pi Hahirotu, wọ́n la ààrin òkun kọjá lọ sinu aṣálẹ̀. Lẹ́yìn ìrìn ọjọ́ mẹta ninu aṣálẹ̀ Etamu, wọ́n pàgọ́ sí Mara.

9 Wọ́n kúrò ní Mara, wọ́n lọ pàgọ́ sí Elimu níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà.

10 Wọ́n kúrò ní Elimu, wọ́n lọ pàgọ́ sí etí Òkun Pupa.

11 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ pàgọ́ sí aṣálẹ̀ Sini.

12 Wọ́n kúrò ní aṣálẹ̀ Sini, wọ́n lọ pàgọ́ sí Dofika.

13 Wọ́n kúrò ní Dofika, wọ́n lọ pàgọ́ sí Aluṣi.

14 Wọ́n kúrò ní Aluṣi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Refidimu níbi tí wọn kò ti rí omi mu.

15 Wọ́n kúrò ní Refidimu lọ sí aṣálẹ̀ Sinai.

16 Láti aṣálẹ̀ Sinai wọ́n lọ sí Kiburotu Hataafa.

17 Láti Kiburotu Hataafa wọ́n lọ sí Haserotu.

18 Láti Haserotu wọ́n lọ sí Ritima.

19 Láti Ritima wọ́n lọ sí Rimoni Peresi.

20 Láti Rimoni Peresi wọ́n lọ sí Libina.

21 Láti Libina wọ́n lọ sí Risa.

22 Láti Risa wọ́n lọ sí Kehelata.

23 Láti Kehelata wọ́n lọ sí Òkè Ṣeferi.

24 Láti Òkè Ṣeferi wọ́n lọ sí Harada.

25 Láti Harada wọ́n lọ sí Makihelotu.

26 Láti Makihelotu wọ́n lọ sí Tahati.

27 Láti Tahati wọ́n lọ sí Tẹra.

28 Láti Tẹra wọ́n lọ sí Mitika.

29 Láti Mitika wọ́n lọ sí Haṣimona.

30 Láti Haṣimona wọ́n lọ sí Moserotu.

31 Láti Moserotu wọ́n lọ sí Bene Jaakani.

32 Láti Bene Jaakani wọ́n lọ sí Hori Hagidigadi.

33 Láti Hori Hagidigadi wọ́n lọ sí Jotibata.

34 Láti Jotibata wọ́n lọ sí Abirona.

35 Láti Abirona wọ́n lọ sí Esiongeberi.

36 Láti Esiongeberi wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini, tíí ṣe Kadeṣi.

37 Láti Kadeṣi wọ́n lọ sí Òkè Hori, lẹ́bàá ilẹ̀ Edomu.

38 Aaroni alufaa gun Òkè Hori lọ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un, níbẹ̀ ni ó sì kú sí ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un, ogoji ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ijipti.

39 Aaroni jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọfa (123) nígbà tí ó kú ní Òkè Hori.

40 Ọba ìlú Aradi, ní ilẹ̀ Kenaani, tí ń gbé Nẹgẹbu gbúròó pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀.

41 Wọ́n kúrò ní Òkè Hori wọn lọ sí Salimona.

42 Wọ́n kúrò ní Salimona wọ́n lọ sí Punoni.

43 Láti Punoni wọ́n lọ sí Obotu.

44 Láti Obotu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu ní agbègbè Moabu.

45 Láti Iyimu wọ́n lọ sí Diboni Gadi.

46 Láti Diboni Gadi wọ́n lọ sí Alimoni Dibilataimu.

47 Láti Alimoni Dibilataimu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu níwájú Nebo.

48 Láti Òkè Abarimu wọ́n lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko.

49 Wọ́n sì pàgọ́ wọn sí ẹ̀bá odò Jọdani láti Beti Jeṣimotu títí dé Abeli Ṣitimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu.

Ìlànà Nípa Líla Odò Jọdani Kọjá

50 OLUWA sọ fún Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko pé

51 kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá ré odò Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani,

52 ẹ gbọdọ̀ lé gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà kúrò. Ẹ run gbogbo àwọn oriṣa tí wọ́n fi òkúta ati irin ṣe ati gbogbo ilé oriṣa wọn.

53 Kí ẹ gba ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí pé mo ti fun yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní yín.

54 Gègé ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Israẹli. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ, sì fún àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kékeré. Ilẹ̀ tí gègé olukuluku bá mú ni yóo jẹ́ tirẹ̀, láàrin àwọn ẹ̀yà yín ni ẹ óo ti pín ilẹ̀ náà.

55 Ṣugbọn bí ẹ kò bá lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò, àwọn tí ó bá kù yóo di ẹ̀gún ní ojú yín ati ẹ̀gún ní ìhà yín, wọn yóo sì máa yọ yín lẹ́nu lórí ilẹ̀ náà.

56 Bí ẹ kò bá lé gbogbo wọn jáde, ohun tí mo ti pinnu láti ṣe sí wọn, ẹ̀yin ni n óo ṣe é sí.”

Categories
NỌMBA

NỌMBA 34

Àwọn Ààlà Ilẹ̀ náà

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’

3 Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn.

4 Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni.

5 Yóo sì yí láti Asimoni lọ dé odò Ijipti, òkun ni yóo sì jẹ́ òpin rẹ̀.

6 “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Òkun ni yóo jẹ́ ààlà yín.

7 “Ní ìhà àríwá, ààlà yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ òkun ńlá lọ títí dé Òkè Hori.

8 Láti ibẹ̀ lọ dé ẹnu ibodè Hamati, títí dé Sedadi,

9 Sifironi ati Hasari Enani.

10 “Ààlà ìhà ìlà oòrùn yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ Hasari Enani lọ sí Ṣefamu.

11 Yóo lọ sí ìhà gúsù sí Ribila ní ìhà ìlà oòrùn Aini títí lọ sí àwọn òkè tí wọ́n wà létí ìhà ìlà oòrùn Òkun-Kinereti.

12 Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”

13 Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù.

14 Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ilẹ̀ tiwọn, tí a pín gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

15 ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko. Wọ́n sì ti pín in ní ìdílé-ìdílé.”

Àwọn Olórí tí Yóo Pín Ilẹ̀ náà

16 OLUWA sọ fún Mose pé,

17 “Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ni yóo pín ilẹ̀ náà fun yín.

18 Mú olórí kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”

19 Àwọn olórí náà nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Juda, a yan Kalebu ọmọ Jefune.

20 Láti inú ẹ̀yà Simeoni, a yan Ṣemueli ọmọ Amihudu.

21 Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, a yan Elidadi ọmọ Kisiloni.

22 Láti inú ẹ̀yà Dani, a yan Buki ọmọ Jogili.

23 Láti inú ẹ̀yà Manase, a yan Hanieli ọmọ Efodu.

24 Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, a yan Kemueli ọmọ Ṣifitani.

25 Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a yan Elisafani ọmọ Parinaki.

26 Láti inú ẹ̀yà Isakari, a yan Palitieli ọmọ Asani.

27 Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, a yan Ahihudu ọmọ Ṣelomi.

28 Láti inú ẹ̀yà Nafutali, a yan Pedaheli ọmọ Amihudu.

29 Àwọn ni OLUWA pàṣẹ fún láti pín ilẹ̀ ìní náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 35

Àwọn Ìlú tí A Fún Àwọn Ọmọ Lefi

1 Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko, OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ninu ilẹ̀ ìní wọn, kí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọn yóo máa gbé, kí wọ́n sì fún wọn ní ilẹ̀ pápá yíká àwọn ìlú wọnyi.

3 Àwọn ìlú náà yóo jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, wọn óo máa gbébẹ̀. Ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú náà ká yóo wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati mààlúù wọn.

4 Kí ilẹ̀ pápá tí yóo yí àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi ká jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ láti ibi odi ìlú wọn siwaju.

5 Lẹ́yìn odi ìlú kọ̀ọ̀kan, kí ẹ wọn ẹgbaa igbọnwọ ní ìhà kọ̀ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìhà gúsù, ati ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati ìhà àríwá; kí ìlú wà ní ààrin. Ilẹ̀ tí ẹ wọ̀n yìí ni yóo jẹ́ ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.

6 Ninu àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi, mẹfa ninu wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Lẹ́yìn ìlú mẹfa yìí, ẹ óo tún fún wọn ní ìlú mejilelogoji pẹlu ilẹ̀ tí ó yí wọn ká.

7 Gbogbo ìlú tí ẹ óo fún wọn yóo jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu ilẹ̀ pápá tí ó yí wọn ká.

8 Bí ilẹ̀ ìní olukuluku ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli bá ti tóbi tó, bẹ́ẹ̀ ni iye ìlú tí wọn yóo fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi yóo pọ̀ tó.”

Àwọn Ìlú-Ààbò

9 OLUWA sọ fún Mose pé,

10 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí wọ́n bá ré Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani,

11 kí wọ́n yan ìlú mẹfa fún ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ.

12 Yóo jẹ́ ibi ààbò fún ẹni tí ó paniyan, bí arakunrin ẹni tí ó pa bá fẹ́ gbẹ̀san, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan títí yóo fi dúró níwájú ìjọ eniyan Israẹli fún ìdájọ́.

13 Ẹ óo yan ìlú mẹfa fún èyí.

14 Mẹta ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani ati mẹta ní ilẹ̀ Kenaani.

15 Wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ sibẹ.

16 “Ṣugbọn bí ẹnìkan bá fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni ẹni tí ó fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

17 Bí ó bá sọ òkúta lu arakunrin rẹ̀ tí arakunrin náà sì kú, apànìyàn ni; pípa ni wọn yóo pa òun náà.

18 Tabi tí ó bá fi ohun ìjà olóró lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

19 Arakunrin ẹni tí a pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.

20 “Bí ẹnìkan bá kórìíra arakunrin rẹ̀, tí ó sì fi ohun ìjà gún un, tabi tí ó ju nǹkan lù ú láti ibi tí ó sápamọ́ sí, tí ẹni náà bá kú,

21 tabi tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lù ú pẹlu ibinu tí ẹni náà sì kú. Apànìyàn náà yóo jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, yóo sì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Arakunrin ẹni tí ó pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.

22 “Ṣugbọn bí ẹnìkan bá ṣèèṣì paniyan, tí kì í ṣe pẹlu ìríra, kì báà jẹ́ pé ó fi ohun ìjà gún un, tabi kí ó ṣèèṣì ju nǹkan lù ú,

23 tabi bí ẹnìkan bá ṣèèṣì sọ òkúta láì wo ibi tí ó sọ òkúta náà sí, tí òkúta náà sì pa eniyan tí kì í ṣe pé ó ti fẹ́ pa olúwarẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀,

24 kí ìjọ eniyan Israẹli ṣe ìdájọ́ láàrin ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan ati arakunrin ẹni tí wọ́n pa, tí ó fẹ́ gbẹ̀san, gẹ́gẹ́ bí ìlànà yìí.

25 Kí ìjọ eniyan gba ẹni tí ó paniyan náà lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí wọ́n mú un pada lọ sí ìlú ààbò rẹ̀. Níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí tí olórí alufaa tí a fi òróró yàn yóo fi kú.

26 Ṣugbọn bí apànìyàn náà bá rékọjá odi ìlú ààbò rẹ̀,

27 tí arakunrin ẹni tí ó pa bá rí i tí ó sì pa á, olùgbẹ̀san náà kì yóo ní ẹ̀bi;

28 nítorí pé apànìyàn náà gbọdọ̀ dúró ní ìlú ààbò rẹ̀ títí tí olórí alufaa yóo fi kú, lẹ́yìn náà, ó lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

29 Èyí yóo jẹ́ ìlànà ati òfin fun yín láti ìrandíran yín níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

30 “Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn.

31 Kí ẹ má ṣe gba owó ìtanràn lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa òun náà.

32 Bí apànìyàn kan bá sá lọ sí ìlú ààbò, ẹ kò gbọdọ̀ gba owó ìtanràn lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó baà lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ṣáájú ikú olórí alufaa.

33 Bí ẹ bá ṣe èyí, ẹ óo sọ ilẹ̀ yín di aláìmọ́ nítorí pé ìpànìyàn a máa sọ ilẹ̀ di àìmọ́. Ikú apànìyàn nìkan ni ó sì lè ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilẹ̀ tí ó ti di àìmọ́ nípa ìpànìyàn.

34 Ẹ má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, àní, ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli láàrin àwọn tí èmi OLUWA ń gbé.”

Categories
NỌMBA

NỌMBA 36

Ogún Àwọn Obinrin Abilékọ

1 Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ati ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, wá sọ́dọ̀ Mose ati àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli,

2 wọ́n ní, “OLUWA pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi gègé pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan Israẹli. Ó sì pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi ilẹ̀-ìní arakunrin wa Selofehadi fún àwọn ọmọbinrin rẹ̀.

3 Ṣugbọn bí wọ́n bá lọ́kọ lára ẹ̀yà Israẹli mìíràn, a ó gba ilẹ̀-ìní wọn kuro ninu ilẹ̀-ìní awọn baba wa, ilẹ̀-ìní wọn yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ wa dínkù.

4 Nígbà tí ọdún jubili bá kò, tí a óo dá gbogbo ilẹ̀-ìní pada fún àwọn tí wọ́n ni wọ́n, ilẹ̀-ìní àwọn ọmọbinrin Selofehadi yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ tiwa dínkù.”

5 Mose bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí fún un, pé, “Ohun tí ẹ̀yà Manase sọ dára,

6 nítorí náà OLUWA wí pé àwọn ọmọbinrin Selofehadi ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wù wọ́n, ṣugbọn ó gbọdọ̀ jẹ́ láti inú ẹ̀yà wọn.

7 Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

8 Obinrin tí ó bá ní ilẹ̀-ìní gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà rẹ̀, kí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli lè máa jogún ilẹ̀ ìní baba rẹ̀.”

9 Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

10 Àwọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA fún Mose;

11 Mahila, Tirisa, Hogila, Milika ati Noa fẹ́ ọkọ láàrin àwọn arakunrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.

12 Wọ́n fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, ilẹ̀-ìní wọn sì dúró ninu ẹ̀yà baba wọn.

13 Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA ti pa láṣẹ fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ní òdìkejì Jẹriko.