Categories
NỌMBA

NỌMBA 20

Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀ ní Kadeṣi

1 Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí.

2 Kò sí omi fún àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n ṣe ibùdó sí, wọ́n sì kó ara wọn jọ sí Mose ati Aaroni.

3 Wọ́n ń kùn pé: “Ìbá sàn fún wa bí ó bá jẹ́ pé a ti kú nígbà tí àwọn arakunrin wa kú níwájú OLUWA.

4 Kí ló dé tí ẹ fi mú àwọn eniyan OLUWA wá sinu aṣálẹ̀ yìí? Ṣé kí àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa lè kú ni?

5 Kí ló dé tí ẹ fi mú wa wá láti Ijipti sí ibi burúkú yìí, kò sí ọkà, kò sí èso ọ̀pọ̀tọ́, tabi èso àjàrà tabi èso pomegiranate, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi mímu.”

6 Mose ati Aaroni kúrò níwájú àwọn eniyan náà, wọ́n lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, wọ́n dojúbolẹ̀, ògo OLUWA sì farahàn.

7 OLUWA sọ fún Mose pé,

8 “Mú ọ̀pá tí ó wà níwájú Àpótí Majẹmu, kí ìwọ ati Aaroni kó àwọn eniyan náà jọ, kí o sọ̀rọ̀ sí àpáta níwájú wọn, àpáta náà yóo sì tú omi jáde. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe fún àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní omi.”

9 Mose lọ mú ọ̀pá náà níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

10 Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?”

11 Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu.

12 Ṣugbọn OLUWA bínú sí Mose ati Aaroni, ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbà mí gbọ́, ẹ kò sì fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà, ẹ̀yin kọ́ ni yóo kó wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fún wọn.”

13 Èyí ni omi Meriba, nítorí níbẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbolohun asọ̀ pẹlu OLUWA, tí OLUWA sì fi ara rẹ̀ hàn wọ́n pé mímọ́ ni òun.

Ọba Edomu kò Jẹ́ kí Àwọn Ọmọ Israẹli Kọjá

14 Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa.

15 Bí àwọn baba ńlá wa ṣe lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ará Ijipti lo àwọn baba ńlá wa ati àwa náà ní ìlò ẹrú.

16 Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ.

17 Jọ̀wọ́ gbà wá láàyè kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu oko yín tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi inú kànga yín. Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, a kò ní yà sí ọ̀tún tabi òsì títí tí a óo fi kọjá ilẹ̀ rẹ.”

18 Ṣugbọn àwọn ará Edomu dáhùn pé, “A kò ní jẹ́ kí ẹ gba ilẹ̀ wa kọjá, bí ẹ bá sì fẹ́ kọjá pẹlu agídí, a óo ba yín jagun.”

19 Àwọn ọmọ Israẹli ní, “Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, bí àwa tabi ẹran wa bá tilẹ̀ mu omi yín, a óo sanwó rẹ̀. Ohun kan tí a sá fẹ́ ni pé kí ẹ jẹ́ kí á kọjá.”

20 Àwọn ará Edomu tún dáhùn pé, “Rárá o, ẹ kò lè kọjá.” Wọ́n sì jáde pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun ati agbára ogun láti lọ dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Israẹli.

21 Nígbà tí àwọn ará Edomu kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli gba ilẹ̀ wọn kọjá, wọ́n bá gba ọ̀nà ibòmíràn.

Ikú Aaroni

22 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Kadeṣi, wọ́n wá sí òkè Hori

23 ní agbègbè ilẹ̀ Edomu. Níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose ati Aaroni pé,

24 “Níhìn-ín ni Aaroni yóo kú sí, kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí pé n óo fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ̀yin mejeeji lòdì sí àṣẹ mi ní Meriba.

25 Nítorí náà mú Aaroni ati ọmọ rẹ̀ Eleasari wá sórí òkè Hori.

26 Níbẹ̀ ni kí o ti bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, kí o gbé e wọ Eleasari. Níbẹ̀ ni Aaroni óo kú sí.”

27 Mose ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, gbogbo wọn sì gòkè Hori lọ níwájú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

28 Mose bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, ó gbé e wọ Eleasari. Aaroni sì kú sí orí òkè náà, Mose ati Eleasari sì sọ̀kalẹ̀.

29 Nígbà tí àwọn eniyan náà mọ̀ pé Aaroni ti kú, wọ́n ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 21

Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Kenaani

1 Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani tí ń gbé ìhà gúsù ní Nẹgẹbu Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń gba ọ̀nà Atarimu bọ̀, ó lọ bá wọn jagun, ó sì kó ninu wọn lẹ́rú.

2 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, Bí ó bá ti àwọn lẹ́yìn tí àwọn bá ṣẹgun àwọn eniyan náà, àwọn óo pa àwọn eniyan náà run patapata.

3 OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima.

Ejò Idẹ

4 Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà,

5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.”

6 OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú.

7 Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà.

8 OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.”

9 Mose bá rọ ejò idẹ kan, ó gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá ti wò ó, a sì yè.

Láti Òkè Hori sí Àfonífojì Moabu

10 Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò níbẹ̀, wọ́n pa àgọ́ wọn sí Obotu.

11 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n pa àgọ́ sí Òkè-Abarimu ní aṣálẹ̀ tí ó wà níwájú Moabu, ní ìhà ìlà oòrùn.

12 Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ pa àgọ́ sí àfonífojì Seredi.

13 Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori.

14 Nítorí náà ni a ṣe kọ ọ́ sinu Ìwé Ogun OLUWA pé:

“Ìlú Wahebu ní agbègbè Sufa,

ati àwọn àfonífojì Arinoni,

15 ati ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn àfonífojì náà

tí ó lọ títí dé ìlú Ari,

tí ó lọ dé ààlà Moabu.”

16 Láti ibẹ̀, wọ́n ṣí lọ sí Beeri, níbi kànga tí ó wà níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose pé, “Pe àwọn eniyan náà jọ, n óo sì fún wọn ní omi.”

17 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí pe:

“Ẹ sun omi jáde, ẹ̀yin kànga!

Ẹ máa kọrin sí i!

18 Kànga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́,

tí àwọn olórí wà

pẹlu ọ̀pá àṣẹ ọba ati ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ wọn.”

Wọ́n sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀ Matana.

19 Láti Matana, wọ́n ṣí lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli wọ́n ṣí lọ sí Bamotu,

20 láti Bamotu wọ́n ṣí lọ sí àfonífojì tí ó wà ní ilẹ̀ àwọn Moabu ní ìsàlẹ̀ òkè Pisiga tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.

Ìṣẹ́gun lórí Ọba Sihoni ati Ọba Ogu

21 Àwọn ọmọ Israẹli bá ranṣẹ sí Sihoni ọba àwọn ará Amori pé,

22 “Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

23 Sihoni kò gbà kí àwọn ọmọ Israẹli gba orí ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Ṣugbọn ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Jahasi ninu aṣálẹ̀.

24 Àwọn ọmọ Israẹli pa pupọ ninu wọn, wọ́n gba ilẹ̀ wọn láti odò Arinoni lọ dé odò Jaboku títí dé ààlà àwọn ará Amoni. Wọn kò gba ilẹ̀ àwọn ará Amoni nítorí pé wọ́n jẹ́ alágbára.

25 Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ìlú àwọn ará Amori, Heṣiboni ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, wọ́n sì ń gbé inú wọn.

26 Heṣiboni ni olú ìlú Sihoni, ọba àwọn ará Amori. Ọba yìí ni ó bá ọba Moabu jà, ó sì gba ilẹ̀ rẹ̀ títí dé odò Arinoni.

27 Ìdí èyí ni àwọn akọrin òwe ṣe ń kọrin pé:

“Wá sí Heṣiboni!

Jẹ́ kí á tẹ ìlú ńlá Sihoni dó,

kí á sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

28 Ní àkókò kan, láti ìlú Heṣiboni,

àwọn ọmọ ogun Sihoni jáde lọ bí iná;

wọ́n run ìlú Ari ní Moabu,

ati àwọn oluwa ibi gíga Arinoni.

29 Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé!

Ẹ di ẹni ìparun, ẹ̀yin ọmọ oriṣa Kemoṣi!

Ó ti sọ àwọn ọmọkunrin yín di ẹni tí ń sálọ fún ààbò;

ó sì sọ àwọn ọmọbinrin yín di ìkógun

fún Sihoni ọba àwọn ará Amori.

30 Ṣugbọn nisinsinyii, a ti pa ìrandíran wọn run,

láti Heṣiboni dé Diboni,

láti Naṣimu dé Nofa lẹ́bàá Medeba.”

31 Àwọn ọmọ Israẹli sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ àwọn ará Amori.

32 Mose rán eniyan lọ ṣe amí Jaseri, wọ́n sì gba àwọn ìlú agbègbè rẹ̀, wọ́n lé àwọn ará Amori tí ń gbé inú rẹ̀ kúrò.

33 Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣí, wọ́n gba ọ̀nà Baṣani. Ogu ọba Baṣani sì bá wọn jagun ní Edirei.

34 Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Má bẹ̀rù rẹ̀, mo ti fi òun ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Kí o ṣe é bí o ti ṣe Sihoni ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni.”

35 Àwọn ọmọ Israẹli pa Ogu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo eniyan rẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 22

Ọba Moabu Ranṣẹ Pe Balaamu

1 Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko.

2 Nígbà tí Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu rí gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli ṣe sí àwọn ará Amori,

3 ẹ̀rù wọn ba òun ati àwọn eniyan rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí pé wọ́n pọ̀. Jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn ará Moabu nítorí àwọn ọmọ Israẹli.

4 Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.”

5 Nítorí náà, Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu ranṣẹ lọ pe Balaamu ọmọ Beori ní Petori lẹ́bàá Odò Yufurate ní ilẹ̀ Amawi pé, “Àwọn eniyan kan jáde ti ilẹ̀ Ijipti wá, wọ́n pàgọ́ sórí ilẹ̀ mi, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà.

6 Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!”

7 Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un.

8 Balaamu sọ fún wọn pé, “Ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ọ̀la, n óo sọ ohun tí OLUWA bá sọ fún mi fun yín.” Àwọn àgbààgbà náà sì dúró lọ́dọ̀ Balaamu.

9 Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó bi í pé, “Àwọn ọkunrin wo ni wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?”

10 Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé,

11 àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.”

12 Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.”

13 Nígbà tí Balaamu jí ní òwúrọ̀, ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Balaki pé, “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín nítorí OLUWA ti sọ pé n kò gbọdọ̀ ba yín lọ.”

14 Nígbà náà ni wọ́n pada lọ sọ́dọ̀ Balaki, wọn sì sọ fún un wí pé Balaamu kọ̀, kò bá àwọn wá.

15 Balaki tún rán àwọn àgbààgbà mìíràn tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì ṣe pataki ju àwọn ti iṣaaju lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu.

16 Wọ́n jíṣẹ́ fún un pé Balaki ní, “Mo bẹ̀ ọ́, má jẹ́ kí ohunkohun dí ọ lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ mi.

17 N óo sọ ọ́ di eniyan pataki, ohunkohun tí o bá sọ, n óo ṣe é. Jọ̀wọ́ wá bá mi ṣépè lé àwọn eniyan wọnyi.”

18 Balaamu dá àwọn oníṣẹ́ Balaki lóhùn pé, “Balaki ìbáà fún mi ní ààfin rẹ̀, kí ààfin náà sì kún fún fadaka ati wúrà, n kò ní lòdì sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun mi, ninu nǹkan kékeré tabi nǹkan ńlá.

19 Ṣugbọn ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, kí n lè mọ ohun tí OLUWA yóo tún bá mi sọ.”

20 Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọkunrin wọnyi wá bẹ̀ ọ́ pé kí o bá wọn lọ, máa bá wọn lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni o gbọdọ̀ ṣe.”

21 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaamu di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì bá àwọn àgbààgbà Moabu lọ.

Balaamu ati Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Rẹ̀

22 OLUWA bínú sí Balaamu nítorí pé ó bá wọn lọ. Bí ó ti ń lọ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ meji, angẹli OLUWA dúró ní ojú ọ̀nà rẹ̀ ó dínà fún un.

23 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli tí ó dúró ní ọ̀nà pẹlu idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu igbó. Balaamu lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà láti darí rẹ̀ sójú ọ̀nà.

24 Angẹli náà tún dúró ní ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà meji, ògiri sì wà ní ìhà mejeeji.

25 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí i, ó fún ara rẹ̀ mọ́ ògiri, ẹsẹ̀ Balaamu sì fún mọ́ ògiri pẹlu, Balaamu bá tún lù ú.

26 Lẹ́ẹ̀kan sí i, angẹli náà lọ siwaju, ó dúró ní ọ̀nà tóóró kan níbi tí kò sí ààyè rárá láti yà sí.

27 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli náà, ó wó lulẹ̀ lábẹ́ Balaamu. Inú bí Balaamu gidigidi, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.

28 Nígbà náà ni OLUWA la kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lóhùn ó sì sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo fi ṣe ọ́ tí o fi lù mí nígbà mẹta?”

29 Balaamu dáhùn pé, “Nítorí tí ò ń fi mí ṣẹ̀sín, bí ó bá jẹ́ pé idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ọ́.”

30 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà dáhùn pé, “Ṣebí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni mí, tí o sì ti ń gùn mí láti iye ọjọ́ yìí títí di òní? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”

Balaamu dáhùn pé, “Rárá o.”

31 Nígbà náà ni OLUWA la Balaamu lójú láti rí angẹli tí ó dúró lójú ọ̀nà pẹlu idà lọ́wọ́ rẹ̀, Balaamu sì dojúbolẹ̀.

32 Angẹli náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹta? Mo wá láti dínà fún ọ nítorí pé kò yẹ kí o rin ìrìn àjò yìí.

33 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ rí mi, ó sì yà fún mi nígbà mẹta, bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, ǹ bá ti pa ọ́, ǹ bá sì dá òun sí.”

34 Balaamu dá angẹli náà lóhùn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, n kò sì mọ̀ pé o dúró lójú ọ̀nà láti dínà fún mi. Ó dára, bí o kò bá fẹ́ kí n lọ, n óo pada.”

35 Angẹli OLUWA sì dáhùn pé, “Máa bá àwọn ọkunrin náà lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni kí o sọ.” Balaamu sì bá wọn lọ.

Balaki Lọ Pàdé Balaamu

36 Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà létí odò Arinoni ní ààlà ilẹ̀ Moabu.

37 Balaki wí fún un pé, “Kí ló dé tí o kò fi wá nígbà tí mo ranṣẹ sí ọ lákọ̀ọ́kọ́? Ṣé o rò pé n kò lè sọ ọ́ di ẹni pataki ni?”

38 Balaamu dáhùn pé, “Wíwá tí mo wá yìí, èmi kò ní agbára láti sọ ohunkohun bíkòṣe ohun tí OLUWA bá sọ fún mi.”

39 Balaamu bá Balaki lọ sí ìlú Kiriati-husotu.

40 Níbẹ̀ ni Balaki ti fi akọ mààlúù ati aguntan ṣe ìrúbọ, ó sì fún Balaamu ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ninu ẹran náà.

41 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaki mú Balaamu lọ sí ibi gegele Bamotu Baali níbi tí ó ti lè rí apá kan àwọn ọmọ Israẹli.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 23

Àsọtẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ tí Balaamu Sọ

1 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.”

2 Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

3 Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan.

4 Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”

5 OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un.

6 Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà.

7 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:

“Láti Aramu, Balaki mú mi wá,

ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn.

Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu,

kí o sì fi Israẹli ré.’

8 Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè,

báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e?

Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé,

báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè?

9 Mo rí wọn láti òkè gíga,

mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè.

Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé;

wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

10 Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn?

Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli?

Jẹ́ kí n kú ikú olódodo,

kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.”

11 Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”

12 Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Keji tí Balaamu Sọ

13 Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”

14 Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”

16 OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ.

17 Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀.

18 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní:

“Balaki, dìde, wá gbọ́,

fetí sí mi, ọmọ Sipori;

19 Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́,

bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada.

Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe,

bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀.

20 OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn,

Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò.

21 Kò rí ìparun ninu Jakọbu,

bẹ́ẹ̀ ni kò rí ìpọ́njú níwájú Israẹli.

OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn,

Òun sì ni ọba wọn.

22 OLUWA mú wọn jáde láti Ijipti wá,

Ó sì ń jà fún wọn bí àgbáǹréré.

23 Kò sí òògùn kan tí ó lè ran Jakọbu,

bẹ́ẹ̀ ni àfọ̀ṣẹ kan kò lè ran Israẹli.

Wò ó! Àwọn eniyan yóo máa wí nípa Israẹli pé,

‘Wo ohun tí Ọlọrun ṣe!’

24 Wo orílẹ̀-èdè Israẹli! Ó dìde dúró bí abo kinniun,

ó sì gbé ara rẹ̀ sókè bíi kinniun.

Kò ní sinmi títí yóo fi jẹ ẹran tí ó pa tán,

tí yóo sì fi mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tán.”

25 Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti kọ̀, tí o kò ṣépè lé wọ́n, má súre fún wọn.”

26 Balaamu dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ n kò tí sọ fún ọ pé ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ?”

Àsọtẹ́lẹ̀ Kẹta Tí Balaamu Sọ

27 Balaki sọ fún Balaamu pé, “N óo mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá Ọlọrun yóo gbà pé kí o bá mi ṣépè lé àwọn eniyan náà níbẹ̀.”

28 Ó bá mú Balaamu lọ sórí òkè Peori tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.

29 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ ìrúbọ meje kí o sì mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje wá.”

30 Balaki ṣe ohun tí Balaamu sọ, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 24

1 Nígbà tí Balaamu rí i pé OLUWA ń súre fún àwọn ọmọ Israẹli, kò lọ bíi ti iṣaaju láti bá OLUWA pàdé. Ṣugbọn ó kọjú sí aṣálẹ̀,

2 ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e,

3 ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní,

“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,

ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú;

4 ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,

mo sì lajú sílẹ̀ kedere rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.

Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀.

5 Báwo ni àgọ́ rẹ ti dára tó ìwọ Jakọbu,

ati ibùdó rẹ ìwọ Israẹli!

6 Ó dàbí àfonífojì tí ó tẹ́ lọ bẹẹrẹ,

bí ọgbà tí ó wà lẹ́bàá odò.

Ó dàbí àwọn igi aloe tí OLUWA gbìn,

ati bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

7 Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀,

omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀;

àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu.

Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ,

ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga.

8 Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá,

ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré.

Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run,

wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.

9 Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun,

bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde?

Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli,

ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!”

10 Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta!

11 Nítorí náà máa lọ sí ilé rẹ. Mo ti pinnu láti sọ ọ́ di eniyan pataki tẹ́lẹ̀ ni, ṣugbọn OLUWA ti dí ọ lọ́nà.”

12 Balaamu bá dáhùn pé: “Ṣebí mo ti sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí o rán wá pé,

13 bí o tilẹ̀ fún mi ní ààfin rẹ, tí ó sì kún fún fadaka ati wúrà, sibẹsibẹ, n kò ní agbára láti ṣe ohunkohun ju ohun tí OLUWA bá sọ lọ. N kò lè dá ṣe rere tabi burúkú ní agbára mi, ohun tí OLUWA bá sọ ni n óo sọ.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Ìkẹyìn tí Balaamu Sọ

14 Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.”

15 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé,

“Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí,

ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú.

16 Ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun,

tí ó ní ìmọ̀ ẹni tí ó ga jùlọ,

tí ó sì ń rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare.

Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ kò wà ní dídì.

17 Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ,

mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ.

Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu,

ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá;

yóo run àwọn àgbààgbà Moabu,

yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀.

18 Yóo ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní Edomu,

yóo sì gba ilẹ̀ wọn.

Yóo ṣẹgun àwọn ará Seiri tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wọn,

yóo sì gba ilẹ̀ wọn.

Israẹli yóo sì máa pọ̀ sí i ní agbára.

19 Láti inú ìdílé Jakọbu ni àṣẹ ọba yóo ti jáde wá,

yóo sì pa àwọn tí ó kù ninu ìlú náà run.”

20 Nígbà tí ó wo Amaleki, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé:

“Amaleki ni orílẹ̀-èdè tí ó lágbára jùlọ,

Ṣugbọn yóo ṣègbé níkẹyìn.”

21 Nígbà tí ó wo àwọn ará Keni, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé:

“Ibi ìpamọ́ tí ẹ̀ ń gbé

dàbí ìtẹ́ tí ó wà lórí àpáta gíga.

22 Ṣugbọn ẹ̀yin ará Keni yóo di ẹni ìparun,

àwọn ará Aṣuri yóo ko yín lẹ́rú.”

23 Balaamu tún fi òwe sọ ọ̀rọ̀ wọnyi:

“Ta ni yóo là nígbà tí Ọlọrun bá ṣe nǹkan wọnyi?

24 Àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n kún fún ọmọ ogun yóo wá láti Kitimu,

wọn yóo borí àwọn ará Aṣuri ati Eberi,

ṣugbọn Kitimu pàápàá yóo ṣègbé.”

25 Balaamu bá dìde, ó pada sí ilé rẹ̀; Balaki náà bá pada sí ilé rẹ̀.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 25

Àwọn Ọmọ Israẹli ní Peori

1 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí àfonífojì Ṣitimu, àwọn ọkunrin wọn ń bá àwọn ọmọbinrin Moabu tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe àgbèrè.

2 Àwọn obinrin wọnyi a sì máa pè wọ́n lọ síbi àsè ìbọ̀rìṣà. Wọn a máa jẹ oúnjẹ wọn, wọn a sì ma bá wọn bọ oriṣa wọn.

3 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe da ara wọn pọ̀ mọ́ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori, ibinu OLUWA sì ru sí wọn.

4 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí Israẹli, kí o so wọ́n kọ́ sórí igi ninu oòrùn títí tí wọn óo fi kú níwájú OLUWA. Nígbà náà ni n kò tó ni bínú sí àwọn eniyan náà mọ́.”

5 Mose sì wí fún àwọn onídàájọ́ Israẹli pé, “Olukuluku yín gbọdọ̀ pa àwọn eniyan rẹ̀ tí ó lọ sin oriṣa Baali tí ó wà ní Peori.”

6 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli mú ọmọbinrin Midiani wọlé lójú Mose ati gbogbo àwọn eniyan, níbi tí wọ́n ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA.

7 Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, rí i, ó dìde láàrin àwọn eniyan, ó sì mú ọ̀kọ̀ kan,

8 ó tọ ọkunrin náà lọ ninu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi ọ̀kọ̀ náà gún òun ati obinrin náà ní àgúnyọ. Àjàkálẹ̀ àrùn sì dúró láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

9 Àwọn tí wọ́n kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn náà jẹ́ ẹgbaa mejila (24,000).

10 OLUWA sọ fún Mose pé,

11 “N kò ní bínú sí Israẹli mọ nítorí ohun tí Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, ṣe. Ó kọ̀ láti gba ìbọ̀rìṣà láàyè, nítorí náà ni n kò ṣe ní fi ibinu pa àwọn ọmọ Israẹli run.

12 Nítorí náà, sọ fún un pé mo bá a dá majẹmu alaafia.

13 Majẹmu náà ni pé mo ti yan òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ láti máa ṣe alufaa ní Israẹli títí lae nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọrun rẹ̀, ó sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan Israẹli.”

14 Orúkọ ọmọ Israẹli tí ó pa pẹlu ọmọbinrin Midiani ni Simiri, ọmọ Salu, olórí ilé kan ninu ẹ̀yà Simeoni.

15 Orúkọ ọmọbinrin Midiani náà ni Kosibi, ọmọ Suri, baálé ilé kan ní ilẹ̀ Midiani.

16 OLUWA sọ fún Mose pé,

17 “Kọlu àwọn ará Midiani, kí o sì pa wọ́n run

18 nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati títàn tí wọ́n tàn yín ní Peori, ati nítorí ọ̀rọ̀ Kosibi, ọmọ baálé kan ní ilẹ̀ Midiani, arabinrin wọn, tí a pa nígbà àjàkálẹ̀ àrùn ti Peori.”

Categories
NỌMBA

NỌMBA 26

Ètò Ìkànìyàn Keji

1 Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn náà, OLUWA sọ fún Mose ati Eleasari alufaa ọmọ Aaroni pé,

2 “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.”

3 Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko,

4 wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:

5 Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu,

6 ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi.

7 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730).

8 Palu bí Eliabu,

9 Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA.

10 Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.

11 Ṣugbọn àwọn ọmọ Kora kò kú.

12 Àwọn ọmọ Simeoni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Nemueli, ìdílé Jamini, ati ìdílé Jakini;

13 ìdílé Sera ati ti Ṣaulu.

14 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba (22,200).

15 Àwọn ọmọ Gadi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Sefoni, ìdílé Hagi, ati ìdílé Ṣuni;

16 ìdílé Osini, ati ìdílé Eri;

17 ìdílé Arodu ati ìdílé Areli.

18 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Gadi jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).

19 Àwọn ọmọ Juda ni Eri ati Onani. Eri ati Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.

20 Àwọn ọmọ Juda ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣela, ìdílé Peresi, ati ìdílé Sera.

21 Àwọn ọmọ Peresi nìwọ̀nyí: ìdílé Hesironi ati ìdílé Hamuli.

22 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbaa mejidinlogoji ó lé ẹẹdẹgbẹta (76,500).

23 Àwọn ọmọ Isakari ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Tola, ìdílé Pua;

24 ìdílé Jaṣubu ati ìdílé Ṣimironi.

25 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé ọọdunrun (64,300).

26 Àwọn ọmọ Sebuluni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Seredi, ìdílé Eloni ati ìdílé Jaleeli.

27 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹta (60,500).

28 Àwọn ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: Manase ati Efuraimu.

29 Àwọn ọmọ Manase ni: ìdílé Makiri, Makiri bí Gileadi.

30 Àwọn ọmọ Gileadi nìwọ̀nyí: ìdílé Ieseri, ìdílé Heleki;

31 ìdílé Asirieli, ìdílé Ṣekemu;

32 ìdílé Ṣemida, ìdílé Heferi.

33 Selofehadi ọmọ Heferi kò bí ọmọkunrin kankan, àfi ọmọbinrin. Orúkọ àwọn ọmọbinrin Selofehadi ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa.

34 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ìdílé Manase jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (52,700).

35 Àwọn ọmọ Efuraimu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣutela, ìdílé Bekeri ati ìdílé Tahani.

36 Àwọn ọmọ Ṣutela nìwọ̀nyí, ìdílé Erani.

37 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Efuraimu jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (32,500). Àwọn ni ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé.

38 Àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Bela, ìdílé Aṣibeli, ìdílé Ahiramu;

39 ìdílé Ṣefufamu ati ìdílé Hufamu.

40 Àwọn ọmọ Bela nìwọ̀nyí: ìdílé Aridi ati ìdílé Naamani.

41 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé ẹgbẹjọ (45,600).

42 Àwọn ọmọ Dani ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣuhamu.

43 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé irinwo (64,400).

44 Àwọn ọmọ Aṣeri ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Imina, ìdílé Iṣifi ati ìdílé Beria.

45 Àwọn ọmọ Beria ni: ìdílé Heberi ati ìdílé Malikieli.

46 Orúkọ ọmọ Aṣeri obinrin sì ni Sera.

47 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400).

48 Àwọn ọmọ Nafutali ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Jahiseeli, ìdílé Guni,

49 ìdílé Jeseri ati ìdílé Ṣilemu.

50 Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Nafutali jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé egbeje (45,400).

51 Gbogbo wọn ní àpapọ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (601,730).

52 OLUWA sọ fún Mose pé,

53 “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

54 Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn.

55 Gègé ni kí ẹ ṣẹ́, kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún olukuluku ẹ̀yà gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

56 Gègé ni kí ẹ ṣẹ́ kí ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ẹ̀yà tí ó pọ̀ ati àwọn ẹ̀yà kéékèèké.”

57 Àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Geriṣoni, ìdílé Kohati ati ìdílé Merari,

58 Àwọn ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí: ìdílé Libini, ìdílé Heburoni, ìdílé Mahili, ìdílé Muṣi ati ìdílé Kora. Kohati ni baba Amramu.

59 Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu.

60 Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

61 Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n rúbọ sí OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu iná tí kò mọ́.

62 Gbogbo àwọn ọmọkunrin tí a kà ninu ẹ̀yà Lefi láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹrun (23,000). Wọn kò kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nítorí pé wọn kò ní ilẹ̀ ìní ní Israẹli.

63 Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí.

64 Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó tíì dáyé ninu wọn nígbà tí Mose ati Aaroni alufaa, ka àwọn ọmọ Israẹli ní aṣálẹ̀ Sinai.

65 Nítorí pé OLUWA ti sọ pé gbogbo àwọn ti ìgbà náà ni yóo kú ninu aṣálẹ̀. Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua ọmọ Nuni nìkan ni ó kù lára wọn.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 27

Àwọn Ọmọbinrin Selofehadi

1 Nígbà náà ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa, àwọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, ti ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu,

2 lọ fi ẹjọ́ sun Mose ati Eleasari alufaa ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ pé,

3 “Baba wa kú sinu aṣálẹ̀ láìní ọmọkunrin kankan. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA, ṣugbọn ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni.

4 Kí ló dé tí orúkọ baba wa yóo fi parẹ́ kúrò ninu ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkunrin? Nítorí náà, ẹ fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn eniyan baba wa.”

5 Mose bá bá OLUWA sọ̀rọ̀ nípa wọn,

6 OLUWA sì sọ fún un pé,

7 “Ohun tí àwọn ọmọbinrin Selofehadi bèèrè tọ́, fún wọn ní ilẹ̀ ìní baba wọn láàrin àwọn eniyan baba wọn.

8 Sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnìkan bá kú láìní ọmọkunrin, àwọn ọmọbinrin rẹ̀ yóo jogún ilẹ̀ ìní rẹ̀.

9 Bí kò bá sì ní ọmọbinrin, ilẹ̀ ìní rẹ̀ yóo jẹ́ ti àwọn arakunrin rẹ̀.

10 Bí kò bá ní arakunrin, kí ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún àwọn arakunrin baba rẹ̀.

11 Bí baba rẹ̀ kò bá ní arakunrin, ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún ìbátan rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ ọn jùlọ ninu ìdílé rẹ̀. Ìbátan rẹ̀ yìí ni yóo jogún rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.”

Yíyan Joṣua láti Rọ́pò Mose

12 OLUWA sọ fún Mose pé, “Gun orí òkè Abarimu yìí lọ, kí o sì wo ilẹ̀ tí n óo fún àwọn ọmọ Israẹli.

13 Lẹ́yìn náà tí o bá ti wò ó tán, ìwọ náà yóo kú gẹ́gẹ́ bíi Aaroni arakunrin rẹ,

14 nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini).

15 Mose bá gbadura báyìí pé,

16 “OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè gbogbo nǹkan alààyè. Èmi bẹ̀ ọ́, yan ẹnìkan tí yóo máa ṣáájú àwọn eniyan wọnyi:

17 ẹni tí ó lè máa ṣáájú wọn lójú ogun, kí àwọn eniyan rẹ má baà wà bí aguntan tí kò ní olùṣọ́.”

18 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ẹni tí Ẹ̀mí èmi OLUWA wà ninu rẹ̀, gbé ọwọ́ rẹ lé e lórí,

19 kí o mú un wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan, kí o sì fún un ní àṣẹ lójú wọn.

20 Fún un ninu iṣẹ́ rẹ, kí àwọn ọmọ Israẹli lè tẹríba fún un.

21 Yóo máa gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Eleasari alufaa. Eleasari yóo sì máa lo Urimu ati Tumimu láti mọ ohun tí mo fẹ́. Ìtọ́ni Urimu ati Tumimu ni Eleasari yóo fi máa darí Joṣua ninu ohun gbogbo tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣe.”

22 Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un. Ó mú Joṣua wá siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo àwọn eniyan,

23 ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, ó sì fún un ní àṣẹ.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 28

Ẹbọ Àtìgbàdégbà

1 OLUWA sọ fún Mose

2 pé kí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn máa mú ọrẹ wá fún ohun ìrúbọ sí òun OLUWA ní àkókò rẹ̀, ati àwọn nǹkan tí wọn yóo máa fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn.

3 “Ọrẹ tí wọn óo máa mú wá fún ẹbọ sísun tí ẹ óo máa rú sí OLUWA nìwọ̀nyí: ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ sísun ojoojumọ:

4 Ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àárọ̀ ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ àṣáálẹ́,

5 pẹlu ìdámẹ́wàá ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró tí a gún pọ̀.

6 Èyí ni ẹbọ sísun ojoojumọ tí a ti fi ìlànà rẹ̀ lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

7 Ẹbọ ohun mímu rẹ̀ yóo máa jẹ́ idamẹrin òṣùnwọ̀n hini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. O óo sì ta ọtí líle náà sílẹ̀ lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ bí ẹbọ sí OLUWA.

8 Ní ìrọ̀lẹ́, kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ bíi ti ẹbọ ohun jíjẹ òwúrọ̀ pẹlu ẹbọ ohun mímu rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ìsinmi

9 “Ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ fi ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ pẹlu idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu.

10 Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun yìí ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi pẹlu ẹbọ ojoojumọ ati ẹbọ ohun mímu.

Ẹbọ Ọjọ́ Kinni Oṣù

11 “Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Àwọn nǹkan tí ẹ óo máa fi rúbọ ni: ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n.

12 Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan.

13 Ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí jẹ́ ẹbọ sísun olóòórùn dídùn fún OLUWA.

14 Kí ẹbọ ohun mímu jẹ́ ààbọ̀ òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún akọ mààlúù kan, ìdámẹ́ta òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún àgbò kan ati idamẹrin òṣùnwọ̀n hini ọtí waini fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí ni ìlànà ẹbọ sísun ti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.

15 Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ yìí, ẹ óo tún fi òbúkọ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí OLUWA.

Ẹbọ Àjọ̀dún Àjọ Àìwúkàrà

16 “Ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni Àjọ̀dún Ìrékọjá OLUWA.

17 Ọjọ́ kẹẹdogun oṣù náà ni ọjọ́ àjọ̀dún, ẹ óo máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ meje.

18 Ní ọjọ́ kinni àjọ̀dún náà ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

19 Kí ẹ máa fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí wọn kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

20 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,

21 ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

22 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.

23 Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ojoojumọ.

24 Báyìí ni ẹ óo ṣe rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA ní ojoojumọ fún ọjọ́ meje náà yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

25 Ní ọjọ́ keje ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

Ẹbọ Àjọ̀dún Ìkórè

26 “Ní ọjọ́ kinni àjọ̀dún ìkórè, nígbà tí ẹ óo bá mú ẹbọ ohun jíjẹ ti ọkà titun wá fún OLUWA, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

27 Kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji, ati àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

28 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò: ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,

29 ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

30 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.

31 Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi pẹlu ẹbọ ohun mímu wọn, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ojoojumọ.

Categories
NỌMBA

NỌMBA 29

Ẹbọ Àjọ̀dún Ọdún Titun

1 “Ní ọjọ́ kinni oṣù keje, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan. Ó jẹ́ ọjọ́ tí ẹ óo máa fun fèrè.

2 Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA.

3 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa kan fún àgbò;

4 ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan,

5 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.

6 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọjọ́ kinni oṣù, ati ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu ojoojumọ, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù

7 “Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

8 Kí ẹ fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù kan, ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

9 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan;

10 ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan,

11 ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín. Ẹ óo tún fi òbúkọ mìíràn rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ pẹlu.”

Ẹbọ Àjọ̀dún Àgọ́

12 “Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje yìí, ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò ní ṣe iṣẹ́ kankan fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún náà. Àjọ̀dún àyẹ́sí ni fún OLUWA.

13 Ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹtala, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA.

14 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo máa rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa, fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kọ̀ọ̀kan,

15 ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

16 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

17 “Ní ọjọ́ keji, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mejila, àgbò meji, ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

18 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni,

19 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

20 “Ní ọjọ́ kẹta, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mọkanla, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

21 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni;

22 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

23 “Ní ọjọ́ kẹrin, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹ́wàá, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

24 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ti ọjọ́ kinni;

25 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

26 “Ní ọjọ́ karun-un, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹsan-an, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

27 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni,

28 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

29 “Ní ọjọ́ kẹfa, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹjọ, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

30 Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni;

31 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

32 “Ní ọjọ́ keje, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meje, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.

33 Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni,

34 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

35 “Ní ọjọ́ kẹjọ ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì ní gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

36 Ẹ máa fi akọ mààlúù kan ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLÚWA.

37 Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ọjọ́ kinni;

38 pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

39 “Àwọn ni àwọn ẹbọ tí ẹ óo máa rú sí OLUWA ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín, pẹlu ẹ̀jẹ́ yín, ẹbọ ọrẹ àtinúwá yín, ati ẹbọ sísun yín, ẹbọ ohun jíjẹ yín, ati ẹbọ ohun mímu yín, ati ẹbọ alaafia yín.”

40 Mose sọ gbogbo rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.