Categories
NEHEMAYA

NEHEMAYA 10

1 Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ sí ìwé náà tí wọ́n sì fi èdìdì dì í nìwọ̀nyí: Nehemaya, gomina, ọmọ Hakalaya, ati Sedekaya.

2 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ alufaa wọnyi: Seraya, Asaraya, ati Jeremaya,

3 Paṣuri, Amaraya, ati Malikija,

4 Hatuṣi, Ṣebanaya, ati Maluki,

5 Harimu, Meremoti, ati Ọbadaya,

6 Daniẹli, Ginetoni, ati Baruku,

7 Meṣulamu, Abija, ati Mijamini,

8 Maasaya, Biligai, Ṣemaaya. Àwọn ni alufaa.

9 Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua ọmọ Asanaya, Binui ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Henadadi, ati Kadimieli,

10 ati àwọn arakunrin wọn: Ṣebanaya ati Hodaya, Kelita, Pelaaya, ati Hanani,

11 Mika, Rehobu, ati Haṣabaya,

12 Sakuri, Ṣerebaya, ati Ṣebanaya,

13 Hodaya, Bani, ati Beninu.

14 Àwọn ìjòyè wọn tí wọ́n fọwọ́ sí ìwé náà ni: Paroṣi, Pahati Moabu, Elamu, Satu, ati Bani,

15 Bunni, Asigadi, ati Bebai,

16 Adonija, Bigifai, ati Adini,

17 Ateri, Hesekaya ati Aṣuri,

18 Hodaya, Haṣumu, ati Besai,

19 Harifi, Anatoti, ati Nebai,

20 Magipiaṣi, Meṣulamu, ati Hesiri,

21 Meṣesabeli, Sadoku, ati Jadua,

22 Pelataya, Hanani, ati Anaaya,

23 Hoṣea, Hananaya, ati Haṣubu,

24 Haloheṣi, Pileha, ati Ṣobeki,

25 Rehumu, Haṣabina, ati Maaseaya,

26 Ahija, Hanani, ati Anani,

27 Maluki, Harimu, ati Baana.

Àdéhùn náà

28 Àwọn eniyan yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn akọrin, àwọn iranṣẹ tẹmpili ati àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun, àwọn iyawo wọn, àwọn ọmọ wọn ọkunrin, àwọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́njú mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,

29 wọ́n parapọ̀ pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn ọlọ́lá wọn; wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé àwọn ó máa pa òfin Ọlọrun mọ́, àwọn óo sì máa tẹ̀lé e, bí Mose iranṣẹ rẹ̀ ti fún wọn. Wọ́n óo máa ṣe gbogbo ohun tí OLUWA tíí ṣe Oluwa wọn paláṣẹ, wọn ó sì máa tẹ̀lé ìlànà ati òfin rẹ̀.

30 A kò ní fi àwọn ọmọ wa obinrin fún àwọn ọmọ àwọn àlejò tí ń gbé ilẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọ wa.

31 Bí wọn bá sì kó ọjà tabi oúnjẹ wá tà ní ọjọ́ ìsinmi, a kò ní rà á lọ́wọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tabi ní ọjọ́ mímọ́ kankan.

A óo sì yọ̀ǹda gbogbo èso ọdún keje keje, ati gbogbo gbèsè tí eniyan bá jẹ wá.

32 A óo sì tún fẹnu kò sí ati máa dá ìdámẹ́ta ṣekeli wá fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa lọdọọdun.

33 A óo máa pèsè burẹdi ìfihàn ati ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo, ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ati ti oṣù tuntun fún àwọn àsè tí wọ́n ti là sílẹ̀, ati fún gbogbo ohun mímọ́, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli kúrò, ati fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa.

34 A ti dìbò láàrin àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan, bí wọn yóo ṣe máa ru igi wá sí ilé Ọlọrun wa, ní oníléjilé, ní ìdílé ìdílé, ní àwọn àkókò tí a yàn lọdọọdun, tí wọn yóo fi máa rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin.

35 A ti gbà á bí ojúṣe wa pé àkọ́so èso ilẹ̀ wa ati àkọ́so gbogbo èso igi wa lọdọọdun, ni a óo máa gbé wá sí ilé OLUWA.

36 A óo máa mú àwọn àkọ́bí ọmọ wa, ati ti àwọn mààlúù wa lọ sí ilé Ọlọrun wa, fún àwọn alufaa tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àkọ́já ewébẹ̀ wa, ati àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn wa.

37 Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ kù, ati ọrẹ wa, èso gbogbo igi, ọtí waini, ati òróró. A óo máa kó wọn tọ àwọn alufaa lọ sí gbọ̀ngàn ilé Ọlọrun wa.

A óo sì máa mú ìdámẹ́wàá èso ilẹ̀ wa lọ fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n máa ń gba ìdámẹ́wàá káàkiri gbogbo ilẹ̀ wa.

38 Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni yóo wà pẹlu àwọn ọmọ Lefi nígbà tí àwọn ọmọ Lefi bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóo yọ ìdámẹ́wàá gbogbo ìdámẹ́wàá tí wọ́n bá gbà lọ sí ilé Ọlọrun wa. Wọn óo kó o sinu gbọ̀ngàn ninu ilé ìpa-nǹkan-mọ́-sí.

39 Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Lefi yóo dá oúnjẹ, waini ati òróró jọ sinu àwọn gbọ̀ngàn, níbi tí àwọn ohun èlò tí a ti yà sí mímọ́ fún lílò ní ilé Ọlọrun wa, pẹlu àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ati àwọn olùṣọ́ tẹmpili, ati àwọn akọrin.

A kò ní fi ọ̀rọ̀ ilé Ọlọrun wa falẹ̀.

Categories
NEHEMAYA

NEHEMAYA 11

Àwọn Eniyan Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

1 Àwọn olórí àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu, àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù dìbò láti yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá láti lọ máa gbé Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, àwọn mẹsan-an yòókù sì ń gbé àwọn ìlú yòókù.

2 Àwọn eniyan náà súre fún àwọn tí wọ́n fa ara wọn kalẹ̀ láti lọ máa gbé Jerusalẹmu.

3 Àwọn ìjòyè ní àwọn agbègbè wọn ń gbé Jerusalẹmu, ṣugbọn ní àwọn ìlú Juda, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ń gbé orí ilẹ̀ rẹ̀, ní ìlú wọn, títí kan àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn iranṣẹ tẹmpili, ati àwọn ìran iranṣẹ Solomoni.

4 Àwọn ọmọ Juda kan, ati àwọn ọmọ Bẹnjamini kan ń gbé Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ Juda náà ni: Ataaya, ọmọ Usaya, ọmọ Sakaraya, ọmọ Amaraya, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Mahalaleli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Pẹrẹsi.

5 Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya, ọmọ Baruku, ọmọ Kolihose, ọmọ Hasaya, ọmọ Adaya, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sakaraya, ọmọ ará Ṣilo.

6 Gbogbo àwọn ọmọ Peresi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jẹ́ akọni, wọ́n jẹ́ ọtalenirinwo ó lé mẹjọ (468).

7 Àwọn ọmọ Bẹnjamini ni: Salu ọmọ Meṣulamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaaya, ọmọ Kolaya, ọmọ Maaseaya, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaya.

8 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Gabai ati Salai. Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bẹnjamini wá jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mejidinlọgbọn (928).

9 Joẹli ọmọ Sikiri ni alabojuto wọn, Juda ọmọ Hasenua ni igbákejì rẹ̀ ní ìlú náà.

10 Àwọn alufaa ni: Jedaaya ọmọ Joiaribu ati Jakini;

11 Seraaya, ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí ilé Ọlọrun,

12 ati àwọn arakunrin wọn tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ ilé náà, wọ́n jẹ́ ẹgbẹrin lé mejilelogun (822).

Adaya ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelalaya, ọmọ Amisi, ọmọ Sakaraya, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija,

13 ati àwọn arakunrin rẹ̀, àwọn baálé baálé lápapọ̀ jẹ́ ojilerugba ó lé meji (242).

Amaṣisai, ọmọ Asareli, ọmọ Asai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Imeri,

14 ati àwọn arakunrin rẹ̀. Alágbára ati akọni eniyan ni wọ́n, wọ́n jẹ́ mejidinlaadoje (128). Sabidieli ọmọ Hagedolimu ni alabojuto wọn.

15 Àwọn ọmọ Lefi ni: Ṣemaaya, ọmọ Haṣubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Bunni.

16 Ṣabetai ati Josabadi, láàrin àwọn olórí ọmọ Lefi, ni wọ́n ń bojútó àwọn iṣẹ́ òde ilé Ọlọrun.

17 Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sabidi, ọmọ Asafu, ni olórí tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdúpẹ́ ninu adura, ati Bakibukaya tí ó jẹ́ igbákejì ninu àwọn arakunrin rẹ̀, Abuda, ọmọ Ṣamua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni.

18 Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní ìlú mímọ́ náà jẹ́ ọrinlerugba ó lé mẹrin (284).

19 Àwọn aṣọ́nà ni, Akubu, Talimoni ati àwọn arakunrin wọn, àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ mejilelaadọsan-an (172).

20 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà ní àwọn ìlú Juda, kaluku sì ń gbé orí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

21 Ṣugbọn àwọn iranṣẹ tẹmpili ń gbé ilẹ̀ Ofeli, Siha ati Giṣipa sì ni olórí wọn.

22 Usi ni alabojuto àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Usi yìí jẹ́ ọmọ Bani, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mika, lára àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin. Òun ni olùdarí ìsìn ninu ilé Ọlọrun.

23 Ọba ti fi àṣẹ lélẹ̀ nípa iṣẹ́ àwọn akọrin, ètò sì wà fún ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa fún wọn lojoojumọ.

24 Petahaya ọmọ Meṣesabeli, lára àwọn ọmọ Sera, ọmọ Juda, ni aṣojú ọba nípa gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli.

Àwọn Tí Wọn Ń Gbé Àwọn Ìlú Kéékèèké ati Àwọn Ìlú Ńlá

25 Ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìletò ati àwọn pápá oko wọn, àwọn ará Juda kan ń gbé Kiriati Ariba ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, àwọn mìíràn sì ń gbé Diboni ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀, ati ní Jekabuseeli ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

26 ati ní Jeṣua, ati ní Molada, ati ní Betipeleti,

27 ní Hasariṣuali ati ní Beeriṣeba, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

28 ní Sikilagi ati ní Mekona ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

29 ní Enrimoni, ní Sora, ati ní Jarimutu,

30 ní Sanoa, ati Adulamu, ati àwọn ìletò àyíká wọn, ní Lakiṣi ati àwọn ìgbèríko rẹ̀, ati ní Aseka ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀. Wọ́n pàgọ́ láti Beeriṣeba títí dé àfonífojì Hinomu.

31 Àwọn eniyan Bẹnjamini náà ń gbé Geba lọ sókè, títí dé Mikimaṣi, Aija, Bẹtẹli, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,

32 ní Anatoti,

33 Nobu, Ananaya ati Hasori, ní Rama ati Gitaimu,

34 ní Hadidi, Seboimu, ati Nebalati,

35 ní Lodi, ati Ono, àfonífojì àwọn oníṣọ̀nà.

36 A sì pa àwọn ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ Lefi kan ní Juda pọ̀ mọ́ ti àwọn ọmọ Bẹnjamini.

Categories
NEHEMAYA

NEHEMAYA 12

Orúkọ Àwọn Alufaa ati Àwọn Ọmọ Lefi

1 Orúkọ àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá Serubabeli ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua dé nìwọ̀nyí: Seraaya, Jeremaya ati Ẹsira,

2 Amaraya, Maluki, ati Hatuṣi,

3 Ṣekanaya, Rehumu, ati Meremoti,

4 Ido, Ginetoi, ati Abija,

5 Mijamini, Maadaya, ati Biliga,

6 Ṣemaaya, Joiaribu ati Jedaaya,

7 Salu ati Amoku, Hilikaya, ati Jedaaya. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí alufaa ati olórí àwọn arakunrin wọn ní ìgbà ayé Jeṣua.

8 Àwọn ọmọ Lefi ni: Jeṣua, Binui ati Kadimieli; Ṣerebaya, Juda, ati Matanaya, tí òun pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀ wà nídìí ètò àwọn orin ọpẹ́.

9 Bakibukaya ati Uno arakunrin wọn a máa dúró kọjú sí wọn ní àkókò ìsìn.

Àwọn Ìran Joṣua Olórí Alufaa

10 Joṣua ni baba Joiakimu, Joiakimu ni baba Eliaṣibu, Eliaṣibu ni baba Joiada,

11 Joiada ni baba Jonatani, Jonatani sì ni baba Jadua.

Àwọn Baálé Baálé ní Ìdílé Àwọn Alufaa

12 Nígbà tí Joiakimu jẹ́ olórí alufaa, àwọn alufaa wọnyi ní olórí baálé ní ìdílé tí a dárúkọ wọnyi:

Meraya ni baálé ní ìdílé Seraaya,

Hananaya ni baálé ní ìdílé Jeremaya,

13 Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ẹsira,

Jehohanani ni baálé ní ìdílé Amaraya,

14 Jonatani ni baálé ní ìdílé Maluki,

Josẹfu ni baálé ní ìdílé Ṣebanaya,

15 Adina ni baálé ní ìdílé Harimu,

Helikai ni baálé ní ìdílé Meraiotu,

16 Sakaraya ni baálé ní ìdílé Ido,

Meṣulamu ni baálé ní ìdílé Ginetoni,

17 Sikiri ni baálé ní ìdílé Abija,

Pilitai ni baálé ní ìdílé Miniamini ati Moadaya,

18 Ṣamua ni baálé ní ìdílé Biliga,

19 Jehonatani ni baálé ní ìdílé Ṣemaaya,

Matenai ni baálé ní ìdílé Joiaribu,

20 Usi ni baálé ní ìdílé Jedaaya,

Kalai ni baálé ní ìdílé Salai,

21 Eberi ni baálé ní ìdílé Amoku,

Haṣabaya ni baálé ní ìdílé Hilikaya,

Netaneli ni baálé ní ìdílé Jedaaya.

Àkọsílẹ̀ Ìdílé Àwọn Alufaa ati ti Àwọn Ọmọ Lefi

22 Nígbà ayé Eliaṣibu ati Joiada, Johanani ati Jadua, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa ṣe àkọsílẹ̀ àwọn baálé baálé ní ìdílé baba wọn títí di àkókò ìjọba Dariusi ọba Pasia.

23 Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn baálé baálé ninu àwọn ọmọ Lefi títí di ìgbà ayé Johanani ọmọ Eliaṣibu wà ninu ìwé Kronika.

Ìlànà Iṣẹ́ inú Tẹmpili

24 Àwọn tí wọ́n jẹ́ aṣiwaju ninu àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Haṣabaya, Ṣerebaya, ati Joṣua ọmọ Kadimieli pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn dúró kọjú sí ara wọn, àwọn ìhà mejeeji yin Ọlọrun lógo wọ́n sì dúpẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi, eniyan Ọlọrun fi lélẹ̀.

25 Matanaya, Bakibukaya ati Ọbadaya, ati Meṣulamu, Talimoni, ati Akubu ni wọ́n jẹ́ olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà bodè tí wọn ń ṣọ́ àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ẹnubodè.

26 Gbogbo nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati nígbà ayé Nehemaya, gomina, ati Ẹsira Alufaa ati akọ̀wé.

Nehemaya Ṣe Ìyàsímímọ́ Odi Ìlú náà

27 Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́ odi ìlú náà, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Lefi jọ láti gbogbo ibi tí wọ́n wà, wọ́n kó wọn wá sí Jerusalẹmu, láti wá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìyàsímímọ́ náà pẹlu orin ọpẹ́ ati kimbali ati hapu.

28 Àwọn ìdílé akọrin bá kó ara wọn jọ láti gbogbo agbègbè Jerusalẹmu ati láti àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká Netofati,

29 bákan náà ni láti Betigiligali ati láti ẹkùn Geba, ati Asimafeti, nítorí pé àwọn akọrin kọ́ ìletò fún ara wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.

30 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àwọn eniyan ati àwọn bodè ati odi ìlú náà.

31 Mo bá kó àwọn ìjòyè Juda lọ sórí odi náà, mo sì yan ọ̀wọ́ meji pataki tí wọ́n ṣe ìdúpẹ́ tí wọ́n sì tò kọjá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

Àwọn kan tò lọ ní apá ọ̀tún odi náà lọ sí Ẹnubodè Ààtàn,

32 lẹ́yìn náà, Hoṣaaya ati ìdajì àwọn ìjòyè Juda tẹ̀lé wọn,

33 Ati Asaraya, Ẹsira ati Meṣulamu,

34 Juda, Bẹnjamini ati Ṣemaaya, ati Jeremaya.

35 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ alufaa tẹ̀lé wọn pẹlu fèrè.

Àwọn nìwọ̀nyí: Sakaraya, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mikaaya, ọmọ Sakuri, ọmọ Asafu,

36 ati àwọn arakunrin rẹ̀ wọnyi: Ṣemaaya, Asareli ati Milalai, Gilalai, Maai ati Netaneli, Juda, ati Hanani, pẹlu àwọn ohun èlò orin Dafidi eniyan Ọlọ́run. Ẹsira, akọ̀wé, ni ó ṣáájú, àwọn eniyan sì tẹ̀lé e.

37 Ní Ẹnubodè Orísun, wọ́n gòkè lọ tààrà sí ibi àtẹ̀gùn ìlú Dafidi, ní igun odi ìlú, ní òkè ààfin Dafidi, títí lọ dé Ẹnubodè Omi ní apá ìlà oòrùn ìlú.

38 Ọ̀wọ́ keji àwọn tí wọ́n wá ṣe ìdúpẹ́ gba apá òsì, èmi náà sì tẹ̀lé wọn, pẹlu ìdajì àwọn eniyan, a gba orí odi náà lọ, a kọjá Ilé-ìṣọ́ ìléru, lọ sí ibi Odi Gbígbòòrò.

39 A rékọjá Ẹnubodè Efuraimu, a gba Ẹnubodè Àtijọ́, ati Ẹnubodè Ẹja ati Ilé-ìṣọ́ Hananeli ati Ilé-ìṣọ́ Ọgọrun-un, lọ sí Ẹnubodè Aguntan, wọ́n sì dúró ní Ẹnubodè àwọn Olùṣọ́ Tẹmpili.

40 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ́ mejeeji àwọn tí wọ́n wá ṣe ìdúpẹ́ ṣe dúró ninu ilé Ọlọrun, ati èmi pẹlu ìdajì àwọn baálé baálé. Àwọn tí wọ́n tún wà pẹlu mi nìwọ̀nyí:

41 àwọn alufaa: Eliakimu, Maaseaya ati Miniamini Mikaya, Elioenai, Sakaraya ati Hananaya, ń fun fèrè. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya,

42 Ṣemaaya, Eleasari ati Usi, Jehohanani, Malikija, Elamu, ati Eseri. Àwọn akọrin kọrin, Jesirahaya sì ni olórí wọn.

43 Wọ́n ṣe ìrúbọ pataki ní ọjọ́ náà, wọ́n sì yọ̀, nítorí Ọlọrun jẹ́ kí wọ́n yọ ayọ̀ ńlá, àwọn obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wọn náà yọ̀ pẹlu. Àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn réré sì gbúròó igbe ayọ̀ ní Jerusalẹmu.

Pípèsè fún Ìjọ́sìn Ní Tẹmpili

44 Ní ọjọ́ náà, wọ́n yan àwọn kan láti mójútó àwọn ilé ìṣúra, ati ọrẹ tí àwọn eniyan dájọ, àwọn èso àkọ́so, ati ìdámẹ́wàá, àwọn tí wọ́n yàn ni wọ́n ń mójútó pípín ẹ̀tọ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìlú wọn, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé òfin. Inú àwọn ará ilẹ̀ Juda dùn pupọ sí àwọn alufaa ati sí àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ìsìn.

45 Wọ́n ṣe ìsìn Ọlọrun ati ìsìn ìyàsímímọ́ bí àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ṣe, gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi ati ti ọmọ rẹ̀, Solomoni.

46 Nítorí pé látijọ́, ní ìgbà ayé Dafidi ati Asafu, wọ́n ní olórí fún àwọn akọrin, wọ́n sì ní àwọn orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.

47 Nígbà ayé Serubabeli ati Nehemaya, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli a máa fún àwọn akọrin ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà ní ẹ̀tọ́ wọn ojoojumọ, wọn a máa ya ìpín àwọn ọmọ Lefi náà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Lefi náà a sì máa ya ìpín àwọn ọmọ Aaroni sọ́tọ̀.

Categories
NEHEMAYA

NEHEMAYA 13

Yíyẹra Kúrò lára Àwọn Àjèjì

1 Ní ọjọ́ náà, wọ́n kà ninu ìwé Mose sí etígbọ̀ọ́ àwọn eniyan, ibẹ̀ sì ni a ti rí i kà pé àwọn ará Amoni ati àwọn ọmọ Moabu kò gbọdọ̀ wọ àwùjọ àwọn eniyan Ọlọrun,

2 nítorí pé wọn kò gbé oúnjẹ ati omi lọ pàdé àwọn ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu lọ́wẹ̀ láti máa gbé àwọn ọmọ Israẹli ṣépè, ṣugbọn Ọlọrun wa yí èpè náà pada sí ìre fún Israẹli.

3 Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ òfin náà, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì jáde kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

Àtúnṣe Tí Nehemaya ṣe

4 Kí ó tó di àkókò náà, Eliaṣibu alufaa, tí wọ́n yàn láti máa ṣe àkóso àwọn yàrá ilé Ọlọrun wa, tí ó sì ní àjọṣe pẹlu Tobaya,

5 ó ṣètò yàrá ńlá kan fún Tobaya níbi tí wọ́n ń tọ́jú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ sí, ati turari, àwọn ohun èlò ìrúbọ, pẹlu ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn akọrin, ati àwọn olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà, pẹlu àwọn ohun tí wọ́n dá jọ fún àwọn alufaa gẹ́gẹ́ bí òfin.

6 N kò sí ní Jerusalẹmu ní gbogbo àkókò tí nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀, nítorí pé ní ọdún kejilelọgbọn ìjọba Atasasesi, ọba Babiloni, ni mo ti pada tọ ọba lọ. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, mo gba ààyè lọ́wọ́ ọba,

7 mo sì wá sí Jerusalẹmu, ìgbà náà ni mo wá rí nǹkan burúkú tí Eliaṣibu ṣe nítorí Tobaya, tí ó yọ yàrá fún ninu àgbàlá ilé Ọlọrun.

8 Inú bí mi gan-an, mo bá fọ́n gbogbo ẹrù Tobaya jáde kúrò ninu yàrá náà.

9 Mo bá pàṣẹ pé kí wọ́n tún yàrá náà ṣe kí ó mọ́, ẹ̀yìn náà ni mo wá kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun pada ati ọrẹ ẹbọ ohun sísun ati turari.

10 Mo tún rí i wí pé wọn kò fún àwọn ọmọ Lefi ní ẹ̀tọ́ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn akọrin, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ náà fi sá lọ sí oko wọn.

11 Nítorí náà, mo bá àwọn olórí wí, mo ní “Kí ló dé tí ilé Ọlọrun fi di àpatì?” Mo kó wọn jọ, mo sì dá wọn pada sí ààyè wọn.

12 Gbogbo àwọn ọmọ Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró wá sí ilé ìṣúra.

13 Mo bá yan àwọn kan tí yóo máa mójútó ètò ìsúná owó ní àwọn ilé ìṣúra. Àwọn ni: Ṣelemaya, alufaa, Sadoku, akọ̀wé, ati Pedaaya, ọmọ Lefi. Ẹni tí ó jẹ́ igbákejì wọn ni Hanani ọmọ Sakuri, ọmọ Matanaya, nítorí pé wọ́n mọ̀ wọ́n sí olóòótọ́, iṣẹ́ wọn sì ni láti fún àwọn arakunrin wọn ní ẹ̀tọ́ wọn.

14 Ọlọrun mi, ranti mi, nítorí nǹkan wọnyi, kí o má sì pa gbogbo nǹkan rere tí mo ti ṣe sí tẹmpili rẹ rẹ́ ati àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

15 Ní àkókò náà mo rí àwọn ọmọ Juda tí wọn ń fún ọtí waini ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń kó ìtí ọkà jọ, tí wọn ń dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí wọn sì ń gbé waini, ati èso girepu, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ ati oríṣìíríṣìí ẹrù wúwo wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi, mo bá kìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó yẹ kí wọ́n máa ta oúnjẹ.

16 Àwọn ọkunrin kan láti Tire pàápàá tí wọn ń gbé ààrin ìlú náà mú ẹja wá ati oríṣìíríṣìí àwọn nǹkan títà, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn eniyan Juda ati ni Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi.

17 Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo ní, “Irú nǹkan burúkú wo ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi?

18 Irú nǹkan burúkú yìí kọ́ ni àwọn baba yín pàápàá ṣe tí Ọlọrun fi mú kí ibi bá àwa ati ìlú yìí? Sibẹ, ẹ tún ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi, ẹ̀ ń fa ìrúnú Ọlọrun sórí Israẹli.”

19 Nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣú ní àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu kí ó tó di ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ìlẹ̀kùn, ati pé wọn kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀ títí tí ọjọ́ ìsinmi yóo fi rékọjá. Mo yan díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ mi sí àwọn ẹnubodè náà, kí wọ́n má baà kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.

20 Gbogbo àwọn oníṣòwò ati àwọn tí wọn ń ta oríṣìíríṣìí nǹkan sùn sí ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu bíi ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji.

21 Ṣugbọn mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ odi? Bí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ n óo jẹ yín níyà.” Láti ìgbà náà ni wọn kò wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.

22 Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n wá láti ṣọ́ àwọn ẹnubodè, kí wọn lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.

Ranti eléyìí fún rere mi, Ọlọrun mi, kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀.

23 Nígbà náà, mo rí àwọn Juu tí wọn fẹ́ iyawo lára àwọn ará Aṣidodu, àwọn ará Amoni ati ti Moabu,

24 ìdajì àwọn ọmọ wọn ni kò gbọ́ èdè Juda àfi èdè Aṣidodu. Èdè àwọn àjèjì nìkan ni wọ́n gbọ́.

25 Mo bínú sí wọn mo sì gbé wọn ṣépè, mo na àwọn mìíràn, mo sì fa irun wọn tu. Mo sì mú wọn búra ní orúkọ Ọlọrun wí pé: “Ẹ kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọ wọn, tabi kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín tabi kí ẹ̀yin pàápàá fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn.

26 Ṣebí Solomoni ọba pàápàá dẹ́ṣẹ̀ nítorí ó fẹ́ irú àwọn obinrin bẹ́ẹ̀. Kò sí ọba tí ó dàbí rẹ̀ láàrin àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, Ọlọrun sì fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọrun sì fi jọba lórí gbogbo Israẹli, sibẹsibẹ, àwọn obinrin àjèjì ni wọ́n mú un dẹ́ṣẹ̀.

27 Ṣé a óo wá tẹ̀lé ìṣìnà yín, kí á sì máa ṣe irú nǹkan burúkú yìí, kí á sì máa fẹ́ àwọn obinrin àjèjì tí ó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọrun wa?”

28 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olórí alufaa, fẹ́ ọmọ Sanbalati ará Horoni kan, nítorí náà mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi.

29 Ranti, Ọlọrun mi, nítorí pé wọ́n rú òfin àwọn alufaa, wọn kò sì mú ẹ̀jẹ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi ṣẹ.

30 Nítorí náà mo wẹ̀ wọ́n mọ́ ninu gbogbo nǹkan àjèjì, mo sì fi ìdí iṣẹ́ wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alufaa ati ọmọ Lefi. Olukuluku sì ní iṣẹ́ tí ó ń ṣe,

31 mo pèsè igi ìrúbọ, ní àkókò tí ó yẹ ati àwọn èso àkọ́so.

Ranti mi sí rere, Ọlọrun mi.