Categories
MATIU

MATIU 10

Jesu fún Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Mejila Láṣẹ

1 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn.

2 Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀.

3 Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu.

4 Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Iṣẹ́ tí Jesu Rán Àwọn Aposteli Mejila

5 Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria.

6 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ àwọn aguntan ilé Israẹli tí ó sọnù lọ.

7 Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’

8 Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n.

9 Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín.

10 Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.

11 “Bí ẹ bá dé ìlú tabi ìletò kan, ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí bí ẹni tí ó yẹ kan bá wà níbẹ̀; lọ́dọ̀ rẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò níbẹ̀.

12 Nígbà tí ẹ bá wọ inú ilé kan lọ, ẹ kí wọn pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’

13 Bí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ bá wà ninu ilé náà, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó wà níbẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó pada sọ́dọ̀ yín.

14 Bí ẹnìkan kò bá gbà yín sílé, tabi tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò ninu ilé tabi ìlú náà, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀.

15 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ati ti Gomora ní ọjọ́ ìdájọ́, ju ìlú náà lọ!

Inúnibíni tí Ó Ń Bọ̀

16 “Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.

17 Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn eniyan, nítorí wọn yóo fà yín lọ siwaju ìgbìmọ̀ láti fẹ̀sùn kàn yín; wọn yóo nà yín ninu àwọn ilé ìpàdé wọn.

18 Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.

19 Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà.

20 Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni yóo máa sọ̀rọ̀, ẹ̀mí Baba yín ni yóo máa sọ̀rọ̀ ninu yín.

21 “Arakunrin yóo fi arakunrin rẹ̀ fún ikú pa; baba yóo fi ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóo gbógun ti àwọn òbí wọn, wọn yóo fi wọ́n fún ikú pa.

22 Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fara dà á títí dé òpin, òun ni a óo gbà là.

23 Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé.

24 “Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ.

25 Ó tó fún ọmọ-ẹ̀yìn bí ó bá dàbí olùkọ́ rẹ̀. Ó tó fún ẹrú bí ó bá dàbí oluwa rẹ̀. Bí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelisebulu, kí ni wọn yóo pe àwọn ẹni tí ó ń gbé inú ilé rẹ̀!

Ẹni tí Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù

26 “Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù àwọn eniyan. Kò sí ohun tí ó wà ní ìpamọ́, tí kò ní fara hàn. Kò sì sí ohun àṣírí tí a kò ní mọ̀.

27 Ohun tí mo sọ fun yín níkọ̀kọ̀, ẹ sọ ọ́ ní gbangba. Ohun tí wọ́n yọ́ sọ fun yín, ẹ kéde rẹ̀ lórí òrùlé.

28 Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì.

29 Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́! Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín.

30 Gbogbo irun orí yín ni ó níye.

31 Nítorí náà ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.

Ìjẹ́wọ́ Kristi níwájú Eniyan

32 “Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

33 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

Ọ̀rọ̀ nípa Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀

34 “Ẹ má rò pé mo mú alaafia wá sáyé. N kò mú alaafia wá; idà ni mo mú wá.

35 Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀.

36 Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.

37 “Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi.

38 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi.

39 Ẹni tí ó bá sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóo jèrè rẹ̀.

Èrè

40 “Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.

41 Ẹni tí ó bá gba wolii ní orúkọ wolii yóo gba èrè tí ó yẹ wolii. Ẹni tí ó bá gba olódodo ní orúkọ olódodo yóo gba èrè olódodo.

42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yìí tí ó kéré jùlọ ní ife omi tútù mu, nítorí pé ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

Categories
MATIU

MATIU 11

1 Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu.

Johanu Onítẹ̀bọmi Ranṣẹ sí Jesu

2 Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé,

3 “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”

4 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé,

5 àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.

6 Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”

7 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu pada lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn eniyan nípa Johanu pé, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Ṣé koríko tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín, sọ́hùn-ún? Rárá o!

8 Kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ẹni tí ó wọ aṣọ iyebíye ni bí? Bí ẹ bá ń wá àwọn tí ó wọ aṣọ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba!

9 Ṣugbọn kí ni ẹ jáde lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ.

10 Òun ni àkọsílẹ̀ wà nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’

11 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ninu àwọn tí obinrin bí, kò ì tíì sí ẹnìkan tí ó ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jù lọ ní ìjọba Ọlọrun jù ú lọ.

12 Láti àkókò tí Johanu Onítẹ̀bọmi ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu títí di ìsinsìnyìí ni àwọn alágbára ti gbógun ti ìjọba ọ̀run, wọ́n sì fẹ́ fi ipá gbà á.

13 Nítorí títí di àkókò Johanu gbogbo àwọn wolii ati òfin sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀.

14 Bí ẹ bá fẹ́ gbà á, Johanu ni Elija, tí ó níláti kọ́ wá.

15 Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.

16 “Kí ni ǹ bá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà, tí wọn ń ké sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé.

17 ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, a pe òkú, ẹ kò ṣọ̀fọ̀.’

18 Nítorí Johanu dé, kò jẹ, kò mu. Wọ́n ní, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’

19 Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu. Wọ́n ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣugbọn àyọrísí iṣẹ́ Ọlọrun fihàn pé ọgbọ́n rẹ̀ tọ̀nà.”

Ìdájọ́ lórí Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada

20 Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ìlú wọ̀n-ọn-nì wí níbi tí ó ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu pupọ jùlọ, nítorí wọn kò ronupiwada.

21 Ó ní, “O gbé! Korasini. Ìwọ náà sì gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, tàwọn ti aṣọ ọ̀fọ̀ lára ati eérú lórí.

22 Mo sọ fun yín, yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fun yín lọ.

23 Ati ìwọ, Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o. Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Sodomu ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe ninu rẹ ni, ìbá wà títí di òní.

24 Mo sọ fún ọ pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ọ lọ.”

Jesu ni Ìtura Àwọn Olùpọ́njú

25 Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè.

26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.

27 “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.

28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóo fun yín ní ìsinmi.

29 Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀.

30 Nítorí àjàgà mi tuni lára, ẹrù mi sì fúyẹ́.”

Categories
MATIU

MATIU 12

Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà ní Ọjọ́ Ìsinmi

1 Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́.

2 Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n wí fún un pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi.”

3 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?

4 Bí wọ́n ti wọ inú ilé Ọlọrun lọ, tí wọ́n sì jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, èyí tí ó lòdì sí òfin fún òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ láti jẹ bíkòṣe fún àwọn alufaa nìkan?

5 Tabi ẹ kò kà ninu ìwé Òfin pé iṣẹ́ àwọn alufaa ninu Tẹmpili ní Ọjọ́ Ìsinmi a máa mú wọn ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́? Sibẹ wọn kò jẹ̀bi.

6 Mo sọ fun yín pé ẹni tí ó ju Tẹmpili lọ ló wà níhìn-ín yìí.

7 Bí ó bá jẹ́ pé ìtumọ̀ gbolohun yìí ye yín ni, pé: ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú’ ẹ kì bá tí dá ẹ̀bi fún aláìṣẹ̀.

8 Nítorí Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.”

Ọkunrin tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

9 Lẹ́yìn èyí, Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí inú ilé ìpàdé wọn.

10 Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bá òfin mu láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi?” Kí wọ́n baà lè rí ẹ̀sùn fi kàn án ni wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí.

11 Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde?

12 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí eniyan ti sàn ju aguntan lọ, ó tọ́ láti ṣe rere ní Ọjọ́ Ìsinmi.”

13 Ó bá sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.”

Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò gẹ́gẹ́ bí ekeji.

14 Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á.

Iranṣẹ Ọlọrun

15 Nígbà tí Jesu mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó bá kúrò níbẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan sì tẹ̀lé e, ó sì wo gbogbo wọn sàn.

16 Ó kìlọ̀ fún wọn kí wọn má ṣe polongo òun,

17 kí ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ lè ṣẹ pé,

18 “Wo ọmọ mi tí mo yàn,

àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ̀ mọ́

Èmi óo fi Ẹ̀mí mi sí i lára,

yóo kéde ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.

19 Kò ní ṣàròyé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pariwo,

bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ ohùn rẹ̀ ní títì.

20 Kò ní dá igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó tẹ̀ sí meji.

Kò ní pa iná tí ó ń jó bẹ́lúbẹ́lú,

títí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yóo fi borí.

21 Ninu orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu yóo ní ìrètí.”

Jesu ati Beelisebulu

22 Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran.

23 Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń wí pé, “Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ Dafidi nìyí bí?”

24 Ṣugbọn nígbà tí àwọn Farisi gbọ́, wọ́n ní, “Ojú lásán kọ́ ni ọkunrin yìí fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde; agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó ń lò.”

25 Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń rò. Ó bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìlúkílùú tabi ilékílé tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá ń bá ara wọn jà yóo tú.

26 Bí Satani bá ń lé Satani jáde, ara rẹ̀ ni ó ń gbé ogun tì. Báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró?

27 Bí ó bá jẹ́ pé agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín.

28 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín.

29 “Báwo ni ẹnìkan ṣe lè wọ ilé alágbára lọ, kí ó kó o lẹ́rù, bí kò bá kọ́kọ́ de alágbára náà? Bí ó bá kọ́kọ́ dè é ni yóo tó lè kó o lẹ́rù.

30 “Ẹni tí kò bá ṣe tèmi, ó lòdì sí mi. Ẹni tí kò bá máa bá mi kó nǹkan jọ, ó ń fọ́nká ni.

31 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fun yín pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati gbogbo ìsọ̀rọ̀ òdì ni a óo dárí rẹ̀ ji eniyan; ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì.

32 Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ọmọ-Eniyan yóo rí ìdáríjì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì láyé yìí ati ní ayé tí ń bọ.

Igi ati Èso Rẹ̀

33 “Bákan-meji ni. Ninu kí ẹ tọ́jú igi, kí ó dára, kí èso rẹ̀ sì dára, tabi kí ẹ ba igi jẹ́, kí èso rẹ̀ náà sì bàjẹ́. Èso igi ni a fi ń mọ igi.

34 Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀ yìí! Báwo ni ọ̀rọ̀ yín ti ṣe lè dára nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò dára? Nítorí ohun tí ó bá kún inú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde.

35 Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú.

36 “Ṣugbọn mo sọ fun yín pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí eniyan bá ń sọ láì ronú ni yóo dáhùn fún ní ọjọ́ ìdájọ́.

37 Nítorí nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo fi dá ọ láre; nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo sì fi dá ọ lẹ́bi.”

Àwọn Juu Fẹ́ Àmì láti Ọ̀dọ̀ Jesu

38 Ní àkókò náà ni àwọn kan ninu àwọn amòfin ati ninu àwọn Farisi bi í pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ rí àmì láti ọwọ́ rẹ.”

39 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìran burúkú ati ìran oníbọkúbọ ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fi fún un àfi àmì Jona wolii.

40 Nítorí bí Jona ti wà ninu ẹja ńlá fún ọjọ́ mẹta tọ̀sán-tòru, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo wà ninu ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹta, tọ̀sán-tòru.

41 Àwọn ará Ninefe yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́, wọn yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nítorí iwaasu tí Jona wà fún wọn. Wò ó, ẹni tí ó ju Jona lọ ló wà níhìn-ín.

42 Ọbabinrin láti ilẹ̀ gúsù yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́ yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí ó wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni. Ẹ wò ó, ẹni tí ó ju Solomoni lọ ló wà níhìn-ín.

Ẹ̀mí-Èṣù tún Pada sí Ilé Rẹ̀

43 “Nígbà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ẹnìkan, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ilẹ̀ gbígbẹ láti sinmi. Ó ń wá ibi tí yóo fi ṣe ibùgbé, ṣugbọn kò rí.

44 Ó bá ni, ‘N óo tún pada sí ilé mi, níbi tí mo ti jáde kúrò.’ Nígbà tí ó débẹ̀, ó rí i pé ibẹ̀ ṣófo, ati pé a ti gbá a, a sì ti tọ́jú rẹ̀ dáradára.

45 Ó bá lọ, ó kó àwọn ẹ̀mí meje mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n bá wọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìran burúkú yìí.”

Ìyá Jesu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀

46 Bí Jesu ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ ni ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ bá dé, wọ́n dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. [

47 Ẹnìkan sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”]

48 Jesu dá a lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi? Àwọn ta sì ni arakunrin mi?”

49 Ó bá nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Wò ó ìyá mi ati àwọn arakunrin mi nìwọ̀nyí.

50 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, òun ni arakunrin mi ati arabinrin mi ati ìyá mi.”

Categories
MATIU

MATIU 13

Òwe Afunrugbin

1 Ní ọjọ́ kan náà, Jesu jáde kúrò nílé, ó lọ jókòó létí òkun.

2 Ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan. Ó jókòó níbẹ̀, àwọn eniyan bá dúró ní etí òkun.

3 Ó sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ fún wọn pẹlu òwe. Ó ní:

“Ní ọjọ́ kan, afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.

4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, àwọn irúgbìn kan bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà. Àwọn ẹyẹ bá wá ṣà á jẹ.

5 Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ olókùúta tí kò ní erùpẹ̀ pupọ. Lọ́gán ó yọ sókè, nítorí kò ní erùpẹ̀ tí ó jinlẹ̀.

6 Ṣugbọn nígbà tí oòrùn mú, ó jó o pa, nítorí kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; ó bá rọ.

7 Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin igi ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí wọ́n yọ, ẹ̀gún fún wọn pa.

8 Ṣugbọn àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ rere, wọ́n sì ń so èso, àwọn mìíràn ń so ọgọọgọrun-un, àwọn mìíràn ọgọọgọta, àwọn mìíràn, ọgbọọgbọn.

9 “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Ìdí tí Jesu Fi Ń Lo Òwe

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń fi òwe bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀?”

11 Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a fi àṣírí ìmọ̀ ìjọba ọ̀run hàn, a kò fihan àwọn yòókù wọnyi.

12 Nítorí ẹni tí ó bá ní nǹkan, òun ni a óo tún fún sí i, kí ó lè ní ànító ati àníṣẹ́kù. Ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.

13 Ìdí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nìyí, nítorí wọ́n lajú sílẹ̀ ni, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn.

14 Báyìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aisaya ṣe ṣẹ sí wọn lára, nígbà tí ó sọ pé.

‘Ní ti gbígbọ́, ẹ óo gbọ́,

ṣugbọn kò ní ye yín;

ní ti pé kí ẹ ríran, ẹ óo wò títí,

ṣugbọn ẹ kò ní rí nǹkankan.

15 Ọkàn àwọn eniyan yìí ti le,

etí wọn ti di,

wọ́n sì ti di ojú wọn.

Kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,

kí wọn má baà fi etí wọn gbọ́ràn,

kí wọn má baà mòye,

kí wọn má baà yipada,

kí n wá gbà wọ́n là.’

16 “Ṣugbọn ẹ̀yin ṣe oríire tí ojú yín ríran, tí etí yín sì gbọ́ràn.

17 Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn olódodo dàníyàn láti rí àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rí, ṣugbọn wọn kò rí wọn; wọ́n fẹ́ gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́.

Ìtumọ̀ Òwe Afunrugbin

18 “Ẹ gbọ́ ìtumọ̀ òwe afunrugbin.

19 Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba ọ̀run, tí nǹkan tí ó gbọ́ kò yé e, tí èṣù wá, tí ó mú ohun tí a gbìn sọ́kàn rẹ̀ lọ: òun ni irúgbìn ti ẹ̀bá ọ̀nà.

20 Irúgbìn ti orí ilẹ̀ olókùúta ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á lẹsẹkẹsẹ.

21 Ṣugbọn nítorí kò ní gbòǹgbò ninu ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yóo wà fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí inúnibíni tabi ìṣòro bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, lẹsẹkẹsẹ a kùnà.

22 Ti ààrin igi ẹlẹ́gùn-ún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí àníyàn ayé yìí ati ìtànjẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, tí kò fi so èso.

23 Ṣugbọn èyí tí a fún sórí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ọ̀rọ̀ náà yé, tí ó wá ń so èso, nígbà mìíràn, ọgọrun-un; nígbà mìíràn, ọgọta; nígbà mìíràn, ọgbọ̀n.”

Òwe Èpò láàrin Ọkà

24 Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Bí ìjọba ọ̀run ti rí nìyí. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀.

25 Nígbà tí àwọn eniyan sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó gbin èpò sáàrin ọkà, ó bá lọ.

26 Nígbà tí ọkà dàgbà, tí ó yọ ọmọ, èpò náà dàgbà.

27 Àwọn ẹrú baálé náà bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, ‘Alàgbà, ṣebí irúgbìn rere ni o gbìn sí oko, èpò ti ṣe débẹ̀?’

28 Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’ Àwọn ẹrú rẹ̀ ní, ‘Ṣé kí á lọ tu wọ́n dànù?’

29 Ó bá dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá o! Bí ẹ bá wí pé ẹ̀ ń tu èpò, ẹ óo tu ọkà náà.

30 Ẹ jẹ́ kí àwọn mejeeji jọ dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Ní àkókò ìkórè, n óo sọ fún àwọn olùkórè pé: ẹ kọ́ kó èpò jọ, kí ẹ dì wọ́n nítìí-nítìí, kí ẹ dáná sun ún. Kí ẹ wá kó ọkà jọ sinu abà mi.’ ”

Òwe Wóró Musitadi kan ati Ìwúkàrà

31 Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí wóró musitadi tí ẹnìkan gbìn sinu oko rẹ̀.

32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, sibẹ nígbà tí ó bá dàgbà, a tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ. A di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run óo wá ṣe ìtẹ́ wọn lára ẹ̀ka rẹ̀.”

33 Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”

Ìlò Òwe

34 Jesu sọ gbogbo nǹkan wọnyi fún àwọn eniyan ní òwe. Kò sọ ohunkohun fún wọn láì lo òwe;

35 kí ọ̀rọ̀ tí wolii ti sọ lè ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé,

“Bí òwe bí òwe ni ọ̀rọ̀ mi yóo jẹ́.

N óo sọ àwọn ohun tí ó ti wà ní àṣírí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.”

Ìtumọ̀ Òwe Èpò ninu Oko Ọkà

36 Nígbà tí Jesu kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, ó lọ sinu ilé. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé, “Ṣe àlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”

37 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó fúnrúgbìn rere ni Ọmọ-Eniyan.

38 Ayé ni oko tí ó fúnrúgbìn sí. Irúgbìn rere ni àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ọmọ èṣù.

39 Ọ̀tá tí ó fọ́n èpò ni èṣù. Ìkórè ni ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli ni olùkórè.

40 Nítorí náà, bí wọn tíí kó èpò jọ tí wọn ń sun ún ninu iná, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.

41 Ọmọ-Eniyan yóo rán àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóo kó gbogbo àwọn amúni-ṣìnà ati àwọn arúfin kúrò ninu ìjọba rẹ̀.

42 Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.

43 Àwọn olódodo yóo wá máa ràn bí oòrùn ninu ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.

Òwe Ìṣúra Iyebíye tí Wọ́n Fi Pamọ́

44 “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ìṣúra iyebíye kan tí wọ́n fi pamọ́ ninu ilẹ̀. Nígbà tí ẹnìkan rí i, ó bò ó mọ́lẹ̀, ó lọ tayọ̀tayọ̀, ó ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá ra ilẹ̀ náà.

Òwe Ìlẹ̀kẹ̀

45 “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ọkunrin oníṣòwò kan tí ó ń wá ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye kan.

46 Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó dára pupọ, ó lọ ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá rà á.

Òwe Àwọ̀n

47 “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí àwọ̀n tí a dà sinu òkun, tí ó kó oríṣìíríṣìí ẹja.

48 Nígbà tí ó kún, wọ́n fà á lọ sí èbúté, wọ́n jókòó, wọ́n ṣa àwọn ẹja tí ó dára jọ sinu garawa, wọ́n sì da àwọn tí kò wúlò nù.

49 Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóo wá, wọn óo yanjú àwọn eniyan burúkú kúrò láàrin àwọn olódodo,

50 wọn yóo jù wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.”

Nǹkan Titun ati Nǹkan Àtijọ́ ninu Àpò Ìṣúra

51 Jesu bi wọ́n pé, “Ṣé gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ye yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

52 Ó wá sọ fún wọn pé, “Nítorí èyí ni amòfin tí ó bá ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí baálé ilé kan, tí ó ń mú nǹkan titun ati nǹkan àtijọ́ jáde láti inú àpò ìṣúra rẹ̀.”

Àwọn Ará Nasarẹti Kọ Jesu

53 Lẹ́yìn tí Jesu ti parí gbogbo àwọn òwe wọnyi, ó kúrò níbẹ̀.

54 Nígbà tí ó dé ìlú baba rẹ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn lọ́nà tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ń sọ pé, “Níbo ni eléyìí ti ní irú ọgbọ́n yìí? Níbo ni ó ti rí agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu báyìí?

55 Àbí ọmọ gbẹ́nà-gbẹ́nà yẹn kọ́ ni? Tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Maria, tí àwọn arakunrin rẹ̀ ń jẹ́ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi?

56 Gbogbo àwọn arabinrin rẹ̀ kọ́ ni wọ́n wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín? Níbo ni ó wá ti rí gbogbo nǹkan wọnyi?”

57 Wọ́n sì kọ̀ ọ́.

Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì àfi ní ìlú baba rẹ̀ ati ní ilé rẹ̀.”

58 Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ níbẹ̀ nítorí wọn kò ní igbagbọ.

Categories
MATIU

MATIU 14

Ikú Johanu Onítẹ̀bọmi

1 Ní àkókò náà, Hẹrọdu ọba gbúròó Jesu.

2 Ó wí fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni èyí. Òun ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ó fi ní agbára láti lè ṣe iṣẹ́ ìyanu.”

3 Nítorí Hẹrọdu yìí ni ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú Johanu, kí wọ́n dè é, kí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin Hẹrọdu.

4 Nítorí Johanu sọ fún Hẹrọdu pé kò tọ́ fún un láti fi Hẹrọdiasi ṣaya.

5 Hẹrọdu fẹ́ pa á, ṣugbọn ó bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí wọ́n gbà pé wolii ni Johanu.

6 Nígbà tí Hẹrọdu ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀, ọdọmọbinrin Hẹrọdiasi bẹ̀rẹ̀ sí jó lójú agbo. Èyí dùn mọ́ Hẹrọdu ninu

7 tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkohun tí ó bá bèèrè.

8 Lẹ́yìn tí ìyá ọmọbinrin yìí ti kọ́ ọ ní ohun tí yóo bèèrè, ó ní, “Gbé orí Johanu Onítẹ̀bọmi wá fún mi nisinsinyii ninu àwo pẹrẹsẹ kan.”

9 Ó dun ọba, ṣugbọn nítorí pé ó ti búra, ati nítorí àwọn tí ó wà níbi àsè, ó gbà láti fi fún un.

10 Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ Johanu lórí ninu ẹ̀wọ̀n tí ó wá.

11 Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá ninu àwo pẹrẹsẹ, wọ́n gbé e fún ọdọmọbinrin náà. Ó bá lọ gbé e fún ìyá rẹ̀.

12 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu bá wá, wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ, wọ́n sin ín; wọ́n sì lọ ròyìn fún Jesu.

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

13 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkan tí eniyan kò sí, kí ó lè dá wà. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, wọ́n gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láti ìlú wọn, wọ́n tẹ̀lé e.

14 Bí ó ti ń gúnlẹ̀, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan. Àánú wọn ṣe é, ó bá wo àwọn tí wọ́n ṣàìsàn ninu wọn sàn.

15 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ní, “Aṣálẹ̀ ni ibí yìí, ọjọ́ sì ti lọ. Fi àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ ra oúnjẹ fún ara wọn ninu àwọn ìletò.”

16 Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò yẹ kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní oúnjẹ jẹ.”

17 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí oúnjẹ níhìn-ín, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji.”

18 Ó ní, “Ẹ kó wọn wá fún mi níhìn-ín.”

19 Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan jókòó lórí koríko. Ó mú burẹdi marun-un náà ati ẹja meji; ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́, ó bá bù wọ́n, ó kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá pín in fún àwọn eniyan.

20 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, àjẹkù sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila.

21 Àwọn eniyan tí ó jẹun tó ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.

Jesu Rìn lórí Omi

22 Lẹsẹkẹsẹ, ó bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn wọ ọkọ̀ ojú omi ṣáájú òun lọ sí òdìkejì, nígbà tí ó ń tú àwọn eniyan ká.

23 Nígbà tí ó tú wọn ká tán, ó gun orí òkè lọ gbadura, òun nìkan. Nígbà tí alẹ́ lẹ́, òun nìkan ni ó wà níbẹ̀.

24 Ọkọ̀ ti kúrò ní èbúté, ó ti bọ́ sí agbami. Ìgbì omi wá ń dààmú ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn.

25 Nígbà tí ó di nǹkan bí agogo mẹta òru, Jesu ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó ń rìn lójú omi òkun.

26 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, wọ́n ń sọ pé, “Iwin ni!” Wọ́n bá kígbe, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n.

27 Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!”

28 Peteru sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni, sọ pé kí n máa rìn bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lójú omi.”

29 Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu.

30 Ṣugbọn nígbà tí ó rí i tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́, ẹ̀rù bà á, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rì. Ó bá kígbe pé, “Oluwa, gbà mí!”

31 Lẹsẹkẹsẹ Jesu bá fà á lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ìwọ onigbagbọ kékeré yìí! Kí ni ó mú ọ ṣe iyè meji?”

32 Bí wọ́n ti wọ inú ọkọ́ ni afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀.

33 Àwọn tí ó wà ninu ọkọ̀ júbà rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Lóòótọ́, Ọmọ Ọlọrun ni ọ́!”

Jesu Wo Àwọn Aláìsàn Sàn ní Genesarẹti

34 Lẹ́yìn tí wọ́n ti gúnlẹ̀, wọ́n dé ilẹ̀ Genesarẹti.

35 Àwọn eniyan ibẹ̀ ti dá a mọ̀, wọ́n bá ranṣẹ lọ sí gbogbo agbègbè ibẹ̀; wọ́n gbé gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

36 Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn sá lè fi ọwọ́ kan etí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án ni ó mú lára dá.

Categories
MATIU

MATIU 15

Àṣà Ìbílẹ̀ Àwọn Juu

1 Nígbà náà ni àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá sọ́dọ̀ Jesu láti Jerusalẹmu, wọ́n bi í pé,

2 “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà tí àwọn baba wa fi lé wa lọ́wọ́? Nítorí wọn kì í wẹ ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹun.”

3 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀yin náà ṣe ń fi àṣà ìbílẹ̀ yín rú òfin Ọlọrun?

4 Nítorí Ọlọrun sọ pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’; ati pé, ‘Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ burúkú sí baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á.’

5 Ṣugbọn ẹ̀yin sọ pé, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé, ‘Mo ti fi ohun tí ò bá fi jẹ anfaani lára mi tọrẹ fún Ọlọrun,’

6 kò tún níláti bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀mọ́. Báyìí ni ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po.

7 Ẹ̀yin alaiṣootọ! Òtítọ́ ni Aisaya ti sọtẹ́lẹ̀ nípa yín nígbà tí ó wí pé,

8 ‘Ọlọrun sọ pé:

Ẹnu lásán ni àwọn eniyan wọnyi fi ń bọlá fún mi,

ọkàn wọn jìnnà pupọ sí mi.

9 Asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí,

ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí ẹni pé òfin Ọlọrun ni.’ ”

10 Ó wá pe àwọn eniyan jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́, kí ó sì ye yín.

11 Kì í ṣe ohun tí ó ń wọ ẹnu ẹni lọ ni ó ń sọni di aláìmọ́, bíkòṣe ohun tí ó ń jáde láti ẹnu wá ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.”

12 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ó bí wọn ninu?”

13 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi tí ń bẹ lọ́run kò bá gbìn ni a óo hú dànù.

14 Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tí ó ń fọ̀nà hanni ni wọ́n. Bí afọ́jú bá ń fọ̀nà han afọ́jú, àwọn mejeeji yóo jìn sinu kòtò.”

15 Peteru sọ fún un pé, “Túmọ̀ òwe yìí fún wa.”

16 Jesu dá a lóhùn pé, “Kò ì tíì yé ẹ̀yin náà títí di ìwòyí?

17 Kò ye yín pé ikùn ni gbogbo ohun tí eniyan bá fi sí ẹnu ń lọ ati pé eniyan óo tún yà á jáde?

18 Ṣugbọn ohun tí eniyan bá sọ láti inú ọkàn rẹ̀ wá, èyí ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.

19 Nítorí láti inú ọkàn ni èrò burúkú ti ń jáde wá: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe, olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ìsọkúsọ.

20 Àwọn nǹkan wọnyi ni wọ́n ń sọ eniyan di aláìmọ́; kí eniyan jẹun láì wẹ ọwọ́ kò lè sọ eniyan di aláìmọ́.”

Igbagbọ Obinrin Ará Kenaani Kan

21 Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Tire ati Sidoni.

22 Obinrin Kenaani kan tí ó ń gbé ibẹ̀ bá jáde, ó ń kígbe pé, “Ṣàánú mi, Oluwa, ọmọ Dafidi. Ẹ̀mí èṣù ní ń da ọdọmọbinrin mi láàmú.”

23 Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá wá sọ fún un pé, “Lé obinrin yìí lọ, nítorí ó ń pariwo tẹ̀lé wa lẹ́yìn.”

24 Jesu bá dáhùn pé, “Kìkì àwọn aguntan tí ó sọnù, àní ìdílé Israẹli nìkan ni a rán mi sí.”

25 Ṣugbọn obinrin náà wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́.”

26 Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!”

27 Obinrin náà ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa. Ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti inú àwo oúnjẹ oluwa wọn.”

28 Nígbà náà ni Jesu sọ fún un pé, “Obinrin yìí! Igbagbọ rẹ tóbi gidi. Kí ó rí fún ọ bí o ti fẹ́.” Ara ọdọmọbinrin rẹ̀ bá dá láti àkókò náà.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn

29 Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ẹ̀bá òkun Galili; ó gun orí òkè lọ, ó bá jókòó níbẹ̀.

30 Ọ̀pọ̀ eniyan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n gbé àwọn arọ wá, ati àwọn afọ́jú, àwọn amúkùn-ún ati àwọn odi, ati ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bá wò wọ́n sàn.

31 Ẹnu ya àwọn eniyan, nígbà tí wọ́n rí i tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn amúkùn-ún di alára líle, tí àwọn arọ ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran. Wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun Israẹli.

Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan

32 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ ó ní, “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi; wọn kò ní oúnjẹ mọ́. N kò fẹ́ tú wọn ká pẹlu ebi ninu, kí òòyì má baà gbé wọn lọ́nà.”

33 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Níbo ni a óo ti rí oúnjẹ ní aṣálẹ̀ yìí tí yóo yó àwọn eniyan tí ó pọ̀ tó báyìí?”

34 Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?”

Wọ́n ní, “Meje, ati ẹja kéékèèké díẹ̀.”

35 Jesu pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó nílẹ̀.

36 Ó wá mú burẹdi meje náà ati àwọn ẹja náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù wọ́n, ó bá kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá pín wọn fún àwọn eniyan.

37 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó; wọ́n sì kó àjẹkù wọn jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ meje.

38 Àwọn tí wọ́n jẹ oúnjẹ jẹ́ ẹgbaaji (4,000) ọkunrin láì ka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde.

39 Lẹ́yìn tí Jesu ti tú àwọn eniyan ká, ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó bá lọ sí agbègbè Magadani.

Categories
MATIU

MATIU 16

Àwọn Juu ń Fẹ́ Àmì

1 Àwọn Farisi ati àwọn Sadusi wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n ń dán an wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run han àwọn.

2 Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ọjọ́ bá rọ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ dára, nítorí ojú ọ̀run pupa.’

3 Ní òwúrọ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìjì yóo jà lónìí nítorí pé ojú ọ̀run pupa, ó sì ṣú.’ Ẹ mọ ohun tí àmì ojú ọ̀run jẹ́, ṣugbọn ẹ kò mọ àwọn àmì àkókò yìí.

4 Ìran burúkú ati oníbọkúbọ ń wá àmì; ṣugbọn a kò ní fi àmì kan fún un, àfi àmì Jona.”

Ó bá fi wọ́n sílẹ̀ ó sì bá tirẹ̀ lọ.

Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Àwọn Sadusi

5 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rékọjá sí òdìkejì òkun, wọ́n gbàgbé láti mú oúnjẹ lọ́wọ́.

6 Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati àwọn Sadusi.”

7 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wí láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò mú oúnjẹ lọ́wọ́ wá ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”

8 Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń sọ láàrin ara yín nípa oúnjẹ tí ẹ kò ní, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré?

9 Òye kò ì tíì ye yín sibẹ? Ẹ kò ranti burẹdi marun-un tí mo fi bọ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan ati iye agbọ̀n àjẹkù tí ẹ kó jọ?

10 Ti burẹdi meje ńkọ́, tí mo fi bọ́ ẹgbaaji (4,000) eniyan ati iye apẹ̀rẹ̀ àjẹkù tí ẹ kó jọ?

11 Kí ló dé tí kò fi ye yín pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni mò ń sọ? Ẹ ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati Sadusi.”

12 Nígbà náà ni ó wá yé wọn pé kì í ṣe ti ìwúkàrà tí à ń fi sinu burẹdi ni ó ń sọ, ti ẹ̀kọ́ àwọn Farisi ati Sadusi ni ó ń sọ.

Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni tí Jesu Í Ṣe

13 Nígbà tí Jesu dé agbègbè ìlú Kesaria ti Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé Ọmọ-Eniyan jẹ́?”

14 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni. Àwọn mìíràn ní Elija ni. Àwọn mìíràn tún ní Jeremaya ni tabi ọ̀kan ninu àwọn wolii.”

15 Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?”

16 Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun Alààyè.”

17 Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

18 Mo sọ fún ọ pé: Peteruni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé; agbára ikú kò ní lè ká a.

19 N óo fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run. Ohunkohun tí o bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run. Ohunkohun tí o bá sì tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.”

20 Nígbà náà ni Jesu wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Mesaya.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

21 Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí máa fihan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé dandan ni kí òun lọ sí Jerusalẹmu, kí òun jìyà pupọ lọ́wọ́ àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin; ati pé kí wọ́n pa òun, ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí òun dìde.

22 Ni Peteru bá pè é sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “Ọlọrun má jẹ́! Oluwa, irú èyí kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ.”

23 Ṣugbọn Jesu yipada, ó sọ fún Peteru pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nítorí o kò ro nǹkan ti Ọlọrun, ti eniyan ni ò ń rò.”

24 Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.

25 Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóo rí i.

26 Nítorí anfaani wo ni ó ṣe eniyan, tí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Tabi kí ni eniyan lè fi dípò ẹ̀mí rẹ̀?

27 Nítorí Ọmọ-Eniyan yóo wá ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli rẹ̀, yóo wá fi èrè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

28 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn kan wà láàrin àwọn tí ó dúró níhìn-ín, tí kò ní kú títí wọn óo fi rí Ọmọ-Eniyan tí yóo máa bọ̀ wá gẹ́gẹ́ bí Ọba.”

Categories
MATIU

MATIU 17

Jesu Para Dà

1 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu arakunrin Jakọbu, wọ́n lọ sí orí òkè gíga kan; àwọn nìkan wà níbẹ̀.

2 Jesu bá para dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ wá ń tàn bí oòrùn. Aṣọ rẹ̀ mọ́ gbòò bí ọjọ́.

3 Wọ́n wá rí Mose ati Elija tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀.

4 Peteru bá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, kì bá dára kí á máa gbé ìhín. Bí o bá fẹ́, èmi yóo pa àgọ́ mẹta síhìn-ín, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.”

5 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu kan tí ń tàn bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ohùn kan wá láti inú ìkùukùu náà wí pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”

6 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, wọ́n dojúbolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n pupọ.

7 Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó ní, “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.”

8 Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, wọn kò rí ẹnikẹ́ni mọ́, àfi Jesu nìkan.

9 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má sọ ohun tí ẹ rí fún ẹnikẹ́ni títí a óo fi jí Ọmọ-Eniyan dìde kúrò ninu òkú.”

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í pé, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́kọ́ dé?”

11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Òtítọ́ ni pé Elija yóo wá, yóo sì mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.

12 Ṣugbọn mo sọ fun yín, Elija ti dé, ṣugbọn àwọn eniyan kò mọ̀ ọ́n; ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ-Eniyan yóo sì jìyà lọ́wọ́ wọn.”

13 Ó yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà náà pé nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó ń sọ fún wọn.

Jesu Wo Ọmọ tí Ó ní Ẹ̀mí Èṣù Sàn

14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan, ọkunrin kan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀.

15 Ó ní, “Alàgbà, ṣàánú ọmọ mi, nítorí wárápá a máa gbé e, a sì máa joró pupọ. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà, a máa ṣubú lu iná; ní ọpọlọpọ ìgbà ẹ̀wẹ̀, a máa ṣubú sinu omi.

16 Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣugbọn wọn kò lè wò ó sàn.”

17 Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ ati ìran tí ó bàjẹ́ yìí, ìgbà wo ni n óo wà lọ́dọ̀ yín dà? Ìgbà wo ni n óo sì fara dà á fun yín dà? Ẹ mú ọmọ náà wá síhìn-ín.”

18 Jesu bá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà kí ó jáde kúrò ninu rẹ̀, ara ọmọ náà sì dá láti ìgbà náà.

19 Nígbà tí ó yá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu níkọ̀kọ̀, wọn bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”

20 Ó dá wọn lóhùn pé, “Nítorí igbagbọ yín tí ó kéré ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹ bá ní igbagbọ tí kò ju wóró musitadi tí ó kéré pupọ lọ, tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbẹ̀,’ yóo sì kúrò. Kó ní sí ohun kan tí ẹ kò ní lè ṣe. [

21 Irú ẹ̀mí burúkú báyìí kò lè jáde àfi nípa adura ati ààwẹ̀.”]

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

22 Nígbà tí wọ́n péjọ ní Galili Jesu sọ fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́,

23 wọn yóo pa á; a óo sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”

Ọ̀rọ̀ yìí bà wọ́n ninu jẹ́ pupọ.

Jesu San Owó Tẹmpili

24 Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, àwọn tí ń gba owó Tẹmpili lọ sí ọ̀dọ̀ Peteru, wọ́n bi í pé, “Ṣé olùkọ́ni yín kì í san owó Tẹmpili ni?”

25 Ó ní, “Kí ló dé? A máa san án.”

Nígbà tí ó dé ilé, Jesu ló ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ni o rò, Simoni? Lọ́wọ́ àwọn ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó-orí tabi owó-odè? Lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ ni tabi lọ́wọ́ àlejò?”

26 Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àlejò ni.”

Jesu wá sọ fún un pé, “Èyí ni pé kò kan àwọn ọmọ onílẹ̀.

27 Sibẹ kí á má baà jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún wọn, lọ sí etí òkun, ju ìwọ̀ sí omi; ẹja kinni tí o bá fà sókè, mú un, ya ẹnu rẹ̀, o óo rí owó fadaka kan níbẹ̀. Mú un kí o fi fún wọ́n fún owó tèmi ati tìrẹ.”

Categories
MATIU

MATIU 18

Ta ní Ṣe Pataki Jùlọ ní Ìjọba Ọ̀run?

1 Ní àkókò náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Ta ní ṣe pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run?”

2 Jesu bá pe ọmọde kan, ó mú un dúró láàrin wọn,

3 ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ kò bá yipada kí ẹ dàbí àwọn ọmọde, ẹ kò ní wọ ìjọba ọ̀run.

4 Nítorí náà ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọde yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run.

5 Ẹni tí ó bá gba ọ̀kan ninu irú àwọn ọmọde wọnyi ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà.

Ẹ̀tàn sí Ẹ̀ṣẹ̀

6 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun.

7 Ìdájọ́ ńlá ń bẹ fún ayé, nítorí àwọn ohun ìkọsẹ̀. Dandan ni kí àwọn ohun ìkọsẹ̀ dé, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ohun ìkọsẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, ó gbé!

8 “Bí ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àbùkù ọwọ́ tabi ti ẹsẹ̀, jù pé kí o ní ọwọ́ meji tabi ẹsẹ̀ meji kí á sọ ọ́ sinu iná àjóòkú lọ.

9 Bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu ojú kan jù pé kí o ní ojú meji kí á sọ ọ́ sinu iná ọ̀run àpáàdì lọ.

Òwe Aguntan tí Ó Sọnù

10 “Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fi ojú tẹmbẹlu ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi; nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, àwọn angẹli wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ lọ́run nígbà gbogbo. [

11 Nítorí Ọmọ-Eniyan wá láti gba àwọn tí ó ti sọnù là.]

12 “Kí ni ẹ rò? Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan, tí ọ̀kan ninu wọn bá sọnù, ǹjẹ́ ọkunrin náà kò ní fi aguntan mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ lórí òkè, kí ó lọ wá èyí tí ó sọnù?

13 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá rí i, inú rẹ̀ yóo dùn sí i ju àwọn mọkandinlọgọrun-un tí kò sọnù lọ.

14 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run pé kí ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi kí ó ṣègbé.

Arakunrin tí Ó Bá Dẹ́ṣẹ̀

15 “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, tètè lọ bá a sọ̀rọ̀, ìwọ rẹ̀ meji péré. Bí ó bá gbà sí ọ lẹ́nu, o ti tún sọ ọ́ di arakunrin rẹ tòótọ́.

16 Bí kò bá gbọ́, tún lọ bá a sọ ọ́, ìwọ ati ẹnìkan tabi ẹni meji; gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ẹ̀rí ẹnu eniyan meji tabi mẹta ni a óo fi mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.

17 Bí kò bá gba tiwọn, sọ fún ìjọ. Bí kò bá gba ti ìjọ, kà á kún alaigbagbọ tabi agbowó-odè.

18 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run; ohunkohun tí ẹ bá tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.

Adura Àgbàpọ̀

19 “Mo tún sọ fun yín pé bí ẹni meji ninu yín bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé nípa ohunkohun tí wọn bá bèèrè, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún wọn láti ọ̀dọ̀ Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

20 Nítorí níbi tí ẹni meji tabi mẹta bá péjọ ní orúkọ mi, mo wà níbẹ̀ láàrin wọn.”

Òwe Ẹrú tí Kò Ní Ẹ̀mí Ìdáríjì

21 Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Oluwa, ìgbà mélòó ni arakunrin mi óo ṣẹ̀ mí tí n óo dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?”

22 Jesu dá a lóhùn pé, “N kò sọ fún ọ pé ìgbà meje; ṣugbọn kí ó tó ìgbà meje lọ́nà aadọrin!

23 Nítorí pé ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ yanjú owó òwò pẹlu àwọn ẹrú rẹ̀.

24 Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣírò owó, wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọ̀kẹ́ àìmọye.

25 Kò ní ohun tí yóo fi san gbèsè yìí, nítorí náà olówó rẹ̀ pàṣẹ pé kí á ta òun ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ní, kí á fi san gbèsè rẹ̀.

26 Ẹrú náà bá dọ̀bálẹ̀, ó bẹ olówó rẹ̀ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san gbogbo gbèsè mi fún ọ.’

27 Olówó rẹ̀ wá ṣàánú rẹ̀, ó bá dá a sílẹ̀, ó sì bùn ún ní owó tí ó yá.

28 “Nígbà tí ẹrú náà jáde, ó rí ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ó jẹ ẹ́ ní eélòó kan. Ó bá dì í mú, ó fún un lọ́rùn, ó ní; ‘San gbèsè tí o jẹ mí.’

29 Ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá dọ̀bálẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe sùúrù fún mi, n óo san án fún ọ.’

30 Ṣugbọn kò gbà; ẹ̀wọ̀n ni ó ní kí wọ́n lọ jù ú sí títí yóo fi san gbèsè tí ó jẹ.

31 Nígbà tí àwọn ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn pupọ, wọ́n bá lọ ro ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún olówó wọn.

32 Olówó ẹrú náà bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Ìwọ ẹrú burúkú yìí! Mo bùn ọ́ ní adúrú gbèsè nnì nítorí o bẹ̀ mí.

33 Kò ha yẹ kí ìwọ náà ṣàánú ẹrú, ẹlẹgbẹ́ rẹ, bí mo ti ṣàánú rẹ?’

34 Inú bí olówó rẹ̀, ó bá fà á fún ọ̀gá àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n títí yóo fi san gbogbo gbèsè tí ó jẹ tán.

35 “Bẹ́ẹ̀ ni Baba mi ọ̀run yóo ṣe si yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kò bá fi tọkàntọkàn dáríjì arakunrin rẹ̀.”

Categories
MATIU

MATIU 19

Ẹ̀kọ́ nípa Ipò Ọkọ ati Aya sí Ara Wọn

1 Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ó kúrò ní Galili, ó dé ìgbèríko Judia ní òdìkejì odò Jọdani.

2 Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé e tí ó sì wòsàn níbẹ̀.

3 Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò; wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà pé kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdí kankan?”

4 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀, takọ-tabo ni ó dá wọn,

5 tí ó sì wí pé, ‘Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo fi fi baba ati ìyá rẹ́ sílẹ̀ tí yóo fara mọ́ iyawo rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo wá di ara kan?’

6 Èyí ni pé wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́, bíkòṣe ọ̀kan. Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, eniyan kò gbọdọ̀ yà á.”

7 Wọ́n bá tún bi í pé, “Kí ló dé tí Mose fi pàṣẹ pé kí ọkọ fún aya ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?”

8 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Nítorí líle ọkàn yín ni Mose fi gbà fun yín láti kọ aya yín sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.

9 Mo sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí kò bá jẹ́ nítorí àgbèrè, tí ó bá fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe àgbèrè.”

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ọ̀ràn láàrin ọkunrin ati obinrin bá rí bẹ́ẹ̀, kò ṣe anfaani láti gbeyawo.”

11 Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó lè gba nǹkan yìí, àfi àwọn tí Ọlọrun bá fi fún láti gbà á.

12 Nítorí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ akúra kí á tó bí wọn, eniyan sọ àwọn mìíràn di akúra; àwọn ẹlòmíràn sì sọ ara wọn di akúra nítorí ti ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gba èyí, kí ó gbà á.”

Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde

13 Ní àkókò yìí ni wọ́n gbé àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì súre fún wọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí wọn gbé wọn wá wí.

14 Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má dí wọn lọ́nà, nítorí ti irú wọn ni ìjọba ọ̀run.”

15 Ó bá gbé ọwọ́ lé wọn; ó sì kúrò níbẹ̀.

Ìtàn Ọdọmọkunrin Ọlọ́rọ̀

16 Nígbà kan, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Olùkọ́ni, nǹkan rere wo ni kí n ṣe kí n lè ní ìyè ainipẹkun?”

17 Jesu sọ fún un pé, “Nítorí kí ni o ṣe ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kanṣoṣo ni ó wà. Bí o bá fẹ́ wọ inú ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

18 Ó bi Jesu pé, “Òfin bí irú èwo?”

Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké.

19 Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ. Ati pé, fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.”

20 Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?”

21 Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.”

22 Nígbà tí ọdọmọkunrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò níbẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́ nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.

23 Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run.

24 Mo tún ń wí fun yín pé yóo rọrùn fún ràkúnmí láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun lọ.”

25 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, ẹnu yà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo rí ìgbàlà?”

26 Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”

27 Peteru bá bi í pé, “Wò ó, àwa ti fi ilé ati ọ̀nà sílẹ̀, a wá ń tẹ̀lé ọ. Kí ni yóo jẹ́ èrè wa?”

28 Jesu sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá di àkókò àtúndá ayé, tí Ọmọ-Eniyan bá jókòó lórí ìtẹ́ ìgúnwà rẹ̀, ẹ̀yin náà tí ẹ tẹ̀lé mi yóo jókòó lórí ìtẹ́ mejila, ẹ óo máa ṣe ìdájọ́ lórí ẹ̀yà Israẹli mejila.

29 Gbogbo ẹni tí ó bá sì fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, baba tabi ìyá, ọmọ tabi ilẹ̀ sílẹ̀, nítorí orúkọ mi, yóo gba ìlọ́po-ìlọ́po ní ọ̀nà ọgọrun-un, yóo sì tún jogún ìyè ainipẹkun.

30 Ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn; àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú.