Categories
MAKU

MAKU 10

Ẹ̀kọ́ Nípa Ipò Ọkọ ati Aya sí Ara Wọn

1 Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.

2 Àwọn Farisi bá jáde wá, wọ́n ń bi í bí ó bá tọ́ kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè yìí dán an wò ni.

3 Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ni Mose pa láṣẹ fun yín?”

4 Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda pé kí ọkọ kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún iyawo rẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́.”

5 Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Nítorí oríkunkun yín ni Mose fi kọ òfin yìí.

6 Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, takọ-tabo ni Ọlọrun dá wọn.

7 Nítorí èyí ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóo wá fi ara mọ́ iyawo rẹ̀;

8 àwọn mejeeji yóo wá di ọ̀kan. Wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́ bíkòṣe ọ̀kan.

9 Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà á.”

10 Nígbà tí wọ́n pada wọ inú ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í nípa ọ̀rọ̀ náà.

11 Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí ó gbé ẹlòmíràn ní iyawo, ó ṣe àgbèrè sí iyawo rẹ̀ àkọ́kọ́.

12 Bí ó bá sì jẹ́ pé obinrin ni ó kọ ọkọ rẹ̀, tí ó fẹ́ ọkọ mìíràn, òun náà ṣe àgbèrè.”

Jesu Bukun Àwọn Ọmọde

13 Àwọn kan gbé àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí.

14 Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.

15 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọmọde, kò ní wọ ìjọba ọ̀run.”

16 Nígbà náà ni Jesu gbé àwọn ọmọde náà lọ́wọ́, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì súre fún wọn.

Ọkunrin Ọlọrọ̀ kan

17 Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

18 Ṣugbọn Jesu wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan, àfi Ọlọrun nìkan.

19 Ṣé o mọ àwọn òfin: má paniyan, má ṣe àgbèrè, má jalè, má jẹ́rìí èké, má rẹ́nijẹ, bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ?”

20 Ọkunrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin ni mo ti ń pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́.”

21 Jesu wá tẹjú mọ́ ọn, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ wò ó, ó wí fún un pé, “Nǹkankan ló kù kí o ṣe: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn aláìní, o óo wá ní ọrọ̀ ní ọ̀run; lẹ́yìn náà wá, kí o máa tẹ̀lé mi.”

22 Ṣugbọn ojú ọkunrin náà fàro nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó bá jáde lọ pẹlu ìbànújẹ́, nítorí pé ọrọ̀ tí ó ní pọ̀.

23 Jesu bá wo ọ̀tún, ó wo òsì, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Yóo ṣòro pupọ fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!”

24 Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí gbolohun yìí. Ṣugbọn Jesu tún wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọde, yóo ṣòro pupọ láti wọ ìjọba Ọlọrun!

25 Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!”

26 Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pupọ. Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo là?”

27 Jesu tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Kò ṣeéṣe fún eniyan, ṣugbọn ti Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.”

28 Peteru bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé, “Wò ó ná, a ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ láti tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”

29 Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí ẹnìkan tí ó fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi ìyá, tabi baba, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, sílẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere,

30 tí kò ní rí ilé, arakunrin ati arabinrin, ìyá ati ọmọ, ati ilẹ̀ gbà ní ọgọrun-un ìlọ́po ní ìgbà ìsinsìnyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹlu inúnibíni ni, yóo sì tún rí ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.

31 Ṣugbọn ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ẹni iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo wá di ẹni iwájú.”

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

32 Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, tí wọn ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, Jesu ṣáájú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹ̀rù sì ba àwọn eniyan tí wọ́n tẹ̀lé e. Ó bá tún pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun fún wọn.

33 Ó ní, “Lílọ ni à ń lọ sí Jerusalẹmu yìí, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin lọ́wọ́. Wọn yóo dá a lẹ́bi ikú, wọn yóo sì fi lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.

34 Wọn yóo fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n yóo tutọ́ sí i lára, wọn yóo nà án, wọn yóo sì pa á. Ṣugbọn lẹ́yìn ọjọ́ mẹta yóo jí dìde.”

Jakọbu ati Johanu Bèèrè Ipò Ọlá

35 Nígbà náà ni Jakọbu ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ kí o ṣe ohunkohun tí a bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ fún wa.”

36 Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”

37 Wọ́n ní, “Gbà fún wa pé, nígbà tí ó bá di ìgbà ìgúnwà rẹ, kí ọ̀kan ninu wa jókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ, kí ẹnìkejì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ.”

38 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ṣé ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu, tabi kí ojú yín rí irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí?”

39 Wọ́n wí fún un pé, “Àwa lè ṣe é.”

Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ninu irú ife ìrora tí n óo mu ẹ̀yin náà yóo mu, irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí, tiyín náà yóo sì rí i.

40 Ṣugbọn ní ti jíjókòó ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ati ẹ̀gbẹ́ òsì mi, kì í ṣe tèmi láti fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí Ọlọrun ti pèsè wọn sílẹ̀ fún.”

41 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá yòókù gbọ́, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí wọn sí Jakọbu ati Johanu.

42 Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn,

43 ṣugbọn tiyín kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ pataki láàrin yín níláti jẹ́ iranṣẹ yín;

44 ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ aṣaaju ninu yín níláti máa ṣe ẹrú gbogbo yín.

45 Nítorí Ọmọ-Eniyan pàápàá kò wá pé kí eniyan ṣe iranṣẹ fún un, ó wá láti ṣe iranṣẹ ni, ati láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan.”

Jesu Wo Batimiu Afọ́jú Sàn

46 Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe.

47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!”

48 Ọpọlọpọ eniyan ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn sibẹ ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi.”

49 Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.”

Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.”

50 Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà bọ́ aṣọ rẹ̀ sọ sí apá kan, ó fò sókè, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.

51 Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”

Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.”

52 Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.”

Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà.

Categories
MAKU

MAKU 11

Jesu fi Ẹ̀yẹ wọ Jerusalẹmu

1 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, nítòsí Bẹtifage ati Bẹtani, ní orí Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀;

2 ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ẹ̀ ń wò ní ọ̀kánkán yìí, bí ẹ bá ti wọ inú rẹ̀, ẹ óo rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí, tí wọ́n so mọ́ èèkàn, ẹ tú u, kí ẹ fà á wá.

3 Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú u?’ Kí ẹ dáhùn pé, ‘Oluwa fẹ́ lò ó ni, lẹsẹkẹsẹ tí ó bá ti lò ó tán yóo dá a pada sibẹ.’ ”

4 Wọ́n lọ, wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu ìlẹ̀kùn lóde, lẹ́bàá títì, wọ́n bá tú u.

5 Àwọn kan tí wọ́n ti jókòó níbẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”

6 Wọ́n bá dá wọn lóhùn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti wí fún wọn. Àwọn eniyan náà sì yọ̀ǹda fún wọn.

7 Wọ́n bá fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí orí rẹ̀, Jesu bá gùn un.

8 Ọpọlọpọ eniyan tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà, àwọn mìíràn tẹ́ ẹ̀ka igi tí wọ́n ya ní pápá.

9 Àwọn tí ó ń lọ ní iwájú ati àwọn tí ó ń bọ̀ ní ẹ̀yìn ń kígbe pé,

“Hosana!

Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa.

10 Ibukun ni ìjọba tí ń bọ̀,

ìjọba Dafidi baba ńlá wa.

Hosana ní òkè ọ̀run!”

11 Nígbà tí ó wọ Jerusalẹmu, ó wọ àgbàlá Tẹmpili, ó wo ohun gbogbo yíká. Nítorí ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹtani pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.

Jesu Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Gégùn-ún

12 Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń jáde kúrò ní Bẹtani, ebi ń pa á.

13 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ní ewé lókèèrè, ó bá lọ wò ó bí yóo rí èso lórí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ìdí rẹ̀ kò rí ohunkohun àfi ewé, nítorí kò ì tíì tó àkókò èso.

14 Jesu wí fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má rí èso jẹ lórí rẹ mọ́ lae!”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbọ́.

Jesu Lòdì sí Lílò tí Wọn Ń Lo Tẹmpili Bí Ọjà

15 Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, Jesu wọ àgbàlá Tẹmpili lọ, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí wọn ń tà ati àwọn tí wọn ń rà jáde. Ó ti tabili àwọn onípàṣípààrọ̀ owó ṣubú, ó da ìsọ̀ àwọn tí ń ta ẹyẹlé rú.

16 Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé ohunkohun la àgbàlá Tẹmpili kọjá.

17 Ó ń kọ́ wọn pé, “Kò ha wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura fún gbogbo orílẹ̀-èdè ni a óo máa pe ilé mi?’ Ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!”

18 Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin gbọ́, wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi pa á. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, nítorí ìyàlẹ́nu ni ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo eniyan.

19 Nígbà tí ọjọ́ rọ̀ Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú.

Ẹ̀kọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Ó Gbẹ

20 Nígbà tí ó di òwúrọ̀, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ àná ti gbẹ patapata láti orí dé gbòǹgbò.

21 Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ àná. Ó wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, wo igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o fi gégùn-ún, ó ti gbẹ!”

22 Jesu dáhùn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ ní igbagbọ ninu Ọlọrun;

23 mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè yìí pé, ‘ṣídìí kúrò níbi tí o wà, kí o bọ́ sí inú òkun,’ tí kò bá ṣiyèméjì, ṣugbọn tí ó gbàgbọ́ pé, ohun tí òun wí yóo rí bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún un.

24 Nítorí èyí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ohun gbogbo tí ẹ bá bèèrè ninu adura, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fun yín.

25 Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [

26 Bí ẹ kò bá dárí ji eniyan, Baba yín ọ̀run kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”]

Ìbéèrè Nípa Àṣẹ tí Jesu Ń Lò

27 Wọ́n tún wá sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ninu Tẹmpili, àwọn olórí alufaa, ati àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

28 Wọ́n ń bi í pé, “Irú àṣẹ wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó fún ọ ní àṣẹ tí o fi ń ṣe wọ́n?”

29 Jesu dá wọn lóhùn, ó ní, “N óo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn, èmi náà óo wá sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi.

30 Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run ni ó ti gba àṣẹ ni, tabi láti ọwọ́ eniyan? Ẹ dá mi lóhùn.”

31 Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn pé, “Bí a bá wí pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo sọ pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’

32 Àbí kí a wí pé, ‘Láti ọwọ́ eniyan ni?’ ” Wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan nítorí gbogbo eniyan ni ó gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu.

33 Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”

Nígbà náà ni Jesu sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi fun yín.”

Categories
MAKU

MAKU 12

Òwe Nípa Àwọn Alágbàro Ọgbà Àjàrà

1 Jesu bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu oko kan, ó sì ṣe ọgbà yí i ká. Ó wa ihò ìfúntí sí ibẹ̀, ó kọ́ ilé-ìṣọ́, ó gba àwọn alágbàro tí yóo máa mú ninu èso àjàrà fi ṣe owó ọ̀yà wọn. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ìdálẹ̀.

2 Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán ẹrú rẹ̀ kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alágbàro náà pé, kí ó lọ gbà ninu èso àjàrà wá lọ́wọ́ wọn.

3 Ṣugbọn nínà ni wọ́n nà án, wọ́n bá lé e pada ní ọwọ́ òfo.

4 Ó tún rán ẹrú mìíràn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n lu òun lórí ní àlùbẹ́jẹ̀, wọ́n sì dójú tì í.

5 Nígbà tí ó rán ẹrú mìíràn lọ, pípa ni wọ́n pa á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ọpọlọpọ àwọn ẹrú mìíràn, wọ́n lu àwọn kan, wọ́n pa àwọn mìíràn.

6 Ó wá ku ẹnìkan tíí ṣe àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Òun ni ó rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọn yóo bu ọlá fún ọmọ mi.’

7 Ṣugbọn àwọn alágbàro náà wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ jẹ́ tiwa.’

8 Nígbà náà ni wọ́n mú un, wọ́n pa á, wọ́n bá wọ́ ọ jù sẹ́yìn ọgbà àjàrà.

9 “Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà yóo ṣe? Yóo wá, yóo pa àwọn alágbàro wọ̀n-ọn-nì, yóo sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàro mìíràn.

10 Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́, pé,

‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀

ni ó di pataki igun ilé.

11 Iṣẹ́ Oluwa ni èyí,

Ìyanu ni ó jẹ́ ní ojú wa.’ ”

12 Àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin ati àwọn àgbà ń wá ọ̀nà láti mú un, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá tiwọn lọ.

Ìbéèrè nípa Owó-orí ti Ìjọba Kesari

13 Wọ́n rán àwọn kan ninu àwọn Farisi ati àwọn ọ̀rẹ́ Hẹrọdu sí i láti lọ gbọ́ tẹnu rẹ̀.

14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, sọ fún wa, ṣé ó tọ̀nà pé kí á máa san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?”

15 Ṣugbọn Jesu mọ àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí? Ẹ mú owó fadakakan wá fún mi kí n rí i.”

16 Wọ́n fún un ní ọ̀kan. Ó wá bi wọ́n pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ó wà ní ara rẹ̀ yìí?”

Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.”

17 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi nǹkan tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Ọlọrun, ẹ fi fún Ọlọrun.”

Ẹnu yà wọ́n pupọ sí ìdáhùn rẹ̀.

Ìbéèrè Nípa Ajinde

18 Ní àkókò náà, àwọn Sadusi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọ́n ní kò sí ohun tí ń jẹ́ ajinde òkú.) Wọ́n ní,

19 “Olùkọ́ni, Mose kọ òfin kan fún wa pé bí ọkunrin kan bá kú, tí ó fi aya sílẹ̀, tí kò bá ní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó kí ó lè ní ọmọ ní orúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

20 Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà, èyí ekinni fẹ́ aya, ó kú láì ní ọmọ,

21 Ekeji ṣú aya rẹ̀ lópó, ṣugbọn òun náà kú láì ní ọmọ. Ẹkẹta náà kú láì ní ọmọ.

22 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣá ṣe kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn gbogbo wọn, obinrin náà kú.

23 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ ajinde, iyawo ta ni obinrin yìí yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ni ó ti fi ṣe aya?”

24 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ti ṣìnà patapata! Àṣé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tabi agbára Ọlọrun?

25 Nítorí nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò sí pé à ń gbé iyawo tabi à ń fa obinrin fún ọkọ, ṣugbọn bí àwọn angẹli ọ̀run ni wọn yóo rí.

26 Nípa ti pé a óo jí àwọn òkú dìde tabi a kò ní jí wọn, ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mose, níbi ìtàn ìgbẹ́ tí iná ń jó, bí Ọlọrun ti wí fún Mose pé, ‘Èmi ni Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu?’

27 Èyí ni pé Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú bíkòṣe ti àwọn alààyè. Nípa ìbéèrè yìí, ẹ ti ṣìnà patapata.”

Òfin Tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ

28 Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?”

29 Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa.

30 Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo iyè inú rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.’

31 Èyí tí ó ṣìkejì ni pé, ‘Kí ìwọ fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tí ó tóbi ju èyí lọ.”

32 Amòfin náà wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Olùkọ́ni. Òtítọ́ ni o sọ pé, ‘Ọlọrun kan ni ó wà. Kò sí òmíràn lẹ́yìn rẹ̀’;

33 ati pé, ‘Kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa bí a ti fẹ́ràn ara wa’ tayọ gbogbo ẹbọ sísun ati ẹbọ yòókù.”

34 Nígbà náà ni Jesu ṣe akiyesi pé ó fi òye sọ̀rọ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọrun.”

Kò sì sí ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti tún bi í ní ìbéèrè kankan mọ́.

Ìbéèrè Jesu Nípa Ọmọ Dafidi

35 Bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili, ó bèèrè pé, “Báwo ni àwọn amòfin ṣe wí pé ọmọ Dafidi ni Kristi?

36 Dafidi fúnrarẹ̀ wí nípa ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́ pé,

‘Oluwa wí fún Oluwa mi pé:

Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

títí n óo fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.’

37 Nígbà tí Dafidi fúnrarẹ̀ pè é ní ‘Oluwa,’ báwo ni ó ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

Pẹlu ayọ̀ ni ọpọlọpọ eniyan ń fetí sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Jesu ṣe Ìkìlọ̀ Nípa Àwọn Amòfin

38 Jesu ń sọ ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ràn ati máa wọ agbádá ńlá káàkiri òde, kí eniyan máa kí wọn ní ọjà, ati láti gba ìjókòó pataki ní ilé ìpàdé.

39 Wọ́n fẹ́ràn ipò ọlá nínú sinagọgu ati ní ibi àsè.

40 Wọ́n a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gbadura gígùn nítorí àṣehàn. Ìdájọ́ tí wọn yóo gbà yóo le pupọ.”

Ọrẹ Opó Kan

41 Bí Jesu ti jókòó lọ́kàn-ánkán àpótí owó, ó ń wò bí ọpọlọpọ eniyan ti ń dá owó sinu àpótí. Ọpọlọpọ àwọn ọlọ́rọ̀ ń dá owó pupọ sinu àpótí owó.

42 Nígbà náà ni talaka opó kan wá, ó dá eépìnnìmeji tí ó jẹ́ kọbọkan sinu àpótí.

43 Jesu wá tọ́ka sí èyí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Mo ń wí fun yín gbangba pé opó talaka yìí dá owó ju gbogbo àwọn tí ó dá owó sinu àpótí lọ.

44 Nítorí ninu ọpọlọpọ ọrọ̀ ni àwọn yòókù ti mú ohun tí wọ́n dá, ṣugbọn òun, ninu àìní rẹ̀, ó dá gbogbo ohun tí ó ní, àní gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀.”

Categories
MAKU

MAKU 13

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Wíwó Tẹmpili

1 Bí ó ti ń jáde kúrò ninu Tẹmpili, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olùkọ́ni, wo òkúta wọnyi ati ilé yìí, wò ó bí wọn ti tóbi tó!”

2 Jesu wí fún un pé, “O rí ilé yìí bí ó ti tóbi tó? Kò ní sí òkúta kan lórí ekeji níhìn-ín tí a kò ní wó lulẹ̀.”

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìrora

3 Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé,

4 “Sọ fún wa, nígbà wo ni àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣẹ ati pé kí ni àmì tí yóo hàn kí gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tó rí bẹ́ẹ̀?”

5 Ni Jesu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tàn yín jẹ.

6 Ọpọlọpọ yóo wá ní orúkọ mi tí wọ́n yóo wí pé àwọn ni Kristi. Wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ.

7 Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa oríṣìíríṣìí ogun nítòsí ati ní ọ̀nà jíjìn, ẹ má ṣe dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ó níláti rí, ṣugbọn òpin ayé kò tíì dé.

8 Nítorí orílẹ̀-èdè yóo gbé ogun ti orílẹ̀-èdè, ìjọba yóo dìde sí ìjọba, ilẹ̀ yóo mì tìtì ní oríṣìíríṣìí ìlú, ìyàn yóo mú ní ọpọlọpọ ilẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora nìwọ̀nyí.

9 “Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn.

10 Ṣugbọn a níláti kọ́kọ́ waasu ìyìn rere fún orílẹ̀-èdè gbogbo ná.

11 Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

12 Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yóo ṣe ikú pa ara wọn; bẹ́ẹ̀ ni baba yóo ṣe sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóo tàpá sí àwọn òbí wọn, wọn yóo sì pa wọ́n.

13 Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun ni a óo gbàlà.

Àkókò Ìpọ́njú Ńlá

14 “Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rí ẹ̀gbin burúkú náà tí ó dúró níbi tí kò yẹ– (kí ó yé ẹni tí ń ka ìwé yìí)– nígbà náà, kí àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ Judia sálọ sí orí òkè.

15 Nígbà tí ẹni tí ó wà ní òkè ilé bá sọ̀kalẹ̀, kí ó má ṣe wọ ilé lọ láti mú ohunkohun jáde.

16 Kí alágbàro ní oko má ṣe dúró mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀.

17 Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ náà yóo jẹ́ fún àwọn aboyún ati àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní àkókò náà.

18 Kí ẹ gbadura kí ó má jẹ́ àkókò tí òtútù mú pupọ.

19 Nítorí ìpọ́njú yóo wà ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ohun gbogbo títí di àkókò yìí, kò sì ní sí irú rẹ̀ mọ́ lae.

20 Bí kò bá jẹ́ pé Oluwa dín àkókò náà kù, ẹ̀dá kankan kì bá tí kù láàyè. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́ tí Ọlọrun yàn, ó dín àkókò rẹ̀ kù.

21 “Bí ẹnikẹ́ni bá wí fun yín pé. ‘Wo Kristi níhìn-ín,’ tabi ‘Wò ó lọ́hùn-ún,’ ẹ má gbàgbọ́.

22 Nítorí àwọn Kristi èké ati àwọn wolii èké yóo dìde, wọn yóo máa ṣe iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ. Wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ, bí ó bá ṣeéṣe.

23 Ṣugbọn ẹ̀yin, ní tiyín, ẹ ṣọ́ra. Mo ti sọ ohun gbogbo fun yín tẹ́lẹ̀.

Dídé Ọmọ-Eniyan

24 “Ní àkókò náà, lẹ́yìn ìpọ́njú yìí oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

25 Àwọn ìràwọ̀ yóo máa já bọ́ láti ojú ọ̀run, a óo wá mi gbogbo àwọn ogun ọ̀run.

26 Nígbà náà ni wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí yóo máa bọ̀ ninu awọsanma pẹlu agbára ńlá ati ògo.

27 Yóo wá rán àwọn angẹli láti lọ kó àwọn àyànfẹ́ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé, láti òpin ayé títí dé òpin ọ̀run.

Ẹ̀kọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́

28 “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó rú ewé, ẹ mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ ìtòsí.

29 Bákan náà nígbà tí ẹ bá rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, kí ẹ mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan wà nítòsí, ó fẹ́rẹ̀ dé.

30 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹ.

31 Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ.

Nígbà Wo ni Àkókò Náà?

32 “Ṣugbọn ní ti ọjọ́ ati wakati náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀, àwọn angẹli kò mọ̀, Ọmọ pàápàá kò mọ̀, àfi Baba.

33 Ẹ ṣọ́ra, ẹ máa fojú sọ́nànítorí ẹ kò mọ wakati náà.

34 Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà.

35 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣọ́nà nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí baálé ilé náà yóo dé: bí ní ìrọ̀lẹ́ ni, tabi ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tabi ní àfẹ̀mọ́jú.

36 Bí ó bá dé lójijì, kí ó má baà ba yín lójú oorun.

37 Ohun tí mò ń wí fun yín ni mò ń wí fún gbogbo eniyan: ẹ máa ṣọ́nà.”

Categories
MAKU

MAKU 14

Ọ̀tẹ̀ Láti Pa Jesu

1 Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á.

2 Nítorí wọ́n ń wí pé, “Kí ó má jẹ́ àkókò àjọ̀dún, kí rògbòdìyàn má baà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn eniyan.”

Obinrin kan Fi Òróró Kun Jesu ní Bẹtani

3 Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, bí ó ti jókòó tí ó fẹ́ máa jẹun ní ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé wá tí ó mú ìgò ojúlówó òróró ìpara olóòórùn dídùn kan tí ó ní iye lórí lọ́wọ́. Ó fọ́ ìgò náà, ó bá tú òróró inú rẹ̀ sí Jesu lórí.

4 Ṣugbọn inú bí àwọn kan níbẹ̀, wọ́n ń sọ̀ láàrin ara wọn pé, “Kí ló dé tí a fi ń fi òróró yìí ṣòfò báyìí?

5 Bí a bá tà á, ìbá tó nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka,à bá sì fún àwọn talaka.” Báyìí ni wọ́n ń fi ohùn líle bá obinrin náà wí.

6 Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu sí? Ohun rere ni ó ṣe sí mi.

7 Nítorí ìgbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, nígbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́, ẹ lè ṣe nǹkan fún wọn; ṣugbọn kì í ṣe ìgbà gbogbo ni èmi yóo máa wà láàrin yín.

8 Ó ti ṣe ohun tí ó lè ṣe: ó fi òróró kun ara mi ní ìpalẹ̀mọ́ ìsìnkú mi.

9 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, a óo máa sọ ohun tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀ níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé.”

Judasi Ṣe Ètò láti Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀

10 Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila, bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa, ó lọ fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

11 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó bá wá, inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Judasi wá ń wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

Àjọ̀dún Ìrékọjá

12 Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọn máa ń pa aguntan láti ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?”

13 Ó bá rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín, ẹ tẹ̀lé e.

14 Kí ẹ sọ fún baálé ilé tí ó bá wọ̀ pé, ‘Olùkọ́ni wí pé yàrá wo ni ààyè wà fún mi, níbi tí èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ti lè jẹ àsè Ìrékọjá?’

15 Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín, ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí wọn ti tọ́jú sílẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”

16 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ, wọ́n wọ inú ìlú, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn; wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.

17 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jesu wá sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.

18 Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”

19 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dààmú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Àbí èmi ni?”

20 Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ọ̀kan ninu ẹ̀yin mejeejila ni, tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ pẹlu mi ninu àwo kan náà.

21 Nítorí Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

22 Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.”

23 Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀.

24 Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan.

25 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé n kò ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ tí n óo mu ún ní ọ̀tun ninu ìjọba Ọlọrun.”

26 Lẹ́yìn tí wọ́n kọ orin tán, wọ́n jáde lọ sí Òkè Olifi.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun

27 Jesu bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, àwọn aguntan yóo bá fọ́nká,’

28 Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.”

29 Ṣugbọn Peteru wí fún un pé, “Bí gbogbo eniyan bá pada lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní pada.”

30 Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ní alẹ́ yìí kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ náà yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”

31 Ṣugbọn Peteru tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Bí ó bá kan ọ̀ràn pé kí n bá ọ kú, sibẹ n kò ní sẹ́ ọ!”

Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń wí.

Jesu Gbadura ní Gẹtisemani

32 Wọ́n dé ibìkan tí wọn ń pè ní Gẹtisemani. Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí mo bá lọ gbadura.”

33 Ó wá mú Peteru, Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀. Àyà bẹ̀rẹ̀ sí pá a, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú.

34 Ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ lè kú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ máa ṣọ́nà.”

35 Ó bá lọ sí iwájú díẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó ń gbadura pé bí ó bá ṣeéṣe kí àkókò yìí kọjá lórí òun.

36 Ó ní, “Baba, Baba, ohun gbogbo ṣeéṣe fún ọ. Mú kí ife kíkorò yìí kọjá kúrò lórí mi. Ṣugbọn ìfẹ́ tìrẹ ni kí o ṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”

37 Ó pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹta, ó rí i pé wọ́n ti sùn lọ! Ó wí fún Peteru pé, “Simoni, ò ń sùn ni? O kò lè ṣọ́nà fún wakati kan péré?

38 Gbogbo yín, ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ tún máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.”

39 Ó tún lọ gbadura, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà bíi ti àkọ́kọ́.

40 Ó tún wá, ó rí i pé wọ́n tún ń sùn, nítorí pé oorun ń kùn wọ́n pupọ. Wọn kò wá mọ ìdáhùn tí wọn ì bá fi fún un mọ́.

41 Ó pada wá ní ẹẹkẹta, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣì wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń gbádùn ìsinmi yín? Àbùṣe bùṣe! Àkókò náà tó. Wọn yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

42 Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ. Ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ti súnmọ́ tòsí.”

Judasi Fi Jesu Fún Àwọn Ọ̀tá

43 Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila dé, pẹlu àwọn eniyan tí ó mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà.

44 Ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá ti fi àmì fún wọn. Ó ní, “Ẹni tí mo bá kí, tí mo fi ẹnu kàn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ọkunrin náà. Ẹ mú un, kí ẹ fà á lọ, ẹ má jẹ́ kí ó bọ́.”

45 Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé, Judasi lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó kí i, ó ní, “Olùkọ́ni!” Ó sì da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.

46 Àwọn tí ó bá a wá bá ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un.

47 Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn tí ó dúró fa idà yọ, ó fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó bá gé e létí.

48 Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ẹ mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́ láti wá mú mi bí ẹni pé ẹ̀ ń bọ̀ wá mú ọlọ́ṣà?

49 Lojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili tí mò ń kọ́ àwọn eniyan, ẹ kò ṣe mú mi nígbà náà. Ṣugbọn kí àkọsílẹ̀ lè ṣẹ ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.”

50 Nígbà náà ni Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá fi í sílẹ̀, wọ́n bá sálọ.

51 Ọdọmọkunrin kan tí ó jẹ́ pé aṣọ funfun nìkan ni ó dà bo ara ń tẹ̀lé e. Nígbà tí wọ́n gbá a mú,

52 ó fi aṣọ ìbora rẹ̀ sílẹ̀, ó bá sálọ níhòòhò.

Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Ìgbìmọ̀

53 Wọ́n mú Jesu lọ sí ọ̀dọ̀ Olórí Alufaa, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ati àwọn amòfin wá péjọ sibẹ.

54 Peteru wà ní òkèèrè, ó ń tẹ̀lé e títí ó fi wọ agbo-ilé Olórí Alufaa, ó bá jókòó pẹlu àwọn iranṣẹ, wọ́n jọ ń yá iná.

55 Àwọn olórí alufaa ati gbogbo Ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí tí ó lòdì sí Jesu, kí wọ́n baà lè pa á, ṣugbọn wọn kò rí.

56 Nítorí ọpọlọpọ ní ń jẹ́rìí èké sí i, ṣugbọn ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu.

57 Àwọn kan wá dìde, wọ́n ń jẹ́rìí èké sí i pé,

58 “A gbọ́ nígbà tí ó ń wí pé, ‘Èmi yóo wó Tẹmpili tí eniyan kọ́ yìí, láàrin ọjọ́ mẹta, èmi óo gbé òmíràn dìde tí eniyan kò kọ́.’ ”

59 Sibẹ ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu.

60 Nígbà náà ni Olórí Alufaa dìde láàrin wọn, ó bi Jesu pé, “Ìwọ kò fèsì rárá?”

61 Ṣugbọn ó sá dákẹ́ ni, kò fèsì kankan.

Olórí Alufaa tún bi í pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún?”

62 Jesu dáhùn pé, “Èmi ni. Ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.”

63 Olórí Alufaa bá fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó ní, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá?

64 Ẹ ti gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun! Kí ni ẹ wí?”

Gbogbo wọn bá dá a lẹ́bi, wọ́n ní ikú ni ó tọ́ sí i.

65 Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lára. Wọ́n fi aṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń sọ ọ́ ní ẹ̀ṣẹ́. Wọ́n sọ fún un pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa, wolii!” Àwọn iranṣẹ wá ń gbá a létí bí wọn ti ń mú un lọ sí àtìmọ́lé.

Peteru Sẹ́ Jesu

66 Nígbà tí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ ní agbo-ilé, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin Olórí Alufaa dé.

67 Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”

68 Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “Èmi kò mọ̀… Ohun tí ò ń sọ kò yé mi rárá!” Ó wá jáde lọ sí apá ẹnu ọ̀nà agbo-ilé. Bẹ́ẹ̀ ni àkùkọ kan bá kọ.

69 Iranṣẹbinrin náà tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn tí ó dúró pé, “Ọkunrin yìí wà ninu wọn!”

70 Ṣugbọn ó tún sẹ́.

Nígbà tí ó ṣe díẹ̀ síi àwọn tí ó dúró sọ fún Peteru pé, “Dájúdájú, o wà ninu wọn nítorí ará Galili ni ọ́.”

71 Peteru bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó bá ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.”

72 Lẹsẹkẹsẹ, àkùkọ kọ ní ẹẹkeji. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta!” Orí Peteru wú, ó bá bú sẹ́kún.

Categories
MAKU

MAKU 15

A Mú Jesu Lọ Siwaju Pilatu

1 Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́.

2 Pilatu bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”

Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”

3 Àwọn olórí alufaa ń fi ẹ̀sùn pupọ kàn án.

4 Pilatu bá tún bi í pé, “O kò sì fèsì rárá? Ìwọ kò gbọ́ bí wọ́n ti ń fi oríṣìíríṣìí ẹ̀sùn kàn ọ́ ni?”

5 Ṣugbọn Jesu kò tún dá a lóhùn rárá mọ́, èyí mú kí ẹnu ya Pilatu.

A Dá Jesu lẹ́bi Ikú

6 Ní ọdọọdún, ni àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, Pilatu a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ fún sílẹ̀.

7 Ẹnìkan wà tí ó ń jẹ́ Baraba, tí ó wà ninu ẹ̀wọ̀n pẹlu àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan tí wọ́n pa eniyan ní àkókò ọ̀tẹ̀.

8 Àwọn eniyan bá gòkè tọ Pilatu lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn.

9 Pilatu wá bi wọ́n pé, “Ẹ fẹ́ kí n dá ọba àwọn Juu sílẹ̀ fun yín bí?”

10 Nítorí ó mọ̀ pé àwọn olórí alufaa ń jowú Jesu, wọ́n sì ń ṣe kèéta rẹ̀, ni wọ́n ṣe fà á wá siwaju òun.

11 Ṣugbọn àwọn olórí alufaa rú àwọn eniyan sókè pé Baraba ni kí ó kúkú dá sílẹ̀ fún wọn.

12 Pilatu tún bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí ẹni tí ẹ̀ ń pè ní ọba àwọn Juu?”

13 Nígbà náà ni gbogbo wọn kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”

14 Ṣugbọn Pilatu bi wọ́n pé, “Nítorí kí ni? Nǹkan burúkú wo ni ó ṣe?”

Ṣugbọn wọ́n sá tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”

15 Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn kí ó lè baà tẹ́ wọn lọ́rùn. Lẹ́yìn tí ó ti ní kí wọ́n na Jesu tán, ó bá fà á fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.

Àwọn Ọmọ-ogun Fi Jesu Ṣe Ẹlẹ́yà

16 Àwọn ọmọ-ogun bá mú un lọ sí inú agbo-ilé tí ààfin gomina wà. Wọ́n pe gbogbo àwọn ọmọ-ogun yòókù,

17 wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ àlàárì, wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí.

18 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!”

19 Wọ́n ń lù ú ní igi lórí, wọ́n ń tutọ́ sí i lára, wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń júbà yẹ̀yẹ́.

20 Nígbà tí wọ́n ti fi ṣe ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì kúrò ní ara rẹ̀, wọ́n fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n bá fà á jáde láti lọ kàn án mọ́ agbelebu.

A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

21 Bí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene, baba Alẹkisanderu ati Rufọsi, ti ń ti ọ̀nà ìgbèríko bọ̀, bí ó ti ń kọjá lọ, wọ́n fi tipátipá mú un láti gbé agbelebu Jesu.

22 Wọ́n wá mú Jesu lọ sí ibìkan tí à ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”).

23 Wọ́n fún un ní ọtí tí wọ́n ti po òjíá mọ́, ṣugbọn kò gbà á.

24 Wọ́n bá kàn án mọ́ agbelebu. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí aṣọ rẹ̀ láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pín àwọn aṣọ náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́.

25 Ní agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni wọ́n kàn án mọ́ agbelebu.

26 Àkọlé orí agbelebu tí wọ́n kọ, tí ó jẹ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni: “Ọba àwọn Juu.”

27 Ní àkókò kan náà, wọ́n kan àwọn ọlọ́ṣà meji kan mọ́ agbelebu, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ọwọ́ òsì rẹ̀. [

28 Báyìí ni àkọsílẹ̀ kan ṣẹ tí ó wí pé, “A kà á kún àwọn arúfin.”]

29 Àwọn tí ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i, wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń wí pé, “Kò tán an! Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta,

30 gba ara rẹ là, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.”

31 Bákan náà ni àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn amòfin ń fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin ara wọn, wọ́n ń wí pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó le gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là.

32 Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.”

Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú.

Ikú Jesu

33 Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀, títí di agogo mẹta ọ̀sán.

34 Nígbà tí ó di agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe tòò, ó ní, “Eloi, Eloi, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

35 Nígbà tí àwọn kan ninu àwọn tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ń wí pé, “Ẹ gbọ́! Ó ń pe Elija!”

36 Ẹnìkan bá sáré, ó ti kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sí orí ọ̀pá láti fún un mu, ó ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á máa wò ó bí Elija yóo wá gbé e sọ̀kalẹ̀!”

37 Ṣugbọn Jesu kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀ ó bá dákẹ́.

38 Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili bá ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀.

39 Nígbà tí ọ̀gágun tí ó dúró lọ́kàn-ánkán rẹ̀ rí bí ó ti dákẹ́ lẹ́yìn tí ó ti kígbe, ó ní, “Dájúdájú, ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”

40 Àwọn obinrin kan wà ní òkèèrè tí wọn ń wo gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ninu wọn ni Maria Magidaleni wà, ati Maria ìyá Jakọbu kékeré ati ìyá Josẹfu, ati Salomi.

41 Àwọn wọnyi ti ń tẹ̀lé e láti ìgbà tí ó ti wà ní Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Ọpọlọpọ àwọn obinrin mìíràn wà níbẹ̀ tí wọ́n bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

Ìsìnkú Jesu

42-43 Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ tíí ṣe ọ̀sẹ̀ ku ọ̀la. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Josẹfu ará Arimatia, ọlọ́lá kan ninu àwọn ìgbìmọ̀, wá. (Ó ń retí àkókò ìjọba Ọlọrun), ó bá fi ìgboyà tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu.

44 Ṣugbọn ẹnu ya Pilatu pé Jesu ti yára kú! Ó pe ọ̀gágun, ó bèèrè bí Jesu ti kú tipẹ́.

45 Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn ọ̀gágun náà, ó yọ̀ǹda òkú Jesu fún Josẹfu.

46 Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.

47 Maria Magidaleni ati Maria ìyá Josẹfu ń wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.

Categories
MAKU

MAKU 16

Ajinde Jesu

1 Lẹ́yìn tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, Maria Magidaleni ati Maria ìyá Jakọbu ati Salomi ra òróró ìkunra, wọ́n fẹ́ lọ fi kun òkú Jesu.

2 Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n dé ibojì bí oòrùn ti ń yọ.

3-4 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn ṣàròyé pé, “Ta ni yóo bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì?” Bí wọ́n ti gbé ojú sókè, wọ́n rí i pé ẹnìkan ti yí òkúta náà kúrò, bẹ́ẹ̀ ni òkúta ọ̀hún sì tóbi gan-an.

5 Nígbà tí wọ́n wo inú ibojì, wọ́n rí ọdọmọkunrin kan tí ó jókòó ní apá ọ̀tún wọn, tí ó wọ aṣọ funfun. Wọ́n bá ta gìrì.

6 Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ṣé Jesu ará Nasarẹti tí a kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá? Ó ti jí dìde. Kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí.

7 Ṣugbọn ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati Peteru pé ó ti lọ ṣáájú yín sí Galili, níbẹ̀ ni ẹ óo gbé rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fun yín.”

8 Nígbà tí wọ́n jáde, aré ni wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, nítorí ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí wọn ń dààmú. Wọn kò sọ ohunkohun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù ń bà wọ́n.

[

9 Àwọn obinrin náà sọ ohun gbogbo tí a rán wọn fún Peteru ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ṣókí.

10 Lẹ́yìn èyí, Jesu fúnrarẹ̀ rán wọn lọ jákèjádò ayé láti kéde ìyìn rere ìgbàlà ayérayé, ìyìn rere tí ó ní ọ̀wọ̀, tí kò sì lè díbàjẹ́ lae.]

Jesu Fara han Maria Magidaleni

[

9 Nígbà tí Jesu jí dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fara han Maria Magidaleni, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje kúrò ninu rẹ̀ nígbà kan.

10 Ó lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá Jesu gbé níbi tí wọn ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọn ń sunkún.

11 Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu wà láàyè ati pé Maria ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Meji

12 Lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn meji kan ninu wọn ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn lọ sí ìgbèríko kan.

13 Wọ́n bá pada lọ ròyìn fún àwọn ìyókù. Sibẹ wọn kò gbàgbọ́.

Jesu Fara Han Àwọn Mọkanla

14 Lẹ́yìn náà ó fara han àwọn mọkanla bí wọ́n ti ń jẹun. Ó bá wọn wí fún aigbagbọ ati ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí wọ́n rí i, tí wọ́n sọ pé ó ti jinde gbọ́.

15 Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá.

16 Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí ó bá ṣe ìrìbọmi, yóo ní ìgbàlà. Ẹni tí kò bá gbàgbọ́ yóo gba ìdálẹ́bi.

17 Àwọn àmì tí yóo máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ nìwọ̀nyí; wọn yóo máa lé ẹ̀mí burúkú jáde ní orúkọ mi; wọn yóo máa fi àwọn èdè titun sọ̀rọ̀;

18 wọn yóo gbé ejò lọ́wọ́, wọn yóo mu òògùn olóró, ṣugbọn kò ní ṣe wọ́n léṣe; wọn yóo gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóo sì dá.”

Ìgòkè-Re-Ọ̀run Ti Jesu

19 Lẹ́yìn tí Jesu Oluwa ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, a gbé e lọ sí òkè ọ̀run, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.

20 Nígbà tí wọ́n túká lọ, wọ́n ń waasu ní ibi gbogbo, Oluwa ń bá wọ́n ṣiṣẹ́, ó ń fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ń bá wọn lọ.]