Categories
LUKU

LUKU 10

Jesu Rán Àwọn Mejilelaadọrin Níṣẹ́

1 Lẹ́yìn èyí, Oluwa yan àwọn mejilelaadọrinmìíràn, ó rán wọn ní meji-meji ṣiwaju rẹ̀ lọ sí gbogbo ìlú ati ibi tí òun náà fẹ́ dé.

2 Ó sọ fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí ó tó kórè pọ̀ ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀ tó. Nítorí náà, ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sí ibi ìkórè rẹ̀.

3 Ẹ máa lọ. Mo ran yín lọ bí aguntan sí ààrin ìkookò.

4 Ẹ má mú àpò owó lọ́wọ́, tabi àpò báárà. Ẹ má wọ bàtà. Bẹ́ẹ̀ ní kí ẹ má kí ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà.

5 Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, ẹ kọ́kọ́ wí pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’

6 Bí ọmọ alaafia bá wà níbẹ̀, alaafia yín yóo máa wà níbẹ̀. Bí kò bá sí, alaafia yín yóo pada sọ́dọ̀ yín.

7 Ninu ilé kan náà ni kí ẹ máa gbé. Ohun tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ fun yín ni kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu. Owó iṣẹ́ alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má máa lọ láti ilé dé ilé.

8 Ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀, tí wọn bá gbà yín, ẹ máa jẹ ohun tí wọn bá gbé kalẹ̀ níwájú yín.

9 Ẹ máa wo àwọn aláìsàn sàn. Kí ẹ sọ fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọrun ti dé àrọ́wọ́tó yín.’

10 Ṣugbọn ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀ tí wọn kò bá gbà yín, ẹ jáde lọ sí títì ibẹ̀, kí ẹ sọ pé,

11 ‘Erùpẹ̀ tí ó lẹ̀ mọ́ wa lẹ́sẹ̀ ninu ìlú yín, a gbọ̀n ọ́n kúrò kí ojú lè tì yín. Ṣugbọn kí ẹ mọ èyí pé ìjọba Ọlọrun wà ní àrọ́wọ́tó yín.’

12 Mo sọ fun yín pé yóo sàn fún Sodomu ní ọjọ́ ńlá náà jù fún ìlú náà lọ.

Jesu Dárò Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada

13 “O gbé! Korasini. O gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, wọn ìbá jókòó ninu eérú pẹlu aṣọ ọ̀fọ̀.

14 Yóo sàn fún Tire ati fún Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ.

15 Ìwọ Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o! Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí!

16 “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá kọ̀ yín èmi ni ó kọ̀. Ẹni tí ó bá sì wá kọ̀ mí, ó kọ ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.”

Àwọn Mejilelaadọrin Pada Dé

17 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejilelaadọrinpada dé pẹlu ayọ̀. Wọ́n ní, “Oluwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbọ́ràn sí wa lẹ́nu ní orúkọ rẹ.”

18 Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo rí Satani tí ó ti ọ̀run já bọ́ bí ìràwọ̀.

19 Mo fun yín ní àṣẹ láti tẹ ejò ati àkeekèé mọ́lẹ̀. Mo tún fun yín ní àṣẹ lórí gbogbo agbára ọ̀tá. Kò sí ohunkohun tí yóo pa yín lára.

20 Ẹ má yọ̀ ní ti pé àwọn ẹ̀mí èṣù gbọ́ràn si yín lẹ́nu; ṣugbọn ẹ máa yọ̀ nítorí a ti kọ orúkọ yín sí ọ̀run.”

Jesu Láyọ̀

21 Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́.Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.

22 “Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.”

23 Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ẹ ṣe oríire tí ojú yín rí àwọn ohun tí ẹ rí,

24 nítorí mò ń sọ fun yín pé ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn ọba ni wọ́n fẹ́ rí àwọn nǹkan tí ẹ rí, ṣugbọn tí wọn kò rí i; wọ́n fẹ́ gbọ́ ohun tí ẹ gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́ ọ.”

Aláàánú Ará Samaria

25 Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

26 Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?”

27 Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.”

28 Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.”

29 Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?”

30 Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán.

31 Alufaa kan tí ó ń bọ̀ ṣe kòńgẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà, ṣugbọn nígbà tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ.

32 Bákan náà ni ọmọ Lefi kan. Nígbà tí òun náà dé ibẹ̀, tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ.

33 Ṣugbọn ará Samaria kan tí ó ń gba ọ̀nà yìí kọjá lọ dé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà. Nígbà tí ó rí i, àánú ṣe é.

34 Ó bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fi òróró ati ọtí waini sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ wé e. Ó gbé ọkunrin náà ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó gùn. Ó gbé e lọ sí ilé èrò níbi tí ó ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

35 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ owó fadaka meji jáde, ó fún olùtọ́jú ilé èrò, ó ní, ‘Ṣe ìtọ́jú ọkunrin yìí. Ohun tí o bá ná lé e lórí, n óo san án fún ọ nígbà tí mo bá pada dé.’

36 “Ninu àwọn mẹta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ ọmọnikeji ẹni tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”

37 Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”

Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.”

Jesu Bẹ Mata ati Maria Wò

38 Bí wọ́n ti ń lọ ninu ìrìn àjò wọn, Jesu wọ inú abúlé kan. Obinrin kan tí ń jẹ́ Mata bá gbà á lálejò.

39 Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

40 Ṣugbọn Mata kò rójú nítorí aájò tí ó ń ṣe nípa oúnjẹ. Ni Mata bá wá, ó ní, “Alàgbà, arabinrin mi fi èmi nìkan sílẹ̀ láti máa tọ́jú oúnjẹ, o sì dákẹ́ ò ń wò ó níran! Sọ fún un kí ó wá ràn mí lọ́wọ́.”

41 Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Mata! Mata! Ò ń ṣe aájò, o sì ń dààmú nípa ohun pupọ.

42 Ṣugbọn ẹyọ nǹkankan ni ó jẹ́ koṣeemani. Maria ti yan ipò tí ó dára tí a kò ní gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”

Categories
LUKU

LUKU 11

Adura Oluwa

1 Nígbà kan, Jesu wà níbìkan, ó ń gbadura. Nígbà tí ó parí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, kọ́ wa bí a ti í gbadura gẹ́gẹ́ bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”

2 Ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ máa wí pé,

‘Baba, ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ.

Kí ìjọba rẹ dé.

3 Máa fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lojoojumọ.

4 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,

nítorí àwa náà ń dáríjì gbogbo ẹni tí ó bá jẹ wá ní gbèsè.

Má ṣe fà wá sinu ìdánwò.’ ”

5 Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní ọ̀rẹ́ kan, tí ó wá lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ yìí ní ọ̀gànjọ́ òru, tí ó sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi, yá mi ní burẹdi mẹta,

6 nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti ìrìn àjò dé bá mi, n kò sì ní oúnjẹ tí n óo fún un’;

7 kí ọ̀rẹ́ náà wá ti inú ilé dáhùn pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu. Mo ti ti ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi sì wà lórí ẹní pẹlu mi, n kò lè tún dìde kí n fún ọ ní nǹkankan mọ́.’

8 Mò ń sọ fun yín pé, bí kò tilẹ̀ fẹ́ dìde kí ó fún ọ nítorí o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nítorí tí o kò tijú láti wá kan ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lórí lóru, yóo dìde, yóo fún ọ ní ohun tí o nílò.

9 “Bákan náà mo sọ fun yín, ẹ bèèrè, a óo fi fun yín; ẹ wá kiri, ẹ óo rí; ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín.

10 Nítorí gbogbo ẹni tí ó bá bèèrè ni yóo rí gbà; ẹni tí ó bá wá kiri yóo rí; ẹni tí ó bá sì kan ìlẹ̀kùn ni a óo ṣí i fún.

11 Baba wo ninu yín ni ó jẹ́ fún ọmọ rẹ̀ ní ejò, nígbà tí ọmọ bá bèèrè ẹja?

12 Tabi bí ó bá bèèrè ẹyin tí ó jẹ́ fún un ní àkeekèé?

13 Nítorí náà bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fún àwọn ọmọ yín ní ohun tí ó dára, mélòó-mélòó ni Baba yín ọ̀run yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”

Jesu ati Beelisebulu

14 Ní ìgbà kan, Jesu ń lé ẹ̀mí èṣù kan tí ó yadi jáde. Nígbà tí ẹ̀mí Èṣù náà ti jáde tán ọkunrin odi náà sọ̀rọ̀, ẹnu wá ya àwọn eniyan.

15 Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

16 Àwọn ẹlòmíràn ń dẹ ẹ́, wọ́n ń bèèrè àmì ọ̀run láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

17 Ṣugbọn Jesu mọ èrò wọn, ó sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun, ilé tí ó bá dìde sí ara rẹ̀ yóo tú ká.

18 Bí Satani bá gbé ogun ti ara rẹ̀, báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró? Nítorí ẹ̀ ń sọ pé agbára Beelisebulu ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.

19 Bí ó bá jẹ́ agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ní ti èrò yín yìí, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín.

20 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín.

21 “Nígbà tí ọkunrin alágbára bá wà ní ihamọra, tí ó ń ṣọ́ ilé rẹ̀, kò sí ohun tí ó lè ṣe dúkìá rẹ̀.

22 Ṣugbọn nígbà tí ẹni tí ó lágbára jù ú lọ bá dé, tí ó ṣẹgun rẹ̀, a gba ohun ìjà tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a sì pín dúkìá rẹ̀ tí ó jí kó.

23 “Ẹni tí kò bá sí lẹ́yìn mi, olúwarẹ̀ lòdì sí mi ni, ẹni tí kò bá ti bá mi kó nǹkan jọ, a jẹ́ pé títú ni ó ń tú wọn ká.

Ẹ̀mí Èṣù Tí Ó Tún Pada

24 “Nígbà tí ẹ̀mí èṣù bá jáde kúrò ninu ẹnìkan, á máa wá ilẹ̀ gbígbẹ kiri láti sinmi. Nígbà tí kò bá rí, á ní, ‘N óo tún pada sí ilé mi níbi tí mo ti jáde kúrò.’

25 Nígbà tí ó bá dé ibẹ̀, tí ó rí i pé a ti gbá a, a sì ti ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,

26 ẹ̀mí èṣù náà yóo bá lọ mú àwọn ẹ̀mí meje mìíràn wá tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n óo bá wọ ibẹ̀ wọn óo máa gbébẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà á wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”

Ẹni Tí Ó Ṣe Oríire Tòótọ́

27 Bí Jesu ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, obinrin kan láàrin àwọn eniyan fọhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bí ọ, tí ó wò ọ́ dàgbà náà ṣe oríire lọpọlọpọ.”

28 Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Èyí tí ó jù ni pé àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń pa á mọ́ ṣe oríire.”

Àwọn Kan Bèèrè Àmì Lọ́wọ́ Jesu

29 Nígbà tí ọ̀pọ̀ eniyan péjọ yí i ká, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fún un àfi àmì Jona.

30 Nítorí bí Jona ti di àmì fún àwọn ará Ninefe, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́ àmì fún ìran yìí.

31 Ayaba láti ilẹ̀ gúsù yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí ó wá láti òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Solomoni, Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Solomoni lọ wà níhìn-ín.

32 Àwọn eniyan Ninefe yóo dìde dúró ní ọjọ́ ìdájọ́ láti ko ìran yìí lójú, wọn yóo sì dá wọn lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nígbà tí Jona waasu fún wọn. Ẹ wò ó! Ẹni tí ó ju Jona lọ wà níhìn-ín.

Ìmọ́lẹ̀ Ara

33 “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ tan fìtílà, tí ó jẹ́ fi pamọ́, tabi kí ó fi igbá bò ó. Ńṣe ni yóo gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà kí àwọn tí ó bá ń wọlé lè ríran.

34 Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn.

35 Nítorí náà kí ẹ ṣọ́ra kí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu yín má baà jẹ́ òkùnkùn.

36 Bí gbogbo ara rẹ bá ní ìmọ́lẹ̀, tí kò sí ibìkan tí ó ṣókùnkùn, ńṣe ni yóo mọ́lẹ̀ bí ìgbà tí àtùpà bá tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.”

Jesu Bá Àwọn Farisi ati Àwọn Amòfin Wí

37 Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, Farisi kan pè é pé kí ó wá jẹun ninu ilé rẹ̀. Ó bá wọlé, ó jókòó.

38 Ẹnu ya Farisi náà nígbà tí ó rí i pé Jesu kò kọ́kọ́ wẹwọ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun.

39 Oluwa wá sọ fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa fọ òde kọ́ọ̀bù ati àwo oúnjẹ, ṣugbọn inú yín kún fún ìwà ipá ati nǹkan burúkú!

40 Ẹ̀yin aṣiwèrè wọnyi! Mo ṣebí ẹni tí ó dá òde, òun náà ni ó dá inú.

41 Ohun kan ni kí ẹ ṣe: ẹ fi àwọn ohun tí ó wà ninu kọ́ọ̀bù ati àwo ṣe ìtọrẹ àánú; bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan di mímọ́ fun yín.

42 “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ̀ ń ṣe ìdámẹ́wàá lórí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, gbúre ati oríṣìíríṣìí ewébẹ̀, nígbà tí ẹ kò ka ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ Ọlọrun sí. Àwọn ohun tí ẹ kò kà sí wọnyi ni ó yẹ kí ẹ ṣe, láì gbàgbé àwọn nǹkan yòókù náà.

43 “Ẹ gbé! Ẹ̀yin Farisi. Nítorí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú ninu ilé ìpàdé. Ẹ tún fẹ́ràn kí eniyan máa ki yín láàrin ọjà.

44 Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.”

45 Ọ̀kan ninu àwọn amòfin sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ báyìí, ò ń fi àbùkù kan àwa náà!”

46 Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin amòfin náà gbé! Nítorí ẹ̀ ń di ẹrù bàràkàtà-bàràkàtà lé eniyan lórí nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò jẹ́ fi ọwọ́ yín kan ẹrù kan.

47 Ẹ gbé! Nítorí ẹ̀ ń kọ́ ibojì àwọn wolii, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn baba yín ni wọ́n pa wọ́n.

48 Ṣíṣe tí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fi yín hàn bí ẹlẹ́rìí pé ẹ lóhùn sí ìwà àwọn baba yín: wọ́n pa àwọn wolii, ẹ̀yin wá ṣe ibojì sí ojú-oórì wọn.

49 Ìdí nìyí tí ọgbọ́n Ọlọrun ṣe wí pé, ‘N óo rán àwọn wolii ati àwọn òjíṣẹ́ si yín, ẹ óo pa ninu wọn, ẹ óo ṣe inúnibíni sí àwọn mìíràn.’

50 Nítorí náà, ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wolii tí a ti ta sílẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé,

51 ohun tí ó ṣẹ̀ lórí Abeli títí dé orí Sakaraya tí a pa láàrin ibi pẹpẹ ìrúbọ ati Ilé Ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo wọn.

52 “Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin. Ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ́wọ́, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé. Ẹ tún ń dá àwọn tí ó fẹ́ wọlé dúró!”

53 Nígbà tí Jesu jáde kúrò ninu ilé, àwọn amòfin ati àwọn Farisi takò ó, wọ́n ń bi í léèrè ọ̀rọ̀ pupọ,

54 wọ́n ń dẹ ẹ́ kí wọn lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu.

Categories
LUKU

LUKU 12

Jesu Ṣe Ìkìlọ̀ Nípa Àgàbàgebè

1 Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè.

2 Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀.

3 Kí ẹ mọ̀ pé ohunkohun tí ẹ sọ ní ìkọ̀kọ̀, a óo gbọ́ nípa rẹ̀ ní gbangba. Ohun tí ẹ bá sọ ninu yàrá, lórí òrùlé ni a óo ti pariwo rẹ̀.

Ẹni Tí Ó Yẹ Láti Bẹ̀rù

4 “Mò ń sọ fun yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, pé kí ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara, tí kò tún sí ohun tí wọ́n le ṣe mọ́ lẹ́yìn rẹ̀!

5 N óo fi ẹni tí ẹ̀ bá bẹ̀rù hàn yín. Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá pa ara tán, ó ní àṣẹ láti tún sọ eniyan sinu ọ̀run àpáàdì. Mo sọ fun yín, ẹ bẹ̀rù olúwarẹ̀.

6 “Mo ṣebí kọbọ meji ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ marun-un. Sibẹ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí Ọlọrun fi ojú fò dá.

7 Àní sẹ́, gbogbo irun orí yín ni ó níye. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.

Jíjẹ́wọ́ Jesu Níwájú Eniyan

8 “Mo sọ fun yín, gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, Ọmọ-Eniyan yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun.

9 Ṣugbọn ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan ni a óo sẹ́ níwájú àwọn angẹli Ọlọrun.

10 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ kan lòdì sí Ọmọ-Eniyan, a óo dáríjì í. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́, a kò ní dáríjì í.

11 “Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ sinu ilé ìpàdé ati siwaju àwọn ìjòyè ati àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe dààmú nípa bí ẹ óo ti ṣe wí àwíjàre tabi pé kí ni ẹ óo sọ.

12 Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ yóo kọ yín ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ ní àkókò náà.”

Òwe Nípa Aṣiwèrè Ọlọ́rọ̀

13 Ẹnìkan ninu àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, sọ fún arakunrin mi kí ó fún mi ní ogún tí ó kàn mí.”

14 Jesu dá a lóhùn pé, “Arakunrin, ta ni ó yàn mí ní onídàájọ́ tabi ẹni tí ń pín ogún kiri?”

15 Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ ṣọ́ra, ẹ ta kété sí ojúkòkòrò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, nítorí ọ̀pọ̀ dúkìá nìkan kọ́ níí sọni di eniyan.”

16 Jesu bá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ìkórè oko rẹ̀ pọ̀ pupọ.

17 Ó wá ń rò ninu ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kí ni ǹ bá ṣe o, nítorí n kò rí ibi kó ìkórè oko mi pamọ́ sí?’

18 Ó ní, ‘Mo mọ ohun tí n óo ṣe! Ńṣe ni n óo wó àwọn abà mi. N óo wá kọ́ àwọn ńláńlá mìíràn; níbẹ̀ ni n óo kó àgbàdo mi sí ati àwọn ìkórè yòókù.

19 N óo wá sọ fún ọkàn mi pé: ọkàn mi, o ní ọ̀pọ̀ irè-oko tí ó wà ní ìpamọ́ fún ọdún pupọ. Ìdẹ̀ra dé. Máa jẹ, máa mu, máa gbádùn!’

20 Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’

21 “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun.”

Ẹ̀kọ́ Nípa Ṣíṣe Àníyàn

22 Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa páyà nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora.

23 Nítorí ẹ̀mí ṣe pataki ju oúnjẹ lọ, ara sì ṣe pataki ju aṣọ lọ.

24 Ẹ ṣe akiyesi àwọn ẹyẹ; wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè. Wọn kò ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà. Sibẹ Ọlọrun ń bọ́ wọn. Mélòó-mélòó ni ẹ fi sàn ju àwọn ẹyẹ lọ.

25 Ta ni ninu yín tí ó lè páyà títí dé ibi pé yóo fi ẹsẹ̀ bàtà kan kún gíga rẹ̀?

26 Nítorí náà, bí ẹ kò bá lè ṣe ohun tí ó kéré jùlọ, kí ló dé tí ẹ fi ń páyà nípa àwọn nǹkan yòókù?

27 Ẹ ṣe akiyesi àwọn òdòdó inú igbó bí wọ́n ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé Solomoni pàápàá ninu ọlá rẹ̀ kò wọ aṣọ tí ó dára tó wọn.

28 Bí Ọlọrun bá wọ koríko ìgbẹ́ láṣọ báyìí, koríko tí yóo wà lónìí, tí a óo fi dáná lọ́la, mélòó-mélòó ni yóo fi aṣọ wọ̀ yín, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré yìí!

29 “Nítorí náà, ẹ̀yin ẹ má máa páyà kiri nítorí ohun tí ẹ óo jẹ.

30 (Nítorí pé irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn alaigbagbọ ayé yìí ń dààmú kiri sí.) Baba yín sá mọ̀ pé ẹ nílò wọn.

31 Ṣugbọn kí ẹ máa kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni yóo fun yín pẹlu.

Ìṣúra Ní Ọ̀run

32 “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fun yín ní ìjọba rẹ̀.

33 Ẹ ta àwọn ohun tí ẹ ní, kí ẹ fi ṣe ìtọrẹ-àánú. Ẹ dá àpò fún ara yín tí kò ní gbó laelae; ẹ to ìṣúra tí ó dájú jọ sí ọ̀run, níbi tí olè kò lè súnmọ́, tí kòkòrò kò sì lè ba nǹkan jẹ́.

34 Nítorí níbi tí ìṣúra yín bá wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín náà yóo wà.

Àwọn Ọmọ-Ọ̀dọ̀ Tí Ó Ń Ṣọ́nà

35 “Ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, kí ẹ di ara yín ní àmùrè, kí àtùpà yín wà ní títàn.

36 Kí ẹ dàbí àwọn tí ó ń retí oluwa wọn láti pada ti ibi igbeyawo dé. Nígbà tí ó bá dé, tí ó bá kanlẹ̀kùn, lẹsẹkẹsẹ ni wọn yóo ṣí ìlẹ̀kùn fún un.

37 Àwọn ẹrú tí oluwa wọn bá dé, tí ó bá wọn, tí wọn ń ṣọ́nà, ṣe oríire. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo di ara rẹ̀ ní àmùrè, yóo fi wọ́n jókòó lórí tabili, yóo wá gbé oúnjẹ ka iwájú wọn.

38 Bí ó bá dé ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tí ó bá wọn bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe oríire.

39 Kí ẹ mọ èyí pé bí ó bá jẹ́ pé baálé ilé mọ àkókò tí olè yóo dé, kò ní fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ kí olè kó o.

40 Ẹ̀yin náà, ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní àkókò tí ẹ kò nírètí ni Ọmọ-Eniyan yóo dé.”

Ẹrú Olódodo ati Ẹrú Alaiṣododo

41 Peteru wá bi Jesu pé, “Oluwa, àwa ni o pa òwe yìí fún tabi fún gbogbo eniyan?”

42 Oluwa sọ pé, “Ta ni olóòótọ́ ati ọlọ́gbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí oluwa rẹ̀ fi ṣe olórí àwọn iranṣẹ ilé rẹ̀ pé kí ó máa fún wọn ní oúnjẹ lásìkò.

43 Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ṣe oríire tí oluwa rẹ̀ bá bá a tí ó ń ṣe bí wọ́n ti rán an nígbà tí ó bá dé.

44 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé oluwa rẹ̀ yóo fi ṣe ọ̀gá lórí gbogbo nǹkan tí ó ní.

45 Ṣugbọn bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Yóo pẹ́ kí oluwa mi tó dé,’ tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó tún ń mutí yó,

46 ní ọjọ́ tí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà kò retí, ati ní àkókò tí kò rò tẹ́lẹ̀ ni oluwa rẹ̀ yóo dé, yóo kun ún wẹ́lẹwẹ̀lẹ, yóo sì fún un ní ìpín pẹlu àwọn alaiṣootọ.

47 “Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ.

48 Ṣugbọn èyí tí kò bá mọ̀, tí ó bá tilẹ̀ ṣe ohun tí ó fi yẹ kí ó jìyà, ìyà díẹ̀ ni yóo jẹ. Nítorí ẹni tí a bá fún ní nǹkan pupọ, nǹkan pupọ ni a óo retí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹni tí a bá sì fi nǹkan pupọ ṣọ́, nǹkan pupọ ni a óo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

Jesu Dá Ìyapa Sílẹ̀

49 “Iná ni mo wá sọ sí ayé. Ìbá ti dùn tó bí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jó!

50 Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi. Ara mi kò lè balẹ̀ títí yóo fi kọjá.

51 Ẹ má ṣe rò pé alaafia ni mo mú wá sí ayé. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ará! Mò ń sọ fun yín, ìyapa ni mo mú wá.

52 Láti ìgbà yìí, ẹni marun-un yóo wà ninu ilé kan, àwọn mẹta yóo lòdì sí àwọn meji; àwọn meji yóo lòdì sí àwọn mẹta.

53 Baba yóo lòdì sí ọmọ, ọmọ yóo lòdì sí baba. Ìyá yóo lòdì sí ọmọ rẹ̀ obinrin, ọmọbinrin yóo lòdì sí ìyá rẹ̀. Ìyakọ yóo lòdì sí iyawo ilé, iyawo ilé yóo lòdì sì ìyakọ rẹ̀.”

Àmì Àkókò

54 Jesu tún sọ fún àwọn eniyan pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i tí òjò ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, ẹ óo sọ pé, ‘Òjò yóo rọ̀.’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí.

55 Bí atẹ́gùn bá fẹ́ wá láti gúsù, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ooru yóo mú,’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí.

56 Ẹ̀yin alágàbàgebè! Ẹ mọ àmì ilẹ̀ ati ti ojú sánmà, ṣugbọn ẹ kò mọ àmì àkókò yìí!

Ẹ Bá Ọ̀tá Yín Rẹ́

57 “Kí ló dé tí ẹ̀yin fúnra yín kò fi lè mọ ohun tí ó tọ̀nà?

58 Bí o bá ń bá ẹni tí ó pè ọ́ lẹ́jọ́ lọ sí kóòtù, gbìyànjú láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹlu rẹ̀ bí ẹ ti ń lọ lọ́nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́. Onídàájọ́ yóo bá fi ọ́ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́, ni ọlọ́pàá yóo bá tì ọ́ mọ́lé.

59 Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé, o kò ní jáde kúrò níbẹ̀ títí o óo fi san gbogbo gbèsè tí o jẹ, láìku kọbọ!”

Categories
LUKU

LUKU 13

Ẹ Ronupiwada, Bí Bẹ́ẹ̀ Kọ̀ Ẹ Óo Ṣègbé

1 Ní àkókò náà gan-an, àwọn kan sọ fún un nípa àwọn ará Galili kan tí Pilatu pa bí wọ́n ti ń rúbọ lọ́wọ́.

2 Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí?

3 Rárá o! Mò ń sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.

4 Tabi àwọn mejidinlogun tí ilé-ìṣọ́ gíga ní Siloamu wólù, tí ó pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé wọ́n burú ju gbogbo àwọn eniyan yòókù tí ó ń gbé Jerusalẹmu lọ ni?

5 Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.”

Ẹ̀kọ́ Nípa Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Tí Kò Léso

6 Ó wá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Ẹnìkan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sinu ọgbà rẹ̀. Ó dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, ṣugbọn kò rí.

7 Ó wá sọ fún olùtọ́jú ọgbà pé, ‘Ṣé o rí i! Ó di ọdún mẹta tí mo ti ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí tí n kò rí. Gé e lulẹ̀. Kí ló dé tí yóo kàn máa gbilẹ̀ lásán?’

8 Ṣugbọn olùtọ́jú ọgbà dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, fi í sílẹ̀ ní ọdún yìí, kí n walẹ̀ yí i ká, kí n bu ilẹ̀dú sí i.

9 Bí ó bá so èso ní ọdún tí ń bọ̀, ó dára. Bí kò bá so èso, gé e.’ ”

Jesu Wo Obinrin Tí Kò Lè Nàró Sàn Ní Ọjọ́ Ìsinmi

10 Jesu ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu ilé ìpàdé kan ní Ọjọ́ Ìsinmi.

11 Obinrin kan wà tí ó ní irú ẹ̀mí èṣù kan tí ó sọ ọ́ di aláìlera fún ọdún mejidinlogun. Ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀, kò lè nàró dáradára.

12 Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é, ó sọ fún un pé, “Obinrin yìí, a wò ọ́ sàn kúrò ninu àìlera rẹ.”

13 Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun.

14 Ṣugbọn inú bí olórí ilé ìpàdé nítorí Jesu ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó bá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ọjọ́ mẹfa wà tí a níláti fi ṣiṣẹ́. Ẹ wá fún ìwòsàn láàrin àwọn ọjọ́ mẹfa yìí. Ẹ má wá fún ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi mọ́!”

15 Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin alágàbàgebè! Èwo ninu yín ni kì í tú mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ibùjẹ ẹran kí ó lọ fún un ní omi ní Ọjọ́ Ìsinmi?

16 Ẹ wá wo obinrin yìí, ọmọ Abrahamu, tí Satani ti dè fún ọdún mejidinlogun. Ṣé kò yẹ kí á tú u sílẹ̀ ninu ìdè yìí ní Ọjọ́ Ìsinmi?”

17 Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ báyìí, ojú ti gbogbo àwọn tí ó takò o. Ńṣe ni inú gbogbo àwọn eniyan dùn nítorí gbogbo ohun ìyanu tí ó ń ṣe.

Àwọn Òwe Nípa Wóró Musitadi ati Nípa Ìwúkàrà

18 Nítorí náà Jesu sọ pé, “Kí ni à bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Kí ni ǹ bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19 Ó dàbí ẹyọ wóró musitadi kan, tí ẹnìkan mú, tí ó gbìn sí oko rẹ̀. Nígbà tí ó bá dàgbà, ó di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń ṣe ìtẹ́ wọn sí orí ẹ̀ka rẹ̀.”

20 Ó tún sọ pé, “Kí ni ǹ bá fi ìjọba Ọlọrun wé?

21 Ó dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”

Ẹnu Ìlẹ̀kùn Tí Ó Há

22 Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ láti ìlú dé ìlú ati láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ àwọn eniyan bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu.

23 Ẹnìkan wá bi í pé, “Alàgbà, ǹjẹ́ àwọn eniyan tí yóo là kò ní kéré báyìí?”

Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé,

24 “Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé.

25 Nígbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó bá ti ìlẹ̀kùn, ẹ óo wá dúró lóde, ẹ óo bẹ̀rẹ̀ sí kanlẹ̀kùn, ẹ óo wí pé, ‘Alàgbà, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn yóo da yín lóhùn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí!’

26 Ẹ óo wá máa sọ pé, ‘A jẹ, a mu níwájú rẹ. O kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní ìgboro wa.’

27 Ṣugbọn yóo sọ fun yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi.’

28 Ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà nígbà tí ẹ bá rí Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu ati gbogbo àwọn wolii ní ìjọba Ọlọrun, tí wọ́n wá tì yín mọ́ òde.

29 Àwọn eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, láti àríwá ati láti gúsù, wọn yóo jókòó níbi àsè ní ìjọba Ọlọrun.

30 Àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú; àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.”

Jesu Dárò Jerusalẹmu

31 Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.”

32 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ fún ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yẹn pé, ‘Mò ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, mo tún ń ṣe ìwòsàn lónìí ati lọ́la. Ní ọ̀tunla n óo parí iṣẹ́ mi.’

33 Mo níláti kúrò kí n máa bá iṣẹ́ mi lọ lónìí, lọ́la ati lọ́tùn-unla, nítorí bí wolii kan yóo bá kú, ní Jerusalẹmu ni yóo ti kú.

34 “Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ òkúta lu àwọn tí a ti rán sí ọ, nígbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tií kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbà fún mi!

35 Ẹ wò ó! Ọlọrun ti fi ìlú yín sílẹ̀ fun yín! Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ kò ní rí mi títí di ìgbà tí ẹ óo wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Oluwa.’ ”

Categories
LUKU

LUKU 14

Jesu Wo Ọkunrin Tí Ara Rẹ̀ Wú Sàn

1 Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, Jesu lọ jẹun ní ilé ọ̀kan ninu àwọn olóyè láàrin àwọn Farisi. Wọ́n bá ń ṣọ́ ọ.

2 Ọkunrin kan wà níwájú rẹ̀ níbẹ̀ tí gbogbo ara rẹ̀ wú bòmù-bòmù.

3 Jesu bi àwọn amòfin ati àwọn Farisi tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ṣé ó dára láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, tabi kò dára?”

4 Wọ́n bá dákẹ́. Jesu bá mú ọkunrin náà, ó wò ó sàn, ó bá ní kí ó máa lọ.

5 Ó wá bi wọ́n pé, “Ta ni ninu yín tí ọmọ rẹ̀, tabi mààlúù rẹ̀ yóo já sinu kànga ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á yọ lẹsẹkẹsẹ?”

6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn.

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìrẹ̀lẹ̀

7 Nígbà tí Jesu ṣe akiyesi bí àwọn tí a pè sí ibi àsè ti ń yan ipò ọlá, ó wá pa òwe kan fún wọn. Ó ní,

8 “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ sí ibi iyawo, má ṣe lọ jókòó ní ipò ọlá. Bóyá ẹni tí ó pè ọ́ tún pe ẹlòmíràn tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ.

9 Ẹni tí ó pè ọ́ yóo wá tọ̀ ọ́ wá, yóo sọ fún ọ pé, ‘Fi ààyè fún ọkunrin yìí,’ Ìwọ yóo wá fi ìtìjú bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ààyè lẹ́yìn.

10 Tí wọn bá pè ọ́, lọ jókòó lẹ́yìn, kí ẹni tí ó pè ọ́ lè wá sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi súnmọ́ iwájú.’ Nígbà náà ìwọ yóo ní iyì lójú gbogbo àwọn tí ó wà níbi àsè.

11 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”

12 Ó wá sọ fún ẹni tí ó pè é fún oúnjẹ pé, “Nígbà tí o bá se àsè, ìbáà jẹ́ lọ́sàn-án tabi lálẹ́, má ṣe pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tabi àwọn arakunrin rẹ tabi àwọn ẹbí rẹ tabi àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Bí o bá pè wọ́n, àwọn náà yóo pè ọ́ wá jẹun níjọ́ mìíràn, wọn yóo sì san oore tí o ṣe wọ́n pada fún ọ.

13 Ṣugbọn bí o bá se àsè, pe àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú.

14 Èyí ni yóo fún ọ láyọ̀, nítorí wọn kò lè san án pada fún ọ. Ṣugbọn Ọlọrun yóo san án pada fún ọ nígbà tí àwọn olódodo bá jí dìde kúrò ninu òkú.”

Òwe Nípa Àsè Ńlá

15 Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn tí ó wà níbi àsè gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún Jesu pé, “Ẹni tí ó bá jẹun ní ìjọba ọ̀run ṣe oríire!”

16 Jesu sọ fún un pé, “Ọkunrin kan se àsè ńlá kan; ó pe ọ̀pọ̀ eniyan sibẹ.

17 Nígbà tí àkókò ati jẹun tó, ó rán iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tí ó ti pè láti sọ fún wọn pé, ‘Ó yá o! A ti ṣetán!’

18 Ni gbogbo wọn patapata láìku ẹnìkan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí. Ekinni sọ fún un pé, ‘Mo ra ilẹ̀ kan, mo sì níláti lọ wò ó. Mo tọrọ àforíjì, yọ̀ǹda mi.’

19 Ẹnìkejì ní, ‘Mo ra mààlúù fún ẹ̀rọ-ìroko. Mò ń lọ dán an wò, dákun, yọ̀ǹda mi.’

20 Ẹnìkẹta ní, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé iyawo ni, nítorí náà n kò lè wá.’

21 “Iranṣẹ náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún oluwa rẹ̀. Inú wá bí baálé ilé náà. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Tètè lọ sí gbogbo títì ati ọ̀nà ẹ̀bùrú ìlú, kí o lọ kó àwọn aláìní, àwọn aláàbọ̀ ara, àwọn afọ́jú, ati àwọn arọ wá síhìn-ín.’

22 Nígbà tí iranṣẹ náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, ó ní, ‘Alàgbà, a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, sibẹ àyè tún kù.’

23 Oluwa iranṣẹ náà sọ fún un pé, ‘Lọ sí ọ̀nà oko, kí o bẹ àwọn ẹni tí o bá rí, kí wọ́n wọlé wá, kí inú ilé mi baà kún.

24 Nítorí kò sí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọ̀n-ọn-nì tí a ti kọ́kọ́ pè tí yóo tọ́ wò ninu àsè mi!’ ”

Ohun Tí Eniyan Gbọdọ̀ Ṣe Kí Ó Tó Lè Jẹ́ Ọmọ-ẹ̀yìn

25 Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan péjọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá yíjú pada sí wọn, ó ní,

26 “Bí ẹnìkan bá fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá kórìíra baba rẹ̀ ati ìyá rẹ̀, ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati ẹ̀gbọ́n, ati àbúrò rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí ó fi mọ́ ẹ̀mí òun pàápàá, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

27 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

28 “Nítorí ta ni ninu yín tí yóo fẹ́ kọ́ ilé ńlá kan, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye tí yóo ná òun, kí ó mọ̀ bí òun bá ní ohun tí òun yóo fi parí rẹ̀?

29 Kí ó má wá jẹ́ pé yóo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ tán, kò ní lè parí rẹ̀ mọ́. Gbogbo àwọn tí ó bá rí i yóo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́.

30 Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọkunrin yìí bẹ̀rẹ̀ ilé, kò lè parí rẹ̀!’

31 “Tabi ọba wo ni yóo lọ ko ọba mìíràn lójú ogun tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó gba ìmọ̀ràn bí òun yóo bá lè ko ẹni tí ó ní ọ̀kẹ́ kan ọmọ-ogun lójú?

32 Bí kò bá ní lè kò ó lójú, kí ọ̀tá rẹ̀ tó dé ìtòsí, yóo tètè rán ikọ̀ sí i pé òun túúbá.

33 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni ninu yín tí kò bá kọ gbogbo ohun tí ó ní sílẹ̀, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

Iyọ̀ Tí Ó Di Òbu

34 “Iyọ̀ dára. Ṣugbọn bí iyọ̀ bá di òbu, báwo ni a ti ṣe lè mú kí ó tún dùn?

35 Kó wúlò fún oko tabi fún ààtàn mọ́ àfi kí á dà á sóde. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Categories
LUKU

LUKU 15

Òwe Nípa Aguntan tí Ó Sọnù

1 Gbogbo àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

2 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá ń kùn; wọ́n ń sọ pé, “Eléyìí ń kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ra, ó tún ń bá wọn jẹun.”

3 Jesu bá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní:

4 “Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan tí ọ̀kan sọnù ninu wọn, ṣé kò ní fi mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ ní pápá, kí ó wá èyí tí ó sọnù lọ títí yóo fi rí i?

5 Nígbà tí ó bá wá rí i, yóo gbé e kọ́ èjìká rẹ̀ pẹlu ayọ̀.

6 Nígbà tí ó bá dé ilé, yóo pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóo wí fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí aguntan mi tí ó sọnù.’

7 Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ayọ̀ tí yóo wà ní ọ̀run nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada ju ti ìtorí àwọn olódodo mọkandinlọgọrun-un tí kò nílò ìrònúpìwàdà lọ.

Òwe Nípa Owó tí Ó Sọnù

8 “Tabi, kí obinrin kan ní naira mẹ́wàá, bí ó ba sọ naira kan nù, ṣé kò ní tan iná, kí ó gbálẹ̀, kí ó fẹ̀sọ̀ wá a títí yóo fi rí i?

9 Nígbà tí ó bá rí i, yóo pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, yóo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí owó tí mo sọnù.’

10 Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn angẹli Ọlọrun yóo máa yọ̀ nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada.”

Òwe Nípa Ọmọ tí Ó Sọnù

11 Jesu ní, “Ọkunrin kan ní ọmọ meji.

12 Èyí àbúrò sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ogún tèmi tí ó tọ́ sí mi.’ Ni baba bá pín ogún fún àwọn ọmọ mejeeji.

13 Kò pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ tí àbúrò yìí fi kó gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó bá lọ sí ìlú òkèèrè, ó sá fi ìwà wọ̀bìà ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ pátá ní ìnákúnàá.

14 Nígbà tí ó ná gbogbo ohun ìní rẹ̀ tán, ìyàn wá mú pupọ ní ìlú náà, ebi sì bẹ̀rẹ̀ sí pa á.

15 Ni ó bá lọ ń gbé ọ̀dọ̀ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀. Ọmọ-ìbílẹ̀ ìlú yìí ba rán an lọ sí oko rẹ̀ láti máa ṣe ìtọ́jú ẹlẹ́dẹ̀.

16 Ìbá dùn mọ́ ọn láti máa jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kì í fún un ní ohunkohun.

17 Nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, ‘Àwọn alágbàṣe baba mi tí wọn ń jẹ oúnjẹ ní àjẹṣẹ́kù kò níye. Èmi wá jókòó níhìn-ín, ebi ń pa mí kú lọ!

18 N óo dìde, n óo tọ baba mi lọ. N óo wí fún un pé, “Baba, mo ti ṣẹ Ọlọrun, mo sì ti ṣẹ ìwọ náà.

19 N kò yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ mọ́. Fi mí ṣe ọ̀kan ninu àwọn alágbàṣe rẹ.” ’

20 Ó bá dìde, ó lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀.

“Bí ó ti ń bọ̀ ní òkèèrè ni baba rẹ̀ ti rí i. Àánú ṣe é, ó yára, ó dì mọ́ ọn lọ́rùn, ó bá fẹnu kò ó ní ẹnu.

21 Ọmọ náà sọ fún un pé, ‘Baba, mo ti ṣẹ Ọlọrun, mo sì ti ṣẹ ìwọ náà.’

22 Ṣugbọn baba náà sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ tètè mú aṣọ tí ó dára jùlọ wá, kí ẹ fi wọ̀ ọ́. Ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, ẹ fún un ní bàtà kí ó wọ̀.

23 Ẹ wá lọ mú mààlúù tí ó sanra wá, kí ẹ pa á, kí ẹ jẹ́ kí á máa ṣe àríyá.

24 Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ṣugbọn ó tún wà láàyè; ó ti sọnù, ṣugbọn a ti rí i.’ Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àríyá.

25 “Ní gbogbo àkókò yìí, èyí ẹ̀gbọ́n wà ní oko. Bí ó ti ń bọ̀ tí ó ń súnmọ́ etílé, ó gbọ́ ìlù ati ijó.

26 Ó pe ọmọde kan, ó wádìí ohun tí ń ṣẹlẹ̀.

27 Ọmọ yìí bá sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa mààlúù tí ó sanra, ó se àsè nítorí tí àbúrò rẹ pada dé ní alaafia.’

28 Inú bí èyí ẹ̀gbọ́n, ó bá kọ̀, kò wọlé. Ni baba rẹ̀ bá jáde lọ láti lọ bẹ̀ ẹ́.

29 Ṣugbọn ó sọ fún baba rẹ̀ pé, ‘Wo ati ọdún tí mo ti ń sìn ọ́, n kò dá àṣẹ rẹ kọjá rí; sibẹ o kò fún mi ni ọmọ ewúrẹ́ kan kí n fi ṣe àríyá pẹlu àwọn ọ̀rẹ́ mi rí.

30 Ṣugbọn nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, àpà ara rẹ̀, tí ó ti run ogún rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn aṣẹ́wó, o wá pa mààlúù tí ó sanra fún un.’

31 Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ mi, ìwọ wà lọ́dọ̀ mi nígbà gbogbo, gbogbo ohun tí mo ní, tìrẹ ni.

32 Ó yẹ kí á ṣe àríyá, kí á sì máa yọ̀, nítorí àbúrò rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè, ó ti sọnù, a sì tún rí i.’ ”

Categories
LUKU

LUKU 16

Òwe Ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n Ẹ̀wẹ́

1 Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò.

2 Ọ̀gá rẹ̀ bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Irú ìròyìn wo ni mò ń gbọ́ nípa rẹ yìí? Ṣírò iṣẹ́ rẹ bí ọmọ-ọ̀dọ̀, nítorí n óo dá ọ dúró lẹ́nu iṣẹ́.’

3 Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o, nítorí ọ̀gá mi yóo dá mi dúró lẹ́nu iṣẹ́. Èmi nìyí, n kò lè roko. Ojú sì ń tì mí láti máa ṣagbe.

4 Mo mọ ohun tí n óo ṣe, kí àwọn eniyan lè gbà mí sinu ilé wọn nígbà tí wọ́n bá gba iṣẹ́ lọ́wọ́ mi.’

5 “Ó bá pe ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí ó jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè. Ó bi ekinni pé, ‘Èló ni o jẹ ọ̀gá mi?’

6 Òun bá dáhùn pé, ‘Ọgọrun-un garawa epo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, tètè jókòó, kọ aadọta.’

7 Ó bi ekeji pé, ‘Ìwọ ńkọ́? Èló ni o jẹ?’ Ó ní, ‘Ẹgbẹrun òṣùnwọ̀n àgbàdo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, kọ ẹgbẹrin.’

8 “Ọ̀gá ọmọ-ọ̀dọ̀ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ náà yìn ín nítorí pé ó gbọ́n. Nítorí àwọn ọmọ ayé yìí mọ ọ̀nà ọgbọ́n tí wọ́n fi ń bá ara wọn lò ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.

9 “Ní tèmi, mò ń sọ fun yín, fún anfaani ara yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí wá ọ̀rẹ́ fún ara yín, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí owó kò bá sí mọ́, kí wọn lè gbà yín sí inú ibùgbé tí yóo wà títí lae.

10 Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré yóo ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan ńlá.

11 Nítorí náà bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa nǹkan owó ti ayé yìí, ta ni yóo fi dúkìá tòótọ́ sí ìkáwọ́ yín?

12 Bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa ohun tí ó jẹ́ ti ẹlòmíràn, ta ni yóo fun yín ní ohun tí ó jẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín?

13 “Kò sí ọmọ-ọ̀dọ̀ kan tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má sì ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún sin owó.”

Òfin ati Ìjọba Ọlọrun

14 Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n fẹ́ràn owó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń yínmú sí i.

15 Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun.

16 “Ìwé òfin Mose ati ìwé àwọn wolii ni ó wà fún ìlànà títí di àkókò Johanu. Láti ìgbà náà ni a ti ń waasu ìyìn rere ti ìjọba Ọlọrun. Pẹlu ipá sì ni olukuluku fi ń wọ̀ ọ́.

17 Ó rọrùn kí ọ̀run ati ayé kọjá ju pé kí kínńkínní ninu òfin kí ó má ṣẹ lọ.

18 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ tí ó gbé iyawo mìíràn ṣe àgbèrè. Bí ẹnìkan bá sì gbé obinrin tí a ti kọ̀ sílẹ̀ ní iyawo òun náà ṣe àgbèrè.

Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ ati Lasaru

19 “Ọkunrin kán wà tí ó lówó. Aṣọ àlàárì ati àwọn aṣọ olówó iyebíye mìíràn ni ó máa ń wọ̀. Oúnjẹ àdídùn ni ó máa ń jẹ, lojoojumọ ni ó máa ń se àsè.

20 Talaka kan wà tí ó ń jẹ́ Lasaru, tíí máa ń jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé ọlọ́rọ̀ yìí. Gbogbo ara Lasaru jẹ́ kìkì egbò.

21 Inú rẹ̀ ìbá dùn láti máa jẹ ẹ̀rúnrún tí ó ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili olówó yìí. Pẹlu bẹ́ẹ̀ náà, ajá a máa wá lá egbò ara rẹ̀.

22 “Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín.

23 Ní ipò òkú ni ó rí ara rẹ̀, tí ó ń joró. Ó wá rí Abrahamu ní òkèèrè pẹlu Lasaru ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

24 Ó bá pè é, ó ní, ‘Abrahamu, Baba, ṣàánú mi. Rán Lasaru kí ó ti ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó wá kán an sí mi láhọ́n, nítorí mò ń jẹ ìrora ninu iná yìí.’

25 “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ, ranti pé nígbà tí o wà láyé, kìkì ohun rere ni o gbà, nígbà tí ó jẹ́ pé nǹkan burúkú ni Lasaru gbà. Nisinsinyii, ìdẹ̀ra ti dé bá Lasaru nígbà tí ìwọ ń jẹ̀rora.

26 Ati pé ọ̀gbun ńlá kan wà láàrin àwa ati ẹ̀yin, tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó bá fẹ́ kọjá sí ọ̀dọ̀ yín kò ní lè kọjá; bákan náà àwọn tí ó bá fẹ́ ti ọ̀hún kọjá wá sí ọ̀dọ̀ wa kò ní lè kọjá.’

27 Olówó náà wá sọ pé, ‘Baba, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀ ọ́, rán Lasaru lọ sí ilé baba mi.

28 Arakunrin marun-un ni mo ní; kí ó lọ kìlọ̀ fún wọn kí àwọn náà má baà wá sí ibi oró yìí.’

29 “Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Wọ́n ní ìwé Mose ati ìwé àwọn wolii. Kí wọ́n fetí sí wọn.’

30 Ṣugbọn ọlọ́rọ̀ náà ní, ‘Ó tì, Abrahamu, Baba! Bí ẹnìkan bá jí dìde ninu òkú, tí ó lọ sọ́dọ̀ wọn, wọn yóo ronupiwada.’

31 Ṣugbọn Abrahamu sọ fún un pé, ‘Bí wọn kò bá fetí sí ohun tí Mose ati àwọn wolii kọ, bí ẹni tí ó ti kú bá tilẹ̀ jí dìde tí ó lọ bá wọn, kò ní lè yí wọn lọ́kàn pada.’ ”

Categories
LUKU

LUKU 17

Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ohun Ìkọsẹ̀

1 Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “A kò lè ṣàì rí ohun ìkọsẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó ti ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀ gbé!

2 Ó sàn fún un kí á so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, kí á jù ú sinu òkun jù pé kí ó mú ohun ìkọsẹ̀ bá ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi.

3 Ẹ ṣọ́ra yín!

Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀

“Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, bá a wí; bí ó bá ronupiwada, dáríjì í.

4 Bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ẹẹmeje ní ọjọ́ kan, tí ó yipada sí ọ lẹẹmeje, tí ó bẹ̀ ọ́ pé, ‘Jọ̀ọ́ má bínú,’ dáríjì í.”

Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Igbagbọ

5 Àwọn aposteli sọ fún Oluwa pé, “Bù sí igbagbọ wa!”

6 Oluwa sọ fún wọn pé, “Bí ẹ bá ní igbagbọ tí ó kéré bíi wóró musitadi tí ó kéré jùlọ, bí ẹ bá wí fún igi sikamore yìí pé, ‘Hú kúrò níbí tigbòǹgbò- tigbòǹgbò, kí o lọ hù ninu òkun!’ Yóo ṣe bí ẹ ti wí.

Òwe Iṣẹ́ Ọmọ-Ọ̀dọ̀

7 “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní iranṣẹ kan tí ó lọ roko tabi tí ó lọ tọ́jú àwọn aguntan, tí ó bá wọlé dé láti inú oko, ǹjẹ́ ohun tí yóo sọ fún un ni pé kí ó tètè wá jókòó kí ó jẹun?

8 Àbí yóo sọ fún iranṣẹ náà pé, ‘Tọ́jú ohun tí n óo jẹ. Ṣe gírí kí o gbé oúnjẹ fún mi. Nígbà tí mo bá jẹ tán, tí mo mu tán, kí o wá jẹ tìrẹ.’

9 Ǹjẹ́ ó jẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ nítorí pé ó ṣe ohun tí ó níláti ṣe?

10 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ ṣe. Nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pa láṣẹ fun yín tán, kí ẹ sọ pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ ni a jẹ́. Ohun tí a ṣe kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọpẹ́. Ohun tí ó yẹ kí á ṣe ni a ti ṣe.’ ”

Jesu Wo Àwọn Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn

11 Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ó ń gba ààrin Samaria ati Galili kọjá.

12 Bí ó tí ń wọ abúlé kan lọ, àwọn ọkunrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá kan pàdé rẹ̀. Wọ́n dúró lókèèrè,

13 wọ́n kígbe pé, “Ọ̀gá, Jesu, ṣàánú wa.”

14 Nígbà tí ó rí wọn, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ fi ara yín hàn alufaa.”

Bí wọ́n ti ń lọ, ara wọn bá dá.

15 Nígbà tí ọ̀kan ninu wọn rí i pé ara òun ti dá, ó pada, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun pẹlu ohùn gíga.

16 Ó bá dojúbolẹ̀ níwájú Jesu, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria ni.

17 Jesu bèèrè pé, “Ṣebí àwọn mẹ́wàá ni mo mú lára dá. Àwọn mẹsan-an yòókù dà?

18 Kò wá sí ẹni tí yóo pada wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, àfi àlejò yìí?”

19 Jesu bá sọ fún un pé, “Dìde, máa lọ. Igbagbọ rẹ ni ó mú ọ lára dá.”

Bí Ìjọba Yóo Ti Ṣe Dé

20 Àwọn Farisi bi Jesu nípa ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo dé. Ó dá wọn lóhùn pé, “Dídé ìjọba Ọlọrun kò ní àmì tí a óo máa fẹjú kí á tó ri pé ó dé tabi kò dé.

21 Kì í ṣe ohun tí àwọn eniyan yóo máa sọ pé, ‘Ó wà níhìn-ín’ tabi ‘Ó wà lọ́hùn-ún.’ Nítorí ìjọba Ọlọrun wà láàrin yín.”

22 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí ẹ óo fẹ́ rí ọ̀kan ninu ọjọ́ dídé Ọmọ-Eniyan, ṣugbọn ẹ kò ní rí i.

23 Wọn yóo máa sọ pé, ‘Wò ó níhìn-ín’ tabi, ‘Wò ó lọ́hùn-ún’. Ẹ má lọ, ẹ má máa sáré tẹ̀lé wọn kiri.

24 Nítorí bí mànàmáná tíí kọ yànràn, tíí sìí tan ìmọ́lẹ̀ láti òkè délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo rí ní ọjọ́ tí ó bá dé.

25 Ṣugbọn dandan ni pé kí ó kọ́kọ́ jìyà pupọ, kí ìran yìí sì kẹ̀yìn sí i.

26 Àní bí ó ti rí ní àkókò Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé.

27 Nítorí ní àkókò Noa, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbeyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí di ọjọ́ tí Noa fi wọ inú ọkọ̀, ìkún-omi bá dé, ó bá pa gbogbo wọn rẹ́.

28 Bákan náà ni ó rí ní àkókò ti Lọti. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń fúnrúgbìn, wọ́n ń kọ́lé,

29 títí di ọjọ́ tí Lọti fi jáde kúrò ní Sodomu, tí Ọlọrun fi rọ̀jò iná ati òkúta gbígbóná lé wọn lórí, tí ó pa gbogbo wọn rẹ́.

30 Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ọjọ́ tí Ọmọ-Eniyan bá yọ dé.

31 “Ní ọjọ́ náà, bí ẹnìkan bá wà lórí ilé, tí àwọn nǹkan rẹ̀ wà ninu ilé, kí ó má sọ̀kalẹ̀ lọ kó o. Bákan náà ni ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sílé.

32 Ẹ ranti iyawo Lọti

33 Ẹni tí ó bá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, yóo gbà á là.

34 Mo sọ fun yín, ní ọjọ́ náà, eniyan meji yóo sùn lórí ibùsùn kan, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.

35 Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ògì, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. [

36 Àwọn ẹni meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.”]

37 Wọ́n bi í pé, “Níbo ni, Oluwa?”

Ó dá wọn lóhùn pé, “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn igún ń péjọ sí.”

Categories
LUKU

LUKU 18

Òwe Nípa Opó Kan ati Adájọ́

1 Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀.

2 Ó ní, “Adájọ́ kan wà ní ìlú kan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun, tí kò sì ka ẹnikẹ́ni sí.

3 Opó kan wà ninu ìlú náà tíí máa lọ sí ọ̀dọ̀ adájọ́ yìí tíí máa bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe ẹ̀tọ́ fún mi nípa ọ̀rọ̀ tí ó wà láàrin èmi ati ọ̀tá mi.’

4 Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan,

5 ṣugbọn nítorí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, n óo ṣe ẹ̀tọ́ fún un, kí ó má baà fi wahala rẹ̀ da mí lágara!’ ”

6 Oluwa wá sọ pé, “Ẹ kò gbọ́ ohun tí adájọ́ alaiṣootọ yìí wí!

7 Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn?

8 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé yóo ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn kíákíá. Ǹjẹ́ nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé, yóo bá igbagbọ ní ayé mọ́?”

Òwe Nípa Farisi Kan ati Agbowó-odè

9 Ó wá pa òwe yìí fún àwọn tí wọ́n gbójú lé ara wọn bí olódodo, tí wọn ń kẹ́gàn gbogbo àwọn eniyan yòókù.

10 Ó ní, “Àwọn ọkunrin meji kan gòkè lọ sí Tẹmpili wọ́n lọ gbadura. Ọ̀kan jẹ́ Farisi, ekeji jẹ́ agbowó-odè.

11 “Èyí Farisi dá dúró, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, ‘Ọlọrun, mo dúpẹ́ pé ń kò dàbí àwọn yòókù, àwọn oníwọ̀ra, alaiṣootọ, alágbèrè. N kò tilẹ̀ dàbí agbowó-odè yìí.

12 Ẹẹmeji ni mò ń gbààwẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mò ń dá ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí mo bá gbà.’

13 “Ṣugbọn èyí agbowó-odè dúró ní òkèèrè. Kò tilẹ̀ gbé ojú sókè. Ó bá ń lu ara rẹ̀ láyà (bí àmì ìdárò), ó ní, ‘Ọlọrun ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’

14 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”

Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde

15 Àwọn eniyan ń gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá, pé kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tí wọ́n gbé wọn wá wí.

16 Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.

17 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọde, kò ní wọ inú rẹ̀.”

18 Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

19 Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo.

20 Ṣé o mọ òfin wọnyi: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè; ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké; bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.’ ”

21 Ìjòyè náà dáhùn pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti ń pamọ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin.”

22 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.”

23 Nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ bàjẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.

24 Nígbà tí Jesu rí bí inú rẹ̀ ti bàjẹ́, ó ní, “Yóo ṣòro fún àwọn olówó láti wọ ìjọba Ọlọrun.

25 Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun.”

26 Àwọn tí ó gbọ́ ní, “Ta wá ni a óo gbà là?”

27 Ó dáhùn pé, “Ohun tí kò ṣeéṣe fún eniyan, ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”

28 Peteru sọ fún un pé, “Wò ó ná! Àwa ti fi ohun gbogbo tí a ní sílẹ̀, a sì ti ń tẹ̀lé ọ.”

29 Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí ẹni tí ó fi ilé, iyawo, arakunrin, òbí tabi ọmọ sílẹ̀, nítorí ti ìjọba Ọlọrun,

30 tí kò ní rí ìlọ́po-ìlọ́po gbà ní ayé yìí, yóo sì ní ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.”

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ Lẹẹkẹta

31 Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ.

32 Nítorí a óo fi í lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. Wọn óo fi ṣe ẹ̀sín, wọn óo fi àbùkù kàn án, wọn óo tutọ́ sí i lára.

33 Nígbà tí wọ́n bá nà án tán, wọn óo sì pa á. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta, yóo jí dìde.”

34 Ṣugbọn ohun tí ó sọ kò yé wọn. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà sápamọ́ fún wọn. Wọn kò mọ ohun tí ó ń sọ.

Jesu Wo Afọ́jú Alágbe Sàn Ní Jẹriko

35 Nígbà tí Jesu súnmọ́ etí ìlú Jẹriko, afọ́jú kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó jókòó, ó ń ṣagbe.

36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń kọjá lọ, ó wádìí ohun tí ó dé.

37 Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.”

38 Ni alágbe náà bá pariwo pé, “Jesu, ọmọ Dafidi, ṣàánú mi!”

39 Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú mi.”

40 Jesu bá dúró, ó ní kí wọ́n lọ fà á lọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí ó dé, Jesu bi í pé,

41 “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”

Ó dáhùn pé, “Alàgbà, mo fẹ́ tún ríran ni!”

42 Jesu sọ fún un pé, “Ǹjẹ́, ríran. Igbagbọ rẹ mú ọ lára dá.”

43 Lójú kan náà ó sì tún ríran, ó bá ń tẹ̀lé Jesu, ó ń yin Ọlọrun lógo. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun.

Categories
LUKU

LUKU 19

Jesu ati Sakiu

1 Nígbà tí Jesu dé Jẹriko, ó ń la ìlú náà kọjá.

2 Ọkunrin kan wà tí ó ń jẹ́ Sakiu. Òun ni olórí agbowó-odè níbẹ̀. Ó sì lówó.

3 Ó fẹ́ rí Jesu kí ó mọ ẹni tí í ṣe. Ṣugbọn kò lè rí i nítorí ọ̀pọ̀ eniyan ati pé eniyan kúkúrú ni.

4 Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá.

5 Nígbà tí Jesu dé ọ̀gangan ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sọ fún un pé, “Sakiu, tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbọdọ̀ dé sí lónìí.”

6 Ni Sakiu bá sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á lálejò.

7 Nígbà tí àwọn eniyan rí i, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jesu, wọ́n ní, “Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí!”

8 Sakiu bá dìde dúró, ó sọ fún Oluwa pé, “N óo pín ààbọ̀ ohun tí mo ní fún àwọn talaka. Bí mo bá sì ti fi ọ̀nà èrú gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mo ṣetán láti dá a pada ní ìlọ́po mẹrin.”

9 Jesu bá dá a lóhùn pé, “Lónìí yìí ni ìgbàlà wọ inú ilé yìí, nítorí ọmọ Abrahamu ni Sakiu náà.

10 Nítoí Ọmọ-Eniyan dé láti wá àwọn tí wọ́n sọnù kiri, ati láti gbà wọ́n là.”

Òwe Nípa Owó Wúrà

11 Bí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọnyi, ó tún fi òwe kan bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àwọn eniyan sí rò pé ó tó àkókò tí ìjọba Ọlọrun yóo farahàn.

12 Nítorí náà ó sọ fún wọn pé, “Ọkunrin ìjòyè pataki kan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n fẹ́ fi jọba níbẹ̀ kí ó sì pada wálé lẹ́yìn náà

13 Ó bá pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní owó wúrà kọ̀ọ̀kan. Ó ní, ‘Ẹ máa lọ fi ṣòwò kí n tó dé.’

14 Ṣugbọn àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀ kórìíra rẹ̀. Wọ́n bá rán ikọ̀ ṣiwaju rẹ̀ láti lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí ọkunrin yìí jọba lórí àwọn!

15 “Nígbà tí ọkunrin yìí jọba tán, tí ó pada dé, ó bá ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó ti fún lówó, kí ó baà mọ èrè tí wọ́n ti jẹ.

16 Ekinni bá dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà kan tí o fún mi pa owó wúrà mẹ́wàá.’

17 Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ọmọ-ọ̀dọ̀ rere. O ti ṣe olóòótọ́ ninu ohun kékeré. Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’

18 Ekeji dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà rẹ pa owó wúrà marun-un.’

19 Oluwa rẹ̀ wí fún òun náà pé, ‘Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú marun-un.’

20 “Ẹkẹta dé, ó ní, ‘Alàgbà, owó wúrà rẹ nìyí, aṣọ ni mo fi dì í, mo sì fi pamọ́,

21 nítorí mo bẹ̀rù rẹ. Nítorí òǹrorò eniyan ni ọ́. Níbi tí o kò fi nǹkan sí ni o máa ń wá a sí; níbi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o ti máa ń kórè.’

22 Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ gan-an ni n óo fi ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ burúkú yìí. O mọ̀ pé níbi tí n kò fi nǹkan sí ni mo máa ń wá a sí, ati pé níbi tí n kò fúnrúgbìn sí ni mo ti máa ń kórè.

23 Kí ni kò jẹ́ kí o lọ fi owó mi pamọ́ sí banki, tí ó fi jẹ́ pé bí mo ti dé yìí, ǹ bá gbà á pẹlu èlé?’

24 “Ó bá sọ fún àwọn tí ó dúró níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó wúrà náà ní ọwọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní owó wúrà mẹ́wàá.’

25 Wọ́n bá dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, ṣebí òun ti ní owó wúrà mẹ́wàá!’

26 Ó wá sọ fún wọn pé, ‘Gbogbo ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i. Ọwọ́ ẹni tí kò sì ní, ni a óo ti gba ìba díẹ̀ tí ó ní!

27 Ní ti àwọn ọ̀tá mi wọnyi, àwọn tí kò fẹ́ kí n jọba, ẹ mú wọn wá síhìn-ín, kí ẹ pa wọ́n lójú mi!’ ”

28 Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí tán ó tẹ̀síwájú, ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu.

29 Nígbà tí ó súnmọ́ ẹ̀bá Bẹtifage ati Bẹtani, ní apá òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

30 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ó wà ní ọ̀kánkán yìí. Nígbà tí ẹ bá wọ ibẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ fà á wá.

31 Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ Kí ẹ sọ fún un pé, ‘Oluwa nílò rẹ̀ ni.’ ”

32 Àwọn tí ó rán bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí ó ti sọ fún wọn.

33 Nígbà tí wọn ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn oluwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”

34 Wọ́n sọ fún wọn pé, “Oluwa nílò rẹ̀ ni.”

35 Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún.

36 Bí ó ti ń lọ, wọ́n ń tẹ́ ẹ̀wù wọn sọ́nà.

37 Nígbà tí ó súnmọ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Olifi, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ayọ̀ kígbe sókè, wọ́n ń yin Ọlọrun nítorí gbogbo ohun ńlá tí wọ́n ti rí.

38 Wọ́n ń wí pé,

“Aláásìkí ni ẹni tí ó ń bọ̀ bí ọba ní orúkọ Oluwa.

Alaafia ní ọ̀run! Ògo ní òkè ọ̀run!”

39 Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Farisi tí wọ́n wà láàrin àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”

40 Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Mò ń sọ fun yín pé, bí àwọn wọnyi bá dákẹ́, àwọn òkúta yóo kígbe sókè.”

Jesu Sunkún Lórí Jerusalẹmu

41 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ etí ìlú, ó wo ìlú náà, ó bá bú sẹ́kún lórí rẹ̀.

42 Ó ní, “Ìbá ti dára tó lónìí, bí o bá mọ̀ lónìí ohun tí ó jẹ́ ọ̀nà alaafia rẹ! Ṣugbọn ó pamọ́ fún ọ.

43 Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn ọ̀tá rẹ yóo gbógun tì ọ́, wọn óo yí ọ ká, wọn yóo há ọ mọ́ yípo.

44 Wọn yóo wó ọ lulẹ̀, wọn yóo sì pa àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ. Wọn kò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ekeji ninu rẹ, nítorí o kò fura nígbà tí Ọlọrun wá bẹ̀ ọ́ wò!”

Jesu Lòdì sí Lílo Tẹmpili Bí Ọjà

45 Nígbà tí Jesu wọ inú Tẹmpili, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tajà jáde.

46 Ó sọ fún wọn pè, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!”

47 Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili lojoojumọ. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin, pẹlu àtìlẹ́yìn àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ń wá ọ̀nà láti pa á,

48 ṣugbọn wọn kò rí ọ̀nà, nítorí gbogbo eniyan ń fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.