Categories
LUKU

LUKU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìyìn Rere Luku

fi Jesu hàn wá gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún Israẹli ati Olùgbàlà gbogbo eniyan. Luku kọ ọ́ sinu àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé Ẹ̀mí Oluwa ló pe Jesu láti “waasu Ìròyìn Ayọ̀ fún àwọn òtòṣì.” Ìtara fún àwọn eniyan tí wọ́n ṣe aláìní ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni ó sì kún inú Ìyìn Rere yìí, pataki jùlọ ninu àwọn orí tí wọ́n wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí tí ó ṣe ìkéde dídé Jesu, bẹ́ẹ̀ náà sì tún ni ní ìparí ìwé Luku, nígbà tí Jesu gòkè re ọ̀run. Ẹni tí ó kọ Ìyìn Rere Luku náà ni ó kọ ìtàn ìtànkálẹ̀ ìsìn igbagbọ ninu ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli.

Gẹ́gẹ́ bí a ti to “Àwọn ohun tí ó wà ninu ìwé yìí ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí”, apá keji ati apá kẹfa kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó jẹ́ pé ninu Ìyìn Rere yìí nìkan ni a ti sọ nípa wọn. Lára irú ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni orin tí àwọn angẹli kọ, ati ìbẹ̀wò àwọn olùṣọ́-aguntan ní àkókò tí a bí Jesu. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìtàn bí Jesu ṣe lọ sinu Tẹmpili nígbà tí ó wà ní ọmọde, ati òwe Aláàánú ará Samaria, ati ti ọmọ tí ó sọnù. Jákèjádò ìwé Ìyìn Rere yìí ni ẹni tí ó kọ ọ́ tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ adura, ati ti Ẹ̀mí Mímọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni ti ipa tí àwọn obinrin kó ninu iṣẹ́ tí Jesu ṣe láyé, ati ọ̀rọ̀ lórí bí Ọlọrun ṣe máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-4

Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi ati ti Jesu, ati ìgbà èwe wọn 1:5–2:52

Iṣẹ́ tí Johanu Onítẹ̀bọmi ṣe 3:1-20

Ìrìbọmi ati ìdánwò Jesu 3:21–4:13

Iṣẹ́ tí Jesu ṣe ní gbangba ní Galili 4:14–9:50

Láti Galili dé Jerusalẹmu 9:51–19:27

Ọ̀sẹ̀ ìkẹyìn Jesu ní Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀ 19:28–23:56

Ajinde, ìfarahàn, ati ìgòkè-re-ọ̀run Oluwa 24:1-53

Categories
LUKU

LUKU 1

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju sí Tiofilu

1 Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ti kọ ìròyìn lẹ́sẹẹsẹ, nípa ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ láàrin wa;

2 àwọn tí nǹkan wọnyi ṣojú wọn, tí wọ́n sì sọ fún wa.

3 Mo ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ohun gbogbo fínnífínní. Èmi náà wá pinnu láti kọ ìwé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ọlọ́lá jùlọ, Tiofilu,

4 kí o lè mọ òtítọ́ àwọn nǹkan tí wọ́n kọ́ ọ.

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi

5 Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni.

6 Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.

7 Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó.

8 Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili.

9 Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn alufaa, Sakaraya ni ìbò mú láti sun turari ninu iyàrá Tẹmpili Oluwa.

10 Gbogbo àwọn eniyan ń gbadura lóde ní àkókò tí ó ń sun turari.

11 Angẹli Oluwa kan bá yọ sí i, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ turari.

12 Nígbà tí Sakaraya rí i, ó ta gìrì, ẹ̀rù bà á.

13 Ṣugbọn angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaraya, nítorí pé adura rẹ ti gbà. Elisabẹti iyawo rẹ yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo pe orúkọ rẹ̀ ní Johanu.

14 Ayọ̀ yóo kún ọkàn rẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá ọ yọ̀ nígbà tí ẹ bá bí ọmọ náà.

15 Ọmọ náà yóo jẹ́ ẹni ńlá níwájú Oluwa. Kò gbọdọ̀ mu ọtíkọ́tí, ìbáà jẹ́ líle tabi èyí tí kò le. Yóo kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ìgbà tí ó bá tí wà ninu ìyá rẹ̀;

16 ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ni yóo sì yipada sí Oluwa Ọlọrun wọn.

17 Òun ni yóo ṣáájú Oluwa pẹlu ẹ̀mí Elija ati agbára rẹ̀. Yóo mú kí àwọn baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu àwọn ọmọ wọn. Yóo yí àwọn alágídí ọkàn pada sí ọ̀nà rere. Yóo sọ àwọn eniyan di yíyẹ lọ́dọ̀ Oluwa.”

18 Sakaraya bi angẹli náà pé, “Báwo ni n óo ti ṣe mọ̀? Nítorí pé mo ti di arúgbó; iyawo mi alára náà sì ti di àgbàlagbà.”

19 Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ.

20 Nítorí pé ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, o óo ya odi, o kò ní lè sọ̀rọ̀ títí ọjọ́ tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí yóo ṣẹ nígbà tí ó bá yá.”

21 Àwọn eniyan ti ń retí Sakaraya. Ẹnu yà wọ́n pé ó pẹ́ ninu iyàrá Tẹmpili.

22 Nígbà tí ó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé ó ti rí ìran ninu iyàrá Tẹmpili ni. Ó yadi, ọwọ́ ni ó fi ń ṣe àpèjúwe fún wọn.

23 Nígbà tí ó parí àkókò tí yóo fi ṣiṣẹ́ alufaa ninu Tẹmpili, ó pada lọ sí ilé rẹ̀.

24 Lẹ́yìn náà, Elisabẹti lóyún. Ó bá fi ara pamọ́ fún oṣù marun-un. Ó ní,

25 “Oluwa ni ó ṣe èyí fún mi. Ó ti fi ojú àánú wò mí, ó sì ti mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀gàn fún mi lójú eniyan kúrò.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìbí Jesu

26 Ní oṣù kẹfa, Ọlọrun rán angẹli Geburẹli lọ sí ìlú kan ní Galili tí wọn ń pè ní Nasarẹti.

27 Ọlọrun rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wundia kan tí ó jẹ́ iyawo àfẹ́sọ́nà ọkunrin kan tí ń jẹ́ Josẹfu, ti ìdílé Dafidi. Wundia náà ń jẹ́ Maria.

28 Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.”

29 Nígbà tí Maria gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ń rò lọ́kàn rẹ̀ pé, irú kíkí wo nìyí?

30 Angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí o ti bá ojurere Ọlọrun pàdé.

31 O óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni o óo pe orúkọ rẹ̀.

32 Eniyan ńlá ni yóo jẹ́. Ọmọ Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè é. Oluwa Ọlọrun yóo fún un ní ìtẹ́ Dafidi, baba rẹ̀.

33 Yóo jọba lórí ìdílé Jakọbu títí lae, ìjọba rẹ̀ kò ní lópin.”

34 Maria bá bi angẹli náà pé, “Báwo ni yóo ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí n kò tíì mọ ọkunrin?”

35 Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóo tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá Ògo yóo ṣíji bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Mímọ́ Ọlọrun ni a óo máa pe ọmọ tí ìwọ óo bí.

36 Ati pé Elisabẹti, ìbátan rẹ náà ti lóyún ọmọkunrin kan ní ìgbà ogbó rẹ̀. Ẹni tí wọ́n ti ń pè ní àgàn rí sì ti di aboyún oṣù mẹfa.

37 Nítorí kò sí ohun tí ó ṣòro fún Ọlọrun.”

38 Maria bá dáhùn pé, “Iranṣẹ Oluwa ni mí. Kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà bá fi í sílẹ̀ lọ.

Maria Lọ Bẹ Elisabẹti Wò

39 Lẹ́yìn náà, Maria múra pẹlu ìwàǹwára, ó lọ sí ìlú Judia kan tí ó wà ní agbègbè orí òkè.

40 Ó wọ inú ilé Sakaraya, ó bá kí Elisabẹti.

41 Bí Elisabẹti ti gbọ́ ohùn Maria, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabẹti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.

42 Ó kígbe sókè, ó ní, “Ibukun Ọlọrun wà lórí rẹ pupọ láàrin àwọn obinrin. Ibukun Ọlọrun sì wà lórí ọmọ inú rẹ.

43 Mo ṣe ṣe oríire tó báyìí, tí ìyá Oluwa mi fi wá sọ́dọ̀ mi?

44 Nítorí bí mo ti gbọ́ ohùn rẹ nígbà tí o kí mi, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ inú mi sọ nítorí ó láyọ̀.

45 Ayọ̀ ń bẹ fún ọ nítorí o gba ohun tí Oluwa ti sọ gbọ́, pé yóo ṣẹ.”

Maria Kọ Orin Ìyìn

46 Nígbà náà ni Maria sọ pé,

“Ọkàn mi gbé Oluwa ga,

47 ẹ̀mí mi yọ̀ sí Ọlọrun, Olùgbàlà mi,

48 nítorí ó ti bojúwo ipò ìrẹ̀lẹ̀ iranṣẹbinrin rẹ̀.

Wò ó! Láti ìgbà yìí lọ

gbogbo ìran ni yóo máa pè mí ní olóríire.

49 Nítorí Olodumare ti ṣe ohun ńlá fún mi,

Mímọ́ ni orúkọ rẹ̀;

50 àánú rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran

fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

51 Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn,

ó tú àwọn tí ó gbéraga ninu ọkàn wọn ká.

52 Ó yọ àwọn ìjòyè kúrò lórí oyè,

ó gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga.

53 Ó fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ àwọn tí ebi ń pa,

ó mú àwọn ọlọ́rọ̀ jáde lọ́wọ́ òfo.

54 Ó ran Israẹli ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́

nígbà tí ó ranti àánú rẹ̀,

55 gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí ó ti ṣe fún àwọn baba wa:

fún Abrahamu ati fún ìdílé rẹ̀ títí lae.”

56 Maria dúró lọ́dọ̀ Elisabẹti tó bíi oṣù mẹta, ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀.

Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi

57 Nígbà tí àkókò Elisabẹti tó tí yóo bí, ó bí ọmọkunrin kan.

58 Àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ pé Oluwa ti ṣàánú pupọ fún un, wọ́n wá bá a yọ̀.

59 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá láti kọ́ ọmọ náà ní ilà-abẹ́. Wọ́n fẹ́ sọ ọ́ ní Sakaraya, bí orúkọ baba rẹ̀.

60 Ṣugbọn ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Rárá o! Johanu ni a óo máa pè é.”

61 Wọ́n sọ fún un pé, “Kò sí ẹnìkan ninu àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí ó ń jẹ́ orúkọ yìí.”

62 Wọ́n wá ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀ pé báwo ni ó fẹ́ kí á máa pe ọmọ náà.

63 Ó bá bèèrè fún nǹkan ìkọ̀wé, ó kọ ọ́ pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu ya gbogbo eniyan.

64 Lẹsẹkẹsẹ ohùn Sakaraya bá là, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀, ó ń yin Ọlọrun.

65 Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo àwọn aládùúgbò wọn. Ìròyìn tàn ká gbogbo agbègbè olókè Judia, wọ́n ń sọ ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀.

66 Gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ń da ọ̀rọ̀ náà rò ninu ọkàn wọn, wọ́n ń sọ pé, “Irú ọmọ wo ni èyí yóo jẹ́?” Nítorí ọwọ́ Oluwa wà lára rẹ̀.

Sakaraya Sọ Àsọtẹ́lẹ̀

67 Sakaraya, baba ọmọ náà, kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé,

68 Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹli

nítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀,

ó sì ti dá wọn nídè.

69 Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún wa

ní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀;

70 gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́,

láti ọjọ́ pípẹ́;

71 pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa

ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa;

72 pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò,

ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́

73 gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa,

74 pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,

ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà,

75 pẹlu ọkàn kan ati pẹlu òdodo

níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

76 “Ìwọ, ọmọ mi,

wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́,

nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é,

77 láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn eniyan rẹ̀,

nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

78 nítorí àánú Ọlọrun wa,

nípa èyí tí oòrùn ìgbàlà fi ràn lé wa lórí láti òkè wá,

79 láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní òkùnkùn

ati àwọn tí ó jókòó níbi òjìji ikú,

láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà alaafia.”

80 Ọmọ náà ń dàgbà, ó sì ń lágbára sí i lára ati lẹ́mìí. Ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni ó ń gbé títí di àkókò tí ó fara han àwọn eniyan Israẹli.

Categories
LUKU

LUKU 2

Ìbí Jesu

1 Ní àkókò náà, àṣẹ kan jáde láti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu pé kí gbogbo ayé lọ kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìjọba.

2 Èyí ni àkọsílẹ̀ ekinni tí wọ́n ṣe nígbà tí Kureniu jẹ́ gomina Siria.

3 Gbogbo àwọn eniyan bá lọ kọ orúkọ wọn sílẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ sí ìlú ara rẹ̀.

4 Josẹfu náà gbéra láti Nasarẹti ìlú kan ní ilẹ̀ Galili, ó lọ sí ìlú Dafidi tí ó ń jẹ́ Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Judia, nítorí ẹbí Dafidi ni.

5 Ó lọ kọ orúkọ sílẹ̀ pẹlu Maria iyawo àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí ó lóyún, tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ.

6 Ó wá yá nígbà tí wọ́n wà ní Bẹtilẹhẹmu, àkókò tó fún Maria láti bímọ.

7 Ó bá bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkunrin, ó fi ọ̀já wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, nítorí kò sí àyè fún wọn ninu ilé èrò.

8 Ní àkókò náà, àwọn olùṣọ́-aguntan wà ní pápá, níbi tí wọn ń ṣọ́ aguntan wọn ní òru.

9 Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an.

10 Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan.

11 Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya.

12 Àmì tí ẹ óo fi mọ̀ ọ́n nìyí: ẹ óo rí ọmọ-ọwọ́ náà tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.”

13 Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé,

14 “Ògo fún Ọlọrun lókè ọ̀run,

alaafia ní ayé fún àwọn tí inú Ọlọrun dùn sí.”

15 Lẹ́yìn tí àwọn angẹli náà ti pada kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-aguntan ń sọ láàrin ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtilẹhẹmu tààrà, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tí Oluwa bùn wá gbọ́.”

16 Wọ́n bá yára lọ. Wọ́n wá Maria kàn ati Josẹfu ati ọmọ-ọwọ́ náà tí a tẹ́ sí ibùjẹ ẹran.

17 Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sọ ohun gbogbo tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ náà.

18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ohun tí àwọn olùṣọ́-aguntan náà sọ fún wọn.

19 Ṣugbọn Maria ń ṣe akiyesi gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó ń dà wọ́n rò ní ọkàn rẹ̀.

20 Àwọn olùṣọ́-aguntan náà pada síbi iṣẹ́ wọn, wọ́n ń fi ògo ati ìyìn fún Ọlọrun fún gbogbo nǹkan tí wọ́n gbọ́, ati àwọn nǹkan tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí angẹli náà ti sọ fún wọn.

A Sọ Jesu Lórúkọ

21 Nígbà tí ọjọ́ kẹjọ pé láti kọ ọmọ náà ní ilà-abẹ́, wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu, gẹ́gẹ́ bí angẹli ti wí, kí ìyá rẹ̀ tó lóyún rẹ̀.

A Gbé Jesu lọ sí Tẹmpili

22 Nígbà tí ó tó àkókò fún àwọn òbí rẹ̀ láti ṣe àṣà ìwẹ̀mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, wọ́n gbé ọmọ náà lọ sí Jerusalẹmu láti fi í fún Oluwa.

23 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin Oluwa pé, “Gbogbo àkọ́bí lọkunrin ni a óo pè ní mímọ́ fún Oluwa.”

24 Wọ́n tún lọ láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ninu òfin Oluwa: pẹlu àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji.

25 Ọkunrin kan wà ní Jerusalẹmu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simeoni. Ó jẹ́ olódodo eniyan ati olùfọkànsìn, ó ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo tu Israẹli ninu. Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu rẹ̀.

26 Ẹ̀mí Mímọ́ ti fihàn án pé kò ní tíì kú tí yóo fi rí Mesaya tí Oluwa ti ṣe ìlérí.

27 Ẹ̀mí wá darí rẹ̀ sí Tẹmpili ní àkókò tí àwọn òbí ọmọ náà gbé e wá, láti ṣe gbogbo ètò tí ó yẹ gẹ́gẹ́ bí òfin.

28 Ni Simeoni bá gbé ọmọ náà lọ́wọ́, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní,

29 “Nisinsinyii, Oluwa, dá ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ sílẹ̀ ní alaafia,

gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

30 Nítorí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ,

31 tí o ti pèsè níwájú gbogbo eniyan;

32 ìmọ́lẹ̀ láti fi ọ̀nà han àwọn kèfèrí

ati ògo fún Israẹli, eniyan rẹ.”

33 Ẹnu ya baba ati ìyá Jesu nítorí ohun tí ó sọ nípa rẹ̀.

34 Simeoni wá súre fún wọn. Ó sọ fún Maria ìyá rẹ̀ pé, “A gbé ọmọ yìí dìde fún ìṣubú ati ìdìde ọpọlọpọ ní Israẹli ati bí àmì tí àwọn eniyan yóo kọ̀.

35 Nítorí yóo mú kí àṣírí èrò ọkàn ọpọlọpọ di ohun tí gbogbo eniyan yóo mọ̀. Ìbànújẹ́ yóo sì gún ọ ní ọkàn bí idà.”

36-37 Wolii obinrin kan wà tí ń jẹ́ Ana, ọmọ Fanuẹli, ẹ̀yà Aṣeri. Arúgbó kùjọ́kùjọ́ ni. Ọdún meje péré ni ó ṣe ní ilé ọkọ, tí ọkọ rẹ̀ fi kú. Láti ìgbà náà ni ó ti di opó, ó sì tó ẹni ọdún mẹrinlelọgọrin ní àkókò yìí. Kì í fi ìgbà kan kúrò ninu Tẹmpili. Ó ń sìn pẹlu ààwẹ̀ ati ẹ̀bẹ̀ tọ̀sán-tòru.

38 Ní àkókò náà gan-an ni ó dé, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun, ó ń sọ nípa ọmọ yìí fún gbogbo àwọn tí wọn ń retí àkókò ìdásílẹ̀ Jerusalẹmu.

Àwọn Òbí Jesu Gbé e Pada Lọ sí Nasarẹti

39 Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí gbogbo nǹkan wọnyi tán gẹ́gẹ́ bí òfin Oluwa, wọ́n pada lọ sí Nasarẹti ìlú wọn ní ilẹ̀ Galili.

40 Ọmọ náà ń dàgbà, ó ń lágbára, ó kún fún ọgbọ́n, ojurere Ọlọrun sì wà pẹlu rẹ̀.

Jesu lọ sí Tẹmpili Nígbà Ọ̀dọ́ Rẹ̀

41 Àwọn òbí Jesu a máa lọ sí Àjọ̀dún Ìrékọjá ní Jerusalẹmu ní ọdọọdún.

42 Nígbà tí Jesu di ọmọ ọdún mejila, wọ́n lọ sí àjọ yìí gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn.

43 Nígbà tí àjọ̀dún parí, tí wọn ń pada lọ sí ilé, ọmọde náà, Jesu, dúró ní Jerusalẹmu, ṣugbọn àwọn òbí rẹ̀ kò fura.

44 Wọ́n ṣebí ó wà láàrin ọ̀pọ̀ eniyan tí ń kọ́wọ̀ọ́ rìn ni. Lẹ́yìn tí wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri láàrin àwọn mọ̀lẹ́bí ati àwọn ojúlùmọ̀ wọn.

45 Nígbà tí wọn kò rí i, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a.

46 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, wọ́n rí i ninu Tẹmpili, ó jókòó láàrin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, òun náà sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.

47 Ẹnu ya gbogbo àwọn tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye rẹ̀ ati nítorí bí ó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọn ń bi í.

48 Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ẹnu yà wọ́n. Ìyá rẹ̀ bá bi í pé, “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Èmi ati baba rẹ dààmú pupọ nígbà tí à ń wá ọ.”

49 Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń wá mi kiri? Ẹ kò mọ̀ pé dandan ni fún mi kí n wà ninu ilé Baba mi?”

50 Gbolohun tí ó sọ fún wọn yìí kò sì yé wọn.

51 Ó bá bá wọn lọ sí Nasarẹti, ó sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Ìyá rẹ̀ pa gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi mọ́ ní ọkàn rẹ̀.

52 Bí Jesu ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì ń bá ojurere Ọlọrun ati ti àwọn eniyan pàdé.

Categories
LUKU

LUKU 3

Iwaasu Johanu Onítẹ̀bọmi

1 Ní ọdún kẹẹdogun tí Ọba Tiberiu ti wà lórí oyè, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ gomina Judia, tí Hẹrọdu jẹ́ baálẹ̀ Galili, tí Filipi arakunrin rẹ̀ jẹ́ baálẹ̀ Ituria ati ti agbègbè Tirakoniti, Lusaniu jẹ́ baálẹ̀ Abilene;

2 Anasi ati Kayafa sì jẹ́ olórí alufaa. Johanu ọmọ Sakaraya gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní aṣálẹ̀ tí ó wà.

3 Ó bá ń kiri gbogbo ìgbèríko odò Jọdani, ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n.

4 Èyí rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé ọ̀rọ̀ wolii Aisaya pé,

“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní aṣálẹ̀ pé,

‘Ẹ la ọ̀nà fún Oluwa,

ẹ ṣe ojú ọ̀nà tí ó tọ́ fún un láti rìn!

5 Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí

gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké

ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀.

A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ,

a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán

6 Gbogbo eniyan ni yóo rí ìgbàlà Ọlọrun.’ ”

7 Johanu ń sọ fún àwọn eniyan tí ó jáde lọ ṣe ìrìbọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fun yín láti sá fún ibinu tí ń bọ̀?

8 Ẹ fihàn ninu ìwà yín pé ẹ ti ronupiwada. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ láti máa rò ninu ara yín pé, ‘A ní Abrahamu ní baba.’ Nítorí mò ń sọ fun yín pé Ọlọrun lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu láti inú òkúta wọnyi.

9 A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí. Nítorí náà, igikígi tí kò bá máa so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.”

10 Àwọn eniyan wá bi í pé, “Kí ni kí a wá ṣe?”

11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó bá ní dàńṣíkí meji, kí ó fún ẹni tí kò ní lọ́kan. Ẹni tí ó bá ní oúnjẹ níláti ṣe bákan náà.”

12 Àwọn agbowó-odè náà wá láti ṣe ìrìbọmi. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, kí ni kí a ṣe?”

13 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe gbà ju iye tí ó tọ́ lọ.”

14 Àwọn ọmọ-ogun náà ń bi í pé, “Àwa náà ńkọ́, kí ni kí a ṣe?”

Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rù ba ẹnikẹ́ni láti lọ́ wọn lọ́wọ́ gbà, Ẹ má ṣe fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni. Ẹ jẹ́ kí owó oṣù yín to yín.”

15 Àwọn eniyan ń retí, gbogbo wọn ń rò ninu ọkàn wọn bí Johanu bá ni Mesaya.

16 Johanu sọ fún gbogbo eniyan pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín, ṣugbọn ẹni tí ó jù mí lọ ń bọ̀. Èmi kò tó ẹni tíí tú okùn bàtà rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ati iná ni yóo fi wẹ̀ yín mọ́.

17 Àtẹ ìfẹ́kà ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ tí yóo fi fẹ́ ọkà inú oko rẹ̀; yóo kó ọkà rẹ̀ sinu abà, yóo sì sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”

18 Ní ọ̀nà yìí ati ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà mìíràn, Johanu ń gba àwọn eniyan níyànjú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn.

19 Ní àkókò kan, Johanu bá Hẹrọdu baálẹ̀ wí nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi, iyawo Filipi, arakunrin rẹ̀, tí Hẹrọdu gbà. Ó tún bá a wí fún gbogbo nǹkan burúkú mìíràn tí ó ṣe.

20 Hẹrọdu wá tún fi ti Johanu tí ó sọ sẹ́wọ̀n kún gbogbo ìwà burúkú rẹ̀.

Johanu Ṣe Ìrìbọmi fún Jesu

21 Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀.

22 Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.”

Ìrandíran Jesu

23 Jesu tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ọmọ Josẹfu ni àwọn eniyan mọ̀ ọ́n sí. Josẹfu jẹ́ ọmọ Eli,

24 ọmọ Matati, ọmọ Lefi, ọmọ Meliki, ọmọ Janai, ọmọ Josẹfu,

25 ọmọ Matatiya, ọmọ Amosi, ọmọ Nahumu, ọmọ Esili, ọmọ Nagai,

26 ọmọ Maati, ọmọ Matatiya, ọmọ Semehin, ọmọ Joseki, ọmọ Joda,

27 ọmọ Johana, ọmọ Resa, ọmọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ọmọ Neri,

28 ọmọ Meliki, ọmọ Adi, ọmọ Kosamu, ọmọ Elimadamu, ọmọ Eri,

29 ọmọ Joṣua ọmọ Elieseri, ọmọ Jorimu, ọmọ Matati, ọmọ Lefi,

30 ọmọ Simeoni, ọmọ Juda, ọmọ Josẹfu, ọmọ Jonamu, ọmọ Eliakimu,

31 ọmọ Melea, ọmọ Mena, ọmọ Matati, ọmọ Natani, ọmọ Dafidi,

32 ọmọ Jese, ọmọ Obedi, ọmọ Boasi, ọmọ Salimoni, ọmọ Naṣoni,

33 ọmọ Aminadabu, ọmọ Adimini, ọmọ Arini, ọmọ Hesironi, ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda,

34 ọmọ Jakọbu, ọmọ Isaaki, ọmọ Abrahamu, ọmọ Tẹra, ọmọ Nahori,

35 ọmọ Serugi, ọmọ Reu, ọmọ Pelegi, ọmọ Eberi, ọmọ Sela,

36 ọmọ Kainani, ọmọ Afasadi, ọmọ Ṣemu, ọmọ Noa, ọmọ Lamẹki,

37 ọmọ Metusela, ọmọ Enọku, ọmọ Jaredi, ọmọ Mahalaleli, ọmọ Kenani,

38 ọmọ Enọṣi, ọmọ Seti, ọmọ Adamu, ọmọ Ọlọrun.

Categories
LUKU

LUKU 4

Ìdánwò Jesu

1 Jesu pada láti odò Jọdani, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí bá darí rẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀.

2 Ogoji ọjọ́ ni èṣù fi dán an wò. Kò jẹ ohunkohun ní gbogbo àkókò náà. Lẹ́yìn náà, ebi wá ń pa á.

3 Èṣù sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, sọ fún òkúta yìí pé kí ó di àkàrà.”

4 Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè.’ ”

5 Èṣù bá mú un lọ sí orí òkè kan, ó fi gbogbo ìjọba ayé hàn án ní ìṣẹ́jú kan.

6 Ó sọ fún Jesu pé, “Ìwọ ni n óo fún ní gbogbo àṣẹ yìí ati ògo rẹ̀, nítorí èmi ni a ti fi wọ́n lé lọ́wọ́, ẹni tí ó bá sì wù mí ni mo lè fún.

7 Tí o bá júbà mi, tìrẹ ni gbogbo rẹ̀ yóo dà.”

8 Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o sì máa sìn!’ ”

9 Èṣù tún mú un lọ sí Jerusalẹmu. Ó gbé e ka téńté òrùlé Tẹmpili. Ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀ láti ìhín.

10 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ pé kí wọn pa ọ́ mọ́.’

11 Ati pé, ‘Kí wọn tẹ́wọ́ gbà ọ́ kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ”

12 Jesu dá a lóhùn pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”

13 Nígbà tí Satani parí gbogbo ìdánwò yìí, ó fi Jesu sílẹ̀ títí di àkókò tí ó bá tún wọ̀.

Jesu Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Rẹ̀ ní Galili

14 Jesu pada sí Galili pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko.

15 Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé wọn. Gbogbo eniyan sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere.

Àwọn Ará Nasarẹti Kọ Jesu

16 Ó wá dé Nasarẹti, ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí ilé ìpàdé. Ó bá dìde láti ka Ìwé Mímọ́.

17 Wọ́n fún un ní ìwé wolii Aisaya. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé,

18 “Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi

nítorí ó ti fi òróró yàn mí

láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.

Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀

fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn,

ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran;

láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia,

19 ati láti waasu ọdún tí Oluwa yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là.”

20 Ó bá pa ìwé náà dé, ó fi í fún olùtọ́jú ilé ìpàdé, ó bá jókòó. Gbogbo àwọn eniyan tí ó wà ninu ilé ìpàdé tẹjú mọ́ ọn;

21 ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé, “Lónìí ni àkọsílẹ̀ yìí ṣẹ ní ojú yín.”

22 Gbogbo wọn ni wọ́n gbà fún un, ẹnu sì yà wọ́n fún ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ jáde, wọ́n wá ń sọ pé, “Àbí ọmọ Josẹfu kọ́ nìyí ni?”

23 Ó sọ fún wọn pé, “Ní òtítọ́ ẹ lè pa òwe yìí fún mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn! Ohun gbogbo tí a gbọ́ pé o ṣe ní Kapanaumu, ṣe wọ́n níhìn-ín, ní ìlú baba rẹ.’ ”

24 Ó tún fi kún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí wolii kan tíí ní iyì ní ìlú baba rẹ̀.

25 “Òtítọ́ ni mo sọ fun yín pé opó pọ̀ ní Israẹli ní àkókò Elija, nígbà tí kò fi sí òjò fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ìyàn fi mú níbi gbogbo.

26 A kò rán Elija sí ọ̀kankan ninu wọn. Ọ̀dọ̀ ẹni tí a rán an sí ni opó kan ní Sarefati ní agbègbè Sidoni.

27 Àwọn adẹ́tẹ̀ pọ̀ ní Israẹli ní àkókò wolii Eliṣa. Kò sí ọ̀kan ninu wọn tí a wòsàn, àfi Naamani ará Siria.”

28 Nígbà tí àwọn tí ó wà ninu ilé ìpàdé gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí gbogbo wọn.

29 Wọ́n dìde, wọ́n tì í sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ibi tí ìlú wọn wà, wọ́n fẹ́ taari rẹ̀ ní ogedengbe.

30 Ṣugbọn ó la ààrin wọn kọjá, ó bá tirẹ̀ lọ.

Ọkunrin Tí Ó Ní Ẹ̀mí Èṣù

31 Jesu bá lọ sí Kapanaumu, ìlú kan ní ilẹ̀ Galili. Ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi.

32 Ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀, nítorí pẹlu àṣẹ ni ó fi ń sọ̀rọ̀.

33 Ọkunrin kan wà ninu ilé ìpàdé tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ó bá kígbe tòò,

34 ó ní, “Háà! Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ ti Ọlọrun ni ọ́.”

35 Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára.

36 Ẹnu ya gbogbo eniyan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Irú ọ̀rọ̀ wo ni èyí? Nítorí pẹlu àṣẹ ati agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí èṣù wí, wọ́n sì ń jáde!”

37 Òkìkí Jesu sì kàn ká gbogbo ìgbèríko ibẹ̀.

Jesu Wo Ọpọlọpọ Eniyan Sàn

38 Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu.

39 Ó bá lọ dúró lẹ́bàá ibùsùn ìyá náà, ó bá ibà náà wí, ibà sì fi ìyá náà sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún wọn.

40 Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn.

41 Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.”

Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya.

Jesu Ń Waasu Kiri

42 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jesu jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí ẹnìkankan. Àwọn eniyan ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fẹ́ dá a dúró kí ó má kúrò lọ́dọ̀ wọn.

43 Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Dandan ni fún mi láti waasu ìyìn rere ìjọba ọ̀run ní àwọn ìlú mìíràn, nítorí ohun tí Ọlọrun rán mi wá ṣe nìyí.”

44 Ni ó bá ń waasu ní gbogbo àwọn ilé ìpàdé ní Judia.

Categories
LUKU

LUKU 5

Jesu Pe Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Rẹ̀ Àkọ́kọ́

1 Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

2 Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn.

3 Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan.

4 Nígbà tí ó parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, ó sọ fún Simoni pé, “Tu ọkọ̀ lọ sí ibú, kí o da àwọ̀n sí omi kí ó lè pa ẹja.”

5 Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.”

6 Nígbà tí ó dà á sinu omi, ẹja tí ó kó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọ̀n fẹ́ ya.

7 Wọ́n bá ṣe àmì sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ keji pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n da ẹja kún inú ọkọ̀ mejeeji, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ rì.

8 Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.”

9 Nítorí ẹnu yà á ati gbogbo àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ẹja tí wọ́n rí pa.

10 Ẹnu ya Jakọbu náà ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Simoni. Jesu wá sọ fún Peteru pé, “Má bẹ̀rù. Láti ìgbà yìí lọ eniyan ni ìwọ yóo máa mú wá.”

11 Nígbà tí wọ́n tu ọkọ̀ dé èbúté, wọ́n fi ohun gbogbo sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé e.

Jesu Wo Adẹ́tẹ̀ Sàn

12 Ní àkókò kan nígbà tí Jesu wà ninu ìlú kan, ọkunrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò ní gbogbo ara rí i. Ó bá wá dojúbolẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.”

13 Jesu bá na ọwọ́, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́ kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà fi í sílẹ̀.

14 Jesu bá kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni, ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ fún ìsọdi-mímọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ. Èyí yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.”

15 Ṣugbọn ńṣe ni ìròyìn rẹ̀ túbọ̀ ń tàn kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan wá ń péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìlera wọn.

16 Ṣugbọn aṣálẹ̀ ni ó máa ń lọ láti dá gbadura.

Jesu Wo Ọkunrin Arọ Kan Sàn

17 Ní ọjọ́ kan bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn Farisi ati àwọn amòfin jókòó níbẹ̀. Wọ́n wá láti gbogbo ìletò Galili ati ti Judia ati láti Jerusalẹmu. Agbára Oluwa wà pẹlu Jesu láti fi ṣe ìwòsàn.

18 Àwọn ẹnìkan gbé ọkunrin arọ kan wá tí ó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé e dé iwájú Jesu.

19 Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n gbé e gun orí òrùlé. Wọ́n bá dá òrùlé lu kí wọ́n fi lè gbé arọ náà pẹlu ibùsùn rẹ̀ sí ààrin àwọn eniyan níwájú Jesu.

20 Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó ní, “Arakunrin, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

21 Àwọn amòfin ati àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun báyìí? Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan lẹ́yìn Ọlọrun nìkan ṣoṣo?”

22 Jesu ti mọ ohun tí wọ́n ń bá ara wọn sọ, ó bá dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro irú èrò báyìí ní ọkàn yín?

23 Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde kí o máa rìn’?

24 Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni,” ó bá sọ fún arọ náà pé, “Mo sọ fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”

25 Lẹsẹkẹsẹ ó dìde lójú gbogbo wọn, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọrun lógo.

26 Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan. Wọ́n ń yin Ọlọrun lógo. Ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ń sọ pé, “Ìròyìn kò tó àfojúbà ni ohun tí a rí lónìí!”

Jesu Pe Lefi

27 Lẹ́yìn èyí Jesu jáde lọ. Ó rí agbowó-odè kan tí ó ń jẹ́ Lefi tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Jesu sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”

28 Ó bá fi ohun gbogbo sílẹ̀, ó dìde, ó ń tẹ̀lé e.

29 Lefi bá se àsè ńlá fún Jesu ninu ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ẹlòmíràn, tí wọn ń bá wọn jẹun.

30 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?”

31 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá.

32 Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mo wá pè sí ìrònúpìwàdà.”

Ìbéèrè Nípa Ààwẹ̀ Gbígbà

33 Àwọn kan sọ fún un pé, “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ń gbààwẹ̀ nígbà pupọ, wọn a sì máa gbadura. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n ń mu ní tiwọn ni.”

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn.

35 Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo mú ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn. Wọn óo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.”

36 Jesu wá pa òwe kan fún wọn pé, “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ya lára ẹ̀wù titun kí ó fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ba ẹ̀wù titun jẹ́, aṣọ titun tí ó sì fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù kò bá ara wọn mu.

37 Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọtí titun yóo bẹ́ àpò, ọtí yóo tú dànù, àpò yóo sì tún bàjẹ́.

38 Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni wọ́n ń fi ọtí titun sí.

39 Kò sí ẹni tí ó bá ti mu ọtí tí ó mú, tíí fẹ́ mu ọtí àṣẹ̀ṣẹ̀pọn. Nítorí yóo sọ pé, ‘Ọtí tí ó mú ni ó dára.’ ”

Categories
LUKU

LUKU 6

Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Jesu Ń Já Ọkà Ní Ọjọ́ Ìsinmi

1 Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, bí Jesu ti ń la oko ọkà kan kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń fi ọwọ́ ra á, wọ́n bá ń jẹ ẹ́.

2 Àwọn kan ninu àwọn Farisi sọ pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi?”

3 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?

4 Bí ó ti wọ ilé Ọlọrun lọ, tí ó mú burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, tí ó jẹ ẹ́, tí ó tún fún àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi àwọn alufaa nìkan?”

5 Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.”

Ọkunrin Tí Ọwọ́ Rẹ̀ Rọ

6 Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi mìíràn, Jesu wọ inú ilé ìpàdé lọ, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.

7 Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ń ṣọ́ Jesu bí yóo ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn fi kàn án.

8 Ṣugbọn ó ti mọ ohun tí wọn ń rò ní ọkàn wọn. Ó sọ fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde kí o dúró ní ààrin.” Ọkunrin náà bá dìde dúró.

9 Jesu wá sọ fún wọn pé, “Mo bi yín, èwo ni ó bá òfin mu, láti ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là, tabi láti pa á run?”

10 Ó wá wo gbogbo wọn yíká, ó sọ fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ bá bọ́ sípò.

11 Inú wọn ru sókè, wọ́n wá ń bá ara wọn jíròrò nípa ohun tí wọn ìbá ṣe sí Jesu.

Jesu Yan Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Mejila

12 Ní ọjọ́ kan, Jesu lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Gbogbo òru ni ó fi gbadura sí Ọlọrun.

13 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó yan àwọn mejila ninu wọn, tí ó pè ní aposteli.

14 Àwọn ni Simoni tí ó sọ ní Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu,

15 Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Simoni tí ó tún ń jẹ́ Seloti,

16 Judasi ọmọ Jakọbu ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó di ọ̀dàlẹ̀.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn

17 Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun.

18 Wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati pé kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìsàn wọn. Ó tún ń wo àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú sàn.

19 Gbogbo àwọn eniyan ni ó ń wá a, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án nítorí agbára ń ti ara rẹ̀ jáde. Ó bá wo gbogbo wọn sàn.

Ìre ati Ègún

20 Ó bá gbé ojú sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé,

“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin talaka,

nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọrun.

21 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ebi ń pa nisinsinyii,

nítorí ẹ óo yó.

Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sunkún nisinsinyii,

nítorí ẹ óo rẹ́rìn-ín.

22 “Ayọ̀ ń bẹ fun yín nígbà tí àwọn eniyan bá kórìíra yín, tí wọ́n bá le yín ní ìlú bí arúfin, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n bá fi orúkọ yín pe ibi, nítorí Ọmọ-Eniyan.

23 Ẹ máa yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ sì máa jó, nítorí èrè pọ̀ fun yín ní ọ̀run. Irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wolii.

24 “Ṣugbọn ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ gbé,

nítorí ẹ ti jẹ ìgbádùn tiyín tán!

25 Ẹ̀yin tí ẹ yó nisinsinyii, ẹ gbé,

nítorí ebi ń bọ̀ wá pa yín.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń yọ̀ nisinsinyii, ẹ gbé,

nítorí ọ̀fọ̀ óo ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì sunkún.

26 “Nígbà tí gbogbo eniyan bá ń ròyìn yín ní rere, ẹ gbé, nítorí bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wolii.

Ẹ Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Yín

27 “Ṣugbọn fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, mo sọ fun yín pé: ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín: ẹ máa ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín.

28 Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín.

29 Bí ẹnìkan bá gba yín létí, ẹ yí ẹ̀gbẹ́ keji sí i. Ẹni tí ó bá gba agbádá yín, ẹ má ṣe du dàńṣíkí yín mọ́ ọn lọ́wọ́.

30 Bí ẹnikẹ́ni bá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ yín, ẹ fún un. Bí ẹnìkan bá mú nǹkan yín, ẹ má bèèrè rẹ̀ pada.

31 Bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan máa ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.

32 “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn.

33 Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀.

34 Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

35 Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú.

36 Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.

Ọ̀rọ̀ Nípa Ṣíṣe Ìdájọ́

37 “Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́bi. Ẹ máa dáríjì eniyan, Ọlọrun yóo sì dáríjì yín.

38 Ẹ máa fún eniyan lẹ́bùn, Ọlọrun yóo sì fun yín ní ẹ̀bùn. Òṣùnwọ̀n rere, tí a kì tí ó kún, tí a mì dáradára, tí ó kún tí ó ń ṣàn sílẹ̀ ni a óo fi wọ̀n ọ́n le yín lọ́wọ́. Nítorí òṣùnwọ̀n tí ẹ bá lò fún ẹlòmíràn ni a óo lò fun yín.”

39 Jesu wá tún pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Afọ́jú kò lè fi ọ̀nà han afọ́jú. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú kòtò ni àwọn mejeeji yóo bá ara wọn.

40 Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Ṣugbọn bí ọmọ-ẹ̀yìn bá jáfáfá yóo dàbí olùkọ́ rẹ̀.

41 “Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi ńlá tí ó wà lójú ìwọ alára?

42 Báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Ọ̀rẹ́, jẹ́ kí n bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí o kò rí ìtì igi tí ó wà lójú ara rẹ? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi kúrò lójú ara rẹ, nígbà náà, ìwọ óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.

Igi ati Èso Rẹ̀

43 “Igi rere kò lè so èso burúkú. Bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lé so èso rere.

44 Èso tí igi kan bá so ni a óo fi mọ̀ ọ́n. Nítorí eniyan kò lè ká èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹlẹ́gùn-ún. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò lè rí èso ọsàn lórí igi ọdán.

45 Eniyan rere ń mú ohun rere wá láti inú orísun rere ọkàn rẹ̀. Eniyan burúkú ń mú nǹkan burúkú jáde láti inú ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí ohun tí ó bá wà ninu ọkàn ẹni ni ẹnu ẹni ń sọ jáde.

Ìpìlẹ̀ Meji

46 “Kí ló dé tí ẹ̀ ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa,’ tí ẹ kì í ṣe ohun tí mo sọ?

47 Ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó ń ṣe é, n óo sọ fun yín ẹni tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jọ.

48 Ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé, tí ó wa ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí ó jìn, tí ó wá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé orí àpáta. Nígbà tí ìkún omi dé, tí àgbàrá bì lu ilé náà, kò lè mì ín, nítorí wọ́n kọ́ ọ dáradára.

49 Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò ṣe é, ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé kalẹ̀ láì ní ìpìlẹ̀. Nígbà tí àgbàrá bì lù ú, lẹsẹkẹsẹ ni ó wó, ó sì wó kanlẹ̀ patapata.”

Categories
LUKU

LUKU 7

Jesu Wo Iranṣẹ Ọ̀gágun Kan Sàn

1 Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ.

2 Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un.

3 Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn.

4 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tètè. Wọ́n ní, “Ọ̀gágun náà yẹ ní ẹni tí o lè ṣe èyí fún,

5 nítorí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, òun fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ ilé ìpàdé fún wa.”

6 Jesu bá ń bá wọn lọ. Ṣugbọn nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn sí ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí Jesu kí wọ́n sọ pé, “Alàgbà, má ṣe ìyọnu. Èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ ilé rẹ̀.

7 Òun ni kò jẹ́ kí èmi fúnra mi wá sọ́dọ̀ rẹ. Ṣugbọn sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá.

8 Nítorí èmi náà jẹ́ ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ. Mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ Yóo lọ ni. Bí mo bá sì sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ Yóo wá ni. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ Yóo ṣe é ni.”

9 Nígbà tí Jesu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹnu yà á. Ó bá yipada sí àwọn eniyan tí ó ń tẹ̀lé e, ó ní, “Mò ń sọ fun yín, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!”

10 Nígbà tí àwọn tí ọ̀gágun rán pada dé ilé, wọ́n rí ẹrú náà tí ara rẹ̀ ti dá.

Jesu Jí Ọmọ Opó Kan Dìde Ní Naini

11 Láìpẹ́ lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Naini. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ eniyan ń bá a lọ.

12 Nígbà tí wọ́n súnmọ́ ẹnu odi ìlú náà, wọ́n rí òkú ọmọ kan tí wọn ń gbé jáde. Ọmọ yìí nìkan náà ni ìyá rẹ̀ bí. Opó sì ni ìyá náà. Ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti inú ìlú wá pẹlu obinrin náà.

13 Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.”

14 Ni ó bá lọ, ó fi ọwọ́ kan pósí. Àwọn tí wọ́n gbé pósí bá dúró. Ó bá sọ pé, “Ọdọmọkunrin, mo sọ fún ọ, dìde.”

15 Ọdọmọkunrin tí ó ti kú yìí bá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Jesu bà fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.

16 Ẹ̀rù ba gbogbo eniyan, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun, wọ́n ní, “Wolii ńlá ti dìde ni ààrin wa. Ọlọrun ti bojúwo àwọn eniyan rẹ̀.”

17 Ìròyìn ohun tí ó ṣe yìí tàn ká gbogbo Judia ati gbogbo agbègbè ibẹ̀.

Johanu Ranṣẹ Sí Jesu

18 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ròyìn gbogbo nǹkan wọnyi fún un. Johanu bá pe meji ninu wọn,

19 ó rán wọn sí Oluwa láti bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”

20 Nígbà tí àwọn ọkunrin náà dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n ní, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó rán wa sí ọ láti bi ọ́ pé, ‘Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?’ ”

21 Ní àkókò náà, Jesu ń wo ọpọlọpọ eniyan sàn ninu àìsàn ati àrùn. Ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọpọlọpọ àwọn afọ́jú ni ó jẹ́ kí wọ́n ríran.

22 Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ sọ ohun tí ẹ rí ati ohun tí ẹ gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran; àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́; àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde; à ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka.

23 Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!”

24 Lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ Johanu lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ nípa Johanu fún àwọn eniyan. Ó ní, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Igi légbélégbé tí afẹ́fẹ́ ń tì sọ́tùn-ún, ati sósì ni bí?

25 Kí ni ẹ jáde lọ wò? Ọkunrin tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye ni bí? Bí ẹ bá fẹ́ rí àwọn tí ó wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba.

26 Àní, kí ni ẹ lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ!

27 Òun ni a kọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ, òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’

28 Mo sọ fun yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni jákèjádò ayé yìí tí ó ṣe pataki ju Johanu lọ. Sibẹ, ẹni tí ó kéré jùlọ ninu ìjọba ọ̀run ṣe pataki jù ú lọ.”

29 Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan gbọ́, tí ó fi mọ́ àwọn agbowó-odè pàápàá, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun, wọ́n lọ ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ètò ìrìbọmi Johanu.

30 Ṣugbọn àwọn Farisi ati àwọn amòfin kọ ìlànà Ọlọrun fún wọn, wọn kò ṣe ìrìbọmi ti Johanu.

31 Jesu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ta ni èmi ìbá fi àwọn eniyan òde òní wé? Ta ni kí a wí pé wọ́n jọ?

32 Wọ́n jọ àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà. Àwọn kan ń pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé, ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, A sun rárà òkú fun yín, ẹ kò sunkún.’

33 Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi dé, kò jẹ, kò mu, ẹ sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù ni.’

34 Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu, ẹ ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’

35 Sibẹ a mọ̀ pé ọgbọ́n Ọlọrun tọ̀nà nípa ìṣesí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.”

Jesu Dárí Ji Obinrin Ẹlẹ́ṣẹ̀ Kan

36 Ọ̀kan ninu àwọn Farisi pe Jesu pé kí ó wá bá òun jẹun. Jesu bà lọ sí ilé Farisi yìí lọ jẹun.

37 Obinrin kan báyìí wà ninu ìlú tí ó gbọ́ pé Jesu ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ìgò òróró olóòórùn dídùn lọ́wọ́,

38 ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀.

39 Nígbà tí Farisi tí ó pe Jesu wá jẹun rí i, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìbá jẹ́ pé wolii ni ọkunrin yìí, ìbá ti mọ irú ẹni tí obinrin yìí tí ó ń fọwọ́ kàn án jẹ́, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

40 Jesu sọ fún un pé, “Simoni, mo fẹ́ bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ kan.”

Simoni ní, “Olùkọ́ni, máa wí.”

41 Jesu ní, “Àwọn meji kan jẹ gbèsè. Wọ́n yá owó lọ́wọ́ ẹnìkan tí í máa ń yá eniyan lówó pẹlu èlé. Ọ̀kan jẹ ẹ́ ní àpò marun-un owó fadaka, ekeji jẹ ẹ́ ní aadọta owó fadaka.

42 Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà ati san gbèsè wọn, ẹni tí ó yá wọn lówó bùn wọ́n ní owó náà. Ninu àwọn mejeeji, ta ni yóo fẹ́ràn rẹ̀ jù?”

43 Simoni dáhùn pé, “Ẹni tí ó fún ni owó pupọ ni.”

Jesu wá sọ fún un pé, “O wí ire.”

44 Jesu bá yipada sí obinrin náà, ó sọ fún Simoni pé, “Ṣé o rí obinrin yìí? Mo wọ ilé rẹ, o kò fún mi ní omi kí n fi fọ ẹsẹ̀. Ṣugbọn obinrin yìí fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún.

45 O kò fi ìfẹnukonu kí mi. Ṣugbọn obinrin yìí kò dẹ́kun láti fi ẹnu kan ẹsẹ̀ mi láti ìgbà tí mo ti wọ ilé.

46 O kò fi òróró kùn mí lórí. Ṣugbọn obinrin yìí fi òróró olóòórùn dídùn kùn mí lẹ́sẹ̀.

47 Nítorí èyí, mo sọ fún ọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í, nítorí ó ní ìfẹ́ pupọ. Ṣugbọn ẹni tí a bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀ jì, ìfẹ́ díẹ̀ ni yóo ní.”

48 Ó bá sọ fún obinrin náà pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

49 Àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun bà bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Ta ni eléyìí tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan?”

50 Jesu bá sọ fún obinrin náà pé, “Igbagbọ rẹ ti gbà ọ́ là. Máa lọ ní alaafia.”

Categories
LUKU

LUKU 8

Àwọn Obinrin Tí Wọn Ń Ran Jesu Lọ́wọ́

1 Lẹ́yìn èyí, Jesu ń rìn káàkiri láti ìlú dé ìlú, ati láti abúlé dé abúlé. Ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ń bá a kiri.

2 Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obinrin kan tí Jesu ti wòsàn kúrò ninu ẹ̀mí èṣù ati àìlera ń bá a kiri. Ninu wọn ni Maria tí à ń pè ní Magidaleni wà, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje jáde ninu rẹ̀,

3 ati Joana iyawo Kusa, ọmọ-ọ̀dọ̀ Hẹrọdu, ati Susana ati ọpọlọpọ àwọn mìíràn. Àwọn yìí ni wọ́n ń fi ohun ìní wọn bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ bùkátà wọn.

Òwe Afunrugbin

4 Ọpọlọpọ eniyan ń wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn láti ìlú dé ìlú. Ó wá fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé:

5 “Afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, irúgbìn díẹ̀ bọ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.

6 Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí àpáta. Nígbà tí ó hù, ó bá gbẹ nítorí kò sí omi.

7 Irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin ẹ̀gún. Nígbà tí òun ati ẹ̀gún jọ dàgbà, ń ṣe ni ẹ̀gún fún un pa.

8 Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ dáradára, ó dàgbà, ó sì so èso. Irúgbìn kọ̀ọ̀kan so ọgọọgọrun-un.”

Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó wá tún sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

Ìdí Tí Jesu Fi Ń Lo Òwe

9 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí.

10 Ó ní, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ àṣírí ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn fún àwọn yòókù, bí òwe bí òwe ni, pé wọn yóo máa wo nǹkan ṣugbọn wọn kò ní mọ ohun tí wọn rí, wọn yóo máa gbọ́ràn ṣugbọn òye ohun tí wọn gbọ́ kò ní yé wọn.

Jesu Ṣe Àlàyé Òwe Nípa Afunrugbin

11 “Ìtumọ̀ òwe yìí nìyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

12 Àwọn tí ó bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà ni àwọn tí wọ́n gbọ́, lẹ́yìn náà èṣù wá, ó mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má baà gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.

13 Àwọn tí ó bọ́ sórí òkúta ni àwọn tí ó gbọ́, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò ní gbòǹgbò. Wọ́n gbàgbọ́ fún àkókò díẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ìdánwò dé, wọ́n bọ́hùn.

14 Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́, ṣugbọn àkólékàn ayé, ìlépa ọrọ̀, ati ìgbádùn ayé fún ọ̀rọ̀ náà pa, wọn kò lè dàgbà láti so èso.

15 Àwọn ti ilẹ̀ dáradára ni àwọn tí ó fi ọkàn rere ati ọkàn mímọ́ gba ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso nípa ìfaradà.

Fìtílà Tí A Bò Mọ́lẹ̀

16 “Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ tan fìtílà tán, kí ó fi àwo bò ó mọ́lẹ̀, tabi kí ó gbé e sábẹ́ ibùsùn. Orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà, kí gbogbo ẹni tí ó bá ń wọlé lè ríran.

17 “Nítorí kò sí ohun kan tí ó pamọ́ tí kò ní fara hàn, kò sì sí nǹkan bòńkẹ́lẹ́ kan tí eniyan kò ní mọ̀.

18 “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra nípa bí ẹ ti ṣe ń gbọ́ràn, nítorí ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i, ṣugbọn lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní ni a óo ti gba ìwọ̀nba tí ó rò pé òun ní.”

Ìyá ati Àwọn Arakunrin Jesu

19 Ìyá Jesu ati àwọn arakunrin rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè dé ibi tí ó wà nítorí ọ̀pọ̀ eniyan.

20 Àwọn eniyan bá sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ fi ojú kàn ọ́.”

21 Ṣugbọn Jesu wí fún gbogbo wọn pé, “Ìyá mi ati àwọn arakunrin mi ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń ṣe é.”

Jesu Mú Kí Ìgbì Dákẹ́ Rọ́rọ́

22 Ní ọjọ́ kan Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọjá lọ sí òdìkejì òkun.” Ni wọ́n bá lọ.

23 Bí wọ́n ti ń wakọ̀ lọ, Jesu bá sùn lọ. Ìjì líle kan bá bẹ̀rẹ̀ lójú òkun, omi bẹ̀rẹ̀ sí ya wọ inú ọkọ̀; ẹ̀mí wọn sì wà ninu ewu.

24 Ni wọ́n bá lọ jí Jesu, wọ́n ní, “Ọ̀gá! Ọ̀gá! Ọkọ̀ mà ń rì lọ!”

Ni Jesu bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi wí, ni ìgbì bá rọlẹ̀, gbogbo nǹkan bá dákẹ́ jẹ́.

25 Ó bá bi wọ́n pé, “Igbagbọ yín dà?”

Pẹlu ìbẹ̀rù ati ìyanu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ pé, “Ta nì yìí? Ó pàṣẹ fún afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi, wọ́n sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu!”

Jesu Wo Wèrè Ará Geraseni Sàn

26 Wọ́n gúnlẹ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Gerasenití ó wà ní òdì keji òkun tí ó dojú kọ ilẹ̀ Galili.

27 Bí ó ti bọ́ sí èbúté, ọkunrin kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú ìlú wá pàdé rẹ̀. Ó ti pẹ́ tí ó ti fi aṣọ kanra gbẹ̀yìn, kò sì lè gbé inú ilé mọ́, àfi ní itẹ́ òkú.

28 Nígbà tí ó rí Jesu, ó kígbe, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó kébòòsí pé, “Kí ni ó pa èmi ati ìwọ pọ̀, Jesu, ọmọ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo? Mo bẹ̀ ọ́ má dá mi lóró!”

29 Nítorí Jesu ti pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò ninu ọkunrin yìí. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ní í máa ń dé sí i. Wọn á fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́, wọn á tún kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Ṣugbọn jíjá ni yóo já ohun tí wọ́n fi dè é, ni yóo bá sálọ sinu aṣálẹ̀.

30 Jesu bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”

Ó ní, “Ẹgbaagbeje,” Nítorí àwọn ẹ̀mí èṣù tí ó ti wọ inú rẹ̀ pọ̀.

31 Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá bẹ Jesu pé kí ó má lé àwọn lọ sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.

32 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ lórí òkè. Àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí àwọn kó sí inú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà. Ó bá gbà fún wọn.

33 Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá jáde kúrò ninu ọkunrin tí à ń wí yìí, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, ni agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí inú òkun, wọ́n bá rì sómi.

34 Nígbà tí àwọn tí ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ ròyìn ní ìlú ati ní ìgbèríko.

35 Àwọn eniyan bà jáde láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀, tí ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, ojú rẹ̀ sì wálẹ̀. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan.

36 Àwọn tí ó mọ̀ bí ara ọkunrin náà ti ṣe dá ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn.

37 Gbogbo àwọn eniyan agbègbè Geraseni bá bẹ Jesu pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Ó bá tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó pada sí ibi tí ó ti wá.

38 Ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀ bẹ Jesu pé kí ó jẹ́ kí òun máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó ní,

39 “Pada lọ sí ilé rẹ, kí o lọ ròyìn ohun tí Ọlọrun ṣe fún ọ.”

Ni ọkunrin náà bá ń káàkiri gbogbo ìlú, ó ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un.

Ìtàn Ọmọbinrin Jairu ati Ti Obinrin Tí Ó Fọwọ́ Kan Aṣọ Jesu

40 Nígbà tí Jesu pada dé, àwọn eniyan fi tayọ̀tayọ̀ gbà á, nítorí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.

41 Ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Jairu, tí ó jẹ́ alákòóso ilé ìpàdé, wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá òun kálọ sí ilé,

42 nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila.

Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún.

43 Obinrin kan wà tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀, tí kò dá fún ọdún mejila. Ó ti ná gbogbo ohun tí ó ní fún àwọn oníṣègùn ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè wò ó sàn.

44 Ó bá gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, lẹsẹkẹsẹ ìsun ẹ̀jẹ̀ náà bá dá lára rẹ̀.

45 Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?”

Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?”

46 Ṣugbọn Jesu tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Ẹnìkan fọwọ́ kàn mí sẹ́ẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé agbára ti ara mi jáde.”

47 Nígbà tí obinrin náà rí i pé kò ṣe é fi pamọ́, ó bá jáde, ó ń gbọ̀n. Ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó bá sọ ìdí tí òun ṣe fọwọ́ kàn án lójú gbogbo eniyan ati bí òun ṣe rí ìwòsàn lẹsẹkẹsẹ.

48 Jesu wá wí fún un pé, “Ọmọbinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá, máa lọ ní alaafia.”

49 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀, àwọn kan wá láti ọ̀dọ̀ alákòóso ilé ìpàdé, wọ́n ní, “Ọdọmọdebinrin rẹ ti kú. Má wulẹ̀ yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.”

50 Ṣugbọn nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn pé, “Má bẹ̀rù, ṣá gbàgbọ́, ara ọmọ rẹ yóo dá.”

51 Nígbà tí Jesu dé ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé àfi Peteru, Johanu ati Jakọbu, baba ati ìyá ọmọ náà.

52 Gbogbo àwọn eniyan ń sunkún, wọ́n ń dárò nítorí ọmọ náà. Ṣugbọn Jesu ní, “Ẹ má sunkún mọ́, nítorí ọmọ náà kò kú, ó ń sùn ni.”

53 Ńṣe ni wọ́n ń fi Jesu rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú.

54 Jesu fa ọmọ náà lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ọmọ, dìde.”

55 Ẹ̀mí rẹ̀ bá pada sinu rẹ̀, ni ó bá dìde lẹsẹkẹsẹ. Jesu bá sọ fún wọn pé kí wọn fún un ní oúnjẹ.

56 Ẹnu ya àwọn òbí ọmọ náà. Ṣugbọn ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún ẹnikẹ́ni.

Categories
LUKU

LUKU 9

Iṣẹ́ Tí Jesu Fi Rán Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Mejila

1 Jesu pe àwọn mejila jọ. Ó fún wọn ní agbára ati àṣẹ láti lé gbogbo ẹ̀mí èṣù jáde ati láti ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àìsàn.

2 Ó rán wọn láti waasu ìjọba Ọlọrun ati láti ṣe ìwòsàn.

3 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkankan lọ́wọ́ lọ ìrìn àjò yìí: ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́, tabi àpò báárà tabi oúnjẹ tabi owó, tabi àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji.

4 Ilé tí ẹ bá wọ̀ sí, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà.

5 Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, nígbà tí ẹ bá jáde kúrò ninu ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí wọn.”

6 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá ń lọ láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń waasu ìyìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo.

Hẹrọdu Dààmú

7 Nígbà tó yá, Hẹrọdu, baálẹ̀, gbọ́ nípa gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó dààmú; nítorí àwọn kan ń sọ pé Johanu ni ó jí dìde kúrò ninu òkú.

8 Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé Elija ni ó fara hàn. Àwọn mìíràn ní ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó tún pada.

9 Ṣugbọn Hẹrọdu ní “Ní ti Johanu, mo ti bẹ́ ẹ lórí. Ta wá ni òun, tí mò ń gbọ́ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀?” Hẹrọdu bá ń wá ọ̀nà láti fojú kàn án.

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

10 Àwọn aposteli tí Jesu rán níṣẹ́ pada wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe fún un. Ó bá rọra dá àwọn nìkan mú lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Bẹtisaida.

11 Ṣugbọn àwọn eniyan mọ̀, ni wọ́n bá tẹ̀lé e. Ó gbà wọ́n pẹlu ayọ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo àwọn aláìsàn sàn.

12 Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sọ fún un pé, “Tú àwọn eniyan wọnyi ká kí wọ́n lè lọ sí àwọn abúlé káàkiri ati àwọn ìletò láti wọ̀ sí ati láti wá oúnjẹ, nítorí aṣálẹ̀ ni ibi tí a wà yìí.”

13 Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”

Wọ́n dáhùn pé, “A kò ní oúnjẹ pupọ, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji, ṣé kí àwa fúnra wa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn eniyan wọnyi ni?”

14 (Àwọn ọkunrin ninu wọn tó bíi ẹgbẹẹdọgbọn (5,000).)

Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí wọ́n jókòó ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí araadọta.”

15 Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí: wọ́n fi gbogbo wọn jókòó.

16 Jesu bá mú burẹdi marun-un yìí ati ẹja meji, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó gbadura sí i, ó pín wọn sí wẹ́wẹ́, ó bá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fún àwọn eniyan.

17 Gbogbo àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n kó àjẹkù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila.

Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Jesu Í Ṣe

18 Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Jesu nìkan ń dá gbadura tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé mo jẹ́?”

19 Wọ́n dáhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni ọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn ní, Elija ni ọ. Àwọn mìíràn tún sọ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó jí dìde.”

20 Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?”

Peteru dáhùn pé, “Mesaya Ọlọrun ni ọ́.”

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀

21 Jesu wá kìlọ̀ fún wọn kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni.

22 Ó ní, “Dandan ni kí Ọmọ-Eniyan jìyà pupọ, kí àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin kọ̀ ọ́, kí wọ́n sì pa á, ṣugbọn a óo jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”

23 Ó bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀lé mí, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀ lojoojumọ, kí ó wá máa tọ̀ mí lẹ́yìn.

24 Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, òun ni yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

25 Nítorí anfaani wo ni ó jẹ́ fún ẹnikẹ́ni, bí ó bá jèrè gbogbo ayé, ṣugbọn tí ó pàdánù ẹ̀mí ara rẹ̀?

26 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi ati àwọn ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ-Eniyan yóo tijú nígbà tí ó bá dé ninu ògo rẹ̀ ati ògo Baba rẹ̀, pẹlu àwọn angẹli mímọ́.

27 Ṣugbọn mo sọ fun yín dájúdájú, àwọn mìíràn wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun.”

Jesu Paradà Lórí Òkè

28 Ó tó bí ọjọ́ mẹjọ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, Jesu mú Peteru, Johanu ati Jakọbu lọ sí orí òkè kan láti gbadura.

29 Bí ó ti ń gbadura, ìwò ojú rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ wá funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

30 Àwọn ọkunrin meji kan yọ lójijì, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀. Àwọn ni Mose ati Elija.

31 Wọ́n farahàn ninu ògo, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ nípa irú ikú tí yóo kú láìpẹ́, ní Jerusalẹmu.

32 Ṣugbọn oorun ti ń kun Peteru ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n tají, wọ́n rí ògo rẹ̀ ati àwọn ọkunrin meji tí wọ́n dúró tì í.

33 Bí àwọn meji yìí ti ń kúrò lọ́dọ̀ Jesu, Peteru sọ fún un pé, “Ọ̀gá, ìbá dára tí a bá lè máa wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pa àgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, ati ọ̀kan fún Elija.” Ó sọ èyí nítorí kò mọ ohun tíì bá sọ.

34 Bí ó ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, ìkùukùu bá ṣíji bò wọ́n. Ẹ̀rù ba Peteru ati Johanu ati Jakọbu nígbà tí Mose ati Elija wọ inú ìkùukùu náà.

35 Ohùn kan ti inú ìkùukùu náà wá, ó ní “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”

36 Bí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, Jesu nìkan ni wọ́n rí. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá pa ẹnu mọ̀, wọn kò sọ ohun tí wọ́n gbọ́ ati ohun tí wọ́n rí ní àkókò náà fún ẹnikẹ́ni.

Jesu Wo Ọmọ tí Ó ní Wárápá Sàn

37 Ní ọjọ́ keji, lẹ́yìn tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ eniyan wá pàdé rẹ̀.

38 Ọkunrin kan ninu àwùjọ kígbe pé, “Olùkọ́ni, mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú ọmọ mi, nítorí òun nìkan ni mo bí.

39 Ẹ̀mí kan a máa gbé e. Lójijì yóo kígbe tòò, ara rẹ̀ óo le gbandi. Yóo bá máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, ni ẹ̀mí yìí yóo bá gbé e ṣánlẹ̀; kò sì ní tètè fi í sílẹ̀.

40 Mo bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọ́n lé e jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”

41 Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran oníbàjẹ́ ati alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó! N óo ti fara dà á fun yín tó! Mú ọmọ rẹ wá síhìn-ín.”

42 Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.

43 Ẹnu ya gbogbo eniyan sí iṣẹ́ ńlá Ọlọrun.

Jesu Tún Sọtẹ́lẹ̀ Nípa Ikú Rẹ̀

Bí ẹnu ti ń ya gbogbo eniyan sí gbogbo ohun tí Jesu ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

44 “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi wọ̀ yín létí. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò tí a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́.”

45 Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí.

Ta Ni Ẹni Tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ?

46 Àríyànjiyàn kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lórí pé ta ló ṣe pataki jùlọ láàrin wọn.

47 Jesu mọ ohun tí wọn ń rò lọ́kàn. Ó bá mú ọmọde kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

48 Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.”

Ẹni Tí Kò Bá Lòdì sí Yín, Tiyín ni

49 Johanu sọ fún un pé, “Ọ̀gá, a rí ẹnìkan tí ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. A fẹ́ dá a lẹ́kun nítorí kì í ṣe ara wa.”

50 Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé. “Ẹ má dá a lẹ́kun, nítorí ẹni tí kò bá lòdì si yín, tiyín ní ń ṣe.”

Àwọn Ará Abúlé Samaria Kan Kọ Jesu

51 Nígbà tí ó tó àkókò tí a óo gbé Jesu lọ sókè ọ̀run, ọkàn rẹ̀ mú un láti lọ sí Jerusalẹmu.

52 Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é.

53 Ṣugbọn wọn kò gbà á, nítorí ó hàn dájú pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu.

54 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé o fẹ́ kí á pe iná láti ọ̀run kí ó jó wọn pa?”

55 Ṣugbọn Jesu yipada, ó bá wọn wí.

56 Ni wọ́n bá lọ sí ìletò mìíràn.

Àwọn Tí Ó Fẹ́ Tẹ̀lé Jesu

57 Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “N óo máa bá ọ lọ sí ibikíbi tí o bá ń lọ.”

58 Jesu dá a lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”

59 Ó bá sọ fún ẹlòmíràn pé, “Máa tẹ̀lé mi.”

Ṣugbọn onítọ̀hún dáhùn pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”

60 Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn. Ìwọ ní tìrẹ, wá máa waasu ìjọba Ọlọrun.”

61 Ẹlòmíràn tún sọ fún un pé, “N óo tẹ̀lé ọ Oluwa. Ṣugbọn jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”

62 Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Kò sí ẹni tí ó bá ti dá ọwọ́ lé lílo ẹ̀rọ-ìroko, tí ó bá tún ń wo ẹ̀yìn tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọrun.”