Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 20

Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn

1 OLUWA sọ fún Mose

2 pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn ati àwọn àlejò, tí wọn ń ṣe àtìpó ní ààrin wọn tí ó bá fi èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, pípa ni kí wọ́n pa á; kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.

3 Èmi gan-an yóo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó ti fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, ó sì ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ó ti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.

4 Bí àwọn eniyan tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà bá mójú fo ẹni tí ó bá fi ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, tí wọn kò pa á,

5 nígbà náà ni èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, n óo sì yọ wọ́n kúrò lára àwọn eniyan wọn, ati òun, ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n jọ ń bọ oriṣa Moleki.

6 “Bí ẹnìkan bá ń lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, tabi àwọn oṣó, tí ó sì ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, n óo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

7 Nítorí náà, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé, èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

8 Ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn ìlànà mi, kí ẹ sì máa tẹ̀lé wọn. Èmi ni OLUWA tí ó sọ yín di mímọ́.

9 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa á. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀ nítorí pé ó ṣépè lé baba tabi ìyá rẹ̀.

10 “Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa olúwarẹ̀ ati obinrin tí ó bá lòpọ̀.

11 Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, ó dójúti baba rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

12 Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya ọmọ rẹ̀ lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa àwọn mejeeji; wọ́n ti hùwà ìbàjẹ́ láàrin ẹbí, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

13 Bí ọkunrin kan bá bá ọkunrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lòpọ̀ bí a ti ń bá obinrin lòpọ̀, àwọn mejeeji ti ṣe ohun ìríra; pípa ni kí wọ́n pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

14 Bí ẹnìkan bá fẹ́ iyawo, tí ó sì tún fẹ́ ìyá iyawo náà pẹlu, ìwà burúkú ni; sísun ni kí wọ́n sun wọ́n níná, ati ọkunrin ati àwọn obinrin mejeeji, kí ìwà burúkú má baà wà láàrin yín.

15 Bí ọkunrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà.

16 Bí obinrin bá tọ ẹranko lọ, tí ó sì tẹ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún un láti bá a lòpọ̀, pípa ni kí ẹ pa òun ati ẹranko náà, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo wà lórí ara wọn.

17 “Bí ọkunrin kan bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ baba rẹ̀ tabi ọmọ ìyá rẹ̀, tí wọ́n sì rí ìhòòhò ara wọn, ohun ìtìjú ni; lílé ni kí wọ́n lé wọn jáde kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn, nítorí pé ó ti bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀. Orí rẹ̀ ni yóo sì fi ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

18 Bí ọkunrin kan bá bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí obinrin yìí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, lílé ni kí wọ́n lé àwọn mejeeji kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn.

19 “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ, tabi arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ìwà ìbàjẹ́ ni láàrin ẹbí. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

20 Bí ẹnìkan bá bá aya arakunrin baba rẹ̀ lòpọ̀, ohun ìtìjú ni ó ṣe sí arakunrin baba rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóo kú láì bímọ.

21 Bí ọkunrin kan bá bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀, tabi aya àbúrò rẹ̀, ohun àìmọ́ ni, ohun ìtìjú ni ó sì ṣe sí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ̀, àwọn mejeeji yóo kú láì bímọ.

22 “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ kíyèsí gbogbo àwọn ìlànà mi ati àwọn òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ tí mò ń ko yín lọ má baà tì yín jáde.

23 Ẹ kò sì gbọdọ̀ kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo lé jáde fun yín, nítorí pé tìtorí gbogbo ohun tí wọn ń ṣe wọnyi ni mo fi kórìíra wọn.

24 Ṣugbọn mo ti ṣèlérí fun yín pé, ẹ̀yin ni ẹ ó jogún ilẹ̀ wọn, n óo fi ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, tí ó sì ń ṣàn fún wàrà ati oyin fun yín, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo eniyan.

25 Nítorí náà, ẹ níláti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn ẹran tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́; ati láàrin àwọn ẹyẹ tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹyẹ tabi ẹranko kankan tabi àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri lórí ilẹ̀, tí mo ti yà sọ́tọ̀ fun yín pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́.

26 Ẹ níláti jẹ́ mímọ́ fún mi, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA, mo sì ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn eniyan kí ẹ lè máa jẹ́ tèmi.

27 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tabi oṣó, pípa ni kí ẹ pa á; ẹ sọ wọ́n ní òkúta pa ni, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì wà lórí ara wọn.”

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 21

Àwọn Alufaa Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́

1 OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí ikú àwọn eniyan rẹ̀.

2 Àfi ti àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ wọn, bíi ìyá tabi baba rẹ̀; tabi ọmọ tabi arakunrin rẹ̀,

3 tabi ti arabinrin rẹ̀ tí kò tíì mọ ọkunrin, (tí ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí pé kò tíì ní ọkọ, nítorí tirẹ̀, alufaa náà lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́).

4 Kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́, nítorí olórí ló jẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

5 “Alufaa kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ débi pé kí ó fá irun rẹ̀, tabi kí ó gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n rẹ̀ tabi kí ó fi abẹ ya ara rẹ̀.

6 Wọ́n níláti jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun wọn, wọn kò sì gbọdọ̀ sọ orúkọ Ọlọrun wọn di aláìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA; èyí tíí ṣe oúnjẹ Ọlọrun wọn, nítorí náà wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.

7 Nítorí pé alufaa jẹ́ ẹni mímọ́ fún Ọlọrun rẹ̀, kò gbọdọ̀ gbé aṣẹ́wó ní iyawo, tabi obinrin tí ó ti di aláìmọ́, tabi obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.

8 Ẹ gbọdọ̀ ka alufaa sí ẹni mímọ́, nítorí òun ni ó ń rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun yín. Ó níláti jẹ́ ẹni mímọ́ fun yín, nítorí pé èmi OLUWA tí mo yà yín sí mímọ́ jẹ́ mímọ́.

9 Ọmọ alufaa lobinrin, tí ó bá sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa ṣíṣe àgbèrè káàkiri, sọ baba rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí náà sísun ni kí ẹ dáná sun ọmọ náà.

10 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ alufaa àgbà láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n ti ta òróró sí lórí láti yà á sọ́tọ̀, kí ó lè máa wọ àwọn aṣọ mímọ́, kò gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ rí játijàti; kò sì gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya, láti fi hàn pé ó ń ṣọ̀fọ̀.

11 Kò gbọdọ̀ lọ sí ibi tí wọ́n bá tẹ́ òkú sí, tabi kí ó sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú baba rẹ̀ tabi ti ìyá rẹ̀.

12 Kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ninu ibi mímọ́ náà, tabi kí ó sọ ibi mímọ́ Ọlọrun rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí pé, òróró ìyàsímímọ́ Ọlọrun rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Èmi ni OLUWA.

13 Obinrin tí kò bá tíì mọ ọkunrin rí ni ó gbọdọ̀ fẹ́ níyàwó.

14 Kò gbọdọ̀ fi opó ṣe aya tabi obinrin tí ó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, tabi obinrin tí ó ti mọ ọkunrin, tabi aṣẹ́wó; kò gbọdọ̀ fẹ́ èyíkéyìí ninu wọn. Obinrin tí kò tíì mọ ọkunrin rí ni kí ó fẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

15 Kí ó má baà sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìmọ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé èmi ni OLUWA, tí mo sọ ọ́ di mímọ́.”

16 OLUWA sọ fún Mose,

17 kí ó sọ fún Aaroni pé, “Èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ rẹ̀ tí ó bá ní àbùkù kankan kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun rẹ̀.

18 Nítorí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ, kì báà jẹ́ afọ́jú, tabi arọ, ẹni tí ijamba bá bà lójú jẹ́, tabi tí apá tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn ju ekeji lọ,

19 tabi tí ijamba bá ṣe ní ọwọ́ kan tabi ẹsẹ̀ kan,

20 tabi abuké, aràrá, tabi ẹni tí kò ríran dáradára, tabi ẹni tí ó ní àrùn ẹ̀yi tabi ìpẹ́pẹ́, tabi ẹni tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà.

21 Èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ Aaroni, alufaa tí ó bá ti ní àbùkù kan lára kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ sísun sí èmi OLUWA, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ṣì ní àbùkù lára, kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun rẹ̀.

22 Ó lè jẹ ohun jíjẹ ti Ọlọrun rẹ̀, kì báà ṣe ninu èyí tí ó mọ́ jùlọ tabi ninu àwọn ohun tí ó mọ́.

23 Ṣugbọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibi aṣọ ìbòjú náà tabi kí ó wá sí ibi pẹpẹ, nítorí pé ó ní àbùkù, kí ó má baà sọ àwọn ibi mímọ́ mi di aláìmọ́; èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”

24 Mose sì sọ gbogbo nǹkan tí OLUWA rán an fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 22

Àwọn Ohun Ìrúbọ Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́

1 OLUWA rán Mose pé,

2 “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ pé, kí wọ́n máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo àwọn nǹkan mímọ́ tí àwọn eniyan Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLUWA.

3 Bí èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ wọn bá súnmọ́ àwọn nǹkan mímọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí àwọn eniyan Israẹli ti yà sí mímọ́ fún OLUWA; nígbà tí ó wà ní ipò àìmọ́, a óo mú ẹni náà kúrò lọ́dọ̀ mi. Èmi ni OLUWA.

4 “Ẹnikẹ́ni ninu ìran Aaroni tí ó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí ara rẹ̀ bá ń tú, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà, títí tí yóo fi di mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ pé ó fara kan òkú ni, tabi pé ó fara kan ẹni tí nǹkan ọkunrin jáde lára rẹ̀,

5 tabi ẹni tí ó bá fara kan èyíkéyìí ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri, èyí tí ó lè sọ eniyan di aláìmọ́, tabi ẹnikẹ́ni tí ó lè kó àìmọ́ bá eniyan, ohun yòówù tí àìmọ́ rẹ̀ lè jẹ́.

6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tabi irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; kò sì ní jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà títí tí yóo fi wẹ̀.

7 Nígbà tí oòrùn bá wọ̀, yóo di mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà nítorí oúnjẹ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́.

8 Alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó bá kú fúnrara rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú bá pa; kí ó má baà fi òkú ẹran yìí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA.

9 “Àwọn alufaa gbọdọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀ nítorí rẹ̀, kí wọ́n sì kú nítorí àwọn òfin mi tí wọ́n bá rú. Èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.

10 “Àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni àlejò tabi alágbàṣe tí ń gbé ilé alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu wọn.

11 Ṣugbọn bí alufaa bá fi owó ra ẹrú fún ara rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà. Àwọn ọmọ tí ẹrú náà bá sì bí ninu ilé alufaa náà lè jẹ ninu oúnjẹ náà pẹlu.

12 Bí ọmọbinrin alufaa kan bá fẹ́ àjèjì, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n bá fi rúbọ.

13 Ṣugbọn bí ọmọbinrin alufaa kan bá jẹ́ opó, tabi tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láì bímọ fún un, tí ó bá pada sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó wà ní ọdọmọbinrin, ó lè jẹ ninu oúnjẹ baba rẹ̀; sibẹsibẹ àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀.

14 “Bí ẹnìkan bá jẹ ohun mímọ́ kan ní ìjẹkújẹ yóo san án pada fún alufaa pẹlu ìdámárùn-ún rẹ̀.

15 Àwọn alufaa kò gbọdọ̀ sọ àwọn ohun mímọ́ àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n fi ń rúbọ sí OLUWA di aláìmọ́.

16 Kí wọ́n má baà mú àwọn eniyan náà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kó ẹ̀bi rù wọ́n nípa jíjẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; nítorí èmi ni OLUWA tí mo sọ wọ́n di mímọ́.”

17 OLUWA tún rán Mose pé

18 kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé: “Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn eniyan Israẹli tabi àlejò tí ó wà láàrin wọn bá mú ohun ìrúbọ rẹ̀ wá, kì báà ṣe pé láti fi san ẹ̀jẹ́ kan ni, tabi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA,

19 kí ohun ìrúbọ náà baà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, ó níláti jẹ́ akọ, tí kò ní àbùkù, ó lè jẹ́ akọ mààlúù, tabi àgbò, tabi òbúkọ.

20 Ẹ kò gbọdọ̀ fi ohunkohun tí ó bá ní àbààwọ́n rúbọ, nítorí pé, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà á lọ́wọ́ yín.

21 Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA láti san ẹ̀jẹ́, tabi fún ọrẹ àtinúwá; kì báà jẹ́ láti inú agbo mààlúù tabi láti inú agbo aguntan ni yóo ti mú ẹran ìrúbọ yìí, ó níláti jẹ́ pípé, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kan lára, kí ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

22 Bí ẹran náà bá jẹ́ afọ́jú, tabi amúkùn-ún, tabi ẹran tí ó farapa, tabi tí ara rẹ̀ ń tú, tabi tí ó ní èkúkú, ẹ kò gbọdọ̀ fi wọ́n fún OLUWA, tabi kí ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ sí OLUWA.

23 Bí apá tabi ẹsẹ̀ mààlúù tabi àgbò kan bá gùn ju ekeji lọ, ẹ lè mú un wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àtinúwá, ṣugbọn OLUWA kò ní tẹ́wọ́gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹran ìrúbọ láti fi san ẹ̀jẹ́.

24 Bí wọ́n bá tẹ ẹran kan lọ́dàá, tabi bí kóró abẹ́ rẹ̀ bá fọ́, tabi tí abẹ́ rẹ̀ fàya, tabi tí wọ́n la abẹ́ rẹ̀, tabi tí wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ ní abẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ mú un wá fún OLUWA, tabi kí ẹ fi rúbọ ninu gbogbo ilẹ̀ yín.

25 “Bí ẹ bá gba irú ẹran bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò, ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ ohun jíjẹ sí èmi Ọlọrun yín. Níwọ̀n ìgbà tí àbùkù bá ti wà lára wọn, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gba irú wọn lọ́wọ́ yín, nítorí àbùkù náà.”

26 OLUWA sọ fún Mose pé:

27 “Nígbà tí mààlúù, aguntan, tabi ewúrẹ́ bá bímọ, ẹ fi ọmọ náà sílẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, láti ọjọ́ kẹjọ lọ ni ó tó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ẹbọ sísun sí OLUWA.

28 Ẹ kò gbọdọ̀ fi ìyá ẹran ati ọmọ rẹ̀ rúbọ ní ọjọ́ kan náà; kì báà jẹ́ mààlúù, tabi aguntan, tabi ewúrẹ́.

29 Nígbà tí ẹ bá sì ń rú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA, ẹ gbọdọ̀ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

30 Ẹ níláti jẹ gbogbo rẹ̀ tán ní ọjọ́ kan náà, kò gbọdọ̀ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èmi ni OLUWA.

31 “Ẹ gbọdọ̀ ṣàkíyèsí òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni OLUWA.

32 Ẹ kò gbọdọ̀ ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, ẹ gbọdọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún mi láàrin gbogbo eniyan Israẹli. Èmi ni OLUWA tí mo sọ yín di mímọ́,

33 tí mo sì ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti máa jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.”

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 23

Àwọn Àjọ̀dún Ẹ̀sìn

1 OLUWA sọ fún Mose

2 pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Àwọn àjọ̀dún tí èmi OLUWA yàn tí ó gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí ìpéjọ mímọ́ nìwọ̀nyí:

3 Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ati ọjọ́ ìpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, ọjọ́ ìsinmi ni fún OLUWA ní gbogbo ibùgbé yín.

4 Èyí ni àwọn àjọ̀dún ati àpèjọ tí OLUWA yàn, tí wọ́n gbọdọ̀ kéde, ní àkókò tí OLUWA yàn fún wọn.

Àjọ̀dún Ìrékọjá ati Àìwúkàrà

5 “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni kí ẹ máa ṣe àjọ ìrékọjá OLUWA.

6 Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kan náà sì ni àjọ àìwúkàrà OLUWA. Ọjọ́ meje gbáko ni ẹ gbọdọ̀ fi máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.

7 Ní ọjọ́ kinni, ẹ níláti ní àpèjọ, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó bá lágbára.

8 Ṣugbọn, ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA fún ọjọ́ meje náà, ọjọ́ àpèjọ mímọ́ ni ọjọ́ keje yóo jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó lágbára.”

9 OLUWA tún rán Mose pé kí ó

10 sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, tí ẹ bá sì ń kórè nǹkan inú rẹ̀, ẹ níláti gbé ìtí ọkà kan lára àkọ́so oko yín tọ alufaa lọ.

11 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keji, lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi, alufaa yóo fi ìtí ọkà náà rú ẹbọ fífì níwájú OLUWA, kí ẹ lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

12 Ní ọjọ́ tí ẹ bá ń fi ìtí ọkà yín rú ẹbọ fífì, kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ aguntan ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

13 Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu rẹ̀ nìyí: ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí wọ́n fi òróró pò, ẹ óo fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA, kí ẹ sì fi idamẹrin ìwọ̀n hini ọtí waini rú ẹbọ ohun mímu pẹlu rẹ̀.

14 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tabi ọkà, kì báà jẹ́ ọkà yíyan tabi tútù títí di ọjọ́ yìí, tí ẹ óo fi mú ẹbọ Ọlọrun yín wá, ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún ìrandíran yín, ní gbogbo ilẹ̀ yín.

Àjọ̀dún Ìkórè

15 “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi tí ẹ mú ìtí ọkà fún ẹbọ fífì wá fún OLUWA.

16 Ẹ óo ka aadọta ọjọ́ títí dé ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi keje, lẹ́yìn náà, ẹ óo mú ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ fi ọkà titun ṣe wá fún OLUWA.

17 Ẹ óo mú burẹdi meji tí wọ́n fi ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára ṣe wá fún ẹbọ fífì; àwọn àkàrà náà yóo ní ìwúkàrà ninu, ẹ óo mú wọn tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí àkọ́so oko yín.

18 Ẹ óo mú ọ̀dọ́ aguntan meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù lọ́wọ́, pẹlu ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati àgbò meji, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn ìṣù àkàrà meji náà bọ̀. Àwọn ni ẹ óo fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA; pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu, ẹbọ tí a fi iná sun, olóòórùn dídùn, tí OLUWA gbádùn ni.

19 Ẹ óo fi òbúkọ kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ óo sì fi àgbò meji ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ alaafia.

20 Alufaa yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, pẹlu burẹdi tí ẹ fi àkọ́so ọkà ṣe, ati àgbò meji náà, wọn yóo jẹ́ ọrẹ mímọ́ fún OLUWA, tí a óo yà sọ́tọ̀ fún àwọn alufaa.

21 Ẹ pe àpèjẹ mímọ́ ní ọjọ́ náà; ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà. Ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún arọmọdọmọ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín títí lae.

22 “Nígbà tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè títí dé ààlà patapata. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè tán, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ gbọdọ̀ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

Àjọ̀dún Ọdún Titun

23 OLUWA sọ fun Mose

24 pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ ya ọjọ́ kinni oṣù keje sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ẹ óo kéde rẹ̀ pẹlu ìró fèrè, ẹ óo sì ní àpèjọ mímọ́.

25 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kan, ẹ sì níláti rú ẹbọ sísun sí OLUWA.”

Ọjọ́ Ètùtù

26 OLUWA sọ fún Mose pé,

27 “Ọjọ́ kẹwaa oṣù keje ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ní ìpéjọpọ̀ mímọ́ ní ọjọ́ náà, kí ẹ gbààwẹ̀, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

28 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ ètùtù ni, tí wọn yóo ṣe ètùtù fun yín níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

29 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.

30 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, n óo pa á run láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

31 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, ìlànà ni ó jẹ́ títí lae fún ìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín.

32 Yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ẹ sì gbọdọ̀ gbààwẹ̀. Ọjọ́ ìsinmi náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsan-an títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹwaa.”

Àjọ Àgọ́

33 OLUWA sọ fún Mose

34 pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, ẹ óo ṣe àjọ̀dún Àgọ́ fún OLUWA; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi ṣe é.

35 Ìpéjọpọ̀ mímọ́ yóo wà ní ọjọ́ kinni, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà.

36 Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ óo ní ìpéjọpọ̀ mímọ́, ẹ óo sì rú ẹbọ sísun sí OLUWA. Ìpéjọpọ̀ tí ó lọ́wọ̀ ni, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

37 “Àwọn àjọ̀dún wọnyi ni OLUWA ti yà sọ́tọ̀; ẹ óo máa kéde wọn gẹ́gẹ́ bí àkókò ìpéjọpọ̀ mímọ́, láti máa rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA, ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ; ati ẹbọ ohun mímu, olukuluku ní ọjọ́ tí a ti yàn fún wọn.

38 Àwọn ẹbọ wọnyi wà lọ́tọ̀ ní tiwọn, yàtọ̀ sí ti àwọn ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA, ati àwọn ẹ̀bùn yín, ati àwọn ẹbọ ẹ̀jẹ́ yín, ati àwọn ọrẹ ẹbọ àtinúwá tí ẹ óo máa mú wá fún OLUWA.

39 “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè àwọn èso ilẹ̀ yín tán, láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, kí ẹ máa ṣe àjọ àjọ̀dún OLUWA fún ọjọ́ meje; ọjọ́ kinni ati ọjọ́ kẹjọ yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀.

40 Ní ọjọ́ kinni, ẹ óo mú ninu àwọn èso igi tí ó bá dára, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka igi tí ó ní ewé dáradára, ati ẹ̀ka igi wilo etí odò, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín fún ọjọ́ meje.

41 Ọjọ́ meje láàrin ọdún kan ni ẹ óo máa fi ṣe àjọ̀dún fún OLUWA; Ìlànà títí lae ni èyí jẹ́ fún arọmọdọmọ yín. Ninu oṣù keje ọdún ni ẹ óo máa ṣe àjọ àjọ̀dún náà.

42 Inú àgọ́ ni ẹ óo máa gbé fún gbogbo ọjọ́ meje náà; gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ gbé inú àgọ́,

43 kí àwọn arọmọdọmọ yín lè mọ̀ pé, inú àgọ́ ni mo mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa gbé nígbà tí mo kó wọn jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

44 Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe ṣàlàyé àwọn Àjọ àjọ̀dún tí OLUWA yàn, fún àwọn ọmọ Israẹli.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 24

Ìtọ́jú Àwọn Fìtílà

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún àtùpà ilé mímọ́ mi, kí ó lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.

3 Ní ìrọ̀lẹ́, Aaroni yóo máa tan àtùpà náà kalẹ̀ níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, wọn yóo máa wà ní títàn níwájú OLUWA títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èyí yóo wà bí ìlànà, títí lae, fún arọmọdọmọ yín.

4 Aaroni yóo sì máa ṣe ìtọ́jú àwọn àtùpà tí wọ́n wà lórí ọ̀pá fìtílà wúrà, kí wọ́n lè máa wà ní títàn níwájú OLUWA nígbà gbogbo.

Àkàrà Tí Wọ́n Fi Rúbọ sí Ọlọrun

5 “Ẹ mú ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ẹ sì fi ṣe burẹdi mejila, ìdámárùn-ún ìwọ̀n ìyẹ̀fun efa kan ni kí ẹ fi ṣe burẹdi kọ̀ọ̀kan.

6 Ẹ sì máa tò wọ́n kalẹ̀ sí ọ̀nà meji; mẹfa mẹfa ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, lórí tabili tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe.

7 Ẹ fi ojúlówó turari sí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí àmì fún ìrántí.

8 Ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, Aaroni yóo máa tò wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA nígbà gbogbo, ní orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu títí lae.

9 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ni àwọn burẹdi náà, ibi mímọ́ ni wọn yóo sì ti máa jẹ wọ́n, nítorí pé òun ni ó mọ́ jùlọ ninu ìpín wọn, ninu ọrẹ ẹbọ sísun sí OLUWA.”

Àpẹẹrẹ Ìdájọ́ ati Ìjẹníyà Tí Ó Tọ́

10 Ọkunrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli, ṣugbọn tí baba rẹ̀ jẹ́ ará Ijipti. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli jáde, ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun ati ọkunrin kan, tí ó jẹ́ ọmọ Israẹli, ní ibùdó.

11 Ọkunrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli yìí bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, bí ó ti ń búra ni ó ń ṣépè. Wọ́n bá mú un tọ Mose wá; orúkọ ìyá ọmọkunrin náà ni Ṣelomiti ọmọ Dibiri láti inú ẹ̀yà Dani.

12 Wọ́n tì í mọ́lé títí tí wọn fi mọ ohun tí OLUWA fẹ́ kí wọ́n ṣe sí i.

13 OLUWA sọ fún Mose pé,

14 “Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

15 Wí fún àwọn eniyan Israẹli pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé Ọlọrun rẹ̀ yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀.

16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. Gbogbo ìjọ eniyan yóo sọ ọ́ ní òkúta pa, kì báà jẹ́ àlejò, kì báà jẹ́ onílé; tí ó bá ṣá ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á.

17 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa eniyan, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ẹlẹ́ran, yóo san án pada. Ohun tí ẹ̀tọ́ wí ni pé, kí á fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.

19 “Bí ẹnìkan bá ṣá aládùúgbò rẹ̀ lọ́gbẹ́, irú ọgbẹ́ tí ó ṣá aládùúgbò rẹ̀ gan-an ni wọn yóo ṣá òun náà. Bí ẹnìkan bá ṣe aládùúgbò rẹ̀ léṣe, tí ó sì di ohun àbùkù sí i lára, ohun tí ó ṣe sí aládùúgbò rẹ̀ ni kí wọ́n ṣe sí òun náà.

20 Bí ó bá dá egungun aládùúgbò rẹ̀, kí wọ́n dá egungun tirẹ̀ náà, bí ó bá fọ́ ọ lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà, bí ó bá yọ eyín rẹ̀, kí wọ́n yọ eyín tirẹ̀ náà; irú ohun tí ó bá fi ṣe ẹlòmíràn gan-an ni kí wọn fi ṣe òun náà.

21 Ẹni tí ó bá pa ẹran, yóo san òmíràn pada, ẹni tí ó bá sì pa eniyan, wọn yóo pa òun náà.

22 Òfin kan náà tí ó de àlejò, ni ó gbọdọ̀ de onílé, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

23 Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 25

Ọdún Keje

1 OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ lórí òkè Sinai, ó ní,

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, àkókò ìyàsọ́tọ̀ kan gbọdọ̀ wà fún ilẹ̀ náà tí yóo jẹ́ àkókò ìsinmi fún OLUWA.

3 Ọdún mẹfa ni kí ẹ máa fi gbin èso sinu oko yín, ọdún mẹfa náà sì ni kí ẹ máa fi tọ́jú ọgbà àjàrà yín, tí ẹ óo sì máa fi kórè èso rẹ̀.

4 Ṣugbọn ọdún keje yóo jẹ́ ọdún ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀ fún ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sinmi fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sinu oko yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ tọ́jú àjàrà yín.

5 Ohunkohun tí ó bá dá hù fún ara rẹ̀ ninu oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ kórè èso tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà yín tí ẹ kò tọ́jú. Ọdún náà gbọdọ̀ jẹ́ ọdún ìsinmi fún ilẹ̀.

6 Ìsinmi ilẹ̀ yìí ni yóo mú kí oúnjẹ wà fun yín: ati ẹ̀yin alára, tọkunrin tobinrin yín, ati àwọn ẹrú, ati àwọn alágbàṣe yín, ati àwọn àlejò tí wọ́n ń ba yín gbé,

7 ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ tí wọ́n wà ní ilẹ̀ yín, gbogbo èso ilẹ̀ náà yóo sì wà fún jíjẹ.

Ọdún Ìdásílẹ̀ ati Ìdápadà

8 “Ẹ ka ìsinmi ọdún keje keje yìí lọ́nà meje, kí ọdún keje náà fi jẹ́ ọdún mọkandinlaadọta.

9 Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹwaa oṣù keje tíí ṣe ọjọ́ ètùtù, ẹ óo rán ọkunrin kan kí ó lọ fọn fèrè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín.

10 Ẹ ya ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún náà sí mímọ́, kí ẹ sì kéde ìdáǹdè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín fún gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, yóo jẹ́ ọdún jubili fun yín. Ní ọdún náà, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀ ati sinu ìdílé rẹ̀.

11 Ọdún jubili ni ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún yìí yóo jẹ́ fun yín. Ninu ọdún náà, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kórè ohun tí ó bá dá hù fúnra rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ká àjàrà tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà tí ẹ kò tọ́jú.

12 Nítorí pé, ọdún jubili ni yóo máa jẹ́ fun yín, yóo jẹ́ ọdún mímọ́ fun yín, ninu oko ni ẹ óo ti máa jẹ ohun tí ó bá so.

13 “Ní ọdún jubili yìí, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

14 Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ta ilẹ̀ fún aládùúgbò yín, tabi tí ẹ bá ń ra ilẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín.

15 Iye ọdún tí ó bá ti rékọjá lẹ́yìn ọdún jubili ni ẹ óo máa wò ra ilẹ̀ lọ́wọ́ aládùúgbò yín, iye ọdún tí ẹ bá fi lè gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ kan kí ọdún jubili tó dé ni òun náà yóo máa wò láti tà á fun yín.

16 Tí ó bá jẹ́ pé ọdún pupọ ni ó kù, owó ilẹ̀ náà yóo pọ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé ọdún díẹ̀ ni, owó rẹ̀ yóo wálẹ̀; nítorí pé, iye ọdún tí ó bá lè fi gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ náà ni yóo wò láti ta ilẹ̀ náà.

17 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìdára sí ara yín, ṣugbọn ẹ bẹ̀rù Ọlọrun yín; nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

Ìyọnu Tí Ó Wà ninu Ọdún Keje

18 “Nítorí náà, ẹ níláti tẹ̀lé ìlànà mi, kí ẹ sì pa òfin mi mọ́, kí ẹ lè máa gbé inú ilẹ̀ náà láìséwu.

19 Ilẹ̀ náà yóo so ọpọlọpọ èso, ẹ óo jẹ àjẹyó, ẹ óo sì máa gbé inú rẹ̀ láìséwu.

20 “Bí ẹ bá ń wí pé, ‘Kí ni a óo jẹ ní ọdún keje bí a kò bá gbọdọ̀ gbin ohun ọ̀gbìn, tí a kò sì gbọdọ̀ kórè?’

21 Èmi OLUWA yóo pàṣẹ pé kí ibukun mi wà lórí yín ní ọdún kẹfa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ yóo so èso tí yóo to yín jẹ fún ọdún mẹta.

22 Nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn ní ọdún kẹjọ, ẹ óo tún máa rí àwọn èso tí ó ti wà ní ìpamọ́ jẹ títí tí yóo fi di ọdún kẹsan-an, tí ilẹ̀ yóo tún mú èso rẹ̀ jáde wá, àwọn èso ti àtẹ̀yìnwá ni ẹ óo máa jẹ.

Dídá Nǹkan Ìní Pada

23 “Ẹ kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ kan títí ayé, nítorí pé èmi OLUWA ni mo ni gbogbo ilẹ̀, ati pé àlejò ati àtìpó ni ẹ jẹ́ fún mi.

24 “Ninu gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìkáwọ́ yín, ẹ gbọdọ̀ fi ààyè sílẹ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ ra ilẹ̀ pada.

25 Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tí ó bá sì tà ninu ilẹ̀ rẹ̀, ọ̀kan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ yóo dìde láti ra ohun tí ìbátan rẹ̀ tà pada.

26 Bí ẹni náà kò bá ní ẹbí tí ó lè ra ilẹ̀ náà pada, ṣugbọn ní ọjọ́ iwájú, tí nǹkan bá ń lọ déédé fún un, tí ó sì ní agbára láti ra ilẹ̀ náà pada,

27 kí ó ṣírò iye ọdún tí ó ti tà á, kí ó sì san iye owó tí ó bá kù pada fún ẹni tí ó ta ilẹ̀ náà fún, lẹ́yìn náà kí ó pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

28 Ṣugbọn bí kò bá ní agbára tó láti ra ilẹ̀ náà pada fúnra rẹ̀, ilẹ̀ náà yóo wà ní ọwọ́ ẹni tí ó rà á lọ́wọ́ rẹ̀ títí di ọdún jubili. Ní ọdún jubili, ẹni tí ó ra ilẹ̀ náà yóo dá a pada, ẹni tí ó ni ín yóo sì pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.

29 “Bí ẹnìkan bá ta ilé kan ninu ìlú olódi, ó lè rà á pada láàrin ọdún kan lẹ́yìn tí ó ti tà á.

30 Bí ẹni náà kò bá ra ilé náà pada láàrin ọdún kan, ilé yóo di ti ẹni tí ó rà á títí lae ati ti arọmọdọmọ rẹ̀; kò ní jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bí ọdún jubili tilẹ̀ dé.

31 Ṣugbọn a óo ka àwọn ilé tí wọ́n wà ní àwọn ìlú tí kò ní odi pọ̀ mọ́ ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ wọn lé lórí. Ẹni tí ó ta ilẹ̀ lé rà wọ́n pada, ẹni tí ó rà á sì níláti jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ nígbà tí ọdún jubili bá dé.

32 Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi lè ra gbogbo àwọn ilé tí wọ́n wà ní ààrin ìlú wọn pada nígbàkúùgbà.

33 Ṣugbọn bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi kò bá lo ẹ̀tọ́ ìràpadà yìí, ẹni tí ó bá ra ilé náà lọ́wọ́ rẹ̀ ninu ìlú olódi, yóo jọ̀wọ́ ilé náà sílẹ̀ ní ọdún jubili, nítorí pé, àwọn ilé tí ó wà ní ìlú àwọn ọmọ Lefi jẹ́ ìní tiwọn láàrin àwọn eniyan Israẹli.

34 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú wọn, nítorí pé, ogún tiwọn nìyí títí ayérayé.

Yíyá Aláìní Lówó

35 “Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè bọ́ ara rẹ̀ mọ́, o níláti máa bọ́ ọ, kí ó sì máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àlejò ati àjèjì.

36 O kò gbọdọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ, kí o sì jẹ́ kí arakunrin rẹ máa bá ọ gbé.

37 O kò gbọdọ̀ yá a ní owó kí o gba èlé, o kò sì gbọdọ̀ fún un ní oúnjẹ kí o gba èrè.

38 Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ó mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi ilẹ̀ Kenaani fún ọ ati láti jẹ́ Ọlọrun rẹ.

Ìdásílẹ̀ Àwọn Ẹrú

39 “Bí arakunrin rẹ, tí ń gbé tòsí rẹ bá di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún ọ, o kò gbọdọ̀ mú un sìn bí ẹrú.

40 Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tabi bí àlejò; kí ó máa ṣiṣẹ́ fún ọ títí di ọdún jubili.

41 Nígbà náà ni yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ati sórí ilẹ̀ ìní àwọn baba rẹ̀.

42 Nítorí pé, iranṣẹ mi ni wọ́n, tí mo kó jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹnìkan kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.

43 O kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ.

44 Láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká ni ẹ ti lè ra ẹrukunrin tabi ẹrubinrin.

45 Ẹ sì lè rà láàrin àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín ati àwọn ìdílé wọn tí wọ́n wà pẹlu yín, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ yín, wọ́n lè di tiyín.

46 Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín nígbà tí ẹ bá kú, kí wọn lè jogún wọn títí lae. Wọ́n lè di ẹrú yín, ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli tí ẹ jẹ́ arakunrin ara yín, ẹ kò gbọdọ̀ mú ara yín sìn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú ara yín.

47 “Bí àlejò tí ó wà láàrin yín bá di ọlọ́rọ̀ tí arakunrin rẹ̀ tí ó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ sì di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún àlejò náà, tabi fún ọ̀kan ninu ìdílé àlejò yín,

48 lẹ́yìn tí ó bá ti ta ara rẹ̀, wọ́n lè rà á pada: ọ̀kan ninu àwọn arakunrin rẹ̀ lè rà á pada.

49 Arakunrin baba tabi ìyá rẹ̀, tabi ọ̀kan ninu àwọn ìbátan rẹ̀ tabi ẹnìkan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ le rà á pada. Bí òun pàápàá bá sì di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pada.

50 Kí òun ati ẹni tí ó rà á jọ ṣírò iye ọdún tí ó fi ta ara rẹ̀, láti ọdún tí ó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún jubili. Iye ọdún tí ó bá kù ni wọn yóo fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀. Wọn yóo ṣírò àkókò tí ó ti lò lọ́dọ̀ olówó rẹ̀ bí àkókò tí alágbàṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

51 Bí iye ọdún tí ó kù bá pọ̀, yóo ṣírò iye tí owó ìràpadà rẹ̀ kù ninu iye tí wọ́n san lórí rẹ̀, yóo sì san án pada.

52 Bí ọdún tí ó kù tí ọdún jubili yóo fi pé kò bá pọ̀ mọ́, wọn yóo jọ ṣírò iye ọdún tí ó kù fún un láti fi sìn ín, òun ni yóo sì fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀ tí ó kù tí yóo san.

53 Ọkunrin tí ó ta ara rẹ̀ yìí yóo dàbí iranṣẹ tí à ń gbà lọdọọdun sí ẹni tí ó rà á; ẹni tí ó rà á kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un lójú rẹ̀.

54 Bí ẹnikẹ́ni kò bá ra ẹni náà pada lọ́nà tí a ti là sílẹ̀ wọnyi, wọ́n gbọdọ̀ dá òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí ó bá di ọdún jubili.

55 Nítorí pé, iranṣẹ mi ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, iranṣẹ mi tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 26

Ibukun fún Ìgbọràn

1 “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe oriṣa-koriṣa kan fún ara yín, tabi kí ẹ gbé ère gbígbẹ́ kalẹ̀, tabi kí ẹ ri ọ̀wọ̀n òkúta gbígbẹ́ mọ́lẹ̀, kí ẹ sì máa bọ wọ́n, ní gbogbo ilẹ̀ yín, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

2 Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA.

3 “Bí ẹ bá ń tẹ̀lé ìlànà mi, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin mi mọ́,

4 n óo mú kí òjò rọ̀ ní àkókò rẹ̀, ilẹ̀ yóo mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi inú oko yóo sì máa so èso.

5 Ẹ óo máa pa ọkà títí tí èso àjàrà yóo fi tó ká, ẹ óo sì máa ká èso àjàrà lọ́wọ́, títí àwọn nǹkan oko yóo fi tó gbìn. Ẹ óo jẹ, ẹ óo yó, ẹ óo sì máa gbé inú ilẹ̀ yín láìléwu.

6 “N óo fun yín ní alaafia ní ilẹ̀ náà, ẹ óo dùbúlẹ̀, kò sí ẹnìkan tí yóo sì dẹ́rùbà yín. N óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, ogun kò sì ní jà ní ilẹ̀ náà.

7 Ẹ óo lé àwọn ọ̀tá yín jáde, ẹ óo sì máa fi idà pa wọ́n.

8 Marun-un ninu yín yóo lé ọgọrun-un ọ̀tá sẹ́yìn, ọgọrun-un ninu yín yóo sì lé ẹgbaarun (10,000) àwọn ọ̀tá yín sẹ́yìn, idà ni ẹ óo fi máa pa wọ́n.

9 N óo fi ojurere wò yín, n óo mú kí ẹ máa bímọlémọ, kí ẹ sì pọ̀ sí i, n óo sì fi ìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu yín.

10 Ẹ óo jẹ àwọn nǹkan oko tí ẹ kó sí inú abà fún ọjọ́ pípẹ́, ẹ óo sì máa ru ìyókù wọn dànù kí ẹ lè rí ààyè kó tuntun sí.

11 N óo fi ààrin yín ṣe ibùgbé mi, ọkàn mi kò sì ní kórìíra yín.

12 N óo máa rìn láàrin yín, n óo jẹ́ Ọlọrun yín, ẹ óo sì jẹ́ eniyan mi.

13 Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, kí ẹ má baà ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ti dá igi ìdè àjàgà yín kí ẹ lè máa rìn lóòró gangan.

Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn

14 “Ṣugbọn tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tèmi, tí ẹ kò sì pa gbogbo àwọn òfin mi mọ́,

15 bí ẹ bá Pẹ̀gàn àwọn ìlànà mi, tí ọkàn yín sì kórìíra ìdájọ́ mi, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ kọ̀ láti pa àwọn òfin mi mọ́, tí ẹ̀ ń ba majẹmu mi jẹ́,

16 ohun tí n óo ṣe sí yín nìyí: n óo rán ìbẹ̀rù si yín lójijì, àìsàn burúkú ati ibà tí ń bani lójú jẹ́ yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, ẹ óo sì bẹ̀rẹ̀ sí kú sára. Bí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn, òfò ni yóo jásí, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóo jẹ ẹ́.

17 N óo kẹ̀yìn sí yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Àwọn tí ẹ kórìíra ni yóo máa jọba lórí yín, ẹ óo sì máa sá nígbà tí ẹnikẹ́ni kò le yín.

18 “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, sibẹ tí ẹ kò gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

19 Pẹlu gbogbo agbára tí ẹ ní, n óo tẹ̀ yín lórí ba; òjò yóo kọ̀, kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.

20 Iṣẹ́ àṣedànù ni ẹ óo máa ṣe, nítorí pé, ilẹ̀ kò ní mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi oko kò ní so.

21 “Bí ẹ bá lòdì sí mi, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

22 N óo da àwọn ẹranko burúkú sáàrin yín, tí yóo máa gbé yín lọ́mọ lọ, wọn yóo run àwọn ẹran ọ̀sìn yín, n óo dín yín kù, tí yóo fi jẹ́ pé ilẹ̀ yín yóo di ahoro.

23 “Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ ba kọ̀, ti ẹ kò yipada, ṣugbọn tí ẹ kẹ̀yìn sí mi,

24 èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn si yín, n óo sì jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

25 N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́.

26 Nígbà tí mo bá gba oúnjẹ lẹ́nu yín, obinrin mẹ́wàá ni yóo máa jókòó nídìí ẹyọ ààrò kan ṣoṣo láti ṣe burẹdi. Wíwọ̀n ni wọn yóo máa wọn oúnjẹ le yín lọ́wọ́; ẹ óo jẹ, ṣugbọn ẹ kò ní yó.

27 “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, ṣugbọn tí ẹ tún kẹ̀yìn sí mi,

28 n óo fi ibinu kẹ̀yìn sí yín, n óo sì jẹ yín níyà fúnra mi, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

29 Ebi yóo pa yín tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo máa pa àwọn ọmọ yín jẹ.

30 N óo wó àwọn ilé ìsìn yín gbogbo tí wọ́n wà lórí òkè, n óo wó àwọn pẹpẹ turari yín lulẹ̀; n óo kó òkú yín dà sórí àwọn oriṣa yín, ọkàn mi yóo sì kórìíra yín.

31 N óo sọ àwọn ìlú yín di ahoro, àwọn ilé ìsìn yín yóo sì ṣófo, n kò ní gba ẹbọ yín mọ́.

32 N óo run ilẹ̀ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu yóo fi ya àwọn ọ̀tá yín, tí wọn yóo pada wá tẹ̀dó ninu rẹ̀.

33 N óo fọ́n yín káàkiri ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, idà ni wọn yóo máa fi pa yín ní ìpakúpa, ilẹ̀ yín ati àwọn ìlú yín yóo di ahoro.

34 Nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, ilẹ̀ ti ẹ̀yin pàápàá yóo wá ní ìsinmi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà ní ahoro, ilẹ̀ yín yóo gbádùn ìsinmi rẹ̀.

35 Nígbà tí ó bá wà ní ahoro, yóo ní irú ìsinmi tí kò ní rí ni àkókò ìsinmi yín, nígbà tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀.

36 “Ìwọ̀nba àwọn tí wọ́n bá kù, n óo da jìnnìjìnnì bo ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ìró ewé tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lásán yóo máa lé wọn sá; wọn yóo sì máa sá àsá-dojúbolẹ̀ bí ẹni pé ogun ní ń lé wọn. Wọn yóo máa ṣubú nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn.

37 Wọn yóo máa ṣubú lórí ara wọn bí ẹni tí ogun ń lé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń lé wọn. Kò sì ní sí agbára fun yín láti dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín.

38 Ẹ óo parun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóo sì gbé yín mì.

39 Ìwọ̀nba ẹ̀yin tí ẹ bá ṣẹ́kù, kíkú ni ẹ óo máa kú sára lórí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, nítorí àìdára yín ati ti àwọn baba yín.

40 “Ṣugbọn bí wọn bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, nípa ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí mi, ati lílòdì tí wọ́n lòdì sí mi,

41 tí mo fi kẹ̀yìn sí wọn, tí mo fi mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; bí ọkàn wọn tí ó ti yigbì tẹ́lẹ̀ bá rọ̀, tí wọ́n bá sì ṣe àtúnṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

42 n óo ranti majẹmu tí mo bá Jakọbu, ati Isaaki, ati Abrahamu dá, n óo sì ranti ilẹ̀ náà.

43 Ṣugbọn wọn yóo jáde kúrò ninu ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sì ní ìsinmi nígbà ti ó bá wà ní ahoro, nígbà tí wọn kò bá sí níbẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ gba ìjẹníyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé, wọ́n kẹ́gàn ìdájọ́ mi, wọ́n sì kórìíra ìlànà mi.

44 Sibẹsibẹ nígbà tí wọ́n bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n kò ní ṣàì náání wọn; bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kórìíra wọn débi pé kí n pa wọ́n run patapata, kí n sì yẹ majẹmu mi pẹlu wọn, nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.

45 Ṣugbọn n óo tìtorí tiwọn ranti majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, àní àwọn tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, kí n lè jẹ́ Ọlọrun wọn. Èmi ni OLUWA.”

46 Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA fi lélẹ̀ láàrin òun ati àwọn ọmọ Israẹli, láti ọwọ́ Mose.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 27

Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Ohun tí a fi fún OLUWA

1 OLUWA sọ fun Mose

2 pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹnìkan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pataki kan láti fi odidi eniyan fún OLUWA, tí kò bá lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, iye tí ó níláti san nìyí:

3 Fún ọkunrin tí ó jẹ́ ẹni ogún ọdún sí ọgọta ọdún, yóo san aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ìwọ̀n ṣekeli ibi mímọ́ ni kí wọ́n fi wọn owó náà.

4 Bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹni náà yóo san ọgbọ̀n ìwọ̀n ṣekeli.

5 Bí ó bá jẹ́ ọkunrin, tí ó jẹ́ ẹni ọdún marun-un sí ogun ọdún, yóo san ogun ìwọ̀n ṣekeli; bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ṣekeli mẹ́wàá.

6 Bí ó bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọmọ ọdún marun-un, tí ó sì jẹ́ ọkunrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un, bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka mẹta.

7 Bí ẹni náà bá tó ẹni ọgọta ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá jẹ́ ọkunrin, kí ó san ṣekeli mẹẹdogun, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin, kí ó san Ṣekeli mẹ́wàá.

8 “Bí ẹni náà bá jẹ́ talaka tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè san iye tí ó yẹ kí ó san, mú ẹni tí ó fi jẹ́jẹ̀ẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ alufaa kí alufaa díye lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí.

9 “Bí ó bá jẹ́ pé ẹran ni eniyan jẹ́jẹ̀ẹ́ láti mú wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA, gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tí eniyan bá fún OLUWA jẹ́ mímọ́.

10 Kò gbọdọ̀ fi ohunkohun dípò rẹ̀, tabi kí ó pààrọ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ pààrọ̀ ẹran tí kò dára sí èyí tí ó dára, tabi kí ó pààrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára. Bí ó bá jẹ́ pé ó fẹ́ fi ẹran kan pààrọ̀ ẹran mìíràn, ati èyí tí wọ́n pààrọ̀, ati èyí tí wọ́n fẹ́ fi pààrọ̀ rẹ̀, wọ́n di mímọ́.

11 Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́ ni, tí eniyan kò lè fi rúbọ sí OLUWA, kí ẹni náà mú ẹran náà tọ alufaa wá,

12 kí alufaa wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iye tí alufaa bá pè é náà ni iye rẹ̀.

13 Ṣugbọn bí ẹni náà bá fẹ́ ra ẹran náà pada, yóo fi ìdámárùn-ún kún iye owó rẹ̀.

14 “Nígbà tí ẹnìkan bá ya ilé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iyekíye tí alufaa bá pè é ni iye rẹ̀.

15 Bí ẹni tí ó ya ilé yìí sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ilé náà bá tó, yóo sì tún fi ìdámárùn-ún iye owó rẹ̀ lé e. Nígbà tí ó bá san owó ilé náà pada, ilé yóo di tirẹ̀.

16 “Bí ẹnìkan bá ya apá kan ninu ilẹ̀ tí ó jogún sọ́tọ̀ fún OLUWA, ìwọ̀n èso tí eniyan bá lè rí ká lórí ilẹ̀ náà ni wọn yóo fi díye lé e. Bí a bá lè rí ìwọ̀n Homeri baali kan ká ninu rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, iye rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka.

17 Bí ó bá jẹ́ pé láti ọdún jubili ni ó ti ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó lójú yín kò gbọdọ̀ dín.

18 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún Jubili ni ó ya ilẹ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo ṣírò iye tí ó tó, gẹ́gẹ́ bí iye ọdún tí ó kù kí ọdún Jubili mìíràn pé bá ti pẹ́ sí, ẹ óo ṣí iye owó ọdún tí ó dínkù kúrò lára iye ilẹ̀ náà.

19 Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ó bá tó, yóo sì fi ìdámárùn-ún owó rẹ̀ lé e, ilẹ̀ náà yóo sì di tirẹ̀.

20 Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ra ilẹ̀ náà pada, tabi ti ó bá ti ta ilẹ̀ náà fún ẹlòmíràn, kò ní ẹ̀tọ́ láti rà á pada mọ́.

21 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá jọ̀wọ́ ilẹ̀ náà ní ọdún Jubili, ó níláti jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí wọ́n ti fi fún OLUWA; yóo sì di ohun ìní alufaa.

22 “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé rírà ni ó ra ilẹ̀ tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí kì í ṣe apá kan ninu ilẹ̀ àjogúnbá tirẹ̀,

23 alufaa yóo ṣírò iye tí ilẹ̀ náà bá tó títí di ọdún Jubili, ẹni náà yóo sì san iye rẹ̀ ní ọjọ́ náà bí ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA.

24 Nígbà tí ó bá di ọdún Jubili, ilẹ̀ yìí yóo pada di ti ẹni tí wọ́n rà á lọ́wọ́ rẹ̀, tí ilẹ̀ yìí jẹ́ ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́.

25 “Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ninu ibi mímọ́ ni kí ẹ máa lò láti wọn ohun gbogbo: Ogún ìwọ̀n gera ni yóo jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli kan.

26 “Ṣugbọn gbogbo ẹran tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí, ti OLUWA ni, ẹnikẹ́ni kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní yà á sọ́tọ̀ mọ́; kì báà jẹ́ mààlúù tabi aguntan, ti OLUWA ni.

27 Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́, kí ó san owó rẹ̀ pada gẹ́gẹ́ bí iye tí ẹ bá dá lé e, kí ó sì fi ìdámárùn-ún owó náà lé e. Bí ẹni tí ó ni í kò bá sì rà á pada, kí wọ́n tà á ní iyekíye tí ẹ bá dá lé e.

28 “Ṣugbọn ohunkohun tí eniyan bá ti fi fún OLUWA, kì báà jẹ́ eniyan ni, tabi ẹranko, tabi ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀, yóo jẹ́ títà tabi kí ó rà á pada. Ohunkohun tí a bá ti fi fún OLUWA, ó di mímọ́ jùlọ fún OLUWA.

29 Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀ pé ó gbọdọ̀ jẹ́ pípa láàrin àwọn eniyan, ẹnìkan kò gbọdọ̀ rà á pada, pípa ni wọ́n gbọdọ̀ pa á.

30 “Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà, kì báà jẹ́ ti èso ilẹ̀, tabi ti èso igi, ti OLUWA ni; mímọ́ ni fún OLUWA.

31 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá rẹ̀ pada, ó níláti fi ìdámárùn-ún ìdámẹ́wàá yìí lé e.

32 Ìdámẹ́wàá gbogbo agbo mààlúù, ati ti agbo aguntan jẹ́ ti OLUWA. Bí ẹran mẹ́wàá bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran, ikẹwaa gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún OLUWA.

33 Darandaran náà kò gbọdọ̀ bèèrè bóyá ó dára tabi kò dára, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá fẹ́ pààrọ̀ rẹ̀, ati èyí tí ó fi pààrọ̀ ati èyí tí ó pààrọ̀, mejeeji jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ rà á pada.”

34 Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni OLUWA fún Mose lórí Òkè Sinai fún àwọn ọmọ Israẹli.