Categories
LEFITIKU

LEFITIKU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Àwọn ìlànà ìjọ́sìn ati ayẹyẹ tí ó jẹ mọ́ ẹ̀sìn ilẹ̀ Israẹli àtijọ́, ati òfin tí ó de àwọn alufaa tí wọn ń darí ìjọ́sìn ati ayẹyẹ náà, ló wà ninu

Ìwé Lefitiku

.

Kókó pataki inú ìwé yìí ni Mímọ́ Ọlọrun, àwọn ọ̀nà tí àwọn eniyan rẹ̀ ń gbà sìn ín, ati irú ìgbé ayé tí wọn ń gbé kí wọ́n lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu “Ọlọrun, Ẹni Mímọ́ Israẹli.”

Gbolohun kan tí àwọn eniyan mọ̀ jùlọ ninu ìwé yìí wà ní orí 19, ẹsẹ 18. Òun ni Jesu pè ní òfin ńlá keji. Gbolohun náà ni: “Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àwọn òfin tí ó de ẹbọ rírú ati ọrẹ 1:1–7:38

Ètò fífi Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ oyè alufaa 8:1–10:20

Òfin nípa ètùtù fún jíjẹ́ mímọ́ ati jíjẹ́ aláìmọ́ ní ọ̀nà ti ẹ̀sìn 11:1–15:33

Ọjọ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ 16:1-34

Òfin nípa ìgbé ayé mímọ́ ati ìjọ́sìn tí ó jẹ́ mímọ́ 17:1–27:34

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 1

Àwọn Ẹbọ Tí A Sun Lódidi

1 OLUWA pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú Àgọ́ Àjọ ó ní,

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹnikẹ́ni ninu yín bá fẹ́ mú ọrẹ ẹbọ wá fún èmi OLUWA, ninu agbo mààlúù, tabi agbo ewúrẹ́, tabi agbo aguntan rẹ̀ ni kí ó ti mú un.

3 “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA.

4 Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ.

5 Kí ó pa akọ mààlúù náà níbẹ̀, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá siwaju OLUWA, kí wọn da ẹ̀jẹ̀ náà yíká ara pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

6 Mú ẹran náà, kí o bó awọ rẹ̀, kí o sì gé e sí wẹ́wẹ́;

7 kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to igi sórí pẹpẹ náà kí wọ́n sì dáná sí i.

8 Lẹ́yìn náà, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to àwọn igẹ̀ ẹran náà ati orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ sórí igi tí wọ́n dáná sí, lórí pẹpẹ náà.

9 Ṣugbọn ẹni tí ó wá rúbọ yóo fi omi fọ àwọn nǹkan inú ẹran náà ati ẹsẹ̀ rẹ̀, alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ níná lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.

10 “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo aguntan tabi agbo ewúrẹ́ ni ó ti mú ẹran fún ẹbọ sísun rẹ̀, akọ tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú.

11 Kí ó pa á ní apá ìhà àríwá pẹpẹ níwájú OLUWA, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yíká.

12 Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀, ati ọ̀rá rẹ̀, kí alufaa to gbogbo rẹ̀ sórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ.

13 Ṣugbọn kí ó fi omi fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, kí alufaa fi gbogbo rẹ̀ rúbọ, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ náà. Ẹbọ sísun ni; ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA dùn sí.

14 “Bí ó bá jẹ́ pé ẹyẹ ni eniyan bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, kí ó mú àdàbà tabi ọmọ ẹyẹlé wá.

15 Alufaa yóo gbà á, yóo fa ọrùn rẹ̀ tu, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ, lẹ́yìn tí ó bá ti ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ tán;

16 kí ó fa àjẹsí rẹ̀ yọ, kí ó sì tu ìyẹ́ rẹ̀, kí ó dà á sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ náà, níbi tí wọn ń da eérú sí.

17 Kí ó fa apá rẹ̀ mejeeji ya, ṣugbọn kí ó má fà wọ́n já. Lẹ́yìn náà kí alufaa sun ún lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 2

Ẹbọ Ohun Jíjẹ

1 “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú ọkà wá siwaju OLUWA láti fi rúbọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró ati turari sórí rẹ̀.

2 Kí ó gbé e tọ àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, lọ, kí alufaa náà bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ìyẹ̀fun náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀. Ẹ̀kúnwọ́ kan yìí ni alufaa yóo sun fún ìrántí, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLUWA.

3 Ohun tí ó ṣẹ́kù ninu ìyẹ̀fun náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ló mọ́ jùlọ, nítorí pé apá kan ninu ẹbọ sísun sí OLUWA ni.

4 “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu rẹ̀. Ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò ni wọ́n gbọdọ̀ fi yan án, ó sì lè jẹ́ burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu tí a da òróró lé lórí.

5 “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ó fi rúbọ, kí ó jẹ́ èyí tí ìyẹ̀fun rẹ̀ kúnná dáradára, tí a fi òróró pò, kí ó má sì ní ìwúkàrà ninu.

6 Já a sí wẹ́wẹ́, kí o sì da òróró lé e lórí, ẹbọ ohun jíjẹ ni.

7 “Bí ẹbọ rẹ bá jẹ́ ti ohun jíjẹ tí a sè ninu ìkòkò, ìyẹ̀fun rẹ̀ gbọdọ̀ kúnná dáradára kí ó sì ní òróró.

8 Gbé àwọn ẹbọ ohun jíjẹ náà wá siwaju OLUWA. Nígbà tí o bá gbé e fún alufaa, yóo gbé e wá síbi pẹpẹ.

9 Alufaa yóo wá bu díẹ̀ ninu ẹbọ ohun jíjẹ yìí, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ. Ẹbọ tí a fi iná sun ni, tí ó ní òórùn dídùn tí inú OLUWA sì dùn sí.

10 Ohun tí ó bá ṣẹ́kù ninu ohun jíjẹ náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ni ó mọ́ jùlọ lára ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA.

11 “Ẹbọ ohun jíjẹ tí o bá mú wá fún OLUWA kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà ninu, nítorí pé ìwúkàrà tabi oyin kò gbọdọ̀ sí ninu ẹbọ sísun sí OLUWA.

12 O lè mú wọn wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so oko, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ bí ẹbọ olóòórùn dídùn.

13 Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ rẹ ni o gbọdọ̀ fi iyọ̀ sí, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ wọ́n ninu ọrẹ ohun jíjẹ rẹ; nítorí pé iyọ̀ ni ẹ̀rí majẹmu láàrin ìwọ pẹlu Ọlọrun rẹ, o níláti máa fi iyọ̀ sí gbogbo ẹbọ rẹ.

14 Bí o bá fẹ́ fi àkọ́so oko rẹ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí OLUWA, ninu ṣiiri ọkà àkọ́so oko rẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa ni kí o ti mú, kí o yan án lórí iná.

15 Da òróró sí i, kí o sì fi turari sórí rẹ̀. Ẹbọ ohun jíjẹ ni.

16 Alufaa yóo bù ninu ọkà pípa ati òróró náà, pẹlu gbogbo turari orí rẹ̀, yóo sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ìrántí. Ẹbọ sísun sí OLUWA ni.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 3

Ẹbọ Alaafia

1 “Bí ẹnìkan bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia, tí ó sì mú ẹran láti inú agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ náà, kì báà jẹ́ akọ tabi abo, ó níláti jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n níwájú OLUWA.

2 Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹran náà, kí ó sì pa á lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí àwọn alufaa ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo.

3 Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,

4 ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n. Nígbà tí ó bá ń yọ kíndìnrín rẹ̀, yóo yọ ẹ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

5 Àwọn ọmọ Aaroni yóo sun wọ́n lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ; ẹbọ sísun ni, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA sì dùn sí.

6 “Bí ó bá jẹ́ pé aguntan tabi ewúrẹ́ ni yóo mú láti inú agbo ẹran rẹ̀ láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, kì báà jẹ́ akọ tabi abo ẹran, ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n.

7 Bí ó bá jẹ́ ọ̀dọ́ aguntan ni yóo fi rúbọ, kí ó mú un wá siwaju OLUWA,

8 kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; kí àwọn ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yípo.

9 Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá rẹ̀, gbogbo ọ̀rá tí ó wà ní ìrù rẹ̀ títí dé ibi egungun ẹ̀yìn rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo gbogbo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,

10 kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí ati gbogbo ẹ̀dọ̀ rẹ̀.

11 Alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA.

12 “Bí ó bá jẹ́ pé ewúrẹ́ ni yóo fi rú ẹbọ náà, kí ó mú un wá siwaju OLUWA,

13 kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; àwọn ọmọ Aaroni yóo sì da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo.

14 Yóo sì yọ àwọn nǹkan wọnyi ninu rẹ̀ láti fi rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA: gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ọ̀rá tí ó bo ìfun rẹ̀,

15 kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀.

16 Kí alufaa sun wọ́n lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn. Ti OLUWA ni gbogbo ọ̀rá ẹran.

17 Kí èyí jẹ́ ìlànà ayérayé fún àtìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín, pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tabi ẹ̀jẹ̀.”

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 4

Ẹbọ fún Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Eniyan Bá Ṣèèṣì Dá

1 OLUWA ní kí Mose

2 sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, ohun tí wọn óo ṣe nìyí:

3 “Bí ó bá jẹ́ alufaa tí a fi àmì òróró yàn ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì kó ẹ̀bi bá àwọn eniyan, kí ó fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLUWA, fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.

4 Yóo mú akọ mààlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA, yóo gbé ọwọ́ lé e lórí, yóo sì pa á níwájú OLUWA.

5 Alufaa náà yóo wá gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo gbé e wá sinu Àgọ́ Àjọ.

6 Yóo ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìkélé tí ó wà ní ibi mímọ́.

7 Lára ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ turari olóòórùn dídùn tí ó wà níwájú OLUWA, ninu Àgọ́ Àjọ. Yóo sì da ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà.

8 Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá akọ mààlúù tí ó fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀;

9 ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bo ibi ìbàdí ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀

10 (gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń yọ wọ́n lára mààlúù tí wọn ń fi rú ẹbọ alaafia), yóo sì sun wọ́n níná lórí pẹpẹ ẹbọ sísun.

11 Ṣugbọn awọ akọ mààlúù náà, ati gbogbo ẹran rẹ̀ ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ ati nǹkan inú rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀;

12 pátá ni yóo gbé jáde kúrò ninu àgọ́, lọ síbìkan tí ó bá mọ́, níbi tí wọn ń da eérú sí, yóo sì kó igi jọ, yóo dáná sun ún níbẹ̀.

13 “Tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí ẹ̀ṣẹ̀ náà kò hàn sí ìjọ eniyan, tí wọ́n bá ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun gbogbo tí OLUWA ti pa láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, tí wọ́n sì jẹ̀bi,

14 nígbà tí wọ́n bá mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, tí wọ́n sì rí àṣìṣe wọn, gbogbo ìjọ eniyan náà yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo fà á wá síbi Àgọ́ Àjọ.

15 Àwọn àgbààgbà ninu àwọn eniyan náà yóo gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ mààlúù yìí níwájú OLUWA, wọn óo sì pa á níbẹ̀.

16 Lẹ́yìn náà ni alufaa tí a fi òróró yàn yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yìí wá sinu Àgọ́ Àjọ.

17 Yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níbi mímọ́.

18 Yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ ní ìdí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

19 Yóo yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ yóo sì sun ún lórí pẹpẹ.

20 Bí ó ti ṣe akọ mààlúù tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo ṣe akọ mààlúù yìí pẹlu. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún wọn, OLUWA yóo sì dáríjì wọ́n.

21 Lẹ́yìn náà, alufaa yóo gbé mààlúù yìí jáde kúrò ninu àgọ́, yóo sì sun ún bí ó ti sun mààlúù ti àkọ́kọ́; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ eniyan náà.

22 “Bí ìjòyè kan bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi,

23 nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá yìí hàn án, yóo mú òbúkọ kan tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ.

24 Yóo gbé ọwọ́ lé orí òbúkọ yìí, yóo sì pa á níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú OLUWA; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

25 Alufaa yóo ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóo fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun; yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ.

26 Yóo sun gbogbo ọ̀rá òbúkọ náà lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í.

27 “Bí ẹnìkan lásán ninu àwọn eniyan náà bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA ti pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi,

28 lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá hàn án, yóo mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá.

29 Yóo gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, yóo sì pa á, níbi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ sísun.

30 Alufaa yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ.

31 Yóo yọ gbogbo ọ̀rá ewúrẹ́ náà, bí wọ́n ti ń yọ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia, alufaa yóo sì sun ún níná lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, OLUWA yóo sì dáríjì í.

32 “Bí ó bá jẹ́ pé, aguntan ni ó mú wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó níláti jẹ́ abo aguntan tí kò ní àbààwọ́n.

33 Kí ó gbé ọwọ́ lórí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun.

34 Lẹ́yìn náà alufaa yóo yán ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo wá da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ.

35 Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, bí wọ́n ti ń yọ́ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Alufaa yóo kó o lé orí ẹbọ náà, yóo sì fi iná sun ún lórí pẹpẹ fún OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá, OLUWA yóo sì dáríjì í.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 5

Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Ó Nílò Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀ṣẹ̀

1 “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀, nípa pé ó gbọ́ tí wọn ń kéde láàrin àwùjọ pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ nípa ọ̀ràn kan jáde wá láti jẹ́rìí, bí ó bá mọ ohunkohun nípa ọ̀ràn náà, kì báà jẹ́ pé ó rí i ni, tabi wọ́n sọ ohunkohun fún un nípa rẹ̀ ni, tí ó bá dákẹ́, tí kò sọ ohunkohun, yóo jẹ̀bi.

2 “Tabi bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú ẹranko tí ó jẹ́ aláìmọ́ ni, tabi òkú ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ aláìmọ́, tabi òkú ohunkohun tí ń fàyà fà nílẹ̀ tí ó jẹ́ aláìmọ́, bí kò tilẹ̀ mọ̀, sibẹ òun pàápàá di aláìmọ́, ó sì jẹ̀bi.

3 “Tabi bí ó bá fara kan ohun aláìmọ́ kan lára eniyan, ohun yòówù kí ohun náà jẹ́, ó ti sọ ẹni náà di aláìmọ́, bí irú ohun bẹ́ẹ̀ bá pamọ́ fún un, ìgbà yòówù tí ó bá mọ̀, ó jẹ̀bi.

4 “Tabi bí ẹnikẹ́ni bá fi ẹnu ara rẹ̀ búra láìronú, kì báà jẹ́ láti ṣe ibi ni, tabi láti ṣe rere, irú ìbúra kíbùúra tí eniyan lè ṣe láìmọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀, ó di ẹlẹ́bi.

5 “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí a ti dárúkọ wọnyi, kí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá,

6 kí ó sì mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ OLUWA fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Kí ó mú abo ọ̀dọ́ aguntan, tabi ti ewúrẹ́ wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

7 “Bí kò bá ní agbára láti mú ọ̀dọ́ aguntan wá, ohun tí ó tún lè mú tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun.

8 Kí ó kó wọn wá sọ́dọ̀ alufaa, kí alufaa sì fi ekinni rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lílọ́ ni kí alufaa lọ́ ọ lọ́rùn, ṣugbọn kí ó má fà á lọ́rùn tu.

9 Kí alufaa wọ́n díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara pẹpẹ, kí ó ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni.

10 Lẹ́yìn náà yóo fi ẹyẹ keji rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í.

11 “Ṣugbọn bí kò bá ní agbára láti mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji wá, ohun tí yóo mú wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni, ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ó má fi òróró tabi turari olóòórùn dídùn sórí rẹ̀, nítorí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni.

12 Kí ó gbé ìyẹ̀fun náà tọ alufaa wá, kí alufaa bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ sí OLUWA, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni.

13 Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, nítorí pé ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, OLUWA yóo sì dáríjì í. Ìyẹ̀fun yòókù yóo di ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ohun jíjẹ.”

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi

14 OLUWA sọ fún Mose pé:

15 “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ nípa pé kò san àwọn nǹkan tíí ṣe ti OLUWA fún OLUWA, ohun tí yóo mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún OLUWA ni: àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, láti inú agbo aguntan rẹ̀, ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn fadaka ninu ilé OLUWA ni wọn yóo lò láti fi díyelé àgbò náà; ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ni.

16 Yóo san ohun tí ó yẹ kí ó san fún OLUWA tí kò san, pẹlu èlé ìdámárùn-ún rẹ̀ fún alufaa, alufaa yóo sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un, a óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.

17 “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀, sibẹ ó jẹ̀bi, yóo sì san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

18 Kí ó mú àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n wá sí ọ̀dọ̀ alufaa, ó gbọdọ̀ rí i pé àgbò yìí tó iye tí wọn ń ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, alufaa yóo ṣe ètùtù fún un fún àṣìṣe rẹ̀ tí ó ṣèèṣì ṣe, OLUWA yóo sì dáríjì í.

19 Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá sí OLUWA ni.”

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 6

1 OLUWA sọ fún Mose, pé,

2 “Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nípa ṣíṣe èyíkéyìí ninu nǹkan wọnyi: kì báà jẹ́ pé ó kọ̀ láti dá ohun tí aládùúgbò rẹ̀ fi dógò pada ni, tabi pé ó ja aládùúgbò rẹ̀ lólè ni, tabi pé ó rẹ́ ẹ jẹ ni,

3 tabi pé ó rí nǹkan rẹ̀ tí ó sọnù he, tí ó sì ṣe bí ẹni pé òun kò rí i, tabi tí ó búra èké nípa ohunkohun, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó dá.

4 Bí ẹnikẹ́ni bá dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó dá ohun tí ó jí pada, tabi ohun tí ó fi ìrẹ́jẹ gbà, tabi ohun tí wọ́n fi dógò lọ́dọ̀ rẹ̀, tabi ohun tí ó sọnù tí ó rí he,

5 tabi ohunkohun tí ó ti búra èké sí. Kí ó san án pé pérépéré kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, nígbà tí ó bá dá ohun náà pada fún olúwarẹ̀, ní ọjọ́ tí yóo bá rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

6 Kí ó mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi tọ alufaa wá, ohun ìrúbọ náà ni àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, kí ó rí i pé àgbò náà tó iye tí eniyan lè ra ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

7 Alufaa yóo ṣe ètùtù fún ẹni náà níwájú OLUWA, OLUWA yóo sì dárí ohunkohun tí ó bá ṣe jì í.”

Ẹbọ Sísun Lódidi

8 OLUWA sọ fún Mose pé,

9 “Pa á láṣẹ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹbọ sísun: ẹbọ sísun níláti wà lórí ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iná sì níláti máa jò lórí pẹpẹ náà ní gbogbo ìgbà.

10 Kí alufaa wọ ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ funfun rẹ̀, ati ṣòkòtò aṣọ funfun, kí ó kó eérú ẹbọ tí ó ti fi iná sun kúrò lórí pẹpẹ, kí ó sì dà á sí ibìkan.

11 Lẹ́yìn náà, kí ó bọ́ aṣọ iṣẹ́ alufaa rẹ̀ kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí ó wá ru eérú náà jáde kúrò ninu àgọ́ sí ibi mímọ́ kan.

12 Kí iná orí pẹpẹ náà sì máa jó, kò gbọdọ̀ kú nígbà kan. Kí alufaa máa kó igi sí i ní àràárọ̀; kí ó máa to ẹbọ sísun lé e lórí, orí rẹ̀ ni yóo sì ti máa sun ọ̀rá ẹran tí ó bá fi rú ẹbọ alaafia.

13 Iná orí pẹpẹ náà gbọdọ̀ máa jó nígbà gbogbo, kò gbọdọ̀ kú.

Ẹbọ Ohun Jíjẹ

14 “Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ohun jíjẹ. Àwọn ọmọ Aaroni ni yóo máa rúbọ náà níwájú pẹpẹ, níwájú OLUWA.

15 Ọ̀kan ninu wọn yóo bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀, yóo sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA ni.

16 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo jẹ ìyókù, láì fi ìwúkàrà sí i. Ibi mímọ́ kan ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni wọ́n ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

17 Wọn kò gbọdọ̀ fi ìwúkàrà sí i, bí wọ́n bá fi ṣe burẹdi, èmi ni mo fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn ninu ẹbọ sísun mi; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ìmúkúrò ẹ̀bi.

18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọkunrin ninu àwọn ọmọ Aaroni lè jẹ ninu rẹ̀, èyí ni ìlànà mi títí ayérayé láàrin arọmọdọmọ yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ẹbọ wọnyi yóo di mímọ́.”

19 OLUWA sọ fún Mose pé,

20 “Ẹbọ tí àwọn ọmọ Aaroni yóo máa rú, ní ọjọ́ tí wọ́n bá fi wọ́n joyè alufaa nìyí: Ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, ìdajì rẹ̀ ní òwúrọ̀, ìdajì tí ó kù ní àṣáálẹ́.

21 Kí wọ́n fi òróró po ìyẹ̀fun náà dáradára, kí wọ́n tó yan án lórí ààrò, lẹ́yìn náà kí wọ́n rún un gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ, kí wọ́n sì fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.

22 Ẹni tí wọ́n bá yàn sí ipò olórí alufaa lẹ́yìn Aaroni ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo máa rú ẹbọ yìí sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí ìlànà títí lae, gbogbo ìyẹ̀fun náà ni yóo fi rú ẹbọ sísun.

23 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ninu ìyẹ̀fun ẹbọ ohun jíjẹ ti alufaa, gbogbo rẹ̀ ni kí wọ́n fi rú ẹbọ sísun.”

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀ṣẹ̀

24 OLUWA sọ fún Mose pé,

25 “Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran fún ẹbọ sísun, ni kí wọ́n ti máa pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ pẹlu, níwájú OLUWA; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.

26 Alufaa tí ó bá fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo jẹ ẹ́; níbi mímọ́, ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni kí ó ti jẹ ẹ́.

27 Ohunkohun tí ó bá ti kan ẹran rẹ̀ di mímọ́; nígbà tí wọ́n bá sì ta lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára aṣọ kan, ibi mímọ́ ni wọ́n ti gbọdọ̀ fọ aṣọ náà.

28 Fífọ́ ni wọ́n sì gbọdọ̀ fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n bá fi sè é, ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé ìkòkò idẹ ni wọ́n fi sè é, wọ́n gbọdọ̀ fi omi fọ̀ ọ́, kí wọ́n sì ṣàn án nù dáradára.

29 Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ alufaa tí ó bá jẹ́ ọkunrin lè jẹ ninu ohun ìrúbọ yìí; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ.

30 Ṣugbọn bí wọ́n bá mú ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu Àgọ́ Àjọ, tí wọ́n bá lò ó fún ètùtù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran náà, sísun ni wọ́n gbọdọ̀ sun ún.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 7

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi

1 “Èyí ni òfin ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

2 Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ; níbi tí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ sísun ni wọ́n gbọdọ̀ ti pa ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, wọn yóo sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ yípo.

3 Gbogbo ọ̀rá ara rẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ fi rúbọ; ìrù tí ó lọ́ràá ati ọ̀rá tí ó bo ìfun rẹ̀,

4 àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára wọn níbi ìbàdí ati àwọn tí ó bo ẹ̀dọ̀ ni wọn óo mú pẹlu àwọn kíndìnrín náà.

5 Alufaa yóo sun wọ́n lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun fún OLUWA, ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

6 Gbogbo ọkunrin, lára àwọn alufaa lè jẹ ninu rẹ̀, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.

7 “Ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi dàbí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, òfin kan ṣoṣo ni ó de oríṣìí ẹbọ mejeeji: òfin náà sì ni pé alufaa tí ó fi ṣe ètùtù ni ó ni ẹbọ náà.

8 Alufaa tí ó bá rú ẹbọ sísun fún eniyan ni ó ni awọ ẹran ẹbọ sísun náà.

9 Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a yan ati gbogbo èyí tí a sè ninu apẹ tabi ninu àwo pẹrẹsẹ jẹ́ ti alufaa tí ó fi wọ́n rúbọ.

10 Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò tabi tí ó jẹ́ ìyẹ̀fun, yóo wà fún àwọn ọmọ Aaroni bákan náà.

Ẹbọ Alaafia

11 “Èyí ni òfin ẹbọ alaafia, tí eniyan lè rú sí OLUWA.

12 Tí ó bá rú u fún ìdúpẹ́, yóo rú u pẹlu àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, tí a fi òróró pò, ati àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró lé lórí, pẹlu àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná ṣe, tí a fi òróró pò dáradára.

13 Ẹni tí ó bá rú ẹbọ alaafia fún ìdúpẹ́ yóo mú ẹbọ rẹ̀ wá pẹlu àkàrà tí ó ní ìwúkàrà.

14 Kí ó yọ àkàrà kọ̀ọ̀kan kúrò lára ẹbọ kọ̀ọ̀kan, kí ó fi rúbọ sí OLUWA; yóo jẹ́ ti alufaa tí ó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ alaafia náà sára pẹpẹ.

15 Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ ẹran ẹbọ alaafia tí ó fi ṣe ẹbọ ọpẹ́ tán ní ọjọ́ tí ó bá rú ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù di ọjọ́ keji.

16 “Ṣugbọn bí ẹbọ ọrẹ rẹ̀ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́ tabi ọrẹ àtinúwá, wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù, wọ́n lè jẹ ẹ́ ní ọjọ́ keji;

17 ṣugbọn bí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, sísun ni kí ó sun ún.

18 Bí wọ́n bá jẹ ninu ẹran ẹbọ alaafia tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, ẹbọ náà kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́wọ́ ẹni tí ó bá rú u, a kò ní kọ ọ́ sílẹ̀ fún un, nítorí pé ohun ìríra ni, ẹni tí ó bá jẹ ẹ́ ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

19 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ó bá kan ohun àìmọ́ kan, sísun ni ẹ gbọdọ̀ sun irú ẹran bẹ́ẹ̀.

“Gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ́ mímọ́ lè jẹ àwọn ẹran yòókù,

20 ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ lára ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, ní àkókò tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ aláìmọ́, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.

21 Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ìbáà ṣe ohun àìmọ́ ti eniyan, tabi ti ẹranko tabi ohun ìríra kan, lẹ́yìn náà tí ó wá jẹ ninu ẹran tí a fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, a óo yọ ẹni náà kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.”

22 OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé,

23 “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rákọ́ràá, ìbáà jẹ́ ti mààlúù tabi ti aguntan tabi ti ewúrẹ́.

24 Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tí ó kú fúnra rẹ̀ ati ọ̀rá èyí tí ẹranko burúkú pa, fún ohun mìíràn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

25 Nítorí pé a óo yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA, kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.

26 Siwaju sí i, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ibùgbé yín, bí ó ti wù kí ó rí; ìbáà jẹ́ ti ẹyẹ tabi ti ẹranko.

27 A óo yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan Ọlọrun.”

28 OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé,

29 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, yóo mú ẹbọ náà wá fún OLUWA. Ninu ẹbọ alaafia rẹ̀,

30 ni yóo ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ẹbọ sísun wá fún OLUWA. Ọ̀rá ẹran náà pẹlu àyà rẹ̀ ni yóo mú wá. Alufaa yóo fi àyà ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

31 Alufaa yóo sun ọ̀rá ẹran náà lórí pẹpẹ, ṣugbọn àyà rẹ̀ yóo jẹ́ ti Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀.

32 Ẹ óo fún alufaa ní itan ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ lára ẹbọ alaafia yín.

33 Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ Aaroni tí ó bá fi ẹ̀jẹ̀ ati ọ̀rá ẹran náà rúbọ ni ó ni itan ọ̀tún ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.

34 Nítorí mo ti gba àyà tí a fì ati itan tí a fi rúbọ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli lára ọrẹ ẹbọ alaafia wọn, yóo sì jẹ́ ti Aaroni, alufaa, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìpín tiwọn láti ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli.

35 Ìpín Aaroni ni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, lára ẹbọ sísun tí a rú sí OLUWA, àní ẹbọ tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ní ọjọ́ tí a mú wọn wá siwaju OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa.

36 Ní ọjọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti máa fún wọn, ó jẹ́ ìpín tiwọn láti ìrandíran.”

37 Òfin ẹbọ sísun ni, ati ti ẹbọ ohun jíjẹ, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, ti ẹbọ ìyàsímímọ́, ati ti ẹbọ alaafia;

38 tí OLUWA paláṣẹ fún Mose, ní orí òkè Sinai ní ọjọ́ tí ó pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti mú ẹbọ wọn wá fún òun OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 8

Ìyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 OLUWA sọ fún Mose pé,

2 “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati ẹ̀wù iṣẹ́ alufaa wọn, ati òróró ìyàsímímọ́, ati akọ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò meji náà, ati agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.

3 Lẹ́yìn náà, kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.”

4 Mose bá pe gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

5 Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA pàṣẹ pé ẹ gbọdọ̀ ṣe nìyí.”

6 Ó mú Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ jáde, ó fi omi wẹ̀ wọ́n.

7 Ó gbé ẹ̀wù náà wọ Aaroni, ó sì dì í ní àmùrè rẹ̀, ó gbé aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ wọ̀ ọ́ ati efodu rẹ̀, ó sì fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára dì í lámùrè.

8 Ó mú ìgbàyà, ó so ó mọ́ ọn láyà, ó sì fi Urimu ati Tumimu sí ara ìgbàyà náà.

9 Ó fi fìlà dé e lórí, ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà, adé mímọ́ tíí ṣe àmì ìyàsímímọ́, sí iwájú fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún Mose.

10 Mose gbé òróró ìyàsímímọ́, ó ta á sí gbogbo ara Àgọ́ náà ati ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, ó sì yà wọ́n sí mímọ́.

11 Ó mú lára òróró náà ó wọ́n ọn sí ara pẹpẹ nígbà meje, ó ta á sórí pẹpẹ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò tí wọ́n wà níbẹ̀, ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀; ó fi yà wọ́n sí mímọ́.

12 Ó ta díẹ̀ ninu òróró náà sí Aaroni lórí láti yà á sí mímọ́.

13 Mose kó àwọn ọmọ Aaroni, ó wọ̀ wọ́n lẹ́wù, ó sì dì wọ́n ní àmùrè, ó dé wọn ní fìlà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

14 Lẹ́yìn náà, ó mú mààlúù ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ jáde, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin gbé ọwọ́ lé e lórí.

15 Mose pa mààlúù náà, ó gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ti ìka bọ̀ ọ́, ó sì fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ yípo, ó fi yà wọ́n sí mímọ́. Ó da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ fún ètùtù, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yà wọ́n sí mímọ́.

16 Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú mààlúù náà, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tó wà lára wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ.

17 Ṣugbọn ó dáná sun ara ẹran akọ mààlúù náà, ati awọ rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

18 Lẹ́yìn náà, Mose fa àgbò ẹbọ sísun kalẹ̀, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin sì gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

19 Lẹ́yìn náà, Mose pa á, ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yípo.

20 Wọ́n gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sun gbogbo rẹ̀ pẹlu orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ lórí pẹpẹ.

21 Nígbà tí ó fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó fi gbogbo rẹ̀ rú ẹbọ sísun, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

22 Lẹ́yìn náà, ó fa àgbò keji kalẹ̀, èyí tí í ṣe àgbò ìyàsímímọ́. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ wọn lé e lórí.

23 Lẹ́yìn náà Mose pa á, ó tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó fi kan etí ọ̀tún Aaroni, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

24 Wọ́n mú àwọn ọmọ Aaroni náà jáde, Mose tọ́ ninu ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi kan etí ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sórí pẹpẹ yípo.

25 Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá àgbò náà, ati ọ̀rá ìrù rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀, ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ati itan ọ̀tún rẹ̀.

26 Ó mú burẹdi dídùn kan tí kò ní ìwúkàrà ninu, ninu agbọ̀n burẹdi tí ó wà níwájú OLUWA, ati burẹdi olóròóró kan tí kò ní ìwúkàrà ninu ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan, ó kó wọn lé orí ọ̀rá náà ati itan ọ̀tún àgbò náà.

27 Ó kó gbogbo rẹ̀ lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

28 Lẹ́yìn náà, Mose gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sísun bí ẹbọ ìyàsímímọ́, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLÚWA.

29 Mose mú igẹ̀ àyà àgbò náà, ó fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Òun ni ìpín Mose ninu àgbò ìyàsímímọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un.

30 Lẹ́yìn náà, Mose mú ninu òróró ìyàsímímọ́, ati díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sí ara Aaroni ati aṣọ rẹ̀, ati sí ara àwọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ya Aaroni ati àwọn aṣọ rẹ̀ sí mímọ́, ati àwọn ọmọ rẹ̀, tàwọn taṣọ wọn.

31 Mose bá sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin pé, “Ẹ lọ bọ ẹran àgbò náà lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀, pẹlu burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n ọrẹ ẹbọ ìyàsímímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé: ‘Aaroni ati ọmọ rẹ̀ ni kí wọ́n máa jẹ ẹ́’.

32 Ohunkohun tí ó bá kù ninu ẹran ati burẹdi náà, ẹ dáná sun ún.

33 Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà fún ọjọ́ meje títí tí ọjọ́ ètò ìyàsímímọ́ yín yóo fi pé; nítorí ọjọ́ meje gbáko ni ètò ìyàsímímọ́ yín yóo gbà.

34 Gbogbo bí a ti ṣe lónìí ni OLUWA pa láṣẹ pé kí á ṣe, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

35 Lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ni kí ẹ wà tọ̀sán-tòru fún ọjọ́ meje, kí ẹ máa ṣe àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ fun yín, kí ẹ má baà kú; nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó pa á láṣẹ fún mi.”

36 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ láti ẹnu Mose.

Categories
LEFITIKU

LEFITIKU 9

Aaroni Rúbọ sí OLUWA

1 Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati àwọn àgbààgbà Israẹli;

2 ó wí fún Aaroni pé, “Mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun kí o sì fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA. Àwọn ẹran mejeeji yìí kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.

3 Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.

4 Sì mú akọ mààlúù kan ati àgbò kan fún ẹbọ alaafia, kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò, nítorí pé OLUWA yóo fi ara hàn yín lónìí.’ ”

5 Wọ́n mú àwọn ohun tí Mose paláṣẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ, gbogbo ìjọ eniyan sì dúró níwájú OLUWA.

6 Mose sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ fun yín láti ṣe nìyí, ògo OLUWA yóo hàn sí yín.”

7 Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”

8 Aaroni bá súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó pa ọ̀dọ́ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.

9 Àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá fún un, ó sì ti ìka bọ̀ ọ́, ó fi kan ara ìwo pẹpẹ, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ.

10 Ó mú ọ̀rá ọ̀dọ́ mààlúù náà, ati àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ kúrò ninu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

11 Ó sì dáná sun ẹran ati awọ mààlúù náà lẹ́yìn ibùdó.

12 Ó pa ẹran ẹbọ sísun, àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì dà á sí ara pẹpẹ yípo.

13 Wọ́n gbé ẹran ẹbọ sísun tí wọ́n ti gé sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.

14 Ó fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun wọ́n papọ̀ pẹlu ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.

15 Lẹ́yìn náà ó fa ẹran ẹbọ sísun àwọn eniyan náà kalẹ̀, ó mú ewúrẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan náà, ó pa á, ó sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ti àkọ́kọ́.

16 Ó gbé ẹran ẹbọ sísun wá, ó sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

17 Ó gbé ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀.

18 Ó pa akọ mààlúù ati àgbò ẹbọ alaafia fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì dà á sórí pẹpẹ náà yípo.

19 Ó mú ọ̀rá akọ mààlúù, ati ti àgbò náà, pẹlu ìrù wọn tí ó lọ́ràá, ati ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú wọn, ati kíndìnrín ati ẹ̀dọ̀ wọn.

20 Ó kó gbogbo ọ̀rá náà lé orí igẹ̀ ẹran náà; ó sun ún lórí pẹpẹ.

21 Ṣugbọn ó mú àwọn igẹ̀ ẹran náà ati itan ọ̀tún wọn, ó fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, bí Mose ti pa á láṣẹ.

22 Lẹ́yìn náà, Aaroni kọjú sí àwọn eniyan náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi tí ó ti ń rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia.

23 Mose ati Aaroni bá wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn eniyan náà, ògo OLUWA sì yọ sí gbogbo wọn.

24 Lójijì, iná ṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ó jó ẹbọ sísun náà, ati ọ̀rá tí ó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n kígbe sókè, wọ́n sì dojúbolẹ̀.