Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 20

Dafidi Ṣẹgun Raba

1 Nígbà tí àkókò òtútù kọjá, ní àkókò tí àwọn ọba máa ń lọ jagun, Joabu gbógun ti ilẹ̀ Amoni; wọ́n dó ti ìlú Raba. Ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Joabu gbógun ti Raba, ó sì ṣẹgun rẹ̀.

2 Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, ó sì rí i pé adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, òkúta olówó iyebíye kan sì wà lára rẹ̀; wọ́n bá fi dé Dafidi lórí. Dafidi sì tún kó ọpọlọpọ ìkógun mìíràn ninu ìlú náà.

3 Ó kó àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu ìlú náà, ó sì ń fi wọ́n ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́: Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn kan ń lo ọkọ́, àwọn mìíràn sì ń lo àáké. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe sí gbogbo àwọn ìlú Amoni. Òun ati àwọn eniyan rẹ̀ bá pada sí Jerusalẹmu.

Bíbá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun

4 Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri, láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Sibekai, ará Huṣati, pa ìran òmìrán kan, ará Filistia, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sipai, àwọn ará Israẹli bá ṣẹgun àwọn ará Filistia.

5 Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, Elihanani, ọmọ Jairi, pa Lahimi, arakunrin Goliati, ará Gati, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ tóbi tó òpó òfì ìhunṣọ.

6 Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Ọkunrin gbọ̀ngbọ̀nràn kan wà níbẹ̀, ìka mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan ati ní ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ òmìrán ni òun náà.

7 Nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹlẹ́yà, Jonatani, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi bá pa á.

8 Ìran òmìrán, ará Gati ni àwọn mẹtẹẹta; Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 21

Dafidi Ṣe Ètò Ìkànìyàn

1 Satani fẹ́ ta jamba fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí náà ó gbó Dafidi láyà láti kà wọ́n.

2 Dafidi sọ fún Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pé, “Ẹ lọ ka àwọn ọmọ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, kí ẹ wá fún mi lábọ̀, kí n lè mọ iye wọn.”

3 Ṣugbọn Joabu dáhùn pé, “Kí Ọlọrun jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ síi ní ìlọ́po ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un, ju iye tí wọ́n jẹ́ nisinsinyii lọ! Kabiyesi, ṣebí abẹ́ ìwọ oluwa mi ni gbogbo wọn wà? Kí ló wá dé tí o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló dé tí o fi fẹ́ mú àwọn ọmọ Israẹli jẹ̀bi?”

4 Ṣugbọn ti ọba ni ó ṣẹ, Joabu bá lọ kà wọ́n jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì pada wá sí Jerusalẹmu.

5 Joabu fún ọba ní iye àwọn ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ marundinlọgọta (1,100,000) ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, ati ọ̀kẹ́ mẹtalelogun ó lé ẹgbaarun (470,000) ninu àwọn ẹ̀yà Juda.

6 Nítorí pé àṣẹ tí ọba pa yìí burú lójú Joabu, kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi ati ti Bẹnjamini.

7 Inú Ọlọrun kò dùn sí ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà ó jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà.

8 Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, níti ohun tí mo ṣe yìí. Mo sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ji èmi iranṣẹ rẹ, nítorí pé ìwà òmùgọ̀ ni mo hù.”

9 Ọlọrun bá rán Gadi, aríran Dafidi pé,

10 “Lọ sọ fún Dafidi pé, ‘OLUWA ní, nǹkan mẹta ni òun fi siwaju rẹ, kí o yan èyí tí o bá fẹ́ kí òun ṣe sí ọ ninu wọn.’ ”

11 Gadi bá lọ sọ́dọ̀ Dafidi ó lọ sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o yan èyí tí o bá fẹ́ ninu àwọn nǹkan mẹta wọnyi:

12 yálà kí ìyàn mú fún ọdún mẹta, tabi kí àwọn ọ̀tá rẹ máa lé ọ kiri, kí wọ́n sì máa fi idà pa yín fún oṣù mẹta, tabi kí idà OLUWA kọlù ọ́ fún ọjọ́ mẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ náà, kí angẹli Ọlọrun sì máa paniyan jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Sọ èyí tí o bá fẹ́, kí n lè mọ ohun tí n óo sọ fún ẹni tí ó rán mi.”

13 Nígbà náà ni Dafidi wí fún Gadi pé, “Ìdààmú ńlá dé bá mi, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Ọlọrun, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀; má jẹ́ kí n bọ́ sí ọwọ́ eniyan.”

14 Nítorí náà, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn sórí ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n kú sì jẹ́ ẹgbaa marundinlogoji (70,000) eniyan.

15 Ọlọrun rán angẹli kan pé kí ó lọ pa Jerusalẹmu run; ṣugbọn bí ó ti fẹ́ pa á run, OLUWA rí i, ó sì yí ọkàn pada, ó wí fún apanirun náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Angẹli OLUWA náà bá dúró níbi ìpakà Onani ará Jebusi.

16 Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀.

17 Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣebí èmi ni mo pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ka àwọn eniyan? Èmi ni mo ṣẹ̀, tí mo sì ṣe nǹkan burúkú. Kí ni àwọn aguntan wọnyi ṣe? OLUWA, Ọlọrun mi, mo bẹ̀ ọ́, èmi ati ilé baba mi ni kí o jẹ níyà, má jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn eniyan rẹ.”

18 Angẹli OLUWA bá pàṣẹ fún Gadi pé kí ó lọ sọ fún Dafidi pé kí ó lọ tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi.

19 Dafidi bá dìde gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Gadi, tí ó sọ ní orúkọ OLÚWA.

20 Onani ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mẹrin wà níbi tí wọ́n ti ń pakà. Nígbà tí wọ́n rí angẹli náà, wọ́n sápamọ́.

21 Bí Dafidi ti dé ọ̀dọ̀ Onani, tí Onani rí i, ó kúrò níbi tí ó ti ń pa ọkà, ó lọ tẹríba fún Dafidi, ó dojúbolẹ̀.

22 Dafidi sọ fún un pé, “Ta ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA. Iye tí ó bá tó gan-an ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn yìí lè dáwọ́ dúró.”

23 Onani dá Dafidi lóhùn pé, “olúwa mi, mú gbogbo rẹ̀, kí o sì ṣe ohun tí o bá fẹ́ níbẹ̀. Wò ó, mo tún fún ọ ní àwọn akọ mààlúù yìí fún ẹbọ sísun, ati pákó ìpakà fún dídá iná ẹbọ sísun, ati ọkà fún ẹbọ ohun jíjẹ. Mo bùn ọ́ ní gbogbo rẹ̀.”

24 Ṣugbọn Dafidi ọba dá Onani lóhùn pé, “Rárá o, mo níláti ra gbogbo rẹ̀ ní iye tí ó bá tó gan-an ni. N kò ní fún OLUWA ní nǹkan tí ó jẹ́ tìrẹ, tabi kí n rú ẹbọ tí kò ná mi ní ohunkohun sí OLUWA.”

25 Nítorí náà, Dafidi fún Onani ní ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli wúrà, fún ilẹ̀ ìpakà náà.

26 Dafidi tẹ́ pẹpẹ níbẹ̀, ó rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, ó bá képe OLUWA. OLUWA dá a lóhùn: ó rán iná sọ̀kalẹ̀ láti jó ẹbọ sísun náà.

27 OLUWA pàṣẹ fún angẹli náà pé kí ó ti idà rẹ̀ bọ inú àkọ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

28 Nígbà tí Dafidi rí i pé OLUWA ti gbọ́ adura rẹ̀ ní ibi ìpakà Onani ará Jebusi, ó bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ rẹ̀ níbẹ̀.

29 Títí di àkókò yìí, àgọ́ OLUWA tí Mose pa ní aṣálẹ̀, ati pẹpẹ ẹbọ sísun wà ní ibi pẹpẹ ìrúbọ ní Gibeoni.

30 Ṣugbọn Dafidi kò lè lọ sibẹ láti wádìí lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí ó ń bẹ̀rù idà angẹli OLUWA.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 22

1 Nítorí náà Dafidi pàṣẹ pé, “Ibí yìí ni ilé OLUWA Ọlọrun, ati pẹpẹ ẹbọ sísun yóo wà fún Israẹli.”

Ìpalẹ̀mọ́ fún Kíkọ́ Tẹmpili

2 Dafidi pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli péjọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn ṣiṣẹ́, ara wọn ni wọ́n gbẹ́ òkúta fún kíkọ́ tẹmpili.

3 Ó kó ọpọlọpọ irin jọ, tí wọn óo fi rọ ìṣó, tí wọn yóo fi kan àwọn ìlẹ̀kùn ati ìdè, ó kó idẹ jọ lọpọlọpọ pẹlu, ju ohun tí ẹnikẹ́ni lè wọ̀n lọ,

4 ati ọpọlọpọ igi kedari. Ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò le kà wọ́n, nítorí pé ọpọlọpọ igi kedari ni àwọn ará Sidoni ati Tire kó wá fún Dafidi.

5 Nítorí pe Dafidi ní, “Tẹmpili tí a óo kọ́ fún OLUWA gbọdọ̀ dára tóbẹ́ẹ̀ tí òkìkí rẹ̀ yóo kàn ká gbogbo ayé; bẹ́ẹ̀ sì ni Solomoni, ọmọ mi, tí yóo kọ́ ilé náà kéré, kò sì tíì ní ìrírí pupọ. Nítorí náà, n óo tọ́jú àwọn ohun èlò sílẹ̀ fún un.” Dafidi bá tọ́jú àwọn nǹkan tí wọn yóo lò sílẹ̀ lọpọlọpọ kí ó tó kú.

6 Dafidi bá pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó pàṣẹ fún un pé kí ó kọ́ ilé kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

7 Ó ní, “Ọmọ mi, mo ní i lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili kan fún orúkọ OLUWA Ọlọrun mi,

8 ṣugbọn OLUWA sọ fún mi pé mo ti ta ọpọlọpọ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, mo sì ti ja ọpọlọpọ ogun; nítorí ọpọlọpọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà, òun kò ní gbà pé kí n kọ́ tẹmpili òun.

9 OLUWA ní n óo bí ọmọkunrin kan tí ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ ìjọba alaafia, ó ní òun óo fún un ní alaafia, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíká kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu. Solomoni ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. Ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo wà ní alaafia ati àìléwu.

10 Ó ní ọmọ náà ni yóo kọ́ ilé fún òun. Yóo jẹ́ ọmọ òun, òun náà yóo sì jẹ́ baba rẹ̀. Ó ní òun óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Israẹli títí lae.

11 “Nisinsinyii, ìwọ ọmọ mi, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ, kí o lè kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun rẹ fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.

12 Kí OLUWA fún ọ ní ọgbọ́n ati làákàyè kí o lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́ nígbà tí ó bá fi ọ́ jọba lórí Israẹli.

13 Bí o bá pa gbogbo òfin tí Ọlọrun fún Israẹli láti ọwọ́ Mose mọ́, o óo ṣe rere. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́.

14 Mo ti sa gbogbo agbára mi láti tọ́jú ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) talẹnti wúrà kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé OLUWA, aadọta ọ̀kẹ́ (1,000,000) talẹnti fadaka, ati idẹ, ati irin tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè wọ̀n. Mo ti tọ́jú òkúta ati pákó pẹlu. O gbọdọ̀ wá kún un.

15 O ní ọpọlọpọ òṣìṣẹ́: àwọn agbẹ́kùúta, àwọn ọ̀mọ̀lé, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati oríṣìíríṣìí àwọn oníṣẹ́ ọnà tí kò lóǹkà,

16 àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti idẹ, ati ti irin. Bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà nisinsinyii! Kí OLUWA wà pẹlu rẹ!”

17 Dafidi pàṣẹ fún gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli pé kí wọ́n ran Solomoni, ọmọ òun lọ́wọ́.

18 Ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA Ọlọrun yín kò ha wà pẹlu yín? Ǹjẹ́ kò ti fun yín ní ìfọ̀kànbalẹ̀ káàkiri? Nítorí pé ó ti jẹ́ kí n ṣẹgun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, ilẹ̀ náà sì wà lábẹ́ àkóso OLUWA ati ti àwọn eniyan rẹ̀.

19 Nítorí náà, ẹ fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun yín nisinsinyii. Ẹ múra kí ẹ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA ati gbogbo ohun èlò mímọ́ fún ìsìn Ọlọrun lọ sinu ilé tí ẹ óo kọ́ fún OLUWA.”

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 23

1 Nígbà tí Dafidi dàgbà, tí ó di arúgbó, ó fi Solomoni, ọmọ rẹ̀ jọba lórí Israẹli.

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi

2 Dafidi pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn alufaa ati àwọn Lefi jọ.

3 Ó ka gbogbo àwọn Lefi tí wọ́n jẹ́ ọkunrin tí wọ́n dàgbà tó ọmọ ọgbọ̀n ọdún sókè, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa mọkandinlogun (38,000).

4 Dafidi fún ẹgbaa mejila (24,000) ninu wọn ní iṣẹ́ ninu tẹmpili; ó ní kí ẹgbaata (6,000) máa ṣe àkọsílẹ̀ ati ìdájọ́ àwọn eniyan,

5 kí ẹgbaaji (4,000) máa ṣọ́nà, kí ẹgbaaji (4,000) sì máa yin OLUWA pẹlu oríṣìíríṣìí ohun èlò orin tí ọba pèsè.

6 Dafidi pín àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé ìdílé: ti Geriṣomu, ti Kohati, ati ti Merari.

7 Àwọn ọmọ Geriṣomu jẹ́ meji: Ladani ati Ṣimei;

8 Àwọn ọmọ Ladani jẹ́ mẹta: Jeieli tí ó jẹ́ olórí, Setamu ati Joẹli.

9 Àwọn ọmọ Ṣimei ni Ṣelomoti, Hasieli, ati Harani; àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí ìdílé Ladani.

10 Àwọn ọmọ Ṣimei jẹ́ mẹrin: Jahati, Sina, Jeuṣi, ati Beraya.

11 Jahati ni ó jẹ́ olórí, Sisa ni igbákejì rẹ̀, ṣugbọn Jeuṣi ati Beraya kò bí ọmọ pupọ, nítorí náà ni wọ́n fi kà wọ́n sí ìdílé kan ninu ọ̀kan ninu àwọn àkọsílẹ̀.

12 Àwọn ọmọ Kohati jẹ́ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli,

13 Àwọn ọmọ Amramu ni Aaroni ati Mose. Aaroni ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, pé kí òun ati àwọn ìran rẹ̀ títí lae máa sun turari níwájú OLUWA, kí wọ́n máa darí ìsìn OLUWA, kí wọ́n sì máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ rẹ̀ títí lae.

14 A ka àwọn ọmọ Mose, iranṣẹ Ọlọrun, pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà Lefi.

15 Mose bí ọmọkunrin meji: Geriṣomu ati Elieseri.

16 Àwọn ọmọ Geriṣomu ni: Ṣebueli, olórí ìdílé Geriṣomu.

17 Elieseri bí ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Rehabaya, olórí ìdílé rẹ̀, kò sì bí ọmọ mìíràn mọ́, ṣugbọn àwọn ọmọ Rehabaya pọ̀.

18 Iṣari bí ọmọkunrin kan, Ṣelomiti, tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀.

19 Heburoni bí ọmọ mẹrin: Jeraya, tí ó jẹ́ olórí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Amaraya, Jahasieli, Jekameamu.

20 Usieli bí ọmọ meji: Mika, tí ó jẹ́ olórí, ati Iṣaya.

21 Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Mahili bí ọmọkunrin meji: Eleasari ati Kiṣi,

22 Ṣugbọn Eleasari kú láì ní ọmọkunrin kankan; kìkì ọmọbinrin ni ó bí. Àwọn ọmọbinrin rẹ̀ bá fẹ́ àwọn ọmọ Kiṣi, àbúrò baba wọn.

23 Àwọn ọmọ Muṣi jẹ́ mẹta: Mahili, Ederi ati Jeremotu.

24 Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.

25 Dafidi ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi, yóo sì máa gbé Jerusalẹmu títí lae.

26 Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”

27 Gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi ti ṣe, iye àwọn ọmọ Lefi láti ogún ọdún sókè nìyí:

28 Ṣugbọn iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, láti máa ṣe ìtọ́jú àgbàlá ati àwọn yàrá ibẹ̀, láti rí i pé àwọn ohun èlò ilé OLUWA wà ní mímọ́, ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó yẹ ninu ilé OLUWA.

29 Àwọn ni wọ́n tún ń ṣe ètò ṣíṣe burẹdi ìfihàn, ìyẹ̀fun fún ẹbọ ohun jíjẹ, àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ninu, àkàrà díndín fún ẹbọ, ẹbọ tí a po òróró mọ́, ati pípèsè àwọn oríṣìíríṣìí ìwọ̀n.

30 Wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA ní àràárọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́,

31 ati nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń rúbọ sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ oṣù titun, tabi ọjọ́ àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí a yàn láti máa kọrin níwájú OLUWA nígbà gbogbo.

32 Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa bojútó Àgọ́ Àjọ ati ibi mímọ́, tí wọn yóo sì máa ran àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́, níbi iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 24

Iṣẹ́ Àwọn Alufaa

1 Bí a ṣe pín àwọn ọmọ Aaroni nìyí: Aaroni ní ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

2 Nadabu ati Abihu kú ṣáájú baba wọn láì bí ọmọ kankan. Nítorí náà, Eleasari, ati Itamari di alufaa.

3 Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari ati Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi pín àwọn ọmọ Aaroni sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn.

4 Àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé pọ̀ ninu àwọn ọmọ Eleasari ju ti Itamari lọ, nítorí náà, wọ́n pín àwọn ọmọ Eleasari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹrindinlogun, wọ́n sì pín àwọn ọmọ Itamari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹjọ. Bí wọ́n ṣe pín wọn kò sì fì sí ibìkan nítorí pé

5 gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi yàn wọ́n, nítorí pé, bí àwọn alámòójútó ìsìn ati alámòójútó iṣẹ́ ilé Ọlọrun ṣe wà ninu àwọn ìran Eleasari, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wà ninu ti Itamari.

6 Ṣemaaya, akọ̀wé, ọmọ Netaneli, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó kọ orúkọ wọn sílẹ̀ níwájú ọba ati àwọn ìjòyè, ati Sadoku, alufaa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati àwọn baálé baálé ninu ìdílé àwọn alufaa, ati ti àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n bá ti mú ọ̀kan láti inú ìran Eleasari, wọn á sì tún mú ọ̀kan láti ìran Itamari.

7 Gègé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ mú Jehoiaribu, ekeji mú Jedaaya. Gègé sì mú àwọn yòókù wọnyi tẹ̀léra wọn báyìí:

8 Harimu, Seorimu;

9 Malikija, Mijamini;

10 Hakosi, Abija,

11 Jeṣua, Ṣekanaya;

12 Eliaṣibu, Jakimu,

13 Hupa, Jeṣebeabu;

14 Biliga, Imeri,

15 Hesiri, Hapisesi;

16 Petahaya, Jehesikeli,

17 Jakini, Gamuli;

18 Delaaya, Maasaya.

19 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n óo ṣe tẹ̀léra wọn níbi iṣẹ́ ṣíṣe ninu ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Aaroni, baba wọn, ti là sílẹ̀ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun pa fún Israẹli.

Orúkọ Àwọn Ọmọ Lefi

20 Àwọn olórí ninu ìdílé àwọn ọmọ Lefi yòókù nìwọ̀nyí: Ṣubaeli láti inú ìdílé Amramu,

Jedeaya láti inú ìdílé Ṣubaeli.

21 Iṣaya tí ó jẹ́ olórí láti inú ìdílé Rehabaya,

22 Ṣelomiti láti inú ìdílé Iṣari, Jahati láti inú ìdílé Ṣelomiti.

23 Àwọn ọmọ Heburoni jẹ́ mẹrin: Jeraya ni olórí wọn, bí àwọn yòókù wọn ṣe tẹ̀léra nìyí: Amaraya, Jahasieli ati Jekameamu.

24 Mika láti inú ìdílé Usieli, Ṣamiri láti inú ìdílé Mika.

25 Iṣaya ni arakunrin Mika. Sakaraya láti inú ìdílé Iṣaya.

26 Mahili ati Muṣi láti inú ìdílé Merari.

27 Àwọn ọmọ Merari láti inú ìdílé Jaasaya ni Beno ati Ṣohamu, Sakuri ati Ibiri.

28 Eleasari láti inú ìdílé Mahili, Eleasari kò bí ọmọkunrin kankan.

29 Jerameeli ọmọ Kiṣi, láti ìdílé Kiṣi.

30 Muṣi ní ọmọkunrin mẹta: Mahili, Ederi, ati Jerimotu. Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ Lefi nìyí, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

31 Àwọn olórí ìdílé náà ṣẹ́ gègé gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn ti ṣe, níwájú ọba Dafidi, ati Sadoku, ati Ahimeleki, pẹlu àwọn olórí ninu ìdílé alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 25

Àwọn Akọrin Inú Tẹmpili

1 Dafidi ati àwọn olórí ogun ya àwọn kan sọ́tọ̀ ninu àwọn ọmọ Asafu, Hemani ati ti Jedutuni láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fi dùùrù, ati hapu ati aro kọrin. Àkọsílẹ̀ àwọn tí a yàn ati iṣẹ́ wọn nìyí:

2 Lára àwọn ọmọ Asafu wọ́n yan Sakuri, Josẹfu, Netanaya, ati Asarela; wọ́n wà lábẹ́ àkóso Asafu, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ àkóso ọba.

3 Àwọn ọmọ Jedutuni jẹ́ mẹfa: Gedalaya, Seri, ati Jeṣaaya; Ṣimei, Haṣabaya ati Matitaya, abẹ́ àkóso Jedutuni, baba wọn, ni wọ́n wà, wọn a sì máa fi dùùrù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ninu orin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.

4 Àwọn ọmọ Hemani ni: Bukaya, Matanaya, Usieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananaya, Hanani, Eliata, Gidaliti, ati Romamiti Eseri, Joṣibekaṣa, Maloti, Hotiri, ati Mahasioti.

5 Ọmọ Hemani, aríran ọba, ni gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Ọlọrun ṣe láti gbé Hemani ga; Ọlọrun fún un ní ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.

6 Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń lu aro ati hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù lábẹ́ àkóso baba wọn ninu ìsìn ninu ilé Ọlọrun. Ṣugbọn Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà lábẹ́ àkóso ọba.

7 Àpapọ̀ wọn pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí a ti kọ́ ní orin kíkọ sí OLUWA, ati lílo ohun èlò orin, jẹ́ ọọdunrun ó dín mejila (288).

8 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi mọ iṣẹ́ olukuluku; ati kékeré ati àgbà, ati olùkọ́ ati akẹ́kọ̀ọ́.

9 Gègé kinni tí wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé Asafu mú Josẹfu; ekeji mú Gedalaya, òun ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ́ mejila.

10 Ẹkẹta mú Sakuri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

11 Ẹkẹrin mú Isiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

12 Ẹkarun-un mú Netanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

13 Ẹkẹfa mú Bukaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

14 Ekeje mú Jeṣarela, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

15 Ẹkẹjọ mú Jeṣaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

16 Ẹkẹsan-an mú Matanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

17 Ẹkẹwaa mú Ṣimei, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

18 Ikọkanla mú Asareli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

19 Ekejila mú Haṣabaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

20 Ẹkẹtala mú Ṣubaeli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

21 Ẹkẹrinla mú Matitaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

22 Ẹkẹẹdogun mú Jeremotu, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

23 Ẹkẹrindinlogun mu Hananaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

24 Ẹkẹtadinlogun mú Joṣibekaṣa, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

25 Ekejidinlogun mú Hanani, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

26 Ikọkandinlogun mú Maloti, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

27 Gègé ogún mú Eliata, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

28 Ikọkanlelogun mú Hotiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

29 Ekejilelogun mú Gidaliti, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

30 Ẹkẹtalelogun mú Mahasioti, òun ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

31 Ẹkẹrinlelogun mú Romamiti Eseri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 26

Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili

1 Bí a ti ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà nìwọ̀nyí: Meṣelemaya, ọmọ Kore, ní ìdílé Asafu, ninu ìran Kora.

2 Meṣelemaya bí ọmọ meje, orúkọ wọn nìyí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, Sakaraya ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Jediaeli, Sebadaya, ati Jatinieli;

3 Elamu, Jehohanani ati Eliehoenai.

4 Ọmọ mẹjọ ni Obedi Edomu bí nítorí pé Ọlọrun bukun un. Orúkọ àwọn ọmọ náà nìyí, bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí: Ṣemaaya, Jehosabadi, ati Joa; Sakari, ati Netaneli;

5 Amieli, Isakari, ati Peuletai.

6 Ṣemaaya, àkọ́bí Obedi Edomu, bí ọmọ mẹfa, àwọn ni olórí ninu ìdílé wọn nítorí pé alágbára eniyan ni wọ́n.

7 Orúkọ wọn ni: Otini, Refaeli, Obedi, ati Elisabadi, ati àwọn arakunrin wọn, Elihu ati Semakaya, tí wọ́n jẹ́ alágbára eniyan.

8 Gbogbo àwọn arọmọdọmọ Obedi Edomu, ati àwọn ọmọ wọn, pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí wọ́n yẹ láti ṣiṣẹ́ jẹ́ mejilelọgọta.

9 Àwọn ọmọ Meṣelemaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí wọ́n lágbára jẹ́ mejidinlogun.

10 Hosa, láti inú ìran Merari bí ọmọkunrin mẹrin: Ṣimiri (ni baba rẹ̀ fi ṣe olórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí);

11 lẹ́yìn rẹ̀ Hilikaya, Tebalaya ati Sakaraya. Gbogbo àwọn ọmọ Hosa ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mẹtala.

12 Gbogbo àwọn aṣọ́nà tẹmpili ni a pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. A pín iṣẹ́ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí a ti pín iṣẹ́ fún àwọn arakunrin wọn yòókù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.

13 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki.

14 Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá.

15 Obedi Edomu ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà gúsù; àwọn ọmọ rẹ̀ ni a sì yàn láti máa ṣọ́ ilé ìṣúra.

16 Gègé mú Ṣupimu ati Hosa fún ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ati ẹnu ọ̀nà Ṣaleketi, ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí òkè. Olukuluku àwọn aṣọ́nà ni ó ní àkókò iṣẹ́ tirẹ̀.

17 Àwọn eniyan mẹfa ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ní ojoojumọ, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà àríwá, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà gúsù, àwọn meji meji sì ń ṣọ́ ilé ìṣúra.

18 Fún àgọ́ tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ojú ọ̀nà, àwọn meji sì ń ṣọ́ àgọ́ alára.

19 Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà láti inú ìran Kora ati ti Merari.

Àwọn Iṣẹ́ Mìíràn ninu Tẹmpili

20 Ahija, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ibi tí wọn ń kó àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun sí.

21 Ladani, ọ̀kan ninu ìran Geriṣoni, ní àwọn ọmọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé wọn, ọ̀kan ninu wọn ń jẹ́ Jehieli.

22 Àwọn ọmọ Jehieli meji: Setamu ati Joẹli ni wọ́n ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.

23 A pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Amramu, ati àwọn ọmọ Iṣari, ati àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli.

24 Ṣebueli, ọmọ Geriṣomu, láti inú ìran Mose, ni olórí àwọn tí ń bojútó ibi ìṣúra.

25 Ninu àwọn arakunrin Ṣebueli, láti ìdílé Elieseri, a yan Rehabaya ọmọ Elieseri, Jeṣaaya ọmọ Rehabaya, Joramu ọmọ Jeṣaaya, Sikiri ọmọ Joramu ati Ṣelomiti ọmọ Sikiri.

26 Ṣelomiti yìí ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń bojútó àwọn ẹ̀bùn tí Dafidi ọba, ati ti àwọn olórí àwọn ìdílé, ati èyí tí àwọn olórí ọmọ ogun ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un, ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.

27 Ninu àwọn ìkógun tí wọ́n kó lójú ogun, wọ́n ya àwọn ẹ̀bùn kan sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú ilé OLUWA.

28 Ṣelomiti ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ẹ̀bùn tí àwọn eniyan bá mú wá, ati àwọn ohun tí wolii Samuẹli, ati Saulu ọba, ati Abineri, ọmọ Neri, ati Joabu, ọmọ Seruaya, ti yà sọ́tọ̀ ninu ilé OLUWA.

Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù

29 Ninu ìdílé Iṣari, Kenanaya ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n yàn ní alákòóso ati onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli.

30 Ninu ìdílé Heburoni, Haṣabaya ati ẹẹdẹgbẹsan (1,700) àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alágbára ni wọ́n ń bojútó àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ OLUWA ati iṣẹ́ ọba,

31 Ninu ìdílé Heburoni, Jerija ni baba ńlá gbogbo wọn. (Ní ogoji ọdún tí Dafidi dé orí oyè, wọ́n ṣe ìwádìí nípa ìran Heburoni, wọ́n sì rí àwọn ọkunrin tí wọ́n lágbára ninu ìran wọn ní Jaseri ní agbègbè Gileadi).

32 Dafidi ọba, yan òun ati àwọn arakunrin rẹ̀, tí gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa ó lé ẹẹdẹgbẹrin (2,700) alágbára, láti jẹ́ alámòójútó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase nípa gbogbo nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun ati àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ọba.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 27

Àwọn Ológun ati Ètò Òṣèlú

1 Àwọn wọnyi ni àwọn olórí ìdílé ati olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati olórí ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ aṣojú ọba ní gbogbo ìpínlẹ̀ ní oṣooṣù, títí ọdún yóo fi yípo ni wọn máa ń yan ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000) eniyan, tí wọn ń pààrọ̀ ara wọn.

2 Jaṣobeamu, ọmọ Sabidieli, ni olórí ìpín kinni, fún oṣù kinni; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji.

3 Ìran Peresi ni Jaṣobeamu, òun sì ni balogun fún gbogbo àwọn ọ̀gágun fún oṣù kinni.

4 Dodai, láti inú ìran Ahohi, ni olórí ìpín ti oṣù keji, iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

5 Balogun kẹta, tí ó wà fún oṣù kẹta ni Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, alufaa. Iye àwọn tí ó wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

6 Bẹnaya yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọgbọ̀n akọni jagunjagun, òun sì ni olórí wọn. Amisabadi ọmọ rẹ̀ ni ó ń ṣe àkóso ìpín rẹ̀.

7 Asaheli, arakunrin Joabu, ni balogun fún oṣù kẹrin. Sebadaya, ọmọ rẹ̀, ni igbákejì rẹ̀. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

8 Balogun tí ó wà fún oṣù karun-un ni Ṣamuhutu, láti inú ìran Iṣari; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

9 Balogun tí ó wà fún oṣù kẹfa ni Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

10 Balogun tí ó wà fún oṣù keje ni Helesi, ará Peloni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

11 Balogun tí ó wà fún oṣù kẹjọ ni Sibekai, ará Huṣa, láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

12 Balogun tí ó wà fún oṣù kẹsan-an ni Abieseri ará Anatoti, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

13 Balogun tí ó wà fún oṣù kẹwaa ni Maharai, ará Netofa láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

14 Balogun tí ó wà fún oṣù kọkanla ni Bẹnaya, ará Piratoni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

15 Balogun tí ó wà fún oṣù kejila ni Helidai ará Netofati, láti inú ìran Otinieli; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).

Ètò Àkóso Àwọn Ẹ̀yà Israẹli

16 Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí, láti inú ẹ̀yà Reubẹni: Elieseri, ọmọ Sikiri ni olórí patapata. Láti inú ẹ̀yà Simeoni: Ṣefataya, ọmọ Maaka.

17 Láti inú ẹ̀yà Lefi: Haṣabaya, ọmọ Kemueli; láti ìdílé Aaroni: Sadoku;

18 láti inú ẹ̀yà Juda: Elihu, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi; láti inú ẹ̀yà Isakari: Omiri, ọmọ Mikaeli;

19 láti inú ẹ̀yà Sebuluni: Iṣimaya, ọmọ Ọbadaya; láti inú ẹ̀yà Nafutali: Jeremotu, ọmọ Asirieli;

20 láti inú ẹ̀yà Efuraimu: Hoṣea, ọmọ Asasaya; láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase: Joẹli, ọmọ Pedaya;

21 láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Gileadi: Ido, ọmọ Sakaraya; láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini: Jaasieli, ọmọ Abineri;

22 láti inú ẹ̀yà Dani: Asareli, ọmọ Jerohamu. Àwọn ni olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli.

23 Dafidi kò ka àwọn tí wọn kò tó ọmọ ogún ọdún, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìlérí pé òun yóo mú kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

24 Joabu, ọmọ Seruaya, bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn eniyan, ṣugbọn kò parí rẹ̀. Sibẹsibẹ ibinu OLUWA wá sórí Israẹli nítorí rẹ̀; nítorí náà, kò sí àkọsílẹ̀ fún iye àwọn ọmọ Israẹli ninu ìwé ìtàn ọba Dafidi.

25 Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́.

26 Esiri, ọmọ Kelubu, ni alabojuto fún gbogbo iṣẹ́ oko dídá.

27 Ṣimei, ará Rama, ni ó wà fún àwọn ọgbà àjàrà. Sabidi, ará Ṣifimu, ni ó wà fún ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí.

28 Baali Hanani, ará Gederi, ni ó wà fún àwọn ọgbà olifi ati ti igi sikamore. Joaṣi ni ó wà fún ibi tí wọ́n ń kó òróró olifi pamọ́ sí.

29 Ṣitirai, ará Ṣaroni, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní Ṣaroni. Ṣafati, ọmọ Adila, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní àwọn àfonífojì.

30 Obili, ará Iṣmaeli, ni ó wà fún àwọn ràkúnmí. Jedeaya, ará Meronoti, ni ó wà fún àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jasisi, ará Hagiri, sì jẹ́ alabojuto àwọn agbo aguntan.

31 Gbogbo wọn jẹ́ alabojuto àwọn ohun ìní Dafidi ọba.

Àwọn Olùdámọ̀ràn Dafidi Ọba

32 Jonatani, arakunrin baba Dafidi ọba, ni olùdámọ̀ràn nítorí pé ó ní òye, ó sì tún jẹ́ akọ̀wé. Òun ati Jehieli, ọmọ Hakimoni, ní ń ṣe àmójútó àwọn ọmọ ọba.

33 Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn fún ọba, Huṣai ará Ariki sì ni ọ̀rẹ́ ọba.

34 Lẹ́yìn ikú Ahitofeli, Jehoiada, ọmọ Bẹnaya ati Abiatari di olùdámọ̀ràn ọba. Joabu sì jẹ́ balogun ọba.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 28

Ìlànà tí Dafidi Fi Lélẹ̀ fún Kíkọ́ Tẹmpili

1 Dafidi ọba pe gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn olórí àwọn ìpín tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ọba, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, ati ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ alabojuto ohun ìní ati ẹran ọ̀sìn ọba, àwọn tí wọ́n ń tọ́jú àwọn ọmọ ọba, àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ààfin, àwọn eniyan pataki pataki ati àwọn akọni ọmọ ogun, gbogbo wọn péjọ sí Jerusalẹmu.

2 Dafidi bá dìde dúró, ó ní, “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin ará mi ati eniyan mi, mo ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé ìsinmi fún Àpótí Majẹmu OLUWA, ati fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọrun wa; mo ti tọ́jú gbogbo nǹkan sílẹ̀, mo sì ti múra tán.

3 Ṣugbọn, Ọlọrun sọ fún mi pé, kì í ṣe èmi ni n óo kọ́ ilé fún òun, nítorí pé jagunjagun ni mí, mo sì ti ta ẹ̀jẹ̀ pupọ sílẹ̀.

4 Sibẹsibẹ OLUWA Ọlọrun Israẹli yàn mí ninu ilé baba mi láti jọba lórí Israẹli títí lae; nítorí pé ó yan ẹ̀yà Juda láti ṣe aṣaaju Israẹli. Ninu ẹ̀yà Juda, ó yan ilé baba mi, láàrin àwọn ọmọ baba mi, ó ní inú dídùn sí mi, ó fi mí jọba lórí gbogbo Israẹli.

5 OLUWA fún mi ní ọmọ pupọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, ó yan Solomoni láti jọba lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ lórí Israẹli.

6 “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Solomoni, ọmọ rẹ ni yóo kọ́ ilé mi ati àgbàlá mi, nítorí mo ti yàn án láti jẹ́ ọmọ mi, èmi yóo sì jẹ́ baba fún un.

7 N óo fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, bí ó bá ti pinnu láti máa pa òfin ati ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nisinsinyii.’

8 “Nítorí náà, lójú gbogbo ọmọ Israẹli, lójú ìjọ eniyan OLUWA, ati ní etígbọ̀ọ́ Ọlọrun wa, mò ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ máa pa gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, kí ẹ̀yin ati arọmọdọmọ yín baà lè máa gbé ilẹ̀ yìí títí lae.

9 “Ìwọ Solomoni, ọmọ mi, mọ Ọlọrun àwọn baba rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ sìn ín tìfẹ́tìfẹ́, nítorí OLUWA a máa wádìí ọkàn, ó sì mọ gbogbo èrò ati ète eniyan. Bí o bá wá OLUWA, o óo rí i, ṣugbọn bí o bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo ta ọ́ nù títí lae.

10 Kíyèsára, nítorí pé OLUWA ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé kan tí yóo jẹ́ ibi mímọ́, ṣe gírí, kí o sì kọ́ ọ.”

11 Dafidi bá fún Solomoni ní àwòrán tẹmpili náà tí wọ́n fi ọwọ́ yà, ati ti àwọn ilé mìíràn tí yóo kọ́ mọ́ tẹmpili, ati ti àwọn ilé ìṣúra rẹ̀, àwọn yàrá òkè, àwọn yàrá ti inú, ati ti yàrá ìtẹ́ àánú;

12 ati àwòrán gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sinu àgbàlá ilé OLUWA, ati ti àwọn yàrá káàkiri, àwọn ilé ìṣúra tí yóo wà ninu ilé Ọlọrun, ati ti àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n o máa kó ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA pamọ́ sí.

13 Dafidi tún fún un ní ìwé ètò pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn inú ilé OLUWA, ti àwọn ohun èlò fún ìsìn ninu ilé OLUWA;

14 àkọsílẹ̀ ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà fún ìsìn kọ̀ọ̀kan, ti ìwọ̀n fadaka fún gbogbo ohun èlò fadaka fún ìsìn kọ̀ọ̀kan,

15 ti ìwọ̀n àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà ati àwọn fìtílà wọn, ti ìwọ̀n fadaka fún ọ̀pá fìtílà kan ati àwọn fìtílà wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlò olukuluku wọn ninu ìsìn.

16 Ètò ìwọ̀n wúrà fún tabili àkàrà ìfihàn kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n fadaka fún tabili fadaka kọ̀ọ̀kan,

17 ìwọ̀n ojúlówó wúrà fún àwọn àmúga tí a fi ń mú ẹran, àwọn agbada, àwọn ife, àwọn abọ́ wúrà ati ti ìwọ̀n abọ́ fadaka kọ̀ọ̀kan,

18 ìwọ̀n pẹpẹ turari tí a fi wúrà yíyọ́ ṣe ati ohun tí ó ní lọ́kàn nípa àwọn kẹ̀kẹ́ wúrà àwọn Kerubu tí wọ́n na ìyẹ́ wọn bo Àpótí Majẹmu OLUWA.

19 Gbogbo nǹkan wọnyi ni ó kọ sílẹ̀ fínnífínní gẹ́gẹ́ bí ìlànà láti ọ̀dọ̀ OLUWA nípa iṣẹ́ inú tẹmpili; ó ní gbogbo rẹ̀ ni wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ náà.

20 Dafidi bá sọ fún Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Múra gírí, mú ọkàn le, kí o sì ṣe bí mo ti wí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì; nítorí OLUWA Ọlọrun, àní Ọlọrun mi, wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀, títí tí iṣẹ́ ilé OLUWA yóo fi parí.

21 Gbogbo ètò iṣẹ́ ati pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ninu tẹmpili ni a ti ṣe fínnífínní. Àwọn tí wọ́n mọ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ yóo wà pẹlu rẹ, bákan náà, àwọn olórí ati gbogbo eniyan Israẹli yóo wà lábẹ́ àṣẹ rẹ.”

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 29

Àwọn Ẹ̀bùn láti fi Kọ́ Tẹmpili

1 Dafidi ọba sọ fún àpéjọpọ̀ àwọn eniyan pé, “Solomoni ọmọ mi, ẹnìkan ṣoṣo tí Ọlọrun yàn, ó kéré, kò tíì ní ìrírí, iṣẹ́ náà sì tóbi pupọ, nítorí ààfin náà kò ní wà fún eniyan, bíkòṣe fún OLUWA Ọlọrun.

2 Mo ti sa ipá tèmi láti pèsè oríṣìíríṣìí nǹkan sílẹ̀ fún ilé OLUWA: wúrà fún àwọn ohun tí a nílò wúrà fún, fadaka fún àwọn ohun tí a nílò fadaka fún, idẹ fún àwọn ohun tí a nílò idẹ fún, irin fún àwọn ohun tí a nílò irin fún, pákó fún àwọn ohun tí a nílò pákó fún, lẹ́yìn náà, òkúta ìkọ́lé, òkúta olówó iyebíye, àwọn òkúta tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, ati mabu.

3 Lẹ́yìn náà, yàtọ̀ fún gbogbo àwọn nǹkan tí mo ti pèsè fún Tẹmpili Ọlọrun mi, mo ní ilé ìṣúra ti èmi alára, tí ó kún fún wúrà ati fadaka, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ mi sí ilé Ọlọrun mi, mo fi wọ́n sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé náà.

4 Mo ti pèsè ẹgbẹẹdogun (3,000) ìwọ̀n talẹnti wúrà dáradára láti ilẹ̀ Ofiri, ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka tí a ti yọ́, láti fi bo gbogbo ògiri tẹmpili náà,

5 ati àwọn ohun èlò mìíràn tí àwọn oníṣẹ́ ọnà yóo lò: wúrà fún àwọn ohun èlò wúrà, ati fadaka fún àwọn ohun èlò fadaka. Nisinsinyii, ninu yín, ta ló fẹ́ fi tinútinú ṣe ìtọrẹ, tí yóo sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí fún OLUWA?”

6 Nígbà náà ni àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn alabojuto ohun ìní ọba, bẹ̀rẹ̀ sí dá ọrẹ àtinúwá jọ.

7 Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ilé OLUWA nìwọ̀nyí: ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) talẹnti wúrà, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaasan-an (18,000) ìwọ̀n talẹnti idẹ ati ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ìwọ̀n talẹnti irin.

8 Gbogbo àwọn tí wọ́n ní òkúta olówó iyebíye ni wọ́n mú wọn wá tí wọ́n fi wọ́n sí ibi ìṣúra ilé OLUWA, tí ó wà lábẹ́ àbojútó Jehieli ará Geriṣoni.

9 Inú àwọn eniyan náà dùn pé wọ́n fi tinútinú mú ọrẹ wá nítorí pé tọkàntọkàn ati tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n fi mú ọrẹ wá fún OLUWA; inú Dafidi ọba náà sì dùn pupọ pẹlu.

Dafidi Fi Ìyìn fún Ọlọrun

10 Nítorí náà, Dafidi yin OLUWA níwájú gbogbo eniyan, ó ní: “Ìyìn ni fún ọ títí lae, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, Baba ńlá wa,

11 OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo.

12 Láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni ọrọ̀ ati ọlá ti ń wá, o sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ìkáwọ́ rẹ ni ipá ati agbára wà, ó wà ní ìkáwọ́ rẹ láti gbéni ga ati láti fún ni lágbára.

13 A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun wa, a sì yin orúkọ rẹ tí ó lógo.

14 “Ṣugbọn, kí ni mo jẹ́, kí sì ni àwọn eniyan mi jẹ́, tí a fi lè mú ọrẹ tí ó pọ̀ tó báyìí wá fún Ọlọrun tọkàntọkàn? Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ninu ohun tí o fún wa ni a sì ti mú wá fún ọ.

15 Àjèjì ati àlejò ni a jẹ́ ní ojú rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá wa. Gbogbo ọjọ́ wa láyé dàbí òjìji, kò lè wà pẹ́ títí.

16 OLUWA, Ọlọrun wa, tìrẹ ni gbogbo ohun tí a mú wá, láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni wọ́n sì ti wá.

17 Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ.

18 OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa: Abrahamu, Isaaki ati Israẹli, jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí túbọ̀ máa wà ninu àwọn eniyan rẹ títí lae, kí o sì jẹ́ kí ọkàn wọn máa fà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

19 Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Solomoni ọmọ mi, fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa òfin, àṣẹ ati ìlànà rẹ mọ́, kí ó lè ṣe ohun gbogbo, kí ó sì lè kọ́ tẹmpili tí mo ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún.”

20 Dafidi sọ fún gbogbo ìjọ eniyan pé, “Ẹ yin OLUWA Ọlọrun yín.” Gbogbo wọn bá yin OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Wọ́n wólẹ̀, wọ́n sin OLUWA, wọ́n sì tẹríba fún ọba.

21 Ní ọjọ́ keji, wọ́n fi ẹgbẹrun akọ mààlúù rú ẹbọ sísun sí OLUWA, ati ẹgbẹrun àgbò, ati ẹgbẹrun ọ̀dọ́ aguntan, pẹlu ọrẹ ohun mímu ati ọpọlọpọ ẹbọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

22 Wọ́n jẹ, wọ́n sì mu níwájú Ọlọrun ní ọjọ́ náà pẹlu ayọ̀ ńlá.

Wọ́n tún fi Solomoni, ọmọ Dafidi, jẹ ọba lẹẹkeji. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba ní orúkọ OLUWA, Sadoku sì ni alufaa.

23 Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọba, dípò Dafidi, baba rẹ̀. Solomoni ní ìlọsíwájú, gbogbo àwọn eniyan Israẹli sì ń gbọ́ tirẹ̀.

24 Gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn alágbára, ati gbogbo àwọn ọmọ Dafidi ọba ni wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti máa gbọ́ ti Solomoni.

25 OLUWA gbé Solomoni ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fún un ní ọlá ju gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ti jẹ ṣáájú rẹ̀ ní Israẹli.

Àkójọpọ̀ Ìjọba Dafidi

26 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi, ọmọ Jese, ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli.

27 Ó jọba fún ogoji ọdún; ó jọba fún ọdún meje ní Heburoni, ó sì jọba fún ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu.

28 Ẹ̀mí rẹ̀ gùn, ó lọ́rọ̀, ó sì lọ́lá, ó sì di arúgbó kàngẹ́kàngẹ́ kí ó tó kú, Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

29 Ìtàn ìgbé ayé ọba Dafidi láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ni a kọ sí inú ìwé ìtàn tí wolii Samuẹli kọ, èyí tí wolii Natani kọ, ati èyí tí wolii Gadi kọ.

30 Àkọsílẹ̀ yìí sọ bí ó ti ṣe ìjọba rẹ̀, bí agbára rẹ̀ ti tó; ati gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí i, ati èyí tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli ati sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká wọn.