Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 10

Ikú Saulu Ọba

1 Ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, wọ́n sì pa ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Giliboa.

2 Ọwọ́ wọn tẹ Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n pa Jonatani, Abinadabu ati Malikiṣua.

3 Ogun gbóná janjan yí Saulu ká, àwọn tafàtafà rí i, wọ́n ta á lọ́fà, ó sì fara gbọgbẹ́,

4 Saulu ba sọ fún ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì gún mi pa, kí àwọn aláìkọlà ará Filistia má baà fi mi ṣẹ̀sín.” Ṣugbọn ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nítorí pe ẹ̀rù bà á; nítorí náà, Saulu fa idà ara rẹ̀ yọ, ó sì ṣubú lé e.

5 Nígbà tí ọdọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà ṣubú lé idà rẹ̀, ó sì kú.

6 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta ati àwọn ará ilé rẹ̀ ṣe kú papọ̀.

7 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé àfonífojì Jesireeli gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun ti sá lọ, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú, wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn, àwọn ará Filistia wá wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

8 Ní ọjọ́ keji, nígbà tí àwọn ará Filistia wá láti kó ìkógun, wọ́n rí òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta lórí Òkè Giliboa.

9 Wọ́n bọ́ ihamọra Saulu, wọ́n gé orí rẹ̀, wọ́n sì rán àwọn oníṣẹ́ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Filistini láti ròyìn ayọ̀ náà fún àwọn oriṣa wọn ati àwọn eniyan wọn.

10 Wọ́n kó àwọn ihamọra rẹ̀ sinu tẹmpili oriṣa wọn, wọ́n sì kan orí Saulu mọ́ ara ògiri tẹmpili Dagoni, oriṣa wọn.

11 Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ bí àwọn ará Filistia ti ṣe Saulu,

12 gbogbo àwọn akọni ọkunrin tí wọ́n gbóyà gidigidi gbéra, wọ́n lọ gbé òkú Saulu ati òkú àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí Jabeṣi, wọ́n sì sin egungun wọn sí abẹ́ igi oaku ní Jabeṣi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.

13 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ṣe kú nítorí aiṣododo rẹ̀; ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, ó sì lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ abókùúsọ̀rọ̀, ó lọ bèèrè ìtọ́sọ́nà níbẹ̀,

14 dípò kí ó bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ OLUWA. Nítorí náà, OLUWA pa á, ó sì gbé ìjọba rẹ̀ fún Dafidi, ọmọ Jese.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 11

Dafidi Jọba lórí Israẹli ati Juda

1 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá parapọ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Heburoni, wọ́n ní, “Wò ó, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni gbogbo wa pẹlu rẹ.

2 Látẹ̀yìnwá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni ò ń ṣáájú Israẹli lójú ogun. OLUWA Ọlọrun rẹ sì ti ṣèlérí fún ọ pé ìwọ ni o óo máa ṣe olùṣọ́ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan òun, tí o óo sì jọba lé wọn lórí.”

3 Nítorí náà, àwọn àgbààgbà Israẹli wá sọ́dọ̀ Dafidi ọba, ní Heburoni. Dafidi sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA láti ẹnu Samuẹli.

4 Dafidi ati àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu, (Jebusi ni orúkọ Jerusalẹmu nígbà náà, ibẹ̀ ni àwọn ará Jebusi ń gbé.)

5 Àwọn ará Jebusi sọ fún Dafidi pé, “O ò ní wọ ìlú yìí.” Ṣugbọn Dafidi ṣẹgun ibi ààbò Sioni, tí à ń pè ní ìlú Dafidi.

6 Dafidi ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ pa ará Jebusi kan ni yóo jẹ́ balogun fún àwọn ọmọ ogun mi.” Joabu, ọmọ Seruaya ni ó kọ́kọ́ lọ, ó sì di balogun.

7 Dafidi lọ ń gbé ibi ààbò náà, nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní ìlú Dafidi.

8 Ó tún ìlú náà kọ́ yípo, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, ibi tí a ti kun ilẹ̀ náà yíká. Joabu sì parí èyí tí ó kù.

9 Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí di alágbára sí i, nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu rẹ̀.

Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi tí Wọ́n Jẹ́ Olókìkí

10 Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn akọni ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí; àwọn ni wọ́n fọwọsowọpọ pẹlu àwọn ọmọ Israẹli, láti fi Dafidi jọba, tí wọ́n sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ti ṣe fún Israẹli.

11 Àkọsílẹ̀ orúkọ wọn nìyí: Jaṣobeamu láti ìdílé Hakimoni ni olórí àwọn ọ̀gágun olókìkí mẹta. Òun ni ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun (300) eniyan ninu ogun kan ṣoṣo.

12 Ẹni tí ó tẹ̀lé e ninu àwọn ọ̀gágun olókìkí mẹta náà ni Eleasari ọmọ Dodo ará Aho.

13 Ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí Dafidi bá àwọn ará Filistia jagun ní Pasi Damimu, wọ́n wà ninu oko ọkà baali kan nígbà tí àwọn ọmọ ogun Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí sá fún àwọn ará Filistia.

14 Ṣugbọn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ dúró gbọningbọnin ninu oko náà, wọ́n bá àwọn ará Filistia jà. OLUWA gbà wọ́n, ó sì fún wọn ní ìṣẹ́gun ńlá.

15 Ní ọjọ́ kan, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun olókìkí lọ sọ́dọ̀ Dafidi nígbà tí ó wà ní ihò Adulamu, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini dó sí àfonífojì Refaimu.

16 Ibi ààbò ni Dafidi wà nígbà náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ogun Filistini sì ti wọ Bẹtilẹhẹmu,

17 Dafidi ranti ilé, ó ní, “Kì bá ti dùn tó kí n rí ẹni fún mi ní omi mu láti inú kànga tí ó wà lẹ́nu ibodè Bẹtilẹhẹmu!”

18 Àwọn akọni mẹta náà bá la àgọ́ àwọn ọmọ ogun Filistia já, dé ibi kànga náà, wọ́n sì bu omi náà wá fún Dafidi. Ṣugbọn ó kọ̀, kò mu ún; kàkà bẹ́ẹ̀, ó tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún OLUWA.

19 Ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe nǹkan yìí níwájú Ọlọrun mi. Ǹjẹ́ ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin wọnyi?” Nítorí pé ẹ̀mí wọn ni wọ́n fi wéwu kí wọn tó rí omi yìí bù wá; nítorí náà ni ó ṣe kọ̀, tí kò sì mu ún. Ó jẹ́ ohun ìgboyà tí àwọn akọni mẹta náà ṣe.

20 Abiṣai, arakunrin Joabu, ni olórí àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun. Ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀ òkìkí tirẹ̀ náà súnmọ́ ti àwọn akọni mẹta náà.

21 Òun ni ó lókìkí jùlọ ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun náà, ó sì di olórí wọn; ṣugbọn kò ní òkìkí tó àwọn akọni mẹta.

22 Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, láti ìlú Kabiseeli, jẹ́ ọmọ ogun tí ó ti ṣe ọpọlọpọ ohun ìyanu, ó pa àwọn abàmì eniyan meji ará Moabu. Ó wọ ihò lọ pa kinniun kan ní ọjọ́ kan tí yìnyín bo ilẹ̀.

23 Ó pa ará Ijipti kan tí ó ga ju mita meji lọ. Ará Ijipti náà gbé ọ̀kọ̀ tí ó tóbi lọ́wọ́. Ṣugbọn kùmọ̀ ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ lọ bá a, ó gba ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi pa á.

24 Àwọn ohun tí Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ṣe nìyí, tí ó sọ ọ́ di olókìkí, yàtọ̀ sí ti àwọn akọni mẹta tí a sọ nípa wọn.

25 Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba.

26 Àwọn olókìkí mìíràn ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí: Asaheli, arakunrin Joabu; ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu;

27 Ṣamotu, láti Harodu;

28 Helesi, láti inú ìdílé Peloni, Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa, ati Abieseri, láti Anatoti

29 Sibekai, láti inú ìdílé Huṣati, ati Ilai, láti inú ìdílé Aho;

30 Maharai, ará Netofa, ati Helodi, ọmọ Baana, ará Netofa;

31 Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ati Bẹnaya, ará Piratoni;

32 Hurai, ará etí odò Gaaṣi, ati Abieli, ará Aribati;

33 Asimafeti, ará Bahurumu, ati Eliaba ará Ṣaaliboni;

34 Haṣemu, ará Gisoni, ati Jonatani, ọmọ Ṣagee, ará Harari;

35 Ahiamu, ọmọ Sakari, ará Harari, ati Elifali, ọmọ Uri;

36 Heferi, ará Mekerati, ati Ahija, ará Peloni;

37 Hesiro, ará Kamẹli, ati Naarai ọmọ Esibai;

38 Joẹli, arakunrin Natani, ati Mibihari, ọmọ Hagiri,

39 Seleki, ará Amoni, ati Naharai, ará Beeroti, tí ń ru ihamọra Joabu ọmọ Seruaya.

40 Ira, ará Itiri, ati Garebu ará Itiri,

41 Uraya, ará Hiti, ati Sabadi, ọmọ Ahilai,

42 Adina, ọmọ Ṣisa, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, olórí kan láàrin ẹ̀yà Reubẹni, pẹlu ọgbọ̀n àwọn ọmọ ogun rẹ̀;

43 Hanani, ọmọ Maaka, ati Joṣafati, ará Mitini;

44 Usaya, ará Aṣiteratu, Ṣama, ati Jeieli, àwọn ọmọ Hotamu, ará Aroeri,

45 Jediaeli, ọmọ Ṣimiri, ati Joha, arakunrin rẹ̀, ará Tisi,

46 Elieli, ará Mahafi, ati Jẹribai, ati Joṣafia, àwọn ọmọ Elinaamu, ati Itima ará Moabu;

47 Elieli, ati Obedi, ati Jaasieli, ará Mesoba.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 12

Àwọn tí Wọ́n Kọ́kọ́ Jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Dafidi Ọba láti Inú Ẹ̀yà Bẹnjamini

1 Àwọn ọkunrin wọnyi ni wọ́n lọ bá Dafidi ní Sikilagi, nígbà tí ó ń farapamọ́ fún Saulu, ọmọ Kiṣi; wọ́n wà lára àwọn akọni tí wọ́n ń ran Dafidi lọ́wọ́ lójú ogun.

2 Tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lè fi ọwọ́ ọ̀tún ati ọwọ́ òsì ta ọfà tabi kí wọ́n fi fi kànnàkànnà. Ninu ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ti wá, wọ́n sì jẹ́ ìbátan Saulu.

3 Olórí wọn ni Ahieseri, lẹ́yìn náà, Joaṣi, ọmọ Ṣemaa; ará Gibea ni àwọn mejeeji. Lẹ́yìn wọn ni: Jesieli ati Peleti, àwọn ọmọ Asimafeti; Beraka, ati Jehu, ará Anatoti.

4 Iṣimaya, ará Gibeoni, akikanju jagunjagun ati ọ̀kan ninu “àwọn ọgbọ̀n” jagunjagun olókìkí ni, òun sì ni olórí wọn; Jeremaya, Jahasieli, Johanani ati Josabadi ará Gedera.

5 Elusai, Jerimotu, ati Bealaya; Ṣemaraya, Ṣefataya ará Harifi;

6 Elikana, Iṣaya, ati Asareli, Joeseri, ati Jaṣobeamu, láti inú ìdílé Kora,

7 Joela, ati Sebadaya, àwọn ọmọ Jehoramu, ará Gedori.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Gadi

8 Àwọn ọkunrin tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Gadi láti darapọ̀ mọ́ Dafidi, ní ibi ààbò tí ó wà ninu aṣálẹ̀ nìwọ̀nyí; akọni ati ògbólógbòó jagunjagun ni wọ́n, wọ́n já fáfá ninu lílo apata ati ọ̀kọ̀, ojú wọn dàbí ti kinniun, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín lórí òkè.

9 Orúkọ wọn, ati bí wọ́n ṣe tẹ̀léra nìyí: Eseri ni olórí wọn, lẹ́yìn náà ni Ọbadaya, Eliabu;

10 Miṣimana, Jeremaya,

11 Atai, Elieli,

12 Johanani, Elisabadi,

13 Jeremaya, ati Makibanai.

14 Àwọn ọmọ ẹ̀yà Gadi wọnyi ni olórí ogun, àwọn kan jẹ́ olórí ọgọrun-un ọmọ ogun, àwọn kan sì jẹ́ olórí ẹgbẹrun, olukuluku gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ akikanju sí.

15 Àwọn ni wọ́n la odò Jọdani kọjá ninu oṣù kinni, ní àkókò ìgbà tí ó kún bo bèbè rẹ̀, wọ́n sì ṣẹgun gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, ní apá ìhà ìlà oòrùn ati apá ìwọ̀ oòrùn.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Bẹnjamini ati Ẹ̀yà Juda

16 Àwọn kan láti inú ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Bẹnjamini wá sọ́dọ̀ Dafidi níbi ààbò.

17 Dafidi lọ pàdé wọn, ó ní, “Tí ẹ bá wá láti darapọ̀ mọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́, ati láti ràn mí lọ́wọ́, inú mi dùn sí yín; ṣugbọn bí ẹ bá wá ṣe amí fún àwọn ọ̀tá mi, nígbà tí ó ti jẹ́ pé n kò ní ẹ̀bi, Ọlọrun àwọn baba wa rí yín, yóo sì jẹ yín níyà.”

18 Ẹ̀mí Ọlọrun bá bà lé Amasai, olórí àwọn ọgbọ̀n ọmọ ogun olókìkí, ó bá dáhùn pé,

“Tìrẹ ni wá, Dafidi;

a sì wà pẹlu rẹ, ọmọ Jese!

Alaafia, alaafia ni fún ọ,

alaafia sì ni fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ!

Nítorí pé Ọlọrun rẹ ń ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Dafidi bá gbà wọ́n, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Manase

19 Àwọn kan ninu ẹ̀yà Manase darapọ̀ mọ́ Dafidi nígbà tí òun pẹlu àwọn ará Filistia wá láti bá Saulu jagun. (Sibẹsibẹ kò lè ran àwọn Filistia lọ́wọ́, nítorí pé lẹ́yìn tí àwọn ọba àwọn Filistini jíròrò láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ewu ń bẹ nítorí pé yóo darapọ̀ pẹlu Saulu, ọ̀gá rẹ̀.”) Wọ́n bá dá a pada lọ sí Sikilagi.

20 Bí ó ti ń pada lọ sí Sikilagi, àwọn ará Manase kan wá, wọ́n bá darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi. Orúkọ wọn ni: Adina, Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli; Josabadi, Elihu ati Siletai, olórí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ ogun ninu ẹ̀yà Manase.

21 Wọ́n ran Dafidi lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, wọ́n sì jẹ́ ọ̀gágun.

22 Lojoojumọ ni àwọn eniyan ń wá sọ́dọ̀ Dafidi láti ràn án lọ́wọ́; títí tí wọ́n fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n dàbí ogun ọ̀run.

Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi

23 Àwọn ìpín ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní Heburoni, láti gbé ìjọba Saulu lé Dafidi lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí:

24 Láti inú ẹ̀yà Juda, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó dín igba (6,800) wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀.

25 Láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹẹdẹgbaarin ó lé ọgọrun-un (7,100), àwọn akọni jagunjagun ni wọ́n wá.

26 Láti inú ẹ̀yà Lefi, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó dín irinwo (4,600);

27 Jehoiada, olóyè, wá láti inú ìran Aaroni pẹlu ẹgbaaji ó dín ọọdunrun (3,700) ọmọ ogun

28 Sadoku ọdọmọkunrin akikanju jagunjagun wá, pẹlu ọ̀gágun mejilelogun ninu àwọn ará ilé baba rẹ̀.

29 Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹlu Saulu, àwọn tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaaji (3,000). Tẹ́lẹ̀ rí, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ìdílé Saulu.

30 Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹrin (20,800) akikanju ati alágbára, tí wọ́n jẹ́ olókìkí ninu ìdílé wọn ni wọ́n wá.

31 Láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase, ẹgbaasan-an (18,000) wá; yíyàn ni wọ́n yàn wọ́n láti lọ fi Dafidi jọba.

32 Láti inú ẹ̀yà Isakari, àwọn igba (200) olórí ni wọ́n wá, àwọn tí wọ́n mọ ohun tí ó bá ìgbà mu, ati ohun tí ó yẹ kí Israẹli ṣe; wọ́n wá pẹlu àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ wọn.

33 Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaarun (50,000) àwọn ọmọ ogun, tí wọ́n gbóyà, tí wọ́n mọ̀ nípa ogun jíjà, tí wọ́n sì ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹlu ọkàn kan.

34 Láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbẹrun (1,000) ọ̀gágun wá, ọ̀kẹ́ meji ó dín ẹẹdẹgbaaji (37,000) ni àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu wọn; gbogbo wọn ní apata ati ọ̀kọ̀.

35 Láti inú ẹ̀yà Dani, ẹgbaa mẹrinla ó lé ẹgbẹta ọkunrin (28,600) tí wọ́n dira ogun ni wọ́n wá.

36 Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ọ̀kẹ́ meji (40,000) ni àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun.

37 Láti inú àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ẹ̀yà Reubẹni, ti Gadi, ati ìdajì ti Manase, ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ọmọ ogun tí wọ́n ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá.

38 Gbogbo wọn ni wọ́n ti dira ogun, tí wọ́n wá sí Heburoni pẹlu ìpinnu láti fi Dafidi jọba lórí Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù náà sì pinnu bákan náà.

39 Wọ́n wà níbẹ̀ pẹlu Dafidi fún ọjọ́ mẹta, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, nítorí àwọn arakunrin wọn ti pèsè oúnjẹ sílẹ̀ dè wọ́n.

40 Bákan náà ni gbogbo àwọn aládùúgbò wọn láti ọ̀nà jíjìn bí ẹ̀yà Isakari ati ti Sebuluni ati Nafutali di oúnjẹ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, ati ìbakasíẹ, ati akọ mààlúù wá fún wọn. Wọ́n kó ọpọlọpọ oúnjẹ, àkàrà dídùn tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣe, ìdì èso resini, waini, ati òróró, pẹlu akọ mààlúù ati aguntan, nítorí pé ayọ̀ kún gbogbo orílẹ̀-èdè Israẹli.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 13

A Gbé Àpótí Majẹmu kúrò ní Kiriati Jearimu

1 Dafidi jíròrò pẹlu àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati àwọn ti ọgọọgọrun-un, ati gbogbo àwọn olórí.

2 Lẹ́yìn náà ó sọ fún gbogbo ìjọ Israẹli pé, “Bí ó bá dára lójú yín, tí ó sì jẹ́ ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa, ẹ jẹ́ kí á ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilé Israẹli, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọ́n ní pápá oko, kí wọ́n wá darapọ̀ mọ́ wa.

3 Kí á sì lọ sí ibi tí Àpótí Majẹmu Ọlọrun, tí a ti patì láti ayé Saulu wà, kí á gbé e pada wá sọ́dọ̀ wa.”

4 Gbogbo ìjọ eniyan sì gbà bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó dára lójú wọn.

5 Nítorí náà Dafidi kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti Ṣihori ní Ijipti títí dé ẹnubodè Hamati láti lọ gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun láti Kiriati Jearimu lọ sí Jerusalẹmu.

6 Dafidi ati gbogbo ọmọ Israẹli lọ sí ìlú Baala, tí à ń pè ní Kiriati Jearimu, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu tí à ń fi orúkọ OLUWA pè, OLUWA tí ó jókòó, tí ó fi àwọn Kerubu ṣe ìtẹ́.

7 Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà jáde láti ilé Abinadabu, wọ́n gbé e lé orí kẹ̀kẹ́ titun. Usa ati Ahio sì ń wa kẹ̀kẹ́ náà.

8 Dafidi ati àwọn eniyan ń fi tagbára-tagbára jó níwájú Ọlọrun, pẹlu orin ati àwọn ohun èlò orin: dùùrù, hapu, ìlù, Kimbali ati fèrè.

9 Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Kidoni, àwọn mààlúù tí wọn ń fa kẹ̀kẹ́ náà kọsẹ̀, Usa bá di Àpótí Majẹmu náà mú kí ó má baà ṣubú.

10 Ṣugbọn inú bí Ọlọrun sí Usa, ó sì lù ú pa, nítorí pé ó fi ọwọ́ kan Àpótí Majẹmu, ó sì kú níwájú Ọlọrun.

11 Inú bí Dafidi nítorí pé Ọlọrun lu Usa pa, láti ọjọ́ náà ni a ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa títí di òní.

12 Ẹ̀rù Ọlọrun ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó ní, “Báwo ni mo ṣe lè gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun sọ́dọ̀?”

13 Nítorí náà, Dafidi kò gbé Àpótí Majẹmu sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi, kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbé e yà sí ilé Obedi Edomu, ará Giti.

14 Àpótí Majẹmu Ọlọrun náà wà ní ilé Obedi Edomu yìí fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun ilé Obedi Edomu ati gbogbo ohun tí ó ní.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 14

Akitiyan Dafidi ní Jerusalẹmu

1 Hiramu, ọba Tire kó àwọn òṣìṣẹ́ ranṣẹ sí Dafidi, pẹlu igi kedari ati àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti bá a kọ́ ilé rẹ̀.

2 Dafidi ṣe akiyesi pé Ọlọrun ti fi ìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Israẹli, ati pé Ọlọrun ti gbé ìjọba òun ga nítorí àwọn ọmọ Israẹli eniyan rẹ̀.

3 Dafidi tún fẹ́ àwọn iyawo mìíràn ní Jerusalẹmu, ó sì bí àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin sí i.

4 Àwọn tí ó bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua, Ṣobabu, Natani, ati Solomoni;

5 Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti;

6 Noga, Nefegi, ati Jafia;

7 Eliṣama, Beeliada, ati Elifeleti.

Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Filistia

8 Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi òróró yan Dafidi lọ́ba lórí Israẹli, gbogbo wọn wá gbógun ti Dafidi. Nígbà tí Dafidi gbọ́, òun náà múra láti lọ gbógun tì wọ́n.

9 Àwọn ará Filistia ti dé sí àfonífojì Refaimu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rú.

10 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní: “Ṣé kí n lọ bá àwọn ará Filistia jà? Ṣé o óo jẹ́ kí n ṣẹgun wọn?”

Ọlọrun dá a lóhùn pé, “Lọ bá wọn jà, n óo jẹ́ kí o ṣẹgun wọn.”

11 Dafidi bá lọ kọlù wọ́n ní Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun wọn, ó ní, “Ọlọrun ti lò mí láti kọlu àwọn ọ̀tá mi bí ìkún omi.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu.

12 Àwọn ará Filistia fi oriṣa wọn sílẹ̀ nígbà tí wọn ń sá lọ, Dafidi sì pàṣẹ pé kí wọ́n sun wọ́n níná.

13 Láìpẹ́, àwọn ará Filistia tún wá gbógun ti àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, wọ́n sì kó wọn lẹ́rú.

14 Dafidi bá tún lọ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun. Ọlọrun sì dá a lóhùn pé, “Má ṣe bá wọn jà níhìn-ín, ṣugbọn yípo lọ sẹ́yìn wọn kí o kọlù wọ́n ní òdìkejì àwọn igi balisamu.

15 Nígbà tí o bá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi balisamu ni kí o kọlù wọ́n, nítorí pé n óo ṣáájú rẹ lọ láti kọlu ogun Filistini.”

16 Dafidi ṣe ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún un, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Gibeoni títí dé Gasa.

17 Òkìkí Dafidi kàn káàkiri, OLUWA sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ̀ máa ba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 15

Ìmúra láti Gbé Àpótí Majẹmu Pada

1 Dafidi kọ́ ọpọlọpọ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó tọ́jú ibìkan fún Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ó sì pa àgọ́ lé e lórí.

2 Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.”

3 Nítorí náà, Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sí Jerusalẹmu, kí wọ́n baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wá sí ibi tí ó pèsè sílẹ̀ fún un.

4 Dafidi kó àwọn ọmọ Aaroni ati àwọn ọmọ Lefi jọ:

5 Iye àwọn ọmọ Lefi tí ó kó jọ láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: ọgọfa (120) ọkunrin, Urieli ni olórí wọn;

6 láti inú ìdílé Merari: igba ó lé ogún (220) ọkunrin, Asaaya ni olórí wọn,

7 láti inú ìdílé Geriṣomu, aadoje (130) ọkunrin, Joẹli ni olórí wọn;

8 láti inú ìdílé Elisafani, igba (200) ọkunrin, Ṣemaaya ni olórí wọn,

9 láti inú ìdílé Heburoni, ọgọrin ọkunrin, Elieli ni olórí wọn,

10 láti inú ìdílé Usieli, ọkunrin mejilelaadọfa (112), Aminadabu ni olórí wọn.

11 Dafidi pe Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa, pẹlu àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi mẹfa, Urieli, Asaaya, ati Joẹli, Ṣemaaya, Elieli, ati Aminadabu,

12 ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí ìdílé yín ninu ẹ̀yà Lefi. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin ati àwọn eniyan yín, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli wá síbi tí mo ti tọ́jú sílẹ̀ fún un.

13 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé e lákọ̀ọ́kọ́, OLUWA Ọlọrun wa jẹ wá níyà, nítorí pé a kò tọ́jú rẹ̀ bí ó ti tọ́.”

14 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli.

15 Àwọn ọmọ Lefi fi ọ̀pá gbé e lé èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Mose.

16 Dafidi pàṣẹ fún àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n yan àwọn akọrin láàrin ara wọn, tí wọn yóo máa fi ohun èlò orin bíi hapu, dùùrù, ati aro dá orin ayọ̀.

17 Nítorí náà àwọn ọmọ Lefi yan Hemani, ọmọ Joẹli ati Asafu, arakunrin rẹ̀, ọmọ Berekaya, ati àwọn arakunrin wọn láti ìdílé Merari, arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaaya.

18 Wọ́n yan àwọn arakunrin wọn wọnyi kí wọ́n wà ní ipò keji sí wọn: Sakaraya, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Bẹnaya, Maaseaya, Matitaya, Elifelehu ati Mikineiya, pẹlu àwọn aṣọ́nà: Obedi Edomu ati Jeieli.

19 Wọ́n yan àwọn akọrin, Hemani, Asafu ati Etani láti máa lu aro tí wọ́n fi idẹ ṣe

20 Sakaraya, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Maaseaya ati Bẹnaya ń lo hapu,

21 ṣugbọn Matitaya, Elifelehu, Mikineiya, Obedi Edomu, Jeieli ati Asasaya ni wọ́n ń tẹ dùùrù.

22 Kenanaya ni a yàn láti máa darí orin àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé ó ní ìmọ̀ orin.

23 Berekaya ati Elikana ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.

24 Àwọn alufaa tí wọ́n yàn láti máa fọn fèrè níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun ni: Ṣebanaya, Joṣafati, Netaneli, Amasa, Sakaraya, Bẹnaya, ati Elieseri. Obedi Edomu ati Jehaya pẹlu ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.

Gbígbé Àpótí Majẹmu Lọ sí Jerusalẹmu

25 Dafidi ati àwọn àgbààgbà Israẹli ati àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun bá lọ sí ilé Obedi Edomu, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ayọ̀.

26 Nítorí pé Ọlọrun ran àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA lọ́wọ́, wọ́n fi mààlúù meje ati àgbò meje rúbọ.

27 Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu, ati àwọn akọrin ati Kenanaya, olórí àwọn akọrin wọ aṣọ funfun tí ń dán, Dafidi sì wọ efodu funfun.

28 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ.

29 Bí wọ́n ti ń gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wọ ìlú Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu yọjú láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi tí ń jó, tí ń fò sókè tayọ̀tayọ̀, ó sì pẹ̀gàn rẹ̀ ninu ara rẹ̀.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 16

1 Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun kalẹ̀ ninu àgọ́ tí Dafidi ti tọ́jú sílẹ̀ fún un, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú Ọlọrun.

2 Nígbà tí Dafidi rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA,

3 ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, atọkunrin atobinrin, ní burẹdi kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran yíyan kọ̀ọ̀kan ati àkàrà èso resini.

4 Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.

5 Asafu ni olórí, àwọn tí ipò wọn tún tẹ̀lé tirẹ̀ ni: Sakaraya, Jeieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Matitaya, Eliabu, Bẹnaya, Obedi Edomu ati Jeieli àwọn tí wọ́n ń ta hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù. Asafu ni ó ń lu aro.

6 Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun.

7 Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA.

Orin Ìyìn

8 Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA, ẹ képe orúkọ rẹ̀,

ẹ kéde ohun tí ó ti ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè.

9 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn sí i,

ẹ sọ nípa àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe!

10 Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo,

kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀.

11 OLUWA ni kí ẹ máa tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́,

Ẹ máa sìn ín nígbà gbogbo.

12 Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,

gbogbo nǹkan ìyanu tí ó ṣe, ati gbogbo ìdájọ́ rẹ̀,

13 ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,

ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

14 Òun ni OLUWA Ọlọrun wa,

ìdájọ́ rẹ̀ ká gbogbo ayé.

15 Kò ní í gbàgbé majẹmu rẹ̀ títí lae,

àní àwọn ohun tí ó ti pa láṣẹ láti ṣe fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,

16 majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,

ìlérí tí ó ti ṣe fún Isaaki,

17 tí ó sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu Jakọbu,

gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ohun tí yóo wà títí lae,

18 ó ní, “Ẹ̀yin ni n óo fún ní ilẹ̀ Kenaani,

bí ohun ìní yín, tí ẹ óo jogún.”

19 Nígbà tí wọn kò tíì pọ̀ pupọ,

tí wọn kò sì jẹ́ nǹkan,

tí wọ́n jẹ́ àjèjì níbẹ̀,

20 tí wọn ń lọ káàkiri láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji,

láti ìjọba kan sí òmíràn,

21 kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,

ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.

22 Ó ní, “Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,

ẹ má sì pa àwọn wolii mi lára!”

23 Ẹ kọrin sí OLUWA, gbogbo ayé!

Ẹ máa kéde ìgbàlà rẹ̀ lojoojumọ.

24 Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

ẹ polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan!

25 OLUWA tóbi, ìyìn tọ́ sí i lọpọlọpọ

ó sì yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún un ju gbogbo àwọn oriṣa lọ.

26 Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun,

ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run.

27 Ògo ati agbára yí i ká,

ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀.

28 Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé,

ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́!

29 Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un,

ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀!

Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́,

30 ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé,

ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae.

31 Kí inú ọ̀run kí ó dùn,

kí ayé kí ó yọ̀,

kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!”

32 Kí òkun ati ohun gbogbo tó wà ninu rẹ̀ hó yèè,

kí pápá oko búsáyọ̀, ati gbogbo ẹ̀dá tó wà ninu rẹ̀.

33 Àwọn igi igbó yóo kọrin ayọ̀

níwájú OLUWA, nítorí ó wá láti ṣe ìdájọ́ ayé.

34 Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA nítorí pé ó ṣeun,

ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ sì wà títí lae!

35 Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa,

kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ,

kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.

36 Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,

lae ati laelae!”

Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA.

Ìjọ́sìn ní Gibeoni ati ní Jerusalẹmu

37 Dafidi fi Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí iwájú Àpótí Majẹmu OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ lojoojumọ,

38 pẹlu Obedi Edomu ati àwọn arakunrin rẹ̀ mejidinlaadọrin; ó sì fi Obedi Edomu, ọmọ Jedutuni ati Hosa ṣe aṣọ́nà.

39 Ó fi Sadoku, alufaa ati àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ibi Àgọ́ OLUWA ní ibi pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Gibeoni,

40 láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́, bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli.

41 Hemani wà pẹlu wọn, ati Jedutuni ati àwọn mìíràn tí a yàn, tí a sì dárúkọ, láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

42 Hemani ati Jedutuni ní fèrè, aro, ati àwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn tí wọ́n fi ń kọrin ìyìn. Àwọn ọmọ Jedutuni ni wọ́n yàn láti máa ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà.

43 Lẹ́yìn náà olukuluku pada sí ilé rẹ̀, Dafidi náà pada sí ilé rẹ̀ láti lọ súre fún àwọn ará ilé rẹ̀.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 17

Iṣẹ́ tí Natani Jẹ́ fún Dafidi

1 Ní ọjọ́ kan ní àkókò tí Dafidi ọba ń gbe ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani, wolii, pé, “Wò ó, èmi ń gbé ilé tí a fi igi kedari kọ́, ṣugbọn Àpótí Majẹmu OLUWA wà ninu àgọ́.”

2 Natani bá dá a lóhùn pé, “Ṣe gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ, nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu rẹ.”

3 Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an, Ọlọrun sọ fún Natani pé,

4 “Lọ sọ fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, èmi ‘OLUWA sọ pé kì í ṣe òun ni óo kọ́ ilé tí n óo máa gbé fún mi.

5 Nítorí pé n kò tíì gbé inú ilé kankan láti ìgbà tí mo ti kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò lóko ẹrú títí di òní. Inú àgọ́ kan ni mo ti ń dé inú àgọ́ mìíràn, tí mo sì ń lọ láti ibìkan dé ibòmíràn.

6 Sọ pé, mo ní ninu gbogbo ibi tí mo ti ń bá àwọn ọmọ Israẹli lọ káàkiri, ǹjẹ́ mo tíì yanu bèèrè lọ́wọ́ onídàájọ́ kankan, lára àwọn tí mo pàṣẹ fún láti máa darí àwọn eniyan mi, pé kí wọ́n kọ́ ilé kedari fún mi?’

7 “Nítorí náà, sọ fún un pé, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ‘mo mú un wá láti inú pápá, níbi tí ó ti ń da ẹran, pé kí ó wá jọba lórí, àwọn eniyan mi, Israẹli.

8 Mo sì ń wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó ń lọ, mo sì ti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run níwájú rẹ̀, n óo sì gbé orúkọ rẹ̀ ga bí orúkọ àwọn eniyan ńlá ayé.

9 N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo fìdí wọn múlẹ̀, wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́, àwọn ìkà kò tún ní ṣe wọ́n lófò mọ́ bíi ti àtijọ́,

10 nígbà tí mo ti yan àwọn adájọ́ láti darí Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo tẹ orí àwọn ọ̀tá wọn ba. Bákan náà, èmi OLUWA ṣe ìlérí pe n óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀.

11 Nígbà tí ọjọ́ bá pé tí ó bá kú, tí a sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀, n óo gbé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, àní ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin rẹ̀, n óo sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.

12 Yóo kọ́ ilé kan fún mi, n óo jẹ́ kí atọmọdọmọ rẹ̀ wà lórí ìtẹ́ títí lae.

13 N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi. N kò ní yẹ ìfẹ́ ńlá mi tí mo ní sí i, bí mo ti yẹ ti Saulu, tí ó ṣáájú rẹ̀.

14 N óo fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ ní ilé mi ati ninu ìjọba mi títí lae. N óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.’ ”

15 Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni Natani sọ fún Dafidi, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí i lójú ìran.

Adura Ọpẹ́ tí Dafidi Gbà

16 Dafidi bá lọ jókòó níwájú OLUWA, ó gbadura báyìí pé, “Kí ni èmi ati ilé mi jẹ́, tí o fi gbé mi dé ipò tí mo dé yìí?

17 Gbogbo èyí kò sì tó nǹkan lójú rẹ, Ọlọrun, o tún ṣèlérí nípa ìdílé èmi iranṣẹ rẹ fún ọjọ́ iwájú, o sì ti fi bí àwọn ìran tí ń bọ̀ yóo ti rí hàn mí, OLUWA Ọlọrun!

18 Kí ni mo tún lè sọ nípa iyì tí o bù fún èmi, iranṣẹ rẹ? Nítorí pé o mọ èmi iranṣẹ rẹ.

19 OLUWA, nítorí ti èmi iranṣẹ rẹ, ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni o fi ṣe àwọn nǹkan ńlá wọnyi, tí o sì fi wọ́n hàn.

20 Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, OLUWA, kò sì sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti fi etí wa gbọ́.

21 Ní gbogbo ayé, orílẹ̀-èdè wo ni ó tún dàbí Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí ìwọ Ọlọrun rà pada láti jẹ́ eniyan rẹ, tí o sì sọ orúkọ rẹ̀ di ńlá nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí o ṣe nígbà tí ó lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn eniyan rẹ, tí o rà pada láti ilẹ̀ Ijipti?

22 O ti sọ àwọn eniyan rẹ, Israẹli, di tìrẹ títí lae, ìwọ OLUWA sì di Ọlọrun wọn.

23 “Nisinsinyii, OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí o sọ nípa èmi iranṣẹ rẹ ṣẹ, ati ti ìran mi lẹ́yìn ọ̀la, kí o sì ṣe bí o ti wí.

24 Orúkọ rẹ yóo fìdí múlẹ̀ sí i, àwọn eniyan rẹ yóo sì máa gbé ọ́ ga títí lae, wọn yóo máa wí pé ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ó jẹ́ Ọlọrun Israẹli ni Israẹli mọ̀ ní Ọlọrun,’ ati pé ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ, yóo fìdí múlẹ̀ sí i níwájú rẹ.

25 Nítorí pé ìwọ Ọlọrun mi, ti fi han èmi iranṣẹ rẹ pé o óo fìdí ìdílé mi múlẹ̀, nítorí náà ni mo ṣe ní ìgboyà láti gbadura sí ọ.

26 OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun, o ti ṣe ìlérí ohun rere yìí fún èmi iranṣẹ rẹ.

27 Nítorí náà, jẹ́ kí ó wù ọ́ láti bukun ìdílé èmi iranṣẹ rẹ, kí ìdílé mi lè wà níwájú rẹ títí lae, nítorí ẹnikẹ́ni tí o bá bukun, olúwarẹ̀ di ẹni ibukun títí lae.”

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 18

Àwọn Ogun tí Dafidi Jà ní Àjàṣẹ́gun

1 Lẹ́yìn náà, Dafidi gbógun ti àwọn Filistini, ó ṣẹgun wọn, ó sì jagun gba ìlú Gati ati àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ lọ́wọ́ wọn.

2 Dafidi ṣẹgun àwọn ará Moabu, wọ́n di iranṣẹ rẹ̀, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un.

3 Ó ṣẹgun Hadadeseri, ọba Siria ní Soba, ní agbègbè ilẹ̀ Hamati, bí Hadadeseri tí ń lọ fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Yufurate.

4 Dafidi gba ẹgbẹrun (1,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ẹẹdẹgbaarin (7,000) ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun lọ́wọ́ rẹ̀. Ó rọ́ àwọn ẹṣin náà lẹ́sẹ̀, ṣugbọn ó dá àwọn kan sí fún ọgọrun-un (100) kẹ̀kẹ́ ogun.

5 Nígbà tí àwọn ará Siria wá láti Damasku, láti ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi gbógun tì wọ́n, ó sì pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn.

6 Dafidi fi àwọn ọmọ ogun ṣọ́ Siria ti Damasku, àwọn ará Siria di iranṣẹ Dafidi, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.

7 Dafidi gba àwọn apata wúrà tí wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ Hadadeseri, ó kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.

8 Ó kó ọpọlọpọ idẹ ní Tibihati ati Kuni, tí wọ́n wà lábẹ́ Hadadeseri. Idẹ yìí ni Solomoni fi ṣe agbada omi ńlá ati òpó ati àwọn ohun èlò idẹ fún ilé OLUWA.

9 Nígbà tí Toi, ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ọba Soba,

10 ó rán Hadoramu, ọmọ rẹ̀, pé kí ó lọ kí Dafidi ọba, kí ó sì bá a yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun tí ó ní lórí Hadadeseri, nítorí Hadadeseri ti bá Toi pàápàá jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Toi sì fi oríṣìíríṣìí ohun èlò wúrà, fadaka, ati idẹ ranṣẹ sí Dafidi.

11 Dafidi yà wọ́n sí mímọ́ fún OLUWA, fún iṣẹ́ ìsìn pẹlu àwọn fadaka ati wúrà tí ó gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun: àwọn bíi Edomu ati Moabu, Amoni, Filistini ati Amaleki.

12 Abiṣai, ọmọ Seruaya, ṣẹgun àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀, ó pa ẹgbaa mẹsan-an (18,000) ninu wọn.

13 Ó fi àwọn ọmọ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì di iranṣẹ Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.

14 Dafidi jọba lórí gbogbo Israẹli, ó ń dá ẹjọ́ òtítọ́, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ fún gbogbo àwọn eniyan.

15 Joabu, ọmọ Seruaya, ni Balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀.

16 Sadoku, ọmọ Ahitubu ati Ahimeleki ọmọ Abiatari ni alufaa.

17 Ṣafiṣa ni akọ̀wé ilé ẹjọ́. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ní ń ṣe àkóso àwọn Kereti ati Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, àwọn ọmọ Dafidi lọkunrin ni wọ́n sì wà ní àwọn ipò tí ó ga ninu ìjọba rẹ̀.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 19

Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni ati Àwọn Ará Siria

1 Nígbà tí ó yá, Nahaṣi, ọba àwọn ará Amoni kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

2 Dafidi ní, “N óo fi ìfẹ́ hàn sí Hanuni bí baba rẹ̀ ti fi ìfẹ́ hàn sí mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ kí i kú àṣẹ̀yìndè baba rẹ̀. Àwọn oníṣẹ́ Dafidi bá lọ sọ́dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ Amoni láti bá a kẹ́dùn.

3 Ṣugbọn àwọn ìjòyè ilẹ̀ Amoni sọ fún ọba pé, “Ṣé o rò pé Dafidi ń bọ̀wọ̀ fún baba rẹ ni ó ṣe rán oníṣẹ́ láti wá bá ọ kẹ́dùn? Rárá o. Ó rán wọn láti wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni, kí ó baà lè ṣẹgun rẹ.”

4 Nítorí náà, Hanuni mú àwọn oníṣẹ́ Dafidi, ó fá irùngbọ̀n wọn, ó gé ẹ̀wù wọn ní ìbàdí, ó sì lé wọn jáde.

5 Ojú tì wọ́n pupọ wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró sí Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa pada bọ̀ wá sílé.

6 Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé Dafidi ti kórìíra àwọn, Hanuni ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ẹgbẹrun (1,000) talẹnti fadaka ranṣẹ sí Mesopotamia, ati sí Aramu-maaka ati sí Soba, láti yá kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin.

7 Wọ́n yá ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ọba Maaka pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ ogun wọn sí ẹ̀bá Medeba. Àwọn ará Amoni náà wá kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti gbogbo ìlú wọn.

8 Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó rán Joabu ati gbogbo àwọn akọni jagunjagun rẹ̀ jáde lọ bá wọn.

9 Àwọn ogun Amoni tò lẹ́sẹẹsẹ siwaju ẹnubodè ìlú wọn, ṣugbọn àwọn ọba tí wọ́n bẹ̀ lọ́wẹ̀ wà lọ́tọ̀ ninu pápá.

10 Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá ti gbógun ti òun níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli láti dojú kọ àwọn ará Siria.

11 Ó fi àwọn ọmọ ogun yòókù sí abẹ́ Abiṣai, arakunrin rẹ̀, wọ́n sì dojú kọ àwọn ọmọ ogun Amoni.

12 Joabu ní, “Bí àwọn ọmọ ogun Siria bá lágbára jù fún mi, wá ràn mí lọ́wọ́, bí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Amoni ni wọ́n bá lágbára jù fún ọ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́.

13 Ṣe ọkàn rẹ gírí, jẹ́ kí á jà gidigidi fún àwọn eniyan wa, ati fún àwọn ìlú Ọlọrun wa; kí OLUWA ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ̀.”

14 Joabu ati àwọn ogun Israẹli súnmọ́ àwọn ọmọ ogun Siria láti bá wọn jà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Siria sá fún wọn.

15 Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn náà sá fun Abiṣai, wọn sì wọ ìlú wọn lọ. Joabu bá pada sí Jerusalẹmu.

16 Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn, wọ́n ranṣẹ lọ pe àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wà ni ìkọjá odò Yufurate, wọ́n sì fi wọ́n sí abẹ́ Ṣobaki, balogun Hadadeseri.

17 Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo ọmọ ogun Israẹli jọ, wọ́n rékọjá odò Jọdani, wọ́n lọ dojú kọ ogun Siria, àwọn ọmọ ogun Siria bá bẹ̀rẹ̀ sí bá Dafidi jagun.

18 Àwọn ogun Siria sá níwájú Israẹli. Dafidi pa ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn tí wọn ń wa kẹ̀kẹ́-ogun ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, ó sì pa Ṣobaki olórí ogun Siria.

19 Nígbà tí àwọn iranṣẹ Hadadeseri rí i pé Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bẹ Dafidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn ín. Nítorí náà, àwọn ará Siria kò wá ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́ mọ́.