Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Kronika Kinni ati Ekeji

sọ ìtàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Samuẹli Kinni ati Ekeji, ati ti inú ìwé Àwọn Ọba. Ṣugbọn bí ìwé Kronika ṣe gbé ìtàn tirẹ̀ kalẹ̀ yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. Ìdí meji pataki ni

Ìwé Kronika

tọ́ka sí pé ó fa àyípadà ìjọba Israẹli, láti ètò yíyan adájọ́ gẹ́gẹ́ bí olórí, sí ètò yíyan ọba láàrin àwọn eniyan.

(1) Ekinni ni láti fihàn pé pẹlu gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Israẹli ati ti Juda, Ọlọrun ṣì ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lórí orílẹ̀-èdè náà nípasẹ̀ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Juda. Òǹkọ̀wé yìí lo àṣeyọrí tí àwọn ọba kan ṣe láti fi gbe akiyesi rẹ̀ lẹ́sẹ̀: Ó tọ́ka sí àṣeyọrí àwọn ọba olókìkí bíi Dafidi ati Solomoni, àwọn àtúnṣe tí àwọn ọba bíi Jehoṣafati, Hesekaya ati Josaya ṣe, ati àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọrun.

(2) Ìdí keji ni láti ṣe àlàyé bí ìjọ́sìn ninu Tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu ṣe bẹ̀rẹ̀, pàápàá ètò àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, ati ìlànà ìjọ́sìn, Dafidi ni wọ́n gbà pé ó ṣe ètò ati ìlànà náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Solomoni ni ó kọ́ Tẹmpili, Dafidi ni ó gba ògo gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì fi ìlànà ìsìn lélẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli ati ìrandíran wọn 1:1–9:44

Ikú Saulu 10:1-14

Ìjọba Dafidi 11:1–29:30

a. Ọpọlọpọ ìdààmú ati àṣeyọrí rẹ̀ 11:1–22:1

b. Ìpalẹ̀mọ́ fún kíkọ́ Tẹmpili 22:2–29:30

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 1

Ìran Adamu títí Dé Orí Abrahamu

1 Adamu bí Seti, Seti bí Enọṣi.

2 Enọṣi bí Kenaani, Kenaani bí Mahalaleli, Mahalaleli bí Jaredi;

3 Jaredi bí Enọku, Enọku bí Metusela, Metusela bí Lamẹki;

4 Lamẹki bí Noa, Noa bí Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti.

5 Àwọn ọmọ Jafẹti ni Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi.

6 Gomeri ni baba ńlá àwọn ọmọ Aṣikenasi, Difati ati Togama.

7 Jafani ni baba ńlá àwọn ọmọ Eliṣa, Taṣiṣi, ati àwọn ará Kitimu, ati Rodọni.

8 Hamu ni baba Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani,

9 Kuṣi bí Ṣeba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka; Raama ni baba Ṣeba ati Dedani,

10 Kuṣi bí Nimrodu. Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí ó di akikanju ati alágbára lórí ilẹ̀ ayé.

11 Ijipti ni baba àwọn ará Lidia ati ti Anamu, ti Lehabu, ati ti Nafitu;

12 àwọn ará Patirusimu ati ti Kasilu tíí ṣe baba ńlá àwọn ará Filistia ati àwọn ará Kafito.

13 Àkọ́bí Kenaani ní Sidoni, lẹ́yìn rẹ̀ ó bí Heti,

14 Kenaani yìí náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Girigaṣi;

15 àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki ati àwọn ará Sini;

16 àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari ati àwọn ará Hamati.

17 Ṣemu ni baba Elamu, Aṣuri, ati Apakiṣadi, Ludi, Aramu, ati Usi, Huli, Geteri ati Meṣeki.

18 Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela ni baba Eberi,

19 Eberi bí ọmọkunrin meji: Ekinni ń jẹ́ Pelegi, (nítorí pé ní àkókò tirẹ̀ ni àwọn eniyan ayé pín sí meji); ọmọ Eberi keji sì ń jẹ́ Jokitani,

20 Jokitani ni ó bí Alimodadi, Ṣelefu, Hasarimafeti, ati Jera;

21 Hadoramu, Usali, ati Dikila;

22 Ebali, Abimaeli, ati Ṣeba,

23 Ofiri, Hafila ati Jobabu; Àwọn ni àwọn ọmọ Jokitani.

24 Arọmọdọmọ Ṣemu títí fi dé orí Abramu nìyí: Ṣemu, Apakiṣadi, Ṣela;

25 Eberi, Pelegi, Reu;

26 Serugi, Nahori, Tẹra;

27 Abramu, tí a tún ń pè ní Abrahamu.

Ìran Iṣimaeli

28 Àwọn ọmọ Abrahamu ni Isaaki ati Iṣimaeli.

29 Àkọsílẹ̀ ìran wọn nìyí: Nebaiotu ni àkọ́bí Iṣimaeli, lẹ́yìn náà ni ó bí Kedari, Adibeeli, ati Mibisamu;

30 Miṣima, Duma ati Masa; Hadadi ati Tema;

31 Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema.

32 Abrahamu ní obinrin kan tí ń jẹ́ Ketura. Ó bí àwọn ọmọ mẹfa wọnyi fún Abrahamu: Simirani, Jokiṣani ati Medani; Midiani, Iṣibaki ati Ṣua. Àwọn ọmọ ti Jokiṣani ni: Ṣeba ati Dedani.

33 Àwọn ọmọ marun-un tí Midiani bí ni Efa, Eferi ati Hanoku, Abida ati Elidaa. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Ketura.

Àwọn Ìran Esau

34 Abrahamu ni baba Isaaki. Àwọn ọmọ Isaaki meji ni Esau ati Jakọbu.

35 Àwọn ọmọ Esau ni Elifasi, Reueli, ati Jeuṣi; Jalamu ati Kora.

36 Àwọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari ati Sefi; Gatamu, Kenasi, Timna ati Amaleki.

37 Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama ati Misa.

Àwọn tí Ń Gbé Edomu Tẹ́lẹ̀

38 Àwọn ọmọ Seiri ni Lotani, Ṣobali ati Sibeoni; Ana, Diṣoni, Eseri ati Diṣani.

39 Àwọn ọmọ Lotani ni Hori ati Homami. Lotani ní arabinrin kan tí ń jẹ́ Timna.

40 Àwọn ọmọ Ṣobali ni Aliani, Manahati ati Ebali; Ṣefi ati Onamu. Sibeoni ni baba Aia ati Ana.

41 Ana ni baba Diṣoni. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hamirani, Eṣibani, Itirani ati Kerani.

42 Eseri ló bí Bilihani, Saafani ati Jaakani. Diṣani ni baba Usi ati Arani.

Àwọn Ọba Edomu

43 Àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní ilẹ̀ Edomu, kí ọba kankan tó jẹ ní ilẹ̀ Israẹli nìwọ̀nyí: Bela, ọmọ Beori; orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu, ọmọ Sera, ará Bosara, jọba tẹ̀lé e.

45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu, ará ìlú kan ní agbègbè Temani, jọba tẹ̀lé e.

46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi, ọmọ Bedadi, tí ó ṣẹgun àwọn ará Midiani ní ilẹ̀ Moabu, jọba tẹ̀lé e. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

47 Nígbà tí Hadadi kú, Samila ará Masireka, jọba tẹ̀lé e.

48 Nígbà tí Samila kú, Ṣaulu ará Rehoboti létí odò Yufurate, jọba tẹ̀lé e.

49 Nígbà tí Ṣaulu kú, Baali Hanani, ọmọ Akibori, jọba tẹ̀lé e.

50 Nígbà tí Baali Hanani kú, Hadadi, jọba tẹ̀lé e. Ìlú tirẹ̀ ni Pau. Iyawo rẹ̀ ni Mehetabeli, ọmọ Matiredi, ìyá rẹ̀ àgbà ni Mesahabu. Nígbà tí ó yá, Hadadi náà kú.

51 Àwọn ìjòyè ẹ̀yà Edomu nìwọ̀nyí: Timna, Alia, ati Jeteti;

52 Oholibama, Ela, ati Pinoni,

53 Kenasi, Temani, ati Mibisari,

54 Magidieli ati Iramu.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 2

Àwọn Arọmọdọmọ Juda

1 Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni;

2 Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri.

3 Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á.

4 Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera.

5 Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli.

6 Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada.

7 Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀.

8 Etani ni ó bí Asaraya.

Ìran Dafidi Ọba

9 Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai.

10 Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda,

11 Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi,

12 Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese.

13 Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea;

14 Netaneli ati Radai;

15 Osemu ati Dafidi.

16 Àwọn arabinrin wọn ni Seruaya ati Abigaili. Seruaya yìí ló bí Abiṣai, Joabu ati Asaheli.

17 Abigaili fẹ́ Jeteri láti inú ìran Iṣimaeli, ó sì bí Amasa fún un.

Ìran Hesironi

18 Hesironi ni baba Kalebu. Asuba (ati Jeriotu) ni aya Kalebu yìí, Asuba bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeseri, Ṣobabu, ati Aridoni.

19 Nígbà tí Asuba kú, Kalebu fẹ́ Efurati, Efurati sì bí Huri fún un.

20 Huri ni ó bí Uri, Uri sì bí Besaleli.

21 Nígbà tí Hesironi di ẹni ọgọta ọdún, ó fẹ́ ọmọbinrin Makiri, baba Gileadi. Ọmọbinrin yìí sì bí ọmọkunrin kan fún un tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Segubu.

22 Segubu ni ó bí Jairi, tí ó jọba lórí ìlú ńláńlá mẹtalelogun ní ilẹ̀ Gileadi.

23 Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi.

24 Lẹ́yìn ìgbà tí Hesironi kú, Kalebu ṣú Efurata, iyawo baba rẹ̀ lópó, ó sì bí Aṣuri, tíí ṣe baba Tekoa.

Àwọn Ìran Jerameeli

25 Jerameeli, àkọ́bí Hesironi, bí ọmọkunrin marun-un: Ramu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Buna, Oreni, Osemu, ati Ahija.

26 Jerameeli tún ní aya mìíràn, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara, òun ni ìyá Onamu.

27 Àwọn ọmọ Ramu, àkọ́bí Jerameeli ni: Maasi, Jamini ati Ekeri.

28 Onamu bí ọmọ meji: Ṣamai ati Jada. Ṣamai náà bí ọmọ meji: Nadabu ati Abiṣuri.

29 Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un.

30 Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú.

31 Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai.

32 Jada, arakunrin Ṣamai, bí ọmọ meji: Jeteri ati Jonatani, ṣugbọn Jeteri kò bímọ títí tí ó fi kú.

33 Jonatani bí ọmọ meji: Peleti ati Sasa. Àwọn ni ìran Jerameeli.

34 Ṣeṣani kò bí ọmọkunrin kankan, kìkì ọmọbinrin ni ó bí; ṣugbọn Ṣeṣani ní ẹrú kan, ará Ijipti, tí ń jẹ́ Jariha.

35 Ṣeṣani fi ọmọ rẹ̀ obinrin fún Jariha, ẹrú rẹ̀, ó sì bí Atai fún ẹrú náà.

36 Atai ni baba Natani, Natani sì ni baba Sabadi.

37 Sabadi bí Efiali, Efiali sì bí Obedi.

38 Obedi ni baba Jehu, Jehu sì ni baba Asaraya.

39 Asaraya ni ó bí Helesi, Helesi ni ó sì bí Eleasa.

40 Eleasa bí Sisimai, Sisimai bí Ṣalumu;

41 Ṣalumu bí Jekamaya, Jekamaya sì bí Eliṣama.

Àwọn Ìran Kalebu Yòókù

42 Àwọn ọmọ Kalebu, arakunrin Jerameeli, nìwọ̀nyí: Mareṣa, baba Sifi ni àkọ́bí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Heburoni.

43 Heburoni bí ọmọ mẹrin: Kora, Tapua, Rekemu ati Ṣema.

44 Ṣema bí Rahamu, Rahamu bí Jokeamu, Rekemu sì bí Ṣamai.

45 Ṣamai ló bí Maoni, Maoni sì bí Betisuri.

46 Kalebu tún ní obinrin kan tí ń jẹ́ Efa, ó bí ọmọ mẹta fún un: Harani, Mosa ati Gasesi. Harani bí ọmọ kan tí ń jẹ́ Gasesi.

47 Àwọn ọmọ Jadai nìwọ̀nyí: Regemu, Jotamu, ati Geṣani, Peleti, Efa ati Ṣaafu.

48 Kalebu tún ní obinrin mìíràn tí ń jẹ́ Maaka. Ó bí ọmọ meji fún un: Ṣeberi ati Tirihana.

49 Maaka yìí kan náà ni ó bí Ṣaafu, baba Madimana, tí ó tẹ ìlú Madimana dó, ati Ṣefa, baba Makibena ati Gibea, àwọn ni wọ́n tẹ ìlú Makibena ati ìlú Gibea dó.

Kalebu tún bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Akisa.

50 Àwọn ìran Kalebu yòókù ni: àwọn ọmọ Huri àkọ́bí Efurata, iyawo Kalebu: ati Ṣobali, baba Kiriati Jearimu;

51 Salima, baba Bẹtilẹhẹmu, ati Harefu baba Betigaderi.

52 Ṣobali baba Kiriati Jearimu ni baba gbogbo àwọn ará Haroe, ati ìdajì àwọn tí ń gbé Menuhotu,

53 Òun náà ni baba ńlá gbogbo àwọn ìdílé tí ń gbé Kiriati Jearimu, àwọn ìdílé bíi Itiri, Puti, Ṣumati, ati Miṣirai; lára wọn ni àwọn tí wọn ń gbé ìlú Sora ati Eṣitaolu ti ṣẹ̀.

54 Salima ni baba àwọn ará Bẹtilẹhẹmu, Netofati, ati ti Atirotu Beti Joabu; àwọn ará Soriti ati ìdajì àwọn ará Manahati.

55 Àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé tí wọn ń gbé Jabesi nìyí: àwọn ará Tirati, Ṣimeati, ati Sukati. Àwọn ni ará Keni tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Hamati baba ńlá wọn ní ilé Rekabu.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 3

Àwọn Ọmọ Dafidi Ọba

1 Àwọn ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Heburoni nìwọ̀nyí, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Aminoni tí Ahinoamu ará Jesireeli bí fún un ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Daniẹli, ọmọ Abigaili ará Kamẹli.

2 Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọbinrin Talimai, ọba ìlú Geṣuri; lẹ́yìn náà Adonija ọmọ Hagiti.

3 Ẹkarun-un ni Ṣefataya, ọmọ Abitali; lẹ́yìn rẹ̀ ni Itireamu ọmọ Egila.

4 Ní Heburoni, níbi tí Dafidi ti jọba fún ọdún meje ati ààbọ̀, ni wọ́n ti bí àwọn mẹfẹẹfa fún un.

Lẹ́yìn náà, Dafidi jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹtalelọgbọn.

5 Àwọn ọmọ tí Dafidi bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:

Batiṣeba, ọmọbinrin Amieli, bí ọmọ mẹrin fún un: Ṣimea, Ṣobabu, Natani ati Solomoni.

6 Àwọn ọmọ mẹsan-an mìíràn tí Dafidi tún bí ni: Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti;

7 Noga, Nefegi, ati Jafia,

8 Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti,

9 Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari.

Ìran Solomoni Ọba

10 Àwọn ọmọ Solomoni ọba nìwọ̀nyí: Rehoboamu, Abija, Asa, ati Jehoṣafati;

11 Joramu, Ahasaya, ati Joaṣi;

12 Amasaya, Asaraya, ati Jotamu;

13 Ahasi, Hesekaya, ati Manase,

14 Amoni ati Josaya.

15 Orúkọ àwọn ọmọ Josaya mẹrẹẹrin, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn ni: Johanani, Jehoiakimu, Sedekaya ati Ṣalumu.

16 Jehoiakimu bí ọmọ meji: Jekonaya ati Sedekaya.

Àwọn Ìran Jehoiakini

17 Àwọn ọmọ Jehoiakini, ọba tí a mú lẹ́rú lọ sí Babiloni nìwọ̀nyí: Ṣealitieli,

18 Malikiramu, Pedaaya, ati Ṣenasari, Jekamaya, Hoṣama ati Nedabaya.

19 Pedaaya bí ọmọ meji: Serubabeli, ati Ṣimei. Serubabeli bí ọmọ meji: Meṣulamu ati Hananaya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣelomiti.

20 Serubabeli tún bí ọmọ marun-un mìíràn: Haṣuba, Oheli, ati Berekaya; Hasadaya ati Juṣabi Hesedi.

21 Hananaya bí ọmọ meji: Pelataya ati Jeṣaaya, àwọn ọmọ Refaaya, ati ti Arinoni, ati ti Ọbadaya, ati ti Ṣekanaya.

22 Ṣekanaya ní ọmọ kan, tí ń jẹ́ Ṣemaaya. Ṣemaaya bí ọmọ marun-un: Hatuṣi, Igali, Baraya, Nearaya ati Ṣafati.

23 Nearaya bí ọmọ mẹta: Elioenai, Hisikaya ati Asirikamu.

24 Elioenai bí ọmọ meje: Hodafaya, Eliaṣibu, Pelaaya, Akubu, Johanani, Delaaya ati Anani.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 4

Ìran Juda

1 Àwọn ọmọ Juda ni: Peresi, Hesironi, Kami, Huri, ati Ṣobali.

2 Ṣobali ni ó bí Reaaya. Reaaya sì bí Jahati. Jahati ni baba Ahumai ati Lahadi. Àwọn ni ìdílé àwọn tí ń gbé Sora.

3 Àwọn ọmọ Etamu ni: Jesireeli, Iṣima, ati Idibaṣi. Orúkọ arabinrin wọn ni Haseleliponi.

4 Penueli ni baba Gedori. Eseri bí Huṣa. Àwọn ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efurata, tí ó jẹ́ baba Bẹtilẹhẹmu.

5 Aṣuri, baba Tekoa, ní aya meji: Hela ati Naara.

6 Naara bí ọmọ mẹrin fún un: Ahusamu, Heferi, Temeni, ati Haahaṣitari.

7 Hela bí ọmọ mẹta fún un: Sereti, Iṣari, ati Etinani.

8 Kosi ni baba Anubi ati Sobeba. Òun ni baba ńlá àwọn ìdílé Ahaheli, ọmọ Harumu.

9 Ọkunrin kan, tí à ń pè ní Jabesi, jẹ́ eniyan pataki ju àwọn arakunrin rẹ̀ lọ. Ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ yìí nítorí ìrora pupọ tí ó ní nígbà tí ó bí i.

10 Jabesi gbadura sí Ọlọrun Israẹli pé, “Ọlọrun jọ̀wọ́ bukun mi, sì jẹ́ kí ilẹ̀ ìní mi pọ̀ sí i. Wà pẹlu mi, pa mí mọ́ kúrò ninu ewu, má jẹ́ kí jamba ṣe mí!” Ọlọrun sì ṣe ohun tí ó fẹ́ fún un.

Àwọn Ìdílé Yòókù

11 Kelubu, arakunrin Ṣuha, ni baba Mehiri, Mehiri ni baba Eṣitoni.

12 Eṣitoni yìí ni ó bí Betirafa, Pasea ati Tẹhina. Tẹhina sì ni baba Irinahaṣi. Àwọn ni wọ́n ń gbé Reka.

13 Kenasi bí ọmọ meji: Otinieli ati Seraaya. Otinieli náà bí Hatati ati Meonotai.

14 Meonotai ni baba Ofira.

Seraaya sì ni baba Joabu, baba àwọn ará Geharaṣimu, ìlú àwọn oníṣọ̀nà. Àwọn ni wọ́n tẹ gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ dó.

15 Kalebu, ọmọ Jefune, bí ọmọ mẹta: Iru, Ela, ati Naamu. Ela ni ó bí Kenasi.

16 Jehaleli sì ni baba Sifi, Sifa, Tiria, ati Asareli.

17 Ẹsira bí Jeteri, Meredi, Eferi, ati Jaloni. Meredi fẹ́ Bitia, ọmọbinrin Farao. Wọ́n bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu ati ọmọkunrin meji: Ṣamai ati Iṣiba.

18 Iṣiba ni baba Eṣitemoa. Meredi tún ní iyawo mìíràn, òun jẹ́ ará Juda, ó bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeredi, baba Gedori, Heberi baba Soko, ati Jekutieli, baba Sanoa.

19 Hodia fẹ́ arabinrin Nahamu, àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ṣẹ ẹ̀yà Garimi, tí wọn ń gbé ìlú Keila sílẹ̀, ati àwọn ìran Maakati tí wọn ń gbé ìlú Eṣitemoa.

20 Simoni ni baba Aminoni, Rina, Benhanani ati Tiloni. Iṣi sì ni baba Soheti ati Benisoheti.

Àwọn Ìran Ṣela

21 Ṣela, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Juda, ni baba Eri, baba Leka. Laada ni baba Mareṣa, ati ìdílé àwọn tí wọ́n ń hun aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun ní Beti Aṣibea

22 ati Jokimu, ati àwọn ará ìlú Koseba, Joaṣi ati Sarafu, tí wọ́n fi ìgbà kan jẹ́ alákòóso ní Moabu, tí wọ́n sì pada sí Bẹtilẹhẹmu. (Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ti àtijọ́.)

23 Wọ́n jẹ́ amọ̀kòkò ní ààfin ọba, wọ́n sì ń gbé ìlú Netaimu ati Gedera.

Àwọn Ìran Simeoni

24 Simeoni ni baba Nemueli, Jamini, Jaribu, Sera, ati Ṣaulu.

25 Ṣaulu bí Ṣalumu, Ṣalumu bí Mibisamu, Mibisamu sì bí Miṣima.

26 Àwọn ọmọ Miṣima nìyí: Hamueli, Sakuri, ati Ṣimei.

27 Ṣimei bí ọmọkunrin mẹrindinlogun ati ọmọbinrin mẹfa. Ṣugbọn àwọn arakunrin rẹ̀ kò bí ọmọ pupọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà rẹ̀ kò pọ̀ bí ẹ̀yà Juda.

28 Àwọn ìran Simeoni ní ń gbé àwọn ìlú wọnyi títí di àkókò ọba Dafidi: Beeriṣeba, Molada, ati Hasariṣuali.

29 Biliha, Esemu, ati Toladi;

30 Betueli, Horima, ati Sikilagi;

31 Beti Makabotu, Hasasusimu, Betibiri, ati Ṣaaraimu.

32 Àwọn ìletò wọn ni: Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni ati Aṣani,

33 àwọn ìlú marun-un pẹlu àwọn ìgbèríko tí ó yí wọn ká títí dé ìlú Baali. Àwọn agbègbè náà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ní àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.

34 Meṣobabu, Jamileki, ati Joṣa, jẹ́ ọmọ Amasaya;

35 Joẹli, ati Jehu, ọmọ Joṣibaya, ọmọ Seraaya, ọmọ Asieli.

36 Elioenai, Jaakoba, ati Jeṣohaya; Asaya, Adieli, Jesimieli ati Bẹnaya;

37 Sisa, ọmọ Ṣifi, ọmọ Aloni, ọmọ Jedaaya, ọmọ Ṣimiri, ọmọ Ṣemaaya.

38 Gbogbo wọn jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, ìdílé àwọn baba wọn sì pọ̀ lọpọlọpọ.

39 Wọ́n rìn títí dé ẹnubodè Gedori, ní apá ìlà oòrùn àfonífojì, láti wá koríko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.

40 Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí ilẹ̀ tí ó ní koríko, tí ó sì dára fún àwọn ẹran wọn. Ilẹ̀ náà tẹ́jú, ó parọ́rọ́, alaafia sì wà níbẹ̀; àwọn ọmọ Hamu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.

41 Nígbà tí Hesekaya, ọba Juda wà lórí oyè, àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi lọ sí Meuni, wọ́n ba àgọ́ àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ jẹ́, wọ́n pa wọ́n run títí di òní, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilẹ̀ tiwọn, nítorí pé koríko tútù pọ̀ níbẹ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.

42 Ẹẹdẹgbẹta (500) ninu àwọn eniyan Simeoni ló lọ sí òkè Seiri; àwọn olórí wọn ni: Pelataya, Nearaya, Refaaya, ati Usieli, lára àwọn ọmọ Iṣi.

43 Wọ́n pa àwọn ọmọ Amaleki yòókù tí wọ́n sá àsálà, wọ́n sì ń gbé orí ilẹ̀ wọn títí di òní olónìí.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 5

Ìran Reubẹni

1 Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí.

2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà Juda di ẹ̀yà tí ó lágbára ju gbogbo ẹ̀yà yòókù lọ, tí wọ́n sì ń jọba lórí wọn, sibẹsibẹ ipò àkọ́bí jẹ́ ti àwọn ọmọ Josẹfu).

3 Àwọn ọmọ Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu, ni: Hanoku, Palu, Hesironi ati Kami.

4 Joẹli ni ó bí Ṣemaya, Ṣemaya bí Gogu, Gogu bí Ṣimei;

5 Ṣimei bí Mika, Mika bí Reaaya, Reaaya bí Baali;

6 Baali bí Beera, tí Tigilati Pileseri ọba Asiria mú lẹ́rú lọ; Beera yìí jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà Reubẹni.

7 Àwọn arakunrin rẹ̀ ní ìdílé wọn, nígbà tí a kọ àkọsílẹ̀, ìran wọn nìyí: olórí wọn ni Jeieli, ati Sakaraya, ati

8 Bela, ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli, tí wọn ń gbé Aroeri títí dé Nebo ati Baali Meoni.

9 Ilẹ̀ wọn lọ ní apá ìlà oòrùn títí dé àtiwọ aṣálẹ̀, ati títí dé odò Yufurate, nítorí pé ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ ní ilẹ̀ Gileadi.

10 Ní àkókò ọba Saulu, àwọn ẹ̀yà Reubẹni wọnyi gbógun ti àwọn ará Hagiriti, wọ́n pa wọ́n run, wọ́n gba ilẹ̀ wọn tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Gileadi.

Àwọn Ìran Gadi

11 Àwọn ẹ̀yà Gadi ń gbé òdìkejì ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀ Baṣani, títí dé Saleka:

12 Joẹli ni olórí wọn ní ilẹ̀ Baṣani, Safamu ni igbá keji rẹ̀; àwọn olórí yòókù ni Janai ati Ṣafati.

13 Àwọn arakunrin wọn ní ìdílé wọn ni: Mikaeli, Meṣulamu, ati Ṣeba; Jorai, Jakani, Sia, ati Eberi, gbogbo wọn jẹ́ meje.

14 Àwọn ni ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jahido, ọmọ Busi.

15 Ahi, ọmọ Abidieli, ọmọ Guni ni olórí ìdílé baba wọn;

16 wọ́n ń gbé Gileadi, Baṣani ati àwọn ìlú tí wọ́n yí Baṣani ká, ati ní gbogbo ilẹ̀ pápá Ṣaroni.

17 A kọ àkọsílẹ̀ wọn ní àkókò Jotamu, ọba Juda, ati ní àkókò Jeroboamu ọba Israẹli.

Àwọn Ọmọ Ogun Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn

18 Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, àwọn ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ní ẹgbaa mejilelogun ati ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (44,760) akọni ọmọ ogun tí wọ́n ń lo asà, idà, ọfà ati ọrun lójú ogun, tí wọ́n gbáradì fún ogun.

19 Wọ́n gbógun ti àwọn ará Hagiriti, Jeturi, Nafiṣi ati Nodabu.

20 Nígbà tí wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ gbà, wọ́n ṣẹgun àwọn ará Hagiriti ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn, nítorí wọ́n ké pe Ọlọrun lójú ogun náà, ó sì gbọ́ igbe wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

21 Àwọn ẹran ọ̀sìn tí wọ́n kó lójú ogun nìwọ̀nyí: ẹgbaa mẹẹdọgbọn (50,000) ràkúnmí, ọ̀kẹ́ mejila lé ẹgbaarun (250,000) aguntan, ati ẹgbaa (2,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; wọ́n sì kó ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọkunrin lẹ́rú.

22 Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n pa, nítorí pé Ọlọrun ni ó jà fún wọn; wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn títí tí àwọn ará Asiria fi kó wọn lẹ́rú.

Ìdajì Ẹ̀yà Manase Tí Ń gbé Ìhà Ìlà Oòrùn

23 Ìdajì ẹ̀yà Manase ń gbé Baṣani, wọ́n pọ̀ pupọ; wọ́n tàn ká títí dé Baali Herimoni, Seniri, ati òkè Herimoni.

24 Àwọn Olórí ìdílé wọn nìwọ̀nyí: Eferi, Iṣi, Elieli, ati Asirieli; Jeremaya, Hodafaya ati Jahidieli, akikanju jagunjagun ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ olókìkí ati olórí ní ilé baba wọn.

A Kó Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Lẹ́rú Lọ

25 Ṣugbọn àwọn ẹ̀yà náà ṣẹ Ọlọrun baba wọn, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa tí àwọn tí Ọlọrun parun nítorí wọn ń bọ.

26 Nítorí náà, Ọlọrun ta Pulu ọba Asiria ati Tigilati Pileseri ọba Asiria, nídìí láti gbógun ti ilẹ̀ náà; wọ́n bá kó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọn ń gbé ìhà ìlà oòrùn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ Hala, Habori, Hara, ati ẹ̀bá odò Gosani títí di òní olónìí.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 6

Ìran Àwọn Olórí Alufaa

1 Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Geṣomu, Kohati ati Merari.

2 Kohati bí ọmọkunrin mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli.

3 Amramu bí ọmọ mẹta: Aaroni, Mose, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu.

Aaroni bí ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

4 Ìran Eleasari ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Eleasari ni baba Finehasi, Finehasi ni ó bí Abiṣua;

5 Abiṣua bí Buki, Buki sì bí Usi.

6 Usi ni baba Serahaya, Serahaya ló bí Meraiotu,

7 Meraiotu bí Amaraya, Amaraya sì bí Ahitubu.

8 Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi,

9 Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani.

10 Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

11 Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu;

12 Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu.

13 Ṣalumu ni baba Hilikaya; Hilikaya bí Asaraya,

14 Asaraya bí Seraaya; Seraaya sì bí Jehosadaki.

15 Jehosadaki lọ sí ìgbèkùn nígbà tí Ọlọrun jẹ́ kí Nebukadinesari wá kó Juda ati Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.

Àwọn Ìran Lefi Yòókù

16 Àwọn ọmọ Lefi ni: Geriṣoni, Kohati ati Merari.

17 Àwọn ọmọ Geriṣoni ni: Libini ati Ṣimei.

18 Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli.

19 Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili ati Muṣi. Àwọn ni baba ńlá àwọn ọmọ Lefi.

20 Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Geriṣoni nìwọ̀nyí: Libini ni baba Jahati, Jahati bí Sima,

21 Sima bí Joa, Joa bí Ido, Ido bí Sera, Sera sì bí, Jeaterai.

22 Àwọn tí ó ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kohati nìwọ̀nyí: Aminadabu ni baba Kora, Kora ló bí Asiri;

23 Asiri bí Elikana, Elikana bí Ebiasafu, Ebiasafu sì bí Asiri.

24 Asiri ni baba Tahati, Tahati ló bí Urieli, Urieli bí Usaya, Usaya sì bí Saulu.

25 Ọmọ meji ni Elikana bí: Amasai ati Ahimotu.

26 Àwọn ọmọ Ahimotu nìwọ̀nyí: Elikana ni baba Sofai, Sofai ni ó bí Nahati;

27 Nahati bí Eliabu, Eliabu bí Jerohamu, Jerohamu sì bí Elikana.

28 Samuẹli bí ọmọkunrin meji: Joẹli ni àkọ́bí, Abija sì ni ikeji.

29 Àwọn ọmọ Merari nìwọ̀nyí: Mahili ni baba Libini, Libini bí Ṣimei,

30 Ṣimei bí Usali, Usali bí Ṣimea, Ṣimea bí Hagaya, Hagaya sì bí Asaya.

Àwọn Ẹgbẹ́ Akọrin Tẹmpili

31 Dafidi fi àwọn wọnyi ṣe alákòóso ẹgbẹ́ akọrin ninu ilé OLUWA lẹ́yìn tí wọn ti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sibẹ;

32 àwọn ni wọ́n ń kọ orin ninu Àgọ́ Àjọ títí tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA parí ní Jerusalẹmu; àṣegbà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn.

33 Àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà, pẹlu àwọn ọmọ wọn nìwọ̀nyí:

Ninu ìdílé Kohati: Hemani, akọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,

34 ọmọ Elikana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toa,

35 ọmọ Sufu, ọmọ Elikana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

36 ọmọ Elikana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asaraya, ọmọ Sefanaya,

37 ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora,

38 ọmọ Iṣari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli.

39 Asafu, arakunrin rẹ̀, ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá ọ̀tun rẹ̀. Asafu yìí jẹ́ ọmọ Berekaya, ọmọ Ṣimea;

40 Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseaya, ọmọ Malikija,

41 ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaya;

42 ọmọ Etani, ọmọ Sima, ọmọ Ṣimei,

43 ọmọ Jahati, ọmọ Geriṣomu, ọmọ Lefi.

44 Etani arakunrin wọn láti inú ìdílé Merari ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá òsì rẹ̀. Ìran Etani títí lọ kan Lefi nìyí: ọmọ Kiṣi ni Etani, ọmọ Abidi, ọmọ Maluki;

45 ọmọ Haṣabaya, ọmọ Amasaya, ọmọ Hilikaya;

46 ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri;

47 ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.

48 Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi, arakunrin wọn yòókù láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó kù ninu ilé Ọlọrun.

Ìran Aaroni

49 Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun ati lórí pẹpẹ turari; àwọn ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ninu ibi mímọ́ jùlọ, tí wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose, iranṣẹ Ọlọrun là sílẹ̀.

50 Àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí: Eleasari baba Finehasi, baba Abiṣua;

51 baba Buki, baba Usi, baba Serahaya;

52 baba Meraiotu, baba Amaraya, baba Ahitubu;

53 baba Sadoku, baba Ahimaasi.

Ibi tí Àwọn Ọmọ Lefi Ń Gbé

54 Ilẹ̀ tí a pín fún ìran Aaroni nìyí, pẹlu ààlà wọn: ìdílé Kohati ni a kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ninu àwọn ọmọ Lefi.

55 Wọ́n fún wọn ní ìlú Heburoni ní ilẹ̀ Juda, ati gbogbo ilẹ̀ pápá oko tí ó yí i ká,

56 ṣugbọn Kalebu ọmọ Jefune ni wọ́n fún ní ìgbèríko ati ìletò tí ó yí ìlú Heburoni ká.

57 Àwọn ọmọ Aaroni ni a pín àwọn ìlú ààbò wọnyi fún: Heburoni, Libina, Jatiri ati Eṣitemoa, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.

58 Bẹ́ẹ̀ náà ni Hileni, ati Debiri,

59 ati Aṣani ati Beti Ṣemeṣi pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká.

60 Àwọn ìlú tí wọ́n pín fún wọn, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini nìwọ̀nyí: Geba, Alemeti, ati Anatoti, pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. Gbogbo àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní gbogbo ìdílé wọn jẹ́ mẹtala.

61 Gègé ni wọ́n ṣẹ́ lórí ìlú mẹ́wàá ara ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, tí wọn sì pín wọn fún àwọn ìdílé Kohati tí ó kù.

62 Ìlú mẹtala ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Geriṣomu ní ìdílé ìdílé lára àwọn ìlú ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Baṣani.

63 Ìlú mejila ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari ní ìdílé ìdílé, lára àwọn ìlú ẹ̀yà Reubẹni, Gadi ati ti Sebuluni.

64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo àwọn ìlú ńláńlá pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.

65 Wọ́n tún ṣẹ́ gègé láti fún wọn ní àwọn ìlú ńláńlá tí a dárúkọ wọnyi lára ìlú àwọn ẹ̀yà Juda, Simeoni ati ti Bẹnjamini.

66 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti pín àwọn ìlú ńláńlá fún àwọn ìdílé kan ninu àwọn ọmọ Kohati.

67 Àwọn ìlú ààbò tí wọ́n fún wọn, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká, ní agbègbè olókè Efuraimu nìwọ̀nyí; Ṣekemu, ati Geseri;

68 Jokimeamu ati Beti Horoni;

69 Aijaloni ati Gati Rimoni.

70 Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Kohati tí ó kù ní Aneri ati Bileamu, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.

71 Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká: Golani ní ilẹ̀ Baṣani, ati Aṣitarotu.

72 Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari; wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ati Daberati;

73 Ramoti ati Anemu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

74 Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní Maṣali ati Abidoni;

75 Hukoku ati Rehobu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

76 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Galili, Hamoni, ati Kiriataimu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

77 Wọ́n pín àwọn ìlú wọnyi fún àwọn ìdílé tí ó kù ninu àwọn ọmọ Merari.

Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní Rimono ati Tabori, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

78 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní ìkọjá Jọdani níwájú Jẹriko, wọ́n fún wọn ní Beseri tí ó wà ní ara òkè, ati Jahasa,

79 Kedemotu ati Mefaati pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

80 Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní Ramoti ní ilẹ̀ Gileadi ati Mahanaimu,

81 Heṣiboni ati Jaseri, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 7

Àwọn Ìran Isakari

1 Àwọn mẹrin ni ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu ati Ṣimironi.

2 Àwọn ọmọ Tola ni: Usi, Refaaya, Jerieli, Jahimai, Ibisamu ati Ṣemueli, àwọn ni baálé ninu ìdílé Tola, baba wọn, akikanju jagunjagun ni wọ́n ní àkókò wọn. Ní ayé Dafidi ọba, àwọn akikanju jagunjagun wọnyi jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹta (22,600).

3 Usi ni ó bí Isiraya. Isiraya sì bí ọmọ mẹrin: Mikaeli, Ọbadaya, Joẹli, ati Iṣaya; wọ́n di marun-un, àwọn maraarun ni wọ́n sì jẹ́ ìjòyè.

4 Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé ìdílé, àwọn jagunjagun tí wọ́n ní tó ẹgbaa mejidinlogun (36,000) kún ara wọn, ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí; nítorí wọ́n ní ọpọlọpọ iyawo ati ọmọ.

5 Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu àwọn ìbátan wọn ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogoji ó lé ẹgbẹrun (87,000).

Àwọn Ìran Bẹnjamini ati Dani

6 Àwọn mẹta ni ọmọ Bẹnjamini: Bela, Bekeri, ati Jediaeli.

7 Bela bí ọmọ marun-un: Esiboni, Usi, Usieli, Jerimotu ati Iri. Àwọn ni baálé ìdílé wọn, wọ́n sì jẹ́ akọni jagunjagun. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu ìdílé wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ati mẹrinlelọgbọn (22,034).

8 Bekeri bí ọmọ mẹsan-an: Semira, Joaṣi, ati Elieseri; Elioenai, Omiri, ati Jeremotu; Abija, Anatoti, ati Alemeti.

9 Àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé, àwọn baálé baálé ní ilé baba wọn, tí wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati igba (20,200).

10 Jediaeli ni baba Bilihani; Bilihani bí ọmọ meje: Jeuṣi, Bẹnjamini, Ehudu, Kenaana, Setani, Taṣiṣi ati Ahiṣahari.

11 Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jediaeli; àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé ní ilé baba wọn ati akọni jagunjagun ninu ìran wọn tó ẹẹdẹgbaasan-an ó lé igba (17,200).

12 Ṣupimu ati Hupimu jẹ́ ọmọ Iri, ọmọ Aheri sì ni Huṣimu.

Àwọn Ìran Nafutali

13 Nafutali bí ọmọ mẹrin: Jasieli, Guni, Jeseri, ati Ṣalumu. Biliha ni ìyá baba wọn.

Àwọn Ìran Manase

14 Manase fẹ́ obinrin kan, ará Aramea; ọmọ meji ni obinrin náà bí fún un; Asirieli, ati Makiri, baba Gileadi.

15 Makiri fẹ́ iyawo kan ará Hupi, ati ọ̀kan ará Ṣupimu. Orúkọ arabinrin rẹ̀ ni Maaka. Orúkọ ọmọ rẹ̀ keji ni Selofehadi; tí gbogbo ọmọ tirẹ̀ jẹ́ kìkì obinrin.

16 Maaka, Iyawo Makiri, bí ọmọ meji: Pereṣi ati Ṣereṣi. Ṣereṣi ni ó bí Ulamu ati Rakemu;

17 Ulamu sì bí Bedani. Àwọn ni ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase.

18 Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila.

19 Ṣemida bí ọmọkunrin mẹrin: Ahiani, Ṣekemu, Liki, ati Aniamu.

Àwọn Ìran Efuraimu

20 Àwọn arọmọdọmọ Efuraimu nìwọ̀nyí: Ṣutela ni baba Beredi, baba Tahati, baba Eleada, baba Tahati,

21 baba Sabadi, baba Ṣutela, Eseri, ati Eleadi; Eseri ati Eleadi yìí ni àwọn ará ìlú Gati pa nígbà tí wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn àwọn ará Gati.

22 Baba wọn, Efuraimu, ṣọ̀fọ̀ wọn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá wá láti tù ú ninu.

23 Lẹ́yìn náà, Efuraimu bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọmọ náà ní Beraya nítorí ibi tí ó dé bá ìdílé wọn.

24 Efuraimu ní ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣeera, òun ló kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati ti ìsàlẹ̀, ati Useni Ṣeera.

25 Orúkọ àwọn ọmọ ati arọmọdọmọ Efuraimu yòókù ni Refa, baba Reṣefu, baba Tela, baba Tahani;

26 baba Ladani, baba Amihudu, baba Eliṣama;

27 baba Nuni, baba Joṣua.

28 Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn.

29 Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká.

Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé.

Àwọn Ìran Aṣeri

30 Àwọn ọmọ Aṣeri nìwọ̀nyí: Imina, Iṣifa, Iṣifi ati Beraya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Sera.

31 Beraya bí ọmọkunrin meji: Heberi ati Malikieli, baba Birisaiti.

32 Heberi bí ọmọkunrin mẹta: Jafileti, Ṣomeri ati Hotamu; ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣua.

33 Jafileti bí ọmọ mẹta: Pasaki, Bimihali, ati Aṣifatu.

34 Ṣomeri, arakunrin Jafileti, bí ọmọkunrin mẹta: Roga, Jehuba ati Aramu.

35 Hotamu, arakunrin rẹ̀, bí ọmọkunrin mẹrin: Sofa, Imina, Ṣeleṣi ati Amali.

36 Sofa bí Ṣua, Haneferi, ati Ṣuali; Beri, ati Imira;

37 Beseri, Hodi, ati Ṣama, Ṣiliṣa, Itirani, ati Beera.

38 Jeteri bí: Jefune, Pisipa, ati Ara.

39 Ula bí: Ara, Hanieli ati Risia.

40 Àwọn ni ìran Aṣeri, wọ́n jẹ́ baálé baálé ni ìdílé baba wọn, àṣàyàn akọni jagunjagun, ati olórí láàrin àwọn ìjòyè. Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n tó ogun jà ninu wọn, ní ìdílé ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtala (26,000).

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 8

Àwọn Ìran Bẹnjamini

1 Bẹnjamini bí ọmọkunrin marun-un, Bela ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Aṣibeli,

2 lẹ́yìn rẹ̀, Ahara, lẹ́yìn rẹ̀, Nohahi, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni, Rafa.

3 Àwọn ọmọ Bela ni: Adari, Gera, ati Abihudi,

4 Abiṣua, Naamani, ati Ahoa,

5 Gera, Ṣefufani, ati Huramu.

6 Àwọn wọnyi ni ìran Ehudu: (Àwọn baálé baálé ninu ìran Geba, tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí ìlú Manahati):

7 Naamani, Ahija ati Gera, tí ń jẹ́ Hegilamu, baba Usa, ati Ahihudu.

8 Lẹ́yìn tí Ṣaharaimu ti kọ àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji, Huṣimu ati Baara sílẹ̀, ó fẹ́ Hodeṣi, ó sì bímọ ní ilẹ̀ Moabu.

9 Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami,

10 Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn.

11 Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.

12 Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.

Àwọn Ará Bẹnjamini Tí Wọ́n Wà Ní Gati ati Aijaloni

13 Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò;

14 àwọn ọmọ Beraya ni: Ahio, Ṣaṣaki, ati Jeremotu,

15 Sebadaya, Aradi, ati Ederi,

16 Mikaeli, Iṣipa ati Joha.

Àwọn Ará Bẹnjamini ní Jerusalẹmu

17 Àwọn ọmọ Elipaali ni: Sebadaya, Meṣulamu, Hiṣiki, ati Heberi,

18 Iṣimerai, Isilaya ati Jobabu.

19 Àwọn ọmọ Ṣimei ni: Jakimu, Sikiri, ati Sabidi;

20 Elienai, Siletai, ati Elieli;

21 Adaaya, Beraaya ati Ṣimirati;

22 Àwọn ọmọ Ṣaṣaki nìwọ̀nyí: Iṣipani, Eberi, ati Elieli;

23 Abidoni, Sikiri, ati Hanani;

24 Hananaya, Elamu, ati Antotija;

25 Ifideaya ati Penueli.

26 Àwọn ọmọ Jerohamu ni: Ṣamṣerai, Ṣeharaya, ati Atalaya;

27 Jaareṣaya, Elija ati Sikiri.

28 Àwọn ni baálé baálé ní ìdílé wọn, ìjòyè ni wọ́n ní ìran wọn; wọ́n ń gbé Jerusalẹmu.

Àwọn Ará Bẹnjamini tí Wọ́n Wà ní Gibeoni ati Jerusalẹmu

29 Jeieli, baba Gibeoni, ń gbé ìlú Gibeoni, Maaka ni orúkọ iyawo rẹ̀.

30 Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, ati Nadabu;

31 Gedori, Ahio, Sekeri, ati

32 Mikilotu (baba Ṣimea). Wọ́n ń bá àwọn arakunrin wọn gbé, àdúgbò wọn kọjú sí ara wọn ní Jerusalẹmu.

Ìdílé Saulu Ọba

33 Neri ni baba Kiṣi, Kiṣi ni ó bí Saulu, Saulu sì bí àwọn ọmọkunrin mẹrin: Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.

34 Jonatani bí Meribibaali, Meribibaali sì bí Mika.

35 Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi.

36 Ahasi ni baba Jehoada. Jehoada sì ni baba: Alemeti, Asimafeti, ati Simiri. Simiri ni ó bí Mosa.

37 Mosa bí Binea; Binea bí Rafa, Rafa bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli.

38 Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani. Aseli ni baba gbogbo wọn.

39 Eṣeki, arakunrin Aseli, bí ọmọ mẹta: Ulamu ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà Jeuṣi, lẹ́yìn náà Elifeleti.

40 Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ jagunjagun, tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lókìkí. Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ̀ pọ̀. Aadọjọ ni wọ́n, ara ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni gbogbo wọ́n.

Categories
KRONIKA KINNI

KRONIKA KINNI 9

Àwọn tí Wọ́n Dé láti Oko Ẹrú Babiloni

1 A kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìran wọn; a kọ wọ́n sinu ìwé Àwọn Ọba Israẹli.

A kó àwọn ẹ̀yà Juda ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni nítorí pé wọ́n ṣe alaiṣootọ sí Ọlọrun.

2 Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pada dé sórí ilẹ̀ wọn, ní ìlú wọn, ni àwọn ọmọ Israẹli, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹmpili.

3 Àwọn eniyan tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Juda, Bẹnjamini, Efuraimu, ati Manase tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:

4 Utai ọmọ Amihudu, ọmọ Omiri, ọmọ Imiri, ọmọ Bani, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda.

5 Àwọn ọmọ Ṣilo ni Asaaya, àkọ́bí rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀.

6 Àwọn ọmọ ti Sera ni Jeueli ati àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹ́wàá (690).

7 Àwọn tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Salu, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Hodafaya, ọmọ Hasenua,

8 Ibineaya, ọmọ Jerohamu, Ela, ọmọ Usi, ọmọ Mikiri, Meṣulamu, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Reueli, ọmọ Ibinija.

9 Àwọn ìbátan wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti tò wọ́n sinu ìwé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹrindinlọgọta (956). Gbogbo wọn jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn, tí ń gbé Jerusalẹmu.

Àwọn Alufaa Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

10 Àwọn alufaa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Jedaaya, Jehoiaribu, Jakini,

11 ati Asaraya ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé Ọlọrun;

12 ati Adaaya, ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Imeri.

13 Àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọrun láìka àwọn eniyan wọn ati àwọn olórí ìdílé wọn gbogbo jẹ́ ẹgbẹsan ó dín ogoji (1,760).

Àwọn Ọmọ Lefi Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

14 Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣemaaya ọmọ Haṣihubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, lára àwọn ọmọ Merari;

15 ati Bakibakari, Hereṣi, Galali ati Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sikiri, ọmọ Asafu,

16 ati Ọbadaya ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Galali, ọmọ Jẹdutumu, ati Berekaya ọmọ Asa, ọmọ Elikana, tí ń gbé agbègbè tí àwọn ọmọ Netofa wà.

Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili Tí Wọn Ń Gbé Jerusalẹmu

17 Àwọn aṣọ́nà Tẹmpili nìwọ̀nyí: Ṣalumu, Akubu, Talimoni, Ahimani, ati àwọn eniyan wọn; (Ṣalumu ni olórí wọn).

18 Wọ́n ń ṣọ́ apá ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn ilé ọba. Àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àgọ́ àwọn ọmọ Lefi tẹ́lẹ̀.

19 Ṣalumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora ati àwọn ará ilé baba rẹ̀. Gbogbo ìdílé Kora ni alabojuto iṣẹ́ ìsìn ninu tẹmpili ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti jẹ́ alabojuto Àgọ́ OLUWA ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀.

20 Finehasi, ọmọ Eleasari ni olórí wọn tẹ́lẹ̀ rí, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.

21 Sakaraya, ọmọ Meṣelemaya ni olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

22 Gbogbo àwọn olùṣọ́nà tí wọ́n yàn láti máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igba ó lé mejila (212). A kọ orúkọ wọn sinu ìwé gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní agbègbè wọn. Dafidi ati Samuẹli aríran, ni wọ́n fi wọ́n sí ipò pataki náà.

23 Nítorí náà, àwọn ati àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ń ṣe alabojuto ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, àwọn ni wọ́n fi ṣe olùṣọ́ Àgọ́ Àjọ.

24 Ọ̀gá aṣọ́nà kọ̀ọ̀kan wà ní ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin: ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìwọ̀ oòrùn, ati àríwá, ati gúsù;

25 àwọn eniyan wọn tí wọn ń gbé àwọn ìletò a máa wá ní ọjọ́ meje meje, láti ìgbà dé ìgbà, láti wà pẹlu àwọn olórí ọ̀gá aṣọ́nà mẹrin náà.

26 Nítorí àwọn olórí mẹrin wọnyi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, ni wọ́n tún ń ṣe alabojuto àwọn yàrá tẹmpili ati àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé Ọlọrun.

27 Wọ́n ń gbé àyíká ilé Ọlọrun, nítorí iṣẹ́ wọn ni láti máa bojútó o, ati láti máa ṣí ìlẹ̀kùn rẹ̀ ní àràárọ̀.

Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù

28 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi ni alabojuto àwọn ohun èlò ìjọ́sìn, iṣẹ́ wọn ni láti máa fún àwọn tí wọ́n ń lò wọ́n, ati láti gbà wọ́n pada sí ipò wọn, kí wọ́n sì kà wọ́n kí wọ́n rí i pé wọ́n pé.

29 Iṣẹ́ àwọn mìíràn ninu wọn ni láti máa tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ tẹmpili ati ohun èlò mímọ́, ati ìyẹ̀fun ọkà, waini, òróró, turari, ati òjíá.

30 Àwọn ọmọ alufaa yòókù ni wọ́n ń po turari,

31 Matitaya, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi tí ó jẹ́ àkọ́bí Ṣalumu ará Kora níí máa ń ṣe àkàrà ìrúbọ.

32 Bákan náà, àwọn kan ninu àwọn ọmọ Kohati, ni wọ́n máa ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn ní ọjọọjọ́ ìsinmi.

33 Àwọn ọmọ Lefi kan wà fún orin kíkọ ninu tẹmpili, wọ́n jẹ́ baálé baálé ninu ẹ̀yà Lefi, ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu tẹmpili ni àwọn ń gbé, wọn kì í bá àwọn yòókù ṣiṣẹ́ mìíràn ninu tẹmpili, nítorí pé iṣẹ́ tiwọn ni orin kíkọ tọ̀sán-tòru.

34 Baálé baálé ni àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi ninu ìdílé wọn, olórí ni wọ́n ninu ẹ̀yà Lefi, wọ́n ń gbé Jerusalẹmu.

Àwọn Baba Ńlá ati Àwọn Àtìrandíran Saulu Ọba

35 Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ìlú Gibeoni, iyawo rẹ̀ ń jẹ́ Maaka,

36 Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, Neri, ati Nadabu;

37 Gedori, Ahio, Sakaraya, ati Mikilotu;

38 Mikilotu bí Ṣimea; àwọn náà ń gbé lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn ni òdìkejì ibùgbé àwọn arakunrin wọn ní Jerusalẹmu.

39 Neri ni ó bí Kiṣi, Kiṣi bí Saulu, Saulu ni baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.

40 Jonatani ni ó bí Meribibaali; Meribibaali sì bí Mika.

41 Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi;

42 Ahasi sì bí Jara. Jara bí ọmọ mẹta: Alemeti, Asimafeti ati Simiri, Simiri bí Mosa,

43 Mosa sì bí Binea. Binea ni baba Refaaya, Refaaya ni ó bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli.

44 Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, ati Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani.