Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 20

Wọ́n Gbógun ti Edomu

1 Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Moabu, ati àwọn ará Amoni, ati díẹ̀ ninu àwọn ará Meuni kó ara wọn jọ láti bá Jehoṣafati jagun.

2 Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi).

3 Ẹ̀rù ba Jehoṣafati gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú OLUWA, ó kéde jákèjádò ilẹ̀ Juda pé kí wọ́n gbààwẹ̀.

4 Àwọn eniyan péjọ láti gbogbo ìlú Juda, wọ́n wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ OLUWA.

5 Jehoṣafati bá dìde dúró láàrin àwọn tí wọ́n ti Juda ati Jerusalẹmu wá sinu tẹmpili, níbi tí wọ́n péjọ sí níwájú gbọ̀ngàn tuntun,

6 ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́.

7 Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae?

8 Wọ́n ti ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ibi mímọ́ sibẹ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ,

9 nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá.

10 “Nisinsinyii, wo àwọn ọmọ ogun Amoni, ati ti Moabu ati ti Òkè Seiri, àwọn tí o kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli bá jà nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti, o kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n run.

11 Wò ó! Wọ́n ń fi burúkú san ire fún wa, wọ́n ń bọ̀ wá lé wa kúrò lórí ilẹ̀ rẹ, tí o fún wa bí ìní.

12 Ọlọrun wa, dá wọn lẹ́jọ́. Nítorí pé agbára wa kò tó láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun wọn tí wọn ń kó bọ̀ wá bá wa jà. A kò mọ ohun tí a lè ṣe, ìwọ ni a gbójú sókè tí à ń wò.”

13 Gbogbo àwọn ọkunrin Juda dúró níwájú OLUWA pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn.

14 Ẹ̀mí OLUWA bà lé Jahasieli, ọmọ Sakaraya, ọmọ Bẹnaya, ọmọ Jeieli, ọmọ Matanaya; ọmọ Lefi ni, láti inú ìran Asafu. Ó bá dìde dúró láàrin àwùjọ àwọn eniyan.

15 Ó ní, “Ẹ fetí sí mi, gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati ti Jerusalẹmu ati ọba Jehoṣafati, OLUWA ní kí ẹ má fòyà, kí ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì nítorí ogun ńlá yìí; nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ó ja ogun ńlá yìí, Ọlọrun ni.

16 Ní ọ̀la, ẹ kógun lọ bá wọn; wọn yóo gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Sisi wá, ẹ óo rí wọn ní òpin àfonífojì ní apá ìlà oòrùn aṣálẹ̀ Jerueli.

17 Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.”

18 Jehoṣafati dojúbolẹ̀, gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.

19 Ni àwọn ọmọ Lefi láti inú ìdílé Kohati ati ti Kora bá dìde, wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n sì yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.

20 Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà lọ sí aṣálẹ̀ Tekoa. Bí wọ́n ti ń lọ, Jehoṣafati dúró, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, ẹ gba ohun tí àwọn wolii rẹ̀ wí gbọ́ pẹlu, ẹ óo sì ní ìṣẹ́gun.”

21 Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé,

“Ẹ yin OLUWA!

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.”

22 Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn, OLUWA gbẹ̀yìn yọ sí àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu ati ti Òkè Seiri tí wọ́n wá bá àwọn eniyan Juda jà, ó sì tú wọn ká.

23 Àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu gbógun ti àwọn ará Òkè Seiri wọ́n sì pa wọ́n run patapata. Lẹ́yìn náà, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn run.

24 Nígbà tí ogun Juda dé ilé ìṣọ́ tí ó wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n wo àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti kú sílẹ̀ lọ bẹẹrẹ; kò sí ẹni tí ó sá àsálà ninu wọn.

25 Nígbà tí Jehoṣafati ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti kó ìkógun, wọ́n rí ọpọlọpọ mààlúù, ati ẹrù aṣọ ati nǹkan ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye. Wọ́n kó wọn títí ó fi sú wọn. Odidi ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi kó ìkógun nítorí pé ó ti pọ̀ jù.

26 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ ní àfonífojì Beraka. Ibẹ̀ ni wọ́n ti yin OLUWA. Nítorí náà ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Beraka títí di òní olónìí.

27 Jehoṣafati kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun, nítorí pé OLUWA ti fún un ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

28 Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, wọ́n wọ inú tẹmpili lọ, pẹlu ìró hapu, ati ti dùùrù ati ti fèrè.

29 Ẹ̀rù OLUWA ba ìjọba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA bá àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Israẹli jagun.

30 Nítorí náà Jehoṣafati jọba ní alaafia, nítorí pé Ọlọrun fún un ní ìsinmi ní gbogbo àyíká rẹ̀.

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Jehoṣafati

31 Jehoṣafati jọba lórí Juda, ẹni ọdún marundinlogoji ni nígbà tí ó gorí oyè. Gbogbo ọdún tí ó lò lórí oyè jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba, ọmọ Ṣilihi.

32 Ó ṣe dáradára gẹ́gẹ́ bí Asa, baba rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA.

33 Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run; àwọn eniyan kò tíì máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọrun àwọn baba ńlá wọn.

34 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn Jehu ọmọ Hanani, tí ó jẹ́ apá kan ìtàn àwọn ọba Israẹli.

35 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Jehoṣafati, ọba Juda lọ darapọ̀ mọ́ Ahasaya, ọba Israẹli, tí ó jẹ́ eniyan burúkú.

36 Wọ́n jọ kan àwọn ọkọ̀ ojú omi tí yóo lọ sí ìlú Taṣiṣi. Wọ́n kan àwọn ọkọ̀ náà ní Esiongeberi.

37 Elieseri ọmọ Dodafahu, ará Mareṣa fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Jehoṣafati wí. Ó ní, “Nítorí pé o darapọ̀ mọ́ Ahasaya, OLUWA yóo ba ohun tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀ jẹ́.” Gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi náà rì, wọn kò sì lè lọ sí Taṣiṣi mọ́.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 21

1 Jehoṣafati kú, wọ́n sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀ ninu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoramu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Jehoramu, Ọba Juda

2 Jehoramu ní arakunrin mẹfa, tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Jehoṣafati, orúkọ wọn ni, Asaraya, Jehieli, ati Sakaraya, Asaraya, Mikaeli ati Ṣefataya.

3 Baba wọn fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn: fadaka, wúrà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye, pẹlu àwọn ìlú olódi ní Juda. Ṣugbọn Jehoramu ni ó fi ìjọba lé lọ́wọ́, nítorí pé òun ni àkọ́bí rẹ̀.

4 Nígbà tí ó jọba tán, tí ó sì ti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ati díẹ̀ ninu àwọn olóyè ní Israẹli.

5 Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún mejilelọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹjọ ní Jerusalẹmu.

6 Ó tẹ̀ sí ọ̀nà burúkú tí àwọn ọba Israẹli rìn, ó ṣe bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé ọmọ Ahabu ni iyawo rẹ̀. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA.

7 Sibẹsibẹ OLUWA kò pa ìdílé Dafidi run nítorí majẹmu tí ó ti bá Dafidi dá, ati ìlérí tí ó ti ṣe pé ọmọ rẹ̀ ni yóo máa wà lórí oyè títí lae.

8 Ní àkókò ìjọba Jehoramu ni Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn.

9 Nítorí náà Jehoramu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ gbógun tì wọ́n. Ní òru, Jehoramu ati ogun rẹ̀ dìde, wọ́n fọ́ ogun Edomu tí ó yí wọn ká tàwọn ti kẹ̀kẹ́ ogun wọn, ati àwọn tí ń wà wọ́n.

10 Láti ìgbà náà ni Edomu ti ń bá Juda ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Ní àkókò kan náà ni Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, ó sì gba òmìnira nítorí pé Jehoramu ti fi ọ̀nà OLUWA àwọn baba rẹ̀ sílẹ̀.

11 Ó tilẹ̀ kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ káàkiri ní agbègbè olókè Juda. Ó fa àwọn ará Jerusalẹmu sinu aiṣododo, ó sì kó àwọn ọmọ Juda ṣìnà.

12 Elija wolii kọ ìwé kan sí Jehoramu, ohun tí ó kọ sinu ìwé náà nìyí: “Gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Dafidi, baba rẹ, ti wí; ó ní, nítorí pé o kò tọ ọ̀nà tí Jehoṣafati baba rẹ tọ̀, tabi ti Asa, baba baba rẹ.

13 Ṣugbọn ò ń hùwà bí àwọn ọba Israẹli, o sì ti fa àwọn Juda ati Jerusalẹmu sinu aiṣododo, bí ìdílé Ahabu ti ṣe fún Israẹli. Pataki jùlọ, o pa àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ baba rẹ, tí wọ́n tilẹ̀ sàn jù ọ́ lọ.

14 Wò ó, OLUWA yóo fi àjàkálẹ̀ àrùn ṣe àwọn eniyan rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya rẹ ati gbogbo ohun tí o ní.

15 Àrùn burúkú kan yóo kọlu ìwọ pàápàá, àrùn inú ni, yóo pọ̀, yóo sì pẹ́ lára rẹ títí tí ìfun rẹ yóo fi bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde.”

16 OLUWA mú kí inú àwọn ará Filistia ati ti àwọn ará Arabia, tí wọn ń gbé nítòsí àwọn ará Etiopia, ru sí Jehoramu.

17 Wọ́n dó ti Juda, wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ní ààfin lọ, pẹlu àwọn ọmọ Jehoramu ati àwọn iyawo rẹ̀. Kò ku ẹyọ ọmọ kan àfi èyí àbíkẹ́yìn tí ń jẹ́ Ahasaya.

18 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, OLUWA fi àrùn inú kan tí kò ṣe é wò bá Jehoramu jà.

19 Lẹ́yìn ọdún keji tí àìsàn náà tí ń ṣe é, ìfun rẹ̀ tú síta, ó sì kú ninu ọpọlọpọ ìrora. Wọn kò dá iná ẹ̀yẹ fún un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe níbi ìsìnkú àwọn baba rẹ̀.

20 Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni nígbà tí ó gorí oyè, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹjọ. Nígbà tí ó kú, kò sí ẹni tí ó sọkún, tabi tí ó ṣọ̀fọ̀ níbi òkú rẹ̀. Ìlú Dafidi ni wọ́n sin ín sí, ṣugbọn kì í ṣe ní ibojì àwọn ọba.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 22

Ahasaya Ọba Juda

1 Àwọn ọmọ ogun Arabia tí wọn ń jà káàkiri pa gbogbo àwọn ọmọ Jehoramu, ọba Juda, àfi Ahasaya, àbíkẹ́yìn rẹ̀. Nítorí náà àwọn ará Jerusalẹmu bá fi Ahasaya jọba lẹ́yìn Jehoramu.

2 Ahasaya jẹ́ ẹni ọdún mejilelogoji, nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún kan ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Atalaya, ọmọ ọmọ Omiri.

3 Ìwà burúkú ni òun náà ń hù bíi ti Ahabu, nítorí pé ìyá rẹ̀ ní ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà ibi.

4 Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, àwọn ará ilé Ahabu ni olùdámọ̀ràn rẹ̀, àwọn ni wọ́n fa ìṣubú rẹ̀.

5 Ìmọ̀ràn wọn ni ó tẹ̀lé tí ó fi pa ogun tirẹ̀ pọ̀ mọ́ ti Joramu, ọba Israẹli, láti bá Hasaeli ọba Siria jagun ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Siria sì ṣá Joramu lọ́gbẹ́ lójú ogun náà,

6 ó bá pada lọ sí ìlú Jesireeli láti wo ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun ní Rama nígbà tí ó ń bá Hasaeli ọba Siria jagun. Ahasaya, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli nítorí ara rẹ̀ tí kò yá.

7 Ọlọrun ti pinnu pé ìparun óo bá Ahasaya nígbà tí ó bá lọ bẹ Joramu wò. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, òun pẹlu Joramu lọ pàdé Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLUWA ti yàn pé òun ni yóo pa ìdílé Ahabu run.

8 Nígbà tí Jehu dé láti pa ilé Ahabu run bí Ọlọrun ti fún un láṣẹ, ó pàdé àwọn ìjòyè Juda ati ọmọ arakunrin Ahasaya tí ó bá Ahasaya wá, ó bá pa wọ́n.

9 Ó wá Ahasaya káàkiri títí; ní Samaria níbi tí ó sá pamọ́ sí ni wọ́n ti rí i mú, wọ́n bá mú un tọ Jehu wá, ó sì pa á. Wọ́n sin òkú rẹ̀, nítorí wọ́n ní, “Ọmọ ọmọ Jehoṣafati, ẹni tí ó fi tọkàntọkàn gbọ́ ti OLUWA ni.”

Ní àkókò yìí, kò sí ẹnikẹ́ni ninu ìdílé Ahasaya tí ó lágbára tó láti jọba ilẹ̀ Juda.

Atalaya, Ọbabinrin ní Juda

10 Nígbà tí Atalaya, ìyá Ahasaya rí i pé ọmọ òun ti kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìran ọba ní Juda.

11 Ṣugbọn Jehoṣeba, ọmọbinrin Jehoramu ọba, tí ó jẹ́ iyawo Jehoiada alufaa, gbé Joaṣi ọmọ Ahasaya sá kúrò láàrin àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, nítorí pé àbúrò rẹ̀ ni Joaṣi yìí. Ó bá fi òun ati olùtọ́jú rẹ̀ pamọ́ sinu yàrá kan. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣeba ṣe gbé ọmọ náà pamọ́ fún Atalaya, tí kò fi rí i pa.

12 Joaṣi wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n gbé e pamọ́ sí ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa tí Atalaya fi jọba ní ilẹ̀ náà.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 23

Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Atalaya

1 Ní ọdún keje Jehoiada alufaa mọ́kàn gírí, ó lọ bá àwọn marun-un ninu àwọn balogun dá majẹmu. Àwọn ni: Asaraya, ọmọ Jerohamu, Iṣimaeli ọmọ Jehohanani, Asaraya ọmọ Obedi, Maaseaya ọmọ Adaya ati Eliṣafati ọmọ Sikiri.

2 Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ kó àwọn Lefi ati àwọn baálé baálé gbogbo ní Israẹli wá sí Jerusalẹmu.

3 Gbogbo wọn pàdé ninu ilé Ọlọrun, wọ́n sì bá ọba dá majẹmu níbẹ̀. Jehoiada wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó! Ọmọ ọba nìyí, ó tó àkókò láti fi jọba nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ṣe pé ìran Dafidi ni yóo máa jọba.

4 Ohun tí ẹ óo ṣe nìyí: nígbà tí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi, ìdámẹ́ta ninu wọn yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA,

5 ìdámẹ́ta yóo wà ní ààfin ọba, ìdámẹ́ta tó kù yóo máa ṣọ́ Ẹnubodè Ìpìlẹ̀; gbogbo àwọn eniyan yóo sì péjọ sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA.

6 Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọnú ilé OLUWA, àfi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn lè wọlé nítorí pé wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ó kù gbọdọ̀ pa àṣẹ OLUWA mọ́.

7 Àwọn ọmọ Lefi yóo yí ọba ká láti ṣọ́ ọ, olukuluku yóo mú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n gbọdọ̀ wà pẹlu ọba níbikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wọnú ilé Ọlọrun, pípa ni kí ẹ pa á.”

8 Àwọn ọmọ Lefi ati gbogbo ọmọ Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada alufaa ti pàṣẹ fún wọn. Olukuluku kó àwọn eniyan rẹ̀ tí wọ́n ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi wá, wọ́n dúró pẹlu àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ipò wọn, nítorí Jehoiada alufaa kò jẹ́ kí wọ́n túká.

9 Jehoiada fún àwọn ọ̀gágun ní ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi tí wọ́n ti kó pamọ́ sinu ilé Ọlọrun.

10 Ó ní kí àwọn eniyan náà dúró, kí wọn máa ṣọ́ ọba, olukuluku pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́. Wọ́n tò láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá, ati ní àyíká pẹpẹ ati ti ilé náà.

11 Jehoiada bá mú Joaṣi jáde, ó gbé adé lé e lórí, ó fún un ní ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi Joaṣi jọba, Jehoiada alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi àmì òróró yàn án lọ́ba. Gbogbo eniyan hó pé, “Kí ọba pẹ́.”

12 Nígbà tí Atalaya gbọ́ híhó àwọn eniyan, ati bí wọ́n ti ń sá kiri tí wọ́n sì ń yin ọba, ó lọ sí ilé OLUWA níbi tí àwọn eniyan péjọ sí,

13 ó rí i tí ọba náà dúró lẹ́bàá òpó lẹ́nu ọ̀nà, àwọn ọ̀gágun ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo eniyan ń hó ìhó ayọ̀, wọ́n ń fọn fèrè, àwọn tí ń lo ohun èlò orin ń fi wọ́n kọrin, àwọn eniyan sì ń gberin. Nígbà tí Atalaya rí nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ẹ̀rù bà á, ó sì kígbe lóhùn rara pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!”

14 Jehoiada bá rán àwọn ọ̀gágun ọmọ ogun ọgọrun-un pé, “Ẹ fà á síta láàrin àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó bá tẹ̀lé e, ẹ pa á.” Nítorí àwọn alufaa ní kí wọ́n má pa á ninu tẹmpili OLUWA.

15 Wọ́n bá mú un lọ sí ẹnu ọ̀nà Ẹṣin, ní ààfin, wọ́n sì pa á sibẹ.

Jehoiada Ṣe Àtúnṣe

16 Jehoiada bá àwọn eniyan náà dá majẹmu pẹlu ọba, pé ti OLUWA ni àwọn yóo máa ṣe.

17 Lẹ́yìn náà, gbogbo wọn lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o palẹ̀, wọ́n wó pẹpẹ ati àwọn ère túútúú, wọ́n sì pa Matani, tí ó jẹ́ alufaa Baali, níwájú pẹpẹ.

18 Jehoiada yan àwọn aṣọ́nà fún ilé OLUWA, lábẹ́ àkóso àwọn alufaa, ọmọ Lefi, ati àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi ti ṣètò láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, pẹlu àjọyọ̀ ati orin, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣètò.

19 Ó fi àwọn aṣọ́nà sí ẹnu àwọn ọ̀nà ilé OLUWA kí ẹnikẹ́ni tí kò bá mọ́ má baà wọlé.

20 Òun pẹlu àwọn balogun, àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn, àwọn gomina, ati gbogbo eniyan ilẹ̀ náà mú ọba láti ilé OLUWA, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà òkè wá sí ààfin, wọ́n sì fi í jókòó lórí ìtẹ́.

21 Inú gbogbo àwọn eniyan dùn, ìlú sì rọ̀ wọ̀ọ̀, nítorí pé wọ́n ti pa Atalaya.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 24

Joaṣi, Ọba Juda

1 Ọmọ ọdún meje ni Joaṣi nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibaya, ará Beeriṣeba.

2 Joaṣi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé Jehoiada alufaa.

3 Jehoiada fẹ́ iyawo meji fún un, wọ́n sì bímọ fún un lọkunrin ati lobinrin.

4 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Joaṣi pinnu láti tún ilé OLUWA ṣe.

5 Ó pe gbogbo àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ máa gba owó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti máa fi tún ilé OLUWA Ọlọrun yín ṣe ní ọdọọdún. Ẹ mójútó iṣẹ́ náà kí ẹ sì ṣe é kíákíá.” Ṣugbọn àwọn alufaa kò tètè lọ.

6 Nítorí náà, ọba ranṣẹ pe Jehoiada tí ó jẹ́ olórí wọn, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Lefi lọ máa gba owó fún àgọ́ ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn eniyan Juda ati Jerusalẹmu bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pa á láṣẹ?”

7 (Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Atalaya, obinrin burúkú n nì, ti fọ́ ilé Ọlọrun, wọ́n sì ti kó gbogbo ohun èlò mímọ́ ibẹ̀, wọ́n ti lò ó fún oriṣa Baali.)

8 Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àpótí kan tí àwọn eniyan yóo máa sọ owó sí, kí wọ́n sì gbé e sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA.

9 Wọ́n kéde káàkiri Jerusalẹmu ati Juda pé kí wọ́n máa mú owó orí wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ Ọlọrun ti pàṣẹ fún Israẹli ninu aṣálẹ̀.

10 Gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo eniyan fi tayọ̀tayọ̀ mú owó orí wọn wá, wọ́n ń sọ ọ́ sinu àpótí náà títí tí ó fi kún.

11 Nígbà tí àwọn Lefi bá gbé àpótí náà wá fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba, tí wọ́n sì rí i pé owó pọ̀ ninu rẹ̀, akọ̀wé ọba ati aṣojú olórí alufaa yóo da owó kúrò ninu àpótí, wọn yóo sì gbé e pada sí ààyè rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ní ojoojumọ, wọ́n sì rí ọpọlọpọ owó kó jọ.

12 Ọba ati Jehoiada gbé owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso iṣẹ́ ilé OLUWA, wọ́n gba àwọn ọ̀mọ̀lé, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn alágbẹ̀dẹ irin ati ti bàbà, láti tún ilé OLUWA ṣe.

13 Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa ninu iṣẹ́ náà fi tagbára tagbára ṣe é. Iṣẹ́ náà tẹ̀síwájú títí tí wọ́n fi tún ilé OLUWA náà ṣe tán, tí ó sì rí bíi ti iṣaaju tí ó sì tún lágbára sí i.

14 Nígbà tí wọ́n tún ilé OLUWA náà ṣe tán, wọ́n kó owó tí ó kù pada sọ́dọ̀ ọba ati Jehoiada. Wọ́n fi owó náà ṣe àwọn ohun èlò fún ìsìn ati ẹbọ sísun ní ilé OLUWA, ati àwo fún turari ati ohun èlò wúrà ati fadaka.

Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé OLUWA lojoojumọ, ní gbogbo àkókò Jehoiada.

Wọ́n Yí Ètò ìjọba Jehoiada pada

15 Nígbà tí Jehoiada dàgbà tí ó di arúgbó, ó kú nígbà tí ó pé ẹni aadoje (130) ọdún.

16 Wọ́n sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi nítorí iṣẹ́ rere tí ó ṣe ní Israẹli fún Ọlọrun ati ní ilé mímọ́ rẹ̀.

17 Ṣugbọn nígbà tí Jehoiada kú, àwọn ìjòyè ní Juda wá kí ọba, wọ́n sì júbà rẹ̀, ó sì gba ìmọ̀ràn wọn.

18 Wọ́n kọ ilé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń sin oriṣa Aṣera ati àwọn ère mìíràn. Nítorí ìwà burúkú yìí, inú bí OLUWA sí Juda ati Jerusalẹmu.

19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA rán àwọn wolii sí wọn láti darí wọn pada sọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ fún wọn, wọ́n kọ etí dídi sí àwọn wolii.

20 Nígbà tí ó yá, Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Sakaraya, ọmọ Jehoiada alufaa, ó bá dìde dúró láàrin àwọn eniyan, ó ní, “Ọlọrun ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi tàpá sí òfin òun OLUWA; ṣé ẹ kò fẹ́ kí ó dára fun yín ni? Nítorí pé, ẹ ti kọ OLUWA sílẹ̀, òun náà sì ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”

21 Ṣugbọn wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, ọba pàṣẹ pé kí wọn sọ ọ́ lókùúta pa ninu gbọ̀ngàn ilé OLUWA.

22 Joaṣi ọba kò ranti oore tí Jehoiada, baba Sakaraya ṣe fún un, ṣugbọn ó pa ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó sì ń kú lọ, ó ní, “Kí OLUWA wo ohun tí o ṣe yìí, kí ó sì gbẹ̀san.”

Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Joaṣi

23 Bí ọdún náà ti ń dópin lọ, àwọn ọmọ ogun Siria gbógun ti Joaṣi. Nígbà tí wọ́n dé Juda ati Jerusalẹmu, wọ́n pa gbogbo àwọn ìjòyè wọn, wọ́n sì kó gbogbo ìkógun wọn ranṣẹ sí Damasku.

24 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wá, sibẹsibẹ OLUWA fi ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Juda lé wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìdájọ́ Joaṣi ọba.

25 Ọba fara gbọgbẹ́ ninu ogun náà, nígbà tí àwọn ogun Siria sì lọ tán, àwọn balogun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn nítorí pé ó pa ọmọ Jehoiada alufaa, wọ́n sì pa á lórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, ṣugbọn kì í ṣe inú ibojì àwọn ọba.

26 Àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba ni Sabadi, ọmọ Ṣimeati ará Amoni, ati Jehosabadi ọmọ Ṣimiriti ará Moabu.

27 Ìtàn àwọn ọmọ rẹ̀, ati ọpọlọpọ àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀, ati bí ó ti tún ilé Ọlọrun ṣe wà, tí a kọ ọ́ sinu ìwé Ìtàn Àwọn Ọba. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 25

Amasaya, Ọba Juda

1 Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Amasaya nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Ìyá rẹ̀ ni Jehoadini ará Jerusalẹmu.

2 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò fi tọkàntọkàn sìn ín.

3 Lẹ́yìn ìgbà tí ìjọba rẹ̀ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n pa baba rẹ̀.

4 Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin Mose ti wí, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ, pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, tabi kí á pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba; olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.”

Wọ́n Gbógun ti Edomu

5 Amasaya pe àwọn eniyan Juda ati Bẹnjamini jọ, ó pín wọn sábẹ́ àwọn ọ̀gágun ní ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ ni gbogbo àwọn tí ó kó jọ. Gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun, tí wọ́n sì lè lo ọ̀kọ̀ ati apata.

6 Ó tún fi ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti fadaka lọ bẹ ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) akọni lọ́wẹ̀ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli.

7 Ṣugbọn wolii Ọlọrun kan lọ bá Amasaya, ó sọ fún un pé, “Kabiyesi, má jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Israẹli bá ọ lọ, nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu Israẹli ati àwọn ará Efuraimu wọnyi.

8 Ṣugbọn bí o bá wá rò pé àwọn wọnyi ni yóo jẹ́ kí ogun rẹ lágbára, OLUWA yóo bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Nítorí Ọlọrun lágbára láti ranni lọ́wọ́ ati láti bini ṣubú.”

9 Amasaya bèèrè lọ́wọ́ wolii náà pé, “Kí ni kí á ṣe nípa ọgọrun-un talẹnti tí mo ti fún àwọn ọmọ ogun Israẹli?”

Ó dáhùn pé, “OLUWA lè fún ọ ní ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

10 Nítorí náà Amasaya dá àwọn ọmọ ogun Efuraimu tí ó gbà pada sílé wọn. Nítorí náà, inú bí wọn gan-an sí Juda, wọ́n sì pada sílé pẹlu ìrúnú.

11 Ṣugbọn Amasaya fi ìgboyà kó ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì Iyọ̀, ó sì pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Seiri.

12 Wọ́n mú ẹgbaarun (10,000) mìíràn láàyè, wọ́n kó wọn lọ sí góńgó orí òkè kan, wọ́n jù wọ́n sí ìsàlẹ̀, gbogbo wọn sì ṣègbé.

13 Àwọn ọmọ ogun Israẹli tí Amasaya dá pada, tí kò jẹ́ kí wọ́n tẹ̀lé òun lọ sógun bá lọ, wọ́n kọlu àwọn ìlú Juda láti Samaria títí dé Beti Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun.

14 Amasaya kó oriṣa àwọn ará Edomu tí ó ṣẹgun wá sílé. Ó kó wọn kalẹ̀, ó ń bọ wọ́n, ó sì ń rúbọ sí wọn.

15 Inú bí OLUWA sí Amasaya gan-an, ó sì rán wolii kan sí i kí ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń bọ àwọn oriṣa tí kò lè gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?”

16 Bí wolii yìí ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dá a lóhùn pé, “Panumọ́, ṣé wọ́n fi ọ́ ṣe olùdámọ̀ràn ọba ni? Àbí o fẹ́ kú ni.”

Wolii náà bá dákẹ́, ṣugbọn, kí ó tó dákẹ́ ó ní, “Mo mọ̀ pé Ọlọrun ti pinnu láti pa ọ́ run fún ohun tí o ṣe yìí, ati pé, o kò tún fetí sí ìmọ̀ràn mi.”

Amasaya Gbógun ti Israẹli

17 Lẹ́yìn tí Amasaya, ọba Juda, ṣe àpérò pẹlu àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, ó ranṣẹ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá, jẹ́ kí á kojú ara wa.”

18 Jehoaṣi ọba Israẹli ranṣẹ sí ọba Juda pé, “Ní àkókò kan, ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n kan ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Mo fẹ́ fẹ́ ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi.’ Ẹranko ìgbẹ́ kan ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀.

19 O bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé o ti ṣẹgun àwọn ará Edomu, ṣugbọn, mo gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí o dúró jẹ́ẹ́ sí ilé rẹ. Kí ló dé tí ò ń fi ọwọ́ ara rẹ fa ìjàngbọ̀n tí ó lè fa ìṣubú ìwọ ati àwọn eniyan rẹ?”

20 Ṣugbọn Amasaya kọ̀, kò gbọ́, nítorí pé Ọlọrun ni ó mú kí ọkàn rẹ̀ le, kí Ọlọrun lè fi Juda lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ nítorí pé wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Edomu.

21 Nítorí náà, Jehoaṣi, ọba Israẹli, gòkè lọ, òun ati Amasaya ọba Juda sì kojú ara wọn lójú ogun ní Beti Ṣemeṣi ní ilẹ̀ Juda.

22 Àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn ará Juda, olukuluku sì fọ́nká lọ sí ilé rẹ̀.

23 Jehoaṣi, ọba Israẹli mú Amasaya, ọba Juda, ọmọ Joaṣi, ọmọ Ahasaya, ní ojú ogun, ní Beti Ṣemeṣi; ó sì mú un wá sí Jerusalẹmu. Ó wó odi Jerusalẹmu palẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Kọ̀rọ̀. Gígùn ibi tí à ń wí yìí jẹ́ irinwo igbọnwọ (200 mita.)

24 Ó kó gbogbo wúrà, fadaka ati àwọn ohun èlò tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú Obedi Edomu ní ilé Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ààfin ọba, ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà níbẹ̀ ati àwọn eniyan, ó sì pada sí Samaria.

25 Amasaya, ọmọ Joaṣi, ọba Juda gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọba Israẹli.

26 Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu ìwé àwọn ọba Juda ati Israẹli.

27 Láti ìgbà tí Amasaya ti pada lẹ́yìn OLUWA ni àwọn eniyan ti dìtẹ̀ mọ́ ọn ní Jerusalẹmu, nítorí náà, ó sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n lépa rẹ̀ lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á níbẹ̀.

28 Wọ́n fi ẹṣin gbé òkú rẹ̀ wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi ní ibojì àwọn baba rẹ̀.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 26

Usaya, Ọba Juda

1 Gbogbo àwọn ará Juda fi Usaya, ọmọ ọdún mẹrindinlogun jọba lẹ́yìn ikú Amasaya baba rẹ̀.

2 Ó tún Eloti kọ́, ó gbà á pada fún Juda lẹ́yìn ikú Amasaya, baba rẹ̀.

3 Ọmọ ọdún mẹrindinlogun ni Usaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya, ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀.

4 Ó ṣe nǹkan tí ó tọ́ níwájú OLUWA, bí Amasaya baba rẹ̀.

5 Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un.

6 Ó gbógun ti àwọn ará Filistia, ó sì wó odi Gati, ati ti Jabine ati ti Aṣidodu lulẹ̀. Ó kọ́ àwọn ìlú olódi ní agbègbè Aṣidodu ati ní ibòmíràn ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia.

7 Ọlọrun ràn án lọ́wọ́, ó ṣẹgun àwọn ará Filistia ati àwọn ará Arabia tí wọ́n ń gbé Guribaali ati àwọn ará Meuni.

8 Àwọn ará Amoni ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún Usaya, òkìkí rẹ̀ kàn káàkiri títí dé agbègbè ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ó di alágbára gan-an.

9 Usaya tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi Ẹnubodè tí ó wà ní igun odi, ati sí ibi Ẹnubodè àfonífojì, ati níbi Ìṣẹ́po Odi. Ó sì mọ odi sí wọn.

10 Ó tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ sinu aṣálẹ̀, ó gbẹ́ ọpọlọpọ kànga, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ agbo ẹran ọ̀sìn ní àwọn ẹsẹ̀ òkè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn ń dá oko fún un ati àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu àjàrà, lórí òkè ati lórí àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀.

11 Usaya ní ọpọlọpọ ọmọ ogun, tí wọ́n tó ogun lọ, ó pín wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí ètò tí Jeieli akọ̀wé, ati Maaseaya, ọ̀gágun ṣe, lábẹ́ àkóso Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun ọba.

12 Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé, tí wọ́n sì jẹ́ akọni ọkunrin jẹ́ ẹgbẹtala (2,600).

13 Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lábẹ́ wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbaarin ati ẹẹdẹgbaata (307,500), wọ́n lágbára láti jagun, ati láti bá ọba dojú kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀.

14 Usaya ọba fún gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní apata, ọ̀kọ̀, àṣíborí, ẹ̀wù ihamọra, ọfà, ati òkúta fún kànnàkànnà wọn.

15 Ó ní àwọn ẹ̀rọ tí àwọn alágbẹ̀dẹ ṣe sórí àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn igun odi ní Jerusalẹmu láti máa tafà ati láti máa sọ àwọn òkúta ńláńlá. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri nítorí pé Ọlọrun ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nà ìyanu títí ó fi di alágbára.

Usaya Jìyà nítorí Ìwà Ìgbéraga Rẹ̀

16 Ṣugbọn nígbà tí Usaya di alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ tì í ṣubú. Ó ṣe aiṣootọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó wọ inú tẹmpili OLUWA, ó lọ sun turari lórí pẹpẹ turari.

17 Ṣugbọn Asaraya, alufaa, wọlé lọ bá a pẹlu àwọn ọgọrin alufaa tí wọ́n jẹ́ akọni.

18 Wọ́n dojú kọ ọ́, wọ́n ní, “Usaya, kò tọ́ fún ọ láti sun turari sí OLUWA; iṣẹ́ àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni ni, àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ láti máa sun turari. Jáde kúrò ninu ibi mímọ́! Nítorí o ti ṣe ohun tí kò tọ́, kò sì buyì kún ọ lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun rẹ.”

19 Inú bí Usaya nítorí pé àwo turari ti wà lọ́wọ́ rẹ̀ tí ó fẹ́ fi sun turari. Níbi tí ó ti ń bínú sí àwọn alufaa, àrùn ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, lójú àwọn alufaa ninu ilé OLUWA.

20 Nígbà tí Asaraya, olórí alufaa ati àwọn alufaa rí i tí ẹ̀tẹ̀ yọ níwájú rẹ̀, wọ́n yára tì í jáde. Ìkánjú ni òun pàápàá tilẹ̀ bá jáde, nítorí pé OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà.

21 Usaya ọba di adẹ́tẹ̀ títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ́ ilé fún un tí ó ń dá gbé; nítorí wọ́n yọ ọ́ kúrò ninu ilé OLUWA. Jotamu ọmọ rẹ̀ di alákòóso ìjọba, ó sì ń darí àwọn ará ìlú.

22 Àwọn nǹkan yòókù tí Usaya ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu àkọsílẹ̀ wolii Aisaya, ọmọ Amosi.

23 Nígbà tí Usaya kú, wọ́n sin ín sí itẹ́ àwọn ọba, wọn kò sin ín sinu ibojì àwọn ọba, nítorí wọ́n ní, “Adẹ́tẹ̀ ni.” Jotamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 27

Jotamu, Ọba Juda

1 Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jotamu nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹrindinlogun. Jeruṣa, ọmọ Sadoku ni ìyá rẹ̀.

2 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bíi Usaya, baba rẹ̀; àfi pé òun kò lọ sun turari ninu tẹmpili OLUWA. Ṣugbọn àwọn eniyan ń bá ìwà burúkú wọn lọ.

3 Ó kọ́ ẹnu ọ̀nà òkè ilé OLUWA, ó sì tún ògiri Ofeli mọ.

4 Ó kọ́ àwọn ìlú ní agbègbè olókè Juda ó sì kọ́ ibi ààbò ati ilé-ìṣọ́ ninu igbó lára òkè.

5 Ó bá ọba àwọn ará Amoni jà, ó sì ṣẹgun wọn. Ní ọdún tí ó ṣẹgun wọn, wọ́n fún un ní ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori alikama ati ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori ọkà baali. Iye kan náà ni wọ́n fún un ní ọdún keji ati ọdún kẹta.

6 Jotamu di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ati àwọn ogun tí ó jà, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó tún ṣe ni a kọ sinu ìwé àwọn ọba Israẹli ati ti Juda.

8 Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu.

9 Nígbà tí Jotamu kú, wọ́n sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 28

Ahasi, Ọba Juda

1 Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Kò sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA bíi Dafidi baba ńlá rẹ̀.

2 Ṣugbọn ó ṣe bí àwọn ọba Israẹli, ó tilẹ̀ yá ère fún oriṣa Baali.

3 Ó ń sun turari ní àfonífojì àwọn ọmọ Hinomu, ó sì ń fi àwọn ọmọkunrin rẹ̀ rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú Israẹli ń hù.

4 Ó rúbọ, ó sun turari ní àwọn ibi ìrúbọ, ati lórí òkè káàkiri ati lábẹ́ gbogbo igi tútù.

Ogun láàrin Siria ati Israẹli

5 Nítorí náà OLUWA Ọlọrun rẹ̀ fi í lé ọba Siria lọ́wọ́. Ọba Siria ṣẹgun rẹ̀, ó sì kó àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́rú lọ sí Damasku. Ọlọrun tún fi lé ọba Israẹli lọ́wọ́, ó ṣẹgun rẹ̀, ó sì pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní ìpakúpa.

6 Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, Peka, ọmọ Remalaya, ọba Israẹli, pa ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ninu àwọn ọmọ ogun Juda; tí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni. Ọlọrun jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀.

7 Sikiri, akikanju jagunjagun kan, ará Efuraimu pa Maaseaya, ọmọ ọba, ati Asirikamu, olórí ogun tí ń ṣọ́ ààfin ọba, ati Elikana, igbákejì ọba.

8 Àwọn tí ará ilẹ̀ Israẹli dè ní ìgbèkùn lọ ninu àwọn ará ilé Juda jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àtàwọn obinrin, àtàwọn ọmọkunrin, àtàwọn ọmọbinrin; wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun lọ sí Samaria.

Wolii Odedi

9 Wolii OLUWA kan tí ń jẹ́ Odedi wà ní ìlú Samaria; ó lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Israẹli nígbà tí wọ́n ń pada bọ̀. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín bínú sí àwọn ará Juda ni ó fi jẹ́ kí ẹ ṣẹgun wọn, ṣugbọn ẹ pa wọ́n ní ìpakúpa tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun pàápàá ṣàkíyèsí rẹ̀.

10 Ẹ tún wá fẹ́ kó tọkunrin tobinrin Juda ati Jerusalẹmu lẹ́rú. Ṣé ẹ̀yin alára náà kò ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín?

11 Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ dá àwọn arakunrin yín tí ẹ ti kó lẹ́rú pada, nítorí ibinu OLUWA wà lórí yín.”

12 Nígbà náà ni àwọn ìjòyè kan lára àwọn ará Efuraimu: Asaraya, ọmọ Johanani, Berekaya, ọmọ Meṣilemoti, Jehisikaya, ọmọ Ṣalumu ati Amasa, ọmọ Hadilai dìde, wọ́n tako àwọn tí ń ti ojú ogun bọ̀, wọ́n sọ fún wọn pé,

13 “Ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ìgbèkùn wọnyi wọ ibí wá, kí ẹ tún wá dákún ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹ̀bi tí ó wà lọ́rùn wa tẹ́lẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ tẹ́lẹ̀, ọwọ́ ibinu OLUWA sì ti wà lára Israẹli.”

14 Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun náà dá àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú ati ẹrù tí wọn ń kó bọ̀ sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè ati gbogbo ìjọ eniyan Israẹli.

15 Àwọn kan tí wọ́n yàn bá dìde, wọ́n kó àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó lẹ́rú ati ẹrù wọn, wọ́n wọ àwọn tí wọ́n wà ní ìhòòhò láṣọ; wọ́n fún wọn ní bàtà, wọ́n pèsè oúnjẹ ati nǹkan mímu fún wọn, wọ́n sì fi òróró sí ọgbẹ́ wọn. Wọ́n gbé gbogbo àwọn tí àárẹ̀ ti mú gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wọn ní Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pada lọ sí Samaria.

Ahasi bẹ Asiria lọ́wẹ̀

16 Ní àkókò yìí, Ahasi ranṣẹ lọ bẹ ọba Asiria lọ́wẹ̀,

17 nítorí pé àwọn ará Edomu tún pada wá gbógun ti Juda; wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n sì kó àwọn kan ninu wọn lẹ́rú lọ.

18 Àwọn ará Filistia ti gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati ní agbègbè Nẹgẹbu, ní Juda. Wọ́n jagun gba Beti Ṣemeṣi, Aijaloni, ati Gederotu, wọ́n sì gba Soko, Timna, ati Gimso pẹlu àwọn ìletò ìgbèríko wọn, wọ́n bá ń gbé ibẹ̀.

19 OLUWA rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi, ọba Juda, nítorí pé ó hùwà ìríra ní Juda, ó sì ṣe aiṣootọ sí OLUWA.

20 Nítorí náà Tigilati Pileseri, ọba Asiria gbógun ti Ahasi, ó sì fìyà jẹ ẹ́, dípò kí ó ràn án lọ́wọ́.

21 Ahasi kó ohun ìṣúra inú ilé OLUWA, ati ti ààfin, ati ti inú ilé àwọn ìjòyè, ó fi san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria, sibẹsibẹ ọba Asiria kò ràn án lọ́wọ́.

Ẹ̀ṣẹ̀ Ahasi

22 Ní àkókò ìyọnu Ahasi ọba, ó túbọ̀ ṣe alaiṣootọ sí OLUWA ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.

23 Ó rúbọ sí àwọn oriṣa àwọn ará Damasku tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn oriṣa àwọn ọba Siria ràn wọ́n lọ́wọ́, n óo rúbọ sí wọn kí wọ́n lè ran èmi náà lọ́wọ́.” Ṣugbọn àwọn oriṣa ọ̀hún ni wọ́n fa ìparun bá òun ati orílẹ̀-èdè rẹ̀.

24 Gbogbo ohun èlò ilé Ọlọrun ni Ahasi gé wẹ́wẹ́, ó sì ti ìlẹ̀kùn ibẹ̀; ó wá tẹ́ pẹpẹ oriṣa káàkiri Jerusalẹmu.

25 Ó ṣe ibi ìrúbọ káàkiri àwọn ìlú Juda níbi tí yóo ti máa sun turari sí àwọn oriṣa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó mú OLUWA Ọlọrun àwọn baba rẹ̀ bínú.

26 Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati ti Israẹli.

27 Nígbà tí Ahasi ọba kú, wọ́n sin ín sí Jerusalẹmu, wọn kò sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba. Hesekaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 29

Hesekaya, Ọba Juda

1 Hesekaya jọba ní Juda nígbà tí ó di ẹni ọdún mẹẹdọgbọn; ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abija, ọmọ Sakaraya.

2 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.

Yíya Tẹmpili sí Mímọ́

3 Ní oṣù kinni ọdún kinni ìjọba rẹ̀, ó ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ó sì tún wọn ṣe.

4 Ó kó àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ sí gbàgede tí ó wà ní apá ìlà oòrùn ilé Ọlọrun.

5 Ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì ya ilé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín sí mímọ́ pẹlu. Ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan ẹ̀gbin kúrò ninu ibi mímọ́,

6 nítorí àwọn baba wa ti ṣe aiṣododo, wọ́n sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, Ọlọrun wa. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọ́n gbójú kúrò lára ibùgbé rẹ̀, wọ́n sì kẹ̀yìn sí i.

7 Wọ́n ti ìlẹ̀kùn yàrá àbáwọlé tẹmpili, wọ́n pa fìtílà tí ó wà ní ibi mímọ́, wọn kò sun turari, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rú ẹbọ sísun ní ibi mímọ́ sí Ọlọrun Israẹli.

8 Nítorí náà ni OLUWA ṣe bínú sí Juda ati Jerusalẹmu, ohun tí Ọlọrun fi wọ́n ṣe sì dẹ́rùba gbogbo eniyan. Wọ́n di ẹni ẹ̀gàn ati ẹni àrípòṣé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i lónìí.

9 Ìdí nìyí tí àwọn baba wa fi ṣubú lójú ogun tí wọ́n sì kó àwọn ọmọ ati àwọn aya wa lẹ́rú.

10 “Nisinsinyii, mo ti pinnu láti bá OLUWA Ọlọrun Israẹli dá majẹmu, kí ibinu gbígbóná rẹ̀ lè kúrò lórí wa.

11 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má jáfara, nítorí pé OLUWA ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀, ati láti sìn ín; láti jẹ́ iranṣẹ rẹ̀ ati láti máa sun turari sí i.”

12 Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ní tẹmpili nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: Mahati, ọmọ Amasai, ati Joẹli, ọmọ Asaraya; láti inú ìdílé Merari: Kiṣi, ọmọ Abidi ati Asaraya, ọmọ Jahaleleli; láti inú ìdílé Geriṣoni: Joa, ọmọ Sima ati Edẹni, ọmọ Joa.

13 Láti inú ìdílé Elisafani: Ṣimiri ati Jeueli; láti inú ìdílé Asafu: Sakaraya ati Matanaya,

14 láti inú ìdílé Hemani: Jeueli ati Ṣimei; láti inú ìdílé Jedutuni: Ṣemaaya ati Usieli.

15 Wọ́n bá kó àwọn arakunrin wọn jọ, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́. Wọ́n wọ ilé OLUWA láti tọ́jú rẹ̀ bí ọba ti pa á láṣẹ, gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.

16 Àwọn alufaa wọ ibi mímọ́ lọ láti tọ́jú rẹ̀. Gbogbo ohun aláìmọ́ tí wọ́n rí ninu tẹmpili OLUWA ni wọ́n kó sí àgbàlá ilé náà. Àwọn ọmọ Lefi sì kó gbogbo wọn lọ dà sí odò Kidironi lẹ́yìn ìlú.

17 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sí mímọ́ ní ọjọ́ kinni oṣù kinni. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá sí yàrá àbáwọlé ilé OLUWA. Ọjọ́ mẹjọ ni wọ́n fi ya ilé OLUWA sí mímọ́, wọ́n parí ní ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù náà.

A Tún Tẹmpili Yà sí Mímọ́

18 Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ Hesekaya ọba lọ, wọ́n sọ fún un pé, “A ti tọ́jú ilé OLUWA: ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, ati tabili àkàrà ìfihàn ati gbogbo ohun èlò rẹ̀.

19 Gbogbo àwọn ohun èlò tí Ahasi ọba ti patì nígbà tí ó ṣe aiṣododo ni a ti tọ́jú, tí a sì ti yà sí mímọ́. A ti kó gbogbo wọn siwaju pẹpẹ OLUWA.”

20 Hesekaya ọba dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ìjòyè ìlú jọ, wọ́n bá lọ sinu ilé OLUWA.

21 Wọ́n fi akọ mààlúù meje, àgbò meje, ọ̀dọ́ aguntan meje ati òbúkọ meje rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba Hesekaya, ati ilé OLUWA ati ilé Juda. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni, fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA.

22 Àwọn akọ mààlúù ni wọ́n kọ́kọ́ pa, àwọn alufaa gba ẹ̀jẹ̀ wọn, wọ́n dà á sára pẹpẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pa àwọn àgbò, wọ́n sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sára pẹpẹ.

23 Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn òbúkọ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ ọba ati ìjọ eniyan, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn lórí.

24 Àwọn alufaa pa àwọn òbúkọ náà, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn rúbọ lórí pẹpẹ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ọmọ Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ pé wọ́n gbọdọ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo eniyan.

25 Ọba pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Lefi dúró ninu ilé OLUWA pẹlu ohun èlò orin bíi kimbali, hapu ati dùùrù, gẹ́gẹ́ bí i àṣẹ tí OLUWA pa, láti ẹnu Dafidi ati wolii Gadi tí í ṣe aríran ọba, ati wolii Natani.

26 Àwọn ọmọ Lefi dúró pẹlu ohun èlò orin Dafidi, àwọn alufaa sì dúró pẹlu fèrè.

27 Hesekaya pàṣẹ pé kí wọ́n rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ náà, àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí kọrin sí OLUWA pẹlu fèrè ati àwọn ohun èlò orin Dafidi, ọba Israẹli.

28 Ọba ati ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sin OLUWA, àwọn akọrin ń kọrin, àwọn afunfèrè ń fun fèrè títí tí ẹbọ sísun náà fi parí.

29 Nígbà tí wọ́n rú ẹbọ sísun tán, ọba ati ìjọ eniyan wólẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun.

30 Ọba ati àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n kọ orin ìyìn Dafidi ati ti Asafu, aríran. Wọ́n fi ayọ̀ kọ orin ìyìn náà, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.

31 Hesekaya bá sọ fún wọn pé: “Nisinsinyii tí ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ wá, kí ẹ sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.” Ìjọ eniyan sì mú ọrẹ ati ẹbọ ọpẹ́ wá, àwọn tí wọ́n fẹ́ sì mú ẹbọ sísun wá.

32 Àwọn nǹkan tí wọn mú wá jẹ́ aadọrin akọ mààlúù, ọgọrun-un (100) àgbò, igba (200) ọ̀dọ́ aguntan, gbogbo rẹ̀ wà fún ẹbọ sísun sí OLUWA.

33 Àwọn ẹran tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ẹbọ jẹ́ ẹgbẹta (600) akọ mààlúù, ati ẹgbẹẹdogun (3,000) aguntan.

34 Àwọn alufaa kò pọ̀ tó láti pa gbogbo ẹran náà, nítorí náà, kí ó tó di pé àwọn alufaa mìíràn yóo ya ara wọn sí mímọ́, àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Lefi, ràn wọ́n lọ́wọ́ títí iṣẹ́ náà fi parí. Àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòótọ́ ní yíya ara wọn sí mímọ́ ju àwọn alufaa lọ.

35 Yàtọ̀ sí ọpọlọpọ ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀rá rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun.

Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ìsìn ninu ilé OLUWA ṣe tún bẹ̀rẹ̀.

36 Hesekaya ati ìjọ eniyan yọ̀ nítorí ohun tí Ọlọrun ṣe fún wọn, nítorí láìròtẹ́lẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.