Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 10

Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Àríwá Dìtẹ̀

1 Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ sibẹ láti fi jọba.

2 Nígbà tí Jeroboamu, ọmọ Nebati, gbọ́, ó pada wá láti Ijipti, níbi tí ó ti sá lọ fún Solomoni.

3 Àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ranṣẹ sí i, òun ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n wí fún un pé,

4 “Àjàgà tí baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn wúwo, ṣugbọn nisinsinyii, dín wahala tí baba rẹ fi wá ṣe kù, kí o sì sọ àjàgà wa di fúfúyẹ́, a óo sì máa sìn ọ́.”

5 Rehoboamu bá dáhùn pé, “Ẹ pada wá gbọ́ èsì lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.” Àwọn eniyan náà bá lọ.

6 Rehoboamu bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli tí wọ́n bá baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà ayé rẹ̀, ó ní, “Ẹ fún mi ní ìmọ̀ràn, irú èsì wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?”

7 Wọ́n gbà á ní ìmọ̀ràn pé, “Bí o bá ṣe dáradára sí àwọn eniyan wọnyi, tí o bá ṣe ohun tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn, tí o sì sọ̀rọ̀ dáradára fún wọn, wọn yóo máa sìn ọ́ títí lae.”

8 Ṣugbọn Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà. Ó lọ jíròrò pẹlu àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọn ń bá a ṣiṣẹ́, ó bi wọ́n pé,

9 “Kí ni èsì tí ó yẹ kí n fún àwọn tí wọ́n sọ fún mi pé kí n sọ àjàgà tí baba mi gbé bọ àwọn lọ́rùn di fúfúyẹ́?”

10 Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé, “Lọ sọ fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi tí ó kéré jù yóo tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ.

11 Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn tèmi yóo tún wúwo ju ti baba mi lọ. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi ta yín.’ ”

12 Ní ọjọ́ kẹta, Jeroboamu pẹlu àwọn ọmọ Israẹli bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn.

13 Ọba kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà, ó gbójú mọ́ wọn,

14 ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.”

15 Ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé ọwọ́ Ọlọrun ni àyípadà yìí ti wá, kí ó lè mú ohun tí ó ní kí wolii Ahija, ará Ṣilo, sọ fún Jeroboamu, ọmọ Nebati, ṣẹ.

16 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Rehoboamu kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dáhùn pé,

“Kí ló kàn wá pẹlu ilé Dafidi?

Kí ló pa wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese?

Ẹ pada sinu àgọ́ yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli

Dafidi, fọwọ́ mú ilé rẹ.”

Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lọ sí ilé wọn,

17 ṣugbọn Rehoboamu jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda.

18 Ọba rán Hadoramu tí ó jẹ́ olórí àwọn akóniṣiṣẹ́ sí àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Rehoboamu ọba bá yára bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá àsálà lọ sí Jerusalẹmu.

19 Láti ìgbà náà lọ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ń bá ilé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 11

Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣemaaya

1 Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) àwọn akọni ọmọ ogun jọ láti inú ẹ̀yà Juda ati Bẹnjamini, láti bá àwọn ọmọ Israẹli jagun, kí ó lè fi ipá gba ìjọba rẹ̀ pada.

2 Ṣugbọn OLUWA sọ fún wolii Ṣemaaya, eniyan Ọlọrun pé,

3 “Sọ fún Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda ati Bẹnjamini pé,

4 OLUWA ní, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ bá àwọn arakunrin yín jà. Kí olukuluku yín pada sí ilé rẹ̀ nítorí èmi ni mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ó ṣẹlẹ̀.’ ” Wọ́n gbọ́ràn sí OLUWA lẹ́nu, wọ́n pada, wọn kò sì lọ bá Jeroboamu jagun mọ́.

Rehoboamu Mọ Odi yí Àwọn Ìlú Ká

5 Rehoboamu ń gbé Jerusalẹmu, ó kọ́ àwọn ìlú ààbò wọnyi sí Juda:

6 Bẹtilẹhẹmu, Etamu, ati Tekoa;

7 Betisuri, Soko, ati Adulamu;

8 Gati, Mareṣa, ati Sifi;

9 Adoraimu, Lakiṣi, ati Aseka;

10 Sora, Aijaloni ati Heburoni. Àwọn ni ìlú olódi ní Juda ati Bẹnjamini.

11 Ó tún àwọn ìlú olódi ṣe, wọ́n lágbára, níbẹ̀ ni ó fi àwọn olórí ogun sí, ó sì kó ọpọlọpọ oúnjẹ, epo ati ọtí waini pamọ́ sibẹ.

12 Ó kó ọ̀kọ̀ ati apata sinu gbogbo wọn, ó sì fi agbára kún agbára wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fi ọwọ́ mú Juda ati Bẹnjamini.

Àwọn Alufaa ati Àwọn Ọmọ Lefi Wá sí Juda

13 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli sì fara mọ́ Rehoboamu. Gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

14 Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun.

15 Ó yan àwọn alufaa ti ara rẹ̀ fún ibi ìrúbọ ati fún ilé ère ewúrẹ́ ati ti ọmọ aguntan tí ó gbé kalẹ̀.

16 Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ sin Ọlọrun Israẹli tọkàntọkàn láti inú olukuluku ẹ̀yà Israẹli, tẹ̀lé àwọn alufaa wá sí Jerusalẹmu láti ṣe ìrúbọ sí OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.

17 Wọ́n sọ ìjọba Juda di alágbára, wọ́n sì ṣe alátìlẹ́yìn fún Rehoboamu ọmọ Solomoni fún ọdún mẹta; wọ́n ń rìn ní ìlànà Dafidi ati ti Solomoni ní gbogbo ìgbà náà.

Àwọn Ìdílé Rehoboamu

18 Rehoboamu fẹ́ Mahalati, ọmọ Jerimotu, ọmọ Dafidi, ìyá rẹ̀ ni Abihaili, ọmọ Eliabu, ọmọ Jese.

19 Iyawo Rehoboamu yìí bí ọmọkunrin mẹta fún un; wọ́n ń jẹ́: Jeuṣi, Ṣemaraya ati Sahamu.

20 Lẹ́yìn náà, ó tún fẹ́ Maaka, ọmọ Absalomu; òun bí ọmọkunrin mẹrin fún un; wọ́n ń jẹ́ Abija, Atai, Sisa ati Ṣelomiti.

21 Maaka, ọmọ Absalomu ni Rehoboamu fẹ́ràn jùlọ ninu àwọn iyawo rẹ̀. Àwọn mejidinlogun ni ó gbé ní iyawo, o sì ní ọgọta obinrin mìíràn. Ó bí ọmọkunrin mejidinlọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin.

22 Ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tí ń jẹ́ Abija ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ. Ó yàn án láti jẹ́ ọba lẹ́yìn tí òun bá kú.

23 Ó dọ́gbọ́n fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe olórí káàkiri, ó pín wọn káàkiri jákèjádò ilẹ̀ Juda ati Bẹnjamini ní àwọn ìlú alágbára. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n ṣe aláìní. Ó sì fẹ́ iyawo fún gbogbo wọn.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 12

Àwọn Ará Ijipti Gbógun ti Juda

1 Láìpẹ́, lẹ́yìn tí Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ tí ó di alágbára, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ kọ òfin OLUWA sílẹ̀.

2 Nígbà tí ó di ọdún karun-un ìjọba rẹ̀, Ọlọrun fi ìyà jẹ ẹ́ nítorí aiṣootọ rẹ̀. Ṣiṣaki ọba Ijipti gbógun ti Jerusalẹmu pẹlu ẹgbẹfa (1,200) kẹ̀kẹ́ ogun,

3 ati ọ̀kẹ́ mẹta (60,000) ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Ijipti. Àwọn ará Libia, àwọn ará Sukiimu, ati àwọn ará Etiopia wà ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

4 Ó gba gbogbo ìlú olódi Juda títí ó fi dé Jerusalẹmu.

5 Lẹ́yìn náà, wolii Ṣemaaya lọ bá Rehoboamu ati gbogbo àwọn olóyè Juda, tí wọ́n ti péjọ sí Jerusalẹmu lórí ọ̀rọ̀ Ṣiṣaki ọba Ijipti. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA ní ẹ ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà ni òun ṣe fi yín lé Ṣiṣaki lọ́wọ́.”

6 Àwọn ìjòyè ní Israẹli ati Rehoboamu ọba bá wí pẹlu ìtẹríba pé, “Olódodo ni Ọlọrun.”

7 Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti ronupiwada, ó sọ fún wolii Ṣemaaya pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, òun kò ní pa wọ́n run mọ́, ṣugbọn òun óo gbà wọ́n sílẹ̀ díẹ̀. Òun kò ní fi agbára lo Ṣiṣaki láti rọ̀jò ibinu òun sórí Jerusalẹmu.

8 Sibẹsibẹ wọn yóo jẹ́ ẹrú rẹ̀, kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ ninu pé kí wọ́n sin òun OLUWA, ati kí wọ́n sin ìjọba àwọn ilẹ̀ mìíràn.

9 Ṣiṣaki bá gbógun ti Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ìṣúra ilé OLUWA lọ, ati ti ààfin ọba patapata, ati apata wúrà tí Solomoni ṣe.

10 Nítorí náà, Rehoboamu ṣe apata bàbà dípò wọn, ó sì fi wọ́n sábẹ́ àkóso olùṣọ́ ààfin.

11 Nígbàkúùgbà tí ọba bá lọ sí ilé OLUWA, olùṣọ́ ààfin á ru apata náà ní iwájú rẹ̀, lẹ́yìn náà yóo kó wọn pada sí ibi tí wọ́n kó wọn pamọ́ sí.

12 Nítorí pé Rehoboamu ronupiwada, OLUWA yí ibinu rẹ̀ pada, kò pa á run patapata mọ́. Nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ dáradára ní ilẹ̀ Juda.

Ìjọba Rehoboamu ní ṣókí

13 Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Jerusalẹmu, agbára rẹ̀ sì pọ̀ sí i. Ọmọ ọdún mọkanlelogoji ni nígbà tí ó jọba. Ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin àwọn ẹ̀yà yòókù, pé kí wọ́n ti máa sin òun. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Amoni.

14 Rehoboamu ṣe nǹkan burúkú, nítorí pé kò fi ọkàn sí ati máa rìn ní ìlànà OLUWA.

15 Gbogbo ohun tí Rehoboamu ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn wolii Ṣemaaya, ati sinu ìwé Ido aríran. Nígbà gbogbo ni ogun máa ń wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu.

16 Nígbà tí Rehoboamu kú, wọ́n sin ín sí ìlú Dafidi, níbi ibojì àwọn baba rẹ̀. Abija ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 13

Ogun láàrin Abija ati Jeroboamu

1 Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Jeroboamu ni Abija jọba ní ilẹ̀ Juda.

2 Ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Mikaya, ọmọ Urieli ará Gibea.

Nígbà kan, ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin Abija ati Jeroboamu.

3 Abija kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) akọni ọmọ ogun jọ láti bá Jeroboamu jagun. Jeroboamu náà kó ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) akọni ọmọ ogun jọ.

4 Abija gun orí òkè Semaraimu tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu lọ. Ó kígbe lóhùn rara, ó ní: “Gbọ́ mi, ìwọ Jeroboamu ati gbogbo ẹ̀yin eniyan Israẹli,

5 ṣé ẹ ẹ̀ mọ̀ pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fi iyọ̀ bá Dafidi dá majẹmu ayérayé pé àtìrandíran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli títí lae?

6 Sibẹsibẹ, Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi, dìde, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Solomoni, oluwa rẹ̀.

7 Ó sì lọ kó àwọn jàǹdùkú ati àwọn aláìníláárí eniyan kan jọ, wọ́n pe Rehoboamu ọmọ Solomoni níjà. Rehoboamu jẹ́ ọmọde nígbà náà, kò sì ní ìrírí tó láti dojú ìjà kọ wọ́n.

8 Nisinsinyii, ẹ rò pé ẹ lè dojú ìjà kọ ìjọba OLUWA, tí ó gbé lé àwọn ọmọ Dafidi lọ́wọ́; nítorí pé ẹ pọ̀ ní iye ati pé ẹ ní ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí Jeroboamu fi wúrà ṣe tí ó pè ní ọlọrun yín?

9 Ẹ ti lé àwọn alufaa OLUWA kúrò lọ́dọ̀ yín: àwọn ọmọ Aaroni, ati àwọn ọmọ Lefi. Ẹ yan alufaa mìíràn dípò wọn bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá ti mú akọ mààlúù tabi aguntan meje wá, ẹ̀ ń yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ alufaa àwọn oriṣa tí kì í ṣe Ọlọrun.

10 “Ṣugbọn ní tiwa, OLUWA Ọlọrun ni à ń sìn; a kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ọmọ Aaroni ni àwọn alufaa wa, àwọn ọmọ Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

11 Ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́ ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun, tí wọ́n sì ń sun turari. Wọ́n ń fi àkàrà ìfihàn sórí tabili wúrà. Ní alaalẹ́, wọ́n ń tan fìtílà wúrà lórí ọ̀pá fìtílà rẹ̀; nítorí àwa ń ṣe ohun tí Ọlọrun wa pa láṣẹ fún wa, ṣugbọn ẹ̀yin ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

12 Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.”

13 Ṣugbọn Jeroboamu ti rán ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan lọ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Juda látẹ̀yìn. Àwọn ọmọ ogun Jeroboamu wà níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, àwọn tí ó rán tí wọ́n sápamọ́ sì wà lẹ́yìn wọn.

14 Nígbà tí Juda rí i pé ogun wà níwájú ati lẹ́yìn wọn, wọ́n ké pe OLUWA, àwọn alufaa sì fọn fèrè ogun.

15 Àwọn ọmọ ogun Juda hó ìhó ogun, bí wọ́n sì ti kígbe ni Ọlọrun ṣẹgun Jeroboamu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli fún Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda.

16 Àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, Ọlọrun sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ ogun Juda lọ́wọ́.

17 Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda pa àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ìpakúpa, tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000) fi kú ninu àwọn akọni ọmọ ogun Israẹli.

18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda ṣe tẹ orí àwọn ọmọ Israẹli ba tí wọ́n sì ṣẹgun wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Juda gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.

19 Abija lé Jeroboamu, ó sì gba ìlú Bẹtẹli, ati Jeṣana, ati Efuroni ati àwọn ìletò tí ó yí wọn ká lọ́wọ́ rẹ̀.

20 Jeroboamu kò sì lè gbérí ní àkókò Abija. Nígbà tí ó yá Ọlọrun lu Jeroboamu pa.

21 Ṣugbọn agbára Abija bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ síi. Iyawo mẹrinla ni ó ní; ó sì bí ọmọkunrin mejilelogun ati ọmọbinrin mẹrindinlogun.

22 Gbogbo nǹkan yòókù ti Abija ṣe ní àkókò ìjọba rẹ̀, ati ohun tí ó sọ, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn wolii Ido.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 14

Asa Ọba Ṣẹgun Àwọn Ará Sudani

1 Nígbà tí Abija ọba kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní àkókò rẹ̀, alaafia wà ní ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́wàá.

2 Asa ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì dùn mọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó mú inú Ọlọrun dùn.

3 Ó kó àwọn pẹpẹ àjèjì ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn kúrò, ó wó àwọn òpó oriṣa wọn lulẹ̀, ó sì fọ́ ère Aṣera.

4 Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Juda láti wá ojurere OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn ati láti pa òfin rẹ̀ mọ́.

5 Ó kó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ tí wọ́n ti ń sun turari ní gbogbo àwọn ìlú Juda jáde. Alaafia sì wà ní àkókò ìjọba rẹ̀.

6 Ó kọ́ àwọn ìlú olódi sí ilẹ̀ Juda nítorí pé alaafia wà ní gbogbo ilẹ̀ náà. Ní gbogbo ọdún rẹ̀ kò sí ogun, nítorí OLUWA fún wọn ní alaafia.

7 Ó bá sọ fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ Juda pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́ àwọn ìlú wọnyi, kí á mọ odi yí wọn ká pẹlu ilé ìṣọ́, kí á kan ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè wọn, kí á sì fi àwọn ọ̀pá ìdábùú sí wọn. Ìkáwọ́ wa ni gbogbo ilẹ̀ náà wà, nítorí pé à ń ṣe ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa. A ti wá ojurere rẹ̀, ó sì fún wa ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà.” Wọ́n kọ́ àwọn ìlú náà, wọ́n sì ń ní ìtẹ̀síwájú.

8 Asa ọba ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ọmọ ogun ní ilẹ̀ Juda, tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀ ati ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) láti Bẹnjamini tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọrun. Gbogbo wọn ni a ti kọ́ ní ogun jíjà tí wọ́n sì jẹ́ akọni.

9 Sera, ará Etiopia, gbógun tì wọ́n pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun (1,000,000) ọmọ ogun ati ọọdunrun (300) kẹ̀kẹ́ ogun. Wọ́n sì jagun títí dé Mareṣa.

10 Asa jáde lọ láti bá a jà. Olukuluku tẹ́ ibùdó ogun rẹ̀ sí àfonífojì Sefata ní Mareṣa.

11 Asa ké pe OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kò sí olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ nítorí pé o lè ran àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lágbára lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn tí wọ́n lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLUWA Ọlọrun wa, nítorí pé ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ní orúkọ rẹ ni a jáde láti wá bá ogun ńlá yìí jà. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun wa, má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣẹgun rẹ.”

12 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun àwọn ará Etiopia fún Asa ati àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Etiopia sì sá.

13 Asa ati àwọn ogun rẹ̀ lé wọn títí dé Gerari. Ọpọlọpọ àwọn ará Etiopia sì kú tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè gbá ara wọn jọ mọ́; wọn sì parun patapata níwájú OLUWA ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Juda sì kó ọpọlọpọ ìkógun.

14 Wọ́n run gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè Gerari, nítorí pé ẹ̀rù OLUWA ba àwọn ará ibẹ̀. Wọ́n fi ogun kó gbogbo àwọn ìlú náà nítorí pé ìkógun pọ̀ ninu wọn.

15 Wọ́n wó gbogbo àgọ́ àwọn tí ń sin mààlúù, wọ́n sì kó ọpọlọpọ aguntan ati ràkúnmí wọn pada sí Jerusalẹmu.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 15

Asa Ṣe Àtúnṣe

1 Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Asaraya ọmọ Odedi.

2 Ó lọ pàdé Asa, ó wí fún un pé, “Gbọ́ mi, ìwọ Asa, ati gbogbo ẹ̀yin ọmọ Juda ati ti Bẹnjamini, OLUWA wà pẹlu yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin náà bá wà pẹlu rẹ̀. Bí ẹ bá wá a, ẹ óo rí i. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun náà yóo kọ̀ yín sílẹ̀.

3 Ọjọ́ pẹ́, tí Israẹli ti wà láìní Ọlọrun òtítọ́, wọn kò ní alufaa tí ń kọ́ ni, wọn kò sì ní òfin.

4 Ṣugbọn nígbà tí ìyọnu dé, wọ́n yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Wọ́n wá OLUWA, wọ́n sì rí i.

5 Ní àkókò náà, kò sí ìbàlẹ̀ ọkàn fún àwọn tí wọn ń jáde ati àwọn tí wọ́n ń wọlé, nítorí ìdààmú ńlá dé bá àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.

6 Orílẹ̀-èdè kan ń pa ekeji run, ìlú kan sì ń pa ekeji rẹ́, nítorí Ọlọrun mú oniruuru ìpọ́njú bá wọn.

7 Ṣugbọn, ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ mọ́kàn le, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ yín, nítorí iṣẹ́ yín yóo ní èrè.”

8 Nígbà tí Asa gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Asaraya ọmọ Odedi sọ, ó mọ́kàn le. Ó kó gbogbo ère kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini ati ní gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n gbà ní agbègbè olókè Efuraimu. Ó tún pẹpẹ OLUWA tí ó wà níwájú yàrá àbáwọlé ilé OLUWA ṣe.

9 Ó kó gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Bẹnjamini jọ, ati àwọn tí wọ́n wá láti Efuraimu, Manase ati Simeoni, tí wọ́n jẹ́ àlejò láàrin wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ eniyan láti ilẹ̀ Israẹli ni wọ́n ti sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.

10 Wọ́n péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹẹdogun ìjọba Asa.

11 Wọ́n mú ẹẹdẹgbẹrin (700) mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan ninu ìkógun tí wọ́n kó, wọ́n fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun baba wọn.

12 Wọ́n dá majẹmu pé àwọn yóo máa sin OLUWA Ọlọrun baba àwọn tọkàntọkàn àwọn;

13 ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, ìbáà ṣe àgbà tabi ọmọde, ọkunrin tabi obinrin, pípa ni àwọn yóo pa á.

14 Wọ́n fi igbe búra ní orúkọ OLUWA pẹlu ariwo ati fèrè.

15 Inú gbogbo Juda sì dùn sí ẹ̀jẹ́ náà, nítorí pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi jẹ́ ẹ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń sin Ọlọrun. Ọlọrun gba ìsìn wọn, ó sì fún wọn ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà.

16 Asa ọba, yọ Maaka ìyá rẹ̀ àgbà pàápàá kúrò ní ipò ìyá ọba, nítorí pé ó gbẹ́ ère ìríra kan fún oriṣa Aṣera. Asa wó ère náà lulẹ̀, ó gé e wẹ́lẹwẹ̀lẹ, ó sì dáná sun ún ní odò Kidironi.

17 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Asa kò wó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ palẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, sibẹsibẹ kò ní ẹ̀bi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

18 Ó kó àwọn nǹkan tí Abija, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ fún Ọlọrun lọ sinu tẹmpili pẹlu gbogbo nǹkan tí òun pàápàá ti yà sí mímọ́: fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò.

19 Kò sí ogun mọ́ rárá títí tí ó fi di ọdún karundinlogoji ìjọba Asa.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 16

Ìyọnu De bá Israẹli

1 Ní ọdún kẹrindinlogoji ìjọba Asa, ní ilẹ̀ Juda, Baaṣa ọba Israẹli gbógun ti Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi Rama láti dí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Juda, kí ẹnikẹ́ni má baà lè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, kí àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ má sì lè jáde.

2 Nítorí náà, Asa kó fadaka ati wúrà láti ilé ìṣúra ilé OLUWA ati láti ààfin ranṣẹ sí Benhadadi, ọba Siria tí ó ń gbé Damasku, ó ranṣẹ sí i pé:

3 “Jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wà láàrin wa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàrin àwọn baba wa. Fadaka ati wúrà yìí ni mo fi ta ọ́ lọ́rẹ; pa majẹmu tí ó wà láàrin ìwọ ati Baaṣa ọba Israẹli tì, kí ó baà lè kó ogun rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.”

4 Benhadadi gba ọ̀rọ̀ Asa, ó bá rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jáde láti lọ gbógun ti àwọn ìlú Israẹli. Wọ́n ṣẹgun Ijoni, Dani, Abeli Maimu ati gbogbo ìlú tí wọ́n kó ìṣúra pamọ́ sí ní ilẹ̀ Nafutali.

5 Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi Rama tí ó ń mọ dúró.

6 Asa bá kó àwọn eniyan jọ jákèjádò Juda, wọ́n lọ kó òkúta ati pákó tí Baaṣa fi ń kọ́ Rama, wọ́n lọ fi kọ́ Geba ati Misipa.

Wolii Hanani

7 Nígbà náà ni Hanani aríran, wá sọ́dọ̀ Asa, ọba Juda, ó wí fún un pé, “Nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun rẹ, àwọn ogun Siria ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.

8 Ṣebí ogun Etiopia ati Libia lágbára gidigidi? Ṣebí wọ́n ní ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin? Ṣugbọn nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.

9 Nítorí ojú OLUWA ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ìwà òmùgọ̀ ni èyí tí o hù yìí; nítorí pé láti ìsinsìnyìí lọ nígbàkúùgbà ni o óo máa jagun.”

10 Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà.

Òpin Ìjọba Asa

11 Gbogbo nǹkan tí Asa ọba ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli.

12 Ní ọdún kọkandinlogoji ìjọba Asa, àrùn burúkú kan mú un lẹ́sẹ̀, àrùn náà pọ̀ pupọ. Sibẹsibẹ, ninu àìsàn náà kàkà kí ó ké pe OLUWA fún ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni ó lọ.

13 Asa kú ní ọdún kọkanlelogoji ìjọba rẹ̀.

14 Wọ́n sin ín sinu ibojì òkúta tí ó gbẹ́ fúnrarẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n tẹ́ ẹ sórí àkéte, tí ó kún fún oniruuru turari tí àwọn tí wọ́n ń ṣe turari ṣe. Wọ́n sì dá iná ńlá kan láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 17

Jehoṣafati di Ọba

1 Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbáradì láti dojú ìjà kọ Israẹli.

2 Ó kó àwọn ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi Juda, ó yan olórí ogun fún wọn ní ilẹ̀ Juda ati ní ilẹ̀ Efuraimu tí Asa baba rẹ̀ gbà.

3 OLUWA wà pẹlu Jehoṣafati nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbà ọ̀dọ̀ Dafidi, baba rẹ̀; kò sì bọ oriṣa Baali.

4 Ṣugbọn ó ń sin Ọlọrun àwọn baba rẹ̀, ó pa òfin Ọlọrun mọ́, kò sì tẹ̀lé ìṣe àwọn ọmọ Israẹli.

5 Nítorí náà OLUWA fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Juda sì ń san owó orí fún un. Nítorí náà ó di ọlọ́rọ̀ ati ọlọ́lá.

6 Ó fi ìgboyà rìn ní ọ̀nà OLUWA, ó wó gbogbo pẹpẹ oriṣa, ó sì gé àwọn ère Aṣera káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda.

7 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó pe àwọn marun-un ninu àwọn ìjòyè rẹ̀: Benhaili, Ọbadaya, ati Sakaraya, Netaneli, ati Mikaya, ó rán wọn jáde láti máa kọ́ àwọn eniyan ní ilẹ̀ Juda.

8 Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wọn lọ ni: Ṣemaaya, Netanaya, ati Sebadaya; Asaheli, Ṣemiramotu, ati Jehonatani; Adonija, Tobija ati Tobadonija. Àwọn alufaa tí wọ́n tẹ̀lé wọn ni Eliṣama ati Jehoramu.

9 Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda pẹlu ìwé òfin lọ́wọ́ wọn, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan.

Títóbi Jehoṣafati

10 OLUWA da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí Juda ká, wọn kò sì gbógun ti Jehoṣafati.

11 Àwọn kan ninu àwọn ará Filistia mú ẹ̀bùn ati fadaka wá fún Jehoṣafati gẹ́gẹ́ bíi ìṣákọ́lẹ̀. Àwọn ará Arabia náà sì mú ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) àgbò, ati ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) òbúkọ wá.

12 Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i, ó kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí ní Juda;

13 ó ní ilé tí wọn ń kó nǹkan pamọ́ sí ní àwọn ìlú ńláńlá Juda.

Ó sì ní àwọn akọni ọmọ ogun ní Jerusalẹmu.

14 Iye àwọn ọmọ ogun tí ó kó jọ nìyí gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: Adinai ni olórí ogun ẹ̀yà Juda, ó sì ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) akọni ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀.

15 Olórí ogun tí ó pọwọ́ lé e ni Jehohanani, ó ní ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) ọmọ ogun lábẹ́ rẹ̀.

16 Olórí ogun kẹta ni Amasaya, ọmọ Sikiri, ẹni tí ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ OLUWA, ó ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) akọni ọmọ ogun.

17 Àwọn olórí ogun láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Eliada, akọni ọmọ ogun, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń lo apata ati ọrun ni wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀.

18 Igbákejì ni Jehosabadi; òun náà ní ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun, lábẹ́ rẹ̀.

19 Gbogbo àwọn wọnyi ni wọ́n wà lábẹ́ ọba ní Jerusalẹmu, láìka àwọn tí ó fi sí àwọn ìlú olódi ní gbogbo ilẹ̀ Juda.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 18

Wolii Mikaya Kìlọ̀ fún Ahabu

1 Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda di ọlọ́rọ̀ ati olókìkí, ó fẹ́ ọmọ Ahabu kí ó lè ní àjọṣepọ̀ pẹlu Ahabu.

2 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Jehoṣafati lọ sí ìlú Samaria láti bẹ Ahabu wò. Láti dá Jehoṣafati lọ́lá pẹlu àwọn tí wọ́n bá a wá, Ahabu pa ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù fún àsè. Ó rọ Jehoṣafati láti bá òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi.

3 Ahabu, ọba Israẹli bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé o óo bá mi lọ gbógun ti Ramoti Gileadi?”

Jehoṣafati dáhùn pé, “Tìrẹ ni èmi ati àwọn eniyan mi, a óo bá ọ lọ jagun náà.”

4 Ṣugbọn Jehoṣafati sọ fún ọba Israẹli pé, “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ná.”

5 Nítorí náà, Ahabu pe gbogbo àwọn Wolii jọ, gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400). Ó bi wọ́n pé, “Ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má lọ?”

Wọ́n dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, Ọlọrun yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.”

6 Ṣugbọn Jehoṣafati bèèrè lọ́wọ́ Ahabu pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA mìíràn mọ́ tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

7 Ahabu dáhùn pé, “Ó ku ọ̀kan tí à ń pè ní Mikaya, ọmọ Imila tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ rere kan kò ti ẹnu rẹ̀ jáde sí mi rí, àfi kìkì burúkú.”

Jehoṣafati dáhùn, ó ní, “Má sọ bẹ́ẹ̀.”

8 Nítorí náà, Ahabu ọba pe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó lọ pe Mikaya wá kíákíá.

9 Àwọn ọba mejeeji gúnwà lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà, ní àbáwọ bodè Samaria, gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

10 Ọ̀kan ninu àwọn wolii tí à ń pè ní Sedekaya, ọmọ Kenaana ṣe àwọn ìwo irin kan, ó sì sọ fún Ahabu pé, “OLUWA ní, pẹlu àwọn ìwo wọnyi ni o óo fi bi àwọn ará Siria sẹ́yìn, títí tí o óo fi run wọ́n patapata.”

11 Àwọn wolii yòókù ń sọ bákan náà, wọ́n ń wí pé, “Lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, o óo ṣẹgun. OLUWA yóo fi wọ́n lé ọba lọ́wọ́.”

12 Iranṣẹ tí ó lọ pe Mikaya sọ fún un pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn wolii ń sọ, pé ọba yóo ṣẹgun, ìwọ náà sọ bẹ́ẹ̀.”

13 Ṣugbọn Mikaya dáhùn pé, “Mo fi orúkọ OLUWA búra pé ohun tí Ọlọrun bá sọ fún mi pé kí n sọ ni n óo sọ.”

14 Nígbà tí ó dé iwájú Ahabu, Ahabu bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má ṣe lọ?”

Mikaya dáhùn pé, “Ẹ lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣẹgun.”

15 Ṣugbọn Ahabu bi í pé, “Ìgbà mélòó ni mo níláti mú ọ búra pé kí o máa sọ òtítọ́ fún mi ní orúkọ OLUWA?”

16 Mikaya bá sọ pé, “Mo rí i tí gbogbo ọmọ ogun Israẹli fọ́n káàkiri lórí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA bá sọ pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí. Jẹ́ kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀ ní alaafia.’ ”

17 Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣé o ranti pé mo ti sọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún mi rí? Àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nìkan ni òun máa ń sọ.”

18 Mikaya bá dáhùn pé, “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ! Mo rí OLUWA, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, àwọn ogun ọ̀run sì wà ní apá ọ̀tún ati apá òsì rẹ̀.

19 OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu, ọba Israẹli, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi, kí ó sì kú níbẹ̀.’ Bí àwọn kan tí ń sọ nǹkankan, ni àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn.

20 Nígbà náà ni ẹ̀mí kan jáde, ó sì dúró níwájú OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tan Ahabu jẹ.’ OLUWA bá bèèrè pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o fẹ́ dá?’

21 Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ”

22 Mikaya ní, “OLUWA ni ó mú kí àwọn wolii rẹ wọnyi máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, ṣugbọn àjálù burúkú ni OLUWA ti pinnu pé yóo dé bá ọ.”

23 Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?”

24 Mikaya dáhùn pé, “Ojú rẹ yóo já a ní ọjọ́ náà, nígbà tí o bá lọ sá pamọ́ sí kọ̀rọ̀ yàrá.”

25 Nígbà náà ni Ahabu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n mú Mikaya lọ sọ́dọ̀ Amoni, gomina ìlú ati sọ́dọ̀ Joaṣi, ọmọ ọba, kí wọ́n sì sọ fún wọn pé:

26 Ẹ ju ọkunrin yìí sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì máa fún un ní omi ati burẹdi nìkan títí òun óo fi pada dé ní alaafia.

27 Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára.

Ikú Ahabu

28 Ahabu ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda lọ gbógun ti Ramoti Gileadi.

29 Ahabu sọ fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sógun yìí, n óo yí ara pada. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Ọba Israẹli bá yíra pada, ó lọ sí ojú ogun.

30 Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀gágun tí wọn ń ṣàkóso àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà bíkòṣe ọba Israẹli nìkan.

31 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati, wọ́n rò pé ọba Israẹli ni, wọ́n bá yíjú sí i láti bá a jà. Jehoṣafati bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, OLUWA sì gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.

32 Nígbà tí àwọn ọ̀gágun náà rí i pé kì í ṣe Ahabu, ọba Israẹli, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀.

33 Ṣugbọn ọmọ ogun Siria kan déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí ìgbàyà ati ihamọra rẹ̀ ti pàdé. Ó bá kígbe sí ẹni tí ó ru ihamọra rẹ̀ pé, “Mo ti fara gbọgbẹ́, yipada kí o gbé mi kúrò lójú ogun.”

34 Ogun gbóná ní ọjọ́ náà, Ahabu ọba bá rá pálá dìde dúró, wọ́n fi ọwọ́ mú un ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó kọjú sí ogun Siria. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, ó kú.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 19

Wolii Kan Bá Jehoṣafati Wí

1 Jehoṣafati ọba Juda pada ní alaafia sí ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

2 Ṣugbọn Jehu, aríran, ọmọ Hanani lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ṣé ó dára kí o máa ran eniyan burúkú lọ́wọ́, kí o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra OLUWA? Nítorí èyí, ibinu OLUWA ru sí ọ.

3 Sibẹsibẹ àwọn nǹkankan wà tí o ṣe tí ó dára, o run àwọn ère oriṣa Aṣera ní ilẹ̀ yìí, o sì ti ṣe ọkàn rẹ gírí láti tẹ̀lé Ọlọ́run.”

Jehoṣafati Ṣe Àtúnṣe

4 Jerusalẹmu ni Jehoṣafati ń gbé, ṣugbọn a máa lọ jákèjádò ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli, láti Beeriṣeba títí dé agbègbè olókè Efuraimu, a máa káàkiri láti yí wọn lọ́kàn pada sí OLUWA Ọlọrun baba wọn.

5 Ó yan àwọn adájọ́ ní gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda.

6 Ó kìlọ̀ fún wọn ó ní, “Ẹ ṣọ́ra gan-an, nítorí pé kì í ṣe eniyan ni ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún, OLUWA ni. Ẹ sì ranti pé OLUWA wà lọ́dọ̀ yín bí ẹ ti ń ṣe ìdájọ́.

7 Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì ṣọ́ra pẹlu àwọn nǹkan tí ẹ ó máa ṣe, nítorí pé OLUWA Ọlọrun wa kì í yí ìdájọ́ po, kì í ṣe ojuṣaaju, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

8 Jehoṣafati tún yan àwọn kan ní Jerusalẹmu ninu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn alufaa ati àwọn baálé baálé ní Israẹli, láti máa fi òfin OLUWA ṣe ìdájọ́ ati láti máa yanjú ẹjọ́ tí kò bá di àríyànjiyàn.

9 Ó kìlọ̀ fún wọn, ó ní “Ohun tí ẹ gbọdọ̀ máa fi tọkàntọkàn ṣe, pẹlu ìbẹ̀rù OLUWA ati òtítọ́ nìyí:

10 Nígbàkúùgbà tí àwọn arakunrin yín bá mú ẹjọ́ wá siwaju yín láti ìlú kan, kì báà ṣe ti ìtàjẹ̀sílẹ̀, tabi ti nǹkan tí ó jẹ mọ́ òfin, tabi àṣẹ, tabi ìlànà, ẹ níláti ṣe àlàyé fún wọn kí wọ́n má baà jẹ̀bi níwájú OLUWA, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí ẹ̀yin náà ati àwọn arakunrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ máa ṣe kí ẹ má baà jẹ̀bi.

11 Amaraya, olórí alufaa ni alabojuto yín ninu gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ OLUWA. Sebadaya, ọmọ Iṣimaeli, tí ó jẹ́ gomina ní Juda ni alabojuto lórí ọ̀rọ̀ ìlú, àwọn ọmọ Lefi yóo sì máa ṣe òjíṣẹ́ yín. Ẹ má bẹ̀rù. Kí OLUWA wà pẹlu ẹ̀yin tí ẹ dúró ṣinṣin.”