Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Kronika Keji

bẹ̀rẹ̀ ìtàn rẹ̀ níbi tí

Kronika Kinni

parí tirẹ̀ sí. Ó sọ àwọn ohun tí Ọba Solomoni ṣe lórí oyè títí tí ó fi kú. Ninu ìwé yìí, a ní àkọsílẹ̀ bí Jeroboamu ṣe darí àwọn ẹ̀yà àríwá Israẹli, tí wọ́n ya kúrò lábẹ́ Rehoboamu, tí ó jọba lẹ́yìn Solomoni, baba rẹ̀; lẹ́yìn náà a tún ní àkọsílẹ̀ ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ gúsù Juda, títí di ìgbà tí wọ́n kó Jerusalẹmu nígbèkùn ní ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla, kí á tó bí OLUWA wa (586 B.C.)

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Àkókò ìjọba Solomoni 1:1–9:31

a. Àwọn ọdún tí Solomoni kọ́kọ́ lò lórí oyè 1:1-17

b. Bí wọ́n ṣe kọ́ Tẹmpili parí 2:1–7:10

d. Àwọn ọdún tí Solomoni lò kẹ́yìn lórí oyè 7:11–9:31

Bí àwọn ẹ̀yà ìhà àríwá ṣe ya lọ 10:1-19

Àwọn Ọba Juda 11:1–36:12

Ìṣubú Jerusalẹmu 36:13-23

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 1

Solomoni Ọba Gbadura fún Ọgbọ́n

1 Solomoni, ọmọ Dafidi, fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, OLUWA Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá.

2 Solomoni bá gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀: àwọn balogun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati ti ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, àwọn adájọ́, àwọn olórí ní Israẹli ati àwọn baálé baálé.

3 Solomoni ati àwọn tí wọ́n péjọ lọ sí ibi gíga tí ó wà ní Gibeoni, nítorí pé àgọ́ ìpàdé Ọlọrun tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa ninu aginjù wà níbẹ̀.

4 Ṣugbọn Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá láti Kiriati Jearimu sinu àgọ́ tí ó pa fún un ní Jerusalẹmu.

5 Pẹpẹ bàbà tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri ṣe, wà níbẹ̀ níwájú àgọ́ OLUWA. Solomoni ati àwọn eniyan rẹ̀ sin OLUWA níbẹ̀.

6 Ó lọ sí ìdí pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA ninu àgọ́ àjọ, ó sì fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀.

7 Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun fara han Solomoni, ó wí fún un pé “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n fún ọ.”

8 Solomoni dá Ọlọrun lóhùn, ó ní “O ti fi ìfẹ́ ńlá tí kìí yẹ̀ han Dafidi, baba mi, o sì ti fi mí jọba nípò rẹ̀.

9 OLUWA, Ọlọrun, mú ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ nisinsinyii, nítorí pé o ti fi mí jọba lórí àwọn eniyan tí wọ́n pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.

10 Fún mi ní ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí n óo fi máa ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi, nítorí pé ó ṣòro fún ẹnikẹ́ni láti ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ tó báyìí.”

11 Ọlọrun dá Solomoni lóhùn pé, “Nítorí pé irú èrò yìí ló wà lọ́kàn rẹ, ati pé o kò sì tọrọ nǹkan ìní, tabi ọrọ̀, ọlá, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, o kò tilẹ̀ tọrọ ẹ̀mí gígùn, ṣugbọn ọgbọ́n ati ìmọ̀ ni o tọrọ, láti máa ṣe àkóso àwọn eniyan mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,

12 n óo fún ọ ní ọgbọ́n ati ìmọ̀; n óo sì fún ọ ní ọrọ̀, nǹkan ìní, ati ọlá, irú èyí tí ọba kankan ninu àwọn tí wọ́n ti jẹ ṣiwaju rẹ kò tíì ní rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí èyí tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ tí yóo ní irú rẹ̀.”

Agbára Solomoni ati Ọrọ̀ Rẹ̀

13 Solomoni kúrò ní àgọ́ ìpàdé tí ó wà ní ibi ìrúbọ ní Gibeoni, ó wá sí Jerusalẹmu, ó sì jọba lórí Israẹli.

14 Solomoni kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin jọ; àwọn kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ egbeje (1,400) àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ ẹgbaafa (12,000); ó kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

15 Fadaka ati wúrà tí ọba kójọ, pọ̀ bíi òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bí igi sikamore tí ó wà ní Ṣefela, ní ẹsẹ̀ òkè Juda.

16 Láti Ijipti ati Kue ni Solomoni ti ń kó ẹṣin wá, àwọn oníṣòwò tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún un ni wọ́n ń ra àwọn ẹṣin náà wá láti Kue.

17 Àwọn oníṣòwò a máa ra kẹ̀kẹ́ ogun kan ni ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka wá fún Solomoni láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn náà ni wọ́n sì ń bá a tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati ti ilẹ̀ Siria.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 2

Ìpalẹ̀mọ́ fún Kíkọ́ Tẹmpili

1 Solomoni ọba pinnu láti kọ́ tẹmpili níbi tí àwọn eniyan yóo ti máa sin OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀.

2 Ó kó ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000) àwọn òṣìṣẹ́ jọ láti máa ru àwọn nǹkan tí yóo fi kọ́lé, ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) àwọn òṣìṣẹ́ tí yóo máa fọ́ òkúta, ati ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) eniyan láti máa bojútó àwọn òṣìṣẹ́.

3 Solomoni ranṣẹ sí Huramu, ọba Tire pé, “Máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Dafidi, baba mi, tí o kó igi kedari ranṣẹ sí i láti kọ́ ààfin rẹ̀.

4 Mo fẹ́ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun mi. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ tí a ó ti máa sun turari olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀. A ó máa mú ẹbọ àkàrà ojoojumọ lọ sibẹ, a ó sì máa rú ẹbọ sísun níbẹ̀ láàárọ̀ ati lálẹ́; ati ní ọjọọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣooṣù, ati ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli títí lae.

5 Ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi pupọ, nítorí pé Ọlọrun wa tóbi ju gbogbo oriṣa lọ.

6 Kò sí ẹni tí ó lè kọ́ ilé fún un, nítorí pé ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò le è gbà á. Kí ni mo jẹ́ tí n óo fi kọ́ ilé fún un, bíkòṣe pé kí n kọ́ ibi tí a óo ti máa sun turari níwájú rẹ̀?

7 Nítorí náà, fi ẹnìkan ranṣẹ sí mi, tí ó mọ̀ nípa iṣẹ́ wúrà, fadaka, bàbà, ati irin, ẹni tí ó lè ṣiṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, ati àlàárì, ati aṣọ aláwọ̀ aró, tí ó sì mọ̀ nípa iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Yóo wà pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tí baba mi ti pèsè sílẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu mi ní Juda ati Jerusalẹmu.

8 Kó igi kedari, sipirẹsi ati aligumu ranṣẹ sí mi láti Lẹbanoni. Mo mọ̀ pé àwọn iranṣẹ rẹ mọ̀ bí wọ́n ṣe ń gé igi ní Lẹbanoni, àwọn iranṣẹ mi náà yóo sì wà pẹlu wọn,

9 láti tọ́jú ọpọlọpọ igi, nítorí pé ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi, yóo sì jọjú.

10 N óo gbé ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n kori ọkà tí a ti lọ̀, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n baali, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati ọtí, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati òróró fún àwọn iranṣẹ rẹ tí wọn yóo gé àwọn igi náà, wọn óo gbé wọn wá fún ọ.”

11 Huramu, ọba Tire, bá dá èsì lẹta Solomoni pada, ó ní, “OLUWA fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn.”

12 Ó tún fi kún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó dá ọ̀run ati ayé, tí ó fún Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó sì ní òye ati ìmọ̀ láti kọ́ tẹmpili fún OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀.

13 Mo ti rán Huramu sí ọ; ó mọṣẹ́, ó sì ní làákàyè.

14 Ará Dani ni ìyá rẹ̀, ṣugbọn ará Tire ni baba rẹ̀. Ó mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti bàbà, ati ti irin; ó sì mọ òkúta, ati igi í gbẹ́. Ó mọ bí a tií ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, aṣọ aláwọ̀ aró, àlàárì, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Ó lè ṣe iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, ó sì lè ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tí wọ́n bá ní kí ó ṣe pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tìrẹ, ati àwọn òṣìṣẹ́ oluwa mi, Dafidi, baba rẹ.

15 Nítorí náà, fi ọkà baali, òróró ati ọtí tí ìwọ oluwa mi ti ṣèlérí ranṣẹ sí èmi iranṣẹ rẹ.

16 A óo gé gbogbo igi tí o bá nílò ní Lẹbanoni, a óo sì tù wọ́n lójú omi wá sí Jọpa, láti ibẹ̀ ni ẹ lè wá kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.”

Kíkọ́ Tẹmpili Bẹ̀rẹ̀

17 Solomoni ka gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje, ó lé ẹgbaaje ati ẹgbẹta (153,600).

18 Ó yan ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ninu wọn láti máa ru nǹkan ìkọ́lé, ó ní kí ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) eniyan máa la òkúta, kí ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) jẹ́ alákòóso tí yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 3

1 Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹmpili OLUWA ní Jerusalẹmu, níbi ìpakà Onani, ará Jebusi, lórí òkè Moraya, níbi tí OLUWA ti fi ara han Dafidi, baba rẹ̀; Dafidi ti tọ́jú ibẹ̀ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀.

2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà ní ọjọ́ keji oṣù keji ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.

3 Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọrun tí Solomoni fi lélẹ̀ gùn ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9).

4 Yàrá kan wà ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní ọgọfa igbọnwọ (mita 54), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ déédé ìbú tẹmpili.

5 Ó yọ́ ojúlówó wúrà bo gbogbo inú rẹ̀. Ó fi igi sipirẹsi tẹ́ gbogbo inú gbọ̀ngàn rẹ̀. Ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó lórí, ó ya igi ọ̀pẹ ati ẹ̀wọ̀n, ó fi dárà sórí rẹ̀.

6 Ó fi òkúta olówó iyebíye ṣe iṣẹ́ ọnà sára ilé náà, wúrà tí ó rà wá láti ilẹ̀ Pafaimu ni ó lò.

7 Ó yọ́ wúrà bo gbogbo igi àjà ilé náà patapata, ati àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, ògiri rẹ̀ ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fi àwòrán àwọn kerubu dárà sí ara àwọn ògiri.

8 Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé ìbú tẹmpili náà, ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9). Ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó yọ́ ìwọ̀n ẹgbẹta (600) talẹnti ojúlówó wúrà, ó fi bo gbogbo inú rẹ̀.

9 Aadọta ìwọ̀n ṣekeli wúrà ni ó fi ṣe ìṣó, ó sì yọ́ wúrà bo gbogbo ara ògiri yàrá òkè.

10 Ó fi igi gbẹ́ kerubu meji, ó yọ́ wúrà bò wọ́n, ó sì gbé wọn sí ibi mímọ́ jùlọ.

11 Gígùn gbogbo ìyẹ́ kerubu mejeeji jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni keji jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ìyẹ́ rẹ̀ keji tí òun náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), nà kan ìyẹ́ kerubu keji.

12 Ekinni ninu àwọn ìyẹ́ kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, ó nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji, ìyẹ́ rẹ̀ keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, òun náà nà kan ìyẹ́ ti kerubu kinni.

13 Àwọn kerubu yìí dúró, wọ́n kọjú sí gbọ̀ngàn ilé náà; gígùn gbogbo ìyẹ́ wọn jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9).

14 Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ti àlàárì ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe aṣọ ìbòjú fún ibi mímọ́ jùlọ, ó sì ya àwòrán kerubu sí i lára.

Àwọn Òpó Idẹ Meji

15 Ó ṣe òpó meji sí iwájú ilé náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ga ní igbọnwọ marundinlogoji (mita 15). Ọpọ́n orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ga ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un (mita 2¼).

16 Ó ṣe àwọn nǹkankan bí ẹ̀wọ̀n, ó fi wọ́n sórí àwọn òpó náà. Ó sì ṣe ọgọrun-un (100) èso pomegiranate, ó so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà.

17 Ó gbé àwọn òpó náà kalẹ̀ níwájú tẹmpili, ọ̀kan ní ìhà àríwá, wọ́n ń pè é ní Jakini, ekeji ní ìhà gúsù, wọ́n ń pè é ní Boasi.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 4

Àwọn Ohun Èlò Inú Tẹmpili

1 Solomoni ọba ṣe pẹpẹ idẹ kan tí ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).

2 Ó ṣe agbada omi kan tí ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½), ó sì ga ní igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Àyíká etí rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 13½).

3 Gbogbo ẹ̀yìn agbada yìí ni ó ya àwòrán mààlúù sí ní ìlà meji meji yíká ìsàlẹ̀ etí rẹ̀.

4 Agbada yìí wà lórí ère mààlúù mejila tí wọ́n kọjú síta: mẹta kọjú sí ìhà àríwá, mẹta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹta kọjú sí ìhà gúsù, mẹta yòókù sì kọjú sí ìlà oòrùn.

5 Agbada náà nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ dàbí etí ife omi ati bí òdòdó lílì. Agbada náà gbà tó ẹgbẹẹdogun ìwọ̀n bati omi.

6 Ó ṣe abọ́ ńlá mẹ́wàá, ó gbé marun-un ka ẹ̀gbẹ́ gúsù, ó sì gbé marun-un yòókù ka ẹ̀gbẹ́ àríwá. Àwọn abọ́ wọnyi ni wọ́n fi ń bu omi láti fọ àwọn ohun tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Omi inú agbada náà sì ni àwọn alufaa máa ń lò láti fi wẹ̀.

7 Solomoni ṣe ọ̀pá fìtílà wúrà mẹ́wàá bí àpẹẹrẹ tí wọ́n fún un. Ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá.

8 Ó ṣe tabili mẹ́wàá, ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. Ó sì ṣe ọgọrun-un àwo kòtò wúrà.

9 Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan fún àwọn alufaa, ati òmíràn tí ó tóbi, ó ṣe ìlẹ̀kùn sí wọn, ó sì yọ́ idẹ bo àwọn ìlẹ̀kùn náà.

10 Ó gbé agbada omi kalẹ̀ sí apá gúsù ìhà ìlà oòrùn igun ilé náà.

11 Huramu mọ ìkòkò, ó rọ ọkọ́, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó ṣe sinu ilé Ọlọrun fún Solomoni ọba.

12 Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, àwọn ọpọ́n meji tí wọ́n dàbí abọ́ tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, nǹkankan tí ó dàbí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dárà sára àwọn ọpọ́n tí ó wà lórí òpó náà,

13 àwọn irinwo òdòdó idẹ tí wọ́n fi ṣe ọnà ní ìlà meji meji yí ọpọ́n orí àwọn òpó náà ká.

14 Ó ṣe àwọn abọ́ ńlá ati ìjókòó wọn.

15 Ó ṣe agbada omi kan ati ère mààlúù mejila sí abẹ́ rẹ̀.

16 Ó mọ àwọn ìkòkò, ó rọ ọkọ́ ati àmúga tí wọ́n fi ń mú ẹran, ati gbogbo ohun èlò wọn. Idẹ dídán ni Huramu fi ṣe gbogbo wọn fún Solomoni ọba, fún lílò ninu ilé OLUWA.

17 Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Sereda ni ọba ti ṣe wọ́n.

18 Àwọn nǹkan tí Solomoni ṣe pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí a kò fi mọ ìwọ̀n idẹ tí ó lò.

19 Solomoni ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ilé Ọlọrun: pẹpẹ wúrà, tabili fún burẹdi ìfihàn.

20 Àwọn ọ̀pá ati fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe láti máa jò níwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ.

21 Ó fi wúrà tí ó dára jùlọ ṣe àwọn òdòdó, àwọn fìtílà ati àwọn ẹ̀mú.

22 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 5

1 Nígbà tí Solomoni ọba parí gbogbo iṣẹ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sinu ilé Ọlọrun: àwọn nǹkan bíi fadaka, wúrà, ati gbogbo ohun èlò, ó pa wọ́n mọ́ ninu àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n wà níbẹ̀.

Gbígbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sinu Tẹmpili

2 Lẹ́yìn náà, Solomoni pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, àwọn olórí ẹ̀yà, ati àwọn baálé baálé ní ìdílé Israẹli ati ti Jerusalẹmu, láti gbé àpótí majẹmu OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu tẹmpili.

3 Gbogbo wọn péjọ sọ́dọ̀ ọba ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù keje.

4 Nígbà tí àwọn àgbààgbà péjọ tán, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà.

5 Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà wá pẹlu àgọ́ àjọ, ati gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu àgọ́ àjọ náà.

6 Solomoni ọba ati gbogbo ìjọ Israẹli dúró níwájú àpótí majẹmu, wọ́n ń fi ọpọlọpọ aguntan ati ọpọlọpọ mààlúù tí kò níye rúbọ.

7 Àwọn alufaa gbé àpótí majẹmu OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu tẹmpili ní ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ àwọn ìyẹ́ kerubu.

8 Àwọn kerubu na àwọn ìyẹ́ wọn sórí ibi tí àpótí náà wà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bo àpótí náà ati àwọn òpó rẹ̀.

9 Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

10 Ohun kan ṣoṣo tí ó wà ninu àpótí náà ni tabili meji tí Mose kó sibẹ ní òkè Horebu, níbi tí Ọlọrun ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.

Ògo OLUWA

11 Gbogbo àwọn alufaa jáde wá láti ibi mímọ́, (nítorí gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà níbẹ̀ ti ya ara wọn sí mímọ́ láìbèèrè ìpín tí olukuluku wà.

12 Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin,

13 àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé:

“OLUWA ṣeun,

ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.”

Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA,

14 tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 6

Ọ̀rọ̀ tí Solomoni Bá Àwọn Eniyan Sọ

1 Solomoni ọba ní,

“OLUWA, o ti sọ pé o óo máa gbé inú òkùnkùn biribiri.

2 Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti kọ́ ilé kan tí ó lógo fún ọ,

ibi tí o óo máa gbé títí lae.”

3 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli wà níbẹ̀, ọba bá yíjú pada sí wọn, ó sì gbadura fún wọn.

4 Lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ohun gbogbo tí ó wí fún Dafidi, baba mi, ṣẹ fúnrarẹ̀, nítorí ó wí pé,

5 ‘Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn eniyan jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, n kò tíì yan ìlú kankan ninu ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé sí fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò yan ẹnìkan kan láti jẹ́ olórí àwọn eniyan mi.

6 Ṣugbọn nisinsinyii, mo yan Jerusalẹmu fún ibi ìjọ́sìn ní orúkọ mi, mo sì ti yan Dafidi láti jẹ́ olórí Israẹli, eniyan mi.’ ”

7 Ó wu Dafidi, baba mi, láti kọ́ ilé kan fún ìjọ́sìn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli.

8 Ṣugbọn OLUWA sọ fún baba mi pé nǹkan dáradára ni pé ó wù ú lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún òun Ọlọrun,

9 ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé náà, ọmọ bíbí inú rẹ̀ ni yóo kọ́ ilé fún òun.

10 “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Mo ti wà ní ipò baba mi, mo ti gorí ìtẹ́ ọba Israẹli, bí OLUWA ti ṣèlérí, mo sì ti kọ́ tẹmpili fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

11 Mo ti gbé àpótí ẹ̀rí sibẹ, inú rẹ̀ sì ni majẹmu tí OLUWA bá àwọn eniyan Israẹli dá wà.”

Adura Solomoni

12 Lẹ́yìn náà, Solomoni dúró níwájú pẹpẹ lójú gbogbo eniyan, ó gbé ọwọ́ mejeeji sókè, ó sì gbadura sí Ọlọrun.

13 Solomoni ti ṣe pẹpẹ bàbà kan, ó gbé e sí àgbàlá ilé náà. Gígùn ati ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta (1.3 mita). Solomoni gun orí pẹpẹ yìí, níbi tí gbogbo eniyan ti lè rí i. Ó kúnlẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọrun;

14 ó bá gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run tabi ní ayé, ìwọ tí ò ń pa majẹmu mọ́, tí o sì ń fi ìfẹ́ ńlá han àwọn iranṣẹ rẹ, tí wọn ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé ìlànà rẹ.

15 O ti mú ìlérí rẹ ṣẹ fún baba mi, Dafidi, iranṣẹ rẹ. O fi ẹnu rẹ ṣèlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú ìlérí náà ṣẹ lónìí.

16 Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọn bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣe.

17 Nisinsinyii, jọ̀wọ́ Ọlọrun Israẹli, mú ọ̀rọ̀ rẹ tí o sọ fún Dafidi, iranṣẹ rẹ ṣẹ.

18 “Ṣugbọn ṣé ìwọ Ọlọrun yóo máa bá eniyan gbé lórí ilẹ̀ ayé? Bí ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́, mélòó mélòó ni ilé tí mo kọ́ yìí?

19 Sibẹsibẹ, jọ̀wọ́ fetí sí adura ati ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ. OLUWA Ọlọrun mi, gbọ́ igbe èmi iranṣẹ rẹ, ati adura tí mò ń gbà níwájú rẹ.

20 Máa bojútó ilé yìí tọ̀sán-tòru. O ti sọ pé ibẹ̀ ni àwọn eniyan yóo ti máa jọ́sìn ní orúkọ rẹ. Jọ̀wọ́ máa gbọ́ adura tí èmi iranṣẹ rẹ bá gbà nígbà tí mo bá kọjú sí ilé yìí.

21 Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ, ati ti Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ibí yìí láti gbadura. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa láti ibùgbé rẹ ní ọ̀run, kí o sì dáríjì wá.

22 “Bí ẹnìkan bá ṣẹ aládùúgbò rẹ̀, tí a sì mú un wá kí ó wá búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé yìí,

23 OLUWA, gbọ́ láti ọ̀run, kí o ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá ṣẹ̀ níyà bí ó ti tọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí o dá ẹni tí kò ṣẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.

24 “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn eniyan rẹ lójú ogun nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ ọ́, ṣugbọn bí wọ́n bá ronupiwada, tí wọ́n ranti orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ ninu ilé yìí,

25 jọ̀wọ́ gbọ́ láti ọ̀run, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada sórí ilẹ̀ tí o ti fún àwọn ati àwọn baba wọn.

26 “Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà,

27 jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

28 “Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́,

29 gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí,

30 jọ̀wọ́, gbọ́ láti ilé rẹ ní ọ̀run, dáríjì wọ́n, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ni o mọ ọkàn ọmọ eniyan.

31 Kí àwọn eniyan rẹ lè máa bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa.

32 “Bákan náà, nígbà tí àwọn àjèjì, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, bá ti ọ̀nà jíjìn wá, láti gbadura sí ìhà ilé yìí, nítorí orúkọ ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ńlá, ati agbára rẹ,

33 gbọ́ láti ibùgbé rẹ lọ́run; kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà bá ń tọrọ lọ́dọ̀ rẹ, kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, kí wọ́n lè mọ̀ pé ilé ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, ni ilé tí mo kọ́ yìí.

34 “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ sójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn, láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà, tí wọ́n bá kọjú sí ìhà ìlú tí o ti yàn yìí ati sí ìhà ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ yìí,

35 gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì jà fún wọn.

36 “Bí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í ṣẹ̀), tí inú bá bí ọ sí wọn, tí o sì mú kí àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ọ̀nà jíjìn tabi nítòsí,

37 sibẹ, tí wọ́n bá ranti, tí wọ́n sì ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ tí wọ́n sọ pé, ‘àwọn ti ṣẹ̀, àwọn ti hu ìwà tí kò tọ́, àwọn sì ti ṣe burúkú,’

38 tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ninu ìgbèkùn níbi tí a kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n gbadura sí ìhà ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wọn, ati sí ìlú tí o ti yàn, ati sí ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ,

39 gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, jà fún àwọn eniyan rẹ, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ jì wọ́n.

40 “Nisinsinyii, Ọlọrun mi, bojúwò wá kí o sì tẹ́tí sí adura tí wọ́n bá gbà níhìn-ín.

41 Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, dìde, lọ sí ibùjókòó rẹ, ìwọ ati àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Gbé ìgbàlà rẹ wọ àwọn alufaa rẹ bí ẹ̀wù, kí o sì jẹ́ kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ yọ̀ ninu ire rẹ.

42 Áà! OLUWA Ọlọrun, má ṣe kọ ẹni tí a fi òróró yàn, ranti ìfẹ́ rẹ tí kìí yẹ̀ sí Dafidi, iranṣẹ rẹ.”

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 7

Yíya Tẹmpili sí Mímọ́

1 Nígbà tí Solomoni parí adura rẹ̀, iná kan ṣẹ́ láti ọ̀run, ó jó gbogbo ẹbọ sísun ati ọrẹ, ògo OLUWA sì kún inú tẹmpili.

2 Àwọn alufaa kò sì lè wọ inú tẹmpili lọ mọ́ nítorí ògo OLUWA ti kún ibẹ̀.

3 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí i bí iná ati ògo OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí tẹmpili, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun, wọ́n fi ọpẹ́ fún un, “Nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé àánú rẹ̀ wà títí lae.”

4 Lẹ́yìn náà, ọba ati gbogbo àwọn eniyan rúbọ sí OLUWA.

5 Solomoni ọba fi ẹgbaa mọkanla (22,000) mààlúù ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rúbọ. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn eniyan náà ṣe ya ilé Ọlọrun sí mímọ́.

6 Àwọn alufaa dúró ní ipò wọn, àwọn ọmọ Lefi náà dúró láti kọrin sí OLUWA pẹlu ohun èlò orin tí Dafidi ṣe ati ìlànà tí ó fi lélẹ̀ láti máa fi kọrin ọpẹ́ sí OLUWA pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ wà títí lae;” ní gbogbo ìgbà tí Dafidi bá lò wọ́n láti kọrin ìyìn. Àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè gbogbo eniyan yóo sì dìde dúró.

7 Solomoni ya gbọ̀ngàn ààrin tí ó wà níwájú ilé OLUWA sí mímọ́, nítorí pé ibẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun tí ó sì sun ọ̀rá ẹran fún ẹbọ alaafia, nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó ṣe kò lè gba gbogbo ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ọ̀rá.

8 Solomoni ṣe àjọyọ̀ yìí fún ọjọ́ meje gbáko, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wà pẹlu rẹ̀, eniyan pọ̀ lọ bí eṣú, láti ẹnu bodè Hamati títí dé odò Ijipti.

9 Wọ́n fi ọjọ́ meje ṣe ìyàsímímọ́ pẹpẹ, wọ́n sì fi ọjọ́ meje ṣe àjọyọ̀. Ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n pe àpéjọ mímọ́.

10 Ní ọjọ́ kẹtalelogun oṣù keje, Solomoni ní kí àwọn eniyan máa pada lọ sílé wọn. Inú wọn dùn nítorí ohun rere tí OLUWA ṣe fún Dafidi, ati Solomoni ati gbogbo Israẹli.

Ọlọrun Tún Farahan Solomoni

11 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sí ilé OLUWA ati sí ilé ti ara rẹ̀, ni ó ṣe ní àṣeyọrí.

12 Lẹ́yìn náà, OLUWA fara han Solomoni lóru, ó ní, “Mo ti gbọ́ adura rẹ, mo sì ti yan ibí yìí ní ilé ìrúbọ fúnra mi.

13 Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi,

14 bí àwọn eniyan mi, tí à ń fi orúkọ mi pè, bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì wá ojurere mi, tí wọ́n bá yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú wọnyi; n óo gbọ́ láti ọ̀run, n óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n óo sì wo ilẹ̀ wọn sàn.

15 Nisinsinyii, n óo fojú sílẹ̀, etí mi yóo sì ṣí sí adura tí wọ́n bá gbà níbí yìí.

16 Mo ti yan ibí yìí, mo sì ti yà á sí mímọ́, kí á lè máa jọ́sìn ní orúkọ mi níbẹ̀ títí lae. Ojú ati ọkàn mi yóo wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.

17 Ṣugbọn, bí ìwọ bá tẹ̀lé ìlànà mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o tẹ̀lé ìlànà ati àṣẹ mi,

18 n óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀, bí mo ti bá Dafidi, baba rẹ, dá majẹmu pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli.

19 Ṣugbọn tí o bá yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí o kọ àṣẹ mi ati òfin tí mo ṣe fún ọ sílẹ̀, tí o sì ń lọ bọ oriṣa, tí ò ń foríbalẹ̀ fún wọn,

20 n óo fà yín tu kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fun yín bí ẹni fa igi tu. N óo sì kọ tẹmpili yìí, tí mo ti yà sí mímọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi sílẹ̀, nítorí pé yóo di ohun ẹ̀gàn ati àmúpòwe láàrin gbogbo eniyan.

21 “Tẹmpili yìí gbayì gidigidi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà náà, àwọn ẹni tó bá ń rékọjá lọ yóo máa sọ tìyanu-tìyanu pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati sí tẹmpili yìí?’

22 Àwọn eniyan yóo dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n ń lọ bọ oriṣa, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí ibi yìí fi bá wọn.’ ”

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 8

Àwọn Àsẹyọrí Solomoni

1 Ó gba Solomoni ní ogún ọdún láti kọ́ tẹmpili OLUWA ati ààfin tirẹ̀.

2 Lẹ́yìn náà, ó tún àwọn ìlú tí Huramu ọba, fún un kọ́, ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli sibẹ.

3 Ó lọ gbógun ti ìlú Hamati ati Soba, ó sì ṣẹgun wọn.

4 Ó kọ́ ìlú Tadimori ní aṣálẹ̀, ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra jọ sí ní Hamati.

5 Ó kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati Beti Horoni ti ìsàlẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìlú olódi, wọ́n ní ìlẹ̀kùn ati ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn,

6 bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Baalati ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ wà, ati ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin, ati gbogbo ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ati ní Lẹbanoni, ati ní gbogbo ibi tí ìjọba rẹ̀ dé.

7 Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ilẹ̀ náà lára àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, tí wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli,

8 gbogbo ìran àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun, ni Solomoni ń fi tipátipá kó ṣiṣẹ́ títí di òní olónìí.

9 Ṣugbọn kò fi ipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bí ẹrú, ṣugbọn ó ń lò wọ́n bíi jagunjagun, òṣìṣẹ́ ìjọba, balogun kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

10 Àwọn olórí lára àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni jẹ́ igba ati aadọta (250), àwọn ni wọ́n ń ṣe àkóso àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́.

11 Solomoni mú iyawo rẹ̀, ọmọ Farao kúrò ní ìlú Dafidi, lọ sí ibi tí ó kọ́ fún un. Ó ní, “Iyawo mi kò gbọdọ̀ máa gbé ààfin Dafidi, ọba Israẹli; nítorí pé ibikíbi tí àpótí OLUWA bá ti wọ̀, ó ti di ibi mímọ́.”

12 Solomoni rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ OLUWA tí ó kọ́ siwaju yàrá àbáwọlé ní tẹmpili.

13 Ó ń rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose ti fi lélẹ̀, lojoojumọ, ati ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun ati àwọn àjọ̀dún mẹta pataki tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe lọdọọdun: àjọ àìwúkàrà, àjọ ìkórè ati àjọ ìpàgọ́.

14 Gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀, Solomoni pín àwọn alufaa sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, ó sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa kọ orin ìyìn ati láti máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn alufaa ninu iṣẹ́ wọn ojoojumọ. Ó yan àwọn aṣọ́nà sí oríṣìíríṣìí ẹnu ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí Dafidi eniyan Ọlọrun ti pa á láṣẹ.

15 Wọn kò sì yapa kúrò ninu ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀ fún àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi nípa àwọn ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe, ati nípa ilé ìṣúra.

16 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe láti ìgbà tí ó ti fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀ títí di ìgbà tí ó parí iṣẹ́ náà patapata.

17 Solomoni lọ sí Esiongeberi ati Elati ní etí òkun ní ilẹ̀ Edomu.

18 Huramu fi àwọn ọkọ̀ ojú omi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ranṣẹ, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ofiri pẹlu àwọn iranṣẹ Solomoni, wọ́n sì kó ojilenirinwo ati mẹ́wàá (450) ìwọ̀n talẹnti wúrà wá fún Solomoni ọba.

Categories
KRONIKA KEJI

KRONIKA KEJI 9

Ìbẹ̀wò Ọbabinrin Ṣeba sí Solomoni

1 Nígbà tí ọbabinrin ìlú Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti wá dán an wò pẹlu àwọn ìbéèrè tó le. Ó wá ninu ọlá ńlá rẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni wọ́n tẹ̀lé e lẹ́yìn, pẹlu àwọn ràkúnmí tí wọ́n ru oríṣìírìṣìí turari olóòórùn dídùn, ati ọpọlọpọ wúrà ati òkúta olówó iyebíye. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un.

2 Solomoni dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ẹyọ kan tí ó rú Solomoni lójú, tí kò dáhùn pẹlu àlàyé.

3 Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí ọgbọ́n Solomoni ti jinlẹ̀ tó, ati ààfin tí ó kọ́,

4 oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀ ati bí àwọn ìjòyè rẹ̀ ti jókòó, àwọn iranṣẹ rẹ̀, ìwọṣọ ati ìṣesí wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ní ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ.

5 Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Kò sí irọ́ ninu gbogbo ohun tí mo ti gbọ́ nípa rẹ ati nípa ọgbọ́n rẹ.

6 N kò gba ohun tí wọ́n sọ fún mi gbọ́ títí tí mo fi dé ìhín, tí èmi gan-an sì fi ojú ara mi rí i. Ohun tí wọ́n sọ fún mi kò tó ìdajì ọgbọ́n rẹ, ohun tí mo rí yìí pọ̀ ju ohun tí wọ́n sọ fún mi lọ.

7 Àwọn iyawo rẹ ṣoríire. Àwọn òṣìṣẹ́ rẹ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ náà ṣoríire.

8 Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó gbé ọ gorí oyè láti jọba ní orúkọ rẹ̀. Ó ní ìfẹ́ sí Israẹli, ó fẹ́ fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae; nítorí náà, ó fi ọ́ jọba lórí wọn, láti máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo.”

9 Ó fún ọba ní àwọn ẹ̀bùn wọnyi tí ó mú wá: ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn ati ohun ọ̀ṣọ́ òkúta olówó iyebíye. Kò tún sí irú turari tí ọbabinrin yìí mú wá fún Solomoni ọba mọ́.

10 Àwọn iranṣẹ Huramu ati àwọn iranṣẹ Solomoni tí wọ́n mú wúrà wá láti Ofiri, tún mú igi aligumu ati àwọn òkúta olówó iyebíye wá pẹlu.

11 Igi aligumu yìí ni ọba fi ṣe àtẹ̀gùn láti máa gòkè ati láti máa sọ̀kalẹ̀ ninu tẹmpili OLUWA ati ninu ààfin ọba. Ó tún fi ṣe dùùrù ati hapu fún àwọn akọrin. Kò sí irú wọn rí ní gbogbo ilẹ̀ Juda.

12 Solomoni ọba fún ọbabinrin náà ní gbogbo ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ẹ̀bùn tí ó fún un ju èyí tí òun alára mú wá lọ. Lẹ́yìn náà ọbabinrin náà pada lọ sí ìlú rẹ̀.

Ọrọ̀ Solomoni Ọba

13 Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń rí ní ọdọọdún jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó lé mẹfa (666) talẹnti (kilogiramu 23,000),

14 láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ati àwọn ọlọ́jà ń mú wá. Àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina àwọn agbègbè ìjọba rẹ̀ náà a máa mú wúrà ati fadaka wá fún un.

15 Solomoni fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe igba (200) apata ńláńlá. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ṣekeli.

16 Ó tún fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe ọọdunrun (300) apata kéékèèké. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọọdunrun (300) ṣekeli. Ọba kó wọn sí ààfin Igbó Lẹbanoni.

17 Ọba fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì yọ́ ojúlówó wúrà bò ó.

18 Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn kan tí ó ní ìṣísẹ̀ mẹfa ati àpótí ìtìsẹ̀ kan tí a fi wúrà ṣe, tí a kàn mọ́ ìtẹ́. Igbọwọle wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìtẹ́ náà, tí ère kinniun meji wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn.

19 Wọ́n ṣe ère kinniun mejila sí ẹ̀gbẹ́ àtẹ̀gùn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìṣísẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Kò sí irú rẹ̀ rí ní ìjọba kankan.

20 Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife Solomoni, ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Igbó Lẹbanoni. Fadaka kò jámọ́ nǹkankan ní àkókò ìjọba Solomoni.

21 Nítorí pé, ọba ní àwọn ọkọ̀ ojú omi tí àwọn iranṣẹ Huramu máa ń gbé lọ sí Taṣiṣi. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹta ni àwọn ọkọ̀ náà máa ń dé; wọn á máa kó wúrà, fadaka, eyín erin, ati oríṣìíríṣìí àwọn ọ̀bọ ati ẹyẹ ọ̀kín wá sílé.

22 Solomoni ọba ní ọrọ̀ ati ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba yòókù lọ lórí ilẹ̀ ayé.

23 Gbogbo wọn ni wọ́n ń wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un. Fún ọpọlọpọ ọdún ni

24 ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn máa ń mú ẹ̀bùn wá fún un lọdọọdun, àwọn ẹ̀bùn bíi: ohun èlò fadaka, ati ti wúrà, aṣọ, ohun ìjà ogun, turari, ẹṣin, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

25 Solomoni ọba ní ẹgbaaji (4,000) ilé fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, ó ní ẹgbaafa (12,000) ẹlẹ́ṣin. Ó kó àwọn kan sí àwọn ìlú tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ó kó ìyókù sí Jerusalẹmu, níbi tí ọba ń gbé.

26 Solomoni jọba lórí àwọn ọba gbogbo, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati títí dé ààlà Ijipti.

27 Ní àkókò tirẹ̀, ó mú kí fadaka pọ̀ bí òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bíi igi sikamore tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè Juda.

28 A máa ra ẹṣin wá láti Ijipti ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.

Ìjọba Solomoni Ní Ṣókí

29 Gbogbo ìtàn ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn wolii Natani, ati ninu ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Ahija ará Ṣilo, ati ninu ìwé ìran tí Ido rí nípa Jeroboamu ọba Israẹli, ọmọ Nebati.

30 Solomoni jọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli fún ogoji ọdún.

31 Ó kú, a sì sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀. Rehoboamu, ọmọ rẹ̀, ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀.