Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 10

Ìkìlọ̀ Nípa Ìbọ̀rìṣà

1 Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá.

2 Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìrìbọmi ninu ìkùukùu ati ninu òkun, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Mose.

3 Gbogbo wọn ni wọ́n jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà.

4 Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi.

5 Ṣugbọn sibẹ inú Ọlọrun kò dùn sí ọpọlọpọ ninu wọn, nítorí ọpọlọpọ wọn ni wọ́n kú dànù káàkiri ninu aṣálẹ̀.

6 Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, pé kí á má ṣe kó nǹkan burúkú lé ọkàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti kó o lé ọkàn.

7 Kí ẹ má sì di abọ̀rìṣà bí àwọn mìíràn ninu wọn. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn eniyan náà jókòó láti jẹ ati láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣe àríyá.”

8 Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè bí àwọn mìíràn ninu wọn ti ṣe àgbèrè, tí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹẹdogun (23,000) eniyan fi kú ní ọjọ́ kan.

9 Bẹ́ẹ̀ ni kí á má ṣe dán Oluwa wò, bí àwọn mìíràn ninu wọn ti dán an wò, tí ejò fi ṣán wọn pa.

10 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n.

11 Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. A kọ wọ́n sílẹ̀ kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, àwa tí a wà ní ìgbà ìkẹyìn.

12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kí ó ṣọ́ra kí ó má baà ṣubú.

13 Kò sí ìdánwò kan tí ó dé ba yín bíkòṣe irú èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrin eniyan. Ṣugbọn Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé, kò ní jẹ́ kí ẹ rí ìdánwò tí ó ju èyí tí ẹ lè fara dà lọ. Ṣugbọn ní àkókò ìdánwò, yóo pèsè ọ̀nà àbáyọ, yóo sì mú kí ẹ lè fara dà á.

14 Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.

15 Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n. Ẹ̀yin fúnra yín náà, ẹ gba ohun tí mò ń sọ rò.

16 Ife ibukun tí à ń dúpẹ́ fún, ṣebí àjọpín ninu ẹ̀jẹ̀ Kristi ni. Burẹdi tí a bù, ṣebí àjọpín ninu ara Kristi ni.

17 Nítorí burẹdi kan ni ó wà, ninu ara kan yìí ni gbogbo wa sì wà, nítorí ninu burẹdi kan ni gbogbo wa ti ń jẹ.

18 Ẹ ṣe akiyesi ìṣe àwọn ọmọ Israẹli. Ṣebí àwọn tí ń jẹ ẹbọ ń jẹ ninu anfaani lílo pẹpẹ ìrúbọ fún ìsìn Ọlọrun?

19 Nítorí náà, ṣé ohun tí mò ń sọ ni pé ohun tí a fi rúbọ fún oriṣa jẹ́ nǹkan? Tabi pé oriṣa jẹ́ nǹkan?

20 Rárá o! Ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn abọ̀rìṣà fi ń rúbọ, ẹ̀mí burúkú ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọrun. N kò fẹ́ kí ẹ ní ìdàpọ̀ pẹlu àwọn ẹ̀mí burúkú.

21 Ẹ kò lè mu ninu ife Oluwa tán kí ẹ tún lọ mu ninu ife ti ẹ̀mí burúkú. Ẹ kò lè jẹ ninu oúnjẹ orí tabili Oluwa, kí ẹ tún lọ jẹ ninu oúnjẹ orí tabili ẹ̀mí burúkú.

22 Àbí a fẹ́ mú Oluwa jowú ni bí? Àbí a lágbára jù ú lọ ni?

Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun

23 Lóòótọ́, “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan ni ó ń ṣe eniyan ní anfaani. “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe.” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí a lè ṣe ni ó ń mú ìdàgbà wá.

24 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe máa wá ire ti ara rẹ̀ bíkòṣe ire ẹnìkejì rẹ̀.

25 Kí ẹ jẹ ohunkohun tí ẹ bá rà ní ọjà láì wádìí ohunkohun kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́;

26 “Nítorí Oluwa ni ó ni ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”

27 Bí ẹnìkan ninu àwọn alaigbagbọ bá pè yín wá jẹun, tí ẹ bá gbà láti lọ, ẹ jẹ ohunkohun tí ó bá gbé kalẹ̀ níwájú yín láì wádìí ohunkohun, kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́.

28 Ṣugbọn bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, “A ti fi oúnjẹ yìí ṣe ìrúbọ,” ẹ má jẹ ẹ́, nítorí ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ati nítorí ẹ̀rí-ọkàn.

29 Kì í ṣe ẹ̀rí-ọkàn tiyín ni mò ń sọ bíkòṣe ẹ̀rí-ọkàn ti ẹni tí ó pe akiyesi yín sí oúnjẹ náà.

Kí ló dé tí yóo fi jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ni yóo máa sọ bí n óo ti ṣe lo òmìníra mi?

30 Bí mo bá jẹ oúnjẹ pẹlu ọpẹ́ sí Ọlọrun, ẹ̀tọ́ wo ni ẹnìkan níláti bá mi wí fún ohun tí mo ti dúpẹ́ fún?

31 Nítorí náà, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń jẹ ni, tabi pé ẹ̀ ń mu ni, ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ máa ṣe é fún ògo Ọlọrun.

32 Ẹ má ṣe jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún àwọn Juu tabi fún àwọn tí kì í ṣe Juu tabi fún ìjọ Ọlọrun.

33 Ní tèmi, mò ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó wu gbogbo eniyan ní gbogbo ọ̀nà. Kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani tèmi ni mò ń wá, bíkòṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani ọpọlọpọ eniyan, kí á lè gbà wọ́n là.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 11

1 Ẹ máa fara wé mi bí èmi náà tí ń fara wé Kristi.

Obinrin Níláti Bo Orí ninu Ìsìn

2 Mo yìn yín nítorí pé ẹ̀ ń ranti mi nígbà gbogbo, ati pé ẹ kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ tí mo fi kọ yín látijọ́ bọ́ lọ́wọ́ yín.

3 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Kristi ni orí fún olukuluku ọkunrin, ọkunrin ni orí fún obinrin, Ọlọrun wá ni orí Kristi.

4 Ọkunrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu tí ó bo orí fi àbùkù kan orí rẹ̀.

5 Ṣugbọn obinrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu láì bo orí rẹ̀ fi àbùkù kan orí rẹ̀. Ó dàbí kí ó kúkú fá orí rẹ̀.

6 Nítorí bí obinrin kò bá bo orí, kí ó kúkú gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ ìtìjú fún obinrin láti gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀ tabi láti fá orí rẹ̀ a jẹ́ pé ó níláti bo orí rẹ̀.

7 Nítorí kò tọ́ kí ọkunrin bo orí rẹ̀, nítorí àwòrán ati ògo Ọlọrun ni. Ṣugbọn ògo ọkunrin ni obinrin.

8 Nítorí ọkunrin kò wá láti ara obinrin; obinrin ni ó wá láti ara ọkunrin.

9 Ati pé a kò dá ọkunrin nítorí obinrin, obinrin ni a dá nítorí ọkunrin.

10 Nítorí èyí, ó yẹ kí obinrin ní àmì àṣẹ ní orí nítorí àwọn angẹli.

11 Ṣugbọn ṣá, ninu Oluwa, bí obinrin ti nílò ọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin nílò obinrin.

12 Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ara ọkunrin ni obinrin ti wá, láti inú obinrin ni ọkunrin náà sì ti wá. Ṣugbọn ohun gbogbo ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá.

13 Ẹ̀yin náà ẹ ro ọ̀rọ̀ ọ̀hún wò láàrin ara yín. Ǹjẹ́ ó bójú mu pé kí obinrin gbadura sí Ọlọrun láì bo orí?

14 Mo ṣebí ìṣe ẹ̀dá pàápàá kọ yín pé tí ọkunrin bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn, ó fi àbùkù kan ara rẹ̀;

15 bẹ́ẹ̀ sì ni pé ohun ìyìn ni ó jẹ́ fún obinrin tí ó bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn. Nítorí a fi irun gígùn fún obinrin láti bò ó lórí.

16 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ mọ̀ pé ní tiwa, a kò ní oríṣìí àṣà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ninu àwọn ìjọ Ọlọrun.

Ìwà Tí Kò Dára Nípa Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

17 Nígbà tí mò ń sọ èyí, nǹkankan wà tí n kò yìn yín fún, nítorí nígbà tí ẹ bá péjọ, ìpéjọpọ̀ yín ń ṣe ibi ju rere lọ.

18 Nítorí, ní ọ̀nà kinni, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìyapa a máa wà láàrin yín. Mo gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà ninu ìròyìn yìí.

19 Nítorí ìyapa níláti wà láàrin yín, kí àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́ láàrin yín lè farahàn.

20 Nítorí èyí, nígbà tí ẹ bá péjọ sí ibìkan náà, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni ẹ̀ ń jẹ.

21 Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó!

22 Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí.

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

23 Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi,

24 lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”

25 Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”

26 Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé.

Jíjẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa Láìyẹ

27 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jẹ burẹdi, tabi tí ó ń mu ninu ife Oluwa láìyẹ jẹ̀bi ìlòkulò ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa.

28 Kí olukuluku yẹ ara rẹ̀ wò kí ó tó jẹ ninu burẹdi, kí ó sì tó mu ninu ife Oluwa.

29 Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó ń mu láìmọ ìyàtọ̀ tí ó wà ninu ara Kristi, ìdájọ́ ni ó ń jẹ, tí ó sì ń mu, lórí ara rẹ̀.

30 Nítorí èyí ni ọpọlọpọ ninu yín ṣe di aláìlera ati ọlọ́kùnrùn, tí ọpọlọpọ tilẹ̀ ti kú.

31 Ṣugbọn tí a bá ti yẹ ara wa wò, a kò ní dá wa lẹ́jọ́.

32 Ṣugbọn bí a bá bọ́ sinu ìdájọ́ Oluwa, ó fi ń bá wa wí ni, kí ó má baà dá wa lẹ́bi pẹlu àwọn yòókù.

33 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá péjọ láti jẹun, ẹ máa dúró de ara yín.

34 Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun kí ó tó kúrò ní ilé, kí ìpéjọpọ̀ yín má baà jẹ́ ìdálẹ́bi fun yín. Nígbà tí mo bá dé, n óo ṣe ètò nípa àwọn nǹkan tí ó kù.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 12

Àwọn Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

1 Ẹ̀yin ará, n kò fẹ́ kí nǹkan nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣókùnkùn si yín.

2 Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ jẹ́ aláìmọ Ọlọrun, ẹ̀ ń bọ oriṣa tí kò lè fọhùn. À ń tì yín síwá sẹ́yìn.

3 Nítorí náà, mò ń fi ye yín pé kò sí ẹni tí ó lè máa fi agbára Ẹ̀mí Ọlọrun sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ fi Jesu gégùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè wí pé, “Jesu ni Oluwa,” láìjẹ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ bá darí rẹ̀.

4 Oríṣìíríṣìí ni ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà ni wọ́n ti ń wá.

5 Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ iranṣẹ ni ó wà, ṣugbọn Oluwa kan náà ni à ń sìn.

6 Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà, ṣugbọn Ọlọrun kan náà ní ń ṣe ohun gbogbo ninu gbogbo eniyan.

7 Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ń farahàn ninu olukuluku wa fún ire gbogbo wa.

8 Nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ti fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, a sì fún ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà.

9 Ẹlòmíràn ní igbagbọ, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà;

10 ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àtiṣe iṣẹ́ ìyanu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn iwaasu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí èké, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti túmọ̀ àwọn èdè àjèjì.

11 Ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni gbogbo ẹ̀bùn wọnyi ti wá; bí ó sì ti wù ú ni ó pín wọn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

Gbogbo Ìjọ Jẹ́ Ẹ̀yà Ara Kan

12 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan, tí ó ní ọpọlọpọ ẹ̀yà, bí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ti pọ̀ tó, sibẹ tí ara jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni Kristi rí.

13 Nítorí nípa Ẹ̀mí kan ni gbogbo wa fi ṣe ìrìbọmi tí a fi di ara kan, ìbáà ṣe pé a jẹ́ Juu tabi Giriki, à báà jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ninu Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni a ti fún gbogbo wa mu.

14 Nítorí kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo ni ara ní; wọ́n pọ̀.

15 Bí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ọwọ́, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” èyí kò wí pé kì í tún ṣe ẹ̀yà ara mọ́.

16 Bí etí bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ojú, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” kò wí pé kí ó má ṣe ẹ̀yà ara mọ́.

17 Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, báwo ni yóo ti ṣe gbọ́ràn? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, báwo ni yóo ti ṣe gbóòórùn?

18 Ṣugbọn lóòótọ́ ni, Ọlọrun fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú.

19 Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yà kan ṣoṣo ni gbogbo ara ní, níbo ni ara ìbá wà?

20 Bí ó ti wà yìí, ẹ̀yà pupọ ni ó ní, ṣugbọn ara kan ṣoṣo ni.

21 Ojú kò lè wí fún ọwọ́ pé, “N kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè wí fún ẹsẹ̀ pé, “N kò nílò yín.”

22 Kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara tí kò lágbára jẹ́ àwọn tí a kò lè ṣe aláìní.

23 Àwọn ẹ̀yà mìíràn tí a rò pé wọn kò dùn ún wò ni à ń dá lọ́lá jù. Àwọn ẹ̀yà ara tí kò dùn ún wò ni à ń yẹ́ sí jùlọ.

24 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀yà ara tí ó dùn ún wò kò nílò ọ̀ṣọ́ lọ títí. Ọlọrun ti ṣe ètò àwọn ẹ̀yà ara ní ọ̀nà tí ó fi fi ọlá fún àwọn ẹ̀yà tí kò dùn ún wò,

25 kí ó má baà sí ìyapa ninu ara, ṣugbọn kí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣe aájò kan náà fún ara wọn.

26 Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jẹ ìrora, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù níí máa bá a jẹ ìrora. Bí ara bá tu ẹ̀yà kan, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù ni yóo máa bá a yọ̀.

27 Ẹ̀yin ni ara Kristi, ẹ̀yà ara rẹ̀ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yín.

28 Oríṣìíríṣìí eniyan ni Ọlọrun yàn ninu ìjọ: àwọn kinni ni àwọn aposteli, àwọn keji, àwọn wolii; àwọn kẹta, àwọn olùkọ́ni; lẹ́yìn náà, àwọn oníṣẹ́ ìyanu, kí ó tó wá kan àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn tabi àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, tabi àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti darí ètò iṣẹ́ ìjọ, ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti sọ èdè àjèjì.

29 Gbogbo yín ni aposteli bí? Àbí gbogbo yín ni wolii? Ṣé gbogbo yín ni olùkọ́ni? Àbí gbogbo yín ni ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìyanu?

30 Kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ ní ẹ̀bùn kí á ṣe ìwòsàn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ lè sọ èdè àjèjì. Àbí gbogbo yín ni ẹ lè túmọ̀ àwọn èdè àjèjì?

31 Ẹ máa fi ìtara lépa àwọn ẹ̀bùn tí ó ga jùlọ.

Ṣugbọn n óo fi ọ̀nà kan tí ó dára jùlọ hàn yín.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 13

Ìfẹ́

1 Ǹ báà lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí eniyan ń fọ̀, kódà kí n tún lè sọ ti àwọn angẹli, bí n kò bá ní ìfẹ́, bí idẹ tí ń dún lásán ni mo rí; mo dàbí páànù tí wọn ń lù, tí ń hanni létí bí agogo.

2 Ǹ báà ní ẹ̀bùn wolii, kí n ní gbogbo ìmọ̀, kí n mọ gbogbo àṣírí ayé, kí n ní igbagbọ tí ó gbóná tóbẹ́ẹ̀ tí ó lè ṣí òkè ní ìdí, tí n kò bá ní ìfẹ́, n kò já mọ́ nǹkankan.

3 Ǹ báà kò gbogbo ohun tí mo ní, kí n fi tọrẹ, kódà kí n fi ara mi rú ẹbọ sísun, bí n kò bá ní ìfẹ́, kò ṣe anfaani kankan fún mi.

4 Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, a máa ṣe oore. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kì í fọ́nnu.

5 Ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í hùwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan. Kì í tètè bínú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn.

6 Ìfẹ́ kì í fi nǹkan burúkú ṣe ayọ̀, ṣugbọn a máa yọ̀ ninu òtítọ́.

7 Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa ní ìrètí ninu ohun gbogbo, a sì máa foríti ohun gbogbo.

8 Ìfẹ́ kò lópin. Ní ti ọ̀rọ̀ wolii, wọn yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Ní ti àwọn èdè àjèjì wọn yóo di ohun tí a kò gbúròó mọ́. Ní ti ìmọ̀, yóo di ohun tí kò wúlò mọ́.

9 Kò sí ẹni tí ó mọ ọ̀ràn ní àmọ̀tán, bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii tí ó ríran, ní àrítán.

10 Ṣugbọn nígbà tí ohun tí ó pé bá dé, àwọn ohun tí kò pé yóo di ohun tí kò wúlò mọ́.

11 Nígbà tí mo wà ní ọmọde, èmi a máa sọ̀rọ̀ bí ọmọde, èmi a máa gbèrò bí ọmọde, ṣugbọn nisinsinyii tí mo ti dàgbà, mo ti pa ìwà ọmọde tì.

12 Nítorí nisinsinyii, à ń ríran bàìbàì ninu dígí. Ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ojú yóo kojú, a óo sì ríran kedere. Nisinsinyii, kò sí ohunkohun tí mo mọ̀ ní àmọ̀tán. Ṣugbọn nígbà náà, n óo ní ìmọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti mọ̀ mí.

13 Ní gbolohun kan, àwọn nǹkan mẹta ni ó wà títí lae; igbagbọ, ìrètí, ati ìfẹ́; ṣugbọn èyí tí ó tóbi jù ninu wọn ni ìfẹ́.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 14

Ẹ̀bùn Èdè Àjèjì ati Ti Ìsọtẹ́lẹ̀

1 Ẹ máa lépa ìfẹ́. Ṣugbọn ẹ tún máa tiraka láti ní Ẹ̀mí Mímọ́, pàápàá jùlọ, ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀.

2 Nítorí ẹni tí ó bá ń fi èdè sọ̀rọ̀ kò bá eniyan sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Nítorí pé kò sí ẹni tí ó gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Ẹ̀mí ni ó gbé e tí ó fi ń sọ ohun àṣírí tí ó ń sọ tí kò yé eniyan.

3 Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń bá eniyan sọ̀rọ̀ fún ìdàgbà ti ẹ̀mí, fún ìtùnú, ati ìwúrí.

4 Ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ara rẹ̀ nìkan ni ó ń mú dàgbà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń mú ìjọ dàgbà.

5 Inú mi ìbá dún bí gbogbo yín bá lè máa fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ohun tí ìbá dùn mọ́ mi ninu jùlọ ni pé kí ẹ lè máa waasu. Ẹni tí ó ń waasu ju ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ lọ, àfi bí ó bá túmọ̀ ohun tí ó fi èdè àjèjì sọ, kí ìjọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ fún ìdàgbà ẹ̀mí.

6 Ará, ǹjẹ́ bí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, tí mò ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, anfaani wo ni mo ṣe fun yín? Kò sí, àfi bí mo bá ṣe àlàyé nípa ìfihàn, tabi ìmọ̀, tabi iwaasu, tabi ẹ̀kọ́ tí mo fi èdè àjèjì sọ.

7 Bí àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí à ń fi kọ orin, bíi fèrè tabi dùùrù, kò bá dún dáradára, ta ni yóo mọ ohùn orin tí wọn ń kọ?

8 Bí ohun tí fèrè ogun bá ń wí kò bá yé eniyan, ta ni yóo palẹ̀ mọ́ fún ogun?

9 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni tí ẹ bá ń lo èdè àjèjì, tí ẹ kò lo ọ̀rọ̀ tí ó yé eniyan, báwo ni eniyan yóo ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Afẹ́fẹ́ lásán ni ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ sí.

10 Láìsí àní-àní, oríṣìíríṣìí èdè ni ó wà láyé, ṣugbọn kò sí èyí tí kò ní ìtumọ̀ ninu wọn.

11 Nítorí náà, bí n kò bá gbọ́ èdè kan, mo di aláìgbédè lójú ẹni tí ó bá ń sọ èdè náà, òun náà sì di kògbédè lójú mi.

12 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń tiraka láti ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ máa wá àwọn ẹ̀bùn tí yóo mú ìjọ dàgbà.

13 Ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ fi níláti gbadura fún ẹ̀bùn láti lè túmọ̀ rẹ̀.

14 Bí mo bá ń fi èdè àjèjì gbadura, ẹ̀mí mi ni ó ń gbadura, ṣugbọn n kò lo òye ti inú ara mi nígbà náà.

15 Kí ni kí á wá wí? N óo gbadura bí Ẹ̀mí bá ti darí mi, ṣugbọn n óo kọrin pẹlu òye.

16 Bí o bá ń gbadura ọpẹ́ ní ọkàn rẹ, bí ẹnìkan bá wà níbẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, báwo ni yóo ṣe lè ṣe “Amin” sí adura ọpẹ́ tí ò ń gbà nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ?

17 Ọpẹ́ tí ò ń ṣe lè dára ṣugbọn kò mú kí ẹlòmíràn lè dàgbà.

18 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí mò ń sọ ọpọlọpọ èdè àjèjì ju gbogbo yín lọ.

19 Ṣugbọn ninu ìjọ, ó yá mi lára kí n sọ ọ̀rọ̀ marun-un pẹlu òye kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn, jù kí n sọ ọ̀rọ̀ kí ilẹ̀ kún ní èdè àjèjì lọ.

20 Ará, ẹ má máa ṣe bí ọmọde ninu èrò yín. Ó yẹ kí ẹ dàbí ọmọde tí kò mọ ibi, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò yín.

21 Ninu Òfin, ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Oluwa wí pé,

“N óo bá àwọn eniyan yìí sọ̀rọ̀

láti ẹnu àwọn eniyan tí ó ń sọ èdè àjèjì,

ati láti ẹnu àwọn àlejò.

Sibẹ wọn kò ní gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”

22 Àwọn èdè àjèjì yìí kì í ṣe àmì fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bíkòṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́.

23 Nítorí náà, nígbà tí gbogbo ìjọ bá péjọ pọ̀ sí ibìkan náà, tí gbogbo yín bá ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, tí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, tabi àwọn alaigbagbọ bá wọlé, ǹjẹ́ wọn kò ní sọ pé ẹ̀ ń ṣiwèrè ni?

24 Ṣugbọn bí gbogbo yín bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, bí ẹnìkan tí ó jẹ́ alaigbagbọ tabi ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ bá wọlé, yóo gbọ́ ohun tí ó jẹ́ ìbáwí ati ohun tí yóo mú un yẹ ara rẹ̀ wò ninu ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ.

25 Àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yóo hàn kedere, ni yóo bá dojúbolẹ̀, yóo sì júbà Ọlọrun. Yóo sọ pé, “Dájúdájú Ọlọrun wà láàrin yín.”

Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo Létòlétò

26 Ará, kí ni kókó ohun tí à ń sọ? Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, bí ẹnìkan bá ní orin, tí ẹnìkan ní ẹ̀kọ́, tí ẹnìkan ní ìfihàn, tí ẹnìkan ní èdè àjèjì, tí ẹnìkan ní ìtumọ̀ fún èdè àjèjì, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun gbogbo fún ìdàgbà ìjọ.

27 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, kí wọ́n má ju meji lọ, tabi ó wá pọ̀jù patapata, kí wọ́n jẹ́ mẹta. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, kí ẹnìkan sì máa túmọ̀ ohun tí wọn ń sọ.

28 Bí kò bá sí ẹni tí yóo ṣe ìtumọ̀, kí ẹni tí ó fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ dákẹ́ ninu ìjọ. Kí ó máa fi èdè àjèjì bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọ̀rọ̀.

29 Ẹni meji tabi mẹta ni kí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀, kí àwọn yòókù máa fi òye bá ohun tí wọn ń sọ lọ.

30 Bí ẹlòmíràn tí ó jókòó ní àwùjọ bá ní ìfihàn, ẹni kinni tí ó ti ń sọ̀rọ̀ níláti dákẹ́.

31 Gbogbo yín lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, lọ́kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo yín lè rí ẹ̀kọ́ kọ́, kí gbogbo yín lè ní ìwúrí.

32 Àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ níláti lè káwọ́ ara wọn nígbà tí ẹ̀mí bá gbé wọn láti sọ àsọtẹ́lẹ̀.

33 Nítorí Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun ìdàrúdàpọ̀. Ọlọrun alaafia ni.

Ipò Obinrin ninu Ìsìn

Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun,

34 àwọn obinrin gbọdọ̀ panumọ́ ninu ìjọ. A kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀. Wọ́n níláti wà ní ipò ìtẹríba, gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí.

35 Bí nǹkankan bá wà tí wọ́n fẹ́ mọ̀, kí wọ́n bi àwọn ọkọ wọn ní ilé. Ìtìjú ni fún obinrin láti sọ̀rọ̀ ninu ìjọ.

36 Ṣé ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kọ́ bẹ̀rẹ̀ ni àbí ẹ̀yin nìkan ni ẹ mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun?

Gbolohun Ìparí Nípa Ètò Ìsìn

37 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé wolii ni òun tabi pé òun ní agbára Ẹ̀mí, kí olúwarẹ̀ mọ̀ pé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni ohun tí mo kọ ranṣẹ si yín yìí.

38 Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni kò bá gba ohun tí a wí yìí, a kò gba òun náà.

39 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ máa tiraka láti sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ẹ má ka fífi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ sí èèwọ̀.

40 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo létòlétò, ní ọ̀nà tí ó dára.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 15

Ajinde Kristi

1 Ará, mo fẹ́ ran yín létí ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, tí ẹ gbà, tí ẹ sì bá dúró.

2 Nípa ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là, tí ẹ bá dì mọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ asán ni igbagbọ yín.

3 Nítorí ohun kinni tí ó ṣe pataki jùlọ tí èmi fúnra mi kọ́, tí mo sì fi kọ́ yín ni pé Kristi kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.

4 Ati pé a sin ín, a sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.

5 Ó fara han Peteru. Lẹ́yìn náà ó tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.

6 Lẹ́yìn náà ó tún fara han ẹẹdẹgbẹta (500) àwọn onigbagbọ lẹ́ẹ̀kan náà. Ọpọlọpọ ninu wọn wà títí di ìsinsìnyìí, ṣugbọn àwọn mìíràn ti kú.

7 Lẹ́yìn náà, ó fara han Jakọbu, ó sì tún fara han gbogbo àwọn aposteli.

8 Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín gbogbo wọn, ó wá farahàn mí, èmi tí mo dàbí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé.

9 Nítorí èmi ni mo kéré jùlọ ninu àwọn aposteli. N kò tilẹ̀ yẹ ní ẹni tí wọn ìbá máa pè ní aposteli, nítorí pé mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọrun.

10 Ṣugbọn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí kò sì jẹ́ lásán lórí mí, nítorí mo ṣe akitiyan ju gbogbo àwọn aposteli yòókù lọ. Ṣugbọn kì í ṣe èmi tìkara mi, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tí ó wà pẹlu mi ni.

11 Nítorí náà, ìbáà ṣe èmi ni, tabi àwọn aposteli yòókù, bákan náà ni iwaasu wa, bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí ẹ gbàgbọ́.

Ajinde Òkú

12 Nígbà tí ó jẹ́ pé, à ń kéde pé Kristi jinde kúrò ninu òkú, báwo ni àwọn kan ninu yín ṣe wá ń wí pé kò sí ajinde òkú?

13 Bí kò bá sí ajinde òkú, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde.

14 Bí a kò bá jí Kristi dìde ninu òkú, a jẹ́ pé asán ni iwaasu wa, asán sì ni igbagbọ yín.

15 Tí ó bá jẹ́ pé a kò jí àwọn òkú dìde, a tún jẹ́ pé a purọ́ mọ́ Ọlọrun, nítorí a jẹ́rìí pé ó jí Kristi dìde, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jí i dìde.

16 Nítorí pé bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde.

17 Bí a kò bá sì jí Kristi dìde, a jẹ́ pé lásán ni igbagbọ yín, ẹ sì wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín sibẹ.

18 Tí ó bá wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn onigbagbọ tí wọ́n ti kú ti ṣègbé!

19 Tí ó bá jẹ́ pé ninu ayé yìí nìkan ni a ní ìrètí ninu Kristi, àwa ni ẹni tí àwọn eniyan ìbá máa káàánú jùlọ!

20 Ṣugbọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni pé a ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú, òun sì ni àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú.

21 Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ eniyan ni ikú fi dé, nípasẹ̀ eniyan náà ni ajinde òkú fi dé.

22 Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Adamu ni gbogbo eniyan ṣe kú, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ Kristi ni a sọ gbogbo eniyan di alààyè.

23 Ṣugbọn a óo jí olukuluku dìde létòlétò: Kristi ni ẹni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá farahàn, a óo jí àwọn tíí ṣe tirẹ̀ dìde.

24 Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé, lẹ́yìn tí ó bá ti dá ìjọba pada fún Ọlọrun Baba, tí ó sì ti pa gbogbo àṣẹ, ọlá ati agbára run.

25 Nítorí ó níláti jọba títí Ọlọrun yóo fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí ìkáwọ́ rẹ̀.

26 Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí yóo parun.

27 Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ó ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn nígbà tí ó sọ pé, “Gbogbo nǹkan ni ó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀,” ó dájú pé ẹnìkan ni kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀: ẹni náà sì ni Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ Kristi.

28 Nígbà tí gbogbo nǹkan bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tán, ni Ọmọ fúnrarẹ̀ yóo wá bọ́ sí ìkáwọ́ Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀, kí Ọlọrun lè jẹ́ olórí ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.

29 Ó tún ku nǹkankan! Nítorí kí ni àwọn kan ṣe ń ṣe ìrìbọmi nítorí àwọn tí ó kú? Bí a kò bá ní jí àwọn òkú dìde, kí ni ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìrìbọmi nítorí wọn?

30 Àwa náà ńkọ́? Nítorí kí ni a ṣe ń fi ẹ̀mí wa wéwu nígbà gbogbo?

31 Lojoojumọ ni mò ń kú! Ará, mo fi ìgbéraga tí mo ní ninu yín búra, àní èyí tí mo ní ninu Kristi Jesu Oluwa wa.

32 Bí mo bá tìtorí iyì eniyan bá ẹranko jà ní Efesu, anfaani wo ni ó ṣe fún mi? Bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, bí wọ́n ti máa ń wí, wọn á ní:

“Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ, kí á máa mu,

nítorí ọ̀la ni a óo kú.”

33 Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́.

34 Ẹ ronú, kí ẹ sì máa ṣe dáradára. Ẹ má dẹ́ṣẹ̀ mọ́. Àwọn tí kò mọ Ọlọrun wà láàrin yín! Mò ń sọ èyí kí ojú kí ó lè tì yín ni.

Ara Lẹ́yìn Ajinde

35 Ṣugbọn ẹnìkan lè bèèrè pé, “Báwo ni a óo ti ṣe jí àwọn òkú dìde? Irú ara wo ni wọn óo ní?”

36 Ìwọ òmùgọ̀ yìí! Bí irúgbìn tí a bá gbìn kò bá kọ́ kú, kò lè hù.

37 Ohun tí ó bá hù kì í rí bí ohun tí a gbìn ti rí, nítorí pé irúgbìn lásán ni, ìbáà ṣe àgbàdo tabi àwọn ohun ọ̀gbìn yòókù.

38 Ọlọrun ni ó ń fún un ní ara tí ó bá fẹ́, a fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ní ara tirẹ̀.

39 Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe oríṣìí kan náà. Ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara eniyan, ọ̀tọ̀ ni ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ni ti ẹyẹ, ọ̀tọ̀ ni ti ẹja.

40 Àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí tí ń fò lófuurufú wà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti orí ilẹ̀ wà. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà ti àwọn tí ń fò lófuurufú. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà àwọn ti orí ilẹ̀.

41 Ọ̀tọ̀ ni ẹwà oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ ni ti àwọn ìràwọ̀, ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ara wọn ní ẹwà.

42 Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà ajinde àwọn òkú. A gbìn ín ní ara tíí díbàjẹ́; a jí i dìde ní ara tí kì í díbàjẹ́.

43 A gbìn ín ní àìlọ́lá; a jí i dìde pẹlu ògo. A gbìn ín pẹlu àìlera: a jí i dìde pẹlu agbára.

44 A gbìn ín pẹlu ara ti ẹ̀dá, a jí i dìde ní ara ti ẹ̀mí. Bí ara ti ẹ̀dá ti wà, bẹ́ẹ̀ ni ti ẹ̀mí wà.

45 Ó wà ninu àkọsílẹ̀ pé, “Adamu, ọkunrin àkọ́kọ́ di alààyè;” ṣugbọn Adamu ìkẹyìn jẹ́ ẹ̀mí tí ó ń sọ eniyan di alààyè.

46 Kì í ṣe ẹni ti ẹ̀mí ni ó kọ́kọ́ wà bíkòṣe ẹni ti ara, lẹ́yìn náà ni ẹni ti ẹ̀mí.

47 Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá.

48 Bí ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí a fi erùpẹ̀ dá rí. Bí ẹni tí ó wá láti ọ̀run ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ti ọ̀run rí.

49 Bí a ti gbé àwòrán ti ẹni erùpẹ̀ wọ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé àwòrán ti ẹni ọ̀run wọ̀.

50 Ará, ohun tí mò ń sọ ni pé ẹran-ara ati ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọrun, ati pé ohun tíí bàjẹ́ kò lè jogún ohun tí kì í bàjẹ́.

51-52 Ẹ fetí sílẹ̀! Nǹkan àṣírí ni n óo sọ fun yín. Gbogbo wa kọ́ ni a óo kú, ṣugbọn nígbà tí fèrè ìkẹyìn bá dún, gbogbo wa ni a óo pa lára dà, kíá, bí ìgbà tí eniyan bá ṣẹ́jú. Nítorí fèrè yóo dún, a óo wá jí àwọn òkú dìde pẹlu ara tí kì í bàjẹ́, àwa náà yóo wá yipada.

53 Nítorí ara tíí bàjẹ́ yìí níláti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀; ara tí yóo kú yìí níláti gbé ara tí kì í kú wọ̀.

54 Nígbà tí ara tíí bàjẹ́ bá ti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀ tán, tí ara tí yóo kú bá sì ti gbé ara tí kì í kú wọ̀, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ tí a ti kọ sílẹ̀ yóo wá ṣẹ pé,

“A ti gbé ikú mì,

a sì ti ṣẹgun.”

55 “Ikú, oró rẹ dà?

Isà òkú, ìṣẹ́gun rẹ dà?”

56 Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó fún ikú lóró. Òfin ni ó fún ẹ̀ṣẹ̀ lágbára.

57 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fún wa ní ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi.

58 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ dúró gbọningbọnin, láì yẹsẹ̀. Ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo. Ẹ kúkú ti mọ̀ pé làálàá tí ẹ̀ ń ṣe níbi iṣẹ́ Oluwa kò ní jẹ́ lásán.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 16

Ìtọrẹ Onigbagbọ

1 Nípa ti ìtọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn eniyan Ọlọrun, bí mo ti ṣe ètò pẹlu àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.

2 Ní ọjọọjọ́ ìsinmi, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa mú ọrẹ ninu ohun ìní rẹ̀, kí ó máa fi í sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun bá ti bukun un. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ni ẹ óo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ọrẹ jọ.

3 Nígbà tí mo bá dé, n óo kọ ìwé lé àwọn tí ẹ bá yàn lọ́wọ́, n óo rán wọn láti mú ọrẹ yín lọ sí Jerusalẹmu.

4 Bí ó bá yẹ kí èmi náà lọ, wọn yóo bá mi lọ.

Ètò Nípa Ìrìn Àjò

5 Masedonia ni n óo kọ́ gbà kọjá, n óo wá wá sọ́dọ̀ yín.

6 Bóyá n óo dúró lọ́dọ̀ yín, mo tilẹ̀ lè wà lọ́dọ̀ yín ní àkókò òtútù, kí ẹ lè sìn mí lọ sí ibi tí mo bá tún ń lọ.

7 Nítorí pé, nígbà tí mo bá ń kọjá lọ, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé mo kàn fi ojú bà yín lásán ni. Nítorí mo ní ìrètí pé n óo lè dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí Oluwa bá gbà bẹ́ẹ̀.

8 Mo fẹ́ dúró ní Efesu níhìn-ín títí di àjọ̀dún Pẹntikọsti.

9 Nítorí pé mo ní anfaani pupọ láti ṣiṣẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò pọ̀.

10 Bí Timoti bá dé, kí ẹ rí i pé ẹ fi í lára balẹ̀ láàrin yín, nítorí iṣẹ́ Oluwa tí mò ń ṣe ni òun náà ń ṣe.

11 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi àbùkù kàn án. Ẹ ṣe ètò ìrìn àjò fún un ní alaafia, kí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, nítorí èmi ati àwọn arakunrin ń retí rẹ̀.

12 Nípa ti arakunrin wa Apolo, mo gbà á níyànjú gidigidi pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín pẹlu àwọn arakunrin yòókù. Ṣugbọn ó pinnu pé òun kò fẹ́ wá ní àkókò yìí. Ó ń bọ̀ nígbà tí ó bá yá.

Gbolohun Ìparí

13 Ẹ máa ṣọ́nà. Ẹ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ. Ẹ ṣe bí ọkunrin. Ẹ jẹ́ alágbára.

14 Ẹ máa ṣe gbogbo nǹkan tìfẹ́tìfẹ́.

15 Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun.

16 Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà.

17 Inú mi dùn nígbà tí Stefana ati Fotunatu ati Akaiku dé, nítorí dídé tí wọ́n dé dí àlàfo tí ó ṣí sílẹ̀ nítorí àìsí yín lọ́dọ̀ wa.

18 Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí.

19 Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa.

20 Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Ẹ fi ìfẹnukonu alaafia kí ara yín.

21 Ọwọ́ ara mi ni èmi Paulu fi kọ gbolohun ìkíni yìí.

22 Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni!

Marana ta–Oluwa wa, máa bọ̀!

23 Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.

24 Mo fi ìfẹ́ kí gbogbo yín ninu Kristi Jesu.