Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Paulu kọ ìwé rẹ̀ kinni sí àwọn ará Kọrinti láti ṣe àlàyé nípa ìyọnu kan tí ó bẹ́ sílẹ̀ ninu ìjọ tí Paulu dá sílẹ̀ níbẹ̀. Ohun tí ó fa ìyọnu yìí ni ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sìn ati ìgbé-ayé onigbagbọ. Ìlú Kọrinti tóbi gan-an nígbà náà, oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni ó sì pésẹ̀ sinu ìlú náà. Ìlú Giriki ni, òun sì ni olú-ìlú gbogbo agbègbè Akaya tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ìjọba Romu. Àwọn nǹkan bíi mẹrin ni ó mú kí ìlú Kọrinti lókìkí níbi gbogbo ní àkókò náà. Àwọn ni: ìlọsíwájú òwò, àṣà ìbílẹ̀ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, ìwà ìṣekúṣe níbi gbogbo, ati oríṣìíríṣìí ẹ̀sìn.

Ọ̀rọ̀ tí ó jẹ Paulu Aposteli lógún jùlọ ninu ìwé yìí ni ti àwọn ìyọnu tí ó jẹ mọ́ ti ìyapa ati ti ìṣekúṣe láàrin àwọn ọmọ ìjọ, ati ìbéèrè lórí ọ̀rọ̀ igbeyawo ati ìbálòpọ̀ láàrin ọkunrin ati obinrin; lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rí-ọkàn, ètò ninu ìjọ, oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ati ajinde.

Ó sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìrírí ati ìmọ̀, lórí ìdáhùn tí ìròyìn ayọ̀ Jesu Kristi ní sí àwọn ìbéèrè náà.

Orí ìkẹtàlá (13) ìwé yìí ni ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé mọ̀ jùlọ. Ninu orí yìí ni Paulu ti ṣe àlàyé lórí bí ìfẹ́ ti jẹ́ ẹ̀bùn tí ó dára jùlọ tí Ọlọrun fún àwọn eniyan rẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-9

Ìyapa ninu ìjọ 1:10–4:21

Ìwà àgbèrè ati ìdílé onigbagbọ 5:1–7:40

Àwọn onigbagbọ ati àwọn abọ̀rìṣà 8:1–11:1

Ìsìn ati ìgbé-ayé ninu ìjọ 11:2–14:40

Ajinde Kristi ati ti àwọn onigbagbọ 15:1-58

Ìtọrẹ-àánú àwọn onigbagbọ ní Judia 16:1-4

Ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́ ati ọ̀rọ̀ ìparí 16:5-24

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 1

Ìkíni

1 Èmi Paulu, tí Ọlọrun pè láti jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi Jesu, ati Sositene arakunrin wa ni à ń kọ ìwé yìí–

2 Sí ìjọ Ọlọrun ti ó wà ní Kọrinti, àwọn tí a yà sí mímọ́ nípa ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀, ati gbogbo àwọn tí ń pe orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi níbi gbogbo, Jesu tíí ṣe Oluwa tiwọn ati tiwa.

3 Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó máa wà pẹlu yín.

Ìdúpẹ́

4 Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nígbà gbogbo nítorí yín, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fun yín ninu Kristi Jesu.

5 Nítorí pé ẹ ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn ninu Kristi: ẹ ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ sì tún ní ẹ̀bùn ìmọ̀.

6 Ẹ̀rí Kristi ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ láàrin yín,

7 tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹ̀bùn Ẹ̀mí kan tí ó kù tí ẹ kò ní. Ẹ wá ń fi ìtara retí ìfarahàn Oluwa wa Jesu Kristi,

8 ẹni tí yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ títí dé òpin, tí ẹ óo fi wà láì lẹ́gàn ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa, Jesu Kristi.

9 Ẹni tí ó tó gbẹ́kẹ̀lé ni Ọlọrun tí ó pè yín sinu ìṣọ̀kan pẹlu ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, Oluwa wa.

Ìyapa ninu Ìjọ

10 Ẹ̀yin ará, mo fi orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi bẹ̀ yín, gbogbo yín, ẹ fohùn ṣọ̀kan, kí ó má sí ìyapa láàrin yín. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí èrò yín sì papọ̀.

11 Nítorí pé ninu ìròyìn tí àwọn ará Kiloe mú wá, ó hàn sí mi gbangba pé ìjà wà láàrin yín.

12 Ohun tí mò ń wí ni pé olukuluku yín ní ń sọ tirẹ̀. Bí ẹnìkan ti ń wí pé. “Ẹ̀yìn Paulu ni èmi wà,” ni ẹlòmíràn ń wí pé. “Ẹ̀yìn Apolo ni èmi wà,” tí ẹlòmíràn tún ń wí pé, “Ẹ̀yìn Peteru ni mo wà ní tèmi.” Ẹlòmíràn sì ń wí pé, “Ẹ̀yìn Kristi ni èmi wà.”

13 Ṣé Kristi náà ni ó wá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ báyìí? Ṣé èmi Paulu ni wọ́n kàn mọ́ agbelebu fun yín? Àbí ní orúkọ Paulu ni wọ́n ṣe ìrìbọmi fun yín?

14 Mo dúpẹ́ pé n kò ṣe ìrìbọmi fún ẹnikẹ́ni ninu yín, àfi Kirisipu ati Gaiyu.

15 Kí ẹnikẹ́ni má baà wí pé orúkọ mi ni wọ́n fi ṣe ìrìbọmi fún òun.

16 Mo tún ranti! Mo ṣe ìrìbọmi fún ìdílé Stefana. N kò tún ranti ẹlòmíràn tí mo ṣe ìrìbọmi fún mọ́.

17 Nítorí pé Kristi kò fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrìbọmi rán mi, iṣẹ́ iwaasu ìyìn rere ni ó fi rán mi, kì í sìí ṣe nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, kí agbelebu Kristi má baà di òfo.

Kristi Ni Agbára ati Ọgbọ́n Ọlọrun

18 Nítorí ọ̀rọ̀ agbelebu Kristi jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tí ń ṣègbé. Ṣugbọn lójú àwọn tí à ń gbà là, agbára Ọlọrun ni.

19 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,

“Ọlọrun wí pé, ‘Èmi óo pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,

n óo pa ìmọ̀ àwọn amòye tì sápá kan.’ ”

20 Ipò wo wá ni àwọn ọlọ́gbọ́n wà? Àwọn amòfin ńkọ́? Àwọn tí wọ́n mọ iyàn jà ní ayé yìí ńkọ́? Ṣebí Ọlọrun ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di agọ̀!

21 Bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kì í ṣe ipasẹ̀ gbogbo ọgbọ́n ayé yìí ni eniyan yóo fi mọ Ọlọrun, ó wu Ọlọrun láti gba àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa iwaasu tí à ń wà, tí ó dàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.

22 Nítorí àwọn Juu ń bèèrè àmì: àwọn Giriki ń lépa ọgbọ́n;

23 ṣugbọn ní tiwa, àwa ń waasu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. Ohun ìkọsẹ̀ ni iwaasu wa yìí jẹ́ lójú àwọn Juu, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ sì ni lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù;

24 ṣugbọn lójú àwọn tí Ọlọrun pè, ìbáà ṣe Juu tabi Giriki, Kristi yìí ni agbára Ọlọrun, òun ni ọgbọ́n Ọlọrun.

25 Nítorí agọ̀ Ọlọrun gbọ́n ju eniyan lọ, àìlágbára Ọlọrun sì lágbára ju eniyan lọ!

26 Ẹ̀yin ará, ẹ wo ọ̀nà tí Ọlọrun gbà pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ninu yín ni ọlọ́gbọ́n gẹ́gẹ́ bí èrò ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe alágbára, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe ọlọ́lá.

27 Ṣugbọn Ọlọrun ti yan àwọn nǹkan tí ayé kà sí agọ̀ láti fi dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n, ó yan àwọn nǹkan tí kò lágbára ti ayé, láti fi dójú ti àwọn alágbára;

28 bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀.

29 Ìdí tí Ọlọrun fi ṣe báyìí ni pé kí ẹnikẹ́ni má baà lè gbéraga níwájú òun.

30 Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè.

31 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pe:

“Ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ìgbéraga,

kí ó ṣe ìgbéraga nípa ohun tí Oluwa ṣe.”

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 2

Paulu Ń Waasu Kristi Tí Wọ́n Kàn Mọ́ Agbelebu

1 Ẹ̀yin ará, nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ yín, n kò wá fi ọ̀rọ̀ dídùn tabi ọgbọ́n eniyan kéde àṣírí Ọlọrun fun yín.

2 Nítorí mo ti pinnu pé n kò fẹ́ mọ ohunkohun láàrin yín yàtọ̀ fún Jesu Kristi: àní, ẹni tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu.

3 Pẹlu àìlera ati ọpọlọpọ ìbẹ̀rù ati ìkọminú ni mo fi wá sọ́dọ̀ yín.

4 Ọ̀rọ̀ mi ati iwaasu mi kì í ṣe láti fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ó dùn létí yi yín lọ́kàn pada, iṣẹ́ Ẹ̀mí ati agbára Ọlọrun ni mo fẹ́ fihàn;

5 kí igbagbọ yín má baà dúró lórí ọgbọ́n eniyan bíkòṣe lórí agbára Ọlọrun.

Àṣírí Tí Ẹ̀mí Ọlọrun Fihàn

6 À ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún àwọn tí igbagbọ wọn ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí, kì í sìí ṣe ti àwọn aláṣẹ ayé yìí, agbára tiwọn ti fẹ́rẹ̀ pin.

7 Ṣugbọn à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọrun, ohun àṣírí tí ó ti wà ní ìpamọ́, tí Ọlọrun ti ṣe ètò sílẹ̀ láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé fún ògo wa.

8 Kò sí ọ̀kan ninu àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ àṣírí yìí, nítorí tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá tí kan Oluwa tí ó lógo mọ́ agbelebu.

9 Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,

“Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́,

Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí,

ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.”

10 Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun.

11 Nítorí ẹ̀dá alààyè wo ni ó mọ ohun tí ó wà ninu eniyan kan bíkòṣe ẹ̀mí olúwarẹ̀ tí ó wà ninu rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn nǹkan Ọlọrun: kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Ẹ̀mí Ọlọrun.

12 Ṣugbọn ní tiwa, kì í ṣe ẹ̀mí ti ayé ni a gbà. Ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó fi fún wa, kí á lè mọ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fún wa.

13 Ohun tí à ń sọ kì í ṣe ohun tí eniyan fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n kọ́ wa. Ẹ̀mí ni ó kọ́ wa bí a ti ń túmọ̀ nǹkan ti ẹ̀mí, fún àwọn tí wọ́n ní Ẹ̀mí.

14 Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé.

15 Ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí lè wádìí ohun gbogbo, ṣugbọn eniyan kan lásán kò lè wádìí òun alára.

16 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,

“Ta ni ó mọ inú Oluwa?

Ta ni yóo kọ́ Oluwa lẹ́kọ̀ọ́?”

Ṣugbọn irú ẹ̀mí tí Kristi ní ni àwa náà ní.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 3

Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun

1 Ẹ̀yin ará, n kò lè ba yín sọ̀rọ̀ bí ẹni ti Ẹ̀mí, bíkòṣe bí ẹlẹ́ran-ara, àní gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ọwọ́ ninu Kristi.

2 Wàrà ni mo ti fi ń bọ yín, kì í ṣe oúnjẹ gidi, nítorí nígbà náà ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi. Àní títí di ìsinsìnyìí ẹ kò ì tíì lè jẹ ẹ́,

3 nítorí bí ẹlẹ́ran-ara ni ẹ̀ ń hùwà sibẹ. Nítorí níwọ̀n ìgbà tí owú jíjẹ ati ìjà bá wà láàrin yín, ṣé kò wá fihàn pé bí ẹlẹ́ran-ara ati eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà.

4 Nítorí nígbà tí ẹnìkan ń sọ pé ẹ̀yìn Paulu ni òun wà, tí ẹlòmíràn ń sọ pé ẹ̀yìn Apolo ni òun wà ní tòun, ó fihàn pé bí eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà.

5 Nítorí ta ni Apolo? Ta ni Paulu? Ṣebí iranṣẹ ni wọ́n, tí ẹ ti ipasẹ̀ wọn di onigbagbọ? Olukuluku wọn jẹ́ iṣẹ́ tirẹ̀ bí Ọlọrun ti rán an.

6 Èmi gbin irúgbìn, Apolo bomi rin ohun tí mo gbìn, ṣugbọn Ọlọrun ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn dàgbà.

7 Nítorí èyí, kì í ṣe ẹni tí ń gbin nǹkan, tabi ẹni tí ń bomi rin ín ni ó ṣe pataki, bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú un dàgbà.

8 Ọ̀kan ni ẹni tí ó ń gbin irúgbìn ati ẹni tí ó ń bomi rin ín. Nígbà tí ó bá yá, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóo gba èrè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.

9 Nítorí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ni wá lọ́dọ̀ Ọlọrun. Ẹ̀yin ni ọgbà Ọlọrun.

Tẹmpili Ọlọrun sì ni yín.

10 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀lé tí ó mòye, mo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún mi, ẹlòmíràn wá ń kọ́lé lé e lórí. Ṣugbọn kí olukuluku ṣọ́ra pẹlu irú ohun tí ó ń mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí.

11 Nítorí kò sí ìpìlẹ̀ kan tí ẹnikẹ́ni tún lè fi lélẹ̀ mọ́, yàtọ̀ sí èyí tí Ọlọrun ti fi lélẹ̀, tíí ṣe Jesu Kristi.

12 Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá mọ wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta iyebíye, tabi igi, tabi koríko tabi fùlùfúlù lé orí ìpìlẹ̀ yìí,

13 iṣẹ́ olukuluku yóo farahàn kedere ní ọjọ́ ìdájọ́, nítorí iná ni yóo fi í hàn. Iná ni a óo fi dán iṣẹ́ olukuluku wò.

14 Bí ohun tí ẹnikẹ́ni bá kọ́ lé orí ìpìlẹ̀ yìí kò bá jóná, olúwarẹ̀ yóo gba èrè.

15 Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, olúwarẹ̀ yóo pòfo, ṣugbọn òun alára yóo lá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ẹni tí a fà yọ ninu iná ni.

16 Àbí ẹ kó mọ̀ pé Tẹmpili Ọlọrun ni yín ni, ati pé Ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú yín?

17 Bí ẹnikẹ́ni bá ba Tẹmpili Ọlọrun jẹ́. Ọlọrun yóo pa òun náà run. Nítorí mímọ́ ni Tẹmpili Ọlọrun, ẹ̀yin náà sì ni Tẹmpili Ọlọrun.

18 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Bí ẹnìkan ninu yín bá rò pé òun gbọ́n ọgbọ́n ti ayé yìí, kí ó ka ara rẹ̀ sí òmùgọ̀ kí ó lè gbọ́n.

19 Nítorí agọ̀ ni ọgbọ́n ayé yìí lójú Ọlọrun. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn.”

20 Níbòmíràn, ó tún wí pé, “Oluwa mọ̀ pé asán ni èrò-inú àwọn ọlọ́gbọ́n.”

21 Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tìtorí eniyan gbéraga, nítorí tiyín ni ohun gbogbo:

22 ati Paulu ni, ati Apolo, ati Peteru, ati ayé yìí, ati ìyè, ati ikú, ati àwọn nǹkan ìsinsìnyìí ati àwọn nǹkan àkókò tí ń bọ̀, tiyín ni ohun gbogbo.

23 Ṣugbọn ti Kristi ni yín, Kristi sì jẹ́ ti Ọlọrun.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 4

Iṣẹ́ Àwọn Aposteli

1 Bí ó ti yẹ kí eniyan máa rò nípa wa ni pé a jẹ́ iranṣẹ Kristi ati ìríjú àwọn nǹkan àṣírí Ọlọrun.

2 Ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ ìríjú ni pé kí ó jẹ́ olóòótọ́.

3 Kò ṣe mí ní nǹkankan bí ẹ bá ń dá mi lẹ́jọ́ tabi bí ẹnikẹ́ni bá ń dá mi lẹ́jọ́. Èmi fúnra mi kì í tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.

4 Ọkàn mi mọ́, ṣugbọn n kò wí pé mo pé, Oluwa ni ẹni tí ó ń ṣe ìdájọ́ mi.

5 Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

6 Ẹ̀yin ará, mo fi ara mi ati Apolo ṣe àpẹẹrẹ ohun tí à ń sọ nítorí yín, kí ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára wa, pé kí ẹ má ṣe tayọ ohun tí ó wà ní àkọsílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹnìkejì lọ.

7 Ta ni ó gbe yín ga ju ẹlòmíràn lọ? Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ẹ ti rí i gbà? Kí wá ni ìdí ìgbéraga yín bí ẹni pé ẹ̀yin ni ẹ dá a ní?

8 Ṣé gbogbo nǹkan ti tẹ yín lọ́rùn! Ẹ ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ gbàgbé wa sẹ́yìn, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí jọba! Kì bá wù mí kí ẹ jọba nítòótọ́ kí àwa náà lè ba yín jọba!

9 Nítorí mo rò pé Ọlọrun ti fi àwa òjíṣẹ́ hàn ní ìkẹyìn bí àwọn tí a dá lẹ́bi ikú, nítorí a ti di ẹni tí gbogbo ayé fi ń ṣe ìran wò: ati àwọn angẹli, ati àwọn eniyan.

10 Àwa di òmùgọ̀ nítorí ti Kristi, ẹ̀yin wá jẹ́ ọlọ́gbọ́n ninu Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́lá, àwa jẹ́ aláìlọ́lá!

11 Títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ebi ń pa wá, òùngbẹ ń gbẹ wá, aṣọ sì di àkísà mọ́ wa lára. Wọ́n ń lù wá, a kò sì ní ibùgbé kan tààrà.

12 Àárẹ̀ mú wa bí a ti ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. Àwọn eniyan ń bú wa, ṣugbọn àwa ń súre fún wọn. Wọ́n ń ṣe inúnibíni wa, ṣugbọn à ń fara dà á.

13 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wa, ṣugbọn àwa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí. A di ohun ẹ̀sín fún gbogbo ayé. A di pàǹtí fún gbogbo eniyan títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.

14 Kì í ṣe pé mo fẹ́ dójú tì yín ni mo fi ń kọ nǹkan wọnyi si yín, mò ń kìlọ̀ fun yín gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ mi ni.

15 Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere.

16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìwà jọ mí.

17 Ìdí tí mo ṣe rán Timoti si yín nìyí, ẹni tí ó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ fún mi, ati olóòótọ́ ninu nǹkan ti Oluwa. Òun ni yóo ran yín létí àwọn ohun tí mo fi ń ṣe ìwà hù ninu ìgbé-ayé titun ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ gbogbo àwọn ìjọ níbi gbogbo.

18 Àwọn kan ti ń gbéraga bí ẹni pé n kò ní wá sọ́dọ̀ yín.

19 Ṣugbọn mò ń bọ̀ láìpẹ́, bí Oluwa bá fẹ́. N óo wá mọ agbára tí àwọn tí wọn ń gbéraga ní nígbà náà, yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn lásán.

20 Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu: ti agbára ni!

21 Kí ni ẹ fẹ́? Kí n tọ̀ yín wá pẹlu pàṣán ni, tabi pẹlu ẹ̀mí ìfẹ́ ati ní ìrẹ̀lẹ̀?

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 5

Paulu Ṣe Ìdájọ́ lórí Ìwà Ìbàjẹ́

1 A gbọ́ dájúdájú pé ìwà àgbèrè wà láàrin yín, irú èyí tí kò tilẹ̀ sí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. A gbọ́ pé ẹnìkan ń bá iyawo baba rẹ̀ lòpọ̀!

2 Dípò èyí tí ọkàn yín ìbá fi bàjẹ́, tí ẹ̀ bá sì yọ ẹni tí ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin yín, ẹ wá ń ṣe fáàrí!

3-4 Bí èmi alára kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín mo wà lọ́dọ̀ yín ninu ẹ̀mí. Mo ti ṣe ìdájọ́ ẹni tí ó ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jesu Oluwa bí ẹni pé mo wà lọ́dọ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, tí ẹ̀mí mi sì wà pẹlu yín, pẹlu agbára Oluwa wa Jesu,

5 ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ fún Satani, kí Satani lè pa ara rẹ̀ run, kí á lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa.

6 Fáàrí tí ẹ̀ ń ṣe kò dára! Ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ni ó ń mú burẹdi wú sókè?

7 Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè dàbí burẹdi titun, ẹ óo wá di burẹdi titun ti kò ní ìwúkàrà ninu. Nítorí a ti fi Kristi ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá wa rúbọ.

8 Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́.

9 Mo kọ ìwé si yín pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń hùwà ìbàjẹ́.

10 Kì í ṣe pé kí ẹ yẹra patapata fún àwọn alaigbagbọ tí ń hùwà àgbèrè, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi oníjìbìtì, tabi abọ̀rìṣà. Nítorí ẹ óo níláti jáde kúrò ninu ayé tí ẹ kò bá bá irú àwọn wọnyi lò.

11 Ohun tí mo kọ si yín ni pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tí a bá ń pè ní onigbagbọ tí ó ń hùwà àgbèrè, tabi ti ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà, tabi abanijẹ́, tabi ọ̀mùtí, tabi oníjìbìtì. Ẹ má tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.

12-13 Èwo ni tèmi láti dá alaigbagbọ lẹ́jọ́? Ṣebí àwọn onigbagbọ ara yín ni ẹ̀ ń dá lẹ́jọ́? Ọlọrun ni ó ń ṣe ìdájọ́ àwọn alaigbagbọ. Ẹ yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 6

Onigbagbọ Ń Pe Ara Wọn Lẹ́jọ́ Níwájú Àwọn Alaigbagbọ

1 Kí ló dé tí ẹni tí ó bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkejì rẹ̀ fi ń gbé ẹjọ́ lọ siwaju àwọn alaigbagbọ?

2 Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ ayé? Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ óo ṣe ìdájọ́ ayé, ó ti wá jẹ́ tí ẹ kò fi lè ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó kéré jùlọ?

3 Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwa onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli! Mélòó-mélòó wá ni àwọn nǹkan ti ayé yìí?

4 Bí ẹ bá ní ẹ̀sùn nípa nǹkan ti ayé, kí ló dé ti ẹ fi ń pe àwọn alaigbagbọ tí kò lẹ́nu ninu ìjọ láti máa jókòó lórí ọ̀rọ̀ yín?

5 Kí ojú baà lè tì yín ni mo fi ń sọ̀rọ̀ báyìí! Ṣé kò wá sí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó gbọ́n tó láti dá ẹjọ́ fún ẹnìkan ati arakunrin rẹ̀ ni?

6 Dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, onigbagbọ ń pe onigbagbọ lẹ́jọ́ níwájú àwọn alaigbagbọ!

7 Nǹkankan kù díẹ̀ kí ó tó nípa igbagbọ yín. Òun ni ó mú kí ẹ máa ní ẹ̀sùn sí ara yín. Kí ni kò jẹ́ kí olukuluku yín kúkú máa gba ìwọ̀sí? Kí ni kò jẹ́ kí ẹ máa gba ìrẹ́jẹ?

8 Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ẹ̀ ń fi ìwọ̀sí kan ara yín tí ẹ̀ ń rẹ́ ara yín jẹ, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ onigbagbọ!

9 Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin;

10 àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun.

11 Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.

Ẹ Fi Ara Yín Yin Ọlọrun

12 Ẹnìkan lè sọ pé, “Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí o lè ṣe ni yóo ṣe ọ́ ní anfaani. Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe, ṣugbọn n kò ní jẹ́ kí ohunkohun jọba lé mi lórí.

13 Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ. Ṣugbọn ati oúnjẹ ati ikùn ni Ọlọrun yóo parun. Ara kò wà fún ṣíṣe àgbèrè bíkòṣe pé kí á lò ó fún Oluwa. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wà fún ara.

14 Bí Ọlọrun ti jí Oluwa dìde kúrò ninu òkú, bẹ́ẹ̀ ní yóo jí àwa náà pẹlu agbára rẹ̀.

15 Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni àwọn ẹ̀yà ara yín jẹ́? Ṣé kí a wá sọ ẹ̀yà ara Kristi di ẹ̀yà ara àgbèrè ni? Ọlọrun má jẹ̀ẹ́!

16 Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó bá alágbèrè lòpọ̀ ti di ara kan pẹlu rẹ̀? Ìwé Mímọ́ sọ pé. “Àwọn mejeeji yóo di ara kan.”

17 Ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ìdàpọ̀ pẹlu Oluwa di ọ̀kan pẹlu rẹ̀ ninu ẹ̀mí.

18 Ẹ sá fún ìwà àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan lè máa dá kò kan ara olúwarẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun tìkararẹ̀.

19 Àbí, ẹ kò mọ̀ pé ara yín ni ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà ninu yín, tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun? Ati pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ni ara yín?

20 Iyebíye ni Ọlọrun rà yín, nítorí náà, ẹ fi ara yín yin Ọlọrun.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 7

Èrò nípa Igbeyawo

1 Ọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ẹ kọ nípa rẹ̀, ó dára tí ọkunrin bá lè ṣe é kí ó má ní obinrin rara.

2 Ṣugbọn nítorí àgbèrè, kí olukuluku ọkunrin ní aya tirẹ̀; kí olukuluku obinrin sì ní ọkọ tirẹ̀.

3 Ọkọ gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni iyawo náà gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu ọkọ rẹ̀.

4 Kì í ṣe iyawo ni ó ni ara rẹ̀, ọkọ rẹ̀ ni ó ni í; bákan náà ni ọkọ, òun náà kò dá ara rẹ̀ ni, iyawo rẹ̀ ni ó ni í.

5 Ọkọ ati aya kò gbọdọ̀ fi ara wọn du ara wọn, àfi bí wọ́n bá jọ gbà pé fún àkókò díẹ̀ àwọn yóo yàgò fún ara àwọn, kí wọ́n lè tẹra mọ́ adura gbígbà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ yìí, kí wọn tún máa bá ara wọn lòpọ̀, kí Satani má baà dán wọn wò, tí wọn kò bá lè mú ara dúró.

6 Mo sọ èyí kí ẹ lè mọ̀ pé mo yọ̀ǹda fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ni; kì í ṣe pé mo pa á láṣẹ.

7 Ohun tí ìbá wù mí fun yín ni pé kí gbogbo eniyan rí bí mo ti rí; ṣugbọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun fún olukuluku yàtọ̀, ó fún àwọn kan ní oríṣìí kan, ó fún àwọn mìíràn ní oríṣìí mìíràn.

8 Mò ń sọ fún àwọn tí kò ì tíì gbeyawo ati fún àwọn opó pé ó dára fún wọn láti dá wà, bí mo ti wà.

9 Ṣugbọn bí wọn kò bá lè mú ara dúró, wọ́n níláti gbeyawo. Nítorí ó sàn kí wọ́n gbeyawo jù pé kí ara wọn máa gbóná nítorí èrò ìbálòpọ̀ ọkunrin ati obinrin.

10 Mo ní ọ̀rọ̀ fún àwọn tí ó ti gbeyawo: ọ̀rọ̀ tèmi fúnra mi kọ́, bíkòṣe ti Oluwa wa. Aya kò gbọdọ̀ kọ ọkọ rẹ̀.

11 Bí ó bá kọ ọkọ rẹ̀, ó níláti dá wà ni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ rẹ́, kí ó pada sọ́dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ọkọ náà kò gbọdọ̀ kọ aya rẹ̀.

12 Mo ní ọ̀rọ̀ fún ẹ̀yin yòókù, (èrò tèmi ni o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Oluwa wa.) Bí ọkunrin onigbagbọ kan bá ní aya tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu aya rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ọkọ má ṣe kọ̀ ọ́.

13 Bí obinrin onigbagbọ bá ní ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ, tí ó bá wu ọkọ rẹ̀ láti máa bá a gbé, kí ó má ṣe kọ ọkọ rẹ̀.

14 Nítorí ọkọ tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa aya rẹ̀, aya tí kì í ṣe onigbagbọ di ẹni Ọlọrun nípa ọkọ rẹ̀. Bí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, alaimỌlọrun ni àwọn ọmọ yín ìbá jẹ́ ṣugbọn nisinsinyii ẹni Ọlọrun ni wọ́n.

15 Ṣugbọn bí ẹni tí kì í ṣe onigbagbọ bá yàn láti fi ẹnìkejì tí ó jẹ́ onigbagbọ sílẹ̀, kí ó fi í sílẹ̀. Kò sí ọ̀ranyàn fún ọkọ tabi aya tí ó jẹ́ onigbagbọ ninu irú ọ̀ràn báyìí. Kí ẹ jọ wà ní alaafia ní ipò tí Ọlọrun pè yín sí.

16 Nítorí, ta ni ó mọ̀, bóyá ìwọ aya ni yóo gba ọkọ rẹ là? Tabi ta ni ó mọ̀, ìwọ ọkọ, bóyá ìwọ ni o óo gba aya rẹ là?

Ipò tí Ọlọrun Yàn fún Ẹnìkọ̀ọ̀kan

17 Kí olukuluku máa gbé ìgbé-ayé rẹ̀ bí Oluwa ti yàn án fún un, kí ó sì wà ní ipò tí ó wà nígbà tí Ọlọrun fi pè é láti di onigbagbọ. Bẹ́ẹ̀ ni mò ń fi kọ́ gbogbo àwọn ìjọ.

18 Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ ẹni tí ó kọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe pa ilà rẹ̀ rẹ́. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ aláìkọlà nígbà tí a pè é, kí ó má ṣe kọlà.

19 Ati a kọlà ni, ati a kò kọlà ni, kò sí èyí tí ó ṣe pataki. Ohun tí ó ṣe pataki ni pípa àwọn òfin Ọlọrun mọ́.

20 Kí olukuluku wà ní ipò tí ó wà nígbà tí a pè é láti di onigbagbọ.

21 Ẹrú ni ọ́ nígbà tí a fi pè ọ́? Má ṣe gbé e lékàn. Ṣugbọn bí o bá ní anfaani láti di òmìnira, lo anfaani rẹ.

22 Nítorí ẹrú tí a pè láti di onigbagbọ di òmìnira lọ́dọ̀ Oluwa. Bákan náà ni, ẹni òmìnira tí a pè láti di onigbagbọ di ẹrú Kristi.

23 Iyebíye ni Ọlọrun rà yín. Ẹ má ṣe di ẹrú eniyan mọ́.

24 Ẹ̀yin ará, ipòkípò tí olukuluku bá wà tí a bá fi pè é, níbẹ̀ ni kí ó máa wà níwájú Ọlọrun.

Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Tí Kò Tíì Ṣe Igbeyawo ati Àwọn Opó

25 N kò ní àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Oluwa láti pa fún àwọn wundia. Ṣugbọn mò ń sọ ohun tí mo rò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Oluwa ti ṣàánú fún, tí eniyan sì lè gbẹ́kẹ̀lé.

26 Mo rò pé ohun tí ó dára ni pé kí eniyan má ṣe kúrò ní ipò tí ó wà, nítorí àkókò ìpọ́njú ni àkókò yìí.

27 Bí o bá ti gbé iyawo, má ṣe wá ọ̀nà láti kọ aya rẹ. Bí o bá sì ti kọ aya rẹ, má ṣe wá ọ̀nà láti tún gbé iyawo.

28 Ṣugbọn bí o bá gbeyawo, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Bí wundia náà bá sì lọ́kọ, kò dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn irú àwọn bẹ́ẹ̀ yóo ní ìpọ́njú ní ti ara. Bẹ́ẹ̀ ni n kò sì fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ si yín.

29 Ẹ̀yin ará, ohun tí mò ń sọ nìyí. Àkókò tí ó kù fún wa kò gùn. Ninu èyí tí ó kù, kí àwọn tí wọ́n ní iyawo ṣe bí ẹni pé wọn kò ní.

30 Kí àwọn tí ń sunkún máa ṣe bí ẹni pé wọn kò sunkún. Kí àwọn tí ń yọ̀ máa ṣe bí ẹni pé wọn kò yọ̀. Kí àwọn tí ń ra nǹkan máa ṣe bí ẹni pé kì í ṣe tiwọn ni ohun tí wọ́n ní.

31 Kí àwọn tí ń lo dúkìá ayé máa lò ó láì dara dé e patapata. Nítorí bí ayé yìí ti ń rí yìí, ó ń kọjá lọ.

32 Ṣugbọn mo fẹ́ rí i pé ẹ kò ní ìpayà kan tí yóo mú ọkàn yín wúwo. Ẹni tí kò bá ní iyawo yóo máa páyà nípa nǹkan Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó wu Oluwa.

33 Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbeyawo yóo máa páyà nípa nǹkan ti ayé yìí, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ iyawo rẹ̀ lọ́rùn;

34 ọkàn rẹ̀ yóo pín sí meji. Obinrin tí kò bá lọ́kọ tabi obinrin tí ó bá jẹ́ wundia yóo máa páyà nípa nǹkan ti Oluwa, yóo máa wá ọ̀nà tí yóo fi ya ara ati ọkàn rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Oluwa. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ní ọkọ yóo máa páyà nípa àwọn nǹkan ayé, yóo máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.

35 Fún ire ara yín ni mo fi ń sọ èyí fun yín, kì í ṣe láti dín òmìnira yín kù. Ohun tí mò ń fẹ́ ni pé kí ẹ lè gbé irú ìgbé-ayé tí ó yẹ, kí ẹ lè fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ Oluwa, láìwo ọ̀tún tabi òsì.

36 Ṣugbọn bí ọkunrin kan bá rò pé òun ń ṣe ohun tí kò tọ́ pẹlu wundia àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí wundia náà bá ti dàgbà tó, tí ọkunrin náà kò bá lè mú ara dúró, kí ó ṣe igbeyawo bí ó bá fẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Kí wọ́n ṣe igbeyawo.

37 Ṣugbọn ẹni tí ó bá pinnu ninu ọkàn rẹ̀, tí kò sí ìdí tí ó fi gbọdọ̀ ṣe igbeyawo, bí ó bá lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun yóo jẹ́ kí wundia òun wà bí ó ti wà, nǹkan dáradára ni ó ṣe.

38 Ní gbolohun kan, ẹni tí ó bá gbé wundia rẹ̀ ní iyawo kò ṣe nǹkan burúkú. Ṣugbọn ẹni tí kò bá gbé e ní iyawo ni ó ṣe ohun tí ó dára jùlọ.

39 A ti so obinrin pọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti tún ní ọkọ mìíràn tí ó bá fẹ́. Ṣugbọn onigbagbọ nìkan ní ó lè fẹ́.

40 Ṣugbọn mo rò pé ó sàn fún un pupọ jùlọ tí ó bá dá wà. Mo sì rò pé èmi náà ní Ẹ̀mí Ọlọrun.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 8

Oúnjẹ Tí A Fi Rúbọ fún Oriṣa

1 Ó wá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a fi rúbọ fún oriṣa.

A mọ̀ pé, “Gbogbo wa ni a ní ìmọ̀,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn irú ìmọ̀ yìí a máa mú kí eniyan gbéraga, ṣugbọn ìfẹ́ ní ń mú kí eniyan dàgbà.

2 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun mọ nǹkankan, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò tíì mọ̀ tó bí ó ti yẹ.

3 Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn Ọlọrun, òun ni Ọlọrun mọ̀ ní ẹni tirẹ̀.

4 Nítorí náà nípa oúnjẹ tí a fi rúbọ fún oriṣa, a mọ̀ pé oriṣa kò jẹ́ nǹkankan ninu ayé. Ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi ọ̀kan ṣoṣo.

5 Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí à ń pè ní oriṣa wà, ìbáà ṣe ní ọ̀run tabi ní ayé, gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti pọ̀, tí “àwọn oluwa” tún pọ̀,

6 ṣugbọn ní tiwa, Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba, lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo nǹkan ti wá, ati lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ń lọ. Oluwa kan ni ó wà. Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí a dá gbogbo nǹkan, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá àwa náà.

7 Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó ní ìmọ̀ yìí. Nítorí àwọn mìíràn wà tí èèwọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà ti mọ́ lára tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé, bí wọn bá jẹ irú oúnjẹ yìí, bí ìgbà tí wọn ń bọ̀rìṣà ni. Nítorí wọn kò ní ẹ̀rí ọkàn tí ó lágbára, jíjẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àbùkù fún wọn.

8 Kì í ṣe oúnjẹ ni yóo mú wa dé iwájú Ọlọrun. Bí a kò bá jẹ, kò bù wá kù, bí a bá sì jẹ, kò mú kí á sàn ju bí a ti rí tẹ́lẹ̀ lọ.

9 Ṣugbọn ẹ ṣọ́ra kí òmìnira yín má di ohun tí yóo gbé àwọn aláìlera ṣubú.

10 Nítorí bí ẹnìkan tí ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ kò bá lágbára bá rí ìwọ tí o ní ìmọ̀ tí ò ń jẹun ní ilé oriṣa, ǹjẹ́ òun náà kò ní fi ìgboyà wọ inú ilé oriṣa lọ jẹun?

11 Àyọrísí rẹ̀ ni pé ìmọ̀ tìrẹ mú ìparun bá ẹni tí ó jẹ́ aláìlera, arakunrin tí Kristi ti ìtorí tirẹ̀ kú.

12 Ẹ̀ ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí àwọn arakunrin yín tí ó jẹ́ aláìlera, ẹ̀ ń dá ọgbẹ́ sí ọkàn wọn, ẹ sì ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi.

13 Nítorí náà, bí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni yóo bá gbé arakunrin mi ṣubú, n kò ní jẹ ẹran mọ́ laelae, kí n má baà ṣe ohun tí yóo gbé arakunrin mi ṣubú.

Categories
KỌRINTI KINNI

KỌRINTI KINNI 9

Iṣẹ́ ati Ẹ̀tọ́ Aposteli

1 Ṣebí mo ní òmìnira? Ṣebí aposteli ni mí? Ṣebí mo ti rí Jesu Oluwa wa sójú? Ṣebí àyọrísí iṣẹ́ mi ninu Oluwa ni yín?

2 Bí àwọn ẹlòmíràn kò bá tilẹ̀ gbà mí bí aposteli, ẹ̀yin gbọdọ̀ gbà mí ni, nítorí èdìdì iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ninu Kristi ni ẹ jẹ́.

3 Ìdáhùn mi nìyí fún àwọn tí wọn ń rí wí sí mi.

4 Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹ ati láti mu ni?

5 Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú aya lọ́wọ́ ninu ìrìn àjò wa gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli yòókù ati àwọn arakunrin Oluwa ati Peteru?

6 Àbí èmi ati Banaba nìkan ni a níláti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa?

7 Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú?

8 Kì í ṣe àpẹẹrẹ ti eniyan nìkan ni mo fi ń sọ nǹkan wọnyi. Ṣebí òfin náà sọ nípa nǹkan wọnyi.

9 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu Òfin Mose pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di ẹnu mààlúù tí o fi ń ṣiṣẹ́ lóko ọkà.” Ǹjẹ́ nítorí mààlúù ni Ọlọrun ṣe sọ èyí?

10 Tabi kò dájú pé nítorí tiwa ni ó ṣe sọ ọ́? Dájúdájú nítorí tiwa ni. Nítorí ó yẹ kí ẹni tí ń roko kí ó máa roko pẹlu ìrètí láti pín ninu ìkórè oko, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ó ń pa ọkà ní ìrètí láti pín ninu ọkà náà.

11 Nígbà tí a fúnrúgbìn nǹkan ẹ̀mí fun yín, ṣé ó pọ̀jù pé kí á kórè nǹkan ti ara lọ́dọ̀ yín?

12 Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ láti jẹ lára yín, ṣé ẹ̀tọ́ tiwa kò ju tiwọn lọ?

Ṣugbọn a kò lo anfaani tí a ní yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ à ń fara da ohun gbogbo kí á má baà fa ìdínà fún ìyìn rere Kristi.

13 Ẹ kò mọ̀ pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu Tẹmpili a máa jẹ lára ẹbọ, ati pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ a máa pín ninu nǹkan ìrúbọ tí ó wà lórí pẹpẹ?

14 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere.

15 Ṣugbọn n kò lo anfaani yìí rí. Kì í ṣe pé kí n lè lo anfaani yìí ni mo ṣe ń sọ ohun tí mò ń sọ yìí. Nítorí ó yá mi lára kí ń kúkú kú jù pé kí ẹnikẹ́ni wá sọ ọ̀nà ìṣògo mi di asán lọ.

16 Nítorí bí mo bá ń waasu ìyìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa fi ṣògo. Nítorí dandan ni ó jẹ́ fún mi. Bí n kò bá waasu ìyìn rere, mo gbé!

17 Nítorí bí ó bá jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti retí èrè níbẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ dandan ni mo fi ń ṣe é, iṣẹ́ ìríjú tí a fi sí ìtọ́jú mi ni.

18 Kí wá ni èrè mi? Mo ní ìtẹ́lọ́rùn pé mò ń waasu ìyìn rere lọ́fẹ̀ẹ́, n kò lo anfaani tí ó tọ́ sí mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere.

19 Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira ni mo wà, tí n kò sì sí lábẹ́ ẹnìkan, sibẹ mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo eniyan kí n lè mú ọpọlọpọ wọn wá sọ́dọ̀ Jesu.

20 Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn Juu, èmi a máa di Juu kí n lè jèrè wọn. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí ó gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sábẹ́ Òfin Mose, kí n lè jèrè àwọn tí ó gba ètò ti Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò gba ètò ti Òfin Mose fúnra mi.

21 Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose, èmi a máa fi ara mi sí ipò wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ka òfin Ọlọrun sí, pàápàá jùlọ òfin Kristi. Èmi a máa ṣe bẹ́ẹ̀ kí n lè jèrè àwọn tí kò gba ètò ti Òfin Mose.

22 Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi a di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Èmi a máa sọ ara mi di gbogbo nǹkan fún gbogbo eniyan, kí n lè gba àwọn kan ninu wọn là lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn.

23 Èmi a máa ṣe gbogbo nǹkan wọnyi nítorí ti ìyìn rere, kí n lè ní ìpín ninu ibukun rẹ̀.

24 Ṣebí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn tí ń sáré ìje ni ó ń sáré, ṣugbọn ẹnìkan ṣoṣo níí gba ẹ̀bùn. Ẹ sáré ní ọ̀nà tí ẹ óo fi rí ẹ̀bùn gbà.

25 Nítorí gbogbo àwọn tí ń sáré ìje a máa kó ara wọn ní ìjánu. Wọ́n ń ṣe èyí kí wọ́n lè gba adé tí yóo bàjẹ́. Ṣugbọn adé tí kò lè bàjẹ́ ni tiwa.

26 Nítorí náà, aré tí èmi ń sá kì í ṣe ìsákúsàá láìní ète. Èmi kì í máa kan ẹ̀ṣẹ́ tèmi ní ìkànkukàn, bí ẹni tí ń kan afẹ́fẹ́ lásán lẹ́ṣẹ̀ẹ́.

27 Ṣugbọn mò ń fi ìyà jẹ ara mi, mò ń kó ara mi ní ìjánu. Ìdí ni pé nígbà tí mo bá ti waasu fún àwọn ẹlòmíràn tán, kí èmi alára má baà di ẹni tí kò ní yege ninu iré-ìje náà.