Categories
KỌRINTI KEJI

KỌRINTI KEJI 10

Paulu Gbèjà Ara Rẹ̀

1 Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín.

2 Mo bẹ̀ yín, ẹ má ṣe jẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹlu ìgbójú, nítorí ó dá mi lójú pé mo lè ko àwọn kan, tí wọ́n sọ pé à ń hùwà bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa lójú.

3 Nítorí à ń gbé ìgbé-ayé wa ninu àìlera ti ara, ṣugbọn a kò jagun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa,

4 nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú,

5 ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu.

6 A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa.

7 Nǹkan ti òde ara nìkan ni ẹ̀ ń wò! Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún inú ara rẹ̀ rò wò, nítorí bí ó ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwa náà jẹ́.

8 Nítorí ojú kò tì mí bí mo bá ń ṣe ìgbéraga ní àṣejù nípa àṣẹ tí a ní, tí Oluwa fi fún mi, láti lè mu yín dàgbà ni, kì í ṣe láti fi bì yín ṣubú.

9 N kò fẹ́ kí ẹ rò pé mò ń fi àwọn ìwé tí mò ń kọ dẹ́rù bà yín.

10 Nítorí àwọn kan ń sọ pé, “Àwọn ìwé tí Paulu kọ jinlẹ̀, wọ́n sì le, ṣugbọn bí ẹ bá rí òun alára, bí ọlọ́kùnrùn ni ó rí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ta eniyan lára.”

11 Kí ẹni tí ó bá ń rò báyìí mọ̀ pé bí a ti jẹ́ ninu ọ̀rọ̀ tí a kọ sinu ìwé nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ náà ni a jẹ́ ninu iṣẹ́ wa nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín.

12 Nítorí a kò gbọdọ̀ da ara wa mọ́ àwọn kan tí wọn ń yin ara wọn, tabi kí á fara wé wọn. Fúnra wọn ni wọ́n ṣe òṣùnwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn ara wọn, àwọn tìkalára wọn náà ni wọ́n sì ń fi ara wọn wé. Wọn kò lóye.

13 Ṣugbọn ní tiwa, a kò ní lérí ju bí ó ti yẹ lọ. Òṣùnwọ̀n wa kò tayọ ààlà tí Ọlọrun ti pa sílẹ̀ fún wa, tí a fi mú ìyìn rere dé ọ̀dọ̀ yín.

14 Nítorí kì í ṣe pé a kọjá àyè wa nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, àwa ni a sì kọ́kọ́ mú ìyìn rere Kristi dé ọ̀dọ̀ yín.

15 A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbéraga pupọ ju bí ó ti yẹ lọ lórí iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. A ní ìrètí pé bí igbagbọ yín ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ipò wa pẹlu yín yóo máa ga sí i, gẹ́gẹ́ bí ààyè wa.

16 A óo wá mú ọ̀rọ̀ ìyìn rere kọjá ọ̀dọ̀ yín, láì ṣe ìgbéraga nípa iṣẹ́ tí ẹlòmíràn ti ṣe ní ààyè tirẹ̀.

17 Ṣugbọn ẹni tí yóo bá ṣe ìgbéraga, Oluwa ni kí ó fi ṣe ìgbéraga.

18 Kì í ṣe ẹni tí ó yin ara rẹ̀ ni ó yege, bíkòṣe ẹni tí Oluwa bá yìn.

Categories
KỌRINTI KEJI

KỌRINTI KEJI 11

Paulu ati Àwọn Aposteli Èké

1 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbà mí láyè kí n sọ̀rọ̀ díẹ̀ bí aṣiwèrè. Ẹ gbà mí láyè.

2 Mò ń jowú nítorí yín, bí Ọlọrun tií jowú. Nítorí èmi ni mo ṣe ètò láti fà yín fún Kristi bí ẹni fa wundia tí ó pé fún ọkọ rẹ̀.

3 Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ẹ̀tàn má wọ inú ọkàn yín, tí ẹ óo fi yà kúrò ninu òtítọ́ ati ọkàn kan tí ẹ fi wà ninu Kristi, bí ejò ti fi àrékérekè rẹ̀ tan Efa jẹ.

4 Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà.

5 N kò rò pé mo kéré sí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní “aposteli” pataki wọnyi!

6 Ọ̀rọ̀ lè má dùn lẹ́nu mi, ṣugbọn mo ní ìmọ̀, ní ọ̀nà gbogbo a ti mú kí èyí hàn si yín ninu ohun gbogbo.

7 Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni mo ṣẹ̀ tí mo fi ara mi sí ipò ìrẹ̀lẹ̀, kí ẹ lè ní ipò gíga? Àbí ẹ̀ṣẹ̀ ni, pé mo waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín láì gba nǹkankan lọ́wọ́ yín?

8 Mo fẹ́rẹ̀ jẹ àwọn ìjọ mìíràn run, tí mò ń gba owó lọ́wọ́ wọn láti ṣe iṣẹ́ fun yín.

9 Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo ṣe aláìní, n kò ni ẹnikẹ́ni lára, àwọn arakunrin tí ó wá láti Masedonia ni wọ́n mójútó àwọn ohun tí mo ṣe aláìní. Ninu gbogbo nǹkan, mo ṣe é lófin pé n kò ní wọ̀ yín lọ́rùn, n kò sì ní yí òfin yìí pada!

10 Gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ Kristi ti wà ninu mi, kò sí ohun tí yóo mú mi yipada ninu ohun tí mo fi ń ṣe ìgbéraga ní gbogbo agbègbè Akaya.

11 Nítorí kí ni? A máa ṣe pé n kò fẹ́ràn yín ni? Ọlọrun mọ̀ pé mo fẹ́ràn yín.

12 Bí mo ti ń ṣe ni n óo tún máa ṣe, kí n má baà fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéraga pé iṣẹ́ wọn dàbí tiwa.

13 Aposteli èké ni irú àwọn bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́tàn ni wọ́n, tí wọn ń farahàn bí aposteli Kristi.

14 Irú rẹ̀ kì í ṣe nǹkan ìjọjú, nítorí Satani pàápàá a máa farahàn bí angẹli ìmọ́lẹ̀.

15 Nítorí náà, kò ṣòro fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ láti farahàn bí iranṣẹ tòótọ́. Ṣugbọn ìgbẹ̀yìn wọn yóo rí bí iṣẹ́ wọn.

Ìjìyà Paulu ninu Iṣẹ́ Rẹ̀ Bí Aposteli

16 Mo tún wí lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé aṣiwèrè ni mí. Ṣugbọn bí ẹ bá rò bẹ́ẹ̀, ẹ sá gbà mí bí aṣiwèrè, kí n lè fọ́nnu díẹ̀.

17 N kò sọ̀rọ̀ bí onigbagbọ nípa ohun tí mo fi ń fọ́nnu yìí, bí aṣiwèrè ni mò ń sọ̀rọ̀.

18 Ọpọlọpọ ní ń fọ́nnu nípa nǹkan ti ara, ẹ jẹ́ kí èmi náà fọ́nnu díẹ̀!

19 Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi ń gba àwọn aṣiwèrè, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n!

20 Bí ẹnìkan bá ń lò yín bí ẹrú, tí ó ń jẹ yín run, tí ó fi okùn mu yín, tí ó ń ṣe fùkẹ̀ láàrin yín, tí ó ń gba yín létí, ẹ ṣetán láti gba irú ẹni bẹ́ẹ̀.

21 Ojú tì mí láti gbà pé àwa kò lágbára tó láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀!

Ṣugbọn bí ẹnìkan bá láyà láti fi ohun kan ṣe ìgbéraga, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè, èmi náà láyà láti ṣe ìgbéraga.

22 Ṣé Heberu ni wọ́n ni? Heberu ni èmi náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n? Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà. Ṣé ìdílé Abrahamu ni wọ́n? Òun ni èmi náà.

23 Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà.

24 Ẹẹmarun-un ni àwọn Juu nà mí ní ẹgba mọkandinlogoji.

25 Ẹẹmẹta ni a fi ọ̀pá lù mí. A sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan. Ẹẹmẹta ni ọkọ̀ ojú omi tí mo wọ̀ rì. Fún odidi ọjọ́ kan, tọ̀sán-tòru, ni mo fi wà ninu agbami.

26 Ní ọpọlọpọ ìgbà ni mo wà lórí ìrìn àjò, tí mo wà ninu ewu omi, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, ewu láàrin àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ mi, ewu láàrin àwọn tíí ṣe Juu, ewu ninu ìlú, ewu ninu oko, ewu lójú òkun, ati ewu láàrin àwọn èké onigbagbọ.

27 Mo ti rí ọ̀pọ̀ wahala ati ìṣòro. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kò lè sùn. Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò ń gbààwẹ̀. Mo mọ ìgbà òtútù ati ìgbà tí aṣọ kò tó láti fi bora.

28 Láì ka àwọn nǹkan mìíràn tí n kò mẹ́nubà, lojoojumọ ni àníyàn gbogbo àwọn ìjọ wúwo lọ́kàn mi.

29 Ta ni jẹ́ aláìlera tí n kò ní ìpín ninu àìlera rẹ̀? Ta ni ṣubú sinu ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkàn mi kò bàjẹ́?

30 Bí mo bá níláti fọ́nnu, n óo fọ́nnu nípa àwọn àìlera mi.

31 Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae, mọ̀ pé n kò purọ́.

32 Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ Ọba Areta ń ṣọ́ ẹnu odi ìlú láti mú mi.

33 Apẹ̀rẹ̀ ni wọ́n fi sọ̀ mí kalẹ̀ láti ojú fèrèsé lára odi ìlú, ni mo fi bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Categories
KỌRINTI KEJI

KỌRINTI KEJI 12

Àwọn Ìran Tí Paulu Rí

1 Ó yẹ kí n fọ́nnu. Rere kan kò ti ibẹ̀ wá, sibẹ n óo sọ ti ìran ati ìfarahàn Oluwa.

2 Mo mọ ọkunrin onigbagbọ kan ní ọdún mẹrinla sẹ́yìn. Bí ó wà ninu ara ni o, bí ó rí ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé ọkunrin yìí lọ sí ọ̀run kẹta.

3-4 Mo mọ ọkunrin yìí, bí ninu ara ni o, bí lójú ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé e lọ sí Paradise níbi tí ó gbé gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é sọ, ọ̀rọ̀ àṣírí tí kò gbọdọ̀ jáde lẹ́nu eniyan.

5 N óo fọ́nnu nípa irú ọkunrin bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ní fọ́nnu nípa ara tèmi ati nípa àwọn àìlera mi.

6 Bí mo bá fẹ́ fọ́nnu, kò ní jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè ni n óo sọ; òtítọ́ ni n óo sọ. Ṣugbọn n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má baà rò nípa mi ju ohun tí ó rí ninu ìwà mi ati ohun tí ó gbọ́ lẹ́nu mi lọ.

7 Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga.

8 Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi.

9 Ìdáhùn tí ó fún mi ni pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ. Ninu àìlera rẹ ni agbára mi di pípé.” Nítorí náà ninu àwọn ohun tí ó jẹ́ àìlera fún mi ni mo ní ayọ̀ pupọ jùlọ, àwọn ni n óo fi ṣe ìgbéraga, kí agbára Kristi lè máa bá mi gbé.

10 Nítorí èyí mo ní inú dídùn ninu àìlera mi, ati ninu àwọn ìwọ̀sí, ìṣòro, inúnibíni ati ìpọ́njú tí mo ti rí nítorí ti Kristi. Nítorí nígbà tì mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.

Paulu Ní Àníyàn fún Ìjọ Kọrinti

11 Mo ti di aṣiwèrè! Ẹ̀yin ni ẹ sì sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Nítorí ìyìn ni ó yẹ kí n gbà lọ́dọ̀ yín. Nítorí bí n kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkankan, n kò rẹ̀yìn ninu ohunkohun sí àwọn aposteli yín tí ẹ kà kún pataki.

12 Àwọn àmì aposteli hàn ninu iṣẹ́ mi láàrin yín nípa oríṣìíríṣìí ìfaradà, nípa iṣẹ́ abàmì, iṣẹ́ ìyanu, ati iṣẹ́ agbára.

13 Ọ̀nà wo ni a fi ba yín lò tí ó burú ju ti àwọn ìjọ ìyókù lọ; àfi ti pé èmi fúnra mi kò ni yín lára? Ẹ forí jì mí fún àṣìṣe yìí!

14 Ẹ wò ó! Ẹẹkẹta nìyí tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín. N kò sì ní ni yín lára. Nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan dúkìá yín ni mo fẹ́ bíkòṣe ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí kì í ṣe àwọn ọmọ ni ó yẹ láti pèsè fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí ni ó yẹ kí ó pèsè fún àwọn ọmọ.

15 Ní tèmi, pẹlu ayọ̀ ni ǹ bá fi náwó-nára patapata fún ire ọkàn yín. Bí èmi bá fẹ́ràn yín pupọ, ṣé díẹ̀ ni ó yẹ kí ẹ̀yin fẹ́ràn mi?

16 Ẹ gbà pé n kò ni yín lára. Ṣugbọn àwọn kan rò pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni mí, ati pé ẹ̀tàn ni mo fi mu yín.

17 Ninu àwọn tí mo rán si yín, èwo ni mo lò láti fi rẹ yín jẹ?

18 Mo bẹ Titu kí ó wá sọ́dọ̀ yín. Mo tún rán arakunrin wa pẹlu rẹ̀. Ǹjẹ́ Titu rẹ yín jẹ bí? Ṣebí Ẹ̀mí kan náà ni ó ń darí wa? Tabi kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni a jọ ń ṣiṣẹ́?

19 Ṣé ohun tí ẹ ti ń rò ni pé à ń wí àwíjàre níwájú yín? Rárá o! Níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ni à ń sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gbogbo nǹkan tí à ń ṣe, fún ìdàgbàsókè yín ni.

20 Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò.

21 Ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà tí mo bá tún dé, kí Ọlọrun mi má dójú tì mí níwájú yín, kí n má ní ìbànújẹ́ nítorí ọpọlọpọ tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí wọn kò ronupiwada kúrò ninu ìṣekúṣe, àgbèrè ati ìwà wọ̀bìà tí wọ́n ti ń hù.

Categories
KỌRINTI KEJI

KỌRINTI KEJI 13

Ìkìlọ̀ Ìgbẹ̀yìn

1 Ẹẹkẹta nìyí tí n óo wá sọ́dọ̀ yín. Lẹ́nu ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta ni a óo sì ti mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.

2 Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún àwọn tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ ati àwọn yòókù, tí mo tún sọ nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín lẹẹkeji, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń sọ nisinsinyii tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá tún dé, n kò ní ṣojú àánú;

3 nígbà tí ó ti jẹ́ pé ẹ̀rí ni ẹ̀ ń wá pé Kristi ń lò mí láti sọ̀rọ̀. Kristi kì í ṣe aláìlera ninu ìbálò rẹ̀ pẹlu yín.

4 Òtítọ́ ni pé a kàn án mọ́ agbelebu ní àìlera, ṣugbọn ó wà láàyè nípa agbára Ọlọrun. Òtítọ́ ni pé àwa náà jẹ́ aláìlera pẹlu rẹ̀, ṣugbọn a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀ nípa agbára Ọlọrun ninu ìbálò wa pẹlu yín.

5 Ẹ yẹ ara yín wò bí ẹ bá ń gbé ìgbé-ayé ti igbagbọ. Ẹ yẹ ara yín wò. Àbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ̀ pé Kristi Jesu wà ninu yín? Àfi bí ẹ bá ti kùnà nígbà tí ẹ yẹ ara yín wò!

6 Ṣugbọn mo ní ìrètí pé ẹ mọ̀ pé ní tiwa, àwa kò kùnà.

7 À ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ẹ má ṣe nǹkan burúkú kan, kì í ṣe pé nítorí kí á lè farahàn bí ẹni tí kò kùnà, ṣugbọn kí ẹ̀yin lè máa ṣe rere, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa dàbí ẹni tí ó kùnà.

8 Nítorí a kò lè ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí òtítọ́, àfi òtítọ́.

9 Nítorí náà inú wa dùn nígbà tí àwa bá jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára. Èyí ni à ń gbadura fún, pé kí ẹ tún ìgbé-ayé yín ṣe.

10 Ìdí tí mo fi ń kọ gbogbo nǹkan wọnyi nígbà tí n kò sí lọ́dọ̀ yín ni pé nígbà tí mo bá dé, kí n má baà fi ìkanra lo àṣẹ tí Oluwa ti fi fún mi láti fi mú ìdàgbà wá, kì í ṣe láti fi wo yín lulẹ̀.

Gbolohun Ìdágbére

11 Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ó dìgbà! Ẹ tún ọ̀nà yín ṣe. Ẹ gba ìkìlọ̀ wa. Ẹ ní ọkàn kan náà láàrin ara yín. Ẹ máa gbé pọ̀ ní alaafia. Ọlọrun ìfẹ́ ati alaafia yóo wà pẹlu yín.

12 Ẹ fi ìfẹnukonu ti alaafia kí ara yín. Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín.

13 Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi, ati ìfẹ́ Ọlọrun ati ìdàpọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu gbogbo yín.