Categories
JOHANU

JOHANU 20

Ajinde Jesu

1 Ní kutukutu ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́, Maria Magidaleni lọ sí ibojì náà, ó rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀.

2 Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”

3 Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn náà bá jáde, wọ́n lọ sí ibojì náà.

4 Àwọn mejeeji bẹ̀rẹ̀ sí sáré; ṣugbọn ọmọ-ẹ̀yìn keji ya Peteru sílẹ̀, òun ni ó kọ́ dé ibojì.

5 Ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì, ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ tí ó wà nílẹ̀, ṣugbọn kò wọ inú ibojì.

6 Nígbà tí Simoni Peteru tí ó tẹ̀lé e dé, ó wọ inú ibojì lọ tààrà. Ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ nílẹ̀,

7 ó rí aṣọ tí wọ́n fi wé orí òkú lọ́tọ̀, kò sí lára aṣọ-ọ̀gbọ̀, ó dá wà níbìkan ní wíwé.

8 Ọmọ-ẹ̀yìn keji tí ó kọ́kọ́ dé ẹnu ibojì náà bá wọ inú ibojì; òun náà rí i, ó wá gbàgbọ́.

9 (Nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kò tíì yé wọn pé dandan ni kí ó jí dìde ninu òkú.)

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá tún pada lọ sí ilé wọn.

Jesu Fara Han Maria Magidaleni

11 Ṣugbọn Maria dúró lóde lẹ́bàá ibojì, ó ń sunkún. Bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì,

12 ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí.

13 Wọ́n bi í pé, “Obinrin, kí ló dé tí ò ń sunkún?”

Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa mi lọ, n kò mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”

14 Bí ó ti sọ báyìí tán, ó bojú wẹ̀yìn, ó bá rí Jesu tí ó dúró, ṣugbọn kò mọ̀ pé òun ni.

15 Jesu bi í pé, “Obinrin, kí ní dé tí ò ń sunkún? Ta ni ò ń wá?”

Maria ṣebí olùṣọ́gbà ni. Ó sọ fún un pé, “Alàgbà, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, kí n lè lọ gbé e.”

16 Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!”

Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”)

17 Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ”

18 Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn.

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn

19 Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà, tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu, Jesu dé, ó dúró láàrin wọn. Ó kí wọn pé, “Alaafia fun yín!”

20 Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ hàn wọ́n.

21 Ó tún kí wọn pé, “Alaafia fún yín! Gẹ́gẹ́ bí baba ti rán mi níṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo rán yín.”

22 Lẹ́yìn tí ó sọ bẹ́ẹ̀ tán, ó mí sí wọn, ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́.

23 Àwọn ẹni tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun dáríjì wọ́n. Àwọn ẹni tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ọlọrun kò dáríjì wọ́n.”

Tomasi Kò Kọ́kọ́ Gbàgbọ́

24 Ṣugbọn Tomasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) kò sí láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí Jesu farahàn wọ́n.

25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ fún un pé, “Àwa ti rí Oluwa!”

Ṣugbọn ó sọ fún wọn pé, “Bí n kò bá rí àpá ìṣó ní ọwọ́ rẹ̀, kí n fi ìka mi kan ibi tí àpá ìṣó wọ̀n-ọn-nì wà, kí n fi ọwọ́ mi kan ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, n kò ní gbàgbọ́!”

26 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹjọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tún wà ninu ilé, Tomasi náà wà láàrin wọn. Ìlẹ̀kùn wà ní títì bẹ́ẹ̀ ni Jesu bá tún dé, ó dúró láàrin wọn, ó ní, “Alaafia fun yín!”

27 Ó wá wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá, wo ọwọ́ mi, mú ọwọ́ rẹ wá kí o fi kan ẹ̀gbẹ́ mi. Má ṣe alaigbagbọ mọ́, ṣugbọn gbàgbọ́.”

28 Tomasi dá a lóhùn pé, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”

29 Jesu wí fún un pé, “O wá gbàgbọ́ nítorí o rí mi! Àwọn tí ó gbàgbọ́ láì rí mi ṣe oríire!”

Èrèdí Ìwé Ìyìn Rere yìí

30 Ọpọlọpọ nǹkan ati iṣẹ́ abàmì mìíràn ni Jesu ṣe lójú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí a kò kọ sinu ìwé yìí.

31 Ṣugbọn a kọ ìwọ̀nyí kí ẹ lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun, ati pé tí ẹ bá gbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

Categories
JOHANU

JOHANU 21

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Meje

1 Lẹ́yìn èyí, Jesu tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní òkun Tiberiasi. Bí ó ṣe farahàn wọ́n nìyí:

2 Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan.

3 Simoni Peteru sọ fún wọn pé, “Mò ń lọ pa ẹja.”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa náà yóo bá ọ lọ.” Wọ́n bá jáde lọ, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà wọn kò rí ẹja kankan pa.

4 Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.

5 Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?”

Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!”

6 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀, ẹ óo rí ẹja pa.” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ni wọn kò bá lè fa àwọ̀n mọ́, nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.

7 Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté.

8 Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń bọ̀ ninu ọkọ̀, nítorí wọn kò jìnnà sí èbúté, wọn kò jù bí ìwọ̀n ọgọrun-un ìgbésẹ̀ lọ.

9 Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná eléèédú, wọ́n tún rí burẹdi.

10 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú wá ninu ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.”

11 Nígbà náà ni Simoni Peteru gòkè, ó fa àwọ̀n sí èbúté. Àwọ̀n náà kún fún ẹja ńláńlá, mẹtalelaadọjọ. Ṣugbọn bí wọ́n ti pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò ya.

12 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun.” Kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó bi í pé, “Ta ni ọ́?” Wọ́n mọ̀ pé Oluwa ni.

13 Jesu wá, ó mú burẹdi, ó fi fún wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó fún wọn ní ẹja jẹ.

14 Èyí ni ó di ìgbà kẹta tí Jesu fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lẹ́yìn ajinde rẹ̀ ninu òkú.

Jesu ati Peteru

15 Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jesu bi Simoni Peteru pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi ju àwọn wọnyi lọ?”

Peteru dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”

Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ aguntan mi.”

16 Jesu tún bi í lẹẹkeji pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?”

Ó tún dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”

Jesu wí fún un pé, “Máa tọ́jú àwọn aguntan mi.”

17 Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?”

Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”

Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi.

18 Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, ò ń di ara rẹ ni àmùrè gírí, ò ń lọ sí ibi tí o bá fẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá di arúgbó, ìwọ yóo na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíràn yóo wọ aṣọ fún ọ, yóo fà ọ́ lọ sí ibi tí o kò fẹ́ lọ.”

19 (Jesu sọ èyí bí àkàwé irú ikú tí Peteru yóo fi yin Ọlọrun lógo.) Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”

Jesu ati Ọmọ-Ẹ̀yìn Tí Ó Fẹ́ràn

20 Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?”

21 Nígbà tí Peteru rí i, ó bi Jesu pé, “Oluwa, eléyìí ńkọ́?”

22 Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́? Ìwọ sá máa tẹ̀lé mi ní tìrẹ.”

23 Nígbà tí gbolohun yìí dé etí àwọn onigbagbọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn náà kò ní kú. Ṣugbọn kò sọ fún un pé kò ní kú. Ohun tí ó wí ni pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́?”

24 Ọmọ-ẹ̀yìn náà ni ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi. Òun ni ó kọ nǹkan wọnyi: a mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.

Ìparí Ọ̀rọ̀

25 Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni Jesu ṣe, bí a bá kọ wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé kò ní sí ààyè tó ní gbogbo ayé tí yóo gba ìwé tí a bá kọ wọ́n sí.