Categories
JOHANU

JOHANU 10

Jesu Fi Aguntan Ṣe Àkàwé

1 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni.

2 Ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́-aguntan.

3 Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ.

4 Nígbà tí gbogbo àwọn aguntan rẹ̀ bá jáde, a máa lọ níwájú wọn, àwọn aguntan a sì tẹ̀lé e nítorí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.

5 Aguntan kò jẹ́ tẹ̀lé àlejò, sísá ni wọ́n máa ń sá fún un, nítorí wọn kò mọ ohùn àlejò.”

6 Òwe yìí ni Jesu fi bá wọn sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ń bá wọn sọ kò yé wọn.

Jesu Ni Olùṣọ́-Aguntan Rere

7 Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan.

8 Olè ati ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ṣiwaju mi. Ṣugbọn àwọn aguntan kò gbọ́ ti wọn.

9 Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ.

10 Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

11 “Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.

12 Alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́-aguntan, tí kì í sìí ṣe olówó aguntan, bí ó bá rí ìkookò tí ń bọ̀, a fi àwọn aguntan sílẹ̀, a sálọ. Ìkookò a gbé ninu àwọn aguntan lọ, a sì tú wọn ká,

13 nítorí alágbàṣe lásán ni, kò bìkítà fún àwọn aguntan.

14 Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Mo mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi náà sì mọ̀ mí,

15 gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi náà sì mọ Baba. Mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.

16 Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan.

17 “Ìdí rẹ̀ nìyí tí Baba fi fẹ́ràn mi nítorí mo ṣetán láti kú, kí n lè tún wà láàyè.

18 Ẹnikẹ́ni kò gba ẹ̀mí mi, ṣugbọn èmi fúnra mi ni mo yọ̀ǹda rẹ̀. Mo ní àṣẹ láti yọ̀ǹda rẹ̀, mo ní àṣẹ láti tún gbà á pada. Àṣẹ yìí ni mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

19 Ìyapa tún bẹ́ sáàrin àwọn Juu nítorí ọ̀rọ̀ yìí.

20 Ọpọlọpọ ninu wọn sọ pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ ti dàrú. Kí ni ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí?”

21 Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù lè la ojú afọ́jú?”

Àwọn Juu Kọ Jesu

22 Ní àkókò òtútù-nini, ó tó àkókò Àjọ̀dún Ìyàsímímọ́ Tẹmpili tí wọn ń ṣe ní Jerusalẹmu,

23 Jesu ń rìn kiri ní apá ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni ninu Tẹmpili.

24 Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.”

25 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi,

26 ṣugbọn ẹ kò gbàgbọ́, nítorí ẹ kò sí ninu àwọn aguntan mi.

27 Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi.

28 Mo fún wọn ní ìyè ainipẹkun, wọn kò lè kú mọ́ laelae, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè já wọn gbà mọ́ mi lọ́wọ́.

29 Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju ohun gbogbo lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè já a gbà mọ́ Baba mi lọ́wọ́.

30 Ọ̀kan ni èmi ati Baba mi.”

31 Àwọn Juu tún ṣa òkúta láti sọ lù ú.

32 Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?”

33 Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere ni a fi fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, nítorí ọ̀rọ̀ àfojúdi tí o sọ sí Ọlọrun ni; nítorí pé ìwọ tí ó jẹ́ eniyan sọ ara rẹ di Ọlọrun.”

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’

35 Ìwé Mímọ́ kò ṣe é parẹ́. Bí Ọlọrun bá pe àwọn tí ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ní ọlọ́run,

36 kí ló dé tí ẹ fi sọ pé mò ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí mo wí pé, ‘Ọmọ Ọlọrun ni mí,’ èmi tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó rán wá sí ayé?

37 Bí n kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.

38 Ṣugbọn bí mo bá ń ṣe é, èmi kọ́ ni kí ẹ gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni kí ẹ gbàgbọ́. Èyí yóo jẹ́ kí ẹ wòye, kí ẹ wá mọ̀ pé Baba wà ninu mi, ati pé èmi náà wà ninu Baba.”

39 Nígbà náà ni wọ́n tún ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ó jáde kúrò ní àrọ́wọ́tó wọn.

40 Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀.

41 Ọpọlọpọ eniyan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, ṣugbọn gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkunrin yìí ni ó rí bẹ́ẹ̀.”

42 Ọpọlọpọ eniyan bá gbà á gbọ́ níbẹ̀.

Categories
JOHANU

JOHANU 11

Ikú Lasaru

1 Ọkunrin kan tí ń jẹ́ Lasaru ń ṣàìsàn. Ní Bẹtani ni ó ń gbé, ní ìlú kan náà pẹlu Maria ati Mata arabinrin rẹ̀.

2 Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí.

3 Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.”

4 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.”

5 Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru.

6 Nígbà tí Jesu gbọ́ pé Lasaru ń ṣàìsàn, kò kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ meji.

7 Lẹ́yìn náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á tún pada lọ sí Judia.”

8 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, láìpẹ́ yìí ni àwọn Juu ń fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta, o tún fẹ́ lọ sibẹ?”

9 Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran.

10 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá ń rìn lálẹ́ níí kọsẹ̀, nítorí kò sí ìmọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.”

11 Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó sọ fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti sùn, mò ń lọ jí i.”

12 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, bí ó bá sùn, yóo tún jí.”

13 Ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ bá ni ikú Lasaru, ṣugbọn wọ́n rò pé nípa oorun sísùn ni ó ń sọ.

14 Nígbà náà ni Jesu wá wí fún wọn pàtó pé, “Lasaru ti kú.

15 Ó dùn mọ́ mi nítorí yín pé n kò sí níbẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”

16 Nígbà náà ni Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Ìbejì”) sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kí àwa náà lè bá a kú.”

Jesu Ni Ajinde ati Ìyè

17 Nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé ó ti tó ọjọ́ mẹrin tí òkú náà ti wà ninu ibojì.

18 Bẹtani kò jìnnà sí Jerusalẹmu, kò ju ibùsọ̀ meji lọ.

19 Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ni wọ́n wá láti Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Mata ati Maria láti tù wọ́n ninu nítorí ikú arakunrin wọn.

20 Nígbà tí Mata gbọ́ pé Jesu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀. Ṣugbọn Maria jókòó ninu ilé.

21 Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú!

22 Ṣugbọn nisinsinyii náà, mo mọ̀ pé ohunkohun tí o bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo ṣe é fún ọ.”

23 Jesu wí fún un pé, “Arakunrin rẹ yóo jí dìde.”

24 Mata dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé yóo jí dìde ní ajinde ọjọ́ ìkẹyìn.”

25 Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè.

26 Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?”

27 Ó dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, mo gbàgbọ́ pé ìwọ ni Mesaya Ọmọ Ọlọrun tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.”

Jesu Abánidárò

28 Nígbà tí Mata ti sọ báyìí tán, ó lọ pe Maria arabinrin rẹ̀ sí ìkọ̀kọ̀. Ó ní, “Olùkọ́ni ti dé, ó ń pè ọ́.”

29 Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu.

30 (Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.)

31 Nígbà tí àwọn Juu tí ó wà ninu ilé pẹlu Maria, tí wọn ń tù ú ninu, rí i pé ó sáré dìde, ó jáde, àwọn náà tẹ̀lé e, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti lọ sunkún ni.

32 Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”

33 Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́.

34 Ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?”

Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wá wò ó.”

35 Ni Jesu bá bú sẹ́kún.

36 Nígbà náà ni àwọn Juu sọ pé, “Ẹ ò rí i bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”

37 Àwọn kan ninu wọn ń sọ pé, “Ọkunrin yìí tí ó la ojú afọ́jú, ǹjẹ́ kò lè ṣe é kí ọkunrin yìí má fi kú?”

Lasaru Tún Di Alààyè

38 Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀.

39 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.”

Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!”

40 Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.”

41 Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi.

42 Mo mọ̀ pé nígbà gbogbo ni ò ń gbọ́ tèmi, ṣugbọn nítorí ti àwọn eniyan tí ó dúró yíká ni mo ṣe sọ èyí kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni o rán mi níṣẹ́.”

43 Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó kígbe sókè pé, “Lasaru, jáde wá!”

44 Ẹni tí ó ti kú náà bá jáde pẹlu aṣọ òkú tí wọ́n fi wé e lọ́wọ́ ati lẹ́sẹ̀ ati ọ̀já tí wọ́n fi dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, kí ẹ jẹ́ kí ó máa lọ.”

Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu

45 Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu tí ó wá sọ́dọ̀ Maria gba Jesu gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣe.

46 Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi, wọ́n lọ sọ ohun gbogbo tí Jesu ṣe.

47 Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi bá pe ìgbìmọ̀, wọ́n ní, “Kí ni a óo ṣe o, nítorí ọkunrin yìí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu pupọ?

48 Bí a bá fi í sílẹ̀ báyìí, gbogbo eniyan ni yóo gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóo bá wá, wọn yóo wo Tẹmpili yìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo pa orílẹ̀-èdè wa run.”

49 Nígbà náà ni ọ̀kan ninu wọn, Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà, sọ fún wọn pé, “Ẹ kò mọ nǹkankan!

50 Ẹ kò rí i pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún àwọn eniyan jù pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè ṣègbé!”

51 Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn.

52 Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan.

53 Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu.

54 Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

55 Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ti àwọn Juu, ọ̀pọ̀ eniyan gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti ìgbèríko, kí ó tó tó àkókò àjọ̀dún, kí wọ́n lè ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àjọ̀dún náà.

56 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Jesu, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti dúró ninu Tẹmpili pé, “Kí ni ẹ rò? Ǹjẹ́ ó jẹ́ wá sí àjọ̀dún yìí?”

57 Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.

Categories
JOHANU

JOHANU 12

Maria Tú Òróró Dà Sára Jesu ní Bẹtani

1 Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde.

2 Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun.

3 Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé.

4 Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, sọ pé,

5 “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka,kí á pín in fún àwọn talaka?”

6 Kì í ṣe nítorí pé ó bìkítà fún àwọn talaka ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ olè ni. Òun ni akápò; a máa jí ninu owó tí wọn bá fi pamọ́.

7 Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi.

8 Nígbà gbogbo ni àwọn talaka wà lọ́dọ̀ yín, ṣugbọn èmi kò ní sí lọ́dọ̀ yín nígbà gbogbo.”

Ọ̀tẹ̀ láti Pa Lasaru

9 Nígbà tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu mọ̀ pé Jesu wà ní Bẹtani, wọ́n lọ sibẹ, kì í ṣe nítorí ti Jesu nìkan, ṣugbọn nítorí kí wọ́n lè rí Lasaru tí Jesu jí dìde kúrò ninu òkú.

10 Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru,

11 nítorí pé nítorí rẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn Juu ṣe ń kúrò ninu ẹ̀sìn wọn, tí wọn ń gba Jesu gbọ́.

Jesu Wọ Jerusalẹmu Pẹlu Ẹ̀yẹ

12 Ní ọjọ́ keji, ọpọlọpọ eniyan tí ó wá ṣe àjọ̀dún gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu.

13 Wọ́n bá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n ń kígbe pé, “Hosana! Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Oluwa ati ọba Israẹli.”

14 Jesu rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó bá gùn un, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,

15 “Má bẹ̀rù mọ́, ọdọmọbinrin Sioni,

Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,

ó gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

16 Gbogbo nǹkan wọnyi kò yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò yìí, ṣugbọn nígbà tí a ti ṣe Jesu lógo, wọ́n ranti pé a ti kọ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀ ati pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí i.

17 Àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu Jesu nígbà tí ó fi pe Lasaru jáde kúrò ninu ibojì, tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú, ń ròyìn ohun tí wọ́n rí.

18 Nítorí èyí ni àwọn eniyan ṣe lọ pàdé rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí.

19 Àwọn Farisi bá ń bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jókòó lásán ni! Òfo ni gbogbo làálàá yín já sí! Ẹ kò rí i pé gbogbo eniyan ni wọ́n ti tẹ̀lé e tán!”

Àwọn Giriki Fẹ́ Rí Jesu

20 Àwọn Giriki mélòó kan wà ninu àwọn tí ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn ní àkókò àjọ̀dún náà.

21 Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”

22 Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu.

23 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo.

24 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹyọ irúgbìn kan kò bá bọ́ sílẹ̀, kí ó kú, òun nìkan ni yóo dá wà. Ṣugbọn bí ó bá kú, á mú ọpọlọpọ èso wá.

25 Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ̀ yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ ní ayé yìí yóo pa á mọ́ títí di ìyè ainipẹkun.

26 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ iranṣẹ mi, ó níláti tẹ̀lé mi. Níbi tí èmi alára bá wà, níbẹ̀ ni iranṣẹ mi yóo wà. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ iranṣẹ mi, Baba mi yóo dá a lọ́lá.”

A Níláti Gbé Ọmọ-Eniyan Sókè

27 Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé.

28 Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.”

Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.”

29 Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan tí wọ́n dúró, tí wọ́n gbọ́, ń sọ pé, “Ààrá sán!” Àwọn ẹlòmíràn ń sọ pé, “Angẹli ló bá a sọ̀rọ̀.”

30 Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín.

31 Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde.

32 Ní tèmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò láyé, n óo fa gbogbo eniyan sọ́dọ̀ mi.”

33 Ó sọ èyí, ó fi ṣe àkàwé irú ikú tí yóo kú.

34 Àwọn eniyan bi í pé, “A gbọ́ ninu òfin pé Mesaya wà títí lae. Kí ni ìtumọ̀ ohun tí o sọ pé dandan ni kí á gbé Ọmọ-Eniyan sókè? Ta ni ń jẹ́ Ọmọ-Eniyan?”

35 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ.

36 Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.”

Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn.

Àwọn Juu Kò Gbàgbọ́

37 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́.

38 Èyí mú kí ọ̀rọ̀ wolii Aisaya ṣẹ nígbà tí ó sọ pé,

“Oluwa, ta ni ó gba ìròyìn wa gbọ́?

Ta ni a fi agbára Oluwa hàn fún?”

39 Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Aisaya tún sọ pé,

40 “Ojú wọn ti fọ́,

ọkàn wọn sì ti le;

kí wọn má baà fi ojú wọn ríran,

kí òye má baà yé wọn.

Kí wọn má baà yipada,

kí n má baà wò wọ́n sàn.”

41 Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.

42 Sibẹ ọpọlọpọ ninu àwọn aṣaaju gbà á gbọ́; ṣugbọn wọn kò jẹ́wọ́ nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Farisi, kí wọn má baà yọ wọ́n kúrò ninu àwùjọ;

43 nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ.

Ọ̀rọ̀ Jesu ń dá Eniyan lẹ́jọ́

44 Jesu bá kígbe pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, kì í ṣe èmi ni ó gbàgbọ́ bíkòṣe ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

45 Ẹni tí ó bá rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi.

46 Mo wá sinu ayé bí ìmọ́lẹ̀, kí ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ má baà wà ninu òkùnkùn.

47 Bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò bá pa á mọ́, èmi kò ní dá a lẹ́jọ́, nítorí n kò wá sí ayé láti ṣe ìdájọ́, ṣugbọn mo wá láti gba aráyé là.

48 Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, ó ní ohun tí yóo dá a lẹ́jọ́, ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ni yóo dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn.

49 Nítorí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ti ara mi ni mò ń sọ, bíkòṣe ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́, tí ó ti fún mi ní àṣẹ ohun tí n óo sọ ati ohun tí n óo wí.

50 Mo mọ̀ pé òfin rẹ̀ ń tọ́ni sí ìyè ainipẹkun. Nítorí náà, bí Baba ti sọ fún mi pé kí n wí, bẹ́ẹ̀ gan-an ni mò ń sọ.”

Categories
JOHANU

JOHANU 13

Jesu Wẹ Ẹsẹ̀ Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀

1 Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin.

2 Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.

3 Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ.

4 Ó bá dìde nídìí oúnjẹ, ó bọ́ agbádá rẹ̀ sílẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó lọ́ ọ mọ́ ìbàdí,

5 ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀.

6 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?”

7 Jesu dá a lóhùn pé, “O kò mọ ohun tí mò ń ṣe nisinsinyii; ṣugbọn yóo yé ọ tí ó bá yá.”

8 Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!”

Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.”

9 Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.”

10 Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.”

11 Ó ti mọ ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́; nítorí náà ni ó ṣe sọ pé, “Kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.”

12 Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín?

13 Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.

14 Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín.

15 Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe.

16 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé: ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ, iranṣẹ kò ju ẹni tí ó rán an níṣẹ́ lọ.

17 Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.

18 “Gbogbo yín kọ́ ni ọ̀rọ̀ mi yìí kàn. Mo mọ àwọn tí mo yàn. Ṣugbọn Ìwé Mímọ́ níláti ṣẹ tí ó sọ pé, ‘Ẹni tí ó ń bá mi jẹun ni ó ń jìn mí lẹ́sẹ̀.’

19 Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán.

20 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”

Jesu Sọ Ẹni Tí Yóo fi Òun fún Àwọn Ọ̀tá

21 Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”

22 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú.

23 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí.

24 Simoni Peteru bá ṣẹ́jú sí i pé kí ó bèèrè pé ta ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.

25 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”

26 Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu.

27 Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.”

28 Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un.

29 Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”

30 Lẹsẹkẹsẹ tí Judasi ti gba òkèlè náà tán, ó jáde lọ. Ilẹ̀ ti ṣú nígbà náà.

Òfin Titun

31 Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan.

32 Bí ògo Ọlọrun bá wá yọ lára rẹ̀, Ọlọrun fúnrarẹ̀ yóo mú kí ògo Ọmọ-Eniyan yọ; lọ́gán ni yóo mú kí ògo rẹ̀ yọ.

33 Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii.

34 Òfin titun ni mo fi fun yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín ni kí ẹ fẹ́ràn ara yín.

35 Èyí ni yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóo Sẹ́ Òun

36 Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?”

Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.”

37 Peteru bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí n kò lè tẹ̀lé ọ nisinsinyii? Mo ṣetán láti kú nítorí rẹ.”

38 Jesu dá a lóhùn pé, “O ṣetán láti kú nítorí mi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, kí àkùkọ tó kọ ìwọ óo sẹ́ mi lẹẹmẹta.

Categories
JOHANU

JOHANU 14

Jesu Ni Ọ̀nà Dé Ọ̀dọ̀ Baba

1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ẹ gba Ọlọrun gbọ́, kí ẹ sì gba èmi náà gbọ́.

2 Yàrá pupọ ni ó wà ninu ilé Baba mi. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ n óo sọ fun yín pé mò ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín?

3 Bí mo bá lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín, n óo tún pada wá láti mu yín lọ sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ lè wà níbi tí èmi pàápàá bá wà.

4 Ẹ kúkú ti mọ ọ̀nà ibi tí mò ń lọ.”

5 Tomasi wí fún un pé, “Oluwa, a kò mọ ibi tí ò ń lọ, báwo ni a ti ṣe lè mọ ọ̀nà ibẹ̀?”

6 Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.

7 Bí ẹ bá ti mọ̀ mí, ẹ óo mọ Baba mi. Láti àkókò yìí, ẹ ti mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”

8 Filipi sọ fún un pé, “Oluwa, fi Baba hàn wá, èyí náà sì tó wa.”

9 Jesu wí fún un pé, “Bí mo ti pẹ́ lọ́dọ̀ yín tó yìí, sibẹ ìwọ kò mọ̀ mí, Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi ti rí Baba. Kí ló dé tí o fi tún ń sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá?’

10 Àbí o kò gbàgbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi ni? Èmi fúnra mi kọ́ ni mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fun yín. Baba tí ó ń gbé inú mi ni ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

11 Ẹ gbà mí gbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí iṣẹ́ wọnyi.

12 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

13 Èmi yóo ṣe ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi, kí ògo Baba lè yọ lára Ọmọ.

14 Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ miní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é.

Jesu Ṣèlérí pé Ẹ̀mí Mímọ́ yóo Wá

15 “Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́.

16 N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae.

17 Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín.

18 “Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín.

19 Láìpẹ́, ayé kò ní rí mi mọ́, ṣugbọn ẹ̀yin yóo rí mi. Nítorí èmi wà láàyè, ẹ̀yin náà yóo wà láàyè.

20 Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin yóo mọ̀ pé èmi wà ninu Baba mi, ati pé ẹ̀yin wà ninu mi, èmi náà sì wà ninu yín.

21 “Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.”

22 Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?”

23 Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé.

24 Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.

25 “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ yín.

26 Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín.

27 “Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín.

28 Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ.

29 Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè gbàgbọ́ nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán.

30 N kò tún ní ohun pupọ ba yín sọ mọ́, nítorí aláṣẹ ayé yìí ń bọ̀. Kò ní agbára kan lórí mi.

31 Ṣugbọn kí ayé lè mọ̀ pé mo fẹ́ràn Baba ni mo ṣe ń ṣe bí Baba ti pàṣẹ fún mi.

“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á kúrò níhìn-ín.

Categories
JOHANU

JOHANU 15

Jesu Ni Igi Àjàrà

1 “Èmi ni àjàrà tòótọ́. Baba mi ni àgbẹ̀ tí ń mójútó ọgbà àjàrà.

2 Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ.

3 Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín.

4 Ẹ máa gbé inú mi, èmi óo máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ àfi bí ó bá wà lára igi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò lè so èso àfi bí ẹ bá ń gbé inú mi.

5 “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi.

6 Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná.

7 Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà.

8 Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

9 Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi.

10 Bí ẹ bá pa òfin mi mọ́, ẹ óo máa gbé inú ìfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì ń gbé inú ìfẹ́ rẹ̀.

11 “Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

12 Àṣẹ mi nìyí; ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.

13 Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

14 Ọ̀rẹ́ mi ni yín bí ẹ bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín.

15 N kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́, nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Ṣugbọn mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Baba mi ni mo ti fihàn yín.

16 Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi.

17 Àṣẹ yìí ni mo pa fun yín: ẹ fẹ́ràn ara yín.

Ọmọ-Aráyé Yóo Kórìíra Yín

18 “Bí aráyé bá kórìíra yín, kí ẹ mọ̀ pé èmi ni wọ́n kọ́ kórìíra ṣáájú yín.

19 Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín.

20 Ẹ ranti ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín, pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ kò ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ṣe inúnibíni mi, wọn yóo ṣe inúnibíni yín. Bí wọ́n bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóo pa ti ẹ̀yin náà mọ́.

21 Wọn yóo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi si yín nítorí tèmi, nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

22 Bí n kò bá wá láti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọn kò ní àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

23 Ẹni tí ó bá kórìíra mi, kórìíra Baba mi.

24 Bí n kò bá ṣe irú iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi, sibẹ wọ́n kórìíra èmi ati Baba mi.

25 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ ninu Òfin wọn lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’

26 “Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi.

27 Ẹ̀yin náà yóo sì jẹ́rìí mi nítorí ẹ ti wà pẹlu mi láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi.

Categories
JOHANU

JOHANU 16

1 “Mo sọ gbogbo nǹkan yìí fun yín kí igbagbọ yín má baà yẹ̀.

2 Wọn yóo le yín jáde kúrò ninu ilé ìpàdé wọn. Èyí nìkan kọ́, àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé ẹni tí ó bá ṣe ikú pa yín yóo rò pé òun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọrun ni.

3 Wọn yóo ṣe nǹkan wọnyi nítorí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.

4 Ṣugbọn mo ti sọ gbogbo nǹkan wọnyi fun yín, kí ẹ lè ranti pé mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó bá yá, tí wọn bá ń ṣe é si yín.

Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́

“N kò sọ àwọn nǹkan wọnyi fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nítorí mo wà lọ́dọ̀ yín.

5 Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’

6 Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín.

7 Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín.

8 Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun.

9 Wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé wọn kò gbà mí gbọ́.

10 Wọ́n ṣìnà ní ti òdodo nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ kò sì ní rí mi mọ́.

11 Wọ́n ṣìnà ní ti ìdájọ́ nítorí pé Ọlọrun ti dá aláṣẹ ayé yìí lẹ́bi.

12 “Ọ̀rọ̀ tí mo tún fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn ọkàn yin kò lè gbà á ní àkókò yìí.

13 Ṣugbọn nígbà tí Ẹ̀mí òtítọ́ tí mo wí bá dé, yóo tọ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo. Nítorí kò ní sọ ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀; gbogbo ohun tí ó bá gbọ́ ni yóo sọ. Yóo sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fun yín.

14 Yóo fi ògo mi hàn nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo ti gba àwọn ohun tí yóo sọ fun yín.

15 Tèmi ni ohun gbogbo tí Baba ní. Ìdí nìyí ti mo ṣe sọ pé ohun tí ó bá gbà láti ọ̀dọ̀ mi ni yóo sọ fun yín.

Ìbànújẹ́ Yóo Di Ayọ̀

16 “Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.”

17 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Kí ni ìtumọ̀ ohun tí ó wí fún wa yìí, ‘Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi?’ Kí tún ni ìtumọ̀, ‘Nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?’ ”

18 Wọ́n tún ń sọ pé, “Kí ni ìtumọ̀ ‘Láìpẹ́’ tí ó ń wí yìí? Ohun tí ó ń sọ kò yé wa.”

19 Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’

20 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ óo sunkún, ẹ óo ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn inú aráyé yóo dùn. Ẹ óo dààmú ṣugbọn ìdààmú yín yóo di ayọ̀.

21 Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé.

22 Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín.

23 “Ní ọjọ́ náà, ẹ kò ní bi mí léèrè ohunkohun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, yóo fun yín.

24 Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

Jesu Ti Ṣẹgun Ayé

25 “Bí òwe bí òwe ni mo ti ń sọ àwọn nǹkan yìí fun yín. Ṣugbọn àkókò ń bọ̀ nígbà tí n kò ní fi òwe ba yín sọ̀rọ̀ mọ́, kedere ni n óo máa sọ̀rọ̀ nípa Baba fun yín nígbà náà.

26 Ní ọjọ́ náà, ẹ óo bèèrè nǹkan ní orúkọ mi, n kò ní wí fun yín pé èmi yóo ba yín bẹ Baba.

27 Nítorí Baba fúnrarẹ̀ fẹ́ràn yín nítorí pé ẹ̀yin náà fẹ́ràn mi, ẹ ti gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá.

28 Mo wá láti ọ̀dọ̀ Baba, mo jáde wá sinu ayé, n óo tún fi ayé sílẹ̀ láti lọ sọ́dọ̀ Baba.”

29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Kedere ni ò ń sọ̀rọ̀ nisinsinyii, o kò sọ̀rọ̀ lówe lówe mọ́.

30 A wá mọ̀ wàyí pé o mọ ohun gbogbo, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí eniyan bá bi ọ́ kí o tó dáhùn ọ̀rọ̀. Nítorí náà, a gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni o ti wá.”

31 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wá gbàgbọ́ nisinsinyii?

32 Àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ ti dé, nígbà tí ẹ óo túká, tí olukuluku yín yóo lọ sí ilé rẹ̀, tí ẹ óo fi èmi nìkan sílẹ̀. Ṣugbọn kò ní jẹ́ èmi nìkan nítorí Baba wà pẹlu mi.

33 Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ẹ lè ní alaafia nípa wíwà ninu mi. Ẹ óo ní ìpọ́njú ninu ayé, ṣugbọn ẹ ṣe ara gírí, mo ti ṣẹgun ayé.”

Categories
JOHANU

JOHANU 17

Adura Jesu

1 Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ.

2 Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un.

3 Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́.

4 Èmi ti fi ògo fún ọ ninu ayé, mo ti parí iṣẹ́ tí o fún mi ṣe.

5 Nisinsinyii, Baba, jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára mi; àní kí irú ògo tí mo ti ní pẹlu rẹ kí a tó dá ayé tún hàn lára mi.

6 “Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.

7 Nisinsinyii ó ti yé wọn pé láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo tí o fún mi ti wá.

8 Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o fún mi ni mo ti fún wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó ti wá yé wọn pé nítòótọ́, láti ọ̀dọ̀ rẹ ni mo ti wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.

9 “Àwọn ni mò ń gbadura fún, n kò gbadura fún aráyé; ṣugbọn mò ń gbadura fún àwọn tí o ti fún mi, nítorí tìrẹ ni wọ́n.

10 Ohun gbogbo tí mo ní, tìrẹ ni; ohun gbogbo tí ìwọ náà sì ní, tèmi ni. Wọ́n ti jẹ́ kí ògo mi yọ.

11 Èmi kò ní sí ninu ayé mọ́, ṣugbọn àwọn wà ninu ayé. Èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan.

12 Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, mo fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́. Mo pa wọ́n mọ́, ọ̀kan ninu wọn kò ṣègbé àfi ọmọ ègbé, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.

13 Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn.

14 Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé.

15 N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù.

16 Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé.

17 Fi òtítọ́ yà wọ́n sí mímọ́ fún ara rẹ; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.

18 Gẹ́gẹ́ bí o ti rán mi sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni mo rán wọn lọ sinu ayé.

19 Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́.

20 “N kò gbadura fún àwọn wọnyi nìkan. Ṣugbọn mo tún ń gbadura fún àwọn tí yóo gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn,

21 pé kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan. Mo gbadura pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ninu mi, tí èmi náà sì wà ninu rẹ, kí àwọn náà lè wà ninu wa, kí ayé lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.

22 Ògo tí o fi fún mi ni mo fi fún wọn, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti jẹ́ ọ̀kan;

23 èmi ninu wọn ati ìwọ ninu mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, kí ayé lè mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́, ati pé o fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́ràn mi.

24 “Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.

25 Baba mímọ́, ayé kò mọ̀ ọ́, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́, ó ti yé àwọn wọnyi pé ìwọ ni ó rán mi níṣẹ́.

26 Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.”

Categories
JOHANU

JOHANU 18

Àwọn Ọ̀tá Mú Jesu

1 Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

2 Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, mọ ibẹ̀, nítorí ìgbà pupọ ni Jesu ti máa ń lọ sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

3 Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà.

4 Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”

5 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”

Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.”

Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn.

6 Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀.

7 Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”

Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”

8 Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.”

9 (Kí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Ọ̀kan kan kò ṣègbé ninu àwọn tí o ti fi fún mi.”)

10 Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ó ní idà kan fà á yọ, ó bá ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó gé e létí ọ̀tún. Maliku ni orúkọ ẹrú náà.

11 Jesu bá sọ fún Peteru pé, “Ti idà rẹ bọ inú àkọ̀. Àbí kí n má jẹ ìrora ńlá tí Baba ti yàn fún mi ni?”

Wọ́n Mú Jesu lọ siwaju Anasi

12 Ni àwọn ọmọ-ogun ati ọ̀gágun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn Juu bá mú Jesu, wọ́n dè é,

13 wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Anasi tíí ṣe baba iyawo Kayafa, tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ní ọdún náà.

14 Kayafa yìí ni ó fi ìmọ̀ràn fún àwọn Juu pé ó sàn kí ẹnìkan kú fún gbogbo eniyan.

Peteru Sẹ́ Jesu

15 Ṣugbọn Simoni Peteru ń tẹ̀lé Jesu pẹlu ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn. Ọmọ-ẹ̀yìn keji yìí jẹ́ ẹni tí Olórí Alufaa mọ̀.

16 Ṣugbọn Peteru dúró lóde lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn keji tí Olórí Alufaa mọ̀ jáde, ó bá mú Peteru wọ agbo-ilé.

17 Nígbà náà ni ọmọge tí ó ń ṣọ́nà sọ fún Peteru pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkunrin yìí ni ọ́?”

Peteru dáhùn pé, “Rárá o!”

18 Àwọn ẹrú ati àwọn ẹ̀ṣọ́ jọ dúró ní àgbàlá, wọ́n ń yáná tí wọ́n fi èédú dá, nítorí òtútù mú. Peteru náà dúró lọ́dọ̀ wọn, òun náà ń yáná.

Anasi Bi Jesu nípa Ẹ̀kọ́ Rẹ̀

19 Olórí Alufaa bi Jesu nípa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀.

20 Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀.

21 Kí ni ò ń bi mí sí? Bi àwọn tí ó ti gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn; wọ́n mọ ohun tí mo sọ.”

22 Bí ó ti sọ báyìí tán ni ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó dúró níbẹ̀ bá gbá Jesu létí, ó ní, “Olórí Alufaa ni o dá lóhùn bẹ́ẹ̀!”

23 Jesu dá a lóhùn pé, “Bí burúkú ni mo bá sọ, wí ohun tí ó burú níbẹ̀ kí ayé gbọ́. Tí ó bá jẹ́ rere ni mo sọ, kí ló dé tí o fi lù mí?”

24 Nígbà náà ni Anasi fi Jesu ranṣẹ ní dídè sí Kayafa, Olórí Alufaa.

Peteru Tún Sẹ́ Jesu

25 Simoni Peteru wà níbi tí ó dúró, tí ó ń yáná. Wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́?”

Ó sẹ́, ó ní, “Rárá o!”

26 Ọ̀kan ninu àwọn ẹrú Olórí Alufaa, tí ó jẹ́ ẹbí ẹni tí Peteru gé létí bi Peteru pé, “Ǹjẹ́ n kò rí ọ ninu ọgbà pẹlu rẹ̀?”

27 Peteru tún sẹ́. Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kan bá kọ.

Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Pilatu

28 Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá.

29 Pilatu bá jáde lọ sọ́dọ̀ wọn lóde, ó bi wọ́n pé, “Ẹ̀sùn wo ni ẹ fi kan ọkunrin yìí?”

30 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí ọkunrin yìí kò bá ṣe nǹkan burúkú ni, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́ fún ìdájọ́.”

31 Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un lọ, kí ẹ ṣe ìdájọ́ fún un bí òfin yín.”

Ṣugbọn àwọn Juu sọ fún un pé, “A kò ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́ ikú fún ẹnikẹ́ni.”

32 Gbolohun yìí jáde kí ọ̀rọ̀ Jesu lè ṣẹ nígbà tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóo kú.

33 Pilatu bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”

34 Jesu dáhùn pé, “O wí èyí fúnrarẹ ni àbí ẹlòmíràn ni ó sọ bẹ́ẹ̀ fún ọ nípa mi?”

35 Pilatu dáhùn pé, “Èmi í ṣe Juu bí? Àwọn eniyan rẹ ati àwọn olórí alufaa ni wọ́n fà ọ́ wá sọ́dọ̀ mi. Kí ni o ṣe?”

36 Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.”

37 Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?”

Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”

38 Pilatu bi í pé, “Kí ni òtítọ́?”

Wọ́n Dá Jesu Lẹ́bi Ikú

Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tún jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn Juu, ó sọ fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.

39 Ṣugbọn ẹ ní àṣà kan, pé kí n dá ẹnìkan sílẹ̀ fun yín ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá. Ṣé ẹ fẹ́ kí n dá ‘Ọba àwọn Juu’ sílẹ̀ fun yín?”

40 Wọ́n tún kígbe pé, “Òun kọ́! Baraba ni kí o dá sílẹ̀!” (Ọlọ́ṣà paraku ni Baraba yìí.)

Categories
JOHANU

JOHANU 19

1 Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án.

2 Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì,

3 wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí.

4 Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.”

5 Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”

6 Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”

Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.”

7 Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.”

8 Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.

9 Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?”

Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn.

10 Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?”

11 Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.”

12 Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.”

13 Nígbà tí Pilatu gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú Jesu jáde, ó wá jókòó lórí pèpéle ìdájọ́ níbìkan tí wọn ń pè ní “Pèpéle olókùúta,” tí ń jẹ́ “Gabata” ní èdè Heberu.

14 Ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Àjọ̀dún Ìrékọjá ni ọjọ́ náà. Ó tó nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Pilatu sọ fún àwọn Juu pé, “Ọba yín nìyí!”

15 Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!”

Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?”

Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.”

16 Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.

Wọ́n Kan Jesu Mọ́ Agbelebu

Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu.

17 Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu.

18 Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin.

19 Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.”

20 Pupọ ninu àwọn Juu ni ó ka àkọlé náà ní èdè Heberu ati ti Latini ati ti Giriki.

21 Àwọn olórí alufaa àwọn Juu sọ fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ ọ́ pé ‘Ọba àwọn Juu,’ ṣugbọn kọ ọ́ báyìí: ‘Ó ní: èmi ni ọba àwọn Juu.’ ”

22 Ṣugbọn Pilatu dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́ ná.”

23 Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀.

24 Wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Ẹ má jẹ́ kí á ya á, gègé ni kí ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ láti mọ ti ẹni tí yóo jẹ́.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé,

“Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,

wọ́n ṣẹ́ gègé lórí ẹ̀wù mi.”

Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn ọmọ-ogun sì ṣe.

25 Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu.

26 Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.”

27 Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀.

Ikú Jesu

28 Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”

29 Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu.

30 Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!”

Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́.

Ọmọ-ogun Kan Fi Ọ̀kọ̀ Gún Jesu Lẹ́gbẹ̀ẹ́

31 Nítorí ọjọ́ náà jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá, kí òkú má baà wà lórí agbelebu ní Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Juu bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ní ojúgun, kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí agbelebu nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi pataki ni Ọjọ́ Ìsinmi náà.

32 Àwọn ọmọ-ogun bá lọ, wọ́n dá ekinni-keji àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu Jesu lójúgun.

33 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n rí i pé ó ti kú, nítorí náà wọn kò dá a lójúgun.

34 Ṣugbọn ọmọ-ogun kan fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ ati omi bá tú jáde.

35 (Ẹni tí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ojú rẹ̀ ni ó jẹ́rìí, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀, ó mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́.)

36 Gbogbo èyí rí bẹ́ẹ̀ kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Kò sí egungun rẹ̀ kan tí wọ́n ṣẹ́.”

37 Ìwé Mímọ́ tún wí níbòmíràn pé, “Wọn yóo wo ẹni tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ gún.”

Ìsìnkú Jesu

38 Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e.

39 Nikodemu, tí ó fòru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan rí, mú àdàlú òróró olóòórùn dídùn olówó iyebíye oríṣìí meji wá, wíwúwo rẹ̀ tó ọgbọ̀n kilogiramu.

40 Wọ́n fi òróró yìí tọ́jú òkú Jesu, wọ́n bá wé e ní aṣọ-ọ̀gbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìsìnkú àwọn Juu.

41 Ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti kan Jesu mọ́ agbelebu. Ibojì titun kán wà ninu ọgbà náà, wọn kò ì tíì sin òkú kankan sinu rẹ̀ rí.

42 Wọ́n tẹ́ òkú Jesu sibẹ, nítorí ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn Juu ni, ati pé ibojì náà súnmọ́ tòsí.