Categories
JOHANU

JOHANU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìyìn Rere Johanu

fi Jesu hàn gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọrun tí “ó di eniyan tí ó sì ń gbé ààrin wa.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà alára ti wí, ìdí tí a fi kọ ọ́ ni pé kí àwọn tí wọ́n bá kà á lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ṣe ìlérí, òun sì ni Ọmọ Ọlọrun; ati pé kí wọ́n lè ní ìyè nípasẹ̀ gbigbagbọ tí wọ́n bá gbà á gbọ́.

Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ iṣaaju tí ó fihàn pé Jesu ni ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọrun, apá kinni ìyìn rere náà sọ nípa àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìyanu tí ó fihàn pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ṣe ìlérí, òun ni Ọmọ Ọlọrun. Lẹ́yìn èyí, ẹni tí ó kọ ìwé náà ṣe àkójọ àwọn àlàyé tí ó ṣe nípa ohun tí àwọn iṣẹ́ ìyanu dúró fún. Ninu apá tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni ó ti sọ nípa àwọn mélòó kan tí wọ́n gba Jesu gbọ́ tí wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn mìíràn takò ó, wọ́n kọ̀, wọn kò gbà á gbọ́. Orí 13 dé 17 sọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa bí Jesu ti fara mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tímọ́tímọ́ ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un. Ó tún sọ nípa ọ̀rọ̀ ìpalẹ̀mọ́ ati ìmúnilọ́kànle tí Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu. Orí bíi mélòó kan tí ó parí ìwé náà sọ nípa bí wọ́n ṣe mú Jesu, tí wọ́n wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu ati bí ó ṣe jinde. Ó tún sọ nípa bí ó ṣe fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ajinde rẹ̀.

Inú àmì àkámọ́ (brackets), ni wọ́n kọ ìtàn obinrin tí wọ́n mú níbi tí ó ti ń ṣe àgbèrè sí (8:1-11). Ìdí ni pé kò sí ìtàn yìí ninu ọpọlọpọ Bibeli àtijọ́. Ninu àwọn mìíràn tí ó sì wà, ọ̀tọ̀ ni ibi tí wọ́n kọ ọ́ sí.

Johanu tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀bùn ìyè ainipẹkun ninu Kristi. Láti ìsinsìnyìí lọ ni ẹ̀bùn tí àwọn tí wọ́n bá gba Jesu bí ọ̀nà, òtítọ́ ati ìyè yóo rí gbà ti bẹ̀rẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ohun tí ó gúnni lọ́kàn ninu ìwé Johanu ni bí ó ṣe ń mú àwọn nǹkan yẹpẹrẹ inú ìgbé-ayé wa ojoojumọ, tí ó sì ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe pataki láti tọ́ka sí àwọn nǹkan ti ẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ kókó; fún bíi àpẹẹrẹ: omi, oúnjẹ, ìmọ́lẹ̀, olùṣọ́ aguntan ati àwọn aguntan rẹ̀, ati igi àjàrà pẹlu èso rẹ̀.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ 1:1-18

Johanu Onítẹ̀bọmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kinni 1:19-51

Àwọn iṣẹ́ tí Jesu ṣe ní gbangba 2:1–12:50

Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ní Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀ 13:1–19:42

Ajinde ati ìfarahàn Oluwa 20:1-31

Ọ̀rọ̀ ìparí: ìfarahàn mìíràn ní Galili 21:1-25

Categories
JOHANU

JOHANU 1

Ọlọrun di Eniyan

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé, ni Ọ̀rọ̀ ti wà, Ọ̀rọ̀ wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun sì ni Ọ̀rọ̀ náà.

2 Òun ni ó wà pẹlu Ọlọrun ní ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé.

3 Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ninu gbogbo ohun tí a dá, kò sí ohun kan tí a dá lẹ́yìn rẹ̀.

4 Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé.

5 Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀.

6 Ọkunrin kan wà tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johanu.

7 Òun ni ó wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kí ó lè jẹ́rìí sí ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo eniyan lè torí ẹ̀rí rẹ̀ gbàgbọ́.

8 Kì í ṣe òun ni ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn ó wá láti jẹ́rìí ìmọ́lẹ̀ náà.

9 Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé.

10 Ọ̀rọ̀ ti wà ninu ayé. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ayé, sibẹ ayé kò mọ̀ ọ́n.

11 Ó wá sí ìlú ara rẹ̀, ṣugbọn àwọn ará ilé rẹ̀ kò gbà á.

12 Ṣugbọn iye àwọn tí ó gbà á, ni ó fi àṣẹ fún láti di ọmọ Ọlọrun, àní àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.

13 A kò bí wọn bí eniyan ṣe ń bímọ nípa ìfẹ́ ara tabi ìfẹ́ eniyan, ṣugbọn nípa ìfẹ́ Ọlọrun ni a bí wọn.

14 Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.

15 Johanu jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó ń ké rara pé, “Ẹni tí mo sọ nípa rẹ̀ nìyí pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà ṣiwaju mi.’ ”

16 Nítorí láti inú ẹ̀kún ibukun rẹ̀ ni gbogbo wa ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà kún oore-ọ̀fẹ́.

17 Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá.

18 Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.

Ẹ̀rí Johanu Onítẹ̀bọmi nípa Jesu

19 Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”

20 Ó sọ òtítọ́, kò parọ́, ó ní, “Èmi kì í ṣe Mesaya náà.”

21 Wọ́n wá bi í pé, “Ta wá ni ọ́? Ṣé Elija ni ọ́ ni?”

Ó ní, “Èmi kì í ṣe Elija.”

Wọ́n tún bi í pé, “Ìwọ ni wolii tí à ń retí bí?”

Ó ní, “Èmi kọ́.”

22 Wọ́n bá tún bèèrè pé, “Ó dára, ta ni ọ́? Ó yẹ kí á lè rí èsì mú pada fún àwọn tí wọ́n rán wa wá. Kí ni o sọ nípa ara rẹ?”

23 Ó bá dáhùn gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti sọ pé:

“Èmi ni ‘ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé:

Ẹ ṣe ọ̀nà tí ó tọ́ fún Oluwa.’ ”

24 Àwọn Farisi ni ó rán àwọn eniyan sí i.

25 Wọ́n wá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi nígbà tí kì í ṣe ìwọ ni Mesaya tabi Elija tabi wolii tí à ń retí?”

26 Johanu dá wọn lóhùn pé, “Omi ni èmi fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ẹnìkan wà láàrin yín tí ẹ kò mọ̀,

27 ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ṣugbọn n kò tó tú okùn bàtà rẹ̀.”

28 Ní Bẹtani tí ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀, níbi tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi.

Ọ̀dọ́ Aguntan Ọlọrun Farahàn

29 Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ.

30 Òun ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà kí á tó bí mi.’

31 Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn kí á lè fi í han Israẹli ni mo ṣe wá, tí mò ń fi omi ṣe ìwẹ̀mọ́.”

32 Johanu tún jẹ́rìí pé, “Mo ti rí Ẹ̀mí tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run tí ó bà lé e, tí ó sì ń bá a gbé.

33 Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó rán mi láti máa ṣe ìrìbọmi ti sọ fún mi pé, ẹni tí mo bá rí tí Ẹ̀mí bá sọ̀kalẹ̀ lé lórí, tí ó bá ń bá a gbé, òun ni ẹni tí ó ń fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìwẹ̀mọ́.

34 Mo ti rí i, mo wá ń jẹ́rìí pé òun ni Ọmọ Ọlọrun.”

Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Kinni tí Jesu Ní

35 Ní ọjọ́ keji, bí Johanu ati àwọn meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti tún dúró,

36 ó tẹjú mọ́ Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun.”

37 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji náà gbọ́, wọ́n tẹ̀lé Jesu.

38 Nígbà tí Jesu yipada, tí ó rí wọn tí wọn ń tẹ̀lé òun, ó bi wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń wá?”

Wọ́n ní, “Rabi, níbo ni ò ń gbé?” (Ìtumọ̀ “Rabi” ni “Olùkọ́ni.”)

39 Ó ní, “Ẹ ká lọ, ẹ óo sì rí i.” Wọ́n bá bá a lọ, wọ́n rí ibi tí ó ń gbé. Wọ́n dúró lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí ó ti tó bí nǹkan agogo mẹrin ìrọ̀lẹ́.

40 Ọ̀kan ninu àwọn meji tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó tẹ̀lé Jesu ni Anderu arakunrin Simoni Peteru.

41 Lẹsẹkẹsẹ, Anderu rí Simoni arakunrin rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Àwa ti rí Mesaya!” (Ìtumọ̀ “Mesaya” ni “Kristi.”)

42 Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu.

Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.)

Jesu Pe Filipi ati Nataniẹli

43 Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”

44 Ará Bẹtisaida, ìlú Anderu ati ti Peteru, ni Filipi.

45 Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.”

46 Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?”

Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.”

47 Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.”

48 Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?”

Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.”

49 Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.”

50 Jesu wí fún un pé, “Nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni o ṣe gbàgbọ́? Ìwọ yóo rí ohun tí ó jù yìí lọ.”

51 Ó tún wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹ óo rí ọ̀run tí yóo pínyà, ẹ óo wá rí àwọn angẹli Ọlọrun tí wọn óo máa gòkè, tí wọn óo tún máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ-Eniyan.”

Categories
JOHANU

JOHANU 2

Jesu Lọ sí Ibi Igbeyawo Kan ní Kana

1 Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ń ṣe igbeyawo kan ní Kana, ìlú kan ní Galili. Ìyá Jesu wà níbẹ̀.

2 Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà.

3 Nígbà tí ọtí tán, ìyá Jesu sọ fún un pé, “Wọn kò ní ọtí mọ́!”

4 Jesu wí fún un pé, “Kí ni tèmi ati tìrẹ ti jẹ́, obinrin yìí? Àkókò mi kò ì tíì tó.”

5 Ìyá rẹ̀ sọ fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ ṣe ohunkohun tí ó bá wí fun yín.”

6 Ìkòkò òkúta mẹfa kan wà níbẹ̀, tí wọ́n ti tọ́jú fún omi ìwẹ-ọwọ́-wẹ-ẹsẹ̀ àwọn Juu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó bíi garawa omi marun-un tabi mẹfa.

7 Jesu wí fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìkòkò wọnyi.” Wọ́n bá pọnmi kún wọn.

8 Ó bá tún wí fún wọn pé, “Ẹ bù ninu rẹ̀ lọ fún alága àsè.” Wọ́n bá bù ú lọ.

9 Nígbà tí alága àsè tọ́ omi tí ó di ọtí wò, láì mọ ibi tí ó ti wá, (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iranṣẹ tí ó bu omi náà mọ̀), alága àsè pe ọkọ iyawo.

10 Ó ní, “Ọtí tí ó bá dùn ni gbogbo eniyan kọ́ ń gbé kalẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan bá ti mu ọtí yó tán, wọn á wá gbé ọtí èyí tí kò dára tóbẹ́ẹ̀ wá. Ṣugbọn ìwọ fi àtàtà ọtí yìí pamọ́ di àkókò yìí!”

11 Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

12 Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapanaumu, òun, ìyá rẹ̀, àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ bíi mélòó kan.

Jesu Lòdì sí Lílò tí Wọn Ń Lo Tẹmpili Bí Ọjà

13 Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Juu, Jesu gòkè lọ sí Jerusalẹmu.

14 Ó rí àwọn tí ń ta mààlúù, aguntan, ati ẹyẹlé ninu àgbàlá Tẹmpili, ati àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó.

15 Jesu bá fi okùn kan ṣe ẹgba, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo wọn jáde kúrò ninu àgbàlá Ilé Ìrúbọ. Ó lé àwọn tí ń ta aguntan ati mààlúù jáde. Ó da gbogbo owó àwọn onípàṣípààrọ̀ nù, ó sì ti tabili wọn ṣubú.

16 Ó sọ fún àwọn tí ń ta ẹyẹlé pé, “Ẹ gbé gbogbo nǹkan wọnyi kúrò níhìn-ín, ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”

17 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí, “Ìtara ilé rẹ ti jẹ mí lógún patapata.”

18 Àwọn Juu wá bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ óo fihàn wá gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí o fi ń ṣe nǹkan wọnyi?”

19 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá wó Tẹmpili yìí, èmi yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.”

20 Àwọn Juu wí fún un pé, “Aadọta ọdún ó dín mẹrin ni ó gbà wá láti kọ́ Tẹmpili yìí, ìwọ yóo wá kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta?”

21 Ṣugbọn ara rẹ̀ ni ó ń sọ̀rọ̀ bá, tí ó pè ní Tẹmpili.

22 Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ.

Jesu Mọ Inú Gbogbo Eniyan

23 Nígbà tí Jesu wà ní agbègbè Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, ọpọlọpọ eniyan gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n ṣe akiyesi àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe.

24 Ṣugbọn Jesu fúnrarẹ̀ kò gbára lé wọn, nítorí ó mọ gbogbo eniyan.

25 Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un nípa ọmọ aráyé nítorí ó mọ ohun tí ó wà ninu wọn.

Categories
JOHANU

JOHANU 3

Jesu ati Nikodemu

1 Ọkunrin kan wà ninu àwọn Farisi tí ń jẹ́ Nikodemu. Ó jẹ́ ọ̀kan ninu ìgbìmọ̀ àwọn Juu.

2 Ọkunrin yìí fi òru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ó wí fún un pé, “Rabi, a mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni ọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ò ń ṣe wọnyi àfi ẹni tí Ọlọrun bá wà pẹlu rẹ̀.”

3 Jesu bá gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá tún bí láti ọ̀run kò lè rí ìjọba Ọlọrun.”

4 Nikodemu bi í pé, “Báwo ni a ti ṣe lè tún ẹni tí ó ti di àgbàlagbà bí? Kò sá tún lè pada wọ inú ìyá rẹ̀ lẹẹkeji kí á wá tún un bí!”

5 Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá fi omi ati Ẹ̀mí bí, kò lè wọ ìjọba Ọlọrun.

6 Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti ẹran-ara, ẹran-ara ni. Ẹni tí a bá bí ní bíbí ti Ẹ̀mí, ẹ̀mí ni.

7 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu yà ọ́ nítorí mo wí fún ọ pé: dandan ni kí á tún yín bí.

8 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibikíbi tí ó bá wù ú; ò ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣugbọn o kò mọ ibi tí ó ti ń bọ̀, tabi ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu gbogbo ẹni tí a bí ní bíbí ti Ẹ̀mí.”

9 Nikodemu wá bi í pé, “Báwo ni nǹkan wọnyi ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”

10 Jesu ní, “Mo ṣebí olùkọ́ni olókìkí ní Israẹli ni ọ́, sibẹ o kò mọ nǹkan wọnyi?

11 Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, à ń sọ ohun tí a mọ̀, a sì ń jẹ́rìí ohun tí a rí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí wa.

12 Bí mo bá sọ nǹkan ti ayé fun yín tí ẹ kò gbàgbọ́, ẹ óo ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ nǹkan ti ọ̀run fun yín?

13 Kò sí ẹni tí ó tíì gòkè lọ sí ọ̀run rí àfi ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, èyí ni Ọmọ-Eniyan.”

14 Bí Mose ti gbé ejò sókè ní aṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé Ọmọ-Eniyan sókè,

15 kí gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè ainipẹkun.

16 Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun.

17 Nítorí Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé láti dá aráyé lẹ́bi bíkòṣe pé kí aráyé lè ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ìgbàlà.

18 A kò ní dá ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lẹ́bi. Ṣugbọn a ti dá ẹni tí kò bá gbà á gbọ́ lẹ́bi ná, nítorí kò gba orúkọ Ọmọ bíbí Ọlọrun kanṣoṣo gbọ́.

19 Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú.

20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe burúkú a máa kórìíra ìmọ́lẹ̀; kò jẹ́ wá sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, kí eniyan má baà bá a wí nítorí iṣẹ́ rẹ̀.

21 Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń hùwà òtítọ́ á máa wá sí ibi ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ lè hàn pé agbára Ọlọrun ni ó fi ń ṣe wọ́n.

Johanu Tún Sọ̀rọ̀ nípa Jesu

22 Lẹ́yìn èyí, Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Judia, wọ́n ń gbé ibẹ̀, ó bá ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan.

23 Johanu náà ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan ní Anoni lẹ́bàá Salẹmu, nítorí omi pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan ń wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn.

24 (Wọn kò ì tíì ju Johanu sẹ́wọ̀n ní àkókò yìí.)

25 Ọ̀rọ̀ nípa ìwẹ̀mọ́ di àríyànjiyàn láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati ọkunrin Juu kan.

26 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ sọ́dọ̀ Johanu, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ọkunrin tí ó wà pẹlu rẹ ní òdìkejì odò Jọdani, tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀, ń ṣe ìrìbọmi, gbogbo eniyan sì ń tọ̀ ọ́ lọ.”

27 Johanu fèsì pé, “Kò sí ẹni tí ó lè rí ohunkohun gbà àfi ohun tí Ọlọrun bá fún un.

28 Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí mi pé mo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣugbọn èmi ni a rán ṣiwaju rẹ̀.’

29 Ọkọ iyawo ni ó ni iyawo, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo, tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, á máa láyọ̀ láti gbọ́ ohùn ọkọ iyawo. Nítorí náà ayọ̀ mi yìí di ayọ̀ kíkún.

30 Dandan ni pé kí òun túbọ̀ jẹ́ pataki sí i, ṣugbọn kí jíjẹ́ pataki tèmi máa dínkù.”

Ipò Ẹni Tí Ó Wá láti Ọ̀run

31 Ẹni tí ó wá láti òkè ju gbogbo eniyan lọ. Ẹni tí ó jẹ́ ti ayé, ti ayé ni, ọ̀rọ̀ ti ayé ni ó sì ń sọ. Ẹni tí ó wá láti ọ̀run ju gbogbo eniyan lọ.

32 Ohun tí ó rí, tí ó sì gbọ́ ni ó ń jẹ́rìí sí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí rẹ̀.

33 Ẹni tí ó bá gba ẹ̀rí rẹ̀ gbà dájúdájú pé olóòótọ́ ni Ọlọrun.

34 Nítorí pé ẹni tí Ọlọrun rán wá ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí pé Ọlọrun fún un ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí rẹ̀.

35 Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀.

36 Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, ṣugbọn ibinu Ọlọrun wà lórí rẹ̀.

Categories
JOHANU

JOHANU 4

Jesu Bá Obinrin Ará Samaria Sọ̀rọ̀

1 Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ ju àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu lọ; ati pé Jesu ń ṣe ìrìbọmi fún ọpọlọpọ eniyan ju Johanu lọ.

2 Ṣugbọn ṣá, kì í ṣe Jesu fúnrarẹ̀ ni ó ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni.

3 Nígbà tí Jesu mọ̀ pé àwọn Farisi ti gbọ́ ìròyìn yìí, ó kúrò ní Judia, ó tún pada lọ sí Galili.

4 Ó níláti gba ààrin ilẹ̀ Samaria kọjá.

5 Ó dé ìlú Samaria kan tí ń jẹ́ Sikari, lẹ́bàá ilẹ̀ tí Jakọbu fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀.

6 Kànga kan tí ó ní omi wà níbẹ̀, tí Jakọbu gbẹ́ nígbà ayé rẹ. Jesu jókòó létí kànga náà ní nǹkan bí agogo mejila ọ̀sán, àárẹ̀ ti mú un nítorí ìrìn àjò tí ó rìn.

7 Obinrin kan ará Samaria wá pọn omi. Jesu wí fún un pé, “Fún mi ní omi mu.”

8 (Ní àkókò yìí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ ra oúnjẹ ninu ìlú.)

9 Obinrin ará Samaria náà dá Jesu lóhùn pé, “Kí ló dé tí ìwọ tí ó jẹ́ Juu fi ń bèèrè omi lọ́wọ́ èmi tí mo jẹ́ obinrin ará Samaria?” (Gbolohun yìí jáde nítorí àwọn Juu kì í ní ohunkohun ṣe pẹlu àwọn ará Samaria.)

10 Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.”

11 Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, o kò ní ohun tí o lè fi fa omi, kànga yìí sì jìn, níbo ni ìwọ óo ti mú omi ìyè wá?

12 Ìwọ kò ṣá ju Jakọbu baba-ńlá wa, tí ó gbẹ́ kànga yìí fún wa lọ, tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ sì ń mu níbẹ̀?”

13 Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi yìí òùngbẹ yóo tún gbẹ ẹ́.

14 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.”

15 Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí kí òùngbẹ má baà gbẹ mí mọ́, kí n má baà tún wá pọn omi níhìn-ín mọ́.”

16 Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.”

17 Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.”

Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ,

18 nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.”

19 Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́.

20 Ní orí òkè tí ó wà lọ́hùn-ún yìí ni àwọn baba wa ń sin Ọlọrun, ṣugbọn ẹ̀yin wí pé Jerusalẹmu ni ibi tí a níláti máa sìn ín.”

21 Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, gbà mí gbọ́! Àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé, ati ní orí òkè yìí ni, ati ní Jerusalẹmu ni, kò ní sí ibi tí ẹ óo ti máa sin Baba mọ́.

22 Ẹ̀yin ará Samaria kò mọ ẹni tí ẹ̀ ń sìn. Àwa Juu mọ ẹni tí à ń sìn, nítorí láti ọ̀dọ̀ wa ni ìgbàlà ti wá.

23 Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun.

24 Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.”

25 Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.”

26 Jesu wí fún un pé, “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Mesaya náà.”

27 Ní àkókò yìí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé. Ẹnu yà wọ́n pé obinrin ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni ninu wọn kò bi obinrin náà pé kí ni ó ń wá? Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò bi òun náà pé kí ló dé tí ó fi ń bá obinrin sọ̀rọ̀?

28 Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé,

29 “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?”

30 Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu.

31 Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.”

32 Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ní oúnjẹ láti jẹ tí ẹ̀yin kò mọ̀ nípa rẹ̀.”

33 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn pé, “Àbí ẹnìkan ti gbé oúnjẹ wá fún un ni?”

34 Jesu wí fún wọn pé, “Ní tèmi, oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ati láti parí iṣẹ́ tí ó fún mi ṣe.

35 Ṣé ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìkórè ku oṣù mẹrin.’ Mo sọ fun yín, ẹ gbé ojú yín sókè kí ẹ sì rí i bí oko ti pọ́n fun ìkórè.

36 Ẹni tí ń kórè a máa rí èrè gbà, ó ń kó irè jọ sí ìyè ainipẹkun, kí inú ẹni tí ń fúnrúgbìn ati ti ẹni tí ń kórè lè jọ máa dùn pọ̀.

37 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí pé, ‘Ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń fúnrúgbìn, ọ̀tọ̀ ni ẹni tí ń kórè.’

38 Mo ran yín láti kórè níbi tí ẹ kò ti ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn. Àwọn ẹnìkan ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin wá ń jèrè iṣẹ́ wọn.”

39 Ọpọlọpọ ninu àwọn ará Samaria tí ó wá láti inú ìlú gbà á gbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ obinrin tí ó jẹ́rìí pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.”

40 Nígbà tí àwọn ará Samaria dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn. Ó bá dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meji.

41 Ọpọlọpọ àwọn mìíràn tún gbàgbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

42 Wọ́n wí fún obinrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ohun tí o sọ ni a fi gbàgbọ́, nítorí àwa fúnra wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, a wá mọ̀ nítòótọ́ pé òun ni Olùgbàlà aráyé.”

Jesu Wo Ọmọ Ìjòyè kan Sàn

43 Lẹ́yìn ọjọ́ meji, Jesu jáde kúrò níbẹ̀ lọ sí Galili.

44 Nítorí òun fúnrarẹ̀ jẹ́rìí pé, “Wolii kan kò ní ọlá ninu ìlú baba rẹ̀.”

45 Nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, nítorí pé àwọn náà lọ sí ibi àjọ̀dún náà.

46 Jesu tún lọ sí ìlú Kana ti Galili níbi tí ó ti sọ omi di ọtí ní ìjelòó. Ìjòyè kan wà ní Kapanaumu tí ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn.

47 Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ.

48 Jesu wí fún un pé, “Bí ẹ kò bá rí iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu ẹ kò ní gbàgbọ́.”

49 Ìjòyè náà bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, tètè wá kí ọmọ mi tó kú.”

50 Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ọmọ rẹ yóo yè.”

Ọkunrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un gbọ́, ó bá ń lọ sílé.

51 Bí ó ti ń lọ, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá pàdé rẹ̀, wọ́n wí fún un pé, “Ọmọ rẹ ti gbádùn.”

52 Ìjòyè náà wádìí lọ́wọ́ wọn nípa àkókò tí ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Lánàá, ní nǹkan bí aago kan ni ibà náà lọ.”

53 Baba ọmọ náà mọ̀ pé àkókò náà gan-an ni Jesu sọ fún òun pé, “Ọmọ rẹ yóo yè.” Òun ati gbogbo ilé rẹ̀ bá gba Jesu gbọ́.

54 Èyí ni iṣẹ́ abàmì keji tí Jesu ṣe nígbà tí ó kúrò ní Judia, tí ó wá sí Galili.

Categories
JOHANU

JOHANU 5

Jesu wo Arọ kan Sàn ní Jerusalẹmu

1 Lẹ́yìn èyí, ó tó àkókò fún ọ̀kan ninu àjọ̀dún àwọn Juu: Jesu bá lọ sí Jerusalẹmu.

2 Ẹnu ọ̀nà kan wà ní Jerusalẹmu tí wọn ń pè ní ẹnu ọ̀nà Aguntan. Adágún omi kan wà níbẹ̀ tí ń jẹ́ Betisata ní èdè Heberu. Adágún yìí ní ìloro marun-un tí wọn fi òrùlé bò.

3 Níbẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn aláìsàn ti máa ń jókòó: àwọn afọ́jú, àwọn arọ, ati àwọn tí ó ní àrùn ẹ̀gbà. Wọn a máa retí ìgbà tí omi yóo rú pọ̀; [

4 nítorí angẹli Oluwa a máa wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti rú omi adágún náà pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ bọ́ sinu adágún náà lẹ́yìn tí omi náà bá ti rú pọ̀, àìsànkáìsàn tí ó lè máa ṣe é tẹ́lẹ̀, yóo san.]

5 Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji.

6 Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?”

7 Aláìsàn náà dáhùn pé, “Alàgbà, n kò ní ẹni tí yóo gbé mi sinu adágún nígbà tí omi bá rú pọ̀, nígbà tí n óo bá fi dé ibẹ̀, ẹlòmíràn á ti wọ inú omi ṣiwaju mi.”

8 Jesu wí fún un pé, “Dìde, ká ẹní rẹ, kí o máa rìn.”

9 Lẹsẹkẹsẹ ara ọkunrin náà dá, ó ká ẹni rẹ̀, ó bá ń rìn.

Ọjọ́ náà jẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi.

10 Àwọn Juu sọ fún ọkunrin tí ara rẹ̀ ti dá yìí pé, “Ọjọ́ Ìsinmi ni òní! Èèwọ̀ ni pé kí o ru ẹní rẹ!”

11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó mú mi lára dá ni ó sọ pé kí n ká ẹní mi, kí n máa rìn.”

12 Wọ́n bi í pé, “Ta ni ẹni náà tí ó sọ fún ọ pé kí o ru ẹni, kí o máa rìn?”

13 Ṣugbọn ọkunrin náà tí Jesu wòsàn kò mọ ẹni tí ó wo òun sàn, nítorí pé eniyan pọ̀ níbẹ̀, ati pé Jesu ti yẹra kúrò níbẹ̀.

14 Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.”

15 Ọkunrin náà pada lọ sọ fún àwọn Juu pé, Jesu ni ẹni tí ó wo òun sàn.

16 Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi.

17 Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”

18 Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun.

Àṣẹ tí Jesu fi ń Ṣiṣẹ́

19 Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe.

20 Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án. Yóo tún fi àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọnyi lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.

21 Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè.

22 Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́,

23 kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé.

24 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ gbọ́, olúwarẹ̀ ní ìyè ainipẹkun, kò ní wá sí ìdájọ́, ṣugbọn ó ti ré ikú kọjá, ó sì ti bọ́ sinu ìyè.

25 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, tí àwọn òkú yóo gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun, àwọn tí ó bá gbọ́ yóo yè.

26 Nítorí bí Baba ti ní ìyè ninu ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ti fún ọmọ ní agbára láti ní ìyè.

27 Ó ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́, nítorí òun ni Ọmọ-Eniyan.

28 Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, nítorí àkókò ń bọ̀ nígbà tí gbogbo àwọn òkú tí ó wà ní ibojì yóo gbọ́ ohùn rẹ̀,

29 tí wọn yóo sì jáde. Àwọn tí ó ti ṣe rere yóo jí dìde sí ìyè, àwọn tí ó ti ṣe ibi yóo jí dìde sí ìdálẹ́bi.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jesu

30 “Èmi kò lè dá nǹkankan ṣe. Ọ̀rọ̀ Baba mi tí mo bá gbọ́ ni mo fi ń ṣe ìdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí kì í ṣe ìfẹ́ tèmi ni mò ń wá bíkòṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

31 “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni mò ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi lè má jẹ́ òtítọ́.

32 Ṣugbọn ẹlòmíràn ni ó ń jẹ́rìí mi, mo sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí tí ó ń jẹ́ nípa mi.

33 Ẹ ti ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Johanu, ó sì ti jẹ́rìí òtítọ́.

34 Kì í ṣe pé dandan ni fún mi pé kí eniyan jẹ́rìí gbè mí. Ṣugbọn mo sọ èyí fun yín kí ẹ lè ní ìgbàlà.

35 Johanu dàbí fìtílà tí ó ń tàn, tí ó sì mọ́lẹ̀. Ó dùn mọ yín fún àkókò díẹ̀ láti máa yọ̀ ninu ìmọ́lẹ̀ tí ó fi fun yín.

36 Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́.

37 Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ti jẹ́rìí mi. Ẹnikẹ́ni kò ì tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò rí i bí ó ti rí rí.

38 Ẹ kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín nítorí ẹ kò gba ẹni tí ó rán níṣẹ́ gbọ́.

39 Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́.

40 Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè.

41 “Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan.

42 Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín.

43 Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò gbà mí. Ṣugbọn bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ óo gbà á.

44 Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?

45 Ẹ má ṣe rò pé èmi ni n óo fi yín sùn níwájú Baba, Mose tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé gan-an ni yóo fi yín sùn.

46 Bí ẹ bá gba Mose gbọ́, ẹ̀ bá gbà mí gbọ́, nítorí èmi ni ọ̀rọ̀ ìwé tí ó kọ bá wí.

47 Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí ó kọ gbọ́, báwo ni ẹ óo ti ṣe gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”

Categories
JOHANU

JOHANU 6

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

1 Lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí òdìkejì òkun Galili tí ó tún ń jẹ́ òkun Tiberiasi.

2 Ọ̀pọ̀ eniyan ń tẹ̀lé e nítorí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.

3 Jesu bá gun orí òkè lọ, ó jókòó níbẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

4 Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, tíí ṣe àjọ̀dún pataki láàrin àwọn Juu.

5 Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?”

6 Ó fi èyí wá Filipi lẹ́nu wò ni, nítorí òun fúnrarẹ̀ ti mọ ohun tí òun yóo ṣe.

7 Filipi dá a lóhùn pé, “Burẹdi igba owó fadaka kò tó kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lè fi rí díẹ̀díẹ̀ panu!”

8 Nígbà náà ni Anderu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí ó jẹ́ arakunrin Simoni Peteru sọ fún un pé,

9 “Ọdọmọkunrin kan wà níhìn-ín tí ó ní burẹdi bali marun-un ati ẹja meji, ṣugbọn níbo ni èyí dé láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan yìí?”

10 Jesu ní, “Ẹ ní kí wọ́n jókòó.” Koríko pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan náà bá jókòó. Wọ́n tó bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000).

11 Jesu wá mú burẹdi náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá pín in fún àwọn eniyan tí ó jókòó. Bákan náà ni ó ṣe sí ẹja, ó fún olukuluku bí ó ti ń fẹ́.

12 Lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ ẹja ní àjẹtẹ́rùn, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó oúnjẹ tí ó kù jọ, kí ohunkohun má baà ṣòfò.”

13 Wọ́n bá kó o jọ. Àjẹkù burẹdi marun-un náà kún agbọ̀n mejila, lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ tán.

14 Nígbà tí àwọn eniyan rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, wọ́n ní, “Dájúdájú, eléyìí ni wolii Ọlọrun náà tí ó ń bọ̀ wá sí ayé.”

15 Nígbà tí Jesu mọ̀ pé wọn ń fẹ́ wá fi ipá mú òun kí wọ́n sì fi òun jọba, ó yẹra kúrò níbẹ̀, òun nìkan tún pada lọ sórí òkè.

Jesu Rìn lórí Omi

16 Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí èbúté,

17 wọ́n wọ ọkọ̀, wọ́n ń lọ sí Kapanaumu ní òdìkejì òkun. Òkùnkùn ti ṣú ṣugbọn Jesu kò ì tíì dé ọ̀dọ̀ wọn.

18 Ni omi òkun bá bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nítorí afẹ́fẹ́ líle ń fẹ́.

19 Lẹ́yìn tí wọ́n ti wa ọkọ̀ bí ibùsọ̀ mẹta tabi mẹrin wọ́n rí Jesu, ó ń rìn lórí òkun, ó ti súnmọ́ etí ọkọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n.

20 Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

21 Wọ́n bá fi tayọ̀tayọ̀ gbà á sinu ọkọ̀. Lẹsẹkẹsẹ ọkọ̀ sì gúnlẹ̀ sí ibi tí wọn ń lọ.

Àwọn Eniyan Wá Jesu Rí

22 Ní ọjọ́ keji, àwọn tí wọ́n dúró ní òdìkejì òkun rí i pé ọkọ̀ kanṣoṣo ni ó wà níbẹ̀. Wọ́n tún wòye pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni wọ́n lọ.

23 Ṣugbọn àwọn ọkọ̀ mìíràn wá láti Tiberiasi lẹ́bàá ibi tí àwọn eniyan ti jẹun lẹ́yìn tí Oluwa ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun.

24 Nígbà tí àwọn eniyan rí i pé Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn náà bọ́ sinu àwọn ọkọ̀ tí ó wà níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tọpa Jesu lọ sí Kapanaumu.

Jesu ni Oúnjẹ Ìyè

25 Nígbà tí wọ́n rí i ní òdìkejì òkun, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni o ti dé ìhín?”

26 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí iṣẹ́ ìyanu mi ni ẹ ṣe ń wá mi, ṣugbọn nítorí ẹ jẹ oúnjẹ àjẹyó ni.

27 Ẹ má ṣe làálàá nítorí oúnjẹ ti yóo bàjẹ́, ṣugbọn ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ọmọ eniyan yóo fun yín, tí yóo wà títí di ìyè ainipẹkun, nítorí ọmọ eniyan ni Ọlọrun Baba fún ní àṣẹ.”

28 Wọ́n wá bi í pé, “Kí ni kí á ṣe kí á lè máa ṣe iṣẹ́ Ọlọrun?”

29 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ gba ẹni tí ó rán gbọ́.”

30 Wọ́n wá bi í pé, “Iṣẹ́ ìyanu wo ni ìwọ óo ṣe, tí a óo rí i, kí á lè gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni o óo ṣe?

31 Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá jẹ.’ ”

32 Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe Mose ni ó fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá. Baba mi ni ó ń fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá;

33 nítorí oúnjẹ Ọlọrun ni ẹni tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó ń fi ìyè fún aráyé.”

34 Wọ́n bá sọ fún un pé, “Alàgbà, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.”

35 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae.

36 Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ̀yin ti rí mi, sibẹ ẹ kò gbàgbọ́.

37 Gbogbo ẹni tí Baba ti fi fún mi yóo wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, n kò ní ta á nù;

38 nítorí pé mo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bíkòṣe láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

39 Èyí ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́, pé kí n má ṣe sọ ẹnikẹ́ni nù ninu àwọn tí ó fi fún mi, ṣugbọn kí n jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.

40 Nítorí ìfẹ́ Baba mi ni pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ọmọ rẹ̀, tí ó bá gbà á gbọ́, lè ní ìyè ainipẹkun. Èmi fúnra mi yóo jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”

41 Àwọn Juu wá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí i nítorí ó wí pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá.”

42 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ṣebí Jesu ọmọ Josẹfu ni; ẹni tí a mọ baba ati ìyá rẹ̀? Ó ṣe wá sọ pé, láti ọ̀run ni òun ti sọ̀kalẹ̀ wá?”

43 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrin ara yín mọ́.

44 Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi àfi bí Baba tí ó rán mi níṣẹ́ bá fà á wá, èmi óo wá jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.

45 Ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Gbogbo wọn ni Ọlọrun yóo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.’ Gbogbo ẹni tí ó bá gba ọ̀rọ̀ Baba, tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, á wá sọ́dọ̀ mi.

46 Kò sí ẹni tí ó rí Baba rí àfi ẹni tí ó ti wà pẹlu Baba ni ó ti rí Baba.

47 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní ìyè ainipẹkun.

48 Èmi pàápàá ni oúnjẹ tí ó ń fún eniyan ní ìyè.

49 Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, sibẹ wọ́n kú.

50 Ṣugbọn oúnjẹ tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ ni èyí tí ó jẹ́ pé bí ẹnìkan bá jẹ ninu rẹ̀, olúwarẹ̀ kò ní kú.

51 Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.”

52 Gbolohun yìí dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láàrin àwọn Juu. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe lè fún wa ní ẹran-ara rẹ̀ jẹ?”

53 Jesu wá wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ̀yin kò bá jẹ ẹran ara ọmọ eniyan, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò lè ní ìyè ninu yín.

54 Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ní ìyè ainipẹkun, èmi yóo sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.

55 Ẹran-ara mi ni oúnjẹ gidi, ẹ̀jẹ̀ mi sì ni ohun mímu iyebíye.

56 Ẹni tí ó bá jẹ ẹran-ara mi, tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, olúwarẹ̀ ń gbé inú mi, èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀.

57 Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi.

58 Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.”

59 Jesu sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn ní Kapanaumu.

Ọ̀rọ̀ Ìyè Ainipẹkun

60 Ọpọlọpọ tí ó gbọ́ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé, “Ọ̀rọ̀ yìí le, kò sí ẹni tí ó lè gba irú rẹ̀!”

61 Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn nítorí rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ni ó mú kí ọkàn yín dààmú?

62 Tí ẹ bá wá rí Ọmọ-Eniyan tí ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ ńkọ́?

63 Ẹ̀mí ní ń sọ eniyan di alààyè, ẹran-ara kò ṣe anfaani kankan. Ọ̀rọ̀ tí mo ti ba yín sọ jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ati ti ìyè.

64 Ṣugbọn àwọn tí kò gbàgbọ́ wà ninu yín.” Jesu sọ èyí nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti mọ àwọn tí kò gbàgbọ́ ati ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.

65 Ó ní, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, àfi bí Baba mi bá ṣí ọ̀nà fún un láti wá.”

66 Nítorí èyí, ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ̀, wọn kò tún bá a rìn mọ́.

67 Jesu bá bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila pé, “Ẹ̀yin náà fẹ́ lọ bí?”

68 Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Oluwa, ọ̀dọ̀ ta ni à bá lọ? Ìwọ ni o ní ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun.

69 Ní tiwa, a ti gbàgbọ́, a sì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọrun.”

70 Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ̀yin mejila ni mo yàn. Ṣugbọn ẹni ibi ni ọ̀kan ninu yín.”

71 Ó wí èyí nípa Judasi Iskariotu ọmọ Simoni, nítorí òun ni ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ni Judasi Iskariotu yìí.

Categories
JOHANU

JOHANU 7

Àwọn Arakunrin Jesu kò gbà á gbọ́

1 Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á.

2 Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò àjọ̀dún àwọn Juu nígbà tí wọn ń ṣe Àjọ̀dún Ìpàgọ́ ní aṣálẹ̀.

3 Àwọn arakunrin Jesu sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín kí o lọ sí Judia, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ lè rí iṣẹ́ tí ò ń ṣe,

4 nítorí kò sí ẹni tíí fi ohun tí ó bá ń ṣe pamọ́, bí ó bá fẹ́ kí àwọn eniyan mọ òun. Tí o bá ń ṣe nǹkan wọnyi, fi ara rẹ han aráyé.”

5 (Àwọn arakunrin rẹ̀ kò gbà á gbọ́ ni wọ́n ṣe sọ bẹ́ẹ̀.)

6 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó, ìgbà gbogbo ni ó wọ̀ fún ẹ̀yin.

7 Ayé kò lè kórìíra yín, èmi ni wọ́n kórìíra, nítorí ẹ̀rí mi lòdì sí wọn nítorí pé iṣẹ́ wọn burú.

8 Ẹ̀yin ẹ máa lọ sí ibi àjọ̀dún, èmi kò ní lọ sí ibi àjọ̀dún yìínítorí àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó.”

9 Nígbà tí ó wí báyìí tán, ó tún dúró ní ilẹ̀ Galili.

Jesu Lọ sí Àjọ̀dún Ìpàgọ́

10 Lẹ́yìn tí àwọn arakunrin Jesu ti lọ sí ibi àjọ̀dún náà, òun náà wá lọ. Ṣugbọn, kò lọ ní gbangba, yíyọ́ ni ó yọ́ lọ.

11 Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí wá a níbi àjọ̀dún náà, wọ́n ń bèèrè pé, “Níbo ni ó wà?”

12 Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ni àwọn eniyan ń sọ nípa rẹ̀. Àwọn kan ń sọ pé, “Eniyan rere ni.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó ń tan àwọn eniyan jẹ ni.”

13 Ṣugbọn wọn kò sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu.

14 Nígbà tí àjọ̀dún ti fẹ́rẹ̀ kọjá ìdajì, Jesu lọ sí Tẹmpili, ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.

15 Ẹnu ya àwọn Juu, wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni eléyìí ti ṣe mọ ìwé tó báyìí nígbà tí kò lọ sí ilé-ìwé?”

16 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀kọ́ tèmi kì í ṣe ti ara mi, ti ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ni.

17 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, olúwarẹ̀ yóo mọ̀ bí ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ ti Ọlọrun, tabi bí ó bá jẹ́ pé ti ara mi ni mò ń sọ.

18 Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ògo ẹni tí ó rán an níṣẹ́ jẹ́ olóòótọ́, kò sí aiṣododo ninu rẹ̀.

19 Mo ṣebí Mose ti fun yín ní Òfin? Sibẹ kò sí ẹnìkan ninu yín tí ó ń ṣe ohun tí òfin wí. Nítorí kí ni ẹ ṣe ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

20 Àwọn eniyan dá a lóhùn pé, “Nǹkan kọ lù ọ́! Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”

21 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣe iṣẹ́ kan, ẹnu ya gbogbo yín.

22 Nítorí pé Mose fun yín ní òfin ìkọlà, ẹ̀ ń kọlà fún eniyan ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ṣugbọn òfin yìí kò bẹ̀rẹ̀ pẹlu Mose, àwọn baba-ńlá wa ni ó dá a sílẹ̀.

23 Ẹ̀yin ń kọ ilà ní Ọjọ́ Ìsinmi kí ẹ má baà rú òfin Mose, ẹ wá ń bínú sí mi nítorí mo wo eniyan sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi!

24 Ẹ má wo ojú eniyan ṣe ìdájọ́, ṣugbọn ẹ máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́.”

Àbí Jesu Ni Mesaya náà?

25 Àwọn kan ninu àwọn ará Jerusalẹmu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ẹni tí wọ́n fẹ́ pa kọ́ yìí?

26 Wò ó bí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní gbangba tí wọn kò sì sọ ohunkohun sí i. Àbí àwọn aláṣẹ ti mọ̀ dájú pé òun ni Mesaya ni?

27 Ṣugbọn eléyìí kò lè jẹ́ Mesaya, nítorí a mọ ibi tí ó ti wá. Nígbà tí Mesaya bá dé, ẹnikẹ́ni kò ní mọ ibi tí ó ti wá.”

28 Ni Jesu bá kígbe sókè bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili. Ó ní, “Òtítọ́ ni pe ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, tí ẹ̀yin kò mọ̀.

29 Èmi mọ̀ ọ́n, nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó sì rán mi níṣẹ́.”

30 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fi ọwọ́ kàn án nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.

31 Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan gbà á gbọ́, wọ́n ń sọ pé, “Bí Mesaya náà bá dé, ǹjẹ́ yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu ju èyí tí ọkunrin yìí ń ṣe lọ?”

Wọ́n Rán Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Lọ Mú Jesu

32 Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn eniyan ń sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ báyìí láàrin ara wọn nípa Jesu. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá rán àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili pé kí wọ́n lọ mú Jesu wá.

33 Jesu bá dáhùn pé, “Àkókò díẹ̀ ni ó kù tí n óo lò pẹlu yín, lẹ́yìn náà n óo lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.

34 Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, ibi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀.”

35 Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Níbo ni ọkunrin yìí yóo lọ tí àwa kò fi ní rí i? Àbí ó ha fẹ́ lọ sí ààrin àwọn ará wa tí ó fọ́nká sí ààrin àwọn Giriki ni?

36 Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí tí ó sọ pé, ‘Ẹ óo wá mi, ẹ kò ní rí mi, níbi tí mo bá wà, ẹ kò ní lè dé ibẹ̀?’ ”

Odò Omi Ìyè

37 Nígbà tí ó di ọjọ́ tíí àjọ̀dún yóo parí, tíí ṣe ọjọ́ tí ó ṣe pataki jùlọ, Jesu dìde dúró, ó kígbe pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó mu omi.

38 Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóo ti máa sun jáde, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.”

39 Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo.

Ìyapa Bẹ́ Sáàrin Àwọn Eniyan

40 Ninu àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni wolii tí à ń retí nítòótọ́.”

41 Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Òun ni Mesaya.”

Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé, “Báwo ni Mesaya ti ṣe lè wá láti Galili?

42 Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”

43 Ni ìyapa bá bẹ́ sáàrin àwọn eniyan nítorí rẹ̀.

44 Àwọn kan ninu wọn fẹ́ mú un, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn án.

Àwọn Aláṣẹ Kò Gba Jesu Gbọ́

45 Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili tí wọ́n rán lọ mú Jesu pada dé ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi mú un wá?”

46 Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọ̀hún bá dáhùn pé, “Ẹnikẹ́ni kò sọ̀rọ̀ bí ọkunrin yìí rí!”

47 Àwọn Farisi bá bi wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin náà ti di ara àwọn tí ó ń tàn jẹ?

48 Ṣé kò ṣá sí ẹnikẹ́ni ninu àwọn aláṣẹ ati àwọn Farisi tí ó gbà á gbọ́?

49 A ti fi àwọn eniyan wọnyi tí kò mọ Òfin Mose gégùn-ún!”

50 Ọ̀kan ninu àwọn Farisi ọ̀hún ni Nikodemu, ẹni tí ó lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan. Ó bi wọ́n léèrè pé,

51 “Ǹjẹ́ òfin wa dá eniyan lẹ́bi láìjẹ́ pé a kọ́ gbọ́ ti ẹnu rẹ̀, kí á mọ ohun tí ó ṣe?”

52 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àbí ará Galili ni ìwọ náà? Lọ wádìí kí o rí i pé wolii kankan kò lè ti Galili wá!”

Categories
JOHANU

JOHANU 8

Ìtàn Obinrin tí Ó Ṣe Àgbèrè

[

1 Ni olukuluku wọn bá lọ sí ilé wọn; ṣugbọn Jesu lọ sí Òkè Olifi.

2 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó tún lọ sí Tẹmpili. Gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá jókòó, ó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.

3 Àwọn amòfin ati àwọn Farisi mú obinrin kan wá, tí wọ́n ká mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè. Wọ́n ní kí ó dúró láàrin wọn;

4 wọ́n wá sọ fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, a ká obinrin yìí mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè, a ká a mọ́ ọn gan-an ni!

5 Ninu Òfin wa Mose pàṣẹ pé kí á sọ irú àwọn bẹ́ẹ̀ ní òkúta pa. Kí ni ìwọ wí?”

6 Wọ́n sọ èyí láti fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu ni kí wọ́n lè fi ẹ̀sùn kàn án. Jesu bá bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀.

7 Bí wọ́n ti dúró tí wọ́n tún ń bi í, ó gbé ojú sókè ní ìjókòó tí ó wà, ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí kò bá ní ẹ̀ṣẹ̀ ninu yín ni kí ó kọ́ sọ ọ́ ní òkúta.”

8 Ó bá tún bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀.

9 Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbààgbà ni wọ́n kọ́ lọ. Gbogbo wọ́n bá túká pátá láìku ẹnìkan. Ó wá ku obinrin yìí nìkan níbi tí ó dúró sí.

10 Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó bi obinrin náà pé, “Obinrin, àwọn dà? Ẹnìkan ninu wọn kò dá ọ lẹ́bi?”

11 Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.”

Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”]

Jesu ni Ìmọ́lẹ̀ Ayé

12 Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

13 Àwọn Farisi sọ fún un pé, “Ò ń jẹ́rìí ara rẹ, ẹ̀rí rẹ kò jámọ́ nǹkankan.”

14 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá ń jẹ́rìí ara mi, sibẹ òtítọ́ ni ẹ̀rí mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn ẹ̀yin kò mọ ibi tí mo ti wá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì mọ ibi tí mò ń lọ.

15 Ojú ni ẹ̀ ń wò tí ẹ fi ń ṣe ìdájọ́, èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.

16 Bí mo bá tilẹ̀ ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni ìdájọ́ mi, nítorí kì í ṣe èmi nìkan ni mò ń ṣe ìdájọ́, èmi ati Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.

17 Ninu òfin yín a kọ ọ́ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí ẹni meji.

18 Èmi fúnra mi jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi níṣẹ́ náà sì ń jẹ́rìí mi.”

19 Wọ́n bi í pé, “Níbo ni baba rẹ wà?”

Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀ mí, ẹ̀ bá mọ Baba mi.”

20 Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.

Ta Ni Jesu?

21 Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ ní tèmi; ẹ óo máa wá mi kiri, ẹ óo sì kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.”

22 Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Kò ṣá ní pa ara rẹ̀, nítorí ó wí pé, ‘Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.’ ”

23 Ó wá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin, ní tiyín, ìsàlẹ̀ ni ẹ ti wá, ṣugbọn ní tèmi, òkè ọ̀run ni mo ti wá. Ti ayé yìí ni yín, èmi kì í ṣe ti ayé yìí.

24 Nítorí náà, mo wí fun yín pé ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nítorí bí ẹ kò bá gbàgbọ́ pé, ‘Èmi ni,’ ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25 Wọ́n bi í pé, “Ta ni ọ́?”

Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ ẹni tí mo jẹ́ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀.

26 Mo ní ohun pupọ láti sọ nípa yín ati láti fi ṣe ìdájọ́ yín. Olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi níṣẹ́; ohun tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mò ń sọ fún aráyé.”

27 Wọn kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Baba ni ó ń sọ fún wọn.

28 Jesu tún wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Eniyan sókè, nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni, ati pé èmi kò dá ohunkohun ṣe fúnra mi, ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi ni mò ń sọ̀rọ̀ yìí.

29 Ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ wà pẹlu mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí mò ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”

30 Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ báyìí, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́.

Òtítọ́ yóo sọ Yín di Òmìnira

31 Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́;

32 ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.”

33 Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?”

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

35 Ẹrú kì í gbé inú ilé títí, ọmọ níí gbé inú ilé títí.

36 Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ óo di òmìnira nítòótọ́.

37 Mo mọ̀ pé ìran Abrahamu ni yín, sibẹ ẹ̀ ń wá ọ̀nà láti pa mí, nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè ninu yín.

38 Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba mi ni mò ń sọ, ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́ lọ́dọ̀ baba yín ni ẹ̀ ń ṣe.”

39 Wọ́n sọ fún un pé, “Abrahamu ni baba wa.”

Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ọmọ Abrahamu ni yín, irú ohun tí Abrahamu ṣe ni ẹ̀ bá máa ṣe.

40 Ṣugbọn ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, bẹ́ẹ̀ sì ni òtítọ́ tí mo gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọrun ni mo sọ fun yín. Abrahamu kò hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.

41 Irú ohun tí baba yín ṣe ni ẹ̀ ń ṣe.”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í ṣe ọmọ àlè, baba kan ni a ní, òun náà sì ni Ọlọrun.”

42 Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi.

43 Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi.

44 Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́.

45 Ṣugbọn nítorí pe òtítọ́ ni mò ń sọ, ẹ kò gbà mí gbọ́.

46 Ta ni ninu yín tí ó ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ mi lọ́wọ́ rí? Bí mo bá ń sọ òtítọ́, kí ló dé tí ẹ kò fi gbà mí gbọ́?

47 Ẹni tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ìdí tí ẹ kò fi gbọ́ ni èyí, nítorí ẹ kì í ṣe ẹni Ọlọrun.”

Jesu ti wà ṣiwaju Abrahamu

48 Àwọn Juu sọ fún un pé, “A kúkú ti sọ pé ará Samaria ni ọ́, ati pé o ní ẹ̀mí èṣù!”

49 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù rárá! Èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ṣugbọn ẹ̀yin ń bu ẹ̀tẹ́ lù mí.

50 Èmi kò wá ògo ti ara mi, ẹnìkan wà tí ó ń wá ògo mi, òun ni ó ń ṣe ìdájọ́.

51 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní kú laelae.”

52 Àwọn Juu wá sọ fún un pé, “A wá mọ̀ dájú pé o ní ẹ̀mí èṣù wàyí! Abrahamu kú. Àwọn wolii kú. Ìwọ wá ń sọ pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní tọ́ ikú wò laelae.’

53 Abrahamu baba wa, tí ó ti kú ńkọ́? Ṣé ìwọ jù ú lọ ni? Ati àwọn wolii tí wọ́n ti kú? Ta ni o tilẹ̀ ń fi ara rẹ pè?”

54 Jesu dáhùn pé, “Bí mo bá bu ọlá fún ara mi, òfo ni ọlá mi. Baba mi ni ó bu ọlá fún mi, òun ni ẹ̀yin ń pè ní Ọlọrun yín.

55 Ẹ kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn èmi mọ̀ ọ́n. Bí mo bá sọ pé èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóo di òpùrọ́ bíi yín. Ṣugbọn mo mọ̀ ọ́n, mo sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.

56 Inú Abrahamu baba yín dùn láti rí àkókò wíwá mi, ó rí i, ó sì yọ̀.”

57 Àwọn Juu sọ fún un pé, “Ìwọ yìí ti rí Abrahamu, nígbà tí o kò ì tíì tó ẹni aadọta ọdún?”

58 Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kí wọ́n tó bí Abrahamu ni èmi ti wà.”

59 Wọ́n bá ṣa òkúta, wọ́n fẹ́ sọ ọ́ lù ú, ṣugbọn ó fi ara pamọ́, ó bá kúrò ninu Tẹmpili.

Categories
JOHANU

JOHANU 9

Jesu Wo Ẹni tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú Sàn

1 Bí Jesu ti ń kọjá lọ, ó rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá.

2 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé, “Olùkọ́ni, ta ni ó dẹ́ṣẹ̀, ọkunrin yìí ni, tabi àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n fi bí i ní afọ́jú?”

3 Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni.

4 Dandan ni fún mi kí n ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi ní ojúmọmọ, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ ṣú ná, tí ẹnikẹ́ni kò ní lè ṣiṣẹ́.

5 Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”

6 Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó tutọ́ sílẹ̀, ó fi po amọ̀, ó bá fi lẹ ojú ọkunrin náà.

7 Ó wí fún un pé, “Lọ bọ́jú ninu adágún tí ó ń jẹ́ Siloamu.” (Ìtumọ̀ Siloamu ni “rán níṣẹ́.”) Ọkunrin náà lọ, ó bọ́jú, ó bá ríran.

8 Nígbà tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn tí wọn máa ń rí i tẹ́lẹ̀ tí ó máa ń ṣagbe, rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ọkunrin yìí kọ́ ni ó ti máa ń jókòó, tí ó máa ń ṣagbe rí?”

9 Àwọn kan ń sọ pé, “Òun ni!” Àwọn mìíràn ń sọ pé, “Rárá o, ó jọ ọ́ ni.”

Ọkunrin náà ni, “Èmi gan-an ni.”

10 Wọ́n bi í pé, “Báwo ni ojú rẹ́ ti ṣe là?”

11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”

12 Wọ́n bi í pé, “Níbo ni ọkunrin náà wà?”

Ó dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀.”

Àwọn Farisi Wádìí Ìwòsàn Afọ́jú Náà

13 Àwọn kan bá mú ọkunrin tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí yìí lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi.

14 (Ọjọ́ Ìsinmi ni ọjọ́ tí Jesu po amọ̀, tí ó fi la ojú ọkunrin náà.)

15 Àwọn Farisi tún bi ọkunrin náà bí ó ti ṣe ríran. Ó sọ fún wọn pé, “Ó lẹ amọ̀ mọ́ mi lójú, mo lọ bọ́jú, mo bá ríran.”

16 Àwọn kan ninu àwọn Farisi ń sọ pé, “Ọkunrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nítorí kò pa òfin Ọjọ́ Ìsinmi mọ́.”

Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé “Báwo ni ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí?” Ìyapa bá bẹ́ sáàrin wọn.

17 Wọ́n tún bi ọkunrin afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ alára sọ nípa lílà tí ó là ọ́ lójú?”

Ọkunrin náà ní, “Wolii ni.”

18 Àwọn Juu kò gbàgbọ́ pé ó ti fọ́jú rí kí ó tó ríran títí wọ́n fi pe àwọn òbí ọkunrin náà.

19 Wọ́n bi wọ́n pé, “Ọmọ yín nìyí, tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ti ṣe wá ríran nisinsinyii?”

20 Àwọn òbí rẹ̀ dáhùn pé, “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí; ati pé afọ́jú ni a bí i.

21 Ṣugbọn àwa kò mọ̀ bí ó ti ṣe wá ń ríran nisinsinyii. Ẹ bi í, kì í ṣe ọmọde, yóo fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bí ó ti rí.”

22 Àwọn òbí rẹ̀ fèsì báyìí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu; nítorí àwọn Juu ti pinnu láti yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu ni Mesaya kúrò ninu àwùjọ.

23 Nítorí èyí ni àwọn òbí ọkunrin náà ṣe sọ pé, “Kì í ṣe ọmọde, ẹ bi òun alára léèrè.”

24 Wọ́n tún pe ọkunrin náà tí ó ti fọ́jú rí lẹẹkeji, wọ́n wí fún un pé, “Sọ ti Ọlọrun! Ní tiwa, àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkunrin yìí.”

25 Ọkunrin náà sọ fún wọn pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o, tabi ẹlẹ́ṣẹ̀ kọ́, èmi kò mọ̀. Nǹkankan ni èmi mọ̀: afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii, mo ríran.”

26 Wọ́n bi í pé, “Kí ni ó ṣe sí ọ? Báwo ni ó ti ṣe là ọ́ lójú?”

27 Ó dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ fun yín lẹ́ẹ̀kan ná, ṣugbọn ẹ kò fẹ́ gbọ́. Kí ló dé tí ẹ fi tún fẹ́ gbọ́? Àbí ẹ̀yin náà fẹ́ di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni?”

28 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u, wọ́n ní, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ní tiwa, ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni wá.

29 Àwa mọ̀ pé Ọlọrun ti bá Mose sọ̀rọ̀, ṣugbọn a kò mọ ibi tí eléyìí ti yọ wá.”

30 Ọkunrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ohun ìyanu ni èyí! Ẹ kò mọ ibi tí ó ti yọ wá, sibẹ ó là mí lójú.

31 A mọ̀ pé Ọlọrun kì í fetí sí ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn a máa fetí sí ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

32 Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé a kò rí i gbọ́ pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú rí.

33 Bí ọkunrin yìí kò bá wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, kì bá tí lè ṣe ohunkohun.”

34 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ìwọ yìí tí wọ́n bí ninu ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n tọ́ dàgbà ninu ẹ̀ṣẹ̀, o wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!” Wọ́n bá tì í jáde.

Ìfọ́jú ti Ẹ̀mí

35 Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ti ọkunrin náà jáde kúrò ninu ilé ìpàdé. Nígbà tí ó rí i, ó bí i pé, “Ìwọ gba Ọmọ-Eniyan gbọ́ bí?”

36 Ọkunrin náà dáhùn pé, “Alàgbà, ta ni ẹni náà, kí n lè gbà á gbọ́?”

37 Jesu wí fún un pé, “Èmi tí ò ń wò yìí, tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.”

38 Ọkunrin náà dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́, Oluwa!” Ó bá dọ̀bálẹ̀ fún un.

39 Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”

40 Farisi wà láàrin àwọn eniyan tí ó wà pẹlu rẹ̀, tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n bi í pé, “Àbí àwa náà fọ́jú?”

41 Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ fọ́jú, ẹ kò bá tí ní ẹ̀bi. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ sọ pé, ‘Àwa ríran’ ẹ̀bi yín wà sibẹ.”