Categories
JOBU

JOBU 40

1 OLUWA tún sọ fún Jobu pé,

2 “Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́?

Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.”

3 Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní:

4 “OLUWA, kí ni mo jámọ́,

tí n óo fi dá ọ lóhùn?

Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.

5 Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,

n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”

6 Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní,

7 “Múra gírí bí ọkunrin,

mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn.

8 Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni?

O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre?

9 Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun,

àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?

10 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́,

kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ.

11 Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga,

kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12 Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ,

rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13 Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀,

dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.

14 Nígbà náà ni n óo gbà pé,

agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun.

15 “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi,

tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ,

koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!

16 Wò ó bí ó ti lágbára tó!

Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.

17 Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari,

gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.

18 Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ,

ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin.

19 “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá,

sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á.

20 Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ,

níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré.

21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi,

lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀.

22 Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó,

igi tí ó wà létí odò yí i ká.

23 Kò náání ìgbì omi,

kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀.

24 Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un?

Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀?

Categories
JOBU

JOBU 41

1 “Ṣé o lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani jáde,

tabi kí o fi okùn di ahọ́n rẹ̀?

2 Ṣé o lè fi okùn sí imú rẹ̀,

tabi kí o fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní àgbọ̀n?

3 Ṣé yóo bẹ̀ ọ́,

tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?

4 Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu,

pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae?

5 Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ,

tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ?

6 Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀?

Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn?

7 Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀,

tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀?

8 Lọ fọwọ́ kàn án;

kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà;

o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae!

9 “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,

nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.

10 Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?

Ta ló tó kò ó lójú?

11 Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?

Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.

12 “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,

tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.

13 Ta ló tó bó awọ rẹ̀,

tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀?

14 Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀?

Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù.

15 Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata,

a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì.

16 Àwọn ìpẹ́ náà lẹ̀ mọ́ ara wọn tímọ́tímọ́,

tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè fẹ́ kọjá láàrin wọn.

17 Wọ́n so pọ̀,

wọ́n lẹ̀ mọ́ ara wọn tóbẹ́ẹ̀,

tí ohunkohun kò lè ṣí wọn.

18 Bí ó bá sín, ìmọ́lẹ̀ á tàn jáde ní imú rẹ̀,

ojú rẹ̀ ń tàn bíi ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kutukutu.

19 Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde,

bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá.

20 Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀,

bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó.

21 Èémí tí ó ń mí jáde dàbí ògúnná,

ahọ́n iná ń yọ ní ẹnu rẹ̀.

22 Kìkì agbára ni ọrùn rẹ̀,

ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.

23 Ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ pọ̀ mọ́ ara wọn,

wọ́n lẹ̀ pọ̀, wọn kò sì ṣe é ṣí.

24 Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,

ó le ju ọlọ lọ.

25 Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára,

wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí.

26 Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,

bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.

27 Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀,

idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà.

28 Bí wọn ta á lọ́fà, kò ní torí rẹ̀ sá,

àwọn òkúta kànnàkànnà dàbí àgékù koríko lójú rẹ̀.

29 Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀,

a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín.

30 Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú,

wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́.

31 Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò,

ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara.

32 Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀,

eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni.

33 Kò sí ohun tí a lè fi wé láyé,

ẹ̀dá tí ẹ̀rù kì í bà.

34 Ó fojú tẹmbẹlu gbogbo ohun gíga,

ó sì jọba lórí gbogbo àwọn ọmọ agbéraga.”

Categories
JOBU

JOBU 42

1 Jobu bá dá OLUWA lóhùn ó ní:

2 “Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo,

kò sì sí ohun tí ó lè da ìpinnu rẹ rú.

3 Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye?

Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi,

ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi,

n kò sì mọ̀ wọ́n.

4 O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀,

nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,

kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi.

5 Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀,

ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ;

6 nítorí náà, ojú ara mi tì mí,

fún ohun tí mo ti sọ,

mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.”

Ìparí

7 Lẹ́yìn ìgbà tí OLUWA ti bá Jobu sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Elifasi ará Temani pé, “Inú ń bí mi sí ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji. Nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi, bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.

8 Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”

9 Nítorí náà, Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha, ati Sofari ará Naama lọ ṣe ohun tí OLUWA sọ fún wọn, OLUWA sì gbọ́ adura Jobu.

10 Lẹ́yìn ìgbà tí Jobu gbadura fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta tán, OLUWA dá ọrọ̀ Jobu pada, ó sì jẹ́ kí ó ní ìlọ́po meji àwọn ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.

11 Àwọn arakunrin ati arabinrin Jobu ati àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pada wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n jẹ àsè ní ilé rẹ̀, wọ́n káàánú rẹ̀, wọ́n sì tù ú ninu, nítorí ohun burúkú tí OLUWA ti mú wá sórí rẹ̀, olukuluku wọn fún un ní owó ati òrùka wúrà kọ̀ọ̀kan.

12 OLUWA bukun ìgbẹ̀yìn Jobu ju ti iṣaaju rẹ̀ lọ, ó ní ẹgbaaje (14,000) aguntan, ẹgbaata (6,000) ràkúnmí, ẹgbẹrun (1,000) àjàgà mààlúù ati ẹgbẹrun (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

13 Ó tún bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.

14 Ó pe àkọ́bí obinrin ni Jemima, ekeji ni Kesaya, ẹkẹta ni Kereni Hapuki.

15 Kò sì sí ọmọbinrin tí ó lẹ́wà bí àwọn ọmọbinrin Jobu ní gbogbo ayé. Baba wọn sì fún wọn ní ogún láàrin àwọn arakunrin wọn.

16 Lẹ́yìn náà Jobu tún gbé ogoje (140) ọdún sí i láyé, ó rí àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹrin.

17 Ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́ kí ó tó kú.