Categories
JOBU

JOBU 10

1 “Ayé sú mi,

nítorí náà n kò ní dákẹ́ ìráhùn;

n óo sọ̀rọ̀ pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn.

2 N óo sọ fún Ọlọrun pé

kí ó má dá mi lẹ́bi;

kí ó sì jẹ́ kí n mọ ìdí

tí ó fi ń bá mi jà.

3 Ṣé ohun tí ó dára ni, Ọlọrun

pé kí o máa ni eniyan lára,

kí o kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

kí o sì fẹ́ràn ète ẹni ibi?

4 Ǹjẹ́ ojú rẹ dàbí ti eniyan?

Ǹjẹ́ a máa rí nǹkan bí eniyan ṣe rí i?

5 Ǹjẹ́ bí ọjọ́ ti eniyan ni ọjọ́ rẹ rí?

Ǹjẹ́ ọdún rẹ rí bíi ti eniyan?

6 Tí o fi wá ń wádìí àṣìṣe mi,

tí o sì ń tanná wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?

7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi,

ati pé kò sí ẹnikẹ́ni

tí ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.

8 Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi,

ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run.

9 Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí,

ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni?

10 Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà,

tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè?

11 Ìwọ ni o fi awọ ati ẹran bò mí,

tí o rán egungun ati iṣan mi pọ̀.

12 O fún mi ní ìyè,

o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi,

ìtọ́jú rẹ sì ti gbé ẹ̀mí mi ró.

13 Sibẹ o pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́ sọ́kàn rẹ,

mo mọ̀ pé èrò ọkàn rẹ ni pé,

14 bí mo bá ṣẹ̀, o óo dójú lé mi,

o kò ní jẹ́ kí n lọ láìjìyà.

15 Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé,

ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn,

nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀.

16 Bí mo bá ṣe àṣeyọrí,

o óo máa lépa mi bíi kinniun;

ò ń lo agbára rẹ láti pa mí lára.

17 O wá àwọn ẹlẹ́rìí tuntun pé kí wọ́n dojú kọ mí,

O tún bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí mi lọpọlọpọ,

O mú kí ogun mìíràn dó tì mí.

18 “Kí ló dé tí o fi mú mi jáde láti inú ìyá mi?

Ìbá sàn kí n ti kú,

kí ẹnikẹ́ni tó rí mi.

19 Wọn ìbá má bí mi rárá,

kí wọ́n gbé mi láti inú ìyá mi lọ sinu ibojì.

20 Ṣebí ọjọ́ díẹ̀ ni mo níláti lò láyé?

Fi mí sílẹ̀ kí n lè ní ìtura díẹ̀,

21 kí n tó pada síbi tí mo ti wá,

sí ibi òkùnkùn biribiri,

22 ibi òkùnkùn ati ìdàrúdàpọ̀,

níbi tí ìmọ́lẹ̀ ti dàbí òkùnkùn.”

Categories
JOBU

JOBU 11

1 Sofari ará Naama dáhùn pé,

2 “Ǹjẹ́ ó dára kí eniyan sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ kalẹ̀ báyìí kí ó má sì ìdáhùn?

Àbí, ṣé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lè mú kí á dá eniyan láre?

3 Ṣé o rò pé ìsọkúsọ rẹ lè pa eniyan lẹ́nu mọ́ ni?

Tabi pé bí o bá ń ṣe ẹlẹ́yà ẹnikẹ́ni kò lè dójútì ọ́?

4 Nítorí o sọ pé ẹ̀kọ́ rẹ tọ̀nà,

ati pé ẹni mímọ́ ni ọ́ lójú Ọlọrun.

5 Ọlọrun ìbá ya ẹnu rẹ̀,

kí ó sọ̀rọ̀ sí ọ.

6 Kì bá jẹ́ fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́,

nítorí ìmọ̀ rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ.

Mọ̀ dájú pé ìyà tí Ọlọrun fi jẹ ọ́

kò to nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.

7 “Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun?

Tabi kí o tọpinpin Olodumare?

8 Ó ga ju ọ̀run lọ, kí lo lè ṣe sí i?

Ó jìn ju isà òkú lọ, kí lo lè mọ̀ nípa rẹ̀?

9 Ó gùn ju ayé lọ,

Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ.

10 Tí ó bá ń kọjá lọ, tí ó sì ti eniyan mọ́lé,

tí ó pe olúwarẹ̀ lẹ́jọ́,

ta ló lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò?

11 Nítorí ó mọ àwọn eniyan lásán,

ṣé bí ó bá rí ẹ̀ṣẹ̀,

kí ó má ṣe akiyesi rẹ̀?

12 Ó di ìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ọmọ rẹ̀ ní eniyan,

kí òmùgọ̀ eniyan tó gbọ́n.

13 “Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́,

o óo lè nawọ́ sí i.

14 Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́,

má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ.

15 Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi;

o óo wà láìléwu,

o kò sì ní bẹ̀rù.

16 O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ,

nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀,

yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ.

17 Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;

òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀.

18 Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí,

a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu.

19 O óo sùn, láìsí ìdágìrì,

ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ.

20 Àwọn ẹni ibi óo pòfo;

gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálà

ni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú,

ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.”

Categories
JOBU

JOBU 12

1 Jobu dáhùn pé:

2 “Láìsí àní àní,

ẹ̀yin ni agbẹnusọ gbogbo eniyan,

bí ẹ bá jáde láyé,

ọgbọ́n kan kò tún ní sí láyé mọ́.

3 Bí ẹ ti ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà ní,

ẹ kò sàn jù mí lọ.

Ta ni kò mọ irú nǹkan, tí ẹ̀ ń sọ yìí?

4 Mo wá di ẹlẹ́yà lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi,

èmi tí mò ń ké pe Ọlọrun,

tí ó sì ń dá mi lóhùn;

èmi tí mo jẹ́ olódodo ati aláìlẹ́bi,

mo wá di ẹlẹ́yà.

5 Lójú ẹni tí ara tù,

ìṣòro kì í báni láìnídìí.

Lójú rẹ̀, ẹni tí ó bá ṣìṣe ni ìṣòro wà fún.

6 Àwọn olè ń gbé ilé wọn ní alaafia,

àwọn tí wọn ń mú Ọlọrun bínú wà ní àìléwu,

àwọn tí ó jẹ́ pé agbára wọn ni Ọlọrun wọn.

7 “Ṣugbọn, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹranko, wọn óo sì kọ́ ọ,

bi àwọn ẹyẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ;

8 tabi kí o bi àwọn koríko, wọn yóo sì kọ́ ọ,

àwọn ẹja inú òkun yóo sì ṣe àlàyé fún ọ.

9 Ta ni kò mọ̀ ninu gbogbo wọn

pé OLUWA ló ṣe èyí?

10 Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà,

ati ẹ̀mí gbogbo eniyan.

11 Ṣebí etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,

ahọ́n a sì máa tọ́ oúnjẹ wò?

12 “Àgbà ló ni ọgbọ́n,

àwọn ogbó tí wọ́n ti pẹ́ láyé ni wọ́n ni òye.

13 Ọlọrun ló ni ọgbọ́n ati agbára,

tirẹ̀ ni ìmọ̀ràn ati ìmọ̀.

14 Ohun tí Ọlọrun bá wó lulẹ̀,

ta ló lè tún un kọ́?

Tí ó bá ti eniyan mọ́lé,

ta ló lè tú u sílẹ̀?

15 Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé,

bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀.

16 Òun ló ni agbára ati ọgbọ́n,

òun ló ni ẹni tí ń tan ni jẹ,

òun náà ló ni ẹni tí à ń tàn.

17 Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,

ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18 Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀,

ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí.

19 Ó rẹ àwọn alufaa sílẹ̀,

ó sì gba agbára lọ́wọ́ àwọn alágbára.

20 Ó pa àwọn agbẹnusọ lẹ́nu mọ́,

ó gba ìmọ̀ àwọn àgbààgbà.

21 Ó dójúti àwọn olóyè,

ó tú àmùrè àwọn alágbára.

22 Ó mú ohun òkùnkùn wá sí ìmọ́lẹ̀,

ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri.

23 Òun níí sọ àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá,

òun náà níí sìí tún pa wọ́n run:

Òun níí kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ,

òun náà níí sì ń tú wọn ká.

24 Ó gba ìmọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjòyè ní gbogbo ayé,

ó sì sọ wọ́n di alárìnká ninu aṣálẹ̀,

níbi tí ọ̀nà kò sí.

25 Wọ́n ń táràrà ninu òkùnkùn,

ó sì mú kí wọ́n máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí.

Categories
JOBU

JOBU 13

1 “Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí,

tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi.

2 Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n,

ẹ kò sàn jù mí lọ.

3 Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀,

Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́.

4 Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi,

ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn.

5 Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni,

à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n!

6 Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi,

kí ẹ sì fetísí àròyé mi.

7 Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni,

kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀?

8 Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni?

Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀?

9 Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò?

Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan?

10 Dájúdájú, yóo ba yín wí,

bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀.

11 Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín,

jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín.

12 Àwọn òwe yín kò wúlò,

àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

13 Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi,

kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi.

14 N óo dijú, n óo fi ẹ̀mí ara mi wéwu.

15 Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí;

sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀.

16 Èyí ni yóo jẹ́ ìgbàlà mi,

nítorí pé ẹni tí kò mọ Ọlọrun,

kò ní lè dúró níwájú rẹ̀.

17 Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi,

kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé.

18 Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀;

mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre.

19 Ta ni yóo wá bá mi rojọ́?

Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú.

20 Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi,

n kò sì ní farapamọ́ fún ọ:

21 ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi,

má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí.

22 Lẹ́yìn náà, sọ̀rọ̀, n óo sì fèsì;

tabi kí o jẹ́ kí èmi sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi lésì.

23 Báwo ni àìdára ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó?

Jẹ́ kí n mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati ibi tí mo ti kọjá ààyè mi.

24 Kí ló dé tí o fi fi ara pamọ́ fún mi

tí o kà mí kún ọ̀tá rẹ?

25 Ṣé o óo máa dẹ́rùba ewé lásán tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,

tabi o óo máa lépa ìyàngbò gbígbẹ?

26 O ti kọ àkọsílẹ̀ burúkú nípa mi,

o mú mi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi.

27 O kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lẹ́sẹ̀,

ò ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,

o sì pa ààlà tí n kò gbọdọ̀ rékọjá.

28 Eniyan ń ṣègbé lọ bí ohun tí ó ń jẹrà,

bí aṣọ tí ikán ti mu.

Categories
JOBU

JOBU 14

1 “Ẹnikẹ́ni tí obinrin bá bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,

ó sì kún fún ìpọ́njú.

2 Yóo kọ́ yọ bí òdòdó, lẹ́yìn náà yóo sì rẹ̀ dànù.

Yóo kọjá lọ bí òjìji, kò sì ní sí mọ́.

3 Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni o dojú kọ,

tí ò ń bá ṣe ẹjọ́?

4 Ta ló lè mú ohun mímọ́ jáde

láti inú ohun tí kò mọ́?

Kò sí ẹni náà.

5 Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un,

tí o mọ iye oṣù rẹ̀,

tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá.

6 Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi,

kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe.

7 “Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé,

yóo tún pada rúwé,

ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ.

8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀,

tí kùkùté rẹ̀ sì kú,

9 bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ,

yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn.

10 Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì,

bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí.

11 Bí adágún omi tíí gbẹ,

ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ,

12 bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn,

tí kì í sìí jí mọ́,

títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí,

tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun.

13 Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì,

kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀,

ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi.

14 Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́?

N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi,

n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé.

15 O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn,

o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16 Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi,

o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi.

17 O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò,

o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀.

18 “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú,

a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀.

19 Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta,

tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ,

bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo.

20 O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ,

o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ.

21 Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀,

a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i.

22 Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀,

ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.”

Categories
JOBU

JOBU 15

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Keji

1 Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,

2 “Ṣé ọlọ́gbọ́n a máa fọ èsì tí kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́?

Kí ó dàbí àgbá òfìfo?

3 Kí ó máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò,

tabi ọ̀rọ̀ tí kò níláárí?

4 Ṣugbọn ò ń kọ ìbẹ̀rù Ọlọrun sílẹ̀,

o sì ń dènà adura níwájú rẹ̀.

5 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni ó ń fa irú ọ̀rọ̀ tí ń ti ẹnu rẹ jáde,

ètè rẹ sì kún fún àrékérekè.

6 Ẹnu rẹ ni ó dá ọ lẹ́bi, kì í ṣe èmi;

ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa rẹ ní ń ta kò ọ́.

7 “Ṣé ìwọ ni ẹni kinni tí wọ́n kọ́ bí láyé?

Tabi o ṣàgbà àwọn òkè?

8 Ṣé o wà ninu ìgbìmọ̀ Ọlọrun?

Tabi ìwọ nìkan ni o rò pé o gbọ́n?

9 Kí ni o mọ̀, tí àwa náà kò mọ̀?

Òye kí ni o ní, tí ó jẹ́ ohun ìpamọ́ fún àwa?

10 Àwọn tí wọ́n hu ewú lórí wà láàrin wa, ati àwọn àgbàlagbà,

àwọn tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.

11 Ṣé ìtùnú Ọlọrun kò tó fún ọ ni,

àní ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń sọ fún ọ?

12 Àgbéré kí lò ń ṣe,

tí o sì ń fi ojú burúkú wò wá.

13 Tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun,

tí ò ń jẹ́ kí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ti ẹnu rẹ jáde?

14 Kí ni eniyan jẹ́, tí ó fi lè mọ́ níwájú Ọlọrun?

Kí ni ẹnikẹ́ni tí obinrin bí já mọ́, tí ó fi lè jẹ́ olódodo?

15 Wò ó, Ọlọrun kò fọkàn tán àwọn angẹli,

àwọn ọ̀run kò sì mọ́ níwájú rẹ̀.

16 Kí á má tilẹ̀ wá sọ ti eniyan

tí ó jẹ́ aláìmọ́ ati ẹlẹ́gbin,

tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi!

17 “Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ,

n óo sọ ohun tí ojú mi rí,

18 (ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ,

tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́,

19 àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà,

àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn).

20 Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,

àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà.

21 Etí rẹ̀ kún fún igbe tí ó bani lẹ́rù,

ninu ìdẹ̀ra rẹ̀ àwọn apanirun yóo dìde sí i.

22 Kò gbàgbọ́ pé òun lè jáde kúrò ninu òkùnkùn;

ati pé dájú, ikú idà ni yóo pa òun.

23 Ó ń wá oúnjẹ káàkiri, ó ń bèèrè pé,

‘Níbo ló wà?’

Òun gan-an sì nìyí, oúnjẹ àwọn igún!

Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn ti súnmọ́ tòsí.

24 Ìdààmú ati ìrora dẹ́rùbà á,

wọ́n ṣẹgun rẹ̀, bí ọba tí ó múra ogun.

25 Nítorí pé ó ṣíwọ́ sókè sí Ọlọrun,

o sì ṣe oríkunkun sí Olodumare,

26 ó ń ṣe oríkunkun sí i,

ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà;

27 nítorí pé ó sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú rẹ̀ yíbò,

ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ kìkì ọ̀rá.

28 Ó ń gbé ìlú tí ó ti di ahoro,

ninu àwọn ilé tí eniyan kò gbọdọ̀ gbé,

àwọn ilé tí yóo pada di òkítì àlàpà.

29 Kò ní ní ọrọ̀,

ohun tí ó bá ní, kò ní pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,

òun alára kò sì ní fìdí múlẹ̀.

30 Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn,

iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀,

afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù.

31 Kí ó má gbẹ́kẹ̀lé òfo,

kí ó má máa tan ara rẹ̀ jẹ,

nítorí òfo ni yóo jẹ́ èrè rẹ̀.

32 A ó san án fún un lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́jọ́ àìpé,

gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ ni yóo sì gbẹ.

33 Yóo gbọn àwọn èso rẹ̀ tí kò tíì pọ́n dànù, bí àjàrà,

yóo sì gbọn àwọn ìtànná rẹ̀ dànù, bí igi olifi.

34 Nítorí asán ni àwùjọ àwọn tí wọn kò mọ Ọlọ́run,

iná yóo sì jó ilé àwọn tí ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

35 Wọ́n ń ro èrò ìkà,

wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi,

wọ́n sì ń pète ẹ̀tàn lọ́kàn.”

Categories
JOBU

JOBU 16

1 Jobu bá dáhùn pé,

2 “Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí,

ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín.

3 Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin?

Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí?

4 Bí ẹ bá wà ní ipò mi,

èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí,

kí n da ọ̀rọ̀ bò yín,

kí n sì máa mi orí si yín.

5 Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun,

kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín.

6 “Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí,

bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi?

7 Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara,

ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro.

8 Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí;

rírù tí mo rù ta àbùkù mi,

ó sì hàn lójú mi.

9 Ó ti fi ibinu fà mí ya,

ó sì kórìíra mi;

ó pa eyín keke sí mi;

ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí.

10 Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,

wọ́n ń gbá mi létí,

wọ́n kó ara wọn jọ sí mi.

11 Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́,

ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà.

12 Nígbà tí ó dára fún mi,

ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀,

ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀,

ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́;

ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí.

13 Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká,

ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi,

ó sì tú òróòro mi jáde.

14 Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo,

ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun.

15 “Mo fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara,

mo sùn gbalaja sinu erùpẹ̀.

16 Mo sọkún títí ojú mi fi pọ́n,

omijé sì mú kí ojú mi ṣókùnkùn,

17 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ibi,

adura mi sì mọ́.

18 “Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀,

má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo.

19 Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run,

alágbàwí mi sì ń bẹ lókè.

20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,

mo sì ń sọkún sí Ọlọrun,

21 ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun,

bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan.

22 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i,

n óo lọ àjò àrèmabọ̀.

Categories
JOBU

JOBU 17

1 “Ọkàn mi bàjẹ́, ọjọ́ ayé mi ti dópin,

ibojì sì ń dúró dè mí.

2 Dájúdájú àwọn ẹlẹ́yà yí mi káàkiri,

wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ lojukooju.

3 Fi nǹkan ẹ̀jẹ́ kan lélẹ̀ fún mi lọ́dọ̀ rẹ;

ta ló wà níbẹ̀ tí yóo ṣe onídùúró fún mi?

4 Níwọ̀n ìgbà tí o ti mú ọkàn wọn yigbì sí ìmọ̀,

nítorí náà, o kò ní jẹ́ kí wọ́n borí.

5 Bí ẹnìkan bá hùwà ọ̀dàlẹ̀, tí ó ṣòfófó àwọn ọ̀rẹ́,

kí ó lè pín ninu ohun ìní wọn,

àwọn ọmọ olúwarẹ̀ yóo jìyà.

6 O ti sọ mí di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn eniyan,

mo di ẹni tí à ń tutọ́ sí lára.

7 Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,

gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji.

8 Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,

aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.

9 Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,

ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.

10 Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ,

n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín.

11 “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú,

àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán.

12 Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,

wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’

13 Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi,

tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn,

14 bí mo bá pe isà òkú ní baba,

tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi,

15 níbo ni ìrètí mi wá wà?

Ta ló lè rí ìrètí mi?

16 Ṣé yóo lọ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni?

Ṣé àwa mejeeji ni yóo jọ wọ inú erùpẹ̀ lọ?”

Categories
JOBU

JOBU 18

1 Bilidadi ará Ṣuha bá tún dáhùn pé,

2 “Ìgbàwo ni o óo sinmi ẹjọ́ tí ò ń tò yìí?

Ohun tí a tí ń bá ọ sọ ni kí o gbé yẹ̀wò,

kí á lè sọ èyí tí a tún fẹ́ sọ.

3 Kí ló dé tí o fi kà wá sí ẹranko,

tí a di òmùgọ̀ lójú rẹ?

4 Ìwọ tí o faraya nítorí inú ń bí ọ,

ṣé kí á sá kúrò láyé nítorí rẹ ni,

tabi kí á ṣí àwọn àpáta nípò pada?

5 “Nítòótọ́, a ti pa fìtílà ẹni ibi,

ahọ́n iná rẹ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.

6 Inú àgọ́ rẹ̀ ṣókùnkùn,

a sì ti pa àtùpà ìgbèrí rẹ̀.

7 Agbára rẹ̀ ti dín kù,

ète rẹ̀ sì gbé e ṣubú.

8 Ó ti ẹsẹ̀ ara rẹ̀ bọ àwọ̀n,

ó ń rìn lórí ọ̀fìn.

9 Tàkúté ti mú un ní gìgísẹ̀,

ó ti kó sinu pańpẹ́.

10 A dẹ okùn sílẹ̀ fún un,

a sì dẹ pańpẹ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀.

11 “Ìbẹ̀rù yí i ká,

wọ́n ń lé e kiri.

12 Ebi pa agbára mọ́ ọn ninu,

ìṣòro sì ti ṣetán láti gbé e ṣubú.

13 Àìsàn burúkú jẹ awọ ara rẹ̀,

àkọ́bí ikú jẹ ẹ́ tọwọ́ tẹsẹ̀.

14 A fipá wọ́ ọ kúrò ninu àgọ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,

a sì mú un lọ sọ́dọ̀ Ọba Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀.

15 Àgọ́ rẹ̀ kún fún àwọn tí kì í ṣe tirẹ̀,

imí-ọjọ́ fọ́nká sí gbogbo ibùgbé rẹ̀.

16 Gbòǹgbò rẹ̀ gbẹ nísàlẹ̀,

ẹ̀ka rẹ̀ sì gbẹ lókè.

17 Ó di ẹni ìgbàgbé lórílẹ̀ ayé,

bẹ́ẹ̀ ni a kò gbórúkọ rẹ̀ mọ́ ní ìgboro.

18 Wọ́n tì í láti inú ìmọ́lẹ̀ sinu òkùnkùn,

wọ́n lé e kúrò láyé.

19 Kò lọ́mọ, kò lọ́mọ ọmọ,

kò sì sí ẹni tí yóo rọ́pò rẹ̀ ní ibùgbé rẹ̀,

láàrin àwọn eniyan rẹ̀.

20 Ẹnu yóo ya àwọn ará ìwọ̀ oòrùn,

ìwárìrì yóo sì mú àwọn ará ìlà oòrùn,

nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.

21 Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé ẹni ibi yóo rí,

àní, ilé ẹni tí kò mọ Ọlọrun.”

Categories
JOBU

JOBU 19

1 Jobu bá dáhùn, ó ní,

2 “Ẹ óo ti ni mí lára pẹ́ tó,

tí ẹ óo máa fi ọ̀rọ̀ yín bà mí ninu jẹ́?

3 Ẹ kẹ́gàn mi ní àìníye ìgbà

ojú kò tilẹ̀ tì yín láti ṣẹ̀ mí?

4 Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé lótìítọ́ ni mo ṣẹ̀,

ṣebí ara mi ni àṣìṣe mi wà?

5 Bí ẹ bá rò pé ẹ sàn jù mí lọ,

tí ẹ sì rò pé ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ni ìdààmú mi,

6 ẹ mọ̀ dájú pé Ọlọrun ni ó dá mi lẹ́bi,

tí ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

7 Mò ń kérora pé wọ́n dá mi lóró,

ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn;

mo pariwo, pariwo,

ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dìde láti ṣe ẹ̀tọ́.

8 Ọlọrun ti dí ọ̀nà mọ́ mi, kí n má baà kọjá,

ó mú ọ̀nà mi ṣókùnkùn.

9 Ó bọ́ ògo mi kúrò,

ó sì gba adé orí mi.

10 Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà,

ó sì ti parí fún mi,

ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu.

11 Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná,

ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀.

12 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ,

wọ́n dó tì mí,

wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká.

13 “Ó mú kí àwọn arakunrin mi jìnnà sí mi,

àwọn ojúlùmọ̀ mi sì di àjèjì sí mi.

14 Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀.

15 Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi.

Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò,

wọ́n ń wò mí bí àjèjì.

16 Mo pe iranṣẹ mi, ṣugbọn kò dáhùn,

bíbẹ̀ ni mo níláti máa bẹ̀ ẹ́.

17 Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ iyawo mi,

mo sì ń rùn sí àwọn ọmọ ìyá mi.

18 Àwọn ọmọde pàápàá ń fojú tẹmbẹlu mi;

bí mo bá dìde wọn á máa sọ̀rọ̀ sí mi.

19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti rí mi sá,

àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.

20 Mo rù kan egungun,

agbára káká ni mo fi sá àsálà.

21 Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,

nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!

22 Ọlọrun ń lépa mi,

ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi!

Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín?

23 “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀!

Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé!

24 Kí á fi kálàmú irin ati òjé

kọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae.

25 Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè,

ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,

26 lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́,

ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run.

27 Fúnra mi ni n óo rí i,

ojú ara mi ni n óo sì fi rí i,

kì í ṣe ti ẹlòmíràn.

“Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi!

28 Bí ẹ bá wí pé, ‘Báwo ni a óo ṣe lépa rẹ̀!’

Nítorí pé òun ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí,

29 ṣugbọn, ẹ bẹ̀rù idà,

nítorí pé ìrúnú níí fa kí á fi idà pa eniyan,

kí ẹ lè mọ̀ dájú pé ìdájọ́ ń bẹ.”