Categories
JOBU

JOBU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Jobu

jẹ́ ìtàn ọkunrin rere kan tí oríṣìíríṣìí ìṣòro dé bá–ó pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ ati ohun ìní rẹ̀, oówo burúkú tún dà bò ó. Ẹni tí ó kọ ìwé yìí fi ewì ṣe àgbékalẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pataki láàrin Jobu ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lórí àwọn àjálù tí ó dé bá Jobu. Àjọṣe láàrin Ọlọrun ati àwọn eniyan ni kókó tí wọ́n tẹnumọ́ jù ninu ọ̀rọ̀ wọn; níkẹyìn Ọlọrun fara han Jobu.

Àwọn ọ̀rẹ́ Jobu fi ojú ìdájọ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wo àjálù tí ó dé bá Jobu. Igbagbọ tiwọn ni pé Ọlọrun a máa san ẹ̀san ohun tí eniyan bá ṣe fún un, ìbáà jẹ́ burúkú tabi ire, ati pé àjálù tí ó dé bá Jobu gbọdọ̀ jẹ́ ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn ní ti Jobu, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀; irú àjálù burúkú yìí kò tọ́ sí i, nítorí ẹni rere ati olódodo eniyan bíi tirẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Pẹlu ẹ̀mí ìgboyà, Jobu bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ìdí tí ó fi lè jẹ́ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí òun. Ninu gbogbo ìṣòro yìí, Jobu di igbagbọ rẹ̀ mú ṣinṣin, ṣugbọn ó fẹ́ kí Ọlọrun dá òun láre kí ó sì jẹ́ kí òun gba ògo òun pada gẹ́gẹ́ bí ẹni rere.

Ọlọrun kò dáhùn sí gbogbo ìbéèrè Jobu, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fi ewì sọ títóbi agbára ńlá rẹ̀ ati ọgbọ́n rẹ̀ fún Jobu. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jobu fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbé Ọlọrun ga gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ati ẹni ńlá, ó sì tọrọ ìdáríjì fún gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó fi ibinu sọ.

Ìparí ọ̀rọ̀ náà ni àkọsílẹ̀ bí Jobu ṣe pada bọ̀ sípò rẹ̀ àtijọ́ tí ó tún ní ọrọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Jobu nìkan ni ó mọ̀ dájú pé Ọlọrun tóbi ju bí àwọn eniyan ṣe ń fi ojú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wò ó lọ. Ọlọrun jẹ àwọn ọ̀rẹ́ Jobu níyà nítorí pé wọn kò mọ ìdí ìnira tí ó dé bá Jobu.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí náà

Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1–2:13

Jobu ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ 3:1–31:40

a. Ìráhùn Jobu 3:1-26

b. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àkọ́kọ́ 4:1–14:22

d. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ẹlẹẹkeji 15:1–21:34

e. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ẹlẹẹkẹta 22:1–27:23

ẹ. Yiyin ọgbọ́n 28:1-28

f. Ọ̀rọ̀ tí Jobu sọ kẹ́yìn 29:1–31:40

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Elihu sọ 32:1–37:24

Èsì tí OLUWA fún Jobu 38:1–42:6

Ọ̀rọ̀ ìparí 42:7-17

Categories
JOBU

JOBU 1

Satani Dán Jobu Wò

1 Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jobu; ó ń gbé ilẹ̀ Usi, ó jẹ́ olódodo ati olóòótọ́ eniyan, ó bẹ̀rù Ọlọrun, ó sì kórìíra ìwà burúkú.

2 Ó bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.

3 Ó ní ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan, ẹgbẹẹdogun (3,000) ràkúnmí, ẹẹdẹgbẹta (500) àjàgà mààlúù, ẹẹdẹgbẹta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ọpọlọpọ iranṣẹ; òun ni ó lọ́lá jùlọ ninu gbogbo àwọn ará ìlà oòrùn.

4 Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa lọ jẹ àsè ninu ilé ara wọn. Olukuluku wọn ní ọjọ́ àsè tirẹ̀, wọn a sì máa pe àwọn arabinrin wọn wá sí ilé láti bá wọn jẹ àsè.

5 Nígbà tí wọ́n bá se àsè náà kárí tán, Jobu yóo ranṣẹ sí wọn láti rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún wọn. Ní àárọ̀ kutukutu, yóo dìde yóo rú ẹbọ sísun fún olukuluku wọn, yóo wí pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti bú Ọlọrun ninu ọkàn wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Jobu máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà.

6 Ní ọjọ́ kan, àwọn ọmọ Ọlọrun wá láti fi ara wọn hàn níwájú OLUWA. Satani náà wà láàrin wọn.

7 OLUWA bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”

Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.”

8 OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?”

9 Satani dáhùn pé, “Ṣé lásán ni Jobu bẹ̀rù ìwọ Ọlọrun ni?

10 Ṣebí nígbà gbogbo ni ò ń dáàbò bo òun ati àwọn ará ilé rẹ̀, ati gbogbo ohun tí ó ní. Ò ń bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, o sì sọ ohun ìní rẹ̀ di pupọ.

11 Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”

12 OLUWA dá Satani lóhùn pé, “Ó dára, ohun gbogbo tí ó ní wà ní ìkáwọ́ rẹ. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan òun fúnra rẹ̀.” Satani bá kúrò níwájú OLUWA.

Ọrọ̀ ati Àwọn Ọmọ Jobu Parun

13 Ní ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Jobu ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkunrin, tí ó jẹ́ àgbà patapata,

14 iranṣẹ kan wá sọ́dọ̀ Jobu, ó ròyìn fún un pé, “Àwọn akọ mààlúù ń fi àjàgà wọn kọlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko nítòsí wọn;

15 àwọn ará Sabea rí wọn, wọ́n sì kó gbogbo wọn, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

16 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Iná Ọlọrun wá láti ọ̀run, ó jó àwọn aguntan ati gbogbo darandaran patapata, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

17 Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ tí iranṣẹ mìíràn fi tún dé, ó ní, “Àwọn ẹgbẹ́ ogun Kalidea mẹta kọlù wá, wọ́n kó gbogbo ràkúnmí wa lọ, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

18 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ iranṣẹ mìíràn dé, ó ní, “Bí àwọn ọmọ rẹ tí ń jẹ àsè ninu ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà,

19 ìjì líle kan fẹ́ la àṣálẹ̀ kọjá, ó fẹ́ lu ilé náà, ó wó, ó sì pa gbogbo wọn, èmi nìkan ni mo sá àsálà láti wá ròyìn fún ọ.”

20 Jobu bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn; ó fá orí rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì sin OLUWA.

21 Ó ní, “Ìhòòhò ni wọ́n bí mi, ìhòòhò ni n óo sì pada lọ. OLUWA níí fún ni ní nǹkan, OLUWA náà ní í sì í gbà á pada, ìyìn ni fún orúkọ OLUWA.”

22 Ninu gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì dá Ọlọrun lẹ́bi.

Categories
JOBU

JOBU 2

Satani Tún Dán Jobu Wò

1 Nígbà tí ó tún yá tí àwọn ọmọ Ọlọrun wá farahàn níwájú OLUWA, Satani náà wà láàrin wọn.

2 OLUWA tún bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”

Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.”

3 Ọlọrun tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé. Ó bẹ̀rù OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú, ó dúró ṣinṣin ninu ìwà òtítọ́ rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o dẹ mí sí i láti pa á run láìnídìí.”

4 Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Ohun gbogbo ni eniyan lè fi sílẹ̀ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

5 Ìwọ fi ọwọ́ kan ara ati eegun rẹ̀ wò, bí kò bá ní sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”

6 OLUWA bá ní, “Ó wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹ̀mí rẹ̀.”

7 Satani bá lọ kúrò níwájú OLUWA, ó sì da oówo bo Jobu lára, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé orí.

8 Jobu ń fi àpáàdì họ ara, ó sì jókòó sinu eérú.

9 Iyawo Jobu bá sọ fún un pé, “Orí òtítọ́ inú rẹ ni o tún wà sibẹ? Fi Ọlọrun bú, kí o kú.”

10 Ṣugbọn ó dáhùn pé, “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ọ̀kan ninu àwọn aláìmòye obinrin bá ń sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ eniyan lè gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun kí ó má gba ibi?” Ninu gbogbo nǹkan wọnyi, Jobu kò dẹ́ṣẹ̀ rárá ninu ọ̀rọ̀ tí ó sọ.

Àwọn Ọ̀rẹ́ Jobu Wá

11 Nígbà tí Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha ati Sofari ará Naama, àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹta, gbọ́ nípa ìyọnu tí ó dé bá Jobu, wọ́n wá láti kí i, ati láti tù ú ninu.

12 Nígbà tí wọ́n rí Jobu ní ọ̀ọ́kán, wọn kò mọ̀ ọ́n mọ́. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n súnmọ́ ọn tí wọ́n mọ̀ pé òun ni, wọ́n bú sẹ́kún, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì ku eruku sórí.

13 Wọ́n jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, tọ̀sán-tòru, láìsọ nǹkankan, nítorí pé wọ́n rí i bí ìrora náà ti pọ̀ tó.

Categories
JOBU

JOBU 3

Jobu Ráhùn sí Ọlọrun

1 Nígbà tí ó yá, Jobu bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó fi ọjọ́ ìbí ara rẹ̀ bú.

2 Ó ní:

3 “Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi,

ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi.

4 Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri!

Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí,

kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́.

5 Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu,

ati òkùnkùn biribiri.

Kí ìkùukùu ṣíji bò ó,

kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á.

6 Kí òkùnkùn ṣú bo alẹ́ ọjọ́ náà biribiri,

kí á yọ ọ́ kúrò ninu àwọn ọjọ́

tí ó wà ninu ọdún,

kí á má sì ṣe kà á kún

àwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ninu oṣù.

7 Kí alẹ́ ọjọ́ náà di òfo,

kí á má ṣe gbọ́ ìró ayọ̀ ninu rẹ̀ mọ́.

8 Kí àwọn tí wọ́n ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi gégùn-ún,

àní àwọn tí wọ́n lè fi àṣẹ rú Lefiatani sókè.

9 Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn,

kí ìrètí rẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ já sí òfo,

kí ó má rí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ mọ́;

10 nítorí pé kò sé inú ìyá mi

nígbà tí ó fẹ́ bí mi,

bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú ibi kúrò lọ́nà mi.

11 “Kí ló dé tí n kò kú

nígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi,

tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi?

12 Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀?

Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú?

13 Ǹ bá ti dùbúlẹ̀,

ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́;

ǹ bá ti sùn,

ǹ bá sì ti máa sinmi

14 pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn,

àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn;

15 tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà,

tí fadaka sì kún ilé wọn.

16 Tabi kí n rí bí ọmọ

tí a bí ní ọjọ́ àìpé,

tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé.

17 Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́,

tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi.

18 Níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbé pọ̀ pẹlu ìrọ̀rùn,

wọn kò sì gbọ́ ohùn akóniṣiṣẹ́ mọ́.

19 Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀,

àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn.

20 “Kí ló dé tí a fi ìmọ́lẹ̀

fún ẹni tí ń kérora,

tí a fi ẹ̀mí fún ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́;

21 tí ó ń wá ikú,

ṣugbọn tí kò rí;

tí ó ń wá ikú lójú mejeeji

ju ẹni tí ń wá ìṣúra tí a fi pamọ́ lọ?

22 Àwọn tí inú wọn ìbá dùn lọpọlọpọ

bí wọ́n bá rí ẹni gbé wọn sin.

23 Kí ló dé tí a fi fi ìmọ́lẹ̀

fún ẹni tí ọ̀nà dàrú mọ́ lójú;

ẹni tí Ọlọrun ti tì sinu àhámọ́?

24 Nítorí ìmí ẹ̀dùn di oúnjẹ fún mi,

ìráhùn mi sì ń tú jáde bí omi.

25 Ohun tí mo bẹ̀rù jù ti dé bá mi,

ohun tí ń fò mí láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.

26 N kò ní alaafia,

bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ̀ mí,

n kò sì ní ìsinmi, àfi ìyọnu.”

Categories
JOBU

JOBU 4

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni

1 Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní:

2 “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀,

ṣé kò ní bí ọ ninu?

Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí?

3 O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan,

o ti fún aláìlera lókun.

4 O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró,

ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára.

5 Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́,

o kò ní sùúrù;

Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ.

6 Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ?

Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?

7 “Ìwọ náà ronú wò,

ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí?

Tabi olódodo kan parun rí?

8 Bí èmi ti rí i sí ni pé,

ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè,

tí ó sì gbin wahala,

yóo kórè ìyọnu.

9 Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run,

ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.

10 Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun,

ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù,

ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.

11 Kinniun alágbára a máa kú,

nítorí àìrí ẹran pa jẹ,

àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.

12 “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létí

mo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.

13 Ninu ìran lóru,

nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,

14 ìbẹ̀rùbojo mú mi,

gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.

15 Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi,

gbogbo irun ara mi sì dìde.

16 Ó dúró jẹ́ẹ́,

ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí.

Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró;

gbogbo nǹkan parọ́rọ́,

nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,

17 ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?

Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?

18 Nígbà tí ó jẹ́ pé,

Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀,

a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;

19 mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ,

tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀,

tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.

20 Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀

kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́,

wọn a parun títí lae

láìsí ẹni tí yóo bìkítà.

21 Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀,

ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’

Categories
JOBU

JOBU 5

1 “Pe ẹnìkan nisinsinyii;

ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn?

Ẹni mímọ́ wo ni o lè tọ̀ lọ?

2 Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀,

owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan.

3 Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀,

ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú.

4 Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀,

wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè,

kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là.

5 Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gún

ni ó ti mú un jáde,

àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri.

6 Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde.

7 A bí eniyan sinu wahala

bí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè.

8 “Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA,

n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́;

9 ẹni tíí ṣe ohun ńlá

tí eniyan kò lè rídìí,

ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà.

10 A máa rọ òjò sórí ilẹ̀,

a sì máa bomi rin oko.

11 A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga,

a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́.

12 A máa da ète àwọn alárèékérekè rú,

kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn.

13 Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn;

ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.

14 Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan,

wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni.

15 Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn,

ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16 Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka,

a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

17 “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí,

nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare.

18 Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́,

ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni.

Ó ń pa ni lára,

ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn.

19 Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà,

bí ibi ń ṣubú lu ara wọn,

kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ.

20 Ní àkókò ìyàn,

yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú.

Ní àkókò ogun,

yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

21 Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gàn,

o kò ní bẹ̀rù nígbà tí ìparun bá dé.

22 Ninu ìparun ati ìyàn,

o óo máa rẹ́rìn-ín,

o kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko ìgbẹ́.

23 O kò ní kan àwọn òkúta ninu oko rẹ,

àwọn ẹranko igbó yóo wà ní alaafia pẹlu rẹ.

24 O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu.

Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ,

kò ní dín kan.

25 Àwọn arọmọdọmọ rẹ yóo pọ̀,

bí ewéko ninu pápá oko.

26 O óo di arúgbó kí o tó kú,

gẹ́gẹ́ bí ọkà tií gbó

kí á tó kó o wá síbi ìpakà.

27 Wò ó! A ti wádìí àwọn nǹkan wọnyi,

òtítọ́ ni wọ́n.

Gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”

Categories
JOBU

JOBU 6

1 Jobu bá dáhùn pé,

2 “Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi,

tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n,

3 ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ.

Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀.

4 Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára,

oró rẹ̀ sì mú mi.

Ọlọrun kó ìpayà bá mi.

5 Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa ké

tí ó bá rí koríko jẹ?

Àbí mààlúù a máa dún

tí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀?

6 Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹ

láì fi iyọ̀ sí i?

Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin?

7 Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ,

Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi.

8 “Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ,

kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́.

9 Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀,

kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù.

10 Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;

n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,

nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.

11 Agbára wo ni mo ní,

tí mo fi lè tún máa wà láàyè?

Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù?

12 Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí?

Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ?

13 Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́.

14 “Ẹni tí ó bá kọ̀

tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀

kò ní ìbẹ̀rù Olodumare.

15 Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi,

ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrá

tí ó yára kún,

tí ó sì tún yára gbẹ,

16 tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn,

tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ,

17 ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́,

bí ilẹ̀ bá ti gbóná,

wọn a sì gbẹ.

18 Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmí

yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiri

wọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀.

19 Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá,

àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí.

20 Ìrètí wọn di òfo

nítorí wọ́n ní ìdánilójú.

Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀,

ṣugbọn òfo ni wọ́n bá.

21 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii.

Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín.

22 Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín?

Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín,

kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi?

23 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá;

tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára?

24 “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi,

ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi;

n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀.

25 Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára,

ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí.

26 Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni?

Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí?

27 Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn,

ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín.

28 “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára,

nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín.

29 Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀,

kí ẹ má baà ṣẹ̀.

Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi.

30 Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni?

Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀?

Categories
JOBU

JOBU 7

1 “Ìgbésí ayé eniyan le koko,

ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí ti alágbàṣe.

2 Ó dàbí ẹrú tí ń wá ìbòòji kiri

ati bí alágbàṣe tí ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀.

3 Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù,

ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́

4 Bí mo bá sùn lóru,

n óo máa ronú pé,

‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’

Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́,

ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún,

títí ilẹ̀ yóo fi mọ́.

5 Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí,

gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò.

6 Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ,

Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí.

7 “Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́,

ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́.

8 Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́;

níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́.

9 Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí,

kò ní pada mọ́.

10 Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́.

11 “Nítorí náà, n kò ní dákẹ́;

n óo sọ ìrora ọkàn mi;

n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde.

12 Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi,

tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí?

13 Nígbà tí mo wí pé,

‘Ibùsùn mi yóo tù mí lára,

ìjókòó mi yóo sì mú kí ara tù mí ninu ìráhùn mi’.

14 Nígbà náà ni ẹ̀yin tún wá fi àlá yín dẹ́rù bà mí,

tí ẹ sì fi ìran pá mi láyà,

15 kí n lè fara mọ́ ọn pé

ó sàn kí á lọ́ mi lọ́rùn pa,

kí n sì lè yan ikú

dípò pé kí n wà láàyè.

16 Ayé sú mi,

n kò ní wà láàyè títí lae.

Ẹ fi mí sílẹ̀,

nítorí ọjọ́ ayé mi dàbí èémí lásán.

17 Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi gbé e ga,

tí o sì fi ń náání rẹ̀;

18 tí ò ń bẹ̀ ẹ́ wò láràárọ̀,

tí o sì ń dán an wò nígbà gbogbo?

19 Yóo ti pẹ́ tó kí ẹ tó mójú kúrò lára mi?

Kí ẹ tó fi mí lọ́rùn sílẹ̀

kí n rí ààyè dá itọ́ mì?

20 Bí mo bá ṣẹ̀, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ yín,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ́ mi?

Kí ló dé tí ẹ fi dójú lé mi,

tí mo di ẹrù lọ́rùn yín?

21 Kí ló dé tí ẹ kò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí

kí ẹ sì fojú fo àìdára mi?

Láìpẹ́ n óo lọ sinu ibojì.

Ẹ óo wá mi,

ṣugbọn n kò ní sí mọ́.”

Categories
JOBU

JOBU 8

1 Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé,

2 “O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó,

tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle?

3 Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po?

Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada?

4 Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni,

ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

5 Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun,

tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare;

6 tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́,

dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́,

yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ.

7 Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́

lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú.

8 “Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́,

kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa.

9 Nítorí ọmọde ni wá,

a kò mọ nǹkankan,

ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji.

10 Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ,

tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀,

tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn.

11 “Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà?

Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi?

12 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́,

yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko,

láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀

13 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí

ó gbàgbé Ọlọrun rí;

ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun.

14 Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán,

ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn.

15 Ó farati ilé rẹ̀,

ṣugbọn kò le gbà á dúró.

Ó dì í mú,

ṣugbọn kò lè mú un dúró.

16 Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀,

àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀.

17 Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́,

òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta.

18 Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀,

kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí.

19 Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ,

àwọn mìíràn óo dìde,

wọn yóo sì gba ipò rẹ̀.

20 “Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́.

21 Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,

ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀.

22 Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ,

ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.”

Categories
JOBU

JOBU 9

1 Jobu dáhùn pé:

2 “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí,

ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?

3 Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn,

olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè.

4 Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀,

agbára rẹ̀ sì pọ̀.

Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ?

5 Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀;

tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú.

6 Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀,

àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì.

7 Ó pàṣẹ fún oòrùn,

oòrùn kò sì yọ;

ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé;

8 òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ,

tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀.

9 Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run:

Beari, Orioni, ati Pileiadesi

ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù.

10 Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá,

ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà.

11 Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i,

ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀.

12 Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà,

ta ló lè dá a dúró?

Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’

13 “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,

yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀.

14 Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́?

Kí ni kí n sọ?

15 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,

sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn.

Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú,

lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí.

16 Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́,

tí ó sì dá mi lóhùn,

sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi.

17 Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀,

ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí;

18 kò ní jẹ́ kí n mí,

ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi.

19 Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni,

agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ!

Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́,

ta ló lè pè é lẹ́jọ́?

20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,

sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí;

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀,

sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.

21 N kò lẹ́bi,

sibẹ n kò ka ara mi kún,

ayé sú mi.

22 Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀,

nítorí náà ni mo fi wí pé,

ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun.

23 Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀,

tí ó já sí ikú òjijì,

a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn.

24 A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,

ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú.

Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun,

ta ló tún tó bẹ́ẹ̀?

25 “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete,

kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn.

26 Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi,

bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa.

27 Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi,

kí n sì tújúká;

kí n má ronú mọ́;

28 ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí,

nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀.

29 Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi,

kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún?

30 Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀,

kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́,

31 sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí.

Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi.

32 Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi,

tí mo fi lè fún un lésì,

tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́.

33 Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji,

tí ó lè dá wa lẹ́kun.

34 Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀,

kí ó má nà mí mọ́!

Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́!

35 Kí n baà le sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù,

nítorí mo mọ inú ara mi.