Categories
JOṢUA

JOṢUA 10

Wọ́n Ṣẹgun Àwọn Ará Amori

1 Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn,

2 ẹ̀rù bà á gidigidi, nítorí pé ìlú ńlá ni ìlú Gibeoni bí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọba aládé. Gibeoni tóbi ju ìlú Ai lọ, akọni sì ni gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀.

3 Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé,

4 “Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí á kọlu Gibeoni, nítorí pé ó ti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia.”

5 Nígbà náà ni àwọn ọba Amori maraarun, ọba Jerusalẹmu, ti Heburoni, ti Jarimutu, ti Lakiṣi, ati ti Egiloni parapọ̀, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ. Wọ́n lọ dó ti Gibeoni, wọ́n sì ń bá a jagun.

6 Àwọn ará Gibeoni bá ranṣẹ sí Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Giligali. Wọ́n ní, “Ẹ má fi àwa iranṣẹ yín sílẹ̀! Ẹ tètè yára wá gbà wá kalẹ̀, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nítorí pé, gbogbo àwọn ọba Amori, tí wọn ń gbé agbègbè olókè, ti kó ara wọn jọ sí wa.”

7 Joṣua bá lọ láti Giligali, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju ati akọni.

8 OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.”

9 Joṣua jálù wọ́n lójijì, lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru rìn láti Giligali.

10 OLUWA mú kí ìpayà bá àwọn ará Amori, nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Wọ́n lé wọn gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, wọ́n sì pa wọ́n títí dé Aseka ati Makeda.

11 Bí wọ́n sì ti ń sá lọ fún àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ ní ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, OLUWA mú kí àwọn òkúta ńláńlá máa bọ́ lù wọ́n láti ojú ọ̀run, títí tí wọ́n fi dé Aseka, wọ́n sì kú. Àwọn tí òkúta ńláńlá wọnyi pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lọ.

12 Ní ọjọ́ tí OLUWA fi àwọn ará Amori lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, Joṣua bá OLUWA sọ̀rọ̀ lójú gbogbo Israẹli, ó ní,

“Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní Gibeoni.

Ìwọ òṣùpá, sì dúró jẹ́ẹ́ ní àfonífojì Aijaloni.”

13 Oòrùn bá dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró jẹ́ẹ́, títí tí àwọn ọmọ Israẹli fi gbẹ̀san tán lára àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n kọ ọ́ sinu ìwé Jaṣari pé, oòrùn dúró ní agbede meji ojú ọ̀run, kò sì tètè wọ̀ fún bí odidi ọjọ́ kan.

14 Irú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ kò wáyé rí ṣáájú ìgbà náà, bẹ́ẹ̀ sì ni, láti ìgbà náà, kò sì tíì tún ṣẹlẹ̀, pé kí OLUWA gba ọ̀rọ̀ sí eniyan lẹ́nu, èyí ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé, OLUWA jà fún Israẹli.

15 Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí àgọ́ wọn ní Giligali.

Joṣua Fi Ogun Kó Àwọn Ọba Amori Maraarun

16 Àwọn ọba maraarun sá, wọ́n sì fi ara pamọ́ sinu ihò tí ó wà ní Makeda.

17 Àwọn kan wá sọ fún Joṣua pé wọ́n ti rí àwọn ọba maraarun ní ibi tí wọ́n fi ara pamọ́ sí ní Makeda.

18 Joṣua dá wọn lóhùn pé, “Ẹ yí òkúta ńláńlá dí ẹnu ihò náà kí ẹ sì fi àwọn eniyan sibẹ, láti máa ṣọ́ wọn.

19 Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ dúró níbẹ̀, ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín lọ, kí ẹ máa pa wọ́n láti ẹ̀yìn. Ẹ má jẹ́ kí wọ́n pada wọnú ìlú wọn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ti fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”

20 Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ti pa wọ́n ní ìpakúpa tán, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ pa gbogbo wọn run, tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù sì ti sá wọ àwọn ìlú olódi wọn lọ tán,

21 gbogbo àwọn eniyan pada sọ́dọ̀ Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Makeda láìsí ewu.

Kò sì sí ẹni tí ó sọ ìsọkúsọ sí àwọn ọmọ Israẹli.

22 Lẹ́yìn náà, Joṣua ní, “Ẹ ṣí ẹnu ihò náà, kí ẹ sì kó àwọn ọba maraarun náà wá fún mi.”

23 Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni.

24 Nígbà tí wọ́n kó àwọn ọba náà dé ọ̀dọ̀ Joṣua, ó pe gbogbo àwọn ọkunrin Israẹli jọ, ó sọ fún àwọn ọ̀gágun tí wọ́n bá a lọ sí ojú ogun pé, “Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ yín tẹ ọrùn àwọn ọba wọnyi.” Wọ́n bá súnmọ́ Joṣua, wọ́n sì tẹ àwọn ọba náà lọ́rùn mọ́lẹ̀.

25 Joṣua bá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí àyà yín já. Ẹ múra, kí ẹ sì ṣe ọkàn gírí, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀ ń bá jà.”

26 Lẹ́yìn náà, Joṣua fi idà pa wọ́n, ó so wọ́n kọ́ orí igi marun-un, wọ́n sì wà lórí àwọn igi náà títí di ìrọ̀lẹ́.

27 Nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọ́n já òkú wọn lulẹ̀ kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu ihò tí wọ́n sápamọ́ sí, wọ́n sì yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò náà. Ó wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

Joṣua Tún Gba Àwọn Ìlú Amori Mìíràn Sí i

28 Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda.

29 Joṣua gbéra ní Makeda, ó kọjá lọ sí Libina pẹlu gbogbo Israẹli láti gbógun ti Libina.

30 OLUWA sì fi ìlú Libina ati ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n fi idà pa wọ́n, wọn kò ṣẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu wọn. Bí ó ti ṣe ọba Jẹriko, náà ló ṣe sí ọba ìlú náà.

31 Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra láti Libina lọ sí Lakiṣi. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì bá a jagun.

32 OLUWA fi ìlú Lakiṣi lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ keji. Wọ́n fi idà pa gbogbo wọn patapata bí wọ́n ti ṣe pa àwọn ará Libina.

33 Horamu ọba Geseri wá láti ran àwọn ará ìlú Lakiṣi lọ́wọ́, Joṣua gbógun tì í, ó sì pa òun ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ láìku ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.

34 Joṣua kúrò ní Lakiṣi, ó lọ sí Egiloni pẹlu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dó ti Egiloni, wọ́n sì bá a jagun.

35 Wọ́n gba ìlú náà ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ patapata gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí àwọn ará Lakiṣi.

36 Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Egiloni lọ sí Heburoni, wọ́n sì gbógun tì í.

37 Wọ́n gba ìlú Heburoni, wọ́n sì fi idà pa ọba ìlú náà ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ láìku ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí ìlú Egiloni tí wọn parun láìku ẹnìkan.

38 Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí Debiri, wọ́n sì gbógun tì í.

39 Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n mú ọba ibẹ̀. Wọ́n gba àwọn ìlú kéékèèké agbègbè rẹ̀ pẹlu. Wọ́n fi idà pa ọba wọn ati gbogbo àwọn ará ìlú náà. Gbogbo wọn ni wọ́n pa láìku ẹnìkan. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Heburoni, ati Libina ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe sí Debiri ati ọba rẹ̀.

40 Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un.

41 Joṣua ṣẹgun gbogbo wọn láti Kadeṣi Banea títí dé Gasa ati gbogbo agbègbè Goṣeni títí dé Gibeoni.

42 Joṣua mú gbogbo àwọn ọba wọnyi, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nítorí pé OLUWA Ọlọrun jà fún Israẹli.

43 Lẹ́yìn náà, Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pada sí àgọ́ wọn, ní Giligali.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 11

Joṣua Ṣẹgun Jabini ati Àwọn tí Wọ́n Darapọ̀ Mọ́ ọn

1 Nígbà tí Jabini ọba Hasori, gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ranṣẹ sí Jobabu, ọba Madoni, ati sí ọba Ṣimironi, ati sí ọba Akiṣafu,

2 ati sí àwọn ọba tí wọ́n wà ní àwọn ìlú olókè ti apá ìhà àríwá, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Araba ní ìhà gúsù Kineroti, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Nafoti-dori ní apá ìwọ̀ oòrùn.

3 Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.

4 Gbogbo wọn jáde pẹlu gbogbo ọmọ ogun wọn, wọ́n pọ̀ yanturu bí eṣú. Wọ́n dàbí iyanrìn etí òkun. Ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò lóǹkà.

5 Gbogbo àwọn ọba wọnyi parapọ̀, wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n sì pàgọ́ sí etí odò Meromu.

6 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí pé ní ìwòyí ọ̀la, òkú wọn ni n óo fi lé Israẹli lọ́wọ́. Dídá ni kí ẹ dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”

7 Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá jálù wọ́n lójijì ní etí odò Meromu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn jagun.

8 OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

9 Joṣua ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí ó ṣe sí wọn: ó dá àwọn ẹṣin wọn lẹ́sẹ̀, ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn níná.

10 Joṣua bá yipada, ó gba ìlú Hasori, ó sì fi idà pa ọba wọn, nítorí pé Hasori ni olú-ìlú ìjọba ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí.

11 Wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà láìku ẹyọ ẹnìkan, wọ́n sì sun ìlú Hasori níná.

12 Joṣua gba gbogbo ìlú àwọn ọba náà, ó kó àwọn ọba wọn, ó fi idà pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún un.

13 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò sun èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí wọ́n kọ́ sórí òkítì níná, àfi Hasori nìkan ni Joṣua dáná sun.

14 Àwọn ọmọ Israẹli kó gbogbo dúkìá ìlú náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní ìkógun, ṣugbọn wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ run patapata, wọn kò dá ẹyọ ẹnìkan sí.

15 Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, iranṣẹ rẹ̀, ni Mose náà ṣe pàṣẹ fún Joṣua, tí Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ohunkohun sílẹ̀ láìṣe, ninu gbogbo nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.

Àwọn Ilẹ̀ Tí Joṣua Gbà

16 Gbogbo ilẹ̀ náà ni Joṣua gbà: ó gba àwọn agbègbè olókè, àwọn tí wọ́n wà ní Nẹgẹbu, gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Goṣeni, àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àwọn tí ó wà ní Araba, ati gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí àwọn òkè Israẹli ati ẹsẹ̀ òkè rẹ̀.

17 Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.

18 Joṣua bá àwọn ọba wọnyi jagun fún ìgbà pípẹ́.

19 Kò sí ìlú tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia àfi àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé ìlú Gibeoni. Gbogbo àwọn yòókù patapata ni wọ́n kó lójú ogun.

20 Nítorí pé, OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n sì gbógun ti Israẹli, kí àwọn ọmọ Israẹli lè pa wọ́n run, kí wọ́n má baà ṣàánú wọn, ṣugbọn kí wọ́n pa wọ́n run gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

21 Ní àkókò yìí ni Joṣua pa ìran àwọn Anakimu run patapata ní gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí òkè, àwọn ìlú bíi: Heburoni, Debiri, Anabu, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Juda, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Israẹli, gbogbo wọn patapata ni Joṣua parun, ati gbogbo ìlú wọn.

22 Àwọn ìran Anakimu yìí kò kù sí ibikíbi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, àfi ní ìlú Gasa, ìlú Gati, ati ìlú Aṣidodu ni àwọn díẹ̀ kù sí.

23 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose, ó sì pín in fún àwọn ọmọ Israẹli; ní ẹlẹ́yà-mẹ̀yà.

Lẹ́yìn náà, wọ́n sinmi ogun jíjà.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 12

Àwọn Ọba Tí Mose Ṣẹgun

1 Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani, láti àfonífojì Arinoni títí dé òkè Herimoni, pẹlu gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn.

2 Wọ́n ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé ìlú Heṣiboni. Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri, tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati láti agbede meji àfonífojì náà, títí dé odò Jaboku, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amoni, ó jẹ́ ìdajì ilẹ̀ Gileadi;

3 ati Araba, títí dé òkun Ṣinerotu ní apá ìlà oòrùn, ní ọ̀nà ìlú Beti Jeṣimotu, títí dé òkun Araba, (tí wọ́n tún ń pè ní Òkun Iyọ̀), títí lọ sí apá ìhà gúsù, títí dé ẹsẹ̀ òkè Pisiga.

4 Wọ́n ṣẹgun Ogu, ọba Baṣani náà. Ogu yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn tí ó kù ninu ìran Refaimu tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei.

5 Lára ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ ni òkè Herimoni wà, ati ìlú Saleka, ati gbogbo Baṣani, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Geṣuri, ati ti àwọn ará Maakati ati ìdajì Gileadi títí dé ààlà ọba Sihoni ti ìlú Heṣiboni.

6 Mose, iranṣẹ OLUWA ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba mejeeji yìí, ó sì pín ilẹ̀ wọn fún ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ilẹ̀ náà sì di tiwọn.

Àwọn Ọba Tí Joṣua Ṣẹgun

7 Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, láti Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni títí dé òkè Halaki, ní apá Seiri. Joṣua pín ilẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

8 Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè wà, ati àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní Araba, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aṣálẹ̀, ati ní Nẹgẹbu. Àwọn tí wọ́n ni ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí ni àwọn ará Hiti ati àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi.

9 Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun gbogbo ọba àwọn ìlú wọnyi: Jẹriko ati Ai, lẹ́bàá Bẹtẹli;

10 Jerusalẹmu ati Heburoni,

11 Jarimutu ati Lakiṣi;

12 Egiloni ati Geseri,

13 Debiri ati Gederi;

14 Horima ati Aradi,

15 Libina ati Adulamu;

16 Makeda ati Bẹtẹli,

17 Tapua ati Heferi;

18 Afeki ati Laṣaroni,

19 Madoni ati Hasori;

20 Ṣimironi Meroni ati Akiṣafu,

21 Taanaki ati Megido;

22 Kedeṣi ati Jokineamu, ní Kamẹli;

23 Dori, tí ó wà ní etí òkun; Goiimu, tí ó wà ní Galili,

24 ati Tirisa. Gbogbo wọn jẹ́ ọba mọkanlelọgbọn.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 13

Ilẹ̀ Tí Ó kù láti Gbà

1 Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà.

2 Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri;

3 láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù.

4 Lẹ́yìn náà, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Meara, tíí ṣe ilẹ̀ àwọn ará Sidoni, títí dé Afeki ní ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amori,

5 ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.

6 Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, láti Lẹbanoni, títí dé Misirefoti Maimu, ati gbogbo àwọn ará Sidoni ni n óo lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn, ẹ pín ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, bí mo ti pàṣẹ fun yín.

7 Ẹ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an yòókù ati ìdajì ẹ̀yà Manase.”

Pípín Agbègbè Tí Ó Wà ní Ìlà Oòrùn Odò Jọdani

8 Ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase gba ilẹ̀ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani;

9 láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba títí dé Diboni;

10 ati gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, títí kan ààlà àwọn ará Amoni;

11 ati Gileadi ati agbègbè Geṣuri ti Maakati, ati gbogbo òkè Herimoni ati gbogbo Baṣani títí dé Saleka;

12 gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ti Baṣani, tí ó jọba ní Aṣitarotu ati Edirei. Ogu yìí nìkan ṣoṣo ni ó ṣẹ́kù ninu ìran Refaimu yòókù. Mose ti ṣẹgun gbogbo wọn, ó sì ti lé wọn jáde.

13 Sibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri ati àwọn ará Maakati jáde; wọ́n ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní olónìí.

14 Ẹ̀yà Lefi nìkan ni Mose kò pín ilẹ̀ fún, ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí OLUWA ni ìpín tiwọn. Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Reubẹni

15 Mose fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni ní ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

16 Ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba.

17 Pẹlu Heṣiboni ati àwọn ìlú agbègbè rẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú. Àwọn ìlú bíi Diboni, Bamoti Baali, ati Beti Baalimeoni;

18 Jahasi, Kedemotu, ati Mefaati;

19 Kiriataimu, Sibima, ati Sereti Ṣahari, tí ó wà ní orí òkè àfonífojì náà;

20 Betipeori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga, ati Beti Jeṣimotu;

21 àní, àwọn ìlú tí ó wà ní orí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ati gbogbo ìjọba Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ó jọba ní Heṣiboni, tí Mose ṣẹgun, pẹlu gbogbo àwọn olórí ilẹ̀ Midiani. Àwọn bíi: Efi, Rekemu, Ṣuri, Huru, ati Reba, ọmọ ọba Sihoni, tí ń gbé ilẹ̀ náà.

22 Ọ̀kan ninu àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lójú ogun ni Balaamu, aláfọ̀ṣẹ, ọmọ Beori.

23 Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni. Àwọn ìlú ńláńlá ati àwọn ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ẹ̀yà Reubẹni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Gadi

24 Mose fún ẹ̀yà Gadi ní ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

25 Ilẹ̀ tiwọn ni Jaseri ati gbogbo ìlú Gileadi, ati ìdajì ilẹ̀ àwọn ará Amoni, títí dé Aroeri tí ó wà ní ìlà oòrùn Raba;

26 láti Heṣiboni, títí dé Ramati Misipe ati Betonimu; ati láti Mahanaimu títí dé agbègbè Debiri;

27 àfonífojì Beti Nimra, Sukotu, ati Safoni, ìyókù ilẹ̀ ìjọba Sihoni, ọba Heṣiboni. Odò Jọdani ni ààlà ilẹ̀ wọn, ní apá ìsàlẹ̀ òkun Kinereti, lọ sí apá ìlà oòrùn, níkọjá odò Jọdani.

28 Àwọn ìlú ńláńlá ati ìlú kéékèèké tí ó wà ninu ilẹ̀ yìí jẹ́ ìpín ẹ̀yà Gadi gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Manase ní ìlà Oòrùn

29 Mose fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ìpín tiwọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

30 Ilẹ̀ tiwọn bẹ̀rẹ̀ láti Mahanaimu, títí dé gbogbo ilẹ̀ Baṣani, gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo àwọn ìlú Jairi tí ó wà ní Baṣani, gbogbo ìlú wọn jẹ́ ọgọta.

31 Ninu ilẹ̀ wọn ni ìdajì Gileadi wà ati Aṣitarotu ati Edirei, àwọn ìlú ńláńlá ilẹ̀ ìjọba Ogu, ọba Baṣani; Mose pín wọn fún àwọn ìdajì ìdílé Makiri, ọmọ Manase, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

32 Àkọsílẹ̀ bí Mose ṣe pín ilẹ̀ tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani ní apá ìlà oòrùn Jẹriko nìyí.

33 Ṣugbọn Mose kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 14

Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Wà Ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn Odò Jọdani

1 Àkọsílẹ̀ bí wọn ṣe pín ilẹ̀ Kenaani, tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí. Eleasari alufaa, Joṣua, ọmọ Nuni, ati àwọn olórí láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe ètò pípín ilẹ̀ náà.

2 Gègé ni wọ́n ṣẹ́, tí wọ́n fi pín in fún ẹ̀yà mẹsan-an ati ààbọ̀ ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

3 Nítorí pé Mose ti fún àwọn ẹ̀yà meji ati ààbọ̀ ní ìpín tiwọn ní òdìkejì odò Jọdani, ṣugbọn kò pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Lefi.

4 Meji ni wọ́n pín àwọn ẹ̀yà Josẹfu sí, àwọn ìpín mejeeji náà ni ẹ̀yà Manase ati ti Efuraimu. Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ìpín kankan ninu ilẹ̀ náà, ṣugbọn wọ́n fún wọn ní àwọn ìlú láti máa gbé, ati pápá, ibi tí wọ́n ti lè máa da mààlúù wọn, ati gbogbo ẹran ọ̀sìn tí wọ́n ní.

5 Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose gan-an ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe pín ilẹ̀ náà.

Wọ́n fún Kalebu ní Heburoni

6 Ní ọjọ́ kan àwọn ẹ̀yà Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Giligali. Ọkunrin kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi bá sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ ohun tí OLUWA sọ fún Mose eniyan Ọlọrun ní Kadeṣi Banea nípa àwa mejeeji?

7 Ẹni ogoji ọdún ni mí nígbà tí Mose iranṣẹ OLUWA rán mi láti Kadeṣi Banea láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Bí ọkàn mi ti rí gan-an nígbà náà ni mo ṣe ròyìn fún un.

8 Ṣugbọn àwọn arakunrin mi tí a jọ lọ dáyàjá àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.

9 Mose bá búra ní ọjọ́ náà pé, ‘Dájúdájú, gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ ni yóo jẹ́ ìpín fún ọ ati fún àwọn ọmọ rẹ títí lae, nítorí pé o ti fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.’

10 OLUWA ti dá ẹ̀mí mi sí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti nǹkan bí ọdún marunlelogoji tí OLUWA ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń rìn ninu aṣálẹ̀. Nisinsinyii, mo ti di ẹni ọdún marundinlaadọrun,

11 bí agbára mi ṣe rí nígbà tí Mose rán wa jáde láti lọ ṣe amí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di òní olónìí, mo tún lágbára láti jagun ati láti wọlé ati láti jáde.

12 Nítorí náà, fún mi ní òkè yìí, tí OLUWA sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ìwọ náà gbọ́ ní ọjọ́ náà pé, àwọn ọmọ Anakimu wà níbẹ̀. Ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, ó ṣeéṣe kí OLUWA wà pẹlu mi kí n sì lè lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.”

13 Joṣua bá súre fún Kalebu ọmọ Jefune, ó sì fún un ní òkè Heburoni, bí ìpín tirẹ̀.

14 Bẹ́ẹ̀ ni Heburoni di ilẹ̀ ìní Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi títí di òní olónìí, nítorí pé ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun Israẹli.

15 Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba; Ariba yìí ni ẹni tí ó jẹ́ alágbára jùlọ ninu àwọn òmìrán tí à ń pè ní Anakimu.

Àwọn eniyan náà sì sinmi ogun jíjà ní ilẹ̀ náà.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 15

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Juda

1 Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí:

Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.

2 Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀,

3 láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka.

4 Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù.

5 Òkun Iyọ̀ ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn, ó lọ títí dé ibi tí odò Jọdani ti ń ṣàn wọ inú òkun.

Níbẹ̀ ni ààlà rẹ̀ ní apá àríwá ti bẹ̀rẹ̀,

6 ó lọ títí dé Beti Hogila, ó lọ dé ìhà àríwá Betaraba, ó tún lọ títí dé ibi òkúta Bohani ọmọ Reubẹni.

7 Ó lọ láti àfonífojì Akori títí dé Debiri, ó wá yípo lọ sí apá ìhà àríwá, lọ sí Giligali, tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, tí ó wà ní apá gúsù àfonífojì náà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ibi odò Enṣemeṣi, ó sì pin sí Enrogeli.

8 Ààlà náà tún lọ sí apá òkè, sí àfonífojì ọmọ Hinomu ní apá gúsù òkè àwọn ará Jebusi (tíí ṣe ìlú Jerusalẹmu). Ó tún lọ títí dé orí òkè náà, tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní òpin ìhà àríwá àfonífojì Refaimu.

9 Láti ibẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ láti orí òkè títí dé odò Nefitoa, ó lọ sí apá ibi tí àwọn ìlú ńláńlá wà lẹ́bàá òkè Efuroni, ó wá pada sí apá Baala (tí a tún ń pè ní Kiriati Jearimu.)

10 Ààlà náà tún yípo lọ sí ìwọ̀ oòrùn Baala, sí apá òkè Seiri, lọ sí apá ìhà àríwá òkè Jearimu (tí a tún ń pè ní Kesaloni), ó bá tún dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sí Beti Ṣemeṣi títí dé ìkọjá Timna.

11 Ó tún gba ti àwọn òkè tí ó wà ní ìhà àríwá Ekironi, ó wá yípo lọ sí Ṣikeroni. Lẹ́yìn náà, ó kọjá lọ sí òkè Baala títí dé Jabineeli, ó wá lọ parí sí Òkun Mẹditarenia.

12 Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.

Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Kalebu Ṣẹgun Heburoni ati Debiri

13 Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua, ó fún Kalebu ọmọ Jefune ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀ ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda. Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba, (tí a tún ń pè ní ìlú Ariba), Ariba yìí ni baba Anaki.

14 Kalebu lé àwọn ìran Anaki mẹtẹẹta jáde níbẹ̀, àwọn ni ìran Ṣeṣai, ìran Ahimani, ati ìran Talimai.

15 Láti ibẹ̀ ó lọ gbógun ti àwọn ará ìlú Debiri. Orúkọ Debiri tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Seferi.

16 Kalebu ṣe ìlérí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹgun Kiriati Seferi tí ó sì gba ìlú náà ni òun yóo fún ní Akisa ọmọ òun, láti fi ṣe aya.

17 Otinieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, ni ó ṣẹgun ìlú náà. Kalebu bá fi Akisa ọmọ rẹ̀ fún un láti fi ṣe aya.

18 Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ó rọ ọkọ rẹ̀ pé kí ó tọrọ ilẹ̀ kan lọ́wọ́ baba òun. Ní ọjọ́ kan, bí Akisa ti sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, baba rẹ̀ bi í pé, “Kí ni ò ń fẹ́?”

19 Akisa dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Fún mi ní ẹ̀bùn, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ Nẹgẹbu, fún mi ní àwọn orísun omi pẹlu.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí wọ́n wà lókè ati àwọn tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀.

Àwọn Ìlú Ńláńlá Tí Wọ́n Wà ní Juda

20 Èyí ni ilẹ̀ ẹ̀yà Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

21 àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní ìpẹ̀kun apá ìhà gúsù lẹ́bàá ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabiseeli, Ederi, Jaguri,

22 Kina, Dimona, Adada,

23 Kedeṣi, Hasori, Itinani;

24 Sifi, Telemu, Bealoti;

25 Hasori Hadata, Kerioti Hesironi (tí a tún ń pè ní Hasori);

26 Amamu, Ṣema, Molada;

27 Hasari Gada, Heṣimoni, Betipeleti;

28 Hasari Ṣuali, Beeriṣeba, Bisiotaya;

29 Baala, Iimu, Esemu;

30 Elitoladi, Kesili, Horima;

31 Sikilagi, Madimana, Sansana;

32 Lebaotu, Ṣilihimu, Aini ati Rimoni; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mọkandinlọgbọn.

33 Àwọn ìlú wọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè nìwọ̀nyí: Eṣitaolu, Sora, Aṣinai.

34 Sanoa, Enganimu, Tapua, Enamu;

35 Jarimutu, Adulamu, Soko, Aseka;

36 Ṣaaraimu, Aditaimu, Gedera, Gederotaimu; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla.

37 Senani, Hadaṣa, Migidaligadi,

38 Dileani, Misipa, Jokiteeli,

39 Lakiṣi, Bosikati, Egiloni, Kaboni;

40 Lahimami, Kitiliṣi; Gederotu;

41 Beti Dagoni, Naama, ati Makeda; gbogbo ìlú ati ìletò wọ́n jẹ́ mẹrindinlogun.

42 Libina, Eteri, Aṣani, Ifita;

43 Aṣinai, Nesibu, Keila;

44 Akisibu, ati Mareṣa; gbogbo ìlú ati ìletò wọ́n jẹ́ mẹsan-an.

45 Ekironi pẹlu àwọn ìlú ati ìletò rẹ̀;

46 láti Ekironi títí dé etí òkun Mẹditarenia, ati gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n wà lẹ́bàá Aṣidodu pẹlu àwọn ìletò wọn.

47 Aṣidodu, pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò rẹ̀; Gasa, pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò rẹ̀ títí dé odò Ijipti, ati etí òkun Mẹditarenia, pẹlu agbègbè rẹ̀.

48 Àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè nìwọ̀nyí: Ṣamiri,

49 Jatiri, Soko, Dana, Kiriati Seferi (tí à ń pè ní Debiri),

50 Anabu, Eṣitemoa, Animi,

51 Goṣeni, Holoni, ati Gilo; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mọkanla.

52 Arabu, Duma, Eṣani, Janimu,

53 Beti Tapua, Afeka, Humita,

54 Kiriati Ariba (tí à ń pè ní Heburoni), ati Siori, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹsan-an.

55 Maoni, Kamẹli, Sifi, Juta.

56 Jesireeli, Jokideamu, Sanoa,

57 Kaini, Gibea, ati Timna, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹ́wàá.

58 Halihuli, Betisuri, Gedori,

59 Maarati, Betanotu, ati Elitekoni, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹfa.

60 Kiriati Baali (tí wọn ń pè ní Kiriati Jearimu), ati Raba, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ meji.

61 Àwọn ìlú tí wọ́n wà ní aṣálẹ̀ ni, Betaraba, Midini, Sekaka;

62 Nibiṣani, Ìlú Iyọ̀, ati Engedi; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹfa.

63 Ṣugbọn àwọn eniyan Juda kò lè lé àwọn Jebusi tí wọn ń gbé inú ilẹ̀ Jerusalẹmu jáde. Àwọn Jebusi yìí sì tún wà láàrin àwọn eniyan Juda ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 16

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 Ààlà ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Josẹfu bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani lẹ́bàá Jẹriko, ní apá ìlà oòrùn àwọn odò Jẹriko, ó lọ títí dé apá aṣálẹ̀. Ó tún bẹ̀rẹ̀ láti Jẹriko lọ sí apá àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, títí dé Bẹtẹli.

2 Láti Bẹtẹli, ó lọ sí Lusi, ó sì kọjá lọ sí Atarotu, níbi tí àwọn ọmọ Ariki ń gbé.

3 Bákan náà ni ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn títí dé agbègbè àwọn ará Jafileti, títí dé apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni. Ó tún lọ láti ibẹ̀ títí dé Geseri, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.

4 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Josẹfu, tí à ń pè ní ẹ̀yà Manase ati ẹ̀yà Efuraimu ṣe gba ìpín tiwọn.

Efuraimu

5 Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni.

6 Láti ibẹ̀ ó lọ títí dé Òkun Mẹditarenia. Mikimetati ni ààlà wọn ní ìhà àríwá. Ní apá ìlà oòrùn ibẹ̀, ààlà ilẹ̀ wọn yípo lọ sí apá Taanati Ṣilo, ó sì kọjá ibẹ̀ lọ ní ìhà ìlà oòrùn lọ sí Janoa.

7 Lẹ́yìn náà, ní ìsàlẹ̀, láti Janoa, lọ sí Atarotu ati Naara. Ó lọ títí dé Jẹriko, ó sì pin sí odò Jọdani.

8 Láti Tapua, ààlà náà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn títí dé odò Kana, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Èyí ni ilẹ̀ tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Efuraimu gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

9 pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọn tí ó wà ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Manase, ṣugbọn tí a fi fún ẹ̀yà Efuraimu.

10 Ṣugbọn wọn kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Geseri jáde, nítorí náà, àwọn ará Kenaani ń gbé ààrin ẹ̀yà Efuraimu títí di òní olónìí. Ẹ̀yà Efuraimu ń fi tipátipá mú wọn ṣiṣẹ́ bí ẹrú.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 17

Ilẹ̀ Ẹ̀yà Manase ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn

1 Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan.

2 Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn.

3 Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkunrin rárá, àfi kìkì ọmọbinrin. Orúkọ wọn ni Mahila, Noa, Hogila, Milika, ati Tirisa.

4 Wọ́n tọ Eleasari, alufaa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn àgbààgbà lọ, wọ́n wí fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí ó pín ilẹ̀ fún àwa náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pín fún àwọn ìbátan wa, tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.” Nítorí náà bí OLUWA ti pa á láṣẹ, wọ́n pín ilẹ̀ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pín fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.

5 Ìdí nìyí tí ìpín mẹ́wàá fi kan Manase láìka Gileadi, ati Baṣani ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.

6 Nítorí pé àwọn ọmọbinrin Manase gba ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin. Wọ́n pín ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Manase yòókù.

7 Ilẹ̀ ti Manase bẹ̀rẹ̀ láti Aṣeri títí dé Mikimetati tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Ṣekemu, ààlà rẹ̀ tún lọ sí apá ìhà gúsù ní apá ọ̀dọ̀ àwọn tí wọn ń gbé Entapua.

8 Àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ilẹ̀ Tapua, ṣugbọn ìlú Tapua gan-an, tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu.

9 Ààlà ilẹ̀ wọn tún lọ sí apá ìsàlẹ̀ títí dé odò Kana, àwọn ìlú wọnyi tí wọ́n wà ní apá gúsù odò náà, láàrin ìlú àwọn ọmọ Manase, jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu. Ààlà àwọn ọmọ Manase tún lọ sí apá àríwá odò náà, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia.

10 Ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìhà gúsù jẹ́ ti àwọn ọmọ Efuraimu, èyí tí ó wà ní apá ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn ọmọ Manase. Òkun Mẹditarenia ni ààlà wọn ní apá ìwọ̀ oòrùn. Ní apá ìhà àríwá, ilẹ̀ wọn lọ títí kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, ó sì kan ti ẹ̀yà Isakari ní apá ìlà oòrùn.

11 Ní ilẹ̀ Isakari, ati ti Aṣeri, àwọn ọmọ Manase ni wọ́n ni ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, Ibileamu ati àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè rẹ̀, ati Dori, Endori, Taanaki ati Megido ati gbogbo àwọn ìletò tí wọ́n wà ní agbègbè wọn. Àwọn náà ni wọ́n ni Nafati.

12 Ṣugbọn àwọn ọmọ Manase kò lè gba àwọn ìlú náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ilẹ̀ náà.

13 Ṣugbọn nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá mú àwọn ará Kenaani sìn, wọn kò sì lé wọn jáde patapata.

Ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase ti Ìwọ̀ Oòrùn Bèèrè fún Ilẹ̀ Sí i

14 Àwọn ẹ̀yà Josẹfu lọ bá Joṣua, wọ́n wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi fún wa ní ẹyọ ilẹ̀ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwa, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn eniyan wa pọ̀ gan-an, nítorí pé OLUWA ti bukun wa?”

15 Joṣua dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá pọ̀, ẹ lọ sí inú igbó, kí ẹ sì gba ilẹ̀ níbẹ̀ ninu ilẹ̀ àwọn ará Perisi ati ti àwọn Refaimu, bí ilẹ̀ olókè ti Efuraimu kò bá tóbi tó fun yín.”

16 Àwọn ẹ̀yà Josẹfu bá dáhùn pé, “Ilẹ̀ olókè yìí kò tó fún wa, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Kenaani tí ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn tí wọn ń gbé Beti Ṣani, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè rẹ̀, ati àwọn tí ń gbé àfonífojì Jesireeli.”

17 Joṣua bá dá àwọn ọmọ Josẹfu: ẹ̀yà Efuraimu ati ti Manase lóhùn, ó ní, “Ẹ pọ̀ nítòótọ́, ẹ sì ní agbára, ilẹ̀ kan ṣoṣo kọ́ ni yóo kàn yín,

18 ẹ̀yin ni ẹ óo ni agbègbè olókè wọnyi pẹlu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó ni, ẹ gbà á, kí ẹ sì ṣán an láti òkè dé ilẹ̀ títí dé òpin ààlà rẹ̀. Ẹ óo lé àwọn ará Kenaani jáde, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn, tí wọ́n sì jẹ́ alágbára.”

Categories
JOṢUA

JOṢUA 18

Pípín Ilẹ̀ Yòókù

1 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀.

2 Ó ku ẹ̀yà meje, ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọn kò tíì pín ilẹ̀ fún.

3 Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín.

4 Ẹ yan eniyan mẹta mẹta wá láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì rán wọn jáde lọ láti rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí wọ́n lè ṣe àkọsílẹ̀ ibi tí wọ́n bá fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn, lẹ́yìn náà, kí wọ́n pada wá jíyìn fún mi.

5 Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.

6 Ẹ óo ṣe àkọsílẹ̀ ìpín mejeeje, ẹ óo sì mú un tọ̀ mí wá. N óo ba yín ṣẹ́ gègé lórí wọn níhìn-ín, níwájú OLUWA Ọlọrun wa.

7 Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.”

8 Àwọn ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, Joṣua sì kìlọ̀ fún wọn, pé, “Ẹ rin ilẹ̀ náà jákèjádò, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sílẹ̀ wá fún mi. N óo sì ba yín ṣẹ́ gègé níhìn-ín níwájú OLUWA ní Ṣilo.” Àwọn ọkunrin náà bá lọ,

9 wọ́n rin ilẹ̀ náà jákèjádò, wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ àpèjúwe àwọn ìlú tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ní ìsọ̀rí meje sinu ìwé kan, wọ́n pada wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ninu àgọ́ ní Ṣilo.

10 Joṣua bá bá wọn ṣẹ́ gègé ní Ṣilo, níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe pín ilẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ìpín tirẹ̀.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Bẹnjamini

11 Ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn wà ní ààrin ilẹ̀ ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Josẹfu.

12 Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni.

13 Láti ibẹ̀ ààlà ilẹ̀ náà gba apá ìhà gúsù, ní ọ̀nà Lusi, kọjá lọ sí ara òkè, (Lusi ni wọ́n ń pè ní Bẹtẹli tẹ́lẹ̀) ààlà náà tún yípo lọ sí apá ìsàlẹ̀, sí ọ̀nà Atarotu Adari, sí orí òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù, ni ìsàlẹ̀ Beti Horoni.

14 Ó tún yípo lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, sí apá ìhà gúsù lọ sí ara àwọn òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù tí ó dojú kọ Beti Horoni, ó sì pin sí Kiriati Baali (tí wọ́n tún ń pè ní Kiriati Jearimu), ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Juda. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ náà.

15 Ààlà ti apá ìhà gúsù ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní àtiwọ ìlú Kiriati Jearimu lọ títí dé Efuroni, títí dé odò Nefitoa,

16 kí ó tó yípo lọ sí ìsàlẹ̀, sí ẹsẹ̀ òkè tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, níbi tí àfonífojì Refaimu pin sí ní ìhà àríwá. Ààlà náà la àfonífojì Hinomu kọjá lọ sí apá ìhà gúsù ní etí Jebusi, ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Enrogeli.

17 Lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí apá àríwá, kí ó tó wa lọ sí Enṣemeṣi títí lọ dé Gelilotu tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, lẹ́yìn náà ó wá sí ìsàlẹ̀ ní ibi tí òkúta Bohani ọmọ Reubẹni wà.

18 Ààlà náà kọjá lọ sí apá ìhà àríwá òkè Betaraba; láti ibẹ̀ ó lọ sí Araba.

19 Ó tún lọ sí apá ìhà àríwá òkè Beti Hogila, kí ó tó wá lọ sí apá etí Òkun Iyọ̀, níbi tí ó ti lọ fi orí sọ òpin odò Jọdani, ní ìhà gúsù. Ó jẹ́ ààlà ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini ní apá ìhà gúsù.

20 Odò Jọdani ni ààlà rẹ̀ ní apá ìlà oòrùn. Èyí ni ilẹ̀ tí a pín fún ẹ̀yà Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé, pẹlu àwọn ààlà ilẹ̀ ìdílé kọ̀ọ̀kan.

21 Àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni: Jẹriko, Beti Hogila, Emeki Kesisi;

22 Betaraba, Semaraimu, Bẹtẹli;

23 Afimu, Para, Ofira;

24 Kefariamoni, Ofini, ati Geba; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila.

25 Gibeoni, Rama, Beeroti

26 Misipa, Kefira, Mosa;

27 Rekemu, Iripeeli, Tarala;

28 Sela, Haelefi, Jebusi (tí à ń pè ní Jerusalẹmu) Gibea, ati Kiriati Jearimu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 19

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Simeoni

1 Ilẹ̀ keji tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Simeoni, ilẹ̀ tiwọn bọ́ sí ààrin ìpín ti ẹ̀yà Juda.

2 Àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn nìyí: Beeriṣeba, Ṣeba, Molada;

3 Hasari Ṣuali, Bala, Esemu;

4 Elitoladi, Betuli, Horima,

5 Sikilagi, Beti Makabotu, ati Hasari Susa;

6 Beti Lebaotu ati Ṣaruheni, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹtala.

7 Enrimoni, Eteri, ati Aṣani, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrin,

8 pẹlu gbogbo àwọn ìletò tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá wọnyi ká títí dé Baalati Beeri, (tí wọ́n ń pè ní Rama) tí ó wà ní Nẹgẹbu ní ìhà gúsù. Òun ni ìpín ti ẹ̀yà Simeoni, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

9 Apá kan ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Simeoni. Ìpín ti ẹ̀yà Juda tóbi jù fún wọn, nítorí náà ni ẹ̀yà Simeoni ṣe mú ninu tiwọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Sebuluni

10 Ilẹ̀ kẹta tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Sebuluni. Agbègbè tí ó jẹ́ ìpín tiwọn lọ títí dé Saridi.

11 Níbẹ̀ ni ààlà ilẹ̀ wọn ti yípo lọ sókè sí apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì wá sí apá ìlà oòrùn Jokineamu.

12 Láti Saridi, ààlà ilẹ̀ náà lọ sí òdìkejì, ní ìhà ìlà oòrùn, títí dé ààlà Kisiloti Tabori, láti ibẹ̀, ó lọ sí Daberati títí lọ sí Jafia;

13 láti Jafia, ó lọ sí apá ìlà oòrùn títí dé Gati Heferi ati Etikasini, nígbà tí ó dé Rimoni, ó yípo lọ sí apá Nea.

14 Ní apá ìhà àríwá, ààlà náà yípo lọ sí Hanatoni, ó sì pin sí àfonífojì Ifitaeli.

15 Ara àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀ ni, Kata, Nahalali, Ṣimironi, Idala, ati Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila.

16 Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Sebuluni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Isakari

17 Ilẹ̀ kẹrin tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Isakari.

18 Lórí ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Jesireeli, Kesuloti, Ṣunemu;

19 Hafaraimu, Sihoni, Anaharati;

20 Rabiti, Kiṣioni, Ebesi;

21 Remeti, Enganimu, Enhada, ati Betipasesi.

22 Ààlà ilẹ̀ náà lọ kan Tabori, Ṣahasuma ati Beti Ṣemeṣi, kí ó tó lọ pin sí odò Jọdani. Gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrindinlogun.

23 Àwọn ni ìlú ati ìletò náà tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Isakari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Aṣeri

24 Ilẹ̀ karun-un tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Aṣeri.

25 Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Helikati, Hali, Beteni, Akiṣafu.

26 Alameleki, Amadi, ati Miṣali, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ náà dé Kamẹli ati Ṣihori Libinati.

27 Ààlà rẹ̀ wá yípo lọ sí apá ìlà oòrùn, títí dé Beti Dagoni, títí dé Sebuluni ati àfonífojì Ifitaeli ní apá àríwá Betemeki ati Neieli. Lẹ́yìn náà ó tún lọ ní apá ìhà àríwá náà títí dé Kabulu,

28 Eburoni, Rehobu, Hamoni, ati Kana, títí dé Sidoni Ńlá;

29 Lẹ́yìn náà, ààlà náà yípo lọ sí Rama; ó dé ìlú olódi ti Tire, lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí Hosa, ó sì pin sí etíkun. Ninu ilẹ̀ wọn ni Mahalabu, Akisibu;

30 Uma, Afeki, ati Rehobu wà, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejilelogun.

31 Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Aṣeri gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Nafutali

32 Ilẹ̀ kẹfa tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Nafutali,

33 Ààlà ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní Helefi, láti ibi igi oaku tí ó wà ní Saananimu, Adaminekebu, ati Jabineeli, títí dé Lakumu, ó sì pin sí odò Jọdani.

34 Níbẹ̀ ni ààlà náà ti yipada lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn sí Asinotu Tabori. Láti ibẹ̀, ó lọ títí dé Hukoku, ó lọ kan ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni ní apá ìhà gúsù, ó sì kan ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri lápá ìwọ̀ oòrùn, ati ti Juda ní apá ìlà oòrùn létí odò Jọdani.

35 Àwọn ìlú olódi tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni Sidimu, Seri, Hamati, Rakati, Kinereti;

36 Adama, Rama, Hasori;

37 Kedeṣi, Edirei, Enhasoru,

38 Yironi, Migidalieli, Horemu, Betanati ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo ìlú ati àwọn ìletò wọn jẹ́ mọkandinlogun.

39 Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Nafutali gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Dani

40 Ilẹ̀ keje tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Dani.

41 Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Sora, Ẹṣitaolu, Iriṣemeṣi;

42 Ṣaalibimu, Aijaloni, Itila,

43 Eloni, Timna, Ekironi,

44 Eliteke, Gibetoni, Baalati;

45 Jehudi, Beneberaki, Gati Rimoni

46 ati Mejakoni, ati Rakoni pẹlu agbègbè tí ó dojú kọ Jọpa.

47 Nígbà tí ilẹ̀ ẹ̀yà Dani bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n bá lọ gbógun ti ìlú Leṣemu, wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Wọ́n yí orúkọ Leṣemu pada sí Dani, tíí ṣe orúkọ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

48 Àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọnyi ni ìpín tí ó kan ẹ̀yà Dani gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Kù

49 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pín gbogbo agbègbè tí ó wà ninu ilẹ̀ náà ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tán, wọ́n pín ilẹ̀ fún Joṣua ọmọ Nuni pẹlu.

50 Wọ́n fún un ní ilẹ̀ tí ó bèèrè fún gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA. Ìlú tí ó bèèrè fún ni Timnati Sera ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ó tún ìlú náà kọ́, ó sì ń gbé ibẹ̀.

51 Bẹ́ẹ̀ ni Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ati àwọn àgbààgbà ninu ẹ̀yà àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹ́ gègé láti pín ilẹ̀ náà ní Ṣilo níwájú OLUWA, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; wọ́n sì parí pípín ilẹ̀ náà.