Categories
JOṢUA

JOṢUA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìwé Joṣua

ni ó sọ ìtàn bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe jagun gba ilẹ̀ Kenaani, lábẹ́ àkóso Joṣua, ẹni tí ó gba ipò Mose gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pataki tí a sọ nípa rẹ̀ ninu ìwé yìí ni: bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe rékọjá odò Jọdani; bí odi Jẹriko ṣe wó lulẹ̀; ogun tí wọ́n jà ní Ai, ati bí wọ́n ṣe tún majẹmu dá pẹlu Ọlọrun. Ẹsẹ tí ọpọlọpọ eniyan mọ̀ jù ninu ìwé yìí ni orí 24 ẹsẹ 15 tí ó kà báyìí pé, “Ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí… Ní tèmi, ati àwọn ará ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.”

Àwọn Ohun tí ó wà ninú Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ṣiṣẹgun àwọn ará Kenaani 1:1–12:24

Pínpín ilẹ̀ náà 13:1–21:45

a. Ilẹ̀ apá ìlà oòrùn Jọdani 13:1-33

b. Ilẹ̀ apá ìwọ̀ oòrùn Jọdani 14:1–19:51

d. Àwọn ìlú ààbò 20:1-9

e. Àwọn ìlú àwọn ọmọ Lefi 21:1-45

Àwọn ẹ̀yà ìlà oòrùn pada sí agbègbè wọn 22:1-34

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Joṣua 23:1-16

Àtúnṣe majẹmu ní Ṣekemu 24:1-33

Categories
JOṢUA

JOṢUA 1

Ọlọrun Pàṣẹ fún Joṣua pé Kí Ó Fi Ogun Kó Ilẹ̀ Kenaani

1 Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé,

2 “Mose iranṣẹ mi ti kú, nítorí náà, ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ẹ múra kí ẹ la odò Jọdani kọjá, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí n óo fun yín.

3 Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀ ni mo ti fun yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Mose.

4 Láti inú aṣálẹ̀ ati òkè Lẹbanoni yìí lọ, títí dé odò ńlá náà, odò Yufurate, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Hiti, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, ni yóo jẹ́ ilẹ̀ yín.

5 Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae.

6 Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn.

7 Ìwọ ṣá ti múra, kí o ṣe ọkàn gírí, kí o sì rí i dájú pé o pa gbogbo òfin tí Mose, iranṣẹ mi, fún ọ mọ́. Má ṣe yẹsẹ̀ kúrò ninu rẹ̀ sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé níbikíbi tí o bá lọ lè máa yọrí sí rere.

8 Máa ka ìwé òfin yìí nígbà gbogbo, kí o sì máa ṣe àṣàrò ninu rẹ̀, tọ̀sán-tòru; rí i dájú pé o pa gbogbo ohun tí wọ́n kọ sinu rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni yóo dára fún ọ, gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé yóo sì máa yọrí sí rere.

9 Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”

Joṣua Pàṣẹ fún Àwọn Eniyan Náà

10 Lẹ́yìn náà, Joṣua pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí àwọn eniyan náà, ó ní,

11 “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.”

12 Joṣua sọ fún àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ti Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase pé,

13 “Ẹ ranti àṣẹ tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa fun yín pé, ‘OLUWA Ọlọrun yín ń pèsè ibi ìsinmi fun yín, yóo sì fi ilẹ̀ yìí fun yín.’

14 Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín ni yóo kù lẹ́yìn lórí ilẹ̀ tí Mose fun yín ní òdìkejì odò Jọdani; ṣugbọn gbogbo àwọn akọni láàrin yín yóo rékọjá sí òdìkejì odò náà pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn arakunrin yín, wọn yóo máa ràn wọ́n lọ́wọ́

15 títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.”

16 Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa ni a óo ṣe, ibikíbi tí o bá sì rán wa ni a óo lọ.

17 Bí a ti gbọ́ ti Mose, bẹ́ẹ̀ ni a óo máa gbọ́ tìrẹ náà. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣá ti wà pẹlu rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹlu Mose.

18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí ó sì kọ̀ láti ṣe ohunkohun tí o bá sọ fún un, pípa ni a óo pa á. Ìwọ ṣá ti múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”

Categories
JOṢUA

JOṢUA 2

Joṣua Rán Àwọn Amí Lọ sí Jẹriko

1 Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu.

2 Àwọn kan bá lọ sọ fún ọba Jẹriko pé, “Àwọn ọkunrin kan, lára àwọn ọmọ Israẹli, wá sí ibí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.”

3 Ọba Jẹriko bá ranṣẹ sí Rahabu ó ní, “Kó àwọn ọkunrin tí wọn dé sọ́dọ̀ rẹ jáde wá, nítorí pé wọ́n wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni.”

4 Ṣugbọn obinrin náà ti kó àwọn ọkunrin mejeeji pamọ́, ó dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni àwọn ọkunrin meji kan wá sọ́dọ̀ mi, ṣugbọn n kò mọ ibi tí wọn ti wá.

5 Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè ni wọ́n jáde lọ, n kò sì mọ ibi tí wọ́n lọ. Ẹ tètè máa lépa wọn lọ, ẹ óo bá wọn lọ́nà.”

6 Ṣugbọn ó ti kó wọn gun orí òrùlé rẹ̀, ó sì ti fi wọ́n pamọ́ sáàrin pòpórò igi ọ̀gbọ̀ tí ó tò jọ sibẹ.

7 Àwọn tí ọba rán bá bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọkunrin náà lọ ní ọ̀nà odò Jọdani, títí dé ibi tí ọ̀nà ti rékọjá odò náà, bí àwọn tí ọba rán ti jáde ní ìlú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi ìlú náà.

8 Kí àwọn amí meji náà tó sùn, Rahabu gun òrùlé lọ bá wọn, ó ní,

9 “Mo mọ̀ pé OLUWA ti fi ilẹ̀ yìí lé e yín lọ́wọ́, jìnnìjìnnì yín ti bò wá, ẹ̀rù yín sì ti ń ba gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí.

10 Nítorí a ti gbọ́ bí OLUWA ti mú kí Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ jáde ní Ijipti, a sì ti gbọ́ ohun tí ẹ ṣe sí Sihoni ati Ogu, àwọn ọba ará Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani, bí ẹ ṣe pa wọ́n run patapata.

11 Bí a ti gbọ́ ni jìnnìjìnnì ti bò wá, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn sì ti bá gbogbo eniyan nítorí yín, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun ọ̀run ati ayé.

12 Nítorí náà, ẹ fi OLUWA búra fún mi nisinsinyii pé, bí mo ti ṣe yín lóore yìí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ṣe ilé baba mi lóore, kí ẹ sì fún mi ní àmì tí ó dájú.

13 Kí ẹ dá baba mi ati ìyá mi sí, ati àwọn arakunrin mi, ati àwọn arabinrin mi, ati gbogbo àwọn eniyan wọn; ẹ má jẹ́ kí á kú.”

14 Àwọn ọkunrin náà bá dá a lóhùn pé, “Kí OLUWA gba ẹ̀mí wa bí a bá pa yín. Bí o kò bá ṣá ti sọ ohun tí a wá ṣe níhìn-ín fún ẹnikẹ́ni, a óo ṣe ọ́ dáradára, a óo sì jẹ́ olóòótọ́ sí ọ nígbà tí OLUWA bá fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́.”

15 Ó bá fi okùn kan sọ̀ wọ́n kalẹ̀ láti ojú fèrèsé, nítorí pé àkọ́pọ̀ mọ́ odi ìlú ni wọ́n kọ́ ilé rẹ̀, inú odi yìí ni ó sì ń gbé.

16 Ó bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ sá lọ sí orí òkè, kí àwọn tí wọ́n ń lépa yín má baà pàdé yín lójú ọ̀nà. Ẹ sá pamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí wọn óo fi pada dé. Lẹ́yìn náà, ẹ máa bá tiyín lọ.”

17 Àwọn ọkunrin náà sọ fún Rahabu pé, “A óo mú ìlérí tí o mú kí á fi ìbúra ṣe fún ọ ṣẹ.

18 Nígbà tí a bá wọ ilẹ̀ yìí, mú okùn pupa yìí, kí o so ó mọ́ ibi fèrèsé tí o ti sọ̀ wá kalẹ̀. Kó baba, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ, ati gbogbo àwọn ará ilé baba rẹ sí inú ilé rẹ.

19 Bí ẹnikẹ́ni bá jáde kúrò ninu ilé rẹ lọ sí ààrin ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí ara rẹ̀, kò sì ní sí ẹ̀bi lọ́rùn wa. Ṣugbọn bí wọn bá pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà lórí wa.

20 Ṣugbọn bí o bá sọ ohun tí a wá ṣe fún ẹnikẹ́ni, ẹ̀bi ìlérí tí a fi ìbúra ṣe yìí kò ní sí lórí wa mọ́.”

21 Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ ti wí gan-an, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.” Ó ní kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì lọ; ó bá so okùn pupa náà mọ́ fèrèsé rẹ̀.

22 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sá lọ sí orí òkè, wọ́n sì farapamọ́ fún ọjọ́ mẹta, títí tí àwọn tí wọn ń lépa wọn fi pada; nítorí pé wọ́n ti wá wọn káàkiri títí ní gbogbo ojú ọ̀nà, wọn kò sì rí wọn.

23 Àwọn ọkunrin meji náà sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ́n lọ bá Joṣua, ọmọ Nuni, wọ́n bá sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn fún un.

24 Wọ́n sọ fún Joṣua pé, “Láìṣe àní àní, OLUWA ti fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn sì ti bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà nítorí wa.”

Categories
JOṢUA

JOṢUA 3

Àwọn Ọmọ Israẹli La Odò Jọdani Kọjá

1 Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbéra ní Akasia lọ sí etí odò Jọdani, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀ kí wọn tó la odò náà kọjá.

2 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, gbogbo àwọn olórí wọn lọ káàkiri àgọ́ náà.

3 Wọ́n pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i pé, àwọn alufaa, ọmọ Lefi gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, kí ẹ̀yin náà gbéra, kí ẹ sì tẹ̀lé wọn.

4 Kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ óo gbà, nítorí pé ẹ kò rin ọ̀nà yìí rí. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àpótí Majẹmu náà jù, ẹ gbọdọ̀ fi àlàfo tí ó tó nǹkan bí ẹgbaa (2,000) igbọnwọ sílẹ̀ láàrin ẹ̀yin ati Àpótí Majẹmu náà.”

5 Joṣua sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nítorí pé OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin yín ní ọ̀la.”

6 Joṣua bá sọ fún àwọn alufaa pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu náà kí ẹ sì máa lọ níwájú àwọn eniyan yìí.” Wọ́n bá gbé Àpótí Majẹmu náà, wọ́n sì ń lọ níwájú wọn.

7 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ.

8 Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí odò Jọdani, ẹ wọ inú odò lọ, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ ”

9 Joṣua bá pe àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun yín wí.

10 Èyí ni ẹ óo fi mọ̀ pé Ọlọrun alààyè wà láàrin yín, kò sì ní kùnà láti lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi, àwọn ará Perisi, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Jebusi, jáde fun yín.

11 Wò ó! Wọn yóo gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé kọjá níwájú yín sinu odò Jọdani.

12 Nítorí náà, ẹ yan àwọn ọkunrin mejila ninu ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

13 Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.”

14 Nígbà náà ni àwọn eniyan náà gbéra ninu àgọ́ wọn láti la odò Jọdani kọjá pẹlu àwọn alufaa tí wọn ń gbé Àpótí Majẹmu lọ níwájú wọn,

15 (àkókò náà jẹ́ àkókò ìkórè, odò Jọdani sì kún dé ẹnu), ṣugbọn bí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu ti dé etídò náà, tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn kan omi,

16 omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko.

17 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá lọ lórí ilẹ̀ gbígbẹ, àwọn alufaa tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA dúró lórí ilẹ̀ gbígbẹ láàrin odò Jọdani, títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi la odò Jọdani kọjá.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 4

Wọ́n To Òkúta Ìrántí Jọ

1 Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani tán, OLUWA wí fún Joṣua pé,

2 “Yan ọkunrin mejila láàrin àwọn eniyan náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

3 Kí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n gbé òkúta mejila láàrin odò Jọdani yìí, lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa dúró sí, kí wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ bí ẹ ti ń lọ, kí ẹ sì kó wọn jọ sí ibi tí ẹ óo sùn lálẹ́ òní.”

4 Joṣua bá pe àwọn ọkunrin mejila tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan;

5 ó wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, sí ààrin odò Jọdani, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan sì gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká rẹ̀. Kí iye òkúta tí ẹ óo gbé jẹ́ iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli.

6 Kí èyí lè jẹ́ ohun ìrántí fun yín, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ yín ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí?’

7 Nígbà náà, ẹ óo dá wọn lóhùn pé omi odò Jọdani pín sí meji níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA nígbà tí wọn gbé e kọjá odò náà. Nítorí náà, àwọn òkúta wọnyi yóo jẹ́ ohun ìrántí ayérayé fún àwọn ọmọ Israẹli.”

8 Àwọn ọkunrin náà ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Joṣua pa fún wọn. Wọ́n gbé òkúta mejila láti inú odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Joṣua. Wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ lọ sí ibi tí wọ́n sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì tò wọ́n jọ sibẹ.

9 Joṣua to òkúta mejila mìíràn jọ láàrin odò Jọdani lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu dúró sí; àwọn òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

10 Nítorí pé àwọn alufaa tí ó gbé Àpótí Majẹmu OLUWA dúró láàrin odò Jọdani, títí tí àwọn eniyan náà fi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé kí Joṣua sọ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún un.

11 Aré ni àwọn eniyan náà sá gun òkè odò Jọdani. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti gun òkè odò tan, àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gòkè odò tẹ̀lé wọn, wọ́n sì rékọjá lọ siwaju wọn.

12 Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase náà gòkè odò pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn.

13 Nǹkan bíi ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n ti múra ogun, ni wọ́n rékọjá níwájú OLUWA lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko.

14 OLUWA gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀, bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

15 OLUWA wí fún Joṣua pé,

16 “Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí pé kí wọ́n jáde kúrò ninu odò Jọdani.”

17 Joṣua bá pàṣẹ fún àwọn alufaa náà pé kí wọ́n jáde ninu odò.

18 Nígbà tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA jáde kúrò ninu odò Jọdani, bí wọ́n ti ń gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ gbígbẹ, ni omi odò náà pada sí ààyè rẹ̀. Odò náà sì kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

19 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko.

20 Joṣua bá to àwọn òkúta mejila tí wọ́n kó jáde láti inú odò Jọdani kalẹ̀ ní Giligali.

21 Ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́wọ́ àwọn baba wọn ní ọjọ́ iwájú pé báwo ni ti àwọn òkúta wọnyi ti jẹ́ rí?

22 Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé àwọn ọmọ Israẹli kọjá odò Jọdani yìí lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

23 Nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí odò Jọdani gbẹ títí ẹ fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti mú kí Òkun Pupa gbẹ, títí tí ẹ fi là á kọjá.

24 Kí gbogbo aráyé lè mọ̀ pé, OLUWA lágbára, kí ẹ sì lè máa bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín títí lae.”

Categories
JOṢUA

JOṢUA 5

1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli.

Wọ́n Kọ Ilà Abẹ́ ní Giligali

2 Nígbà náà ni OLUWA wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ, kí o sì fi kọ ilà abẹ́ lẹẹkeji fún àwọn ọmọ Israẹli.”

3 Joṣua bá fi akọ òkúta ṣe abẹ, ó fi kọ ilà abẹ́ fún gbogbo ọkunrin Israẹli ní Gibeati Haaraloti.

4 Ìdí tí Joṣua fi kọ ilà abẹ́ fún wọn ni pé, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ti kú lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n kọ ilà abẹ́, ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bí lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní ilẹ̀ Ijipti kò kọ ilà.

6 Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.

7 Nítorí náà, àwọn ọmọ wọn tí OLUWA gbé dìde dípò wọn ni Joṣua kọ ilà abẹ́ fún, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà.

8 Nígbà tí àwọn eniyan náà kọ ilà abẹ́ tán, olukuluku wà ní ààyè rẹ̀ ninu àgọ́ títí egbò wọn fi jinná.

9 OLUWA wí fún Joṣua pé, “Lónìí yìí ni mo mú ẹ̀gàn àwọn ará Ijipti kúrò lára yín.” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Giligali títí di òní olónìí.

10 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí Giligali, wọ́n ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù náà, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko.

11 Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ.

12 Mana kò dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn ọmọ Israẹli kò rí i kó mọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ninu èso ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọ́n jẹ ninu èso ilẹ̀ Kenaani ní gbogbo ọdún náà.

Joṣua ati Ẹni Tí Ó Mú Idà Lọ́wọ́

13 Nígbà tí Joṣua súnmọ́ ìlú Jẹriko, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i tí ọkunrin kan dúró níwájú rẹ̀ pẹlu idà lọ́wọ́. Joṣua lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi í pé, “Tiwa ni ò ń ṣe ni, tabi ti àwọn ọ̀tá wa?”

14 Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.”

Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?”

15 Balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA dá Joṣua lóhùn pé, “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 6

Wíwó Odi Jẹriko

1 Wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi Jẹriko ninu ati lóde, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnikẹ́ni kò lè jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè wọlé.

2 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn.

3 Ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóo rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lojumọ fún ọjọ́ mẹfa.

4 Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn.

5 Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.”

6 Joṣua, ọmọ Nuni, bá pe àwọn alufaa, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu, kí meje ninu yín sì mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA.”

7 Ó sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa tẹ̀síwájú, ẹ rìn yípo ìlú náà kí àwọn ọmọ ogun ṣáájú Àpótí Majẹmu OLUWA.”

8 Gẹ́gẹ́ bí Joṣua ti pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, àwọn alufaa meje mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú OLUWA, wọ́n ṣáájú, wọ́n ń fọn fèrè ogun wọn; àwọn tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sì tẹ̀lé wọn.

9 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun ṣáájú àwọn alufaa tí wọn ń fọn fèrè ogun, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu. Àwọn tí wọn ń fọn fèrè ogun sì ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́.

10 Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn yín. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ rárá títí di ọjọ́ tí n óo sọ pé kí ẹ hó, nígbà náà ni ẹ óo tó hó.”

11 Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí wọn gbé Àpótí Majẹmu OLUWA yí ìlú náà po lẹ́ẹ̀kan, nígbà tí ó di alẹ́, wọ́n pada sinu àgọ́ wọn, wọ́n sì sùn sibẹ.

12 Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, àwọn alufaa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA.

13 Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́.

14 Ní ọjọ́ keji, wọ́n yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan, wọn sì pada sinu àgọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹfa.

15 Ní ọjọ́ keje, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n yípo ìlú náà bí wọ́n ti máa ń ṣe, nígbà meje. Ọjọ́ keje yìí nìkan ṣoṣo ni wọ́n yípo rẹ̀ lẹẹmeje.

16 Nígbà tí ó di ẹẹkeje, lẹ́yìn tí àwọn alufaa fọn fèrè wọn, Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ hó yèè! Nítorí OLUWA ti fi ìlú yìí le yín lọ́wọ́.

17 OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́.

18 Ẹ yẹra fún ohunkohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ má baà di ẹni ègún nípa mímú ohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀, kí ẹ má baà sọ àgọ́ Israẹli di ohun ìparun, kí ẹ sì kó ìyọnu bá a.

19 Ṣugbọn gbogbo fadaka ati wúrà ati àwọn ohun èlò idẹ ati ti irin jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, inú ilé ìṣúra OLUWA ni a óo kó wọn sí.”

20 Àwọn alufaa fọn fèrè ogun, bí àwọn eniyan ti gbọ́ ìró fèrè, gbogbo wọn hó yèè! Odi ìlú náà sì wó lulẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun bá rọ́ wọ ààrin ìlú, wọ́n sì gba ìlú náà.

21 Wọ́n run gbogbo àwọn ará ìlú náà patapata: atọkunrin, atobinrin, àtọmọdé, àtàgbà, àtakọ mààlúù, ataguntan, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; gbogbo wọn ni wọ́n fi idà parun.

22 Joṣua sọ fún àwọn ọkunrin meji tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà pé, “Ẹ wọ ilé aṣẹ́wó náà lọ, kí ẹ sì mú obinrin náà wá ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti búra fún un.”

23 Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ ṣe amí náà bá wọlé, wọ́n mú Rahabu jáde, ati baba rẹ̀, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n sì kó wọn sí ẹ̀yìn àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

24 Wọ́n dáná sun ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, àfi fadaka ati wúrà, ati àwọn ohun èlò idẹ, ati ti irin, ni wọ́n kó lọ sinu ilé ìṣúra OLUWA.

25 Ṣugbọn Joṣua dá Rahabu aṣẹ́wó sí, ati ilé baba rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní yìí; nítorí pé, Rahabu ni ó gbé àwọn amí tí Joṣua rán lọ wo ìlú Jẹriko pamọ́.

26 Joṣua bá gégùn-ún nígbà náà pé,

“Ẹni ìfibú OLUWA ni ẹnikẹ́ni tí ó bá dìde láti tún ìlú Jẹriko kọ́.

Àkọ́bí ẹni tí ó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ yóo kú,

àbíkẹ́yìn rẹ̀ yóo kú nígbà tí ó bá gbé ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ ró.”

27 OLUWA wà pẹlu Joṣua, òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 7

Ẹ̀ṣẹ̀ Akani

1 Àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí pé ẹnìkan mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, láti inú ẹ̀yà Juda, mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀, inú sì bí OLUWA gidigidi sí àwọn ọmọ Israẹli.

2 Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai.

3 Wọ́n pada tọ Joṣua wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Má wulẹ̀ jẹ́ kí gbogbo àwọn eniyan lọ gbógun ti ìlú Ai, yan àwọn eniyan bí ẹgbaa (2,000) tabi ẹgbẹẹdogun (3,000) kí wọ́n lọ gbógun ti ìlú náà. Má wulẹ̀ lọ dààmú gbogbo àwọn eniyan lásán, nítorí pé àwọn ará Ai kò pọ̀ rárá.”

4 Nítorí náà, nǹkan bí ẹgbẹẹdogun (3,000) ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ gbógun tì wọ́n. Ṣugbọn wọ́n sá níwájú àwọn ará Ai.

5 Àwọn ọmọ ogun Ai pa tó mẹrindinlogoji (36) ninu wọn, wọ́n sì lé gbogbo wọn kúrò ní ẹnubodè wọn títí dé Ṣebarimu. Wọ́n ń pa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ọkàn àwọn ọmọ Israẹli bá dààmú, àyà wọn sì já.

6 Joṣua fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ hàn, òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli dojúbolẹ̀ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ku eruku sórí.

7 Joṣua bá gbadura, ó ní, “Yéè! OLUWA Ọlọrun! Kí ló dé tí o fi kó àwọn eniyan wọnyi gòkè odò Jọdani láti fà wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wọ́n run? Ìbá tẹ́ wa lọ́rùn kí á wà ní òdìkejì odò Jọdani, kí á sì máa gbé ibẹ̀.

8 OLUWA, kí ni mo tún lè sọ, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn?

9 Àwọn ará Kenaani, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóo gbọ́, wọn yóo yí wa po, wọn yóo sì pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, OLUWA! Kí lo wá fẹ́ ṣe, nítorí orúkọ ńlá rẹ?”

10 Nígbà náà ni OLUWA wí fun Joṣua pé, “Dìde. Kí ló dé tí o fi dojúbolẹ̀?

11 Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n ti rú òfin mi. Wọ́n ti mú ninu àwọn ohun tí a yà sọ́tọ̀, wọ́n ti jalè, wọ́n ti purọ́, wọn sì ti fi ohun tí wọ́n jí pamọ́ sábẹ́ àwọn ohun ìní wọn.

12 Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín.

13 Ẹ dìde, ẹ ya àwọn eniyan náà sí mímọ́; kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti sọ pé àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ wà láàrin ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ẹ kò sì ní lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín títí tí ẹ óo fi kó àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ kúrò láàrin yín.’

14 Nítorí náà, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, a óo mú gbogbo yín wá siwaju OLUWA ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ẹ̀yà tí OLUWA bá mú yóo wá ní agbo-ilé agbo-ilé. Agbo-ilé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ìdílé-ìdílé. Àwọn ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

15 Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pẹlu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, iná ni a óo dá sun àtòun, ati gbogbo nǹkan tí ó ní, nítorí pé ó ti ṣẹ̀ sí majẹmu OLUWA. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli.”

16 Joṣua gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú ẹ̀yà Juda.

17 Ó kó ẹ̀yà Juda wá ní agbo-ilé kọ̀ọ̀kan, wọn sì mú agbo-ilé Sera. Ó kó agbo-ilé Sera wá, wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ibẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Sabidi.

18 Wọ́n sì fa àwọn ọkunrin ìdílé Sabidi kalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, ti ẹ̀yà Juda.

19 Joṣua wí fún Akani pé, “Ọmọ mi, fi ògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí o sì yìn ín. Jẹ́wọ́ ohun tí o ṣe, má fi pamọ́ fún mi.”

20 Akani dá Joṣua lóhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ohun tí mo sì ṣe nìyí:

21 Nígbà tí mo wo ààrin àwọn ìkógun, mo rí ẹ̀wù àwọ̀lékè dáradára kan láti Ṣinari, ati igba ìwọ̀n Ṣekeli fadaka, ati ọ̀pá wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọta Ṣekeli, wọ́n wọ̀ mí lójú, mo bá kó wọn, mo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ ninu àgọ́ mi. Fadaka ni mo fi tẹ́lẹ̀.”

22 Joṣua bá ranṣẹ, wọ́n sáré lọ wo inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n bá àwọn nǹkan náà ní ibi tí ó bò wọ́n mọ́, ó fi fadaka tẹ́lẹ̀.

23 Wọ́n hú wọn jáde ninu àgọ́ rẹ̀, wọ́n kó wọn wá siwaju Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì tẹ́ wọn kalẹ̀ níwájú OLUWA.

24 Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá mú Akani, ọmọ Sera, ati fadaka, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè, ati ọ̀pá wúrà, ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, àwọn akọ mààlúù rẹ̀ ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn aguntan rẹ̀ ati àgọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní, wọ́n kó wọn lọ sí àfonífojì Akori.

25 Joṣua bá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa sinu gbogbo ìyọnu yìí? OLUWA sì ti kó ìyọnu bá ìwọ náà lónìí.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá sọ wọ́n ní òkúta pa, wọ́n sì dáná sun wọ́n.

26 Wọ́n kó òkítì òkúta jọ sórí rẹ̀. Òkítì òkúta náà sì wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

OLUWA bá yí ibinu rẹ̀ pada. Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì Akori.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 8

Gbígbà ati Pípa Ìlú Ai Run

1 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ kí o lọ sí ìlú Ai. Wò ó! Mo ti fi ọba Ai, ati àwọn eniyan rẹ̀, ìlú rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.

2 Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.”

3 Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́.

4 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ fara pamọ́ lẹ́yìn ìlú náà, ẹ má jìnnà sí i pupọ, ṣugbọn ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀.

5 Èmi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu mi nìkan ni a óo wọ ìlú náà. Nígbà tí wọ́n bá jáde sí wa láti bá wa jà bí i ti àkọ́kọ́, a óo sá fún wọn.

6 Wọn yóo máa lé wa lọ títí tí a óo fi tàn wọ́n jáde kúrò ninu ìlú, nítorí wọn yóo ṣe bí à ń sálọ fún wọn bíi ti àkọ́kọ́ ni; nítorí náà ni a óo ṣe sá fún wọn.

7 Ẹ̀yin ẹ dìde níbi tí ẹ farapamọ́ sí, kí ẹ sì gba ìlú náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yóo fi lé yín lọ́wọ́.

8 Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà tán, ẹ ti iná bọ̀ ọ́, kí ẹ sì ṣe bí àṣẹ OLUWA. Ó jẹ́ àṣẹ tí mo pa fun yín.”

9 Joṣua bá rán wọn ṣiwaju, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọn yóo fara pamọ́ sí ní ìwọ̀ oòrùn Ai, láàrin Ai ati Bẹtẹli. Ṣugbọn Joṣua wà pẹlu àwọn eniyan ní gbogbo òru ọjọ́ náà.

10 Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn eniyan náà jọ. Òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli ṣáájú wọn, wọ́n lọ sí Ai.

11 Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá a lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìlú Ai, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí apá ìhà àríwá ìlú náà, odò kan ni ó wà láàrin wọn ati ìlú Ai.

12 Joṣua ṣa nǹkan bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọmọ ogun, ó fi wọ́n pamọ́ sí ààrin Bẹtẹli ati Ai ní apá ìwọ̀ oòrùn Ai.

13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi àwọn ọmọ ogun wọn sí ipò, àwọn tí wọn yóo gbógun ti ìlú gan-an wà ní apá ìhà àríwá ìlú, àwọn tí wọn yóo wà lẹ́yìn wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ṣugbọn Joṣua alára wà ní àfonífojì ní gbogbo òru ọjọ́ náà.

14 Nígbà tí ọba Ai ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ rí i, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ìlú náà bá yára, wọ́n jáde lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ọ̀nà Araba láti kó ogun pàdé àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé àwọn kan ti farapamọ́ sẹ́yìn ìlú.

15 Joṣua ati gbogbo ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá ṣe bí ẹni pé àwọn ará Ai ti ṣẹgun àwọn, wọ́n sì sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ.

16 Àwọn ará Ai bá pe gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ìlú jọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. Bí wọ́n ti ń lé Joṣua lọ ni wọ́n ń jìnnà sí ìlú.

17 Kò sì sí ẹyọ ọkunrin kan tí ó kù ní Ai ati Bẹtẹli tí kò jáde láti lépa àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n fi ìlẹ̀kùn ẹnubodè sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n ń lé àwọn ọmọ Israẹli lọ.

18 OLUWA sọ fun Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ sí ọ̀kánkán Ai, nítorí n óo fi lé ọ lọ́wọ́.” Joṣua bá na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí ọ̀kánkán ìlú náà.

19 Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i.

20 Nígbà tí àwọn ará Ai bojú wẹ̀yìn, tí wọ́n rí i tí èéfín yọ ní ìlú wọn, wọn kò ní agbára mọ́ láti sá síhìn-ín tabi sọ́hùn-ún, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ yíjú pada sí wọn.

21 Nígbà tí Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn tí wọn farapamọ́ ti gba ìlú náà, tí èéfín sì ti yọ sókè, wọ́n yipada, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ará Ai.

22 Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ninu ìlú náà jáde sí wọn, àwọn ará Ai sì wà ní agbede meji àwọn ọmọ Israẹli, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni, àwọn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ keji. Àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n ní ìpakúpa títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

23 Ṣugbọn wọ́n mú ọba Ai láàyè, wọ́n sì mú un tọ Joṣua wá.

24 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata.

25 Gbogbo àwọn ará Ai tí wọ́n pa ní ọjọ́ náà, ati ọkunrin, ati obinrin, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaafa (12,000).

26 Nítorí pé ọwọ́ tí Joṣua fi na ọ̀kọ̀ sókè, kò gbé e sílẹ̀ títí tí wọ́n fi pa gbogbo àwọn ará Ai tán.

27 Àfi ẹran ọ̀sìn ati dúkìá ìlú náà ni àwọn ọmọ Israẹli kó ní ìkógun gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua.

28 Joṣua dáná sun ìlú Ai, ó sì sọ ọ́ di òkítì àlàpà títí di òní olónìí.

29 Ó so ọba Ai kọ́ sórí igi kan títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọn já òkú rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì wọ́ ọ sí ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta jọ lé e lórí, òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

Joṣua Ka Òfin ní Òkè Ebali

30 Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli ní orí òkè Ebali,

31 bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli ati gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sí inú ìwé òfin Mose pé, “Pẹpẹ tí wọ́n fi òkúta tí wọn kò gbẹ́ kọ́, tí ẹnikẹ́ni kò gbé ohun èlò irin sókè láti gbẹ́ òkúta rẹ̀.” Wọ́n rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA lórí rẹ̀.

32 Joṣua mú òfin tí Mose kọ tẹ́lẹ̀, ó dà á kọ sórí àwọn òkúta náà lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

33 Gbogbo Israẹli, ati onílé, ati àlejò, gbogbo àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, ati àwọn aṣiwaju dúró ní òdìkejì Àpótí Majẹmu OLUWA, níwájú àwọn alufaa, ọmọ Lefi, tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu náà. Ìdajì wọn dúró níwájú òkè Ebali bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli.

34 Lẹ́yìn náà Joṣua ka gbogbo òfin náà sókè ati ibukun tí ó wà ninu rẹ̀, ati ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin.

35 Kò sí ohun tí Mose pa láṣẹ tí Joṣua kò kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àlejò tí wọ́n wà ní ààrin wọn.

Categories
JOṢUA

JOṢUA 9

Àwọn Ará Gibeoni Tan Joṣua Jẹ

1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ní òdìkejì odò Jọdani ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní etí òkun Mẹditarenia ní agbègbè Lẹbanoni, àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, gbọ́ nípa ìṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli,

2 gbogbo wọn parapọ̀, wọ́n fi ohùn ṣọ̀kan láti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli jagun.

3 Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí ìlú Jẹriko ati Ai,

4 wọ́n lo ọgbọ́n, wọ́n tọ́jú oúnjẹ, wọ́n mú àwọn àpò ìdọ̀họ tí wọ́n ti gbó, wọ́n dì wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọ́n mú awọ ìpọnmi tí ó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀,

5 wọ́n wọ sálúbàtà tí ó ti gbó ati aṣọ àkísà, gbogbo oúnjẹ tí wọn mú lọ́wọ́ ni ó ti gbẹ, tí ó sì ti bu.

6 Wọ́n tọ Joṣua lọ ninu àgọ́ tí ó wà ní Giligali, wọ́n wí fún òun ati àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ọ̀nà jíjìn ni a ti wá, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á dá majẹmu.”

7 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí fún àwọn ará Hifi náà pé, “Bóyá nítòsí ibí ni ẹ ti wá, báwo ni a ṣe lè ba yín dá majẹmu?”

8 Wọ́n sọ fún Joṣua pé “Iranṣẹ yín ni wá.”

Joṣua bá dá wọn lóhùn pé, “Ta ni yín, níbo ni ẹ sì ti wá?”

9 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ọ̀nà jíjìn ni àwa iranṣẹ rẹ ti wá nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, nítorí a ti gbúròó rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,

10 ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, Sihoni ọba àwọn ará Heṣiboni ati Ogu ọba àwọn ará Baṣani tí ń gbé Aṣitarotu.”

11 Gbogbo àwọn àgbààgbà wa ati gbogbo àwọn ará ilẹ̀ wa bá wí fún wa pé, “Ẹ wá lọ bá àwọn eniyan wọnyi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìn àjò náà, ẹ wí fún wọn pé iranṣẹ yín ni wá, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á jọ dá majẹmu.

12 Ẹ wò ó! Burẹdi wa nìyí, ó gbóná nígbà tí a dì í nílé fún ìrìn àjò yìí ní ọjọ́ tí a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti gbẹ, ó sì ti bu.

13 Titun ni àwọn awọ ìpọnmi wọnyi nígbà tí a kó wọn jáde tí a sì pọn omi sinu wọn. Ẹ wò ó, wọ́n ti gbó, wọ́n sì ti ya. Àwọn aṣọ wa ati àwọn bàtà wa ti gbó nítorí ìrìn àjò náà jìn.”

14 Àwọn ọmọ Israẹli bá wọn jẹ ninu oúnjẹ wọn, wọn kò sì bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ OLUWA.

15 Joṣua bá wọn dá majẹmu alaafia, pé, àwọn kò ní pa wọ́n, àwọn àgbààgbà Israẹli sì búra fún wọn.

16 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti bá àwọn eniyan náà ṣe àdéhùn, ni wọ́n gbọ́ pé nítòsí wọn ni wọ́n wà, ati pé aládùúgbò ni wọ́n.

17 Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìlú wọn. Àwọn ìlú náà ni: Gibeoni, Kefira, Beeroti ati Kiriati Jearimu.

18 Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò pa wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà wọn ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Gbogbo ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí i kùn sí àwọn àgbààgbà.

19 Ṣugbọn gbogbo àwọn àgbààgbà dá ìjọ eniyan náà lóhùn pé, “A ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli, a kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kàn wọ́n mọ́.

20 Ohun tí a lè ṣe ni pé kí á dá wọn sí, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a ti ṣe fún wọn.”

21 Àwọn àgbààgbà bá wí fún wọn pé, “Ẹ má pa wọ́n.” Àwọn àgbààgbà Israẹli bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà di aṣẹ́gi ati apọnmi fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

22 Joṣua pè wọ́n, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi tàn wá jẹ, tí ẹ wí fún wa pé, ọ̀nà jíjìn ni ẹ ti wá, nígbà tí ó jẹ́ pé ààrin wa níbí ni ẹ̀ ń gbé?

23 Nítorí náà, ẹ di ẹni ìfibú; ẹrú ni ẹ óo máa ṣe, ẹ̀yin ni ẹ óo máa ṣẹ́ igi tí ẹ óo sì máa pọnmi fun ilé Ọlọrun mi.”

24 Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe.

25 Sibẹsibẹ, ọwọ́ yín náà ni a ṣì wà; ẹ ṣe wá bí ó bá ti tọ́ lójú yín.”

26 Ohun tí Joṣua ṣe fún wọn ni pé ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n.

27 Ṣugbọn láti ọjọ́ náà ni Joṣua ti sọ wọ́n di ẹni tí ó ń ṣẹ́ igi, tí ó sì ń pọn omi fún àwọn eniyan Israẹli, ati fún pẹpẹ OLUWA. Títí di òní, àwọn ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà ní ibi tí OLUWA yàn pé kí àwọn ọmọ Israẹli ti máa jọ́sìn.