Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 50

Ogun kó Babiloni

1 OLUWA bá wolii Jeremaya sọ̀rọ̀ nípa Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea pé:

2 “Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

ta àsíá, kí o sì kéde.

Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé,

‘Ogun tí kó Babiloni,

ojú ti oriṣa Bẹli,

oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú.

Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’

3 “Nítorí pé orílẹ̀-èdè kan láti ìhà àríwá ti gbógun tì í,

yóo sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,

kò sì ní sí ẹni tí yóo gbé inú rẹ̀ mọ́,

ati eniyan ati ẹranko, wọn óo sá kúrò níbẹ̀.

Ìpadàbọ̀ Àwọn Ọmọ Israẹli

4 “Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda, yóo jọ wá pẹlu ẹkún, wọn yóo máa wá OLUWA Ọlọrun wọn.

5 Wọn yóo bèèrè ọ̀nà Sioni, wọn yóo kọjú sibẹ, wọn yóo sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á darapọ̀ mọ́ OLUWA, kí á sì bá a dá majẹmu ayérayé, tí a kò ní gbàgbé mọ́ títí ayé.’

6 “Àwọn eniyan mi dàbí aguntan tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ wọn ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ń lọ síhìn-ín, sọ́hùn-ún lórí òkè, wọ́n ń ti orí òkè kéékèèké bọ́ sí orí òkè ńláńlá; wọ́n ti gbàgbé ọ̀nà agbo wọn.

7 Gbogbo àwọn tí wọn rí wọn ń pa wọ́n jẹ, àwọn ọ̀tá wọn sì ń wí pé, ‘A kò ní ẹ̀bi kankan, nítorí pé wọ́n ti ṣẹ OLÚWA, tí ó jẹ́ ibùgbé òdodo wọn, ati ìrètí àwọn baba wọn.’

8 “Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni, ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, bí òbúkọ tí ó ṣáájú agbo ẹran.

9 Nítorí n óo rú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè sókè, láti ìhà àríwá, n óo sì kó wọn wá, wọn óo wá dóti Babiloni, wọn yóo gbógun tì í. Ibẹ̀ ni ọwọ́ wọn yóo ti tẹ̀ ẹ́, tí wọn óo sì fogun kó o. Ọfà wọn dàbí akọni ọmọ ogun, tí kì í pada sílé lọ́wọ́ òfo.

10 Ohun ìní àwọn ará Kalidea yóo di ìkógun; gbogbo àwọn tí wọn yóo kó wọn lẹ́rù ni yóo kó ẹrù ní àkótẹ́rùn, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìṣubú Babiloni

11 OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará Babiloni, tí ẹ kó àwọn eniyan mi,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú yín dùn ẹ sì ń yọ̀,

tí ẹ sì ń ṣe ojúkòkòrò, bí akọ mààlúù tí ń jẹko ninu pápá,

tí ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin:

12 Ojú yóo ti olú-ìlú yín lọpọlọpọ,

a óo dójú ti ilẹ̀ ìbí yín.

Wò ó! Yóo di èrò ẹ̀yìn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

yóo di aṣálẹ̀ tí ó gbẹ.

13 Nítorí ibinu gbígbóná OLUWA,

ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́;

yóo di ahoro patapata;

ẹnu yóo ya gbogbo ẹni tí ó bá gba Babiloni kọjá,

wọn yóo sì máa pòṣé nítorí ìyà tí a fi jẹ ẹ́.

14 “Ẹ gbógun ti Babiloni yíká, gbogbo ẹ̀yin tafàtafà. Ẹ máa ta á lọ́fà, ẹ má ṣẹ́ ọfà kankan kù, nítorí pé ó ti ṣẹ OLUWA.

15 Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ hó bò ó, ó ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn ibi ààbò rẹ̀ ti wó, àwọn odi rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀. Nítorí ẹ̀san OLUWA ni, ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀; ẹ ṣe sí i bí òun náà ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.

16 Ẹ pa àwọn afunrugbin run ní Babiloni, ati àwọn tí ń lo dòjé ní ìgbà ìkórè. Olukuluku yóo pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, yóo sì sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀, nítorí idà àwọn aninilára.”

Ìpadàbọ̀ Àwọn Ọmọ Israẹli

17 OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù.

18 Nítorí náà èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ ọba Babiloni ati ilẹ̀ rẹ̀ níyà, bí mo ṣe jẹ ọba Asiria níyà.

19 N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi.

20 OLUWA ní, Nígbà tí ó bá yá, tí àkókò bá tó, a óo wá ẹ̀ṣẹ̀ tì ní Israẹli ati Juda; nítorí pé n óo dáríjì àwọn tí mo bá ṣẹ́kù.”

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Babiloni

21 OLUWA ní,

“Ẹ gbógun ti ilẹ̀ Merataimu, ati àwọn ará Pekodi.

Ẹ pa wọ́n, kí ẹ sì run wọ́n patapata.

Gbogbo nǹkan tí mo pàṣẹ fun yín ni kí ẹ ṣe.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22 A gbọ́ ariwo ogun ati ìparun ńlá, ní ilẹ̀ náà.

23 Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀,

tí a sì fọ́ ọ!

Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

24 Mo dẹ tàkúté sílẹ̀ fun yín, ẹ̀yin ará Babiloni:

Tàkúté náà mu yín, ẹ kò sì mọ̀.

Wọ́n ri yín, ọwọ́ sì tẹ̀ yín,

nítorí pé ẹ yájú sí èmi OLUWA.

25 Mo ti ṣí ìlẹ̀kùn ilé ìṣúra àwọn nǹkan ìjà yín,

mo sì kó àwọn ohun ìjà ibinu yín jáde,

nítorí èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní iṣẹ́ kan láti ṣe ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea.

26 Ẹ gbógun tì í ní gbogbo ọ̀nà,

ẹ ṣí àká rẹ̀ sílẹ̀,

ẹ kó o jọ bí òkítì ọkà,

kí ẹ sì pa á run patapata,

ẹ má dá ohunkohun sí ninu rẹ̀.

27 Ẹ pa gbogbo akọ mààlúù rẹ̀,

ẹ fà wọ́n lọ sí ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran.

Àwọn ará Babiloni gbé, nítorí ọjọ́ wọn ti pé,

àní ọjọ́ ìjìyà wọn.”

28 (Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.)

29 “Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli.

30 Nítorí náà àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, yóo kú ní gbàgede rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní a óo parun ní ọjọ́ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31 “Wò ó! Mo dojú kọ ọ́,

ìwọ onigbeeraga yìí,

nítorí pé ọjọ́ ti pé tí n óo jẹ ọ́ níyà.

Èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

32 Agbéraga, o óo fẹsẹ̀ kọ, o óo sì ṣubú,

kò ní sí ẹni tí yóo gbé ọ dìde.

N óo dá iná kan ninu àwọn ìlú rẹ,

iná náà yóo sì jó gbogbo àyíká rẹ.”

33 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “À ń ni àwọn ọmọ Israẹli lára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Juda; gbogbo àwọn tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn ni wọ́n wo ọwọ́ mọ́ wọn, wọn kò jẹ́ kí wọn lọ.

34 Ṣugbọn alágbára ni Olùràpadà wọn, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Dájúdájú, yóo jà fún wọn, kí ó lè fún ayé ní ìsinmi, ṣugbọn kí ìdààmú lè bá àwọn ará Babiloni.”

35 OLUWA ní,

“Idà ni yóo pa àwọn ará Kalidea,

idà ni yóo pa àwọn ará Babiloni,

ati àwọn ìjòyè wọn,

ati àwọn amòye wọn!

36 Idà ni yóo pa àwọn awoṣẹ́ wọn,

kí wọ́n lè di òpè!

Idà ni yóo pa àwọn ọmọ ogun wọn,

kí wọ́n lè parẹ́!

37 Idà ni yóo pa àwọn ẹṣin wọn,

ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn,

idà ni yóo pa gbogbo àwọn àjèjì ọmọ ogun tí wọ́n wà láàrin wọn,

Kí wọ́n lè di obinrin!

Idà ni yóo fọ́ àwọn ilé ìṣúra wọn,

kí wọ́n lè di ìkógun!

38 Ọ̀dá yóo dá ní ilẹ̀ wọn,

kí àwọn odò wọn lè gbẹ!

Nítorí pé ilẹ̀ tí ó kún fún ère ni,

wọ́n sì kúndùn ìbọ̀rìṣà.

39 “Nítorí náà àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò ni yóo máa gbé inú Babiloni, ẹyẹ ògòǹgò yóo máa gbé inú rẹ̀. Kò ní sí eniyan níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ títí lae.

40 Yóo dàbí ìgbà tí Ọlọrun pa Sodomu ati Gomora run, pẹlu àwọn ìlú tí ó yí wọn ká; nítorí náà ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò ní máa dé sibẹ.

41 “Wò ó! Àwọn kan ń bọ̀ láti ìhà àríwá,

orílẹ̀-èdè ńlá, ati ọpọlọpọ ọba,

wọ́n ń gbára wọn jọ láti máa bọ̀ láti òkèèrè.

42 Wọ́n kó ọrun ati ọ̀kọ̀ lọ́wọ́,

ìkà ni wọ́n, wọn kò ní ojú àánú.

Ìró wọn dàbí ìró rírú omi òkun;

wọ́n gun ẹṣin,

wọ́n tò bí àwọn ọmọ ogun.

Wọ́n ń bọ̀ wá dojú kọ ọ́, ìwọ Babiloni!

43 Nígbà tí ọba Babiloni gbọ́ ìró wọn,

ọwọ́ rẹ̀ rọ,

ìrora sì mú un bíi ti obinrin tí ń rọbí.

44 “Wò ó! Bí kinniun tíí yọ ní aginjù odò Jọdani tíí kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí àwọn ará Babiloni, n óo mú kí wọn sá kúrò lórí ilẹ̀ wọn lójijì; n óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀. Nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?

45 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí èmi OLUWA pa lórí Babiloni, ati èrò mi lórí àwọn ará Kalidea: A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ; ibùjẹ ẹran wọn yóo sì parun nítorí tiwọn.

46 Ariwo wíwó odi Babiloni yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 51

Ọlọrun Tún Dá Babiloni lẹ́jọ́ sí i

1 OLUWA ní,

“Wò ó! N óo gbé ẹ̀mí apanirun kan dìde sí Babiloni,

ati sí àwọn ará Kalidea;

2 n óo rán ìjì líle kan sí Babiloni,

ìjì náà yóo fẹ́ ẹ dànù bí ìyàngbò ọkà

yóo sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,

nígbà tí wọ́n bá gbógun tì í yípo, ní ọjọ́ ìpọ́njú.

3 Kí tafàtafà má kẹ́ ọrun rẹ̀,

kí ó má sì gbé ẹ̀wù irin rẹ̀ wọ̀.

Má ṣe dá àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ sí,

pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run patapata.

4 Kí wọ́n ṣubú, kí wọ́n sì kú ní ilẹ̀ Kalidea,

kí wọ́n gún wọn ní àgúnyọ láàrin ìgboro.

5 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ati Juda kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀;

ṣugbọn ilẹ̀ Kalidea kún fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀,

tí wọ́n dá sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.

6 Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni,

kí olukuluku sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀!

Ẹ má parun nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Babiloni;

nítorí àkókò ẹ̀san OLUWA nìyí,

yóo sì san ẹ̀san fún Babiloni.

7 Ife wúrà ni Babiloni jẹ́ lọ́wọ́ OLUWA,

ó ń pa gbogbo ayé bí ọtí;

àwọn orílẹ̀-èdè mu ninu ọtí rẹ̀,

wọ́n sì ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

8 Babiloni ṣubú lójijì, ó sì fọ́;

ẹ sun ẹkún arò nítorí rẹ̀!

Ẹ fi ìwọ̀ra pa á lára nítorí ìrora rẹ̀,

bóyá ara rẹ̀ yóo yá.

9 À bá wo Babiloni sàn,

ṣugbọn a kò rí i wòsàn.

Ẹ pa á tì, ẹ jẹ́ kí á lọ,

kí olukuluku máa lọ sí ilẹ̀ rẹ̀;

nítorí ẹjọ́ tí a dá a ti dé òkè ọ̀run,

a sì ti gbé e sókè dé ojú ọ̀run.”

10 OLUWA ti dá wa láre;

ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ ròyìn iṣẹ́ OLUWA Ọlọrun wa ní Sioni.

11 Ẹ pọ́n ọfà yín!

Ẹ gbé asà yín!

Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè,

nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run.

Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó.

12 Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni;

ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára.

Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn;

ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́,

nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni.

13 Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká,

tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ,

òpin ti dé bá ọ,

okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já.

14 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra,

pé òun yóo mú kí àwọn eniyan kún inú rẹ bí eṣú,

wọn yóo sì kígbe ìṣẹ́gun lé ọ lórí.

Orin Ìyìn sí Ọlọrun

15 OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé,

tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀,

ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ.

16 Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀,

ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi,

ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé.

Ó dá mànàmáná fún òjò,

ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.

17 Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan, wọn kò sì ní ìmọ̀,

gbogbo alágbẹ̀dẹ wúrà sì gba ìtìjú lórí oriṣa tí wọn dà;

nítorí pé irọ́ ni ère tí wọ́n rọ,

wọn kò ní èémí.

18 Asán ni wọ́n, wọ́n ń ṣini lọ́nà,

píparun ni wọn yóo parun, ní ọjọ́ ìjìyà wọn.

19 Ọlọrun ti Jakọbu kò dàbí àwọn wọnyi,

nítorí pé òun ní ẹlẹ́dàá ohun gbogbo;

ẹ̀yà Israẹli ni eniyan tirẹ̀,

OLUWA àwọn ọmọ ogun sì ni orúkọ rẹ̀.

Òòlù OLUWA

OLUWA sọ fún Babiloni pé,

20 “Ìwọ ni òòlù ati ohun ìjà mi:

ìwọ ni mo fi wó àwọn orílẹ̀-èdè wómúwómú,

ìwọ ni mo sì fi pa àwọn ìjọba run.

21 Ìwọ ni mo fi lu ẹṣin ati ẹni tí ń gùn ún pa;

ìwọ ni mo fi wó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí ń bẹ ninu wọn.

22 Ìwọ ni mo fi lu tọkunrin tobinrin pa,

ìwọ ni mo fi lu tọmọde, tàgbà pa,

ìwọ ni mo sì fi run àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin.

23 Ìwọ ni mo fi pa olùṣọ́-aguntan ati agbo ẹran rẹ̀ rẹ́,

ìwọ ni mo fi run àgbẹ̀ ati àwọn alágbàro rẹ̀,

ìwọ ni mo fi ṣẹ́ apá àwọn gomina ati ti àwọn olórí ogun.”

Ìjìyà Babiloni

24 OLUWA ní,

“Níṣojú yín ni n óo fi san ẹ̀san fún Babiloni,

ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Kalidea,

fún gbogbo ibi tí wọ́n ṣe sí Sioni;

èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

25 Wò ó! Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè ìparun,

tí ò ń pa gbogbo ayé run.

N óo gbá ọ mú, n óo tì ọ́ lulẹ̀ láti orí àpáta,

n óo sì sọ ọ́ di òkè tí ó jóná.

26 Wọn kò ní rí òkúta kan mú jáde ninu rẹ,

tí eniyan lè fi ṣe òkúta igun ilé;

tabi tí wọn lè fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé,

ń ṣe ni o óo wó lulẹ̀ títí ayé.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27 “Ẹ ta àsíá sórí ilẹ̀ ayé,

ẹ fun fèrè ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;

kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,

ẹ sì pe àwọn ìjọba jọ láti dojú kọ ọ́;

àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bíi Ararati, Minni, ati Aṣikenasi.

Ẹ yan balogun tí yóo gbógun tì í;

ẹ kó ẹṣin wá, kí wọn pọ̀ bí eṣú.

28 Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,

kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn,

ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn,

ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn.

29 Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà,

wọ́n wà ninu ìrora,

nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada,

láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro,

láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́.

30 Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà,

wọ́n wà ní ibi ààbò wọn;

àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin.

Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná,

àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́.

31 Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn,

bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata.

32 Wọ́n ti gba ibi ìsọdá odò,

wọ́n ti dáná sun àwọn ibi ààbò,

ìbẹ̀rùbojo sì ti mú àwọn ọmọ ogun.

33 Babiloni dàbí ibi ìpakà, tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí à ń pa ọkà.

Láìpẹ́ ọ̀tá yóo dà á wó, yóo sì di àtẹ̀mọ́lẹ̀.

Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

34 “Nebukadinesari ọba Babiloni ti run Jerusalẹmu,

ó ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,

ó ti sọ ọ́ di ohun èlò òfìfo,

ó gbé e mì bí erinmi,

ó ti kó gbogbo ohun àdídùn inú rẹ̀ jẹ ní àjẹrankùn,

ó ti da ìyókù nù.

35 Jẹ́ kí àwọn tí ń gbé Sioni wí pé,

‘Kí ibi tí àwọn ará Babiloni ṣe sí wa ati sí àwọn arakunrin wa dà lé wọn lórí.’

Kí àwọn ará Jerusalẹmu sì wí pé,

‘Ẹ̀jẹ̀ wa ń bẹ lórí àwọn ará ilẹ̀ Kalidea.’ ”

OLUWA Yóo Ran Israẹli lọ́wọ́

36 Nítorí náà, OLUWA sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,

“Ẹ wò ó, n óo gba ẹjọ́ yín rò,

n óo sì ba yín gbẹ̀san.

N óo jẹ́ kí omi òkun Babiloni gbẹ,

n óo sì jẹ́ kí orísun odò rẹ̀ gbẹ.

37 Babiloni yóo sì di òkítì àlàpà, ati ibùgbé ajáko,

yóo di ibi àríbẹ̀rù ati àrípòṣé, láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀.

38 Gbogbo wọn yóo bú papọ̀ bíi kinniun,

wọn yóo sì ké bí àwọn ọmọ kinniun.

39 Nígbà tí ara wọn bá gbóná,

n óo se àsè kan fún wọn.

N óo rọ wọ́n lọ́tí yó,

títí tí wọn óo fi máa yọ ayọ̀ ẹ̀sín,

tí wọn óo sì sùn lọ títí ayé.

Wọn óo sùn, wọn kò sì ní jí mọ́.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

40 N óo fà wọ́n lọ sí ibi tí wọn tí ń pa ẹran,

bí ọ̀dọ́ aguntan, ati àgbò ati òbúkọ.”

Ìpín Babiloni

41 OLUWA ní,

“Ẹ wò ó bí ogun ti kó Babiloni,

Babiloni tí gbogbo ayé ń pọ́nlé!

Ó wá di àríbẹ̀rù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!

42 Òkun ti ru bo Babiloni mọ́lẹ̀.

Ìgbì òkun ti bò ó mọ́lẹ̀.

43 Àwọn ìlú rẹ̀ ti di àríbẹ̀rù,

wọ́n ti di ilẹ̀ gbígbẹ ati aṣálẹ̀,

ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé mọ́,

tí ọmọ eniyan kò sì gbà kọjá mọ́.

44 N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni,

n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì.

Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́,

odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀.

45 “Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ jáde kúrò níbẹ̀!

Kí olukuluku sá àsálà, kúrò lọ́wọ́ ibinu gbígbóná OLUWA!

46 Ẹ mọ́kàn, ẹ má bẹ̀rù,

nítorí ìròyìn tí ẹ̀ ń gbọ́ nípa ilẹ̀ náà,

nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìròyìn kan ní ọdún yìí,

tí ẹ tún gbọ́ òmíràn ní ọdún tí ń bọ̀,

tí ìwà ipá sì wà ní ilẹ̀ náà,

tí àwọn ìjòyè sì ń dojú ìjà kọ ara wọn.

47 Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀

tí n óo fìyà jẹ àwọn ère ilẹ̀ Babiloni.

Ojú yóo ti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,

òkú àwọn eniyan rẹ̀ tí ogun yóo pa,

yóo wà nílẹ̀ káàkiri ìgboro.

48 Nítorí náà, ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,

yóo yọ̀ nítorí ìṣubú Babiloni,

nítorí pé apanirun yóo wá gbógun tì í, láti ìhà àríwá,

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

49 Bí àwọn tí ogun Babiloni pa ní àwọn orílẹ̀-èdè ayé,

ti ṣubú níwájú rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni Babiloni náà gbọdọ̀ ṣubú,

nítorí àwọn tí wọ́n pa ní Israẹli.”

Ọlọrun Ranṣẹ sí Israẹli ní Babiloni

50 OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní Babiloni pé,

“Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà,

ẹ má dúró, ẹ máa sálọ!

Ẹ ranti OLUWA ní ilẹ̀ òkèèrè,

kí ẹ sì máa ronú nípa Jerusalẹmu pẹlu.

51 Ẹ̀ ń sọ pé ojú ń tì yín nítorí pé wọ́n kẹ́gàn yín;

ẹ ní ìtìjú dà bò yín,

nítorí pé àwọn àjèjì ti wọ ibi mímọ́ ilé OLUWA.

52 Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé,

ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀;

àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora,

ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

53 Bí Babiloni tilẹ̀ ga tí ó kan ojú ọ̀run,

tí ó sì mọ odi yí àwọn ibi ààbò rẹ̀ gíga ká,

sibẹsibẹ n óo rán apanirun sí i.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìparun Túbọ̀ Dé Bá Babiloni

54 OLUWA ní,

“Ẹ gbọ́ igbe kan láti Babiloni!

Igbe ìparun ńlá láti ilẹ̀ àwọn ará Kalidea!

55 Nítorí OLUWA ń wó Babiloni lulẹ̀,

ó sì ń pa á lẹ́nu mọ́.

Igbe wọn ta sókè bíi híhó omi òkun ńlá

56 nítorí pé apanirun ti dé sí i,

àní ó ti dé sí Babiloni.

Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀,

àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé,

nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA,

dájúdájú n óo gbẹ̀san.

57 N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó,

pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

Wọn yóo sun oorun àsùnrayè,

wọn kò sì ní jí mọ́ laelae.

Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ.

58 Odi Babiloni tí ó fẹ̀, yóo wó lulẹ̀,

a óo sì dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí ó ga fíofío.

Iṣẹ́ lásán ni àwọn eniyan ń ṣe,

àwọn orílẹ̀-èdè sì ń yọ ara wọn lẹ́nu lásán ni,

nítorí pé iná yóo jó gbogbo làálàá wọn.”

Jeremaya Ranṣẹ sí Babiloni

59 Jeremaya wolii pa àṣẹ kan fún Seraaya, alabojuto ibùdó ogun, ọmọ Neraya, ọmọ Mahiseaya nígbà tí ó ń bá Sedekaya ọba Juda lọ sí Babiloni ní ọdún kẹrin ìjọba Sedekaya.

60 Jeremaya kọ gbogbo nǹkan burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Babiloni ati gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa rẹ̀ sinu ìwé kan.

61 Ó bá pàṣẹ fún Seraaya pé nígbà tí ó bá dé Babiloni, kí ó rí i dájú pé ó ka gbogbo ohun tí òun kọ sinu ìwé náà sókè.

62 Kí ó sọ pé, “OLUWA, o ti sọ pé o óo pa ibí yìí run, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí nǹkankan tí yóo máa gbé inú rẹ̀ mọ́, ìbáà ṣe eniyan tabi ẹranko. O ní títí lae ni yóo di ahoro.”

63 Jeremaya ní nígbà tí Seraaya bá ka ìwé yìí tán, kí ó di òkúta kan mọ́ ọn kí ó jù ú sí ààrin odò Yufurate,

64 kí ó sì sọ wí pé, “Báyìí ni yóo rí fún Babiloni, kò sì ní gbérí mọ́, nítorí ibi tí OLUWA yóo mú kí ó dé bá a.”

Ibí yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ parí sí.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 52

Ìṣubú Jerusalẹmu

1 Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀.

2 Sedekaya ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bí Jehoiakimu ti ṣe.

3 Nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu ati Juda burú débi pé inú fi bí OLUWA sí wọn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi tì wọ́n jáde kúrò níwájú rẹ̀.

Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.

4 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká.

5 Wọ́n dóti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya.

6 Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn mú ní ààrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará ìlú kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́.

7 Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani.

8 Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa ọba Sedekaya, wọ́n sì bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá fọ́nká lẹ́yìn rẹ̀.

9 Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un.

10 Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, ó sì pa àwọn ìjòyè Juda ní Ribila.

11 Ó yọ ojú Sedekaya mejeeji, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó mú un lọ sí Babiloni, ó sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, títí tí ó fi kú.

Wọ́n Wó Tẹmpili Lulẹ̀

12 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ní ọdún kọkandinlogun tí Nebukadinesari ọba Babiloni jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, wọ ìlú Jerusalẹmu.

13 Ó sun ilé OLUWA níná ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn ilé ńláńlá ní ó dáná sun.

14 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.

15 Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́.

16 Ṣugbọn ó ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀ ninu àwọn talaka pé kí wọn máa ṣe ìtọ́jú ọgbà àjàrà kí wọn sì máa dá oko.

17 Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni.

18 Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.

19 Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.

20 Bàbà tí Solomoni fi ṣe òpó mejeeji ati agbada omi, pẹlu àwọn mààlúù idẹ mejeejila tí wọ́n gbé agbada náà dúró, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLUWA kọjá wíwọ̀n.

21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òpó náà ga ní igbọnwọ mejidinlogun, àyíká wọn jẹ́ igbọnwọ mejila, wọ́n nípọn, ní ìka mẹrin, wọ́n sì ní ihò ninu.

22 Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká.

23 Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà.

Wọ́n Kó Àwọn Ará Juda ní Ìgbèkùn Lọ sí Babiloni

24 Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta.

25 Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro.

26 Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.

27 Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati.

Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn.

28 Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu.

29 Ní ọdún kejidinlogun, ó kó àwọn ẹgbẹrin ó lé mejilelọgbọn (832) eniyan ní Jerusalẹmu.

30 Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600).

31 Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé.

32 Ó bá a sọ ọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga jùlọ, àní ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ.

33 Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

34 Ọba Babiloni sì rí i pé òun ń pèsè gbogbo ohun tí ó nílò lojoojumọ fún un títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.