Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 40

Jeremaya Ń Gbé Ọ̀dọ̀ Gedalaya

1 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, tú u sílẹ̀ ní Rama. Nebusaradani rí Jeremaya tí wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, wọ́n sì kó o pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn kó kúrò ní ìlú Jerusalẹmu ati ní ilẹ̀ Juda tí wọn ń kó lọ sí Babiloni.

2 Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, sọ fún Jeremaya pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ti pinnu láti ṣe ilẹ̀ yìí ní ibi;

3 Ó sì ti ṣe bí ó ti pinnu nítorí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí i, ẹ kò sì fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí náà ni ibi ṣe dé ba yín.

4 Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ.

5 Bí o bá fẹ́ pada, pada lọ bá Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babiloni fi ṣe gomina àwọn ìlú Juda, kí o máa bá a gbé láàrin àwọn eniyan náà. Bí o kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, ibi tí ó bá wù ọ́ láti lọ ni kí o lọ.” Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba bá fún un ní owó, oúnjẹ, ati ẹ̀bùn, ó ní kí ó máa lọ.

6 Jeremaya bá pada sọ́dọ̀ Gedalaya, ọmọ Ahikamu ní Misipa, ó sì ń gbé pẹlu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan tí wọn kù ní ilẹ̀ náà.

Gedalaya, Gomina Juda

7 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu jẹ gomina ní ilẹ̀ Juda, ati pé ó ti fi ṣe olùtọ́jú àwọn ọkunrin, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde ati díẹ̀ ninu àwọn talaka ilẹ̀ Juda, tí wọn kò kó lọ sí Babiloni,

8 wọ́n lọ bá Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n lọ nìwọ̀nyí: Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraaya, ọmọ Tanhumeti, àwọn ọmọ Efai, ará Netofa, Jesanaya, ọmọ ará Maakati, àwọn àtàwọn eniyan wọn.

9 Gedalaya bá búra fún àwọn ati àwọn eniyan wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù ati sin àwọn ará Kalidea. Ẹ máa gbé ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.

10 Ní tèmi, Misipa ni n óo máa gbé kí n lè máa rí ààyè bá àwọn ará Kalidea tí wọn wá dótì wá sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin ẹ máa kó ọtí, èso, ati òróró jọ sinu ìkòkò yín, kí ẹ sì máa gbé àwọn ìlú tí ẹ ti gbà.”

11 Bákan náà, nígbà tí gbogbo àwọn ará Juda tí wọn wà ní ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọn wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni ati ti Edomu ati àwọn tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ káàkiri gbọ́ pé ọba Babiloni dá àwọn eniyan díẹ̀ sí ní Juda, àtipé ó fi Gedalaya, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣe gomina wọn,

12 gbogbo àwọn ará Juda pada láti gbogbo ibi tí wọn sá lọ, wọ́n wá sí ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa, wọ́n sì kó ọtí ati èso jọ lọpọlọpọ.

Wọ́n Pa Gedalaya

13 Johanani ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko wá sọ́dọ̀ Gedalaya ní Misipa.

14 Wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Baalisi, ọba àwọn ọmọ Amoni ti rán Iṣimaeli, ọmọ Netanaya pé kí ó wá pa ọ́?” Ṣugbọn Gedalaya kò gbà wọ́n gbọ́.

15 Johanani bá sọ fún Gedalaya ní ìkọ̀kọ̀ ní Misipa pé, “Jẹ́ kí n lọ pa Iṣimaeli ọmọ Netanaya, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀. Kí ló dé tí o óo jẹ́ kí ó pa ọ́, tí gbogbo Juda tí wọn kóra jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ yóo sì túká; tí àwọn tí wọn ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan Juda yóo sì ṣègbé?”

16 Ṣugbọn Gedalaya sọ fún Johanani, ọmọ Karea pé, “Má ṣe bẹ́ẹ̀, irọ́ ni ò ń pamọ́ Iṣimaeli.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 41

1 Ní oṣù keje ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ọmọ Eliṣama dé, ìdílé ọba ni ó ti wá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. Òun pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá bá lọ sọ́dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu ní Misipa. Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Misipa,

2 Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ati àwọn mẹ́wàá tí wọ́n bá a wá dìde, wọ́n bá fi idà pa Gedalaya tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.

3 Iṣimaeli pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà pẹlu Gedalaya ní Misipa, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà níbẹ̀.

4 Ọjọ́ keji tí wọ́n pa Gedalaya tán, kí ẹnikẹ́ni tó gbọ́ nípa rẹ̀,

5 àwọn ọgọrin eniyan kan wá láti Ṣekemu, Ṣilo ati láti Samaria pẹlu irùngbọ̀n wọn ní fífá, wọ́n fa agbádá wọn ya, wọ́n sì ṣá ara wọn lọ́gbẹ́. Wọ́n mú ọrẹ ẹbọ ati turari lọ́wọ́ wá sí Tẹmpili OLUWA.

6 Iṣimaeli, ọmọ Netanaya sọkún pàdé wọn láti Misipa. Bí ó ti pàdé wọn ó wí pé, “Ẹ máa kálọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu.”

7 Nígbà tí wọ́n wọ ààrin ìlú, Iṣimaeli ọmọ Netanaya ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì kó òkú wọn dà sí inú kòtò.

8 Ṣugbọn àwọn mẹ́wàá kan ninu wọn sọ fún Iṣimaeli pé, “Má pa wá, nítorí a ní ọkà wíítì, ọkà baali, ati òróró ati oyin ní ìpamọ́ ninu oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀ kò sì pa wọ́n bí ó ti pa àwọn yòókù wọn.

9 Kòtò tí Iṣimaeli ju òkú àwọn eniyan tí ó pa sí ni kòtò tí ọba Asa gbẹ́ tí ó fi dí ọ̀nà mọ́ Baaṣa ọba Israẹli; ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya fi òkú eniyan tí ó pa kún kòtò náà.

10 Iṣimaeli bá kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa lẹ́rú, àwọn ọmọ ọba lobinrin ati gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa, àwọn tí Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba fi sí abẹ́ ìṣọ́ Gedalaya. Iṣimaeli kó wọn lẹ́rú ó sì fẹ́ kó wọn kọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Amoni.

11 Nígbà tí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gbọ́ gbogbo iṣẹ́ ibi tí Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ṣe,

12 wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn lọ gbógun ti Iṣimaeli, wọ́n bá a létí odò ńlá tí ó wà ní Gibeoni.

13 Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Iṣimaeli rí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, inú wọn dùn.

14 Ni gbogbo àwọn tí Iṣimaeli kó lẹ́rú ní Misipa bá yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n lọ bá Johanani ọmọ Karea.

15 Ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, pẹlu àwọn mẹjọ sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

16 Lẹ́yìn náà Johanani ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, kó gbogbo àwọn tí Iṣimaeli ọmọ Netanaya kó lẹ́rú ní Misipa, lẹ́yìn tí ó pa Gedalaya ọmọ Ahikamu tán, ó bá kó ati àwọn ọmọ ogun, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde, ati àwọn ìwẹ̀fà, pada wá láti Gibeoni.

17 Wọ́n lọ ń gbé Geruti Kimhamu, tí ó wà lẹ́bàá Bẹtilẹhẹmu. Wọ́n pinnu láti kó lọ sí ilẹ̀ Ijipti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea ń bà wọ́n;

18 nítorí pé Iṣimaeli ọmọ Netanaya ti pa Gedalaya, ọmọ Ahikamu, tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 42

Àwọn Eniyan náà Ní kí Jeremaya Gbadura fún Àwọn

1 Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn olórí ogun ati Johanani, ọmọ Karea ati Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati gbogbo àwọn ará Juda, lọ́mọdé ati lágbà, tọ wolii Jeremaya lọ.

2 Wọ́n wí fún un pé, “Nǹkan kan ni a fẹ́ bẹ̀ ọ́ fún, a sì fẹ́ kí o ṣe é fún wa: jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún àwa ati gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, nítorí pé a ti pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn díẹ̀ ninu wa ni ó kù, bí ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí i.

3 A fẹ́ kí OLUWA Ọlọrun rẹ lè fi ọ̀nà tí a óo gbà hàn wá, kí ó sọ ohun tí a óo ṣe fún wa.”

4 Wolii Jeremaya bá dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́, n óo gbadura sí OLUWA Ọlọrun yín bí ẹ ti wí; gbogbo ìdáhùn tí OLUWA bá fún mi ni n óo sọ fun yín, n kò ní fi nǹkankan pamọ́.”

5 Wọ́n wí fún Jeremaya pé, “Kí OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ ati òdodo bí a kò bá ṣe gbogbo nǹkan tí OLUWA Ọlọrun bá ní kí o sọ fún wa.

6 Ìbáà jẹ́ rere ni OLUWA Ọlọrun wa tí a rán ọ sí sọ, kì báà jẹ́ burúkú, a óo gbọ́ràn sí i lẹ́nu; kí ó lè dára fún wa; nítorí pé ti OLUWA Ọlọrun wa ni a óo gbọ́.”

Ìdáhùn OLUWA sí Adura Jeremaya

7 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀.

8 Jeremaya bá pe Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki.

9 Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ẹ ní kí n gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ siwaju rẹ̀ ní,

10 ‘Bí ẹ bá dúró ní ilẹ̀ yìí, n óo kọ yín bí ilé, n kò sì ní wo yín lulẹ̀. N óo gbìn yín bí igi, n kò sì ní fà yín tu, nítorí mo ti yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo ṣe sí yín.

11 Ẹ má bẹ̀rù ọba Babiloni tí ẹrù rẹ̀ ń bà yín, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo gbà yín là n óo sì yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀.

12 N óo ṣàánú yín, n óo jẹ́ kí ó ṣàánú yín, kí ó sì jẹ́ kí ẹ máa gbé orí ilẹ̀ yín.’

13 “Bí ẹ bá wí pé ẹ kò ní dúró ní ilẹ̀ yìí, tí ẹ kò sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu;

14 bí ẹ bá ń wí pé, ‘Rárá o, a óo sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a kò ti ní gbúròó ogun tabi fèrè ogun, níbi tí ebi kò ti ní pa wá, a óo sì máa gbé ibẹ̀,’

15 ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí ẹ bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti, pé ẹ óo lọ máa gbé ibẹ̀, ogun tí ẹ̀ ń sá fún yóo bá yín níbẹ̀;

16 ìyàn tí ẹ̀ ń bẹ̀rù yóo tẹ̀lé yín lọ sí Ijipti; ebi tí ẹ páyà rẹ̀ yóo gbá tẹ̀lé yín, ibẹ̀ ni ẹ óo sì kú sí.

17 Gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti láti máa gbé ibẹ̀ yóo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, wọn kò ní ṣẹ́kù, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni wọn kò ní bọ́ ninu ibi tí n óo mú wá sórí wọn.’

18 “Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí mo ti bínú sí àwọn ará Jerusalẹmu, tí inú mi sì ń ru sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni n óo bínú si yín nígbà tí ẹ bá dé Ijipti. Ẹ óo di ẹni ègún, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ẹ̀gàn ati ẹni ẹ̀sín. Ẹ kò sì ní fojú kan ilẹ̀ yìí mọ́.’

19 “OLUWA ti sọ fún ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda pé kí ẹ má lọ sí Ijipti. Ẹ mọ̀ dájúdájú pé mo kìlọ̀ fun yín lónìí

20 pé ẹ ti fi ẹ̀mí ara yín wéwu nítorí ìṣìnà yín. Nítorí pé nígbà tí ẹ rán mi sí OLUWA Ọlọrun yín pé kí n gbadura fun yín, gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín bá wí ni kí n sọ fun yín, ẹ ní ẹ óo sì ṣe é.

21 Mo ti sọ ohun tí Ọlọrun wí fun yín lónìí, ṣugbọn ẹ kò tẹ̀lé ọ̀kan kan ninu ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ní kí n sọ fun yín.

22 Nítorí náà ẹ mọ̀ dájú pé ẹ óo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, ní ibi tí ẹ fẹ́ lọ máa gbé.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 43

Wọ́n Mú Jeremaya Lọ sí Ijipti

1 Nígbà tí Jeremaya parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn rán an sí gbogbo àwọn ará ìlú,

2 Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn ọkunrin aláfojúdi kan wí fún Jeremaya pé, “Irọ́ ni ò ń pa. OLUWA Ọlọrun wa kò rán ọ láti sọ fún wa pé kí á má lọ ṣe àtìpó ní Ijipti.

3 Baruku, ọmọ Neraya, ni ó fẹ́ mú wa kọlù ọ́, kí o lè fà wá lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá; tabi kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni.”

4 Nítorí náà Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun ati gbogbo àwọn ará ìlú kò gba ohun tí OLUWA sọ, pé kí wọ́n dúró ní ilẹ̀ Juda.

5 Kàkà bẹ́ẹ̀, Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun kó gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọ́n pada wá sí ilẹ̀ Juda láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sálọ:

6 àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àwọn ọmọde, àwọn ìjòyè, ati gbogbo àwọn tí Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, fi sábẹ́ àkóso Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremaya wolii ati Baruku ọmọ Neraya.

7 Wọ́n kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, nítorí wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n lọ títí tí wọ́n fi dé Tapanhesi.

8 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní Tapanhesi:

9 Ó ní, “Gbé òkúta ńláńlá lọ́wọ́, kí o bò wọ́n mọ́lẹ̀, níbi pèpéle tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ààfin Farao ní Tapanhesi, lójú àwọn ará Juda,

10 kí o sì wí fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo lọ mú Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ òun wá, yóo sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka orí àwọn òkúta tí òun rì mọ́lẹ̀ yìí, Nebukadinesari yóo sì tẹ́ ìtẹ́ ọlá rẹ̀ sórí wọn.

11 Yóo wá kọlu ilẹ̀ Ijipti, yóo jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn tí yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn, yóo kó àwọn tí yóo lọ sí ìgbèkùn lọ sí ìgbèkùn, yóo sì fi idà pa àwọn tí yóo kú ikú idà.

12 Yóo dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti; yóo jó wọn níná; yóo sì kó àwọn ará ìlú lọ sí ìgbèkùn; yóo fọ ilẹ̀ Ijipti mọ́ bí darandaran tíí ṣa eégbọn kúrò lára aṣọ rẹ̀, yóo sì jáde kúrò níbẹ̀ ní alaafia.

13 Yóo fọ́ àwọn òpó ilé oriṣa Heliopolisi tí ó wà ní ilẹ̀ Ijipti, yóo sì dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 44

Iṣẹ́ Tí OLUWA Rán sí Àwọn Ọmọ Israẹli ní Ijipti

1 Nǹkan tí Jeremaya gbọ́ nípa gbogbo àwọn Juu tí wọn ń gbé Migidoli ati Tapanhesi, ati Memfisi ati ilẹ̀ Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti nìyí.

2 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Ẹ rí gbogbo ibi tí mo jẹ́ kí ó bá Jerusalẹmu ati gbogbo ìlú Juda. Ẹ wò wọ́n lónìí bí wọ́n ti di ahoro, tí kò sì sí eniyan ninu wọn,

3 nítorí ibi tí wọ́n ṣe, wọ́n mú mi bínú nítorí pé wọ́n sun turari sí àwọn oriṣa tí àwọn tabi àwọn baba wọn kò mọ̀ rí, wọ́n sì ń sìn wọ́n.

4 Sibẹsibẹ mo rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, sí wọn, kí wọ́n sọ fún wọn pé kí wọn má ṣe ohun ìríra tí n kò fẹ́.

5 Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò fetí sílẹ̀, wọn kò dáwọ́ ibi ṣíṣe dúró, wọn kò sì yé sun turari sí oriṣa mọ́.

6 Mo bá bínú gan-an sí àwọn ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu; mo sì sọ wọ́n di aṣálẹ̀ ati ahoro bí wọ́n ti wà lónìí.

7 “Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli wá ń bi yín léèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe ara yín ní ibi tó báyìí? Ṣé ẹ fẹ́ kó gbogbo àwọn eniyan wọnyi kúrò ní ilẹ̀ Juda, ati àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àtọmọ ọmú, àtọmọ ọwọ́, títí tí kò fi ní ku ẹnikẹ́ni ninu yín lẹ́yìn ni?

8 Kí ló dé tí ẹ fi ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bí mi ninu, tí ẹ̀ ń sun turari sí àwọn oriṣa ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ̀ ń gbé? Ṣé ẹ fẹ́ kí n pa yín run, kí ẹ di ẹni ẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni ẹ ṣe ń ṣe báyìí?

9 Ṣé ẹ ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín ṣe ní ilẹ̀ Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí àwọn ọba Juda ati àwọn ayaba ṣe ati ẹ̀yin pẹlu àwọn iyawo yín?

10 Wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ títí di òní, tabi kí wọn bẹ̀rù, tabi kí wọ́n pa òfin ati ìlànà tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín mọ́.’

11 “Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ wò ó, n óo dójúlé yín, n óo sì pa gbogbo ọmọ Juda run.

12 N óo run gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Juda tí wọ́n gbójú lé àtilọ máa gbé ilẹ̀ Ijipti, wọn kò ní ku ẹyọ kan ní ilẹ̀ Ijipti. Gbogbo wọn ni wọn óo parun láti orí àwọn mẹ̀kúnnù dé orí àwọn eniyan pataki pataki; ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n. Wọn yóo di ẹni ìfibú, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ègún ati ẹni ẹ̀sín.

13 N óo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, n óo fi ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run bí mo ṣe fi pa Jerusalẹmu run.

14 Ẹnikẹ́ni kò ní yè ninu àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ fi ilẹ̀ Ijipti ṣe ilé; wọn kò ní sá àsálà, wọn kò sì ní yè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní pada sí ilẹ̀ Juda tí ọkàn wọn fẹ́ pada sí. Wọn kò ní pada, àfi àwọn bíi mélòó kan ni wọ́n óo sá àsálà.’ ”

15 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn iyawo wọn ń sun turari sí àwọn oriṣa ati àwọn obinrin tí wọ́n pọ̀ gbáà tí wọn wà nítòsí ibẹ̀, ati àwọn tí wọn ń gbé Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n bá dá Jeremaya lóhùn,

16 wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA.

17 Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi.

18 Ṣugbọn láti ìgbà tí a ti dáwọ́ ati máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run dúró, tí a kò sì máa ta ohun mímu sílẹ̀ mọ́, ni a kò ti ní nǹkankan mọ́, tí ogun ati ìyàn sì fẹ́ẹ̀ pa wá tán.”

19 Àwọn obinrin bá tún dáhùn pé, “Nígbà tí à ń sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ ohun mímu sí i, ṣé àwọn ọkọ wa ni kò mọ̀ pé à ń ṣe àkàrà dídùn, tí à ń ṣe bí ère rẹ̀ fún un ni, ati pé à ń ta ohun mímu sílẹ̀ fún un?”

20 Jeremaya sọ fún gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n dá a lóhùn, lọkunrin ati lobinrin pé:

21 “Ṣebí OLUWA ranti turari tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín, ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà sun ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu, ṣebí OLUWA ranti.

22 OLUWA kò lè farada ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù, ati àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí náà, ni ilẹ̀ yín ṣe di ahoro ati aṣálẹ̀, ati ilẹ̀ tí a fi ń gégùn-ún, tí kò ní olùgbé, títí di òní.

23 Ìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀ si yín ni pé ẹ sun turari, ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ kò pa òfin, ati ìlànà rẹ̀ mọ́.”

24 Jeremaya dá gbogbo àwọn eniyan náà lóhùn, pataki jùlọ àwọn obinrin, ó ní, “Ẹ gbọ́ nǹkan tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti,

25 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹ̀yin ati àwọn iyawo yín ti fi ẹnu ara yín sọ, ẹ sì ti fi ọwọ́ ara yín mú ohun tí ẹ wí ṣẹ pé, “Dájúdájú a ti jẹ́jẹ̀ẹ́ sí oriṣa ọbabinrin ojú ọ̀run láti sun turari sí i, ati láti rú ẹbọ ohun mímu sí i.” ’ Kò burú, ẹ mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ!

26 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Ijipti: Ó ní, ‘Ẹ wò ó, mo ti fi orúkọ ńlá mi búra pé àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti kò ní fi orúkọ mi búra mọ́ pé “Bí OLUWA ti wà láàyè.”

27 Mo dójúlé yín láti ṣe yín ní ibi. Ibi ni n óo ṣe yín, n kò ní ṣe yín ní oore. Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Ijipti ni ogun ati ìyàn yóo pa láìku ẹnìkan.

28 Àwọn eniyan díẹ̀ ni wọn yóo sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Ijipti lọ sí ilẹ̀ Juda. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ sí Ijipti yóo wá mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóo ṣẹ, bóyá tèmi ni, tabi tiwọn.

29 Èyí ni yóo jẹ́ àmì fun yín pé n óo jẹ yín níyà ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ibi tí mo sọ si yín yóo ṣẹ mọ yín lára,

30 Èmi OLUWA ni mo sọ ọ́ pé n óo fi Farao Hofira ọba Ijipti lé ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekaya, ọba Juda lé ọwọ́ ọ̀tá rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ẹni tí ó ń wá ọ̀nà láti pa á.’ ”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 45

Ìlérí Ọlọrun fún Baruku

1 Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya wolii sọ fún Baruku ọmọ Neraya nìyí, ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya, jọba ní Juda. Baruku ń kọ ohun tí Jeremaya ń sọ sílẹ̀ bí Jeremaya tí ń sọ̀rọ̀.

2 Ó ní: “OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún ìwọ Baruku pé,

3 ò ń sọ pé, o gbé, nítorí pé OLUWA ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora rẹ; àárẹ̀ mú ọ nítorí ìkérora rẹ, o kò sì ní ìsinmi.

4 “Èmi ń wó ohun tí mo kọ́ lulẹ̀, mo sì ń tu ohun tí mo gbìn, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ gbogbo ilẹ̀ náà rí.

5 Ìwọ ń wá nǹkan ńlá fún ara tìrẹ? Má wá nǹkan ńlá fún ara rẹ. Wò ó, n óo mú kí ibi bá gbogbo eniyan, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; ṣugbọn n óo jẹ́ kí o máa sá àsálà ní gbogbo ibi tí o bá ń lọ.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 46

Nebukadinesari ṣẹgun Ijipti ní Kakemiṣi

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya wolii sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí.

2 Ọ̀rọ̀ lórí Ijipti: Nípa àwọn ọmọ ogun Farao Neko, ọba Ijipti, tí wọ́n wà létí odò Yufurate ní Kakemiṣi, àwọn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ṣẹgun ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba Juda.

3 “Ọ̀gágun Ijipti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé,

‘Ẹ tọ́jú asà ati apata,

kí ẹ sì jáde sójú ogun!

4 Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣin, ẹ di ẹṣin yín ní gàárì, kí ẹ sì gùn wọ́n.

Ẹ dúró ní ipò yín, pẹlu àṣíborí lórí yín.

Ẹ pọ́n àwọn ọ̀kọ̀ yín,

kí ẹ gbé ihamọra irin yín wọ̀!’ ”

5 Oluwa ní, “Kí ni mo rí yìí?

Ẹ̀rù ń bà wọ́n, wọ́n sì ń pada sẹ́yìn.

A ti lu àwọn ọmọ ogun wọn bolẹ̀,

wọ́n sì ń sálọ pẹlu ìkánjú;

wọn kò bojú wẹ̀yìn, ìpayà yí wọn ká!

6 Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sálọ,

bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun kò lè sá àsálà.

Ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate, ni wọ́n tí fẹsẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ṣubú.

7 Ta ló ń ru bí odò Naili yìí,

bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀?

8 Ijipti ń ru bí odò Naili,

bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀.

Ijipti wí pé, ‘N óo kún, n óo sì bo ayé mọ́lẹ̀,

n óo pa àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn run.

9 Ó yá, ẹṣin, ẹ gbéra,

kí kẹ̀kẹ́ ogun máa sáré kíkankíkan!

Kí àwọn ọmọ ogun máa nìṣó,

àwọn ọmọ ogun Etiopia ati Puti, tí wọ́n mọ asà á lò,

àwọn ọmọ ogun Ludi, tí wọ́n mọ ọfà á ta dáradára.’ ”

10 Ọjọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ọjọ́ náà,

ọjọ́ ẹ̀san, tí yóo gbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Idà rẹ̀ yóo pa àpatẹ́rùn, yóo sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó.

Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní ń rúbọ,

ní ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate.

11 Gòkè lọ sí Gileadi, kí o lọ wá ìwọ̀ra, ẹ̀yin ará Ijipti,

asán ni gbogbo òògùn tí ẹ lò,

ẹ kò ní rí ìwòsàn.

12 Àwọn orílẹ̀ èdè ti gbọ́ nípa ìtìjú yín,

igbe yín ti gba ayé kan;

nítorí àwọn ọmọ ogun ń rọ́ lu ara wọn;

gbogbo wọn sì ṣubú papọ̀.

Bíbọ̀ Nebukadinesari

13 Ohun tí OLUWA sọ fún wolii Jeremaya nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni nígbà tí ó ń bọ̀ wá ṣẹgun ilẹ̀ Ijipti nìyí:

14 Ó ní, “Ẹ kéde ní Ijipti,

ẹ polongo ní Migidoli, ní Memfisi ati ní Tapanhesi.

Ẹ wí pé, ‘Ẹ gbáradì kí ẹ sì múra sílẹ̀,

nítorí ogun yóo run yín yíká.

15 Kí ló dé tí àwọn akọni yín kò lè dúró?

Wọn kò lè dúró nítorí pé

OLUWA ni ó bì wọ́n ṣubú.’

16 Ogunlọ́gọ̀ yín ti fẹsẹ̀ kọ, wọ́n sì ṣubú,

wọ́n wá ń wí fún ara wọn pé,

‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa,

ati sí ilẹ̀ tí wọn gbé bí wa,

nítorí ogun àwọn aninilára.’

17 “Ẹ pa orúkọ Farao, ọba Ijipti dà,

ẹ pè é ní, ‘Aláriwo tí máa ń fi anfaani rẹ̀ ṣòfò.’

18 Ọba, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,

fi ara rẹ̀ búra pé, bí òkè Tabori ti rí láàrin àwọn òkè,

ati bí òkè Kamẹli létí òkun,

bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan tí yóo yọ si yín yóo rí.

19 Ẹ di ẹrù yín láti lọ sí ìgbèkùn, ẹ̀yin ará Ijipti!

Nítorí pé Memfisi yóo di òkítì àlàpà,

yóo di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo máa gbé ibẹ̀.

20 Ijipti dàbí ọmọ mààlúù tí ó lẹ́wà,

ṣugbọn irù kan, tí ó ti ìhà àríwá fò wá, ti bà lé e.

21 Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀,

dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀;

àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ,

wọn kò lè dúró;

nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn,

ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé.

22 Ó ń dún bí ejò tí ó ń sálọ;

nítorí pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń bọ̀ tagbára tagbára,

wọ́n ń kó àáké bọ̀ wá bá a,

bí àwọn tí wọn ń gé igi.

23 Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí,

nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà.

24 A óo dójú ti àwọn ará Ijipti,

a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

25 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

26 N óo fà wọ́n lé àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́; n óo fà wọ́n fún Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan yóo máa gbé Ijipti bíi ti àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

OLUWA Yóo Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là

27 “Ṣugbọn ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,

ọmọ Israẹli, ẹ má fòyà;

n óo gbà yín là láti ọ̀nà jíjìn,

n óo kó arọmọdọmọ yín yọ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.

Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ óo pada máa gbé ní ìrọ̀rùn.

Kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rù bà yín.

28 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,

nítorí pé mo wà pẹlu yín.

N óo run gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo le yín lọ,

ṣugbọn n kò ní pa yín run.

Bí ó bá tọ́ kí n jẹ yín níyà, n óo jẹ yín níyà,

kìí ṣe pé n óo fi yín sílẹ̀ láìjẹ yín níyà.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 47

Iṣẹ́ tí OLUWA Rán sí Àwọn Ará Filistia

1 OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa,

2 Ó ní,

“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,

yóo di àgbàrá tí ó lágbára;

yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,

yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.

Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

3 Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún,

tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré,

tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo,

Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n,

nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ;

4 nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia,

ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni.

Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run,

àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori.

5 Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun.

Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

6 Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA,

yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi?

Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’

7 Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe?

OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 48

Ìparun Moabu

1 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Moabu pé,

“Nebo gbé nítorí yóo di ahoro!

Ojú yóo ti Kiriataimu nítorí ogun óo kó o;

ìtìjú yóo bá ibi ààbò rẹ̀, wọn óo wó o lulẹ̀;

2 ògo Moabu ti dópin!

Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni,

wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’

Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu;

ogun yóo máa le yín kiri.

3 Gbọ́ igbe kan ní Horonaimu,

igbe ìsọdahoro ati ìparun ńlá!

4 “Moabu ti parun; a gbọ́ igbe àwọn ọmọ rẹ̀.

5 Bí wọn tí ń gun òkè Luhiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọkún,

nítorí pé nígbà tí wọn tí ń lọ níbi ẹsẹ̀ òkè Horonaimu,

ni wọ́n tí ń gbọ́ igbe ìparun; pé,

6 ‘Ẹ sá! Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín!

Ẹ sáré bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aṣálẹ̀!’

7 “Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ.

Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀.

8 Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú,

ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀;

àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9 Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ;

àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.”

10 (Ègún ń bẹ lórí ẹni tí ó bá ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ OLUWA;

ègún sì ń bẹ lórí ẹni tí ó bá sì kọ̀, tí kò máa fi idà rẹ̀ pa eniyan.)

A pa Àwọn Ìlú Moabu Run

11 OLUWA ní,

“Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn,

kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí.

Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí.

A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn.

Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada.

12 “Nítorí náà, àkókò ń bọ̀,

tí n óo jẹ́ kí wọn da Moabu nù, bí ẹni da ọtí nù.

Àwọn tí wọn ń da ọtí nù ni n óo rán, tí wọn óo wá tẹ̀ ẹ́ bí ìgò ọtí

wọn óo dà á nù patapata, wọn óo sì fọ́ ìgò rẹ̀.

13 Kemoṣi yóo di ohun ìtìjú fún Moabu,

gẹ́gẹ́ bí Bẹtẹli, tí Israẹli gbójú lé, ṣe di ohun ìtìjú fún Israẹli.

14 Ẹ ṣe lè wí pé alágbára ni yín, ati pé ẹ jẹ́ akikanju lójú ogun?

15 Ẹni tí yóo pa ilẹ̀ Moabu ati àwọn ìlú rẹ̀ run ti dé,

àwọn àṣàyàn ọmọkunrin rẹ̀ sì ti lọ sí ibi tí wọn ó ti pa wọ́n.

Èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

16 Ọjọ́ ìdààmú Moabu fẹ́rẹ̀ dé, ìpọ́njú rẹ̀ sì ń bọ̀ kánkán.

17 “Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ dárò rẹ̀,

kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ orúkọ rẹ̀ sì wí pé,

‘Ọ̀pá àṣẹ tí ó lágbára ti kán,

ọ̀pá àṣẹ tí ó lógo ti ṣẹ́.’

18 Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni!

Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́,

ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀.

19 Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o máa ṣọ́nà, ìwọ tí ò ń gbé Aroeri!

Bèèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n sálọ; bi àwọn tí ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’

20 Ìtìjú ti bá Moabu, nítorí pé ó ti wó lulẹ̀; ẹ kígbe, ẹ máa sọkún.

Ẹ kéde rẹ̀ ní ipadò Anoni, pé,

‘Moabu ti parẹ́, ó ti di òkítì àlàpà.’

21 “Ìdájọ́ ti dé sórí àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú: Holoni, Jahisai, ati Mefaati;

22 Diboni, Nebo, ati Beti Dibilataimu,

23 Kiriataimu, Betigamuli, ati Betimeoni,

24 Kerioti, Bosira, ati gbogbo àwọn ìlú ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lókèèrè.

25 Ipá Moabu ti pin, a sì ti ṣẹ́ ẹ lápá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

A Óo Rẹ Moabu sílẹ̀

26 OLUWA ní,

“Ẹ rọ Moabu lọ́tí yó,

nítorí pé ó gbéraga sí OLUWA;

kí ó lè máa yíràá ninu èébì rẹ̀,

a óo sì fi òun náà ṣẹ̀sín.

27 Moabu, ṣebí ò ń fi Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́?

Ṣé o bá a láàrin àwọn ọlọ́ṣà ni,

tí ó fi jẹ́ pé nígbàkúùgbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ń ṣe ni o máa ń mi orí rẹ?

28 “Ẹ fi ààrin ìlú sílẹ̀, kí ẹ lọ máa gbé inú àpáta, ẹ̀yin ará Moabu!

Ẹ ṣe bí àdàbà, tí ó kọ́lé rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ẹnu ihò àpáta.

29 A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,

ó ní ìgbéraga lọpọlọpọ,

a ti gbọ́ nípa èrò gíga rẹ̀, ati ìgbéraga rẹ̀,

nípa àfojúdi rẹ̀, ati nípa ìwà ìjọra-ẹni-lójú rẹ̀.

30 Mo mọ̀ pé aláfojúdi ni.

Ó ń fọ́nnu lásán ni, kò lè ṣe nǹkankan tó yanjú.

31 Nítorí náà, ni mo ṣe ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, tí mò ń kígbe sókè nítorí Moabu

tí mo sì ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ará Kiri Heresi.

32 Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima,

ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ!

Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri,

apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ.

33 Wọ́n ti mú ayọ̀ ati ìdùnnú kúrò ní ilẹ̀ ọlọ́ràá Moabu;

mo ti mú kí ọtí waini tán níbi tí wọ́n ti ń ṣe é,

kò sí ẹni tí ó ń ṣe ọtí waini pẹlu ariwo ayọ̀ mọ́, ariwo tí wọn ń pa kì í ṣe ti ayọ̀.

34 “Heṣiboni ati Eleale kígbe sókè, igbe wọn sì dé Jahasi láti Soari, ó dé Horonaimu ati Egilati Ṣeliṣiya. Àwọn odò Nimrimu pàápàá ti gbẹ.

35 N óo pa àwọn tí ń rú ẹbọ níbi pẹpẹ ìrúbọ run, ati àwọn tí ń sun turari sí oriṣa ní ilẹ̀ Moabu.

36 “Nítorí náà ni mo ṣe ń dárò Moabu ati àwọn ará Kiri Heresi bí ẹni fi fèrè kọ orin arò nítorí pé gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n kó jọ ti ṣègbé.

37 Gbogbo wọn ti fá irun orí ati irùngbọ̀n wọn; wọ́n ti fi abẹ ya gbogbo ọwọ́ wọn, wọ́n sì lọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìbàdí.

38 Gbogbo eniyan ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ní gbogbo orí ilé Moabu, ati àwọn ìta gbangba rẹ̀. Nítorí pé mo ti fọ́ Moabu, bíi ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

39 A ti fọ́ Moabu túútúú! Ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn! Moabu pẹ̀yìndà pẹlu ìtìjú! Moabu wá di ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká.”

Moabu Kò ní Lè Sá Àsálà

40 OLUWA ní,

“Wò ó, ẹnìkan yóo fò wá bí ẹyẹ idì,

yóo sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ lé Moabu lórí.

41 Ogun yóo kó àwọn ìlú Moabu,

wọn óo sì gba àwọn ibi ààbò rẹ̀.

Ní ọjọ́ náà, ọkàn àwọn ọmọ ogun Moabu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ó ń rọbí,

42 Moabu yóo parun, kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,

nítorí pé ó ṣe ìgbéraga sí OLÚWA.

43 Ẹ̀yin ará Moabu,

ìpayà, ọ̀gbun ati tàkúté ń bẹ níwájú yín!

44 Ẹni tí ó ń sálọ nítorí ìpayà,

yóo jìn sinu ọ̀gbun,

ẹni tí ó bá sì jáde ninu ọ̀gbun

yóo kó sinu tàkúté.

N óo mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá Moabu

nígbà tí àkókò ìjìyà rẹ̀ bá tó.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

45 Àwọn tí wọn ń sá fún ogun dúró ní ibi ààbò Heṣiboni,

wọn kò lágbára mọ́,

nítorí iná ṣẹ́ jáde láti Heṣiboni

ahọ́n iná sì yọ láàrin ilé Sihoni ọba;

iná ti jó Moabu tíí ṣe adé àwọn ọmọ onídàrúdàpọ̀ ní àjórun,

46 Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé!

Ó ti parí fun yín, ẹ̀yin ọmọ Kemoṣi,

nítorí a ti kó àwọn ọmọkunrin yín lẹ́rú,

a ti kó àwọn ọmọbinrin yín lọ sí ìgbèkùn.

47 “Sibẹsibẹ n óo dá ire Moabu pada lẹ́yìn ọ̀la,

èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún Moabu.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 49

Ìdájọ́ OLUWA Lórí Amoni

1 Ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ará Amoni nìyí: Ó ní,

“Ṣé Israẹli kò lọ́mọ ni?

Tabi kò ní àrólé?

Kí ló dé tí àwọn tí ń bọ Milikomu ṣe gba ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi,

tí wọ́n sì fi àwọn ìlú Gadi ṣe ibùjókòó?

2 Nítorí náà, wò ó, àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ kí ariwo ogun sọ, ní Raba ìlú àwọn ọmọ Amoni;

Raba yóo di òkítì àlàpà,

a óo sì dáná sun àwọn ìgbèríko rẹ̀;

Israẹli yóo wá pada fi ogun kó àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú.

3 Sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ìwọ Heṣiboni,

nítorí pé ìlú Ai ti parun!

Ẹ sọkún, ẹ̀yin ọmọbinrin Raba!

Ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀,

ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa sá sókè sódò láàrin ọgbà!

Nítorí pé oriṣa Moleki yóo lọ sí ìgbèkùn,

pẹlu àwọn babalóòṣà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ní ibi ìsìn rẹ̀.

4 Kí ló dé tí ò ń fọ́nnu nípa agbára rẹ,

ipá rẹ ti pin, ìwọ olóríkunkun ọmọbinrin

ìwọ tí o gbójú lé ọrọ̀ rẹ,

tí ò ń wí pé, ‘Ta ló lè dojú kọ mí?’

5 Wò ó! N óo kó ìpayà bá ọ,

láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n yí ọ ká;

èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Gbogbo yín ni yóo fọ́nká,

tí olukuluku yóo sì yà sí ọ̀nà tirẹ̀,

kò sì ní sí ẹni tí yóo kó àwọn tí ń sá fún ogun jọ.

6 “Ṣugbọn lẹ́yìn náà, n óo dá ire àwọn ará Amoni pada.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Edomu

7 Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa Edomu nìyí:Ó ní,

“Ṣé kò sí ọgbọ́n ní Temani mọ́ ni?

Àbí àwọn amòye kò ní ìmọ̀ràn lẹ́nu mọ́?

Ṣé ọgbọ́n ti rá mọ́ wọn ninu ni?

8 Ẹ̀yin ará Dedani, ẹ pada kíá, ẹ máa sálọ.

Ẹ wọ inú ihò lọ, kí ẹ lọ máa gbébẹ̀!

Nítorí pé ní ìgbà tí mo bá jẹ ìran Esau níyà, n óo mú kí ibi dé bá wọn.

9 Bí àwọn tí ń kórè èso àjàrà bá bẹ̀rẹ̀ sí kórè,

ṣebí wọn a máa fi èso díẹ̀ díẹ̀ sílẹ̀?

Bí àwọn olè bá wọlé lóru,

ṣebí ìba ohun tí ó bá wù wọ́n ni wọn yóo kó?

10 Ṣugbọn mo ti tú àwọn ọmọ Esau sí ìhòòhò,

Mo ti sọ ibi tí wọn ń sápamọ́ sí di gbangba,

wọn kò sì rí ibi sápamọ́ sí mọ́.

Àwọn ọmọ wọn ti parun,

pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn aládùúgbò wọn;

àwọn pàápàá sì ti di àwátì.

11 Fi àwọn ọmọ rẹ, aláìníbaba sílẹ̀,

n óo pa wọ́n mọ́ láàyè,

sì jẹ́ kí àwọn opó rẹ gbẹ́kẹ̀lé mi.

12 “Bí àwọn tí kò yẹ kí wọ́n jìyà bá jìyà, ṣé ìwọ wá lè lọ láìjìyà? O kò ní lọ láìjìyà, dájúdájú ìyà óo jẹ ọ́.

13 Nítorí pé mo ti fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, pé Bosira yóo di àríbẹ̀rù ati ohun ẹ̀gàn, ahoro ati ohun àmúgégùn-ún; àwọn ìlú rẹ̀ yóo sì di ahoro títí lae.”

14 Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,

wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè,

wọ́n ní kí wọn kéde pé,

“OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu,

ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í!

15 Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeré

láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,

o óo sì di yẹpẹrẹ,

láàrin àwọn ọmọ eniyan.

16 Ẹ̀rù tí ó wà lára rẹ, ati ìgbéraga ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,

ìwọ tí ò ń gbé pàlàpálá àpáta,

tí o fi góńgó orí òkè ṣe ibùgbé.

Bí o tilẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga, bíi ti ẹyẹ idì,

n óo fà ọ́ lulẹ̀ láti ibẹ̀.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

17 OLUWA ní, “Edomu yóo sì di ibi àríbẹ̀rù, ẹ̀rù yóo máa ba gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba ibẹ̀ kọjá, wọn yóo máa pòṣé nítorí ibi tí ó dé bá a.

18 Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

19 Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?

20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn.

21 Ariwo wíwó odi Edomu wọn yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ títí dé etí òkun pupa.

22 Wò ó! Ẹnìkan yóo fò bí ẹyẹ idì, yóo na ìyẹ́ rẹ̀ sórí Bosira, ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ọmọ ogun Edomu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ń rọbí.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Damasku

23 Ohun tí OLUWA sọ nípa Damasku nìyí, Ó ní,

“Ìdààmú dé bá Hamati ati Aripadi,

nítorí pé wọ́n gbọ́ ìròyìn burúkú:

Jìnnìjìnnì dà bò wọ́n, ọkàn wọn sì dàrú,

bí omi òkun tí kò lè dákẹ́ jẹ́ẹ́.

24 Àárẹ̀ mú Damasku,

ó pẹ̀yìndà pé kí ó máa sálọ,

ṣugbọn ìpayà mú un,

ìrora ati ìbànújẹ́ sì dé bá a, bí obinrin tí ń rọbí.

25 Ẹ wò ó bí ìlú olókìkí tí ó kún fún ayọ̀, ṣe di ibi ìkọ̀sílẹ̀!

26 Àwọn ọdọmọkunrin Damasku yóo ṣubú ní gbàgede rẹ̀ ní ọjọ́ náà,

gbogbo àwọn ọmọ ogun ibẹ̀ yóo sì parun ni;

Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27 N óo dáná sun odi Damasku,

yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Ẹ̀yà Kedari ati ìlú Hasori

28 OLUWA sọ nípa Kedari ati àwọn ìjọba Hasori tí Nebukadinesari ọba Babiloni ṣẹgun pé,

“Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti Kedari!

Ẹ pa àwọn ará ìlà oòrùn run!

29 Ogun yóo kó àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ,

ati àwọn aṣọ àgọ́, ati ohun ìní wọn;

Ọ̀tá yóo kó ràkúnmí wọn lọ,

àwọn eniyan yóo máa kígbe sí wọn pé,

‘Ìpayà wà ní gbogbo àyíká.’

30 “Ẹ̀yin ará Hasori, ẹ sá,

ẹ lọ jìnnà réré, kí ẹ sì máa gbé inú ọ̀gbun.

Nítorí pé Nebukadinesari, ọba Babiloni ń pète ibi si yín,

ó ti pinnu ibi si yín.

31 Ó ní, ‘Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní alaafia, ati láìléwu,

ìlú tí ó dá dúró tí kò sì ní ìlẹ̀kùn tabi ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn fún ààbò.’

32 “Àwọn ràkúnmí ati agbo ẹran wọn yóo di ìkógun.

N óo fọ́n àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn ká sí igun mẹrẹẹrin ayé,

n óo sì mú kí ibi bá wọn láti gbogbo àyíká wọn.

33 Hasori yóo di ibùgbé ajáko,

yóo di ahoro títí laelae.

Ẹnìkan kò ní gbé ibẹ̀ mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ mọ́.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Elamu

34 OLUWA àwọn ọmọ ogun bá Jeremaya wolii sọ nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda.

35 Ó ní, “Wò ó! N óo pa àwọn tafàtafà Elamu, tí wọn jẹ́ orísun agbára wọn,

36 n óo mú kí ẹ̀fúùfù mẹrin láti igun mẹrẹẹrin ojú ọ̀run kọlu Elamu; n óo sì fọ́n wọn ká sinu ẹ̀fúùfù náà, kò sì ní sí orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ará Elamu kò ní fọ́n ká dé.

37 N óo dẹ́rùbà wọ́n; níwájú àwọn ọ̀tá wọn, ati níwájú àwọn tí ń wá ọ̀nà ati pa wọ́n. N óo bínú sí wọn gan-an, n óo sì mú kí ibi dé bá wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rán ogun tẹ̀lé wọn, títí n óo fi pa wọ́n tán.

38 N óo tẹ́ ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè wọn.

39 Ṣugbọn nígbẹ̀yìn, n óo dá ire Elamu pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”