Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 30

Ìlérí OLUWA fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

1 OLUWA Ọlọrun Israẹli bá Jeremaya sọ̀rọ̀:

2 Ó ní, “Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún ọ sinu ìwé,

3 nítorí pé àkókò ń bọ̀ tí n óo dá ire àwọn eniyan mi, Israẹli ati Juda pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo mú wọn pada wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì di ohun ìní wọn.”

4 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa Israẹli ati Juda nìyí:

5 “A ti gbọ́ igbe ìdágìrì ati ti ẹ̀rù,

kò sì sí alaafia.

6 Ẹ bèèrè, kí ẹ sì ṣe ìwádìí;

ǹjẹ́ ọkunrin lè lóyún kí ó sì bímọ?

Kí ló wá dé tí mo rí gbogbo ọkunrin,

tí wọn ń dáwọ́ tẹ ìbàdí bí obinrin tí ń rọbí?

Kí ló dé tí gbogbo yín fajúro?

7 Ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà yóo jẹ́,

kò sí ọjọ́ tí yóo dàbí rẹ̀,

àkókò ìpọ́njú ni yóo jẹ́ fún ilé Jakọbu;

ṣugbọn wọn yóo bọ́ ninu rẹ̀.”

8 OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá,

n óo já àjàgà kúrò lọ́rùn wọn.

N óo já ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi so wọ́n,

wọn kò sì ní ṣe iranṣẹ fún àjèjì mọ́.

9 Ṣugbọn wọn yóo máa sin Ọlọrun wọn,

ati ti Dafidi, ọba wọn, tí n óo gbé dìde fún wọn.

10 “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin eniyan Jakọbu, iranṣẹ mi,

ẹ má sì jẹ́ kí àyà fò yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

N óo ti òkèèrè wá gbà yín là,

N óo gba àwọn ọmọ yín tí wọ́n wà ní ìgbèkùn là pẹlu.

Àwọn ọmọ Jakọbu yóo pada ní ìfọ̀kànbalẹ̀ ati ìrọ̀rùn,

ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.

11 Nítorí pé mo wà pẹlu yín, n óo gbà yín là.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n óo pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,

gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo fọn yín ká sí ni n óo parun patapata,

ṣugbọn n kò ní pa ẹ̀yin run.

N óo jẹ yín níyà,

ṣugbọn n kò ní fi ìyà tí kò tọ́ jẹ yín.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

12 “Egbò yín kò lè san mọ́,

ọgbẹ́ yín sì jinlẹ̀.

13 Kò sí ẹni tí yóo gba ẹjọ́ yín rò,

kò ní sí òògùn fún ọgbẹ́ yín,

kò ní sí ìwòsàn fun yín.

14 Gbogbo àwọn olólùfẹ́ yín ti gbàgbé yín;

wọn kò bìkítà nípa yín mọ́,

nítorí mo ti nà yín bí ọ̀tá mi,

mo sì fi ìyà jẹ yín bí ọ̀tá tí kò láàánú,

nítorí àṣìṣe yín pọ̀,

nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà.

15 Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún,

nítorí ìnira yín tí kò lóògùn?

Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà

ni mo ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi dé ba yín.

16 Ṣugbọn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ yín run, ni a óo pada jẹ run.

Gbogbo àwọn ọ̀tá yín patapata, ni yóo lọ sí ìgbèkùn.

Gbogbo àwọn tí wọ́n fogun kó yín ni ogun yóo kó.

N óo fi ẹrù àwọn tí wọn ń jà yín lólè fún àwọn akónilẹ́rù.

17 N óo fun yín ní ìlera,

n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn,

èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù,

Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ”

18 OLUWA ní,

“Mo ṣetán láti dá ire ilé Jakọbu pada,

n óo fi ojurere wo ibùgbé rẹ̀.

A óo tún ìlú náà kọ́ sórí òkítì rẹ̀,

a óo sì tún kọ́ ààfin rẹ̀ sí ààyè rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

19 Orin ọpẹ́ yóo máa ti ibẹ̀ jáde wá,

a óo sì máa gbọ́ ohùn àwọn tí ń ṣe àríyá pẹlu.

N óo bukun wọn, wọn óo di pupọ,

n óo sọ wọ́n di ẹni iyì, wọn kò sì ní jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ.

20 Àwọn ọmọ wọn yóo rí bí wọn ti rí ní àtijọ́,

àwọn ìjọ wọn yóo fi ìdí múlẹ̀ níwájú mi.

N óo sì fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn ń ni wọ́n lára.

21 Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn,

ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn;

n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi,

nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22 Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì jẹ́ Ọlọrun yín.”

23 Ẹ wo ìjì OLUWA!

Ibinu rẹ̀ ń bọ̀ bí ìjì líle.

Ó ń bọ̀ sórí àwọn oníṣẹ́ ibi.

24 Ibinu gbígbóná OLUWA kò ní yipada,

títí yóo fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.

Òye nǹkan wọnyi yóo ye yín ní ọjọ́ ìkẹyìn.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 31

Israẹli Pada sílé

1 OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli,

tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.

2 Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀;

nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi,

3 OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè.

Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ,

nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.

4 N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú.

5 Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria;

àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀.

6 Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé,

‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni,

sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ”

7 OLUWA ní,

“Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu,

kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè,

ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé,

‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ là

àní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’

8 Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá,

n óo kó wọn jọ láti òpin ayé.

Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn,

ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́.

Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí.

9 Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá,

tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada.

N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn,

lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ;

nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.”

10 OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré;

ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ,

yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’

11 Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada,

yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ.

12 Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni,

wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn:

Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró,

ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù;

ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́.

13 Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà,

àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá.

N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,

n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn.

14 N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ,

n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àánú OLUWA lórí Israẹli

15 OLUWA ní,

“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,

ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni.

Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀,

wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà,

nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́.

16 Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù,

nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn.

17 Ìrètí ń bẹ fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,

àwọn ọmọ rẹ yóo pada sí orílẹ̀-èdè wọn.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

18 “Mo gbọ́ bí Efuraimu tí ń kẹ́dùn,

ó ní: ‘O ti bá mi wí, ìbáwí sì dùn mí,

bí ọmọ mààlúù tí a kò kọ́.

Mú mi pada, kí n lè pada sí ààyè mi,

nítorí pé ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun mi.

19 Nítorí pé lẹ́yìn tí mo ṣáko lọ, mo ronupiwada;

lẹ́yìn tí o kọ́ mi lọ́gbọ́n, ń ṣe ni mo káwọ́ lérí.

Ojú tì mí, ìdààmú sì bá mi,

nítorí ìtìjú ohun tí mo ṣe nígbà èwe mi dé bá mi.’

20 “Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni?

Ṣé ọmọ mi àtàtà ni?

Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀,

nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí;

dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀.

21 Ẹ ri òpó mọ́lẹ̀ lọ fún ara yín,

ẹ sàmì sí àwọn ojú ọ̀nà.

Ẹ wo òpópónà dáradára, ẹ fiyèsí ọ̀nà tí ẹ gbà lọ.

Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ Israẹli,

ẹ pada sí àwọn ìlú yín wọnyi.

22 Ìgbà wo ni ẹ óo ṣe iyèméjì dà, ẹ̀yin alainigbagbọ wọnyi?

Nítorí OLUWA ti dá ohun titun sórí ilẹ̀ ayé,

bíi kí obinrin máa dáàbò bo ọkunrin.”

Ọjọ́ Iwájú Àwọn Eniyan Ọlọrun Yóo Dára

23 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóo tún máa lo gbolohun yìí ní ilẹ̀ Juda ati ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, wọn óo máa wí pé,

‘OLUWA yóo bukun ọ, ìwọ òkè mímọ́ Jerusalẹmu,

ibùgbé olódodo.’

24 Àwọn eniyan yóo máa gbé àwọn ìlú Juda ati àwọn agbègbè rẹ̀ pẹlu àwọn àgbẹ̀ ati àwọn darandaran.

25 Nítorí pé n óo fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní agbára; n óo sì tu gbogbo ọkàn tí ń kérora lára.”

26 Lẹ́sẹ̀ kan náà mo tají, mo wò yíká, oorun tí mo sùn sì dùn mọ́ mi.

27 OLUWA ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo kó àtènìyàn, àtẹranko kún ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Juda.

28 Nígbà tí àkókò bá tó, gẹ́gẹ́ bí mo tí ń ṣọ́ wọn tí mo fi fà wọ́n tu, tí mo wó wọn lulẹ̀, tí mo bì wọ́n wó, tí mo pa wọ́n run, tí mo sì mú kí ibi ó bá wọn; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣọ́ wọn tí n óo fi kọ́ àwọn ìlú wọn tí n óo sì fìdí wọn múlẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

29 Tó bá dìgbà náà, àwọn eniyan kò ní máa wí mọ́ pé,

‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà kíkan,

àwọn ọmọ wọn ni eyín kan.’

30 Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó bá jẹ èso àjàrà kíkan,

òun ni eyín yóo kan.

Olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.

31 “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ń óo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun.

32 Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn.

33 Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi.

34 Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

35 OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán,

tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́,

tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya,

òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

36 Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun,

ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae.

37 Àfi bí eniyan bá lè wọn ojú ọ̀run,

tí ó sì lè wádìí ìpìlẹ̀ ayé,

ni òun lè ké àwọn ọmọ Israẹli kúrò,

nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe.

38 OLUWA ni, “Ẹ wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí a óo tún Jerusalẹmu kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli títí dé Bodè Igun.

39 A óo ta okùn ìwọ̀n odi ìlú títí dé òkè Garebu, ati títí dé Goa pẹlu.

40 Gbogbo àfonífojì tí wọn ń da òkú ati eérú sí, ati gbogbo pápá títí dé odò Kidironi, dé ìkangun Bodè Ẹṣin, ní ìhà ìlà oòrùn, ni yóo jẹ́ ibi mímọ́ fún OLUWA. Wọn kò ní fọ́ ọ mọ́, ẹnìkan kò sì ní wó o lulẹ̀ títí laelae.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 32

Jeremaya Ra Ilẹ̀

1 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹwaa tí Sedekaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kejidinlogun tí Nebukadinesari jọba.

2 Àwọn ọmọ ogun Babiloni dó ti Jerusalẹmu ní àkókò yìí, Jeremaya wolii sì wà ní ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sọ ọ́ sí, ní àgbàlá ààfin ọba Juda.

3 Sedekaya ọba Juda ni ó sọ Jeremaya sẹ́wọ̀n, ó ní, kí ló dé tí Jeremaya fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé OLUWA ní òun óo fi Jerusalẹmu lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á;

4 ati pé Sedekaya ọba Juda kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea. Ó ní Jeremaya sọ pé dájúdájú, OLUWA óo fi òun Sedekaya lé ọba Babiloni lọ́wọ́, àwọn yóo rí ara àwọn lojukooju, àwọn yóo sì bá ara àwọn sọ̀rọ̀.

5 Yóo mú òun Sedekaya lọ sí Babiloni, ibẹ̀ ni òun óo sì wà títí OLUWA yóo fi ṣe ẹ̀tọ́ fún òun. Ó ní bí àwọn tilẹ̀ bá àwọn ará Kalidea jagun, àwọn kò ní borí.

6 Jeremaya ní, “OLUWA sọ fún mi pé,

7 ‘Hanameli ọmọ Ṣalumu, arakunrin baba rẹ, yóo wá bá ọ pé kí o ra oko òun tí ó wà ní Anatoti, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada.’

8 Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’

“Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni.

9 Mo bá ra oko náà lọ́wọ́ Hanameli ọmọ arakunrin baba mi, mo sì wọn fadaka ṣekeli mẹtadinlogun fún un.

10 Mo kọ ọ́ sinu ìwé, mo fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́, mo pe àwọn eniyan láti ṣe ẹlẹ́rìí; mo sì fi òṣùnwọ̀n wọn fadaka náà.

11 Mo mú ìwé ilẹ̀ náà tí a ti fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ati ẹ̀dà rẹ̀,

12 mo sì fún Baruku ọmọ Neraya ọmọ Mahiseaya ní èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, níṣojú Hanameli, ọmọ arakunrin baba mi ati níṣojú àwọn ẹlẹ́rìí tí wọn fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ náà, ati níṣojú gbogbo àwọn ará Juda tí wọn jókòó ní àgbàlá àwọn olùṣọ́ náà.

13 Mo pàṣẹ fún Baruku níṣojú wọn pé,

14 ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o mú ìwé ilẹ̀ yìí, ati èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀ tí a sì ká, ati ẹ̀dà rẹ̀, kí o fi wọ́n sinu ìkòkò amọ̀ kí wọ́n lè wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́.

15 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé: wọn yóo tún máa ra ilẹ̀ ati oko ati ọgbà àjàrà ní ilẹ̀ yìí.’

Adura Jeremaya

16 “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé ilẹ̀ náà lé Baruku ọmọ Neraya lọ́wọ́, mo gbadura sí OLUWA, mo ní:

17 ‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ,

18 ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,

19 ìwọ Olùdámọ̀ràn ńlá, tí ó lágbára ní ìṣe; ìwọ tí ojú rẹ ń rí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ eniyan, tí o sì ń san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;

20 ìwọ tí o ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ijipti, o sì tún ń ṣe iṣẹ́ náà títí di òní ní Israẹli ati láàrin gbogbo eniyan; o sì ti fìdí orúkọ rẹ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.

21 Ìwọ ni o kó àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ, jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu, pẹlu ọwọ́ agbára, ipá ati ìbẹ̀rù ńlá.

22 O sì fún wọn ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí o búra fún àwọn baba ńlá wọn pé o óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.

23 Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn!

24 “ ‘Wo bí àwọn ọ̀tá ti mọ òkítì sí ara odi wa láti gba ìlú wa. Nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, a óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì í lọ́wọ́. Ohun tí o wí ṣẹ, o sì ti rí i.

25 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, sibẹsibẹ, ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o sọ fún mi pé kí n ra ilẹ̀, kí n sì ní àwọn ẹlẹ́rìí.’ ”

26 OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

27 “Wò ó! Èmi ni OLUWA, Ọlọrun gbogbo eniyan, ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún mi láti ṣe?

28 Nítorí náà èmi OLUWA ni mo sọ pé, n óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea ati Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á.

29 Àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun ti ìlú yìí, yóo wọ inú rẹ̀, wọn yóo sì dáná sun ún pẹlu àwọn ilẹ̀ tí wọ́n tí ń sun turari sí oriṣa Baali lórí wọn, tí wọ́n sì tí ń rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa tí wọn ń mú mi bínú.

30 Nítorí láti ìgbà èwe àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn eniyan Juda ni wọ́n tí ń ṣe kìkì nǹkan tí ó burú lójú mi, kìkì nǹkan tí yóo bí mi ninu ni àwọn ọmọ Israẹli náà sì ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31 Láti ọjọ́ tí wọn ti tẹ ìlú yìí dó títí di òní, ni àwọn ará ilẹ̀ yìí tí ń mú mi bínú, tí wọn sì ń mú kí inú mi ó máa ru, kí n lè pa wọ́n rẹ́ kúrò níwájú mi,

32 nítorí gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará ilẹ̀ Juda ṣe láti mú mi bínú, àtàwọn ọba wọn, àtàwọn ìjòyè wọn, àtàwọn alufaa wọn, àtàwọn wolii wọn; àtàwọn ará Juda àtàwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

33 Wọ́n ti yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, wọ́n sì kẹ̀yìn sí mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ wọn ni àkọ́túnkọ́, wọn kò gba ẹ̀kọ́.

34 Wọ́n gbé àwọn ère wọn, tí ó jẹ́ ohun ìríra fun mi sinu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, kí wọ́n lè sọ ọ́ di ibi àìmọ́.

35 Wọ́n kọ́ ojúbọ oriṣa tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hinomu láti máa fi àwọn ọmọ wọn, lọkunrin ati lobinrin rú ẹbọ sí oriṣa Moleki, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò pa á láṣẹ fún wọn, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn pé wọ́n lè ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀, láti mú Juda dẹ́ṣẹ̀.”

Ìlérí Ìrètí

36 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Ìlú tí àwọn eniyan ń sọ pé ọwọ́ ọba Babiloni ti tẹ̀, nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn,

37 n óo kó àwọn eniyan ibẹ̀ jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti fi ibinu, ìrúnú, ati ìkanra lé wọn lọ; n óo kó wọn pada sí ibí yìí, n óo sì mú kí wọn máa gbé ní àìléwu.

38 Wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, Èmi náà óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.

39 N óo fún wọn ní ọkàn ati ẹ̀mí kan, kí wọn lè máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, kí ó lè dára fún àwọn ati àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn.

40 N óo bá wọn dá majẹmu ayérayé, pé n kò ní dẹ́kun ati máa ṣe wọ́n lóore. N óo fi ẹ̀rù mi sí wọn lọ́kàn, kí wọn má baà yapa kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́.

41 Yóo máa jẹ́ ohun ayọ̀ fún mi láti ṣe wọ́n lóore, n óo fi tẹ̀mítẹ̀mí ati tọkàntọkàn fi ìdí wọn múlẹ̀ ninu jíjẹ́ olóòótọ́ ní ilẹ̀ yìí.

42 “Bí mo ṣe mú gbogbo ibi ńlá yìí bá àwọn eniyan wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe mú kí gbogbo ohun rere tí mo ti ṣe ìlérí fún wọn dé bá wọn.

43 Wọn yóo ra oko ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọ pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko ninu rẹ̀, tí ẹ̀ ń sọ pé a ti fi lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́.

44 Wọn yóo máa fi owó ra oko, wọn yóo máa ṣe ìwé ilẹ̀, wọn yóo máa fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́; wọn yóo máa fi èdìdì dì í, àwọn ẹlẹ́rìí yóo sì máa fi ọwọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rí ní ilẹ̀ Bẹnjamini. Nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, ati ní àwọn agbègbè Jerusalẹmu, ní àwọn ìlú Juda, ati àwọn ìlú agbègbè olókè, ní àwọn ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 33

Ìlérí Ìrètí Mìíràn

1 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹẹkeji, nígbà tí ó ṣì wà ní ẹ̀wọ̀n, ní àgbàlá àwọn tí ń ṣọ́ ààfin.

2 OLUWA tí ó dá ayé, tí ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni ó sọ pé:

3 “Ẹ ké pè mí, n óo sì da yín lóhùn; n óo sọ nǹkan ìjìnlẹ̀ ati ìyanu ńlá, tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fun yín.”

4 OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ilé tí wọ́n wà ní ìlú yìí, ati ilé ọba Juda, àwọn tí wọn dótì wá, tí wọn ń gbógun tì wá yóo wó wọn lulẹ̀

5 Ó ní, “Àwọn ará Kalidea ń gbógun bọ̀, wọn yóo da òkú àwọn eniyan tí n óo fi ibinu ati ìrúnú pa kún àwọn ilé tí ó wà ní ìlú yìí, nítorí mo ti fi ara pamọ́ fún ìlú yìí nítorí gbogbo ìwà burúkú wọn.

6 N óo mú ìlera ati ìwòsàn wá bá wọn; n óo wò wọ́n sàn, n óo sì fún wọn ní ọpọlọpọ ibukun ati ìfọ̀kànbalẹ̀.

7 N óo dá ire Juda ati ti Israẹli pada, n óo sì tún wọn kọ́, wọn yóo dàbí wọ́n ti rí lákọ̀ọ́kọ́.

8 N óo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi, n óo dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati oríkunkun tí wọ́n ṣe sí mi jì wọ́n.

9 Orúkọ ìlú yìí yóo sì jẹ́ orúkọ ayọ̀ fún mi, yóo jẹ́ ohun ìyìn ati ògo níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tí yóo gbọ́ nípa nǹkan rere tí n óo ṣe fún wọn; ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn yóo sì wárìrì, nítorí gbogbo nǹkan rere tí n óo máa ṣe fún ìlú náà.”

10 OLUWA ní, “A óo tún gbọ́ ohùn ayọ̀ ati inú dídùn ninu ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí ẹ sọ wí pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko tó ń gbé inú wọn.

11 A óo tún gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo ati ohùn àwọn tí wọn ń kọrin bí wọ́n ti ń mú ẹbọ ọpẹ́ wá sinu ilé OLUWA wí pé:107:1; 118:1; 136:1

‘Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun,

nítorí pé rere ni OLUWA,

nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae!’

Nítorí pé n óo dá ire wọn pada bíi ti ìgbà àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12 OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní gbogbo ibi tí ó ti di ahoro yìí, tí eniyan tabi ẹranko kò gbé ibẹ̀, àwọn olùṣọ́-aguntan yóo sì tún máa tọ́jú àwọn agbo ẹran wọn ninu gbogbo àwọn ìlú ibẹ̀.

13 Àwọn agbo ẹran yóo tún kọjá níwájú ẹni tí ó ń kà wọ́n ninu àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ati àwọn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela ati àwọn ìlú tí wọn wà ní Nẹgẹbu, ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ní agbègbè tí ó yí Jerusalẹmu ká, ati àwọn ìlú Juda. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

14 Ó ní, “Àkókò ń bọ̀, tí n óo mú ìlérí tí mo ṣe fún ilé Israẹli ati ilé Juda ṣẹ.

15 Nígbà tó bá yá, tí àkókò bá tó, n óo mú kí ẹ̀ka òdodo kan ó sọ jáde ní ilé Dafidi, yóo máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo ní ilẹ̀ náà.

16 A óo gba Juda là, Jerusalẹmu yóo sì wà ní àìléwu, orúkọ tí a óo wá máa pè é ni ‘OLÚWA ni Òdodo wa.’ ”

17 Nítorí OLUWA ní kò ní sí ìgbà kan, tí kò ní jẹ́ pé ọkunrin kan ní ilé Dafidi ni yóo máa jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli,

18 bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní sí ìgbà kan tí ẹnìkan ninu àwọn alufaa, ọmọ Lefi, kò ní máa dúró níwájú òun láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, láti máa rú ẹbọ títí lae.

19 OLUWA tún bá Jeremaya sọ̀rọ̀;

20 ó ní, “Bí ẹ bá lè ba majẹmu tí mo bá ọ̀sán ati òru dá jẹ́, tí wọn kò fi ní wà ní àkókò tí mo yàn fún wọn mọ́,

21 òun nìkan ni majẹmu tí mo bá Dafidi iranṣẹ mi dá ṣe lè yẹ̀, tí ìdílé rẹ̀ kò fi ní máa ní ọmọkunrin kan tí yóo jọba; bẹ́ẹ̀ náà ni majẹmu tí mo bá àwọn alufaa, ọmọ Lefi iranṣẹ mi dá.

22 Bí a kò ti ṣe lè ka iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí a kò sì lè wọn yanrìn etí òkun, bẹ́ẹ̀ ní n óo ṣe sọ arọmọdọmọ Dafidi ati arọmọdọmọ Lefi alufaa, iranṣẹ mi, di pupọ.”

23 OLUWA bi Jeremaya pé:

24 “Ṣé o kò gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi ń sọ tí wọn ní, ‘OLUWA ti kọ ìdílé mejeeji tí ó yàn sílẹ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń fojú tẹmbẹlu àwọn eniyan mi, títí tí wọn kò fi dàbí orílẹ̀-èdè lójú wọn mọ́.

25 Bí n kò bá tíì fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu ọ̀sán ati òru, tí n kò sì ṣe ìlànà fún ọ̀run ati ayé,

26 òun nìkan ni n óo fi kọ arọmọdọmọ Jakọbu ati Dafidi, iranṣẹ mi sílẹ̀, tí n kò fi ní máa yan ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ láti jọba lórí ìran Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu. N óo dá ire wọn pada, n óo sì ṣàánú fún wọn.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 34

Iṣẹ́ tí A Rán sí Sedekaya

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya sọ nìyí, nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati gbogbo ìjọba ayé tí wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀, ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbógun ti Jerusalẹmu ati gbogbo àwọn ìlú Juda.

2 OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, kí n lọ sọ fún Sedekaya, ọba Juda pé òun OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ìlú yìí lé ọba Babiloni lọ́wọ́; yóo sì dáná sun ún.

3 Sedekaya, o kò ní sá àsálà, ṣugbọn wọn óo mú ọ, wọn óo fà ọ́ lé Nebukadinesari lọ́wọ́, ẹ óo rí ara yín lojukooju, ẹ óo bá ara yín sọ̀rọ̀, o óo sì lọ sí Babiloni.

4 Sibẹsibẹ, ìwọ Sedekaya, ọba Juda OLUWA ní wọn kò ní fi idà pa ọ́.

5 O óo fi ọwọ́ rọrí kú ni. Bí wọn ti sun turari níbi òkú àwọn baba rẹ, ati níbi òkú àwọn ọba tí wọ́n ti kú ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo sun turari níbi òkú ìwọ náà. Wọn yóo dárò rẹ, wọn yóo máa wí pé, ‘Ó ṣe, oluwa mi,’ nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA ṣe ìlérí; èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

6 Jeremaya wolii bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún Sedekaya ọba Juda, ní Jerusalẹmu,

7 ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu ati Lakiṣi ati Aseka, nítorí pé àwọn nìkan ni wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn ìlú olódi Juda.

Wọ́n Rẹ́ Àwọn Ẹrú Jẹ

8 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Sedekaya ọba ti bá gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu dá majẹmu pé kí wọn kéde ìdásílẹ̀,

9 kí olukuluku dá ẹrú rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n jẹ́ Heberu sílẹ̀, kí wọn máa lọ ní òmìnira; kí ẹnikẹ́ni má sì fi Juu arakunrin rẹ̀ ṣe ẹrú mọ́.

10 Gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn ará ìlú tí wọ́n dá majẹmu yìí ni wọ́n gbọ́ràn, tí wọ́n sì dá àwọn ẹrú wọn lọkunrin ati lobinrin sílẹ̀; wọn kò sì fi wọ́n ṣe ẹrú mọ́.

11 Ṣugbọn nígbà tó yá, wọ́n yí ọ̀rọ̀ pada, wọ́n tún mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, wọ́n tún fi ipá sọ wọ́n di ẹrú.

12 OLUWA wá sọ fún Jeremaya pé,

13 “Èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli bá àwọn baba ńlá yín dá majẹmu nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò lóko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti, mo ní,

14 lẹ́yìn ọdún meje, kí olukuluku yín máa dá ọmọ Heberu tí ó bá fi owó rà lẹ́rú sílẹ̀, lẹ́yìn tí ó bá ti sin oluwa rẹ̀ fún ọdún mẹfa. Mo ní ẹ gbọdọ̀ dá ẹrú náà sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ ní òmìnira, ṣugbọn àwọn baba ńlá yín kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

15 Láìpẹ́ yìí, ẹ ronupiwada, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi; ẹ kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín. Ẹ dá majẹmu níwájú mi ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè.

16 Ṣugbọn ẹ tún yí ọ̀rọ̀ pada, ẹ ba orúkọ mi jẹ́ nípa pé olukuluku yín, ẹ tún mú ẹrukunrin ati ẹrubinrin tí ẹ dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn yín, ẹ sì tún sọ wọ́n di ẹrú pada.

17 Nítorí náà ẹ kò gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu pé kí olukuluku kéde òmìnira fún arakunrin rẹ̀ ati ọmọnikeji rẹ̀. Ẹ wò ó! N óo kéde òmìnira fun yín: òmìnira sí ọwọ́ ogun, àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo sì fi yín ṣe ẹrú fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.

18 Àwọn ọkunrin tí wọn bá rú òfin mi, tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà majẹmu tí wọn dá níwájú mi, n óo bẹ́ wọn bíi ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí wọn bẹ́ sí meji, tí wọ́n sì gba ààrin rẹ̀ kọjá.

19 Bí àwọn ìjòyè Juda ati àwọn ìjòyè Jerusalẹmu, àwọn ìwẹ̀fà, àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ṣe bẹ́ ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù sí meji, tí wọn sì gba ààrin rẹ̀ kọjá láti bá mi dá majẹmu, ni n óo ṣe bẹ́ àwọn náà.

20 N óo fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn; òkú wọn yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.

21 N óo fi Sedekaya, ọba Juda ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn. Wọn óo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni tí ó ti ṣígun kúrò lọ́dọ̀ wọn.

22 Ẹ wò ó, n óo pàṣẹ, n óo sì kó wọn pada sí ìlú yìí, wọn yóo gbógun tì í, wọn yóo gbà á; wọn yóo sì dáná sun ún. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro, kò ní sí eniyan tí yóo máa gbé inú wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 35

Jeremaya ati Àwọn Ọmọ Rekabu

1 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Jehoiakimu ọmọ Josaya, ọba Juda; ó ní,

2 “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu kí o bá wọn sọ̀rọ̀, mú wọn wá sinu ọ̀kan ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu ilé OLUWA, kí o sì fi ọtí lọ̀ wọ́n.”

3 Mo bá mú Jaasanaya ọmọ Jeremaya ọmọ Habasinaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ìdílé Rekabu,

4 mo mú wọn wá sinu ilé OLUWA. Mo kó wọn lọ sinu yàrá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hanani, ọmọ Igidalaya eniyan Ọlọrun, yàrá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá àwọn ìjòyè, lókè yàrá Maaseaya ọmọ Ṣalumu, aṣọ́nà.

5 Mo gbé ìgò ọtí kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Rekabu, mo kó ife tì í. Mo bá sọ fún wọn pé, “Ó yá, ẹ máa mu ọtí waini.”

6 Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “A kò ní mu ọtí kankan nítorí pé Jonadabu, baba ńlá wa tíí ṣe ọmọ Rekabu ti pàṣẹ fún wa pé a kò gbọdọ̀ mu ọtí, ati àwa ati arọmọdọmọ wa títí lae.

7 A kò gbọdọ̀ kọ́ ilé, a kò gbọdọ̀ dá oko, a kò gbọdọ̀ gbin ọgbà àjàrà. Ó ní inú àgọ́ ni kí á máa gbé ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, kí ọjọ́ wa baà lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí à ń gbé.

8 A gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá wa lẹ́nu, à ń pa gbogbo àṣẹ tí ó pa fún wa mọ́, pé kí á má mu ọtí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, àwa, àwọn aya wa ati àwọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin.

9 Ó ní a kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tí a óo máa gbé. A kò ṣe ọgbà àjàrà, tabi kí á dá oko, tabi kí á gbin ohun ọ̀gbìn.

10 Inú àgọ́ ni à ń gbé, a sì pa gbogbo àṣẹ tí Jonadabu baba ńlá wa fún wa mọ́.

11 Ṣugbọn nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti ilẹ̀ yìí, a wí fún ara wa pé kí á wá sí Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ogun, àwọn ará Kalidea ati ti àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe di ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu.”

12 OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé,

13 “Èmi OLUWA, àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o lọ sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu pé, ṣé wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ kí wọn sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi ni?

14 Àwọn ọmọ Rekabu pa òfin tí Jonadabu, baba ńlá wọn, fún wọn mọ́, pé kí wọn má mu ọtí waini, wọn kò sì mu ọtí rárá títí di òní olónìí, nítorí pé wọ́n pa àṣẹ baba ńlá wọn mọ́. Mo ti bá yín sọ̀rọ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

15 Mo ti rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, si yín, ní ọpọlọpọ ìgbà pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú tí ó ń tọ̀, kí ẹ tún ìwà yín ṣe, kí ẹ má sá tẹ̀lé àwọn oriṣa kiri, kí ẹ yé máa sìn wọ́n; kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Ṣugbọn ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

16 Àwọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu mú àṣẹ baba ńlá wọn tí ó pa fún wọn ṣẹ, ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

17 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ́ kí ibi bá àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, nítorí pé mo bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò gbọ́; mo pè wọ́n, wọn kò dáhùn.”

18 Ṣugbọn Jeremaya sọ fún àwọn ọmọ Rekabu pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá yín lẹ́nu, ẹ sì pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ pé kí ẹ máa ṣe,

19 nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní títí lae, kò ní sí ìgbà kan tí Jonadabu, ọmọ Rekabu kò ní ní ẹnìkan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú mi.’ ”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 36

Baruku Ka Àkọsílẹ̀ ninu Ilé OLUWA

1 Ní ọdún kẹrin ìjọba Jehoiakimu ọmọ Josaya ọba Juda, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

2 “Mú ìwé kíká kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ nípa Israẹli ati Juda ati gbogbo orílẹ̀-èdè sinu rẹ̀. Gbogbo ohun tí mo sọ láti ọjọ́ tí mo ti ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Josaya títí di òní, ni kí o kọ.

3 Bóyá bí àwọn ará Juda bá gbọ́ nípa ibi tí mò ń gbèrò láti ṣe sí wọn, olukuluku lè yipada kúrò ninu ọ̀nà ibi rẹ̀, kí n lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára wọn jì wọ́n.”

4 Jeremaya bá pe Baruku ọmọ Neraya, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá a sọ fún un, Baruku bá kọ wọ́n sinu ìwé kíká kan.

5 Jeremaya pàṣẹ fún Baruku pé, “Wọn kò gbà mí láàyè láti lọ sí inú ilé OLUWA;

6 nítorí náà, ìwọ ni óo lọ sibẹ ní ọjọ́ ààwẹ̀ láti ka ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ ní ẹnu mi; tí o sì kọ sí inú ìwé kíká, sí etí gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wá láti ìlú wọn.

7 Ó ṣeéṣe kí wọn mú ẹ̀bẹ̀ wọn wá siwaju OLUWA, kí olukuluku sì yipada kúrò lọ́nà ibi rẹ̀ tí ó ń rìn, nítorí pé ibinu OLUWA pọ̀ lórí wọn.”

8 Baruku bá ṣe gbogbo ohun tí Jeremaya wolii pa láṣẹ fún un lati kà lati inú ìwé ilé Oluwa.

9 Ní oṣù kẹsan-an, ọdún karun-un tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba ní Juda, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn eniyan tí wọ́n ti àwọn ìlú Juda wá sí Jerusalẹmu, kéde ọjọ́ ààwẹ̀ níwájú OLUWA.

10 Baruku bá ka ọ̀rọ̀ Jeremaya tí ó kọ sinu ìwé, sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan ní yàrá Gemaraya, ọmọ Ṣafani, akọ̀wé, tí ó wà ní gbọ̀ngàn òkè ní Ẹnu Ọ̀nà Titun ilé OLUWA.

Wọ́n Ka àkọsílẹ̀ náà sí Etígbọ̀ọ́ Àwọn Ìjòyè

11 Nígbà tí Mikaaya ọmọ Gemaraya, ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA tí ó wà ninu ìwé náà;

12 Ó lọ sí yàrá akọ̀wé ní ààfin ọba, ó bá gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn jókòó níbẹ̀: Eliṣama akọ̀wé ati Delaaya ọmọ Ṣemaaya, ati Elinatani ọmọ Akibori, ati Gemaraya ọmọ Ṣafani, ati Sedekaya ọmọ Hananaya ati gbogbo àwọn ìjòyè.

13 Mikaaya sọ gbogbo ohun tí ó gbọ́, nígbà tí Baruku ka ohun tí ó kọ sinu ìwé fún wọn.

14 Gbogbo àwọn ìjòyè bá rán Jehudi ọmọ Netanaya, ọmọ Ṣelemaya ọmọ Kuṣi pé kí ó lọ sọ fún Baruku kí ó máa bọ̀ kí ó sì mú ìwé tí ó kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́. Baruku, ọmọ Neraya, sì wá sọ́dọ̀ wọn tòun ti ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀.

15 Wọ́n ní kí ó jókòó, kí ó kà á fún àwọn, Baruku bá kà á fún wọn.

16 Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú. Wọ́n bá sọ fún Baruku pé, “A gbọdọ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ọba.”

17 Wọ́n bi Baruku pé, “Sọ fún wa, báwo ni o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀? Ṣé Jeremaya ni ó sọ ọ́, tí ìwọ fi ń kọ ọ́ ni, àbí báwo?”

18 Baruku bá dá wọn lóhùn pé, Jeremaya ni ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún òun ni òun fi kọ ọ́ sinu ìwé.

19 Àwọn ìjòyè bá sọ fún Baruku pé kí òun ati Jeremaya lọ sápamọ́, kí wọn má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí wọ́n wà.

Ọba Sun Ìwé Àkọsílẹ̀ náà níná

20 Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.

21 Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

22 Ninu oṣù kẹsan-an ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ọba sì wà ní ilé tíí máa gbé ní àkókò òtútù, iná kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ń jó ninu agbada.

23 Bí Jehudi bá ti ka òpó mẹta tabi mẹrin ninu ìwé náà, ọba yóo fi ọ̀bẹ gé e kúrò, yóo sì jù ú sinu iná tí ń jó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe títí ó fi fi ìwé náà jóná tán.

24 Sibẹ ẹ̀rù kò ba ọba tabi àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò sì fa aṣọ wọn ya.

25 Elinatani, Dilaaya ati Gemaraya tilẹ̀ bẹ ọba pé kí ó má fi ìwé náà jóná, ṣugbọn kò gbà.

26 Ọba bá pàṣẹ fún Jerameeli ọmọ rẹ̀, ati Seraaya ọmọ Asirieli, ati Ṣelemaya ọmọ Abideeli, pé kí wọn lọ mú Baruku akọ̀wé, ati Jeremaya wolii wá, ṣugbọn OLUWA fi wọ́n pamọ́.

Jeremaya Kọ ìwé mìíràn

27 Lẹ́yìn tí ọba ti fi ìwé náà jóná, ati gbogbo ohun tí Jeremaya ní kí Baruku kọ sinu rẹ̀, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

28 “Mú ìwé mìíràn kí o tún kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé ti àkọ́kọ́, tí Jehoiakimu, ọba Juda fi jóná sinu rẹ̀.

29 Ohun tí o óo kọ nípa Jehoiakimu ọba Juda, nìyí: sọ pé èmi OLUWA ní, ṣé ó fi ìwé ti àkọ́kọ́ jóná ni, ó ní, kí ló dé tí a fi kọ sinu rẹ̀ pé dájúdájú, ọba Babiloni ń bọ̀ wá pa ilẹ̀ yìí run ati pé, yóo pa ati eniyan ati ẹranko tí ó wà ninu rẹ̀ run?

30 Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA níí sọ nípa rẹ̀ ni pé, ẹyọ ọmọ rẹ̀ kan kò ní jọba lórí ìtẹ́ Dafidi. Ìta ni a óo gbé òkú rẹ̀ jù sí, oòrùn yóo máa pa á lọ́sàn-án, ìrì yóo sì máa sẹ̀ sí i lórí lóru.

31 N óo jẹ òun, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo mú kí gbogbo ibi tí mo pinnu lórí wọn ṣẹ sí wọn lára ati sí ara àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn ará Juda, nítorí pé wọn kò gbọ́ràn.”

32 Jeremaya bá fún Baruku akọ̀wé, ọmọ Neraya, ní ìwé mìíràn, Baruku sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ fún un sinu rẹ̀. Ó kọ ohun tí ó wà ninu ìwé àkọ́kọ́ tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná, ó sì fi àwọn nǹkan mìíràn kún un pẹlu.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 37

Ohun Tí Sedekaya Bèèrè lọ́wọ́ Jeremaya

1 Nebukadinesari, ọba Babiloni fi Sedekaya, ọmọ Josaya, jọba ní ilẹ̀ Juda dípò Jehoiakini, ọmọ Jehoiakimu.

2 Ṣugbọn Sedekaya ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan náà kò pa ọ̀rọ̀ tí OLUWA ní kí Jeremaya wolii sọ fún wọn mọ́.

3 Ọba Sedekaya rán Jehukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Sefanaya, alufaa, ọmọ Maaseaya, sí Jeremaya wolii, pé kí ó jọ̀wọ́ bá àwọn gba adura sí OLUWA Ọlọrun.

4 Ní àkókò yìí Jeremaya sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn eniyan, nítorí wọn kò tíì jù ú sẹ́wọ̀n nígbà náà.

5 Àwọn ọmọ ogun Farao ti jáde, wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti; nígbà tí àwọn ará Kalidea tí wọn dóti Jerusalẹmu gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu.

6 OLUWA sọ fún Jeremaya wolii pé kí ó sọ fún àwọn tí ọba Juda rán láti wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé,

7 OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí òun Jeremaya sọ fún ọba pé, àwọn ọmọ ogun Farao tí wọn wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ń múra láti pada sí Ijipti, ilẹ̀ wọn.

8 Àwọn ará Kalidea sì ń pada bọ̀ wá gbé ogun ti ìlú yìí; wọn yóo gbà á, wọn yóo sì dáná sun ún.

9 OLUWA ní kí wọn sọ fún Sedekaya ati àwọn ará Juda kí wọn má tan ara wọn jẹ, kí wọn má sì rò pé àwọn ará Kalidea kò ní pada wá sọ́dọ̀ wọn mọ́, nítorí wọn kò ní lọ.

10 Bí àwọn ará Juda bá tilẹ̀ ṣẹgun gbogbo ọmọ ogun àwọn ará Kalidea, tí wọ́n gbógun tì wọ́n, títí tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ nìkan ni wọ́n kù ninu àgọ́ wọn, wọn yóo dìde sí àwọn ará Juda, wọn yóo sì sun ìlú yìí níná.

Wọ́n Mú Jeremaya, Wọ́n sì Tì Í Mọ́lé

11 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Kalidea ti kúrò ní Jerusalẹmu, nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọmọ ogun Farao ń bọ̀,

12 Jeremaya jáde ní Jerusalẹmu ó fẹ́ lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini kí ó lọ gba ilẹ̀ rẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀.

13 Bí Jeremaya wolii ti dé bodè Bẹnjamini ọ̀kan ninu àwọn oníbodè tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irija ọmọ Ṣelemaya ọmọ Hananaya mú un, ó ní, “O fẹ́ sálọ bá àwọn ará Kalidea ni.”

14 Jeremaya dá a lóhùn, pé, “Rárá o, n kò sálọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea.” Ṣugbọn Irija kọ̀, kò gbọ́, ó sá mú Jeremaya lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè.

15 Inú bí àwọn ìjòyè sí Jeremaya, wọ́n lù ú, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ní ilé Jonatani akọ̀wé, nítorí pé wọ́n ti sọ ibẹ̀ di ọgbà ẹ̀wọ̀n.

16 Lẹ́yìn tí Jeremaya ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọpọlọpọ ọjọ́,

17 Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú un wá sí ààfin rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA ranṣẹ kankan?”

Jeremaya dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí OLUWA sọ ni pé, a óo fi ọ́ lé ọba Babiloni lọ́wọ́.”

18 Jeremaya wá bi Sedekaya ọba pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tabi àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, tabi àwọn ará ìlú yìí, tí ẹ fi jù mí sẹ́wọ̀n?

19 Níbo ni àwọn wolii rẹ wà, àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọ pé, ‘Ọba Babiloni kò ní gbógun ti ìwọ ati ilẹ̀ yìí?’

20 Nisinsinyii, kabiyesi, oluwa mi, jọ̀wọ́ fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi, má dá mi pada sí ilé Jonatani akọ̀wé, kí n má baà kú sibẹ.”

21 Sedekaya ọba bá pàṣẹ, wọ́n sì fi Jeremaya sinu gbọ̀ngàn ọgbà àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n sì ń fún un ní burẹdi kan lojumọ láti òpópónà àwọn oníburẹdi títí tí gbogbo burẹdi fi tán ní ìlú. Bẹ́ẹ̀ ni Jeremaya ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbọ̀ngàn àwọn tí ń ṣọ́ ààfin.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 38

Wọ́n Ju Jeremaya sinu Kànga Gbígbẹ

1 Nígbà tí Ṣefataya, ọmọ Matani, ati Gedalaya, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Paṣuri ọmọ Malikaya gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé,

2 “OLUWA ní, ẹni tí ó bá dúró ní ìlú Jerusalẹmu yóo kú ikú idà, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn; ṣugbọn àwọn tí wọn bá jáde tọ àwọn ará Kalidea lọ yóo yè. Ó ní ọ̀rọ̀ wọn yóo dàbí ẹni tí ó ja àjàbọ́, ṣugbọn yóo wà láàyè.

3 Ati pé dájúdájú, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Babiloni, wọn yóo sì gbà á.”

4 Àwọn ìjòyè náà bá sọ fún ọba pé, “Ẹ jẹ́ kí á pa ọkunrin yìí nítorí pé ó ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tí wọn kù láàrin ìlú, ati gbogbo àwọn eniyan nítorí irú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún wọn. Ọkunrin yìí kò fẹ́ alaafia àwọn eniyan wọnyi, àfi ìpalára wọn.”

5 Sedekaya ọba bá dá wọn lóhùn, pé, “Ìkáwọ́ yín ló wà, n kò jẹ́ ṣe ohunkohun tí ó bá lòdì sí ìfẹ́ yín.”

6 Wọ́n bá mú Jeremaya, wọ́n jù ú sinu kànga Malikaya, ọmọ ọba, tí ó wà ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n fi okùn sọ Jeremaya kalẹ̀ sinu kànga náà, kò sí omi ninu rẹ̀, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremaya sì rì sinu ẹrẹ̀ náà.

7 Nígbà tí Ebedimeleki ará Etiopia tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremaya sinu kànga. Ọba wà níbi tí ó jókòó sí ní ibodè Bẹnjamini.

8 Ebedimeleki jáde ní ààfin, ó lọ bá ọba ó sì wí fún un pé,

9 “Kabiyesi, oluwa mi, gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan wọnyi ṣe sí wolii Jeremaya kò dára. Inú kànga ni wọ́n jù ú sí, ebi ni yóo sì pa á sibẹ nítorí pé kò sí burẹdi ní ìlú mọ́.”

10 Ọba bá pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Etiopia, ó ní, “Mú eniyan mẹta lọ́wọ́, kí ẹ lọ yọ Jeremaya wolii kúrò ninu kànga náà kí ó tó kú.”

11 Ebedimeleki bá mú àwọn ọkunrin mẹta náà, wọ́n lọ sí yàrá kan ní ilé ìṣúra tí ó wà láàfin ọba. Ó mú àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó níbẹ̀, ó so okùn mọ́ wọn, ó sì nà án sí Jeremaya ninu kànga.

12 Ó bá sọ fún Jeremaya pé kí ó fi àwọn àkísà ati àwọn aṣọ tí wọ́n ti gbó náà sí abíyá mejeeji, kí ó fi okùn kọ́ ara rẹ̀ lábíyá. Jeremaya sì ṣe bẹ́ẹ̀.

13 Wọ́n bá fi okùn fa Jeremaya jáde kúrò ninu kànga. Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin.

Sedekaya Bèèrè Ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Jeremaya

14 Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú Jeremaya wolii wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà kẹta tí ó wà ní Tẹmpili OLUWA, ó wí fún Jeremaya pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, má sì fi ohunkohun pamọ́ fún mi.”

15 Jeremaya bá wí fún Sedekaya, ó ní, “Bí mo bá sọ fún ọ, o kò ní pa mí dájúdájú? Bí mo bá sì fún ọ ní ìmọ̀ràn, o kò ní gbà.”

16 Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.”

17 Jeremaya bá wí fún Sedekaya pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọn ó dá ẹ̀mí rẹ sí, wọn kò sì ní dáná sun ìlú yìí, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ yóo sì yè.

18 Ṣugbọn bí o kò bá fi ara rẹ le àwọn ìjòyè ọba Babiloni lọ́wọ́, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kalidea, wọn yóo sì dáná sun ún, ìwọ pàápàá kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn.”

19 Sedekaya ọba bá wí fún Jeremaya pé, “Ẹ̀rù àwọn ará Juda tí wọ́n sá lọ bá àwọn ará Kalidea ń bà mí. Wọ́n lè fà mí lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.”

20 Jeremaya dáhùn pé, “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Tẹ̀lé ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń sọ fún ọ; yóo dára fún ọ, a óo sì dá ẹ̀mí rẹ sí.

21 Ṣugbọn bí o bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ ohun tí OLUWA fihàn mí nìyí:

22 Wò ó, mo rí i tí wọn ń kó àwọn obinrin tí wọ́n wà ní ààfin ọba Juda jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọ́n sì ń wí pé,

‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o fọkàn tán tàn ọ́,

wọ́n sì ti ṣẹgun rẹ;

nisinsinyii tí o rì sinu ẹrẹ̀,

wọ́n pada lẹ́yìn rẹ.’

23 “Gbogbo àwọn aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni wọn yóo kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea, ìwọ gan-an kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ọwọ́ ọba Babiloni yóo tẹ̀ ọ́, wọn yóo sì dáná sun ìlú yìí.”

24 Sedekaya ọba bá kìlọ̀ fún Jeremaya pé, “Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ gbogbo nǹkan tí a jọ sọ, o kò sì ní kú.

25 Bí àwọn ìjòyè bá gbọ́ pé a jọ sọ̀rọ̀, bí wọn bá wá sọ́dọ̀ rẹ tí wọn ní kí o sọ nǹkan tí o bá mi sọ fún àwọn, ati èsì tí mo fún ọ, tí wọn bẹ̀ ọ́ pé kí o má fi ohunkohun pamọ́ fún àwọn, tí wọn sì ṣe ìlérí pé àwọn kò ní pa ọ́,

26 sọ fún wọn pé ẹ̀bẹ̀ ni ò ń bẹ̀ mí pé kí n má dá ọ pada sí ilé Jonatani; kí o má baà kú sibẹ.”

27 Gbogbo àwọn ìjòyè tọ Jeremaya lọ, wọ́n bí í, ó sì fún wọn lésì gẹ́gẹ́ bí ọba tí pàṣẹ fún un. Wọ́n bá dákẹ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n jọ sọ.

28 Jeremaya bá ń gbé gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin títí di ọjọ́ tí ogun kó Jerusalẹmu.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 39

Ìṣubú Jerusalẹmu

1 Ní oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an ìjọba Sedekaya, ọba Juda, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dótì í.

2 Ní ọjọ́ kẹsan-an, oṣù kẹrin, ọdún kọkanla ìjọba rẹ̀, wọ́n wọ ìlú náà.

3 Lẹ́yìn tí ogun ti kó Jerusalẹmu, gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babiloni péjọ, wọ́n sì jókòó ní bodè ààrin: Negali Sareseri, Samgari Nebo, Sarisekimu Rabusarisi, Negali Sareseri, Rabumagiati àwọn ìjòyè ọba Babiloni yòókù.

4 Nígbà tí Sedekaya ọba Juda ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ rí wọn, wọ́n sá. Wọ́n fòru bojú, wọ́n bá jáde ní ìlú; wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba, ní ọ̀nà ibodè tí ó wà láàrin odi meji, wọ́n sì dojú kọ ọ̀nà Araba.

5 Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lé wọn, wọ́n bá Sedekaya ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Nebukadinesari ọba Babiloni ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, ó sì dá Sedekaya lẹ́jọ́.

6 Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya ní Ribila níṣojú rẹ̀, ó sì pa gbogbo àwọn ìjòyè Juda pẹlu.

7 Ó yọ ojú Sedekaya, ó sì fi ẹ̀wọ̀n bàbà dè é láti mú un lọ sí Babiloni.

8 Àwọn ará Kalidea jó ààfin ọba ati ilé àwọn ará ìlú, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀.

9 Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá kó àwọn eniyan tí wọn ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu ní ìgbèkùn, lọ sí Babiloni pẹlu àwọn tí wọn kọ́ sá lọ bá a tẹ́lẹ̀.

10 Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ó sì fún wọn ní ọgbà àjàrà ati oko.

Wọ́n Dá Jeremaya sílẹ̀

11 Nebukadinesari ọba Babiloni pàṣẹ fún Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ pé

12 kí wọn mú Jeremaya, kí wọn tọ́jú rẹ̀ dáradára, kí wọn má pa á lára, ṣugbọn kí wọn ṣe ohunkohun tí ó bá ń fẹ́ fún un.

13 Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ati Nebuṣasibani, ìjòyè pataki kan, ati Negali Sareseri olóyè pataki mìíràn ati gbogbo àwọn olóyè jàǹkànjàǹkàn ninu àwọn ìjòyè ọba Babiloni,

14 wọ́n ranṣẹ lọ mú Jeremaya jáde kúrò ní ìgbèkùn. Wọ́n bá fà á lé Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani lọ́wọ́, pé kí ó mú un lọ sí ilé rẹ̀. Ó bá ń gbé ààrin àwọn eniyan náà.

Ìrètí Wà fún Ebedimeleki

15 OLUWA sọ fún Jeremaya nígbà tí ó wà ní àtìmọ́lé ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba, pé,

16 kí ó lọ sọ fún Ebedimeleki ará Etiopia pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Wò ó, n óo mú ìpinnu ibi tí mo ṣe lórí ìlú yìí ṣẹ, lójú rẹ ni yóo sì ṣẹ.

17 N óo gbà ọ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, wọn kò ní fà ọ́ lé àwọn tí ò ń bẹ̀rù lọ́wọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

18 Nítorí pé, dájúdájú n óo gbà ọ́ sílẹ̀, o ò ní kú ikú idà, ṣugbọn o óo sá àsálà, nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé mi.”