Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 20

Ìjà láàrin Jeremaya ati Paṣuri Alufaa

1 Nígbà tí Paṣuri alufaa, ọmọ Imeri, tí ó jẹ́ olórí àwọn olùṣọ́ ilé OLUWA, gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ,

2 ó ní kí wọn lu Jeremaya, kí wọn kàn ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Bẹnjamini ti òkè, ní ilé OLUWA.

3 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí Paṣuri tú Jeremaya sílẹ̀ ninu ààbà, Jeremaya wí fún un pé, “Kì í ṣe Paṣurini OLUWA pe orúkọ rẹ, ìpayà lọ́tùn-ún ati lósì ni OLUWA pè ọ́.

4 OLUWA ní, ‘N óo sọ ọ́ di ìpayà fún ara rẹ ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn ọ̀tá yóo fi idà pa wọ́n níṣojú rẹ, n óo fi gbogbo ilẹ̀ Juda lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, yóo sì fi idà pa wọ́n.

5 Bákan náà, n óo da gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, ati gbogbo èrè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lé àwọn ará Babiloni lọ́wọ́, pẹlu gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọn, ati gbogbo ìṣúra àwọn ọba Juda; gbogbo rẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ará Babiloni yóo fogun kó, wọn yóo sì rù wọ́n lọ sí Babiloni.

6 Ní ti ìwọ Paṣuri, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ, wọn óo ko yín ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí, ibẹ̀ ni wọ́n óo sì sin yín sí; àtìwọ, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ò ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.’ ”

Ìráhùn Jeremaya sí OLUWA

7 OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn;

o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi.

Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́,

gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.

8 Gbogbo ìgbà tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ni mò ń kígbe pé,

“Ogun ati ìparun dé!”

Nítorí náà, ọ̀rọ̀ OLUWA tí mò ń kéde sọ mí di ẹni yẹ̀yẹ́ tọ̀sán-tòru.

9 Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí mo bá wí pé n kò ní dárúkọ rẹ̀ mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni n kò ní sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́,

ọ̀rọ̀ rẹ a máa jó mi ninu bí iná,

a sì máa ro mí ninu egungun.

Mo gbìyànjú títí pé kí n pa á mọ́ra,

ṣugbọn kò ṣeéṣe.

10 Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé,

“Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì,

ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn.

Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.”

Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí,

tí wọn sì ń retí ìṣubú mi.

Wọ́n ń sọ pé,

“Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn,

ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́;

a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”

11 Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù.

Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀,

apá wọn kò ní ká mi.

Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi.

Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae.

12 OLUWA àwọn ọmọ ogun, ìwọ tíí dán olódodo wò,

ìwọ tí o mọ ọkàn ati èrò eniyan.

Gbẹ̀san lára wọn kí n fojú rí i,

nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

13 Ẹ kọrin sí OLUWA,

ẹ yin OLUWA.

Nítorí pé ó gba ẹ̀mí aláìní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aṣebi.

14 Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi,

kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má jẹ́ ọjọ́ ayọ̀.

15 Ègún ni fún ẹni tí ó yọ̀ fún baba mi,

tí ó sọ fún un pé,

“Iyawo rẹ ti bí ọmọkunrin kan fún ọ,

tí ó mú inú rẹ̀ dùn.”

16 Kí olúwarẹ̀ dàbí àwọn ìlú tí OLUWA parun láìṣàánú wọn.

Kí ó gbọ́ igbe lówùúrọ̀,

ati ariwo ìdágìrì lọ́sàn-án gangan.

17 Nítorí pé kò pa mí ninu oyún,

kí inú ìyá mi lè jẹ́ isà òkú fún mi.

Kí n wà ninu oyún ninu ìyá mi títí ayé.

18 Kí ló dé tí wọn bí mi sáyé?

Ṣé kí n lè máa fojú rí ìṣẹ́ ati ìbànújẹ́ ni?

Kí gbogbo ọjọ́ ayé mi lè kún fún ìtìjú?

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 21

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìṣubú Jerusalẹmu

1 Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya gbọ́ lẹ́nu OLUWA nìyí nígbà tí ọba Sedekaya rán Paṣuri, ọmọ Malikaya, ati alufaa Sefanaya, ọmọ Maaseaya, sí i;

2 tí ọba Sedekaya ní, “Ẹ sọ fún Jeremaya pé kí ó bá wa ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí ó gbógun tì wá; bóyá OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún wa, kí Nebukadinesari kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ wa.”

3 Jeremaya sọ fun awọn tí wọn rán sí i,

4 kí wọ́n sọ fún Sedekaya pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “N óo gba àwọn ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ yín, tí ẹ fi ń bá ọba Babiloni ati àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì yín lẹ́yìn odi jà, n óo dá wọn pada sí ààrin ìlú, n óo sì dojú wọn kọ yín.

5 Èmi fúnra mi ni n óo ba yín jà. Ipá ati agbára, pẹlu ibinu ńlá, ati ìrúnú gbígbóná ni n óo fi ba yín jà.

6 N óo fi àjàkálẹ̀ àrùn ńlá kọlu àwọn ará ìlú yìí, ati eniyan ati ẹranko ni yóo sì kú.

7 Lẹ́yìn náà n óo mú Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, ati ìyàn, bá pa kù ní ìlú yìí, n óo fi wọ́n lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, òun ati àwọn ọ̀tá tí ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Ọba Babiloni yóo fi idà pa wọ́n, kò ní ṣàánú wọn, kò sì ní dá ẹnikẹ́ni sí.”

8 OLUWA ní, “Sọ fún àwọn eniyan yìí pé èmi OLUWA ni mo la ọ̀nà meji níwájú wọn: ọ̀nà ìyè ati ọ̀nà ikú.

9 Ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo pa ẹni tí ó bá dúró sinu ìlú yìí; ṣugbọn ẹni tí ó bá jáde tí ó sì fa ara rẹ̀ fún àwọn ará Kalidea, tí ó gbé ogun tì yín, yóo yè, yóo dàbí ẹni tó ja àjàbọ́.

10 Nítorí pé mo ti dójú lé ìlú yìí láti ṣe ní ibi, kì í ṣe fún rere. Ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ ọba Babiloni, yóo sì dá iná sun ún, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìdájọ́ lórí Ìdílé Ọba Juda

11 OLUWA ní kí n sọ fún ìdílé ọba Juda pé òun OLUWA ní,

12 “Ẹ̀yin ará ilé Dafidi!

Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ní òwúrọ̀,

ẹ máa gba ẹni tí a jà lólè lọ́wọ́ aninilára,

kí ibinu èmi OLUWA má baà ru jáde, nítorí iṣẹ́ ibi yín,

kí ó sì máa jó bíi iná,

láìsí ẹni tí yóo lè pa á.”

13 OLUWA ní,

“Ẹ wò ó, mo dojú ìjà kọ yín,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé àfonífojì,

tí ó dàbí àpáta tí ó yọ sókè ju pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ,

ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé,

‘Ta ló lè dojú ìjà kọ wá?

Àbí ta ló lè wọ inú odi ìlú wa?’

14 N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ yín;

èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

N óo dáná sun igbó yín,

yóo sì jó gbogbo ohun tí ó wà ní agbègbè yín ní àjórun.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 22

Iṣẹ́ tí Jeremaya Jẹ́ fún Ìdílé Ọba Juda

1 OLUWA sọ fún mi pé, kí n lọ sí ilé ọba Juda kí n sọ fún un níbẹ̀ pé,

2 “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, ìwọ ọba Juda, tí o jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ ati àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń gba àwọn ẹnubodè wọnyi wọlé:

3 Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, kí ẹ máa gba ẹni tí wọn ń jà lólè lọ́wọ́ àwọn aninilára. Ẹ má hùwà burúkú sí àwọn àlejò, tabi àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó. Ẹ má ṣe wọ́n níbi, ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibi mímọ́ yìí.

4 Nítorí pé bí ẹ bá fi tọkàntọkàn fetí sí ọ̀rọ̀ mi, àwọn ọba yóo máa wọlé, wọn yóo sì máa jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi. Wọn yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn eniyan.

5 Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí mo wí, mo ti fi ara mi búra pé ilẹ̀ yìí yóo di ahoro. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

6 OLUWA sọ nípa ìdílé ọba Juda pé,

“Bíi Gileadi ni o dára lójú mi,

ati bí orí òkè Lẹbanoni.

Ṣugbọn sibẹ, dájúdájú, n óo sọ ọ́ di aṣálẹ̀;

o óo sì di ìlú tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé.

7 N óo kó àwọn apanirun tí yóo pa ọ́ run wá,

olukuluku yóo wá pẹlu ohun ìjà rẹ̀.

Wọn óo gé àwọn tí wọn dára jùlọ ninu àwọn igi Kedari yín,

wọn óo sì sun wọ́n níná.

8 “Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo máa gba ìlú yìí kọjá; wọn yóo sì máa bi ara wọn pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ìlú ńlá yìí?’

9 Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ majẹmu OLUWA Ọlọrun wọn sílẹ̀ ni, wọ́n ń bọ oriṣa, wọ́n sì ń sìn wọ́n.’ ”

Iṣẹ́ tí Jeremaya Jẹ́ Nípa Joahasi

10 Ẹ̀yin ará Juda,

ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú,

ẹ má sì dárò rẹ̀.

Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún,

nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́

láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí.

11 Nítorí pé OLUWA sọ nípa Joahasi, ọba Juda, ọmọ Josaya, tí ó jọba dípò Josaya baba rẹ̀, tí ó sì jáde kúrò ní ibí yìí pé, “Kò ní pada sibẹ mọ́.

12 Ibi tí wọn mú un ní ìgbèkùn lọ ni yóo kú sí; kò ní fi ojú rí ilẹ̀ yìí mọ́.”

Iṣẹ́ Tí Jeremaya Jẹ́ nípa Jehoiakimu

13 Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé,

tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀.

Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́,

láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un.

14 Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé,

“N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi,

ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.”

Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́.

Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀,

ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún.

15 Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba?

Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni,

tabi kò rí mu?

Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo,

ṣebí ó sì dára fún un.

16 Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní,

ohun gbogbo sì ń lọ dáradára.

Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA?

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

17 Ṣugbọn níbi èrè aiṣododo nìkan ni ojú ati ọkàn yín ń wà,

níbi kí ẹ máa pa aláìṣẹ̀, kí ẹ máa ni eniyan lára,

kí ẹ sì máa hùwà ìkà.

18 Nítorí náà, OLUWA sọ nípa Jehoiakimu, ọba Juda, ọmọ Josaya pé,

wọn kò ní dárò rẹ̀, pé,

“Ó ṣe, arakunrin mi!”

Tabi pé, “Ó ṣe, arabinrin mi!”

Wọn kò ní ké pé,

“Ó ṣe, oluwa mi!” Tabi pé, “Ó ṣe! Áà! Kabiyesi!”

19 Bí ẹni ń ṣe òkú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n óo ṣe òkú rẹ̀;

ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ni wọn yóo wọ́ ọ jù sí.

Iṣẹ́ Tí Jeremaya Jẹ́ nípa Ohun Tí Yóo Ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu

Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu,

20 ẹ gun orí òkè Lẹbanoni lọ, kí ẹ kígbe.

Ẹ dúró lórí òkè Baṣani, kí ẹ pariwo gidigidi,

ẹ kígbe láti orí òkè Abarimu,

nítorí pé a ti pa gbogbo àwọn alájọṣe yín run.

21 OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tí nǹkan ń dára fun yín,

ṣugbọn ẹ sọ pé ẹ kò ní gbọ́.

Bẹ́ẹ̀ ni ẹ tí ń ṣe láti kékeré yín,

ẹ kì í gbọ́rọ̀ sí OLUWA lẹ́nu.

22 Afẹ́fẹ́ yóo fẹ́ gbogbo àwọn olórí yín lọ,

àwọn olólùfẹ́ yín yóo lọ sí ìgbèkùn.

Ojú yóo wá tì yín,

ẹ óo sì di ẹni ẹ̀tẹ́,

nítorí gbogbo ibi tí ẹ̀ ń ṣe.

23 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Lẹbanoni,

tí ẹ kọ́ ilé yín sí ààrin igi kedari.

Ẹ óo kérora nígbà tí ara bá ń ni yín,

tí ara ń ni yín bíi ti obinrin tí ń rọbí ọmọ!

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Jehoiakini

24 OLUWA sọ fún Jehoiakiniọba, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pé, “Mo fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ni òrùka èdìdì ọwọ́ ọ̀tún mi,

25 n óo bọ́ ọ kúrò, n óo sì fi ọ́ lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ati àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ, tí ẹ̀rù wọn sì ń bà ọ́.

26 N óo wọ́ ìwọ ati ìyá tí ó bí ọ jù sí ilẹ̀ àjèjì, tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí ọ sí, ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí.

27 Ṣugbọn ilẹ̀ tí ọkàn yín fẹ́ pada sí, ẹ kò ní pada sibẹ mọ́.”

28 Ṣé àfọ́kù ìkòkò tí ẹnikẹ́ni kò kà kún ni Jehoiakini?

Àbí o ti di ohun èlò àlòpatì?

Kí ló dé tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀

fi di ẹni tí a kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ rí?

29 Ilẹ̀! Ilẹ̀!

Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ!

30 Ó ní, “Ẹ kọ orúkọ ọkunrin yìí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,

ẹni tí kò ní ṣe rere kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀;

nítorí pé kò sí ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀

tí yóo rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi,

Ìdílé rẹ̀ kò sì ní jọba mọ ní Juda.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 23

Ìrètí Ọjọ́ Iwájú

1 OLUWA ní, “Àwọn olùṣọ́-aguntan tí wọn ń tú àwọn agbo aguntan mi ká, tí wọn ń run wọ́n gbé!”

2 Nítorí náà, OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn tí ó fi ṣọ́ àwọn eniyan rẹ̀, láti máa bojútó wọn pé, “Ẹ ti tú àwọn aguntan mi ká, ẹ ti lé wọn dànù, ẹ kò sì tọ́jú wọn. N óo wá ṣe ìdájọ́ fun yín nítorí iṣẹ́ ibi yín, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

3 N óo kó àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn aguntan mi jọ láti gbogbo ibi tí mo lé wọn lọ. N óo kó wọn pada sinu agbo wọn. Wọn óo bímọ lémọ, wọn óo sì máa pọ̀ sí i.

4 N óo wá fún wọn ní olùṣọ́ mìíràn tí yóo tọ́jú wọn. Ẹ̀rù kò ní bà wọ́n mọ́, wọn kò ní fòyà, ọ̀kankan ninu wọn kò sì ní sọnù, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

5 “Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà.

6 Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’

7 “Nítorí náà àkókò kan ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti mọ́,

8 ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Iṣẹ́ tí Jeremaya Jẹ́ nípa Àwọn Wolii

9 Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii,

gbogbo ara mi ń gbọ̀n.

Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó,

mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa,

nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.

10 Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àgbèrè ẹ̀sìn,

ọ̀nà ibi ni wọ́n ń tọ̀,

wọn kò sì lo agbára wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́

nítorí ègún, ilẹ̀ ti di gbígbẹ

gbogbo pápá oko ló ti gbẹ.

11 Ati wolii, ati alufaa, ìwà burúkú ni wọ́n ń hù,

ní ilé mi pàápàá mo rí iṣẹ́ ibi wọn,

èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

12 Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn,

a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú,

nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn.

13 Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria:

Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;

wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà.

14 Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu:

Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn,

wọ́n ń hùwà èké;

wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,

kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀.

Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi,

àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora.

15 Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé:

N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ,

n óo fún wọn ní omi májèlé mu.

Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmu

ni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí.

16 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ.

17 Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.”

18 Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́?

19 Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú.

20 Inú OLUWA kò ní rọ̀ títí yóo fi ṣe ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀. Yóo ye wọn nígbà tí ọjọ́ ìkẹyìn bá dé.”

21 OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

22 Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe.

23 “Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn?

24 Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé?

25 Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá!

26 Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.

27 Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali.

28 Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà?

29 Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́?

30 Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbọ́ lẹ́nu ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi ni mo sọ ọ́.

31 Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ ti ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

32 Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ẹrù OLUWA

33 Bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi, tabi wolii kan, tabi alufaa kan, bá bi ọ́ léèrè pé, “Kí ni iṣẹ́ tí OLUWA rán?” Wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin gan-an ni ẹ jẹ́ ẹrù.OLUWA sì ní òun óo gbé yín sọnù.”

34 Bí wolii kan tabi alufaa kan tabi ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan wọnyi bá wí pé òun ń jẹ́ iṣẹ́ OLUWA, n óo jẹ olúwarẹ̀ ati ilé rẹ̀ níyà.

35 Báyìí ni kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa wí fún ẹnìkejì rẹ, ati fún arakunrin rẹ̀, “Kí ni ìdáhùn OLUWA?” tabi “Kí ni OLUWA wí?”

36 Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nuba ẹrù OLUWA mọ́. Nítorí pé èrò ọkàn olukuluku ni ẹrù OLUWA lójú ara rẹ̀; ẹ sì ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun alààyè po, ọ̀rọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wa.

37 Bí ẹ óo ti máa bèèrè lọ́wọ́ àwọn wolii ni pé, “Kí ni ìdáhùn tí OLUWA fún ọ?” Tabi, “Kí ni OLUWA wí?”

38 Ṣugbọn bí ẹ bá mẹ́nu ba “Ẹrù OLUWA,” lẹ́yìn tí mo ti ranṣẹ si yín pé ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nu bà á mọ́,

39 tìtorí rẹ̀, n óo sọ yín sókè,n óo sì gbe yín sọnù kúrò níwájú mi, àtẹ̀yin, àtìlú tí mo fi fún ẹ̀yin, ati àwọn baba ńlá yín.

40 N óo mú ẹ̀gàn ati ẹ̀sín ba yín, tí ẹ kò ní gbàgbé títí ayérayé.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 24

Apẹ̀rẹ̀ Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Meji

1 Lẹ́yìn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni ti kó Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu kúrò ní ìlú Jerusalẹmu lọ sí Babiloni, pẹlu àwọn ìjòyè Juda, ati àwọn oníṣẹ́ ọnà, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, OLUWA fi ìran yìí hàn mí. Mo rí apẹ̀rẹ̀ èso ọ̀pọ̀tọ́ meji níwájú ilé OLUWA.

2 Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ kinni dára gbáà, ó dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kọ́kọ́ pọ́n. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ keji ti rà patapata tóbẹ́ẹ̀ tí kò ṣe é jẹ.p

3 OLUWA bá bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí?”

Mo ní, “Èso ọ̀pọ̀tọ́ ni, àwọn tí ó dára, dára gan-an, àwọn tí kò sì dára bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ṣe é jẹ.”

4 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

5 “Ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, àwọn tí mo ti mú kí á kó lẹ́rú láti ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, ni pé, n óo kà wọ́n sí rere gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọnyi.

6 N óo fi ojurere wò wọ́n, n óo kó wọn pada wá sí ilẹ̀ yìí. N óo fìdí wọn múlẹ̀, n kò sì ní pa wọ́n run. N óo gbé wọn ró, n kò ní fà wọ́n tu,

7 n óo sì fún wọn ní òye láti mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn; nítorí tí wọn yóo fi tọkàntọkàn yipada sí mi.”

8 Ṣugbọn ohun tí OLUWA sọ nípa Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n kù ní ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ni pé òun óo ṣe wọ́n bí èso burúkú tí kò ṣe é jẹ.

9 Ó ní òun óo sọ wọ́n di ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba ayé. Wọn óo di ẹni ẹ̀gàn, ẹni ẹ̀sín, ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni tí a fi ń ṣẹ́ èpè ní gbogbo ibi tí òun óo tì wọ́n lọ.

10 Ó ní òun óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, títí wọn yóo fi kú tán, tí kò ní ku ẹyọ ẹnìkan lórí ilẹ̀ tí òun fún àwọn ati àwọn baba ńlá wọn.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 25

Àwọn Ọ̀tá láti Ìhà Àríwá

1 Ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kinni tí Nebukadinesari jọba Babiloni, Jeremaya wolii gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nípa gbogbo àwọn ará Juda.

2 Jeremaya sọ ọ̀rọ̀ náà fún gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu.

3 Ó ní, “Fún ọdún mẹtalelogun, láti ọdún kẹtala tí Josaya ọmọ Amoni ti jọba Juda, títí di ọjọ́ òní, ni OLUWA ti ń bá mi sọ̀rọ̀, tí mo sì ti ń sọ ọ́ fun yín lemọ́lemọ́, ṣugbọn tí ẹ kò sì gbọ́.

4 Ẹ kò fetí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo ni OLUWA ń rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, si yín, tí wọn ń sọ fun yín pé

5 kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ ati iṣẹ́ ibi tí ó ń ṣe, kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí OLUWA fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín títí lae, láti ìgbà àtijọ́.

6 Wọ́n ní kí ẹ má wá àwọn oriṣa lọ, kí ẹ má bọ wọ́n, kí ẹ má sì sìn wọ́n. Wọ́n ní kí ẹ má fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú un bínú, kí ó má baà ṣe yín ní ibi.”

7 OLUWA alára ní, “Mo wí, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi; kí ẹ lè fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, fún ìpalára ara yín.”

8 Ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,

9 n óo ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àríwá wá. N óo ranṣẹ sí Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ mi, n óo jẹ́ kí wọn wá dó ti ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ yìí ni n óo parun patapata, tí n óo sọ di àríbẹ̀rù, ati àrípòṣé, ati ohun ẹ̀gàn títí lae.

10 N óo pa ìró ayọ̀ ati ẹ̀rín rẹ́ láàrin wọn, ẹnìkan kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo tuntun mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí iná fìtílà mọ́.

11 Gbogbo ilẹ̀ yìí yóo di àlàpà ati aṣálẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì sin ọba Babiloni fún aadọrin ọdún.

12 Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, n óo jẹ ọba Babiloni ati orílẹ̀-èdè rẹ̀, ati ilẹ̀ àwọn ará Kalidea níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo sì sọ ibẹ̀ di àlàpà títí ayé.

13 N óo mú gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú tí mo ti sọ nípa ilẹ̀ náà ṣẹ, ati gbogbo ohun tí a kọ sinu ìwé yìí, àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremaya sọ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

14 Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba alágbára yóo sọ àwọn ará Babiloni pàápàá di ẹrú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san ìṣe wọn ati iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-èdè náà

15 OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Gba ife ọtí ibinu yìí lọ́wọ́ mi, kí o fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo rán ọ sí mu.

16 Wọn yóo mu ún, wọn yóo sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, wọn yóo máa ṣe bí aṣiwèrè nítorí ogun tí n óo rán sí ààrin wọn.”

17 Mo bá gba ife náà lọ́wọ́ OLUWA, mo sì fún gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLUWA rán mi sí mu:

18 Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí.

19 N óo fún Farao, ọba Ijipti mu, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀

20 ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu).

21 N óo fún Edomu mu, ati Moabu, ati àwọn ọmọ Amoni;

22 ati gbogbo àwọn ọba Tire, ati àwọn ọba Sidoni, ati gbogbo àwọn ọba erékùṣù tí ó wà ní òdìkejì òkun.

23 N óo fún Dedani mu, ati Tema, ati Busi ati gbogbo àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn.

24 N óo fún gbogbo àwọn ọba Arabia mu ati gbogbo àwọn ọba oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tí wọn ń gbé aṣálẹ̀.

25 N óo fún gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Simiri mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Elamu ati gbogbo àwọn ti ilẹ̀ Media;

26 ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ àríwá, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn. N óo sì fún àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ ayé mu pẹlu. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ti mu tiwọn tán, ọba Babiloni yóo wá mu tirẹ̀.

27 OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí ẹ mu ọtí kí ẹ yó, kí ẹ sì máa bì, ẹ ṣubú lulẹ̀ kí ẹ má dìde mọ́; nítorí ogun tí n óo jẹ́ kí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin yín.

28 Bí wọn bá kọ̀ tí wọn kò gba ife náà lọ́wọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, wí fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní wọ́n gbọdọ̀ mu ún ni!

29 Nítorí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ibi ṣẹlẹ̀ sórí ìlú tí à ń fi orúkọ mi pè yìí, ǹjẹ́ ẹ lè lọ láìjìyà bí? Rárá o, ẹ kò ní lọ láìjìyà nítorí pé mo ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé kú ikú idà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

30 “Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé:

‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè,

yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀.

Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀.

Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà.

31 Ariwo náà yóo kàn dé òpin ayé,

nítorí pé OLUWA ní ẹjọ́ láti bá àwọn orílẹ̀-èdè rò.

Yóo dá gbogbo eniyan lẹ́jọ́,

yóo fi idà pa àwọn eniyan burúkú,

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

32 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ibi yóo máa ṣẹlẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, ìjì ńlá yóo sì jà láti òpin ayé wá.

33 Òkú àwọn tí OLUWA yóo pa ní ọjọ́ náà yóo kún inú ayé láti òpin kan dé ekeji. Ẹnikẹ́ni kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, kò sí ẹni tí yóo gbé òkú wọn nílẹ̀; wọn kò ní sin wọ́n. Wọn yóo dàbí ìgbẹ́ lórí ilẹ̀.

34 Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa.

35 Kò ní sí ààbò mọ́ fún àwọn olùṣọ́-aguntan, kò ní sí ọ̀nà ati sá àsálà fún àwọn oluwa àwọn agbo ẹran.

36 Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-aguntan

ati ẹkún ẹ̀dùn ti àwọn oluwa agbo ẹran;

nítorí OLUWA ń ba ibùjẹ ẹran wọn jẹ́.

37 Pápá oko tútù tí ìbẹ̀rù kò sí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti di ahoro

nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.

38 Bíi kinniun tí ó fi ihò rẹ̀ sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fi àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀,

ilẹ̀ wọn sì ti di ahoro

nítorí idà apanirun ati ibinu gbígbóná OLUWA.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 26

A Pe Jeremaya Lẹ́jọ́

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, ọmọ Josaya,

2 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Dúró sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA, kí o sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún gbogbo àwọn ará ìlú Juda tí wọn ń wá jọ́sìn níbẹ̀. Má fi ọ̀rọ̀ kankan pamọ́.

3 Ó ṣeéṣe kí wọ́n gbọ́, kí olukuluku wọn sì yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀; kí n lè yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo fẹ́ ṣe sí wọn nítorí iṣẹ́ burúkú wọn.

4 “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA ní bí wọn kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, kí wọn máa pa òfin tí mo gbé kalẹ̀ fún wọn mọ́,

5 kí wọn sì máa gbọ́ràn sí àwọn iranṣẹ mi lẹ́nu, ati àwọn wolii mi tí mò ń rán sí wọn léraléra, bí wọn kò tilẹ̀ kà wọ́n sí,

6 nítorí náà ni n óo ṣe ṣe ilé yìí bí mo ti ṣe Ṣilo; n óo sì sọ ìlú yìí di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóo máa fi gégùn-ún.”

7 Àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan gbọ́ tí Jeremaya ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ilé OLUWA.

8 Nígbà tí ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn eniyan náà tán, gbogbo wọn rá a mú, wọ́n ní, “Kíkú ni o óo kú!

9 Kí ló dé tí o fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA pé ‘Ilé yìí yóo dàbí Ṣilo, ati pé ìlú yìí yóo di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbébẹ̀ mọ́?’ ” Gbogbo eniyan bá pé lé Jeremaya lórí ninu ilé OLUWA.

10 Nígbà tí àwọn ìjòyè Juda gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lọ sí ilé OLUWA láti ààfin ọba, wọ́n sì jókòó ní Ẹnu Ọ̀nà Titun tí ó wà ní ilé OLUWA.

11 Àwọn alufaa ati àwọn wolii bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “Ẹjọ́ ikú ni ó yẹ kí a dá fún ọkunrin yìí nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ń sọ nípa ìlú yìí, ẹ̀yin náà sá fi etí ara yín gbọ́.”

12 Jeremaya bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “OLUWA ni ó rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹ gbọ́ sí ilé yìí ati ìlú yìí.

13 Nítorí náà, ẹ tún ọ̀nà yín ṣe, ẹ pa ìṣe yín dà, kí ẹ sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, yóo sì yí ọkàn rẹ̀ pada kúrò ninu ibi tí ó sọ pé òun yóo ṣe sí i yín.

14 Ní tèmi, mo wà lọ́wọ́ yín, ohun tí ó bá dára lójú yín ni kí ẹ fi mí ṣe.

15 Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé bí ẹ bá pa mí, ẹ óo fa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sórí ara yín, ati ìlú yìí ati àwọn ará ìlú yìí, nítorí pé nítòótọ́ ni OLUWA rán mi pé kí n sọ gbogbo ohun tí mo sọ kí ẹ gbọ́.”

16 Àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan bá sọ fún àwọn alufaa ati àwọn wolii pé, “Ẹjọ́ ikú kò tọ́ sí ọkunrin yìí, nítorí pé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa ni ó fi ń bá wa sọ̀rọ̀.”

17 Àwọn kan ninu àwọn àgbààgbà ìlú dìde, wọ́n bá gbogbo ìjọ eniyan sọ̀rọ̀; wọ́n ní,

18 “Ní ìgbà Hesekaya ọba Juda, Mika ará Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn ará Juda pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní,

‘A óo kọ Sioni bí ilẹ̀ oko,

Jerusalẹmu yóo di òkítì àlàpà;

òkè ilé yìí yóo sì di igbó kìjikìji.’

19 Ǹjẹ́ Hesekaya ati gbogbo eniyan Juda pa Mika bí? Ṣebí OLUWA yí ibi tí ó ti pinnu láti ṣe sí wọn pada, nítorí pé Hesekaya bẹ̀rù OLUWA ó sì wá ojurere rẹ̀. Ṣugbọn ní tiwa ibi ńláńlá ni a fẹ́ fà lé orí ara wa yìí.”

20 Ọkunrin kan tún wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uraya, ọmọ Ṣemaaya, láti ìlú Kiriati Jearimu. Òun náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ yìí ati ilẹ̀ wa bí Jeremaya ti sọ yìí.

21 Nígbà tí ọba Jehoiakimu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati àwọn ìjòyè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà tí Uraya gbọ́, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí ilẹ̀ Ijipti.

22 Ṣugbọn ọba Jehoiakimu rán Elinatani, ọmọ Akibori, ati àwọn ọkunrin kan lọ sí Ijipti,

23 wọ́n mú Uraya jáde ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n mú un tọ ọba Jehoiakimu wá. Ọba Jehoiakimu fi idà pa á, ó sì ju òkú rẹ̀ sí ibi tí wọn ń sin àwọn talaka sí.

24 Ṣugbọn Ahikamu ọmọ Ṣafani fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ mi, kò sì jẹ́ kí á fà mí lé àwọn eniyan lọ́wọ́ láti pa.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 27

Jeremaya Kọrùn Bọ Àjàgà

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀; ó ní:

2 “Ṣe àjàgà kan pẹlu okùn rẹ̀ kí o sì fi bọ ara rẹ lọ́rùn.

3 Àwọn ikọ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ Sedekaya, ọba Juda, ní Jerusalẹmu, láti ọ̀dọ̀ ọba Edomu ati ọba Moabu, ọba àwọn ọmọ Amoni, ọba Tire, ati ọba Sidoni wá, rán wọn pada sí àwọn oluwa wọn,

4 sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n sọ fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní

5 òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún.

6 Ó ní òun ti fún Nebukadinesari, ọba Babiloni iranṣẹ òun, ní gbogbo àwọn ilẹ̀ wọnyi, òun sì ti fún un ni àwọn ẹranko inú igbó kí wọn máa ṣe iranṣẹ rẹ̀.

7 Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóo máa ṣe ẹrú òun ati ọmọ rẹ̀, ati ọmọ ọmọ rẹ̀, títí àkókò tí ilẹ̀ òun pàápàá yóo fi tó, tí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba ńláńlá yóo sì kó o lẹ́rú.”

8 OLUWA ní, “Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè tabi ìjọba kan bá kọ̀, tí wọn kò sin Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí wọn kò sì ti ọrùn wọn bọ àjàgà rẹ̀, ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ni n óo fi jẹ orílẹ̀-èdè náà níyà títí n óo fi fà á lé ọba Babiloni lọ́wọ́.

9 Nítorí náà, ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín, ati àwọn awoṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín ati àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, ati àwọn oṣó yín, tí wọn ń sọ fun yín pé ẹ kò ní di ẹrú ọba Babiloni.

10 Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín, wọ́n fẹ́ kí á ko yín jìnnà sí ilẹ̀ yín ni. N óo le yín jáde; ẹ óo sì ṣègbé.

11 Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti ọrùn ara rẹ̀ bọ àjàgà ọba Babiloni, tí ó sì ń sìn ín, n óo fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, kí ó lè máa ro ó, kí ó sì máa gbé ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12 Iṣẹ́ yìí kan náà ni mo jẹ́ fún Sedekaya ọba Juda. Mo ní, “Fi ọrùn rẹ sinu àjàgà ọba Babiloni, kí o sin òun ati àwọn eniyan rẹ̀, kí o lè wà láàyè.

13 Kí ló dé tí ìwọ ati àwọn eniyan rẹ fẹ́ kú ikú idà, ikú ìyàn ati ikú àjàkálẹ̀ àrùn bí OLUWA ti wí pé yóo rí fún orílẹ̀-èdè tí ó bá kọ̀ tí kò bá sin ọba Babiloni?

14 Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń wí fun yín pé ẹ kò ní ṣe ẹrú ọba Babiloni, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.

15 OLUWA ní òun kò rán wọn níṣẹ́. Wọ́n kàn ń fi orúkọ òun sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni, kí òun lè le yín jáde, kí ẹ sì ṣègbé, àtẹ̀yin àtàwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín.”

16 Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, mo ní, “OLUWA sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín tí wọn ń wí fun yín pé wọn kò ní pẹ́ kó àwọn ohun èlò ilé èmi OLUWA pada wá láti Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.

17 Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ sin ọba Babiloni, kí ẹ lè wà láàyè. Kí ló dé tí ìlú yìí yóo fi di ahoro?

18 Bí wọn bá jẹ́ wolii nítòótọ́, bí ó bá jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo fi ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu, ẹ ní kí wọn gbadura sí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, kí n má jẹ́ kí wọ́n kó àwọn ohun èlò tí ó kù ní ilé OLUWA ati ní ààfin ọba Juda ati ní Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.”

19 Àwọn ohun èlò kan ṣẹ́kù ninu ilé OLUWA, àwọn bíi: òpó ilé, ati agbada omi tí a fi idẹ ṣe, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó kù ninu ìlú yìí,

20 tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kò kó lọ, nígbà tí ó kó Jehoiakini, ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn ọlọ́lá Juda ati ti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.

21 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Gbogbo àwọn ohun èlò tí ó ṣẹ́kù ní ilé rẹ, ati ní ààfin ọba Juda, ati ní Jerusalẹmu, ni

22 wọn óo kó lọ sí Babiloni, níbẹ̀ ni wọn yóo sì wà títí di ọjọ́ tí mo bá ranti wọn. N óo wá kó wọn pada wá sí ibí yìí nígbà náà.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 28

Wolii Jeremaya ati Wolii Hananaya

1 Ní ọdún kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ní oṣù karun-un ọdún kẹrin, Hananaya wolii ọmọ Aṣuri, tí ó wá láti Gibeoni bá mi sọ̀rọ̀ ní ilé OLUWA lójú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan pé,

2 “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni.

3 Kí ó tó pé ọdún meji, òun óo kó gbogbo ohun èlò tẹmpili òun pada, tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó láti ibí yìí lọ sí Babiloni.

4 Òun óo mú Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú láti Juda lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí, nítorí òun óo ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. Ó ní OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

5 Jeremaya wolii bá dá Hananaya wolii lóhùn níṣojú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn ará ìlú tí wọn dúró ní ilé OLUWA,

6 ó ní, “Amin, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀. Kí OLUWA mú àsọtẹ́lẹ̀ tí o sọ ṣẹ, kí ó kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí.

7 Ṣugbọn gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ìwọ ati gbogbo àwọn eniyan wọnyi.

8 Àwọn wolii tí wọ́n ti wà ṣáájú èmi pẹlu rẹ ní ìgbà àtijọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn nípa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati nípa àwọn ìjọba ńláńlá.

9 Wolii tí ó bá fẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé alaafia yóo wà, nígbà tí ọ̀rọ̀ wolii náà bá ṣẹ ni a óo mọ̀ pé OLUWA ni ó rán an níṣẹ́ nítòótọ́.”

10 Hananaya wolii bá bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, ó sì ṣẹ́ ẹ.

11 Hananaya bá sọ níṣojú gbogbo eniyan pé OLUWA ní bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣẹ́ àjàgà Nebukadinesari ọba Babiloni kúrò lọ́rùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè kí ọdún meji tó pé. Wolii Jeremaya bá bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

12 Lẹ́yìn tí Hananaya wolii bọ́ àjàgà kúrò lọ́rùn Jeremaya, tí ó sì ṣẹ́ ẹ, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

13 “Lọ sọ fún Hananaya pé OLUWA ní àjàgà igi ni ó ṣẹ́, ṣugbọn àjàgà irin ni òun óo fi rọ́pò rẹ̀.

14 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti fi àjàgà irin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè wọnyi kí wọn lè di ẹrú Nebukadinesari ọba Babiloni, kí wọn sì máa sìn ín, nítorí òun ti fi àwọn ẹranko inú igbó pàápàá fún un.”

15 Jeremaya wolii bá sọ fún Hananaya pé, “Tẹ́tí sílẹ̀, Hananaya, OLUWA kò rán ọ níṣẹ́, o sì ń jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gbẹ́kẹ̀lé irọ́.

16 Nítorí náà, OLUWA ní: òun óo mú ọ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún yìí gan-an ni o óo sì kú, nítorí pé o ti sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”

17 Ní ọdún náà gan-an ní oṣù keje, ni Hananaya wolii kú.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 29

Lẹta Jeremaya sí Àwọn Tí Ogun Kó Lọ sí Babiloni

1 Jeremaya wolii kọ ìwé kan ranṣẹ láti Jerusalẹmu, ó kọ ọ́ sí àwọn àgbààgbà láàrin àwọn tí a kó ní ìgbèkùn; ati sí àwọn alufaa ati àwọn wolii, ati gbogbo àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, láti Jerusalẹmu.

2 Ṣáájú àkókò yìí, ọba Jehoiakini ati ìyá ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, pẹlu àwọn ìwẹ̀fà ati àwọn ìjòyè Juda ati ti Jerusalẹmu, ati àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati àwọn oníṣẹ́-ọnà.

3 Ó fi ìwé náà rán Elasa, ọmọ Ṣafani ati Gemaraya, ọmọ Hilikaya: àwọn tí Sedekaya, ọba Juda, rán lọ sọ́dọ̀ Nebukadinesari, ọba Babiloni.

4 Ó ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fún gbogbo àwọn tí a ti kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni pé,

5 ‘Ẹ máa kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ máa dá oko kí ẹ sì máa jẹ èso wọn.

6 Ẹ máa gbé iyawo kí ẹ bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa fẹ́ iyawo fún àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọ yín fún ọkọ, kí wọn lè máa bímọ lọkunrin ati lobinrin. Ẹ máa pọ̀ sí i, ẹ má sì dínkù.

7 Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia.

8 Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé kí ẹ má jẹ́ kí àwọn wolii ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ láàrin yín tàn yín jẹ, kí ẹ má sì fetí sí àlá tí wọn ń lá;

9 nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́.’

10 “Nígbà tí aadọrin ọdún Babiloni bá pé, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ yín, n óo mú ìlérí mi ṣẹ fun yín, n óo sì ko yín pada sí ibí yìí.

11 Nítorí pé mo mọ èrò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fun yín ní ìrètí.

12 Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín.

13 Ẹ óo wá mi, ẹ óo sì rí mi, bí ẹ bá fi tọkàntọkàn wá mi.

14 Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15 “Nítorí ẹ wí pé, ‘OLUWA ti gbé àwọn wolii dìde fun wa ní Babiloni.’

16 Nípa ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú yìí, àní àwọn ará yín tí wọn kò ba yín lọ sí ìgbèkùn,

17 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’

18 Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ.

19 Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo.

20 Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, gbogbo ẹ̀yin tí OLUWA kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.’

21 “Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Jehoiakini, ati Sedekaya ọmọ Maaseaya, tí wọn ń forúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fun yín ni pé: òun óo fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì pa wọ́n lójú yín.

22 Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’

23 nítorí pé wọ́n ti hùwà òmùgọ̀ ní Israẹli, wọ́n bá aya àwọn aládùúgbò wọn ṣe àgbèrè, wọ́n fi orúkọ òun sọ ọ̀rọ̀ èké tí òun kò fún wọn láṣẹ láti sọ. OLUWA ní òun nìkan ni òun mọ ohun tí wọ́n ṣe; òun sì ni ẹlẹ́rìí.”

Ìwé Tí Ṣemaaya Kọ

24 OLUWA ní kí n sọ fún Ṣemaaya tí ń gbé Nehelamu pé,

25 “Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé:

26 “Èmi OLUWA ti fi ìwọ Sefanaya jẹ alufaa dípò Jehoiada tí ó jẹ́ alufaa tẹ́lẹ̀ rí, ati pé mo ní kí o máa ṣe alabojuto gbogbo àwọn wèrè tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé èmi OLUWA, kí o sì máa kan ààbà mọ́ wọn ní ẹsẹ̀, kí o máa fi okùn sí wọn lọ́rùn.

27 Kí ló dé tí o kò bá Jeremaya ará Anatoti tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín wí.

28 Nítorí ó ti ranṣẹ sí wa ní Babiloni pé a á pẹ́ níbí, nítorí náà kí á kọ́lé, kí á máa gbé inú rẹ̀, kí á dá oko, kí á sì máa jẹ èso rẹ̀.”

29 Sefanaya Alufaa ka ìwé náà sí etí Jeremaya wolii.

30 OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé,

31 “Ranṣẹ sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn wí pé ohun tí OLUWA wí nípa Ṣemaaya ará Nehelamu ni pé: nítorí pé Ṣemaaya sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí òun kò rán an, ó sì mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ èké,

32 òun OLUWA óo fìyà jẹ Ṣemaaya ará Nehelamu náà ati ìran rẹ̀; kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo wà láàyè láàrin àwọn eniyan rẹ̀ láti fojú rí nǹkan rere tí n óo ṣe fún àwọn eniyan mi, nítorí ó ti sọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”