Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 10

Ìbọ̀rìṣà ati Ìjọ́sìn Tòótọ́

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli:

2 OLUWA ní,

“Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,

ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run,

bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn,

3 nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn.

Wọn á gé igi ninu igbó,

agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ.

4 Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,

wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀,

kí ó má baà wó lulẹ̀.

5 Ère wọn dàbí aṣọ́komásùnninu oko ẹ̀gúsí,

wọn kò lè sọ̀rọ̀,

gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọn

nítorí pé wọn kò lè dá rìn.

Ẹ má bẹ̀rù wọn

nítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan,

bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.”

6 OLUWA, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, o tóbi lọ́ba,

agbára orúkọ rẹ sì pọ̀.

7 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè?

Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni;

kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọ

láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè,

ati ni gbogbo ìjọba wọn.

8 Aláìmọ̀kan ati òmùgọ̀ ni gbogbo wọn,

ère kò lè kọ́ eniyan lọ́gbọ́n,

nítorí igi lásán ni.

9 Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi,

ati wúrà láti ìlú Ufasi.

Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n,

ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà.

Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupa

ati ti elése àlùkò,

iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn.

10 Ṣugbọn OLUWA ni Ọlọrun tòótọ́,

òun ni Ọlọrun alààyè, Ọba ayérayé.

Tí inú rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí ru ayé á mì tìtì,

àwọn orílẹ̀-èdè kò lè farada ibinu rẹ̀.

11 Wí fún wọn pé àwọn ọlọrun tí kì í ṣe àwọn ni wọ́n dá ọ̀run ati ayé yóo parun láyé ati lábẹ́ ọ̀run.

Orin Ìyìn sí Ọlọrun

12 Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé,

tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀,

tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ.

13 Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run,

ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé,

òun ni ó dá mànàmáná fún òjò,

tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14 Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀;

gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì,

nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn;

kò sí èémí ninu wọn.

15 Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n;

ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni.

16 Ìpín Jakọbu kò rí bí àwọn wọnyi,

nítorí òun ló dá ohun gbogbo,

Israẹli sì ni ẹ̀yà tí ó yàn, gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀;

OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.

17 Ẹ gbé ẹrù yín nílẹ̀,

ẹ̀yin tí ọ̀tá dótì wọnyi!

18 Nítorí OLUWA wí pé,

“Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò.

N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn,

kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.”

19 Mo gbé, nítorí mo fara gbọgbẹ́!

Ọgbẹ́ náà sì pọ̀.

Ṣugbọn mo sọ fún ara mi pé,

“Ìyà gan-an ni èyí jẹ́ fún mi,

mo sì gbọdọ̀ fara dà á.”

20 Àgọ́ mi ti wó, gbogbo okùn rẹ̀ sì ti já.

Àwọn ọmọ mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́.

Kò sí ẹni tí yóo máa bá mi pa àgọ́ mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóo máa bá mi ta aṣọ àgọ́ mi.

21 Nítorí pé òmùgọ̀ ni àwọn olùṣọ́-aguntan,

wọn kò sì ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA,

nítorí náà wọn kò ṣe àṣeyọrí,

tí gbogbo agbo wọn sì fi túká.

22 Ẹ gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ kan! Ó ń tàn kálẹ̀!

Ìdàrúdàpọ̀ ńlá ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,

tí yóo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro

yóo sì di ibùgbé àwọn ajáko.

23 OLUWA, mo mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀dá kò sí ní ọwọ́ ara rẹ̀.

Kò sí ní ìkáwọ́ ẹni tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.

24 Tọ́ mi sọ́nà, OLUWA,

ṣugbọn lọ́nà ẹ̀tọ́ ni kí o bá mi wí,

kì í ṣe pẹlu ibinu rẹ,

kí o má baà sọ mí di ẹni ilẹ̀.

25 Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ ọ́,

ni kí o bínú sí kí ó pọ̀,

ati àwọn tí wọn kì í jọ́sìn ní orúkọ rẹ;

nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,

wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹrun patapata,

wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 11

Jeremaya ati Majẹmu

1 OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀,

2 ó ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí o sì sọ ọ́ fún àwọn ọmọ Juda, ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

3 Sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ majẹmu

4 tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, gbé! Majẹmu tí mo bá wọn dá ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná bí iná tí alágbẹ̀dẹ fi ń yọ́ irin.’ Mo sọ fún wọn nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa fetí sí ohùn mi, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Òun ni ẹ óo fi jẹ́ eniyan mi, tí èmi náà óo sì fi jẹ́ Ọlọrun yín.

5 Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, n óo mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé n óo fún wọn ní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin,’ bí ó ti rí ní òní.”

Mo bá dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA.”

6 OLUWA tún sọ fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda ati ní àwọn òpópó Jerusalẹmu, pé kí wọn fetí sí ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí wọ́n sì ṣe bí ó ti wí.

7 Mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, títí tí ó sì fi di òní, n kò yé kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n fetí sí ohùn èmi OLUWA.

8 Sibẹsibẹ wọn kò gbọ́; wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, olukuluku ń ṣe ohun tí ó wà ní ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ majẹmu yìí ṣẹ mọ́ wọn lára, bí mo ti pa á láṣẹ fún wọn pé kí wọn ṣe, ṣugbọn tí wọn kò ṣe.”

9 OLUWA tún wí fún mi pé, “Àwọn ọmọ Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ń dìtẹ̀.

10 Wọ́n ti pada sí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Wọ́n ti bá àwọn ọlọrun mìíràn lọ, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda ti da majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá.

11 Nítorí náà, OLUWA ní, òun óo mú kí ibi ó dé bá wọn, ibi tí wọn kò ní lè bọ́ ninu rẹ̀. Ó ní bí wọ́n tilẹ̀ ké pe òun, òun kò ní fetí sí tiwọn.

12 Ó ní àwọn ìlú Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu yóo ké pe àwọn oriṣa tí wọn ń sun turari sí, ṣugbọn àwọn oriṣa kò ní lè gbà wọ́n lọ́jọ́ ìṣòro.

13 Bí àwọn ìlú ti pọ̀ tó ní ilẹ̀ Juda bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa ibẹ̀ pọ̀ tó. Bákan náà, Jerusalẹmu, bí òpópó ṣe pọ̀ tó ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ náà ni pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun turari sí Baali, tí ó jẹ́ ohun ìtìjú, ṣe pọ̀ tó ninu rẹ̀.

14 “Nítorí náà, má ṣe gbadura fún àwọn eniyan wọnyi. Má sọkún nítorí wọn, má sì bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí n kò ní gbọ́, nígbà tí wọn bá ké pè mí nígbà ìṣòro wọn.

15 “Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi níláti wà ninu ilé mi lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀? Ṣé ọpọlọpọ ẹ̀jẹ́ ati ẹran tí a fi rúbọ lè mú kí ibi rékọjá rẹ̀? Ṣé ó lè máa yọ̀ nígbà náà?

16 Nígbà kan rí, OLUWA pè ọ́ ní igi olifi eléwé tútù, tí èso rẹ̀ dára; ṣugbọn pẹlu ìró ìjì ńlá, yóo dáná sun ún, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ yóo sì jóná.

17 OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.”

Ète láti Pa Jeremaya

18 OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi.

19 Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20 Ṣugbọn onídàájọ́ òdodo ni ọ́, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó ń dán ọkàn ati èrò eniyan wò, jẹ́ kí n rí i bí o óo ṣe máa gbẹ̀san lára wọn; nítorí pé ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

21 Nítorí náà, OLUWA sọ nípa àwọn ará Anatoti, tí wọn ń wá ẹ̀mí Jeremaya, tí wọn sì ń sọ fún un pé, “O kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ni a óo pa ọ́.”

22 Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní òun óo jẹ wọ́n níyà; àwọn ọdọmọkunrin wọn yóo kú lójú ogun, ìyàn ni yóo sì pa àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn.

23 Kò ní sí ẹni tí yóo ṣẹ́kù nítorí pé òun óo mú kí ibi dé bá àwọn ará Anatoti, nígbà tí àkókò bá tó tí òun óo jẹ wọ́n níyà.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 12

1 Olódodo ni ọ́, OLUWA,

nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́;

sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ.

Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú?

2 O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò;

wọ́n dàgbà, wọ́n so èso;

orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn,

ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ.

3 Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí,

O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wò

o mọ èrò mi sí ọ.

Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa,

yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun.

4 Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀,

tí koríko oko yóo rọ?

Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀,

àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé,

nítorí àwọn eniyan ń wí pé,

“Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.”

5 OLUWA ní,

“Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́,

báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré?

Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú,

báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani?

6 Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàá

ati àwọn ará ilé baba rẹ

ti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ;

àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ:

Má gbẹ́kẹ̀lé wọn,

bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.”

OLUWA Káàánú Àwọn Eniyan Rẹ̀

7 OLUWA wí pé,

“Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀;

mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀.

Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

8 Ogún mi ti dàbí kinniun inú igbó sí mi,

ó ti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi;

nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.

9 Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni?

Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni?

Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ,

ẹ kó wọn wá jẹun.

10 Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,

wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀,

wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀.

11 Wọ́n sọ ọ́ di ahoro,

ilẹ̀ pàápàá ń ráhùn sí mi.

Wọ́n ti sọ gbogbo ilẹ̀ náà di ahoro,

ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún un.

12 Àwọn apanirun ti dé sí gbogbo àwọn òkè inú pápá,

nítorí pé idà Ọlọrun ni ó ń run eniyan, jákèjádò ilẹ̀ náà;

ẹnikẹ́ni kò ní alaafia,

13 Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè.

Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan.

Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè,

nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.”

Ìlérí OLUWA fún Àwọn Aládùúgbò Israẹli

14 Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn.

15 Lẹ́yìn tí mo bá kó wọn kúrò tán, n óo pada ṣàánú wọn, n óo dá olukuluku pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

16 Nígbà tí ó bá yá, bí wọ́n bá fi tọkàntọkàn kọ́ àṣà àwọn eniyan mi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ mi búra, tí wọn ń wí pé, ‘Bí OLUWA Ọlọrun ti wà láàyè’, bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn eniyan mi láti máa fi orúkọ Baali búra, n óo fi ìdí wọn múlẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi.

17 Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣe àìgbọràn, n óo yọ ọ́ kúrò patapata, n óo sì pa á run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 13

Òwe Aṣọ Funfun

1 OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ ra aṣọ funfun kan, kí o lọ́ ọ mọ́ ìdí, má sì tì í bọ omi rárá.”

2 Mo bá ra aṣọ funfun náà, bí OLUWA ti wí, mo lọ́ ọ mọ́ ìdí.

3 OLUWA tún sọ fún mi lẹẹkeji pé,

4 “Dìde, mú aṣọ funfun tí o rà, tí o lọ́ mọ́ ìdí, lọ sí odò Yufurate, kí o lọ fi pamọ́ sí ihò àpáta níbẹ̀.”

5 Mo bá lọ fi pamọ́ sí ẹ̀bá odò Yufurate bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi.

6 Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, OLUWA sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí odò Yufurate kí o mú aṣọ tí mo ní kí o fi pamọ́ sibẹ wá.”

7 Mo bá lọ sí ẹ̀bá odò Yufurate; mo gbẹ́ ilẹ̀, mo yọ aṣọ funfun náà jáde kúrò ní ibi tí mo bò ó mọ́. Ó ti bàjẹ́; kò sì wúlò fún ohunkohun mọ́.

8 OLUWA sọ fún mi pé,

9 “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo ṣe sọ ògo Juda ati ti Jerusalẹmu di ìbàjẹ́.

10 Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun.

11 Bí aṣọ ìlọ́dìí tií lẹ̀ mọ́ ọkunrin lára, bẹ́ẹ̀ ni mo mú kí gbogbo ilé Israẹli ati gbogbo ilé Juda súnmọ́ mi, kí wọ́n lè jẹ́ eniyan mi, ati orúkọ mi, ìyìn mi, ati ògo mi. Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.”

Ìkòkò Waini

12 OLUWA ní, “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún.’ Wọn yóo dá ọ lóhùn pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún ni?’

13 Ìwọ wá wí fún wọn pé, èmi OLUWA ní n óo rọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí ní ọtí àrọyó, ati àwọn ọba tí wọn jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

14 N óo máa sọ wọ́n lu ara wọn. Baba ati ọmọ yóo máa kọlu ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní ṣàánú wọn, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yọ́nú sí wọn débi pé kí n má fẹ́ pa wọ́n run.”

Jeremaya ṣe Ìkìlọ̀ nípa Ìgbéraga

15 Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́,

ẹ má gbéraga nítorí pé OLUWA ló sọ̀rọ̀.

16 Ẹ fi ògo fún OLUWA Ọlọrun yín kí ó tó mú òkùnkùn ṣú.

Kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ kọ lórí òkè,

níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀.

Nígbà tí ẹ bá ń wá ìmọ́lẹ̀,

yóo sọ ọ́ di ìṣúdudu,

yóo sọ ọ́ di òkùnkùn biribiri.

17 Ṣugbọn bí ẹ kò bá ní gbọ́,

ọkàn mi yóo sọkún níkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín.

N óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,

omi yóo sì máa dà lójú mi,

nítorí a ti kó agbo OLUWA ní ìgbèkùn.

18 Wí fún ọba ati ìyá ọba pé,

“Ẹ sọ̀kalẹ̀ lórí ìtẹ́ yín,

nítorí adé yín tí ó lẹ́wà ti ṣí bọ́ sílẹ̀ lórí yín.”

19 Wọ́n ti sé ìlẹ̀kùn odi àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbu

kò sì sí ẹni tí yóo ṣí wọn.

A ti kó gbogbo Juda lọ sí ìgbèkùn,

gbogbo wọn pátá ni a ti kó lọ.

20 Ẹ gbé ojú sókè,

kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá.

Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà,

àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà?

21 Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́,

tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí?

Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí?

22 Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé,

“Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?”

Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín,

tí a sì jẹ yín níyà.

23 Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣiyí àwọ̀ ara rẹ̀ pada?

Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù?

Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere;

ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára.

24 N óo fọn yín ká bí ìyàngbò

tí afẹ́fẹ́ láti inú aṣálẹ̀ ń fẹ́ kiri.

25 Èyí ni ìpín yín,

ìpín tí mo ti yàn fun yín,

nítorí pé ẹ ti gbàgbé èmi OLUWA, ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ọlọrun èké.

26 Èmi gan-an ni n óo ká aṣọ lára yín,

n óo sì fi bò yín lójú, kí ayé lè rí ìhòòhò yín.

27 Mo ti rí ìwà ìbàjẹ́ yín,

gbogbo ìwà àgbèrè yín, bí ẹ tí ń yan ká bí akọ ẹṣin,

ati ìwà ìṣekúṣe yín ní orí àwọn òkè ninu pápá.

Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gbé!

Yóo ti pẹ́ tó kí á tó wẹ̀ yín mọ́?

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 14

Ọ̀gbẹlẹ̀ Ńlá

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Jeremaya nípa ọ̀gbẹlẹ̀ nìyí:

2 “Juda ń ṣọ̀fọ̀,

àwọn ẹnubodè ìlú rẹ̀ wà ninu ìnira.

Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń sọkún ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀,

igbe àwọn ará Jerusalẹmu sì ta sókè.

3 Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi,

àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi.

Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo,

ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn,

wọ́n káwọ́ lérí.

4 Nítorí ilẹ̀ tí ó gbẹ,

nítorí òjò tí kò rọ̀ ní ilẹ̀ náà,

ojú ti àwọn àgbẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí.

5 Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,

nítorí kò sí koríko.

6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè,

wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko.

Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko.

7 Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé,

‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa,

sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá.

Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ,

a ti ṣẹ̀ ọ́.

8 Ìwọ ìrètí Israẹli,

olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro.

Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà?

Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?

9 Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá;

bí alágbára tí kò lè gbani là?

Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA,

a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá,

má fi wá sílẹ̀.’ ”

10 OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé,

“Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri,

wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn;

nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA,

nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn,

yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

11 OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia.

12 Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.”

13 Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.”

14 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ.

15 Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run.

16 Wọn óo gbé àwọn eniyan tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún sọ síta ní òkú ní ìgboro Jerusalẹmu, nígbà tí ìyàn ati ogun bá pa wọ́n tán. Kò ní sí ẹni tí yóo sin òkú wọn, ati ti àwọn iyawo wọn, ati ti àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. N óo da ibi tí wọ́n ṣe lé wọn lórí.”

17 OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé,

‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru,

kí ó má dáwọ́ dúró,

nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi.

18 Bí mo bá jáde lọ sí ìgbèríko,

àwọn tí wọ́n fi idà pa ni wọ́n kún bẹ̀!

Bí mo bá sì wọ ààrin ìlú,

àwọn tí ìyàn di àìsàn sí lára ni wọ́n kún bẹ̀.

Nítorí àwọn wolii ati àwọn alufaa ń lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà,

wọn kò sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.’ ”

Àwọn Eniyan náà Bẹ OLUWA

19 OLUWA, ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ patapata ni?

Àbí Sioni ti di ohun ìríra lọ́kàn rẹ?

Kí ló dé tí o fi lù wá,

tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tiwa kọjá ìwòsàn?

À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé.

À ń retí àkókò ìwòsàn, ṣugbọn ìpayà ni a rí.

20 OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa,

ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa,

nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.

21 Má ta wá nù nítorí orúkọ rẹ,

má sì fi àbùkù kan ìtẹ́ rẹ tí ó lógo.

Ranti majẹmu tí o bá wa dá,

ranti, má sì ṣe dà á.

22 Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn,

ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀?

Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò?

OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni?

Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé,

nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 15

Ìparun Yóo Dé Bá Àwọn Ọmọ Juda

1 OLUWA bá tún sọ fún mi pé, “Mose ati Samuẹli ìbáà wá dúró níwájú mi, ọkàn mi kò lè yọ́ sí àwọn eniyan wọnyi. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ!

2 Bí wọ́n bá bi ọ́ pé níbo ni kí àwọn ó lọ, sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní,

‘Àwọn tí wọn yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn,

kì àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n;

àwọn tí wọn yóo kú ikú ogun,

kí ogun pa wọ́n.

Àwọn tí wọn yóo kú ikú ìyàn,

kí ìyàn pa wọ́n;

àwọn tí wọn yóo lọ sí ìgbèkùn,

kí ogun kó wọn lọ.’

3 Oríṣìí ìparun mẹrin ni n óo jẹ́ kí ó dé bá wọn: idà óo pa wọ́n, ajá óo fà wọ́n ya, àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko óo jẹ wọ́n ní àjẹrun.

4 N óo sọ wọ́n di ohun tí ó bani lẹ́rù fún gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, nítorí ohun tí Manase, ọmọ Hesekaya, ọba Juda, ṣe ní Jerusalẹmu.”

5 OLUWA ní,

“Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ta ni yóo ṣàánú yín?

Ta ni yóo dárò yín?

Ta ni yóo ya ọ̀dọ̀ yín, láti bèèrè alaafia yín?

6 Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,

ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín,

tí mo sì pa yín run.

Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi.

7 Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà,

ní ẹnubodè ilẹ̀ náà.

Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn;

mo ti pa àwọn eniyan mi run,

nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn.

8 Mo ti mú kí opó pọ̀ láàrin wọn ju iyanrìn inú òkun lọ.

Mo mú kí apanirun gbógun ti àwọn ìyá àwọn ọdọmọkunrin ní ọ̀sán gangan.

Mo mú kí ìbẹ̀rù ati ìwárìrì já lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

9 Ẹni tí ó bí ọmọ meje ṣe àárẹ̀, ó sì dákú,

oòrùn rẹ̀ wọ̀ lọ́sàn-án gangan.

Ìtìjú ati àbùkù bá a.

N óo jẹ́ kí ọ̀tá fi idà pa àwọn tí wọ́n kù ninu wọn.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jeremaya Ráhùn sí OLUWA

10 Mo gbé! Ìyá mi, kí ló dé tí o bí mi, èmi tí mo di oníjà ati alárìíyànjiyàn láàrin gbogbo ìlú! N kò yá ẹnikẹ́ni lówó, bẹ́ẹ̀ n kò yáwó lọ́wọ́ ẹnìkan, sibẹsibẹ gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣépè lé mi.

11 Kí èpè wọn mọ́ mi, OLUWA, bí n kò bá sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere níwájú rẹ, bí n kò bá gbadura fún àwọn ọ̀tá mi ní àkókò ìyọnu ati ìdààmú wọn.

12 Ǹjẹ́ ẹnìkan lè ṣẹ́ irin, pàápàá, irin ilẹ̀ àríwá tí wọn fi idẹ lú?

13 OLUWA bá dáhùn pé, “Nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, n óo fi ọrọ̀ ati ohun ìṣúra rẹ fún àwọn tí ń kó ìkógun ní gbogbo agbègbè rẹ, láìgba owó lọ́wọ́ wọn.

14 N óo mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò dé rí. Mo ti fi ibinu dá iná kan, ó ti ràn, yóo máa jó ọ, kò sì ní kú laelae.”

15 Mo bá dáhùn pé, “OLUWA, ṣebí ìwọ náà mọ̀? Ranti mi, kí o sì ràn mí lọ́wọ́. Gbẹ̀san mi lára àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni sí mi. Má mú mi kúrò nítorí ojú àánú rẹ. Ranti pé nítorí rẹ ni wọ́n ṣé ń fi mí ṣẹ̀sín.

16 Nígbà tí mo rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nǹkan ayọ̀ ni ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fún mi, ó sì jẹ́ ìdùnnú ọkàn mi. Nítorí orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun.

17 N kò jókòó láàrin àwọn alárìíyá, bẹ́ẹ̀ ni n kò yọ̀. Mo dá jókòó nítorí àṣẹ rẹ, nítorí o ti fi ìrúnú kún ọkàn mi.

18 Kí ló dé tí ìrora mi kò dáwọ́ dúró, tí ọgbẹ́ mi jinlẹ̀, tí ó kọ̀, tí kò san? Ṣé o fẹ́ dá mi lọ́kàn le lásán ni; bí ẹlẹ́tàn odò tíí gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn?”

19 Nítorí náà OLUWA ní, “Bí o bá yipada, n óo mú ọ pada sípò rẹ, o óo sì tún máa ṣe iranṣẹ mi. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ gidi, tí o dákẹ́ ìsọkúsọ, o óo tún pada di òjíṣẹ́ mi. Àwọn ni yóo pada tọ̀ ọ́ wá, o kò ní tọ̀ wọ́n lọ.

20 N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

21 N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, n óo sì rà ọ́ pada lọ́wọ́ àwọn ìkà, aláìláàánú eniyan.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 16

Ìfẹ́ OLUWA ní Ìgbésí Ayé Jeremaya

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “O kò gbọdọ̀ fẹ́ iyawo tabi kí o bímọ ní ibí yìí.

3 Nítorí ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin tí a bí ní ibí yìí, ati nípa ìyá tí ó bí wọn, ati baba tí a bí wọn fún ni pé,

4 àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.

5 “Má wọ ilé tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, má lọ máa kọrin arò, tabi kí o bá wọn kẹ́dùn, nítorí mo ti mú alaafia mi ati ìfẹ́ mi ati àánú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi.

6 Àtàwọn eniyan pataki pataki, ati mẹ̀kúnnù, ni yóo kú ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní rí ẹni sin òkú wọn, kò ní sí ẹni tí yóo sọkún wọn; ẹnìkan kò ní fi abẹ ya ara, tabi kí ẹnìkan fá orí nítorí wọn.

7 Kò ní sí ẹni tí yóo fún ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní oúnjẹ láti tù ú ninu, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò sì ní bu omi fún ẹnìkan mu, nítorí ikú baba tabi ìyá rẹ̀.

8 “O kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí wọ́n ti ń se àsè, má bá wọn jókòó láti jẹ tabi láti mu.

9 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Wò ó! N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní ibí yìí, n óo sì fi òpin sí ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé ati ti ọkọ iyawo. Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ níṣojú yín, ní ìgbà ayé yín.’

10 “Bí o bá sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn eniyan náà tán, bí wọn bá bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú yìí nípa wa? Kí ni a ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni a ṣẹ OLUWA Ọlọrun wa?’

11 Kí o dá wọn lóhùn pé, nítorí pé àwọn baba wọn ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọlọrun mìíràn, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń bọ wọ́n.

12 Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́. Ẹ̀yin gan-an ti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn baba yín lọ, ẹ wò bí olukuluku yín tí ń tẹ̀lé agídí ọkàn rẹ̀, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi.

13 Nítorí náà, n óo gba yín dànù kúrò ní ilẹ̀ yìí; n óo fọn yín dànù bí òkò, sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí. Níbẹ̀ ni ẹ óo ti máa sin oriṣa, tí ẹ óo máa bọ wọ́n tọ̀sán-tòru, nítorí pé n kò ní ṣàánú yín.”

Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn

14 Nítorí náà, OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra mọ́ pé, ‘Bí OLUWA, tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tí ń bẹ,’

15 ṣugbọn wọn yóo máa búra pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ, ẹni tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde láti ilẹ̀ àríwá ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó lé wọn lọ.’ N óo mú wọn pada sórí ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba wọn.”

Ìjìyà Tí ń Bọ̀

16 Ó ní, “Wò ó, n óo ranṣẹ pe ọpọlọpọ apẹja, wọn yóo sì wá kó àwọn eniyan wọnyi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, n óo ranṣẹ sí ọpọlọpọ ọdẹ, wọn yóo sì wá dọdẹ wọn ní orí gbogbo òkè gíga ati àwọn òkè kéékèèké, ati ninu pàlàpálá àpáta.

17 Nítorí pé mò ń wo gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, kò sí èyí tí n kò rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò sápamọ́ fún mi.

18 N óo gbẹ̀san àìdára wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní ìlọ́po meji, nítorí wọ́n ti fi ohun ìríra wọn sọ ilẹ̀ mi di eléèérí. Wọ́n sì ti kó oriṣa ìríra wọn kún ilẹ̀ mi.”

Adura Igbẹkẹle Jeremaya ninu OLUWA

19 OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi,

ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú.

Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ,

láti gbogbo òpin ayé,

wọn yóo máa wí pé:

“Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún,

ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan.

20 Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun?

Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.”

21 OLUWA ní, “Nítorí náà, wò ó, n óo jẹ́ kí wọn mọ̀;

àní sẹ́, n óo jẹ́ kí wọ́n mọ agbára ati ipá mi;

wọn yóo sì mọ̀ pé orúkọ mi ni OLUWA.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 17

Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà Juda

1 OLUWA ní, “Gègé irin ni a fi kọ ẹ̀ṣẹ̀ Juda sílẹ̀ gègé òkúta dayamọndi ni a sì fi kọ ọ́ sí ọkàn yín, ati sí ara ìwo ara pẹpẹ wọn,

2 níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá ń ranti àwọn pẹpẹ yín, ati àwọn oriṣa Aṣera yín, tí ẹ rì mọ́ ẹ̀gbẹ́ gbogbo igi tútù, ati lórí àwọn òkè gíga;

3 ati lórí àwọn òkè ninu pápá. N óo sọ gbogbo ọrọ̀ yín ati gbogbo ohun ìṣúra yín di ìkógun fún àwọn ọ̀tá yín; n óo fi gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín.

4 Ìwà yín yóo mú kí ilẹ̀ tí mo fun yín bọ́ lọ́wọ́ yín; n óo sí sọ yín di ẹrú àwọn ọ̀tá yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò mọ̀rí. Ẹ ti mú kí ibinu mi máa jó bí iná, kò sì ní kú títí lae.”

Oríṣìíríṣìí Ọ̀rọ̀

5 OLUWA ní,

“Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan,

tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀;

tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA.

6 Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀,

nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i.

Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà,

ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.

7 “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,

tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8 Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò,

tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò.

Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé,

nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini.

Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀,

nígbà gbogbo ni yóo sì máa so.

9 “Ọkàn eniyan kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,

ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀;

ta ni ó lè mọ èrò ọkàn eniyan?

10 Èmi OLUWA ni èmi máa ń wádìí èrò eniyan,

tí èmi sì máa ń yẹ ọkàn eniyan wò,

láti san án fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀,

ati gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

11 Bí àparò tíí pa ẹyin ẹlẹ́yin

bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ.

Ọrọ̀ yóo lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ lọ́sàn-án gangan,

nígbẹ̀yìn yóo di òmùgọ̀.

12 Ìtẹ́ ògo tí a tẹ́ sí ibi gíga láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ibi mímọ́ wa.

13 OLUWA, ìwọ ni Israẹli gbójú lé,

ojú yóo ti gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

A óo kọ orúkọ àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ sórí ilẹ̀,

yóo sì parẹ́,

nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA, orísun omi ìyè, sílẹ̀.

Jeremaya Bèèrè fún Ìrànlọ́wọ́ OLUWA

14 Wò mí sàn, OLUWA, ara mi yóo sì dá,

gbà mí, n óo sì bọ́ ninu ewu.

Nítorí pé ìwọ ni mò ń yìn.

15 Wò ó! Wọ́n ń bi mí pé,

“Níbo ni gbogbo ìhàlẹ̀ OLUWA já sí?

Jẹ́ kí ó ṣẹ, kí á rí i!”

16 N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o rán ibi sí wọn,

bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ ọjọ́ ibi fún wọn.

OLUWA, o mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde kò tún lè ṣàjèjì sí ọ.

17 Má di ohun ẹ̀rù fún mi,

nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ ibi.

18 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi,

ṣugbọn kí ojú má tì mí.

Jẹ́ kí ìpayà bá wọn,

ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà.

Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa.

Pípa Ọjọ́ Ìsinmi Mọ́

19 OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ dúró ní ẹnubodè Bẹnjamini níbí, tí àwọn ọba Juda máa ń gbà wọlé, tí wọn sìí gbà jáde; ati ní gbogbo ẹnubodè Jerusalẹmu,

20 kí o wí pé, ‘Ẹ gbọ́ bí OLUWA ti wí, ẹ̀yin ọba Juda, ati gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé.

21 OLUWA ní kí ẹ ṣọ́ra fún ẹ̀mí yín, ẹ má máa ru ẹrù ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ má gbé ẹrù wọ ẹnubodè Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.

22 Ẹ kò gbọdọ̀ ru ẹrù jáde ní ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ẹ níláti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, bí mo ti pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín.

23 Sibẹ àwọn baba yín kò gbọ́; wọn kò sì fetí sílẹ̀, wọ́n ṣe oríkunkun, kí wọn má baà gbọ́, kí wọn má baà gba ìtọ́ni.

24 Ṣugbọn bí ẹ̀yin bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò gbé ẹrù wọ inú ìlú yìí lọ́jọ́ ìsinmi, tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ láìṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà,

25 àwọn ọba tí yóo máa gúnwà lórí ìtẹ́ Dafidi, yóo máa gba ẹnubodè ìlú yìí wọlé. Àwọn ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn ará Juda ati ará ìlú Jerusalẹmu yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọlé. Àwọn eniyan yóo sì máa gbé ìlú yìí títí ayé.

26 Àwọn eniyan yóo máa wá láti gbogbo ìlú Juda ati àwọn agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Bẹnjamini ati pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, láti àwọn agbègbè olókè ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, wọn yóo máa mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ọrẹ wá, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati turari; wọn yóo máa mú ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.

27 Ṣugbọn bí ẹ kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù wọ inú Jerusalẹmu lọ́jọ́ ìsinmi, n óo ṣá iná sí ẹnubodè Jerusalẹmu, yóo jó àwọn ààfin rẹ̀, kò sì ní ṣe é pa.’ ”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 18

Jeremaya nílé Amọ̀kòkò

1 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “Dìde, lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni óo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ.”

3 Mo bá lọ sí ilé amọ̀kòkò. Mo bá a tí ó ń mọ ìkòkò kan lórí òkúta tí wọn fi ń mọ ìkòkò.

4 Ìkòkò tí ó ń fi amọ̀ mọ bàjẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó bá fi amọ̀ náà mọ ìkòkò mìíràn, tí ó wù ú.

5 OLUWA bá sọ fún mi pé,

6 “Ẹ̀yin ilé Israẹli, ṣé n kò lè ṣe yín bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe ìkòkò tí ó mọ ni? Bí amọ̀ ti rí lọ́wọ́ amọ̀kòkò ni ẹ rí lọ́wọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.

7 Bí mo bá sọ pé n óo fa orílẹ̀-èdè kan, tabi ìjọba kan tu, n óo wó o lulẹ̀, n óo sì pa á run,

8 bí orílẹ̀-èdè ọ̀hún bá yipada kúrò ninu ìwà burúkú rẹ̀, n óo dá ibi tí mo ti fẹ́ ṣe sí i tẹ́lẹ̀ dúró.

9 Bí mo bá sọ pé n óo gbé orílẹ̀-èdè kan dìde, n óo sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀;

10 bí ó bá ṣe nǹkan burúkú lójú mi, tí kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, n óo dá nǹkan rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún un dúró.

11 Nítorí náà, sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, èmi OLUWA ní, mò ń pète ibi kan si yín, mo sì ń pinnu rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, kí olukuluku yín yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe; kí ẹ sì tún ìwà ati ìṣe yín ṣe.

12 Ṣugbọn wọ́n ń wí pé, ‘Rárá o, OLUWA kàn ń sọ tirẹ̀ ni, tinú wa ni a óo ṣe, olukuluku yóo máa lo agídí ọkàn rẹ̀.’ ”

Àwọn Eniyan náà kọ OLUWA Sílẹ̀

13 Nítorí náà OLUWA ní,

“Ẹ bèèrè láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè,

bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ irú rẹ̀ rí.

Israẹli ti ṣe ohun tó burú gan-an.

14 Ṣé yìnyín òkè Lẹbanoni a máa dà ní pàlàpálá Sirioni?

Àbí omi tútù tí máa ń ṣàn láti inú òkè rẹ̀ a máa gbẹ?

15 Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti gbàgbé mi,

wọ́n ń sun turari sí oriṣa èké.

Wọ́n ti kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà àtijọ́ tí wọn ń tọ̀,

wọ́n ti yà sí ọ̀nà ojúgbó tí kì í ṣe ojú ọ̀nà tààrà.

16 Wọ́n sọ ilẹ̀ wọn di ohun ẹ̀rù ati ohun àrípòṣé títí lae.

Gbogbo àwọn tí wọn bá gba ibẹ̀ kọjá ni ẹ̀rù yóo máa bà,

tí wọn yóo sì máa mi orí.

17 N óo fọ́n wọn ká níwájú ọ̀tá bí ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn.

Ẹ̀yìn ni n óo kọ sí wọn lọ́jọ́ àjálù,

wọn kò ní rí ojú mi.”

Wọ́n Gbìmọ̀ Ibi sí Jeremaya

18 Wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹ wá, kí á gbìmọ̀ ibi sí Jeremaya, nítorí pé òfin kò ní parun lọ́dọ̀ àwọn alufaa, ìmọ̀ràn kò ní tán lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sì ní ṣàì máa wà lẹ́nu àwọn wolii. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa pa á, ẹ má sì jẹ́ kí á fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kankan.”

19 Mo bá gbadura pe,

“Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA,

kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi.

20 Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere?

Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi.

Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere,

kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn.

21 Nítorí náà ìyàn ni kí ó pa àwọn ọmọ wọn,

kí ogun pa wọ́n,

kí àwọn aya wọn di aláìlọ́mọ ati opó,

kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọkunrin wọn,

kí idà ọ̀tá sì pa àwọn ọ̀dọ̀ wọn lójú ogun.

22 Kí igbe ẹkún ó sọ ninu ilé wọn,

nígbà tí o bá mú àwọn apanirun wá sórí wọn lójijì;

nítorí pé wọ́n wa kòtò láti mú mi,

wọ́n dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi.

23 OLUWA, gbogbo àbá tí wọn ń dá ni o mọ̀,

o mọ gbogbo ète tí wọn ń pa láti pa mí.

Má dárí ìwà ibi wọn jì wọ́n,

má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ níwájú rẹ.

Jẹ́ kí wọn ṣubú níwájú rẹ,

nígbà tí inú bá ń bí ọ ni kí o bá wọn wí.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 19

Ìgò Amọ̀ Tí Ó Fọ́

1 OLUWA ní kí n lọ ra ìgò amọ̀ kan, kí n mú díẹ̀ ninu àwọn àgbààgbà ìlú ati àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn àgbà alufaa,

2 kí n lọ sí ìsàlẹ̀ àfonífojì ọmọ Hinomu, lẹ́nu Ibodè Àpáàdì; kí n sì kéde ọ̀rọ̀ tí òun óo sọ fún mi níbẹ̀:

3 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọba Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ibi kan wá sórí ilẹ̀ yìí, híhó ni etí gbogbo àwọn tí wọn bá gbọ́ nípa rẹ̀ yóo máa hó.

4 Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí.

5 Wọ́n kọ́ pẹpẹ oriṣa Baali, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọkunrin wọn rú ẹbọ sísun sí i. N kò pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa ṣe bẹ́ẹ̀, n kò fún wọn ní irú ìlànà bẹ́ẹ̀; ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ wá sí mi lọ́kàn.

6 Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀, tí a kò ní pe ibí yìí ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́. Àfonífojì ìpànìyàn ni a óo máa pè é.

7 N óo sọ ìmọ̀ àwọn ará Juda ati ti àwọn ará ìlú Jerusalẹmu di òfo, n óo jẹ́ kí àwọn ọ̀tá wọn ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn fi idà pa wọ́n. N óo sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.

8 N óo sì sọ ìlú yìí di ohun ẹ̀rù ati àrípòṣé, ẹ̀rù ìlú náà yóo sì máa ba gbogbo ẹni tí ó bá kọjá níbẹ̀, wọn yóo máa pòṣé nítorí àjálù tí ó dé bá a.

9 N óo mú kí wọn máa pa ọmọ wọn ọkunrin ati obinrin jẹ. Olukuluku yóo máa pa aládùúgbò rẹ̀ jẹ nítorí ìdààmú tí àwọn ọ̀tá wọn, ati àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn yóo kó bá wọn, nígbà tí ogun bá dótì wọ́n.”

10 OLUWA ní lẹ́yìn náà kí n fọ́ ìgò amọ̀ náà ní ojú àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi,

11 kí n sì sọ fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí ẹni fọ́ ìkòkò amọ̀ ni n óo ṣe fọ́ àwọn eniyan yìí ati ìlú yìí, kò sì ní ní àtúnṣe mọ́. Ní Tofeti ni wọn yóo máa sin òkú sí nígbà tí wọn kò bá rí ààyè sin òkú sí mọ́.

12 Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ìlú yìí ati àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀. Bíi Tofeti ni n óo ṣe ìlú náà; Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13 Àwọn ilé Jerusalẹmu ati àwọn ààfin ọba Juda, gbogbo ilé tí wọn ń sun turari sí àwọn ogun ọ̀run lórí òrùlé wọn, tí wọn sì ti rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa mìíràn, gbogbo wọn ni yóo di aláìmọ́ bíi Tofeti.”

14 Nígbà tí Jeremaya pada dé láti Tofeti, níbi tí OLUWA rán an lọ pé kí ó lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ilé OLUWA, ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n péjọ sibẹ pé,

15 “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘N óo mú kí ibi tí mo ti kéde rẹ̀ dé bá ìlú yìí ati àwọn ìlú tí wọn yí i ká, nítorí wọ́n ti ṣe oríkunkun, wọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.’ ”