Categories
JEREMAYA

JEREMAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Wolii Jeremaya ṣiṣẹ́ ìyìn rere rẹ̀ láàrin ẹgbẹta ọdún ó lé bíi ọdún mẹẹdọgbọn sí ẹgbẹta ọdún ó dín bíi ọdún mẹẹdogun kí á tó bí OLUWA wa (625 sí 585 B.C.) Ní àkókò rẹ̀, ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan nípa irú àjálù ńlá tí yóo dé bá wọn nítorí ìwà ìbọ̀rìṣà ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìran tí ó rí sí wọn ṣẹ nígbà ayé rẹ̀, Nebukadinesari ọba Babiloni ko àwọn ará Jerusalẹmu lẹ́rú, wọ́n dáná sun Jerusalẹmu ati Tẹmpili, wọ́n sì kó ọba Juda ati ọpọlọpọ eniyan lẹ́rú. Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé wọn yóo dá wọn sílẹ̀ lóko ẹrú, wọn yóo dá wọn pada wálé, orílẹ̀-èdè náà yóo sì pada bọ̀ sípò.

A lè pín

Ìwé Jeremaya

sí ọ̀nà bíi marun-un: (1) Ìpè Jeremaya (2) Àwọn iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí orílẹ̀-èdè Juda ati àwọn olórí ní àkókò ìjọba Josaya, Jehoiakimu, Jehoiakini ati Sedekaya. (3) Àwọn àkọsílẹ̀ Baruku, tí ó jẹ́ akọ̀wé Jeremaya, pẹlu ọpọlọpọ àkọsílẹ̀ ìran ati ìṣẹ̀lẹ̀ pataki pataki tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wolii Jeremaya. (4) Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. (5) Ìtàn ìṣubú Jerusalẹmu ati bí wọn ṣe kó àwọn ará orílẹ̀-èdè náà lọ sí oko ẹrú ní Babiloni, ni wọ́n fi parí ìwé yìí.

Jeremaya jẹ́ onífura eniyan, tí ó nífẹ̀ẹ́ àwọn eniyan rẹ̀, tí kì í sìí fẹ́ dájọ́ ìjìyà fún àwọn eniyan rẹ̀. Ó mẹ́nuba àwọn ìṣòro tí ó dojú kọ nítorí pípè tí Ọlọrun pè é láti wá ṣe iṣẹ́ wolii. Ọ̀rọ̀ OLUWA ń jó o lọ́kàn bí iná, nítorí náà, kò lè ṣàì jíṣẹ́ tí OLUWA rán an.

Ọpọlọpọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí ni ó tọ́ka sí àkókò ọjọ́ iwájú, tí majẹmu tuntun yóo wáyé, tí àwọn eniyan Ọlọrun yóo máa tẹ̀lé, wọn kò ní retí, pé kí olùkọ́ kan máa kọ́ wọn, kàkà bẹ́ẹ̀ oókan àyà wọn ni wọn yóo fi majẹmu náà sí. Ìgbé-ayé ìgbà náà yóo yàtọ̀ sí àkókò tí Jeremaya ati àwọn eniyan rẹ̀ ń kojú ìṣòro (31.31-34).

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ìpè Jeremaya 1:1-19

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ní àkókò ìjọba Josaya, Jehoiakimu, Jehoiakini ati Sedekaya 2:1–25:38

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ nígbà ayé Jeremaya 26:1–45:5

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìjìyà àwọn orílẹ̀ èdè 46:1–51:64

Ìṣubú Jerusalẹmu 52:1-34

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 1

1 Ọ̀rọ̀ Jeremaya, ọmọ Hilikaya, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí ó wà ní Anatoti, ní ilẹ̀ Bẹnjamini nìyí.

2 Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀.

3 Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà.

Ọlọrun Pe Jeremaya

4 OLUWA sọ fún mi pé,

5 “Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́,

kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀,

mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.”

6 Mo bá dáhùn pé,

“Háà! OLUWA Ọlọrun!

Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.”

7 Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní,

“Má pe ara rẹ ní ọmọde,

nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ.

Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ.

8 Má bẹ̀rù wọn,

nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.”

9 OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé,

“Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu.

10 Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí,

láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀,

láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú,

láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.”

Ìran Meji

11 OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?”

Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.”

12 OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.”

13 OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?”

Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.”

14 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà.

15 Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda.

16 N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe.

17 Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn.

18 Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ìlú tí a mọ odi yíká lónìí, o di òpó irin ati ògiri tí a fi bàbà mọ fún gbogbo ilẹ̀ yìí, ati fún àwọn ọba ilẹ̀ Juda, àwọn ìjòyè, ati àwọn alufaa rẹ̀, ati àwọn eniyan ilẹ̀ náà.

19 Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ. Nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́ kalẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 2

Ìtọ́jú Ọlọrun lórí Israẹli

1 OLUWA sọ fún mi pé,

2 “Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí.

3 Israẹli jẹ́ mímọ́ fún OLUWA

Òun ni àkọ́so èso rẹ̀.

Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ninu àkọ́so èso yìí di ẹlẹ́bi;

ibi sì dé bá wọn.

Èmi OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Baba Ńlá Israẹli

4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ilé Jakọbu, ati gbogbo ìdílé Israẹli.

5 OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán?

6 Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà,

ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti,

tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já,

ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun,

ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri,

ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá,

tí ẹnikẹ́ni kì í gbé?

7 Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá,

pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀,

ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́,

ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.

8 Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’

Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí,

àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi,

àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali,

wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn.

OLUWA fi Ẹ̀sùn Kan Àwọn Eniyan Rẹ̀

9 “Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́,

n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.”

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

10 Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká,

tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní,

bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí.

11 Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́?

Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn,

wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀.

12 Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run,

kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.”

13 OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji:

wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀,

wọ́n ṣe kànga fún ara wọn;

kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró.

Èrè Aiṣododo Israẹli

14 “Ṣé ẹrú ni Israẹli ni,

àbí ọmọ ẹrú tí ẹrú bí sinu ilé?

Báwo ló ṣe wá di ìjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15 Àwọn kinniun ti bú mọ́ ọn,

wọ́n bú ramúramù.

Wọ́n sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro.

Àwọn ìlú rẹ̀ sì ti tú, wọ́n ti wó palẹ̀,

láìsí eniyan tí ń gbé inú wọn.

16 Bákan náà, àwọn ará Memfisi ati Tapanhesi ti fọ́ adé orí rẹ̀.

17 Ṣebí ọwọ́ ara yín ni ẹ fi fà á sí orí ara yín,

nígbà tí ẹ̀yin kọ Ọlọrun yín sílẹ̀,

nígbà tí ó ń tọ yín sọ́nà?

18 Kí ni èrè tí ẹ rí nígbà tí ẹ lọ sí Ijipti,

tí ẹ lọ mu omi odò Naili,

àbí kí ni èrè tí ẹ gbà bọ̀ nígbà tí ẹ lọ sí Asiria,

tí ẹ lọ mu omi odò Yufurate.

19 Ìwà burúkú yín yóo fìyà jẹ yín,

ìpadà sẹ́yìn yín yóo sì kọ yín lọ́gbọ́n.

Kí ó da yín lójú pé,

nǹkan burúkú ni, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kò sì ní dùn,

pé ẹ fi èmi OLUWA Ọlọrun yín sílẹ̀;

ìbẹ̀rù mi kò sí ninu yín.

Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Israẹli Kọ̀ láti Sin OLUWA

20 OLUWA wí pé,

“Nítorí pé ó ti pẹ́ tí ẹ ti bọ́ àjàgà yín,

tí ẹ sì ti tú ìdè yín;

tí ẹ sọ pé, ẹ kò ní sìn mí.

Ẹ̀ ń lọ káàkiri lórí gbogbo òkè,

ati lábẹ́ gbogbo igi tútù;

ẹ̀ ń foríbalẹ̀, ẹ̀ ń ṣe bíi panṣaga.

21 Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́,

tí èso rẹ̀ dára.

Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata,

tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò?

22 Bí ẹ tilẹ̀ fi eérú fọ ara yín,

tí ẹ sì fi ọpọlọpọ ọṣẹ wẹ̀,

sibẹ, àbààwọ́n ẹ̀bi yín wà níwájú mi.

23 Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́;

ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali?

Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì,

kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣe

bí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀;

tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀.

24 Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára,

tí ń ṣí imú kiri,

nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún.

Ta ló lè dá a dúró?

Kí akọ tí ó bá ń wá a

má wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala,

nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó.

25 Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli,

má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́.

Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí,

nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́,

n óo sì wá wọn kiri.’ ”

Ó Tọ́ kí Israẹli Jìyà

26 OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́,

bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín,

ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín;

27 ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín,

tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín;

nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi,

ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi.

Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín,

ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là.

28 “Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà?

Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín!

Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda.

29 Ẹjọ́ kí ni ẹ wá ń bá mi rò?

Ṣebí gbogbo yín ni ẹ̀ ń bá mi ṣọ̀tẹ̀!

30 Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni,

wọn kò gba ẹ̀kọ́.

Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun,

bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.

31 Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ.

Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli;

tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri?

Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé,

‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri;

a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’

32 Ṣé ọmọbinrin lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀?

Tabi iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lè gbàgbé àwọn aṣọ rẹ̀?

Sibẹ ẹ ti gbàgbé mi tipẹ́.

33 “Ẹ mọ oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí eniyan fi í wá olólùfẹ́ kiri,

tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ ti fi ìrìnkurìn yín

kọ́ àwọn obinrin oníwà burúkú.

34 Ẹ̀jẹ̀ àwọn talaka tí kò ṣẹ̀, wà létí aṣọ yín;

bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bá wọn níbi tí wọ́n ti ń fọ́lé.

Gbogbo èyí wà bẹ́ẹ̀,

35 sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọwọ́ wa mọ́;

dájúdájú, OLUWA ti dá ọwọ́ ibinu rẹ̀ dúró lára wa.’

Ẹ wò ó! N óo dá yín lẹ́jọ́,

nítorí ẹ̀ ń sọ pé ẹ kò dẹ́ṣẹ̀.

36 Ẹ̀ ń fi ara yín wọ́lẹ̀ káàkiri;

ẹ̀ ń yà síhìn-ín sọ́hùn-ún!

Bí Asiria ti dójú tì yín,

bẹ́ẹ̀ ni Ijipti náà yóo dójú tì yín.

37 Ẹ óo ká ọwọ́ lérí ni

nígbà tí ẹ óo bá jáde níbẹ̀.

Nítorí OLUWA ti kọ àwọn tí ẹ gbójúlé,

wọn kò sì ní ṣe yín níre.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 3

Israẹli Alaiṣododo

1 OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀,

tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ,

tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn,

ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada?

Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́?

Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́;

ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi?

2 Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká,

ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé?

Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà,

bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀.

Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́.

3 Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀,

tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ.

Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó,

ojú kò sì tì yín.

4 Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé,

‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.

5 Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni?

Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’

Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀,

ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.”

Israẹli ati Juda Gbọdọ̀ Ronupiwada

6 OLUWA sọ fún mi ní ìgbà ayé ọba Josaya pé: “Ṣé o rí ohun tí Israẹli, alaiṣootọ ẹ̀dá ṣe? Ṣé o rí i bí ó tí ń lọ ṣe àgbèrè lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ gbogbo igi tútù?

7 Mo rò pé yóo pada tọ̀ mí wá, lẹ́yìn tí ó bá ṣe àgbèrè rẹ̀ tán ni; ṣugbọn kò pada; Juda arabinrin rẹ̀, alaiṣootọ sì rí i,

8 ó mọ̀ pé nítorí ìwà àgbèrè Israẹli, alaiṣootọ, ni mo ṣe lé e jáde, tí mo sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Sibẹsibẹ Juda tí òun pàápàá jẹ́ alaiṣootọ, kò bẹ̀rù, òun náà lọ ṣe àgbèrè.

9 Nítorí pé ìwà àgbèrè jẹ́ nǹkan kékeré lójú rẹ̀, ó ṣe àgbèrè pẹlu òkúta ati igi ó sì ba ilẹ̀ náà jẹ́.

10 Sibẹsibẹ, lẹ́yìn gbogbo èyí, Juda arabinrin rẹ̀, ọ̀dàlẹ̀, kò fi tọkàntọkàn pada tọ̀ mí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ayé ni wọ́n ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

11 Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún mi pé, “Israẹli jẹ̀bi, aiṣootọ, ṣugbọn kò tíì tó ti Juda, ọ̀dàlẹ̀.

12 Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé:

‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí.

N kò ní máa bínú lọ títí lae.

13 Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi,

ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ.

O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa,

lábẹ́ gbogbo igi tútù;

o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’

14 “Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.

15 N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín.

16 Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀

17 Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́.

18 Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.”

Ìbọ̀rìṣà Àwọn Eniyan Ọlọrun

19 OLUWA ní,

“Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi,

tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára,

kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù,

láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.

Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ,

ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi.

20 Dájúdájú bí obinrin alaiṣootọ tíí fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni o ti ṣe alaiṣootọ sí mi, ìwọ Israẹli.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

21 A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga,

ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni.

Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn;

wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn.

22 Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ,

n óo mú aiṣootọ yín kúrò.

“Wò wá! A wá sọ́dọ̀ rẹ,

nítorí ìwọ ni OLUWA Ọlọrun wa.

23 Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè,

ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀;

dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà.

24 Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìí

ti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run:

ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn,

àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin.

25 Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá,

nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa;

àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa,

a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 4

Ìpè sí Ìrònúpìwàdà

1 OLUWA ní, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, bí ẹ bá fẹ́ yipada, ọ̀dọ̀ mi ni kí ẹ pada sí. Mo kórìíra ìbọ̀rìṣà; nítorí náà bí ẹ bá jáwọ́ ninu rẹ̀, tí ẹ kò bá ṣìnà kiri mọ́,

2 tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.”

3 Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún.

4 Ẹ kọ ara yín ní ilà abẹ́ fún OLUWA, kí ẹ sì kọ ara yín ní ilà ọkàn, ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu; kí ibinu mi má baà dé, bí iná tí ó ń jó tí kò sí ẹni tí ó lè pa á, nítorí iṣẹ́ ibi yín.”

A fi Ogun Halẹ̀ mọ́ Juda

5 Ẹ sọ ọ́ ní Juda,

ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé,

“Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà,

kí ẹ sì kígbe sókè pé,

‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’

6 Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni,

pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró,

nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá.

7 Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà;

ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra;

ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀,

láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro.

Yóo pa àwọn ìlú yín run,

kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́.

8 Nítorí èyí, ẹ fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,

ẹ sọkún kí ẹ máa ké tẹ̀dùntẹ̀dùn,

nítorí ìrúnú gbígbóná OLUWA

kò tíì yipada kúrò lọ́dọ̀ wa.”

9 OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.”

10 Mo bá dáhùn pé, “Háà, OLUWA Ọlọrun, àṣé ò ń tan àwọn eniyan wọnyi, ati àwọn ará Jerusalẹmu ni, nígbà tí o sọ fún wọn pé, yóo dára fún wọn; àṣé idà ti dé ọrùn wọn!”

11 A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù.

12 Ìjì tí yóo ti ọ̀dọ̀ mi wá yóo le jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nisinsinyii èmi ni mò ń fi ọ̀rọ̀ mi dá wọn lẹ́jọ́.

Àwọn Ọ̀tá yí Juda Ká

13 Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu,

kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì.

Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ.

A gbé, nítorí ìparun dé bá wa.

14 Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ,

kí á lè gbà ọ́ là.

Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ?

15 Nítorí a gbọ́ ohùn kan láti ilẹ̀ Dani,

tí ń kéde ibi láti òkè Efuraimu.

16 Ẹ kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé ó ń bọ̀,

kéde fún Jerusalẹmu pé,

àwọn ológun tí ń dó ti ìlú ń bọ̀, láti ilẹ̀ òkèèrè.

Wọ́n ń kọ lálá sí àwọn ìlú Juda.

17 Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko,

nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA.

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

18 Ìrìn ẹsẹ̀ rẹ ati ìwà rẹ

ni ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá ọ.

Ìjìyà rẹ nìyí, ó sì korò;

ó ti dé oókan àyà rẹ.

Ìbànújẹ́ Jeremaya nítorí Àwọn Eniyan Rẹ̀

19 Oró ò! Oró ò!

Mò ń jẹ̀rora!

Àyà mi ò!

Àyà mi ń lù kìkìkì,

n kò sì lè dákẹ́;

nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun.

20 Àjálù ń ṣubú lu àjálù,

gbogbo ilẹ̀ ti parun.

Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀,

aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan.

21 Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun,

tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun?

22 OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀,

wọn kò mọ̀ mí.

Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n;

wọn kò ní òye.

Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn:

ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.”

Ìran tí Jeremaya Rí nípa Ìparun Tí Ń Bọ̀

23 Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo,

ó rí júujùu;

mo ṣíjú wo ojú ọ̀run,

kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.

24 Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì,

gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún.

25 Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan,

gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ.

26 Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀,

gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA,

nítorí ibinu ńlá rẹ̀.

27 Nítorí OLUWA ti sọ pé,

gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro;

sibẹ òpin kò ní tíì dé.

28 Nítorí èyí, ilẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀,

ojú ọ̀run yóo sì ṣókùnkùn.

Nítorí pé ó ti sọ bẹ́ẹ̀,

ó ti rò ó dáradára, kò tíì jáwọ́ ninu rẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni kò ní yipada.

29 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin ati ti àwọn tafàtafà,

gbogbo ìlú sá jáde fún ààbò.

Wọ́n sá wọ inú igbó lọ,

wọ́n gun orí òkè lọ sinu pàlàpálá òkúta;

gbogbo ìlú sì di ahoro.

30 Ìwọ tí o ti di ahoro,

kí ni èrò rẹ tí o fi wọ aṣọ elése àlùkò?

Tí o wa nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà sára?

Tí o tọ́ ojú?

Tí o tọ́ ètè?

Asán ni gbogbo ọ̀ṣọ́ tí o ṣe,

àwọn olólùfẹ́ rẹ kò kà ọ́ sí,

ọ̀nà ati gba ẹ̀mí rẹ ni wọ́n ń wá.

31 Nítorí mo gbọ́ igbe kan, tí ó dàbí igbe obinrin tí ó ń rọbí,

ó ń kérora bí aboyún tí ó ń rọbí alákọ̀ọ́bí.

Mo gbọ́ igbe Jerusalẹmu tí ń pọ̀ọ̀kà ikú,

tí ó na ọwọ́ rẹ̀ síta, tí ń ké pé,

“Mo gbé! Mò ń kú lọ, lọ́wọ́ àwọn apànìyàn!”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 5

1 Máa sáré lọ, sáré bọ̀ ní àwọn òpópónà Jerusalẹmu,

wò yíká, kí o sì ṣàkíyèsí rẹ̀!

Wo àwọn gbàgede rẹ̀, bóyá o óo rí ẹnìkan,

tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo,

tí ó sì ń fẹ́ òtítọ́,

tí mo fi lè torí rẹ̀ dáríjì Jerusalẹmu.

2 Lóòótọ́ ni wọ́n ń fi orúkọ mi búra pé, “Bí OLUWA tí ń bẹ,”

sibẹ èké ni ìbúra wọn.

3 OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́?

Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n,

o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,

ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí.

Ojú wọn ti dá, ó le koko,

wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada.

4 Nígbà náà ní mo wí lọ́kàn ara mi pé,

“Àwọn aláìní nìkan nìwọ̀nyí,

wọn kò gbọ́n;

nítorí wọn kò mọ ọ̀nà OLUWA,

ati òfin Ọlọrun wọn.

5 N óo lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan pataki pataki,

n óo sì bá wọn sọ̀rọ̀;

nítorí àwọn mọ ọ̀nà OLUWA,

ati òfin Ọlọrun wọn.”

Ṣugbọn gbogbo wọn náà ni wọ́n ti fa àjàgà wọn dá,

tí wọ́n sì ti kọ àṣẹ ati àkóso OLUWA.

6 Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀.

Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run.

Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn,

tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú,

yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.

Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀,

nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun.

7 OLUWA bi Israẹli pé,

“Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́?

Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,

wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra.

Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán,

wọ́n ṣe àgbèrè,

wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè.

8 Wọ́n dàbí akọ ẹṣin tí a kò tẹ̀ lọ́dàá, tí ó yó,

olukuluku wọn ń lé aya aládùúgbò rẹ̀ kiri.

9 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?

Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?

10 Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run,

ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán.

Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,

nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA.

11 Nítorí pé ilé Israẹli ati ilé Juda ti ṣe alaiṣootọ sí mi.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ọlọrun kọ Israẹli sílẹ̀

12 Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA,

wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan;

ibi kankan kò ní dé bá wa,

bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.”

13 Àwọn wolii yóo di àgbá òfo;

nítorí kò sí ọ̀rọ̀ OLUWA ninu wọn.

Bí wọ́n ti wí ni ọ̀rọ̀ yóo rí fún wọn.

14 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní,

“Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí,

wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ.

N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi,

iná yóo sì jó wọn run.

15 Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli,

mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè,

tí yóo ba yín jà.

Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà,

orílẹ̀-èdè alágbára ni.

Ẹ kò gbọ́ èdè wọn,

ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ.

16 Apó ọfà wọn dàbí isà òkú tó yanu sílẹ̀,

alágbára jagunjagun ni gbogbo wọn.

17 Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ,

wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ,

wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin.

Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín,

ati àwọn mààlúù yín.

Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín.

Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.”

18 OLUWA ní, “Ṣugbọn sibẹ, ní gbogbo àkókò yìí, n kò ní pa yín run patapata,

19 nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.”

Ọlọrun Kìlọ̀ fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

20 OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu,

sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda:

21 Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n,

ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran;

ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn.

22 Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín?

Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè.

Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.

Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun,

tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé!

Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan,

kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.

23 Ṣugbọn ọkàn ẹ̀yin eniyan wọnyi le, ọlọ̀tẹ̀ sì ni yín.

Ẹ ti yapa, ẹ sì ti ṣáko lọ.

24 Ẹ kò sì rò ó lọ́kàn yín, kí ẹ wí pé:

‘Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wa,

tí ó ń fún wa ní òjò lákòókò rẹ̀,

ati òjò àkọ́rọ̀ ati àrọ̀kẹ́yìn;

OLUWA tí ó ń bá wa mú ọjọ́ ìkórè lọ́wọ́,

tí kì í jẹ́ kí àsìkò ìkórè ó yẹ̀.’

25 Àìdára yín ti yí ìgbà wọnyi pada,

ẹ̀ṣẹ̀ yín ti dínà ohun rere fun yín.

26 “Àwọn eniyan burúkú wà láàrin àwọn eniyan mi,

wọ́n ń dọdẹ eniyan bí ẹni dọdẹ ẹyẹ,

wọ́n dẹ tàkúté, wọ́n fi ń mú eniyan.

27 Ilé wọn kún fún ìwà ọ̀dàlẹ̀,

bíi kùùkú tí ó kún fún ẹyẹ.

Nítorí èyí, wọ́n di eniyan ńlá,

wọ́n di olówó,

28 wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán.

Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà.

Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba,

kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà;

wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní,

kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́.

29 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?

Kí n má gbẹ̀san ara mi, lára irú orílẹ̀-èdè yìí?

30 Nǹkan burúkú tó yani lẹ́nu,

ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:

31 Àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,

àwọn alufaa ń sọ ọ̀rọ̀ èké àwọn wolii di òfin,

àwọn eniyan mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.

Ṣugbọn kí ni wọ́n óo ṣe nígbà tí òpin bá dé?”

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 6

Àwọn Ọ̀tá Yí Jerusalẹmu Ká

1 Ẹ̀yin ọmọ Bẹnjamini, ẹ sá àsálà!

Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu.

Ẹ fọn fèrè ogun ní Tekoa,

kí ẹ ṣe ìkìlọ̀ fún wọn ní Beti Hakikeremu,

nítorí pé nǹkan burúkú

ati ìparun ńlá ń bọ̀ láti ìhà àríwá.

2 Jerusalẹmu, Ìlú Sioni dára, ó sì lẹ́wà,

ṣugbọn n óo pa á run.

3 Àwọn ọba ati àwọn ọmọ ogun wọn yóo kọlù ú,

wọn yóo pa àgọ́ yí i ká,

ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan yóo pàgọ́ sí ibi tí ó wù ú.

4 Wọn yóo sì wí pé, “Ẹ múra kí á bá a jagun;

ẹ dìde kí á lè kọlù ú lọ́sàn-án gangan!”

Wọn óo tún sọ pé, “A gbé! Nítorí pé ọjọ́ ti lọ,

ilẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣú!

5 Ẹ dìde kí á lè kọlù ú, lóru;

kí á wó àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀!”

6 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀tá pé:

“Ẹ gé àwọn igi tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀;

kí ẹ fi mọ òkítì kí ẹ sì dótì í.

Dandan ni kí n fi ìyà jẹ ìlú náà,

nítorí kìkì ìwà ìninilára ló kún inú rẹ̀.

7 Bí omi ṣé ń sun jáde ninu kànga,

bẹ́ẹ̀ ni ibi ń sun ní Jerusalẹmu.

Ìròyìn ìwà ipá ati ti jàgídíjàgan ń kọlura wọn ninu rẹ̀,

àìsàn ati ìpalára ni à ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.

8 Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín,

bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà,

n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro,

ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.”

Israẹli Ọlọ̀tẹ̀

9 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:

“Ẹ ṣa àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ,

bí ìgbà tí eniyan bá ń ṣa èso àjàrà tókù lẹ́yìn ìkórè.

Tún dá ọwọ́ pada sẹ́yìn, kí o fi wọ́ ara àwọn ẹ̀ka,

bí ẹni tí ń ká èso àjàrà.”

10 Mo ní, “Ta ni kí n bá sọ̀rọ̀, tí yóo gbọ́?

Ta ni kí n kìlọ̀ fún tí yóo gbà?

Etí wọn ti di, wọn kò lè gbọ́ràn mọ́.

Ọ̀rọ̀ OLUWA ń rùn létí wọn,

wọn kò fẹ́ gbọ́ mọ́.

11 Ibinu ìwọ OLUWA mú kí inú mi máa ru,

ara mi kò sì gbà á mọ́.”

OLUWA bá sọ fún mi pé,

“Tú ibinu mi dà sórí àwọn ọmọde ní ìta gbangba,

ati àwọn ọdọmọkunrin níbi tí wọ́n péjọ sí.

Ogun yóo kó wọn, tọkọtaya,

àtàwọn àgbàlagbà àtàwọn arúgbó kùjọ́kùjọ́.

12 Ilé wọn yóo di ilé onílé,

oko wọn, ati àwọn aya wọn pẹlu, yóo di ti ẹni ẹlẹ́ni.

Nítorí pé n óo na ọwọ́ ibinu mi sí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

13 OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,

gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù;

láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa,

èké ni gbogbo wọn.

14 Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jiná,

wọ́n ń kígbe pé: ‘Alaafia ni, alaafia ni’,

nígbà tí kò sí alaafia.

15 Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?

Rárá o, ojú kì í tì wọ́n; nítorí pé wọn kò lójútì.

Nítorí náà, àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,

a ó bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Israẹli Kọ Ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀

16 OLUWA ní,

“Ẹ lọ dúró ní oríta kí ẹ wo òréré,

ẹ bèèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́,

níbi tí ọ̀nà dáradára wà, kí ẹ sì máa tọ̀ ọ́.

Kí ẹ lè ní ìsinmi.”

Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọ́n ní,

“A kò ní tọ ọ̀nà náà.”

17 Mo fi àwọn aṣọ́nà ṣọ́nà nítorí yín.

Mo wí fún wọn pé,

“Ẹ máa dẹtí sílẹ̀ sí fèrè ogun!”

Ṣugbọn wọ́n ní, “A kò ní dẹtí sílẹ̀.”

18 OLUWA ní, “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

kí ẹ̀yin eniyan sì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.

19 Gbọ́! Ìwọ ilẹ̀;

n óo fa ibi lé àwọn eniyan wọnyi lórí,

wọn óo jèrè èso ìwà burúkú wọn;

nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,

wọ́n sì ti tàpá sí òfin mi.

20 Kí ni anfaani turari,

tí wọn mú wá fún mi láti Ṣeba,

tabi ti ọ̀pá turari olóòórùn dídùn tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè wá?

N kò tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹbọ sísun tí ẹ mú wá siwaju mi,

bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ yín kò dùn mọ́ mi.

21 Nítorí náà, n óo gbé ohun ìdínà sọ́nà fún àwọn eniyan wọnyi,

wọn óo sì fẹsẹ̀ kọ;

ati baba, àtọmọ wọn,

àtaládùúgbò, àtọ̀rẹ́,

gbogbo wọn ni yóo parun.”

Ogun láti Ìhà Àríwá

22 OLUWA ní,

“Wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,

orílẹ̀-èdè ńlá ń gbéra bọ̀ láti òpin ayé.

23 Wọ́n ń kó ọrun ati ọ̀kọ̀ bọ̀,

ìkà ni wọ́n, wọn kò sì lójú àánú.

Ìró wọn dàbí híhó omi òkun,

bí wọ́n ti ń gun ẹṣin bọ̀.

Wọ́n tò bí àwọn tí ń lọ sójú ogun,

wọ́n dótì ọ́, ìwọ Jerusalẹmu!”

24 A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ;

ìdààmú dé bá wa,

bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí.

25 Ẹ má lọ sinu oko,

ẹ má sì ṣe rìn lójú ọ̀nà náà,

nítorí ọ̀tá mú idà lọ́wọ́,

ìdágìrì sì wà káàkiri.

26 Ẹ̀yin eniyan mi,

ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ máa yí ninu eérú;

ẹ máa ṣọ̀fọ̀, bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo;

kí ẹ sì máa sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,

nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóo bò yín.

27 Mo ti fi ọ́ ṣe ẹni tí yóo máa dán àwọn eniyan mi wò,

o óo máa dán wọn wò bí ẹni dán irin wò,

o óo gbìyànjú láti mọ ọ̀nà wọn,

kí o lè yẹ ọ̀nà wọn wò, kí o sì mọ̀ ọ́n.

28 Ọlọ̀tẹ̀, aláìgbọràn ni gbogbo wọn,

wọn á máa sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn.

Wọ́n dàbí idẹ àdàlú mọ́ irin,

àmúlùmálà ni gbogbo wọn.

29 Lóòótọ́ à ń fi ẹwìrì fẹ́ iná,

òjé sì ń yọ́ lórí iná;

ṣugbọn alágbẹ̀dẹ ń yọ́ irin lásán ni,

kò mú ìbàjẹ́ ara rẹ̀ kúrò.

30 Ìdọ̀tí fadaka tí a kọ̀ tì ni wọ́n,

nítorí pé OLUWA ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 7

Jeremaya Waasu ninu Tẹmpili

1 OLUWA rán Jeremaya níṣẹ́, ó ní

2 kí Jeremaya dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, kí ó sì kéde pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé láti sin OLUWA.

3 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Ẹ tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe, kí n lè jẹ́ kí ẹ máa gbé ìhín.

4 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí pé: “Tẹmpili OLUWA nìyí, kò séwu, tẹmpili OLUWA nìyí.”

5 “ ‘Bí ẹ bá tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ bá ń dá ẹjọ́ òtítọ́,

6 tí ẹ kò bá fi ìyà jẹ àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, tabi àwọn opó, tabi kí ẹ máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì máa bọ oriṣa káàkiri, kí ẹ fi kó bá ara yín,

7 n óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí títí lae, lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti ìgbà laelae.

8 “ ‘Ẹ wò ó! Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò lè mú èrè wá ni ẹ gbójú lé.

9 Ṣé ẹ fẹ́ máa jalè, kí ẹ máa pa eniyan, kí ẹ máa ṣe àgbèrè, kí ẹ máa búra èké, kí ẹ máa sun turari sí oriṣa Baali, kí ẹ máa bọ àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ káàkiri;

10 kí ẹ sì tún máa wá jọ́sìn níwájú mi ninu ilé yìí, ilé tí à ń fi orúkọ mi pè; kí ẹ máa wí pé, “OLUWA ti gbà wá là;” kí ẹ sì tún pada lọ máa ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí ẹ tí ń ṣe?

11 Ṣé lójú tiyín, ilé yìí, tí à ń fi orúkọ mi pè, ó ti wá di ibi ìsápamọ́ sí fún àwọn olè? Mo ti ri yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

12 Nisinsinyii, ẹ lọ sí ilé mi ní Ṣilo, níbi ìjọ́sìn mi àkọ́kọ́, kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i, nítorí ìwà burúkú Israẹli, àwọn eniyan mi.

13 Nisinsinyii, nítorí gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe wọnyi, tí mo sì ń ba yín sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́, tí ẹ kò gbọ́, tí mo pè yín, tí ẹ kò dáhùn,

14 bí mo ti ṣe sí Ṣilo ni n óo ṣe ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, tí ẹ gbójú lé; ati ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15 N óo le yín kúrò níwájú mi, bí mo ti lé àwọn ọmọ Efuraimu, tí wọ́n jẹ́ arakunrin yín dànù.’ ”

Àìgbọràn Àwọn Eniyan náà

16 OLUWA ní, “Ìwọ Jeremaya ní tìrẹ, má bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan wọnyi, má sọkún nítorí wọn, tabi kí o gbadura fún wọn. Má sì bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí n kò ní gbọ́.

17 Ṣé o kò rí àwọn ohun tí wọn ń ṣe ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu ni?

18 Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn baba wọn ń dá iná, àwọn obinrin ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà fún Ayaba Ọ̀run. Wọ́n sì ń ta ọtí sílẹ̀ fún àwọn oriṣa láti mú mi bínú.

19 Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn?

20 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo tú ibinu gbígbóná mi sórí ibí yìí, n óo bínú sí eniyan ati ẹranko, ati igi oko ati èso ilẹ̀. Ibinu mi óo jó wọn run bí iná, kò sì ní ṣe é pa.

21 “Ẹ da ẹbọ sísun yín pọ̀ mọ́ ẹran tí ẹ fi rúbọ, kí ẹ lè rí ẹran jẹ; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22 Nítorí ní ọjọ́ tí mo kó àwọn baba yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, n kò bá wọn sọ̀rọ̀ ẹbọ sísun tabi ẹbọ rírú, bẹ́ẹ̀ ni n kò pàṣẹ rẹ̀ fún wọn.

23 Àṣẹ tí mo pa fún wọn ni pé kí wọn gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ní n óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà óo sì máa jẹ́ eniyan mi; mo ní kí wọn máa tọ ọ̀nà tí mo bá pa láṣẹ fún wọn, kí ó lè dára fún wọn.

24 Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì tẹ́tí sí mi. Wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn, wọ́n ń ṣe oríkunkun, dípò kí wọ́n máa lọ siwaju, ẹ̀yìn ni wọ́n ń pada sí.

25 Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní ilẹ̀ Ijipti títí di òní, lojoojumọ ni mò ń rán àwọn wolii iranṣẹ mi sí wọn léraléra.

26 Sibẹ wọn kò gbọ́ tèmi, wọn kò tẹ́tí sí mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, oríkunkun ni wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ burúkú wọn ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ.

27 “Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn.

28 O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’

Ìwà Ẹ̀ṣẹ̀ ní Àfonífojì Hinomu

29 “Ẹ gé irun orí yín dànù,

ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè,

nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀,

ó ti fi ibinu ta ìran yín nù.

30 “Àwọn ọmọ Juda ti ṣe nǹkan burúkú. Wọ́n gbé ère wọn kalẹ̀ ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́.

31 Wọ́n kọ́ pẹpẹ Tofeti ní àfonífojì Hinomu, wọ́n ń sun àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn níná níbẹ̀. N kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún wọn; irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ fi ìgbà kan sí lọ́kàn mi.

32 Nítorí náà nígbà tó bá yá, a kò ní pè é ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́, àfonífojì ìpànìyàn ni a óo sì máa pè é. Tofeti ni wọn yóo sì máa sin òkú sí nígbà tí kò bá sí ààyè ní ibòmíràn mọ́.

33 Òkú àwọn eniyan yìí yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati fún àwọn ẹranko, kò sì ní sí ẹni tí yóo lé wọn.

34 N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní Jerusalẹmu, a kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé níbẹ̀ mọ́; nítorí pé n óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro.

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 8

1 “Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu.

2 Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀.

3 Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà

4 OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé,

“Ṣé bí eniyan bá ṣubú

kì í tún dìde mọ́?

Àbí bí eniyan bá ṣìnà,

kì í pada mọ́?

5 Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipada

kúrò lọ́dọ̀ mi,

tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn?

Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́;

wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.

6 Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn,

ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere.

Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀,

kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’

Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú,

bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.

7 Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀;

wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada.

Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.

8 Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé,

‘Ọlọ́gbọ́n ni wá,

a sì mọ òfin OLUWA?’

Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké.

9 Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n:

ìdààmú yóo bá wọn,

ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.

Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀,

ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n?

10 Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn,

n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn.

Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù,

títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,

gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù.

Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn.

11 Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná,

wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’

bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia.

12 Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n

nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́?

Rárá o, ojú kì í tì wọ́n,

nítorí pé wọn kò lójútì.

Nítorí náà àwọn náà óo ṣubú

nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú,

a óo bì wọ́n ṣubú

nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà,

OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

13 “Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà,

igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí,

àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ,

ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn.

Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

14 Àwọn eniyan Ọlọrun bá dáhùn pé,

“Kí ló dé tí a fi jókòó jẹ̀kẹ̀tẹ̀?

Ẹ jẹ́ kí á kó ara wa jọ,

kí á sá lọ sí àwọn ìlú olódi,

kí á sì parun sibẹ;

nítorí OLUWA Ọlọrun wa ti fi wá lé ìparun lọ́wọ́,

ó ti fún wa ní omi tí ó ní májèlé mu,

nítorí pé a ti ṣẹ̀ ẹ́.

15 À ń retí alaafia,

ṣugbọn ire kankan kò dé.

Àkókò ìwòsàn ni à ń retí,

ṣugbọn ìpayà ni a rí.

16 Ẹ gbọ́ bí ẹṣin wọn tí ń fọn imú, ní ilẹ̀ Dani;

gbogbo ilẹ̀ ń mì tìtì nítorí ìró yíyan ẹṣin wọn.

Wọ́n wá run ilẹ̀ náà,

ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,

ati ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.”

17 OLUWA ní, “Wò ó! N óo rán ejò sí ààrin yín:

paramọ́lẹ̀ tí kò ní gbóògùn;

wọn yóo sì bù yín jẹ.”

Jeremaya Káàánú fún Àwọn Eniyan Rẹ̀

18 Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn,

àárẹ̀ mú ọkàn mi.

19 Ẹ gbọ́ igbe àwọn eniyan mi

jákèjádò ilẹ̀ náà tí wọn ń bèèrè pé,

“Ṣé OLUWA kò sí ní Sioni ni?

Tabi ọba rẹ̀ kò sí ninu rẹ̀ ni?”

OLUWA, ọba wọn dáhùn pé,

“Kí ló dé tí wọn ń fi ère wọn mú mi bínú,

pẹlu àwọn oriṣa ilẹ̀ àjèjì tí wọn ń bọ?”

20 Àwọn eniyan ní, “Ìkórè ti parí,

àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn ti kọjá,

sibẹ a kò rí ìgbàlà.”

21 Nítorí ọgbẹ́ àwọn eniyan mi ni ọkàn mi ṣe gbọgbẹ́.

Mò ń ṣọ̀fọ̀, ìdààmú sì bá mi.

22 Ṣé kò sí ìwọ̀ra ní Gileadi ni?

Àbí kò sí oníwòsàn níbẹ̀?

Kí ló dé tí àìsàn àwọn eniyan mi kò sàn?

Categories
JEREMAYA

JEREMAYA 9

1 Orí mi ìbá jẹ́ kìkì omi,

kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé;

tọ̀sán-tòru ni ǹ bá fi máa sọkún,

nítorí àwọn eniyan mi tí ogun ti pa.

2 Ìbá ṣe pé mo ní ilé èrò kan ninu aṣálẹ̀,

ǹ bá kó àwọn eniyan mi dà sílẹ̀ níbẹ̀,

ǹ bá sì kúrò lọ́dọ̀ wọn;

nítorí alágbèrè ni gbogbo wọn,

ati àgbájọ àwọn alárèékérekè eniyan.

3 Bí ẹni kẹ́ ọrun ni wọ́n kẹ́ ahọ́n wọn,

láti máa fọ́n irọ́ jáde bí ẹni ta ọfà;

dípò òtítọ́ irọ́ ní ń gbilẹ̀ ní ilẹ̀ náà.

OLUWA ní,

“Wọ́n ń tinú ibi bọ́ sinu ibi,

wọn kò sì mọ̀ èmi OLUWA.”

4 Kí olukuluku ṣọ́ra lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀,

kí ó má sì gbẹ́kẹ̀lé arakunrin rẹ̀ kankan.

Nítorí pé ajinnilẹ́sẹ̀ ni gbogbo arakunrin,

a-fọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ sì ni gbogbo aládùúgbò.

5 Olukuluku ń tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ,

kò sì sí ẹnìkan tí ń sọ òtítọ́.

Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn ní irọ́ pípa;

wọ́n dẹ́ṣẹ̀ títí, ó sú wọn,

wọn kò sì ronú àtipàwàdà.

6 Ìninilára ń gorí ìninilára,

ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn,

OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.”

7 Nítorí náà, ó ní:

“Wò ó! N óo fọ̀ wọ́n mọ́,

n óo dán wọn wò.

Àbí, kí ni kí n tún ṣe fún àwọn eniyan yìí?

8 Ahọ́n wọn dàbí ọfà apanirun,

wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

Olukuluku ń sọ̀rọ̀ alaafia jáde lẹ́nu fún aládùúgbò rẹ̀,

ṣugbọn ète ikú ni ó ń pa sí i ninu ọkàn rẹ̀.

9 Ṣé n kò wá ní jẹ wọ́n níyà fún àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe wọnyi?

Àbí n kò ní gbẹ̀san ara mi lára irú orílẹ̀-èdè yìí?”

10 Mo ní, “Gbé ẹnu sókè kí o sọkún nítorí àwọn òkè ńlá,

sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn pápá inú aṣálẹ̀,

nítorí gbogbo wọn ti di ahoro, láìsí ẹnìkan tí yóo la ààrin wọn kọjá.

A kò ní gbọ́ ohùn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀.

Ati ẹyẹ, ati ẹranko, gbogbo wọn ti sá lọ.”

11 OLUWA ní, “N óo sọ Jerusalẹmu di àlàpà ati ibùgbé ajáko.

N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro

ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú wọn mọ́.

Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12 Mo bá bèèrè pé, “Ta ni ẹni tí ó gbọ́n, tí òye nǹkan yìí yé? Ta ni OLUWA ti bá sọ̀rọ̀, kí ó kéde rẹ̀? Kí ló dé tí ilẹ̀ náà fi parun, tí ó sì dàbí aṣálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò fi gba ibẹ̀ kọjá?”

13 OLUWA bá dáhùn, ó ní, “Nítorí pé wọ́n kọ òfin tí mo gbékalẹ̀ fún wọn sílẹ̀, wọn kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi,

14 ṣugbọn wọ́n ń fi agídí ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, bí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn.

15 Nítorí náà, n óo fún wọn ní igi tí ó korò jẹ, n óo sì fún wọn ní omi tí ó ní májèlé mu. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16 N óo fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ati àwọn baba ńlá wọn kò mọ̀, n óo sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ idà tẹ̀lé wọn títí tí n óo fi pa wọ́n run.”

Àwọn Eniyan Jerusalẹmu kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́

17 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:

“Ẹ ronú sí ọ̀rọ̀ yìí kí ẹ pe àwọn obinrin tíí máa ń ṣọ̀fọ̀ wá,

ẹ ranṣẹ pe àwọn obinrin tí wọ́n mọ ẹkún sun dáradára;

18 kí wọ́n wá kíá,

kí wọ́n wá máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lé wa lórí,

kí omi sì máa dà lójú wa pòròpòrò.

19 Nítorí a gbọ́ tí ẹkún sọ ní Sioni,

wọ́n ń ké pé, ‘A gbé!

Ìtìjú ńlá dé bá wa,

a níláti kó jáde nílé,

nítorí pé àwọn ọ̀tá ti wó ilé wa.’ ”

20 Mo ní, “Ẹ̀yin obinrin, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,

ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.

Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín obinrin ní ẹkún sísun,

kí ẹ sì kọ́ aládùúgbò yín ní orin arò.

21 Nítorí ikú ti dé ojú fèrèsé wa,

ó ti wọ ààfin wa.

Ikú ń pa àwọn ọmọde nígboro,

ati àwọn ọdọmọkunrin ní gbàgede.”

22 Sọ wí pé,

“Òkú eniyan yóo sùn lọ nílẹ̀ bí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí pápá tí ó tẹ́jú,

ati bíi ìtí ọkà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń kórè ọkà,

kò sì ní sí ẹni tí yóo kó wọn jọ. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

23 OLUWA ní, “Kí ọlọ́gbọ́n má fọ́nnu nítorí ọgbọ́n rẹ̀,

kí alágbára má fọ́nnu nítorí agbára rẹ̀;

kí ọlọ́rọ̀ má sì fọ́nnu nítorí ọrọ̀ rẹ̀.

24 Ṣugbọn ẹni tí ó bá fẹ́ fọ́nnu,

ohun tí ó lè máa fi fọ́nnu ni pé òun ní òye

ati pé òun mọ̀ pé, èmi OLUWA ni OLUWA tí ń ṣe ẹ̀tọ́,

tí sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òdodo hàn lórí ilẹ̀ ayé;

nítorí pé àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni mo ní inú dídùn sí.”

25 Ó ní, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo fìyà jẹ àwọn tí a kọ nílà, ṣugbọn tí wọn ń ṣe bí aláìkọlà,

26 àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.”